Ireti—Idaabobo Ṣiṣekoko Ninu Ayé Amúnirẹ̀wẹ̀sì Kan
Ọdọmọdekunrin ara Korea kan fẹ lati ran iya rẹ̀ lọwọ lati yí ọkàn akẹkọọ kọ́lẹ́ẹ̀jì kan pada lori bi o ti ṣe pataki tó lati ní ireti fun ọjọ-ọla. Ni riranti àkàwé kan ti o ti gbọ́ ni ipade Kristian, o beere lọwọ akẹkọọ naa bi yoo bá bá oun yanju àlọ́ kan. O gbà bẹẹ. O wá sọ pe: “Awọn idile meji kan wà. Awọn mejeeji talaka gidigidi. Òjò ń rọ̀ gan-an, ti òrùlé ilé mejeeji si ń jò. Inu idile kan bajẹ gidigidi, ti wọn si ṣàròyé pupọ nipa ile jíjò naa. Ṣugbọn idile keji layọ ti inu wọn si dun bi wọn ti ń dí òrùlé jíjò naa. Eeṣe ti iyatọ pup̣ọ tobẹẹ fi wà laaarin awọn idile meji wọnyii?” Bi a ti ru ú lọkan soke, ọdọbinrin naa dahun pe oun kò mọ̀. “O dara,” ni ọmọdekunrin naa wi, “idile keji layọ nitori pe wọn ṣẹṣẹ gba ifitonileti lati ọ̀dọ̀ ijọba ilu-nla naa pe awọn ni a o fun ní ilé titun. Nitori naa wọn ni ireti. Iyẹn ni iyatọ naa!”
ÀLỌ́ ọmọdekunrin naa ṣàkàwé otitọ rirọrun kan: Ireti ń yi ọ̀nà ti a gbà ń nimọlara nipa igbesi-aye pada, lọpọ ìgbà laika awọn ayika ipo wa si. Gẹgẹ bi awọn idile meji ti ó ṣapejuwe, ọpọ julọ ninu wa nilati fàyà rán awọn idanwo lilekoko ninu igbesi-aye—awọn iṣoro ilera, àníyàn ọ̀ràn inawo, pakanleke idile, iwa-ọdaran, ati ailonka awọn iṣoro ati iloni nilokulo miiran. Lọpọ ìgbà awa kò lè mu ki iru awọn iṣoro bẹẹ kuro bi a kò ti lè mu ìjì-líle kuro ni ayika wa. Nitori naa a lè nimọlara ijakulẹ, idanikanwa—ni kukuru, àlaìlólùrànlọ́wọ́. Lati mu ọ̀ràn buru sii, a ti lè fi kọ́ wa ni ṣọọṣi pe kò si ireti ọjọ-ọla kankan fun ọpọ julọ ninu awọn ẹlẹṣẹ, pe o lè ní ninu didi ẹni ti a fìyàjẹ titi ayeraye.
A ti sọ pe eroja fun didi ẹni ti o sorikọ ni àìlólùrànlọ́wọ́ ati ainireti. Ṣugbọn o daju gbangba pe awa lè mu ọ̀kan ninu awọn eroja wọnni kuro; kò si ẹnikẹni ninu wa ti o nilati jẹ alainireti. Ireti funraarẹ si lè jẹ́ ohun-ija didara julọ lati mu eroja keji kuro, imọlara àìlólùrànlọ́wọ́. Bi a bá ní ireti, awa lè foriti awọn iṣoro igbesi-aye pẹlu ìwọ̀n iparọrọ ati itẹlọrun dipo biba ijakadi lọ ninu ibanujẹ patapata. Bẹẹni, ireti jẹ idaabobo ṣiṣekoko kan.
Ǹjẹ́ iru ìjẹ́wọ́ bẹẹ ha mu ki o ṣiyemeji bi? Ireti ha fi bẹẹ lagbara niti gidi bi debi pe o lè mú iyatọ pupọ yẹn wa? Ireti ṣiṣeegbarale ha si wa larọọwọto fun ẹnikọọkan wa bi?
Gẹgẹ bi Aṣibori Kan
Papa iṣegun ti bẹrẹ sii mọ agbara pipẹtẹri ti ireti lara. Ẹnikan ti o la Iparundeeru rẹpẹtẹ ti Nazi ja, ogbontagi oniṣegun masunmawo Dokita Shlomo Breznitz, sọ pe ninu ọpọlọpọ ọ̀ràn iṣoro igbesi-aye, “masunmawo ń wá lati inu ọ̀nà ti a gbà ń ṣetumọ inira wọn, kìí ṣe awọn iṣoro naa funraawọn. Ireti ń mú iwuwo wọn dinku.” Ọrọ-ẹkọ kan ninu The Journal of the American Medical Association tẹnumọ ọn pe ireti jẹ́ “oògùn alagbara kan.” Iwe-irohin American Health rohin pe: “Ọpọlọpọ apẹẹrẹ awọn alaisan ni ń bẹ, ni pataki awọn alaisan jẹjẹrẹ, ti ipo wọn dede buru sii nigba ti ohun kan bá mú ki wọn padanu ireti—tabi ti wọn dede sunwọn sii nigba ti wọn rí ohun titun kan lati walaaye fun.”—Fiwe Owe 17:22.
Tipẹtipẹ ni awọn akẹkọọ Bibeli ti mọ ijẹpataki ireti. Ni 1 Tessalonika 5:8, aposteli Paulu rọ awọn Kristian pe: “Ẹ jẹ ki awa, . . . maa wà ni airekọja, ki a maa gbé . . . ireti igbala [wọ̀] fun aṣibori.” Bawo ni “ireti igbala” ṣe dabi aṣibori?
Gbé ohun ti aṣibori kan ń ṣe yẹwo. Awọn ọmọ-ogun ni akoko ti a kọ Bibeli ń wọ aṣibori bàbà tabi ti irin, ti a wọ̀ sori fila alaṣọ ninipọn, tabi onirun-agutan, tabi aláwọ. Aṣibori yii ń daabobo ori rẹ̀ lọwọ awọn ọfà ti ń ta bọ̀n-ùn, ọ̀gọ ti ń fì siwa-sẹhin, ati awọn idà ija-ogun ti ń gbá araawọn. Ó ṣeeṣe, nigba naa, ki ó jẹ pe awọn ọmọ-ogun diẹ ni wọn lọ́tìkọ̀ lati wọ aṣibori bi wọn bá ní ọ̀kan. Bi o ti wu ki o ri, wíwọ aṣibori naa kò tumọ si pe ọmọ-ogun naa ni a kò lè bori tabi pe oun kò nimọlara ohunkohun nigba ti nǹkan bá gbá orí rẹ̀; kaka bẹẹ, aṣibori naa wulẹ mú un daju pe ọpọ julọ awọn ọfà yoo ta danu dipo ṣiṣe ibajẹ ti o lè ṣekupani.
Gẹgẹ bi aṣibori kan ṣe ń daabobo ori, bẹẹni ireti ṣe ń daabobo ero-inu. Ireti lè ṣalaimu ki o ṣeeṣe fun wa lati gbọn yanpọnyanrin tabi ifasẹhin kọọkan danu gẹgẹ bi ẹni pe kò jamọ ohunkohun. Ṣugbọn ireti ń fara gba iru awọn ikọlu bẹẹ ó sì ń ràn wá lọwọ lati rí i daju pe wọn kò jasi aṣekupani si ilera wa niti ero-ori, ero-imọlara, tabi tẹmi.
Ọkunrin oluṣotitọ naa Abrahamu ni kedere wọ aṣibori afiṣapẹẹrẹ yii. Jehofa sọ fun un pe ki o fi ọmọkunrin rẹ aayo-olufẹẹ, Isaaki rubọ. (Genesisi 22:1, 2) Bawo ni ìbá ti rọrùn tó fun Abrahamu lati ṣubu sinu ainireti, imọlara kan ti o ti lè ṣamọna rẹ̀ daradara lati ṣaigbọran si Ọlọrun. Ki ni ó daabobo ero-inu rẹ̀ kuro lọwọ iru awọn imọlara bẹẹ? Ireti kó ipa pataki kan. Gẹgẹ bi Heberu 11:19 ṣe sọ, “o sì pari rẹ̀ si pe Ọlọrun tilẹ lè gbé e [Isaaki] dide, àní kuro ninu oku.” Bakan naa, ireti Jobu ninu ajinde ṣeranwọ lati daabobo ero-inu rẹ̀ lọwọ ìkorò-inú, ti o ti lè ṣamọna rẹ̀ si fifi Ọlọrun ré. (Jobu 2:9, 10; 14:13-15) Jesu Kristi, ni oju iku onirora, rí okun ati itunu ninu ireti alayọ rẹ̀ fun ọjọ-ọla. (Heberu 12:2) Igbọkanle naa pe Ọlọrun kò ni ṣe aitọ, kò tíì kùnà lati mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ ri, ni ipilẹ fun ireti tootọ.—Heberu 11:1.
Ipilẹ fun Ojulowo Ireti
Bi igbagbọ, ojulowo ireti ni a gbekari okodoro, otitọ-gidi, ati otitọ. Eyi lè ya awọn kan lẹnu. Gẹgẹ bi onkọwe kan ṣe sọ́, “o jọ pe pupọ julọ ninu awọn eniyan ronu pe ireti wulẹ jẹ́ iru ọ̀nà omugọ kan lati gbà sẹ́ otitọ.” Sibẹ, ireti tootọ kìí wulẹ ṣe ẹmi ireti bi-o-tilẹ-pẹ́ nǹkan yoo dara, òbu igbagbọ pe awa yoo ri ohunkohun ti a bá fẹ́ tabi pe gbogbo awọn iṣoro wa keekeeke ni a o yanju fun wa. Otitọ gidi yoo fopin si iru itanjẹ meremere bẹẹ.—Oniwasu 9:11.
Ireti gidi yatọ. Ó ń wá lati inu ìmọ̀, kìí ṣe idaniyanfẹ. Gbé idile keji ninu àlọ́ ti a mẹnukan ni ibẹrẹ yẹwo. Ireti wo ni wọn ìbá ti ní bi ijọba wọn bá ti jẹ́ olokiki buruku fun ṣiṣaimu awọn ileri rẹ̀ ṣẹ? Kaka bẹẹ, ileri naa ati ẹ̀rí iṣeegbarale rẹ̀ lè fun idile naa ni idi gbigbopọn fun ireti.
Lọna kan-naa, awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lonii ní ireti ti o sopọ pẹkipẹki mọ ijọba kan—Ijọba Ọlọrun. Ijọba yii wà ni aarin gbùngbùn ihin-iṣẹ Bibeli. Fun ọpọ ẹgbẹrundun ó ti jẹ́ orisun ireti fun awọn obinrin ati ọkunrin, bii Abrahamu. (Heberu 11:10) Ọlọrun ṣeleri pe nipa Ijọba rẹ̀, oun yoo mú opin wá si eto-igbekalẹ ayé ogbologboo yii oun yoo sì mú ọ̀kan ti o jẹ́ titun wọle wá. (Romu 8:20-22; 2 Peteru 3:13) Ireti Ijọba yii jẹ́ gidi, kìí ṣe àlá. Orisun rẹ̀—Jehofa Ọlọrun, Oluwa Ọba-alaṣẹ Agbaye—jẹ́ alaiṣeegbeyemeji dide si, laisasọdun. O wulẹ yẹ ki a ṣayẹwo iṣẹda Ọlọrun ti a lè fojuri lati rí i pe o wà ati pe ó ni agbara ti o tó lati mu gbogbo ileri rẹ̀ ṣẹ. (Romu 1:20) Kiki ohun ti a nilo ni lati ṣayẹwo akọsilẹ awọn ibalo rẹ̀ pẹlu araye finnifinni lati rí i pe ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò tíì lọ laini imuṣẹ rí.—Isaiah 55:11.
Lọna ti o banininujẹ, bi o ti wu ki o ri, ọpọ julọ awọn ti wọn sọ pe Kristian ni awọn ti gbagbe ireti tootọ. Ẹlẹkọọ-isin Paul Tillich sọ ninu iwaasu kan ti a tẹjade ni ẹnu aipẹ yii pe: “Awọn Kristian [ijimiji] kẹkọọ lati duro de opin. Ṣugbọn ni kẹrẹkẹrẹ wọn ṣiwọ diduro. . . . Ifojusọna naa fun ipo awọn nǹkan titun lori ilẹ̀-ayé di alailera, bi o tilẹ jẹ pe ẹnikan gbadura fun un ninu gbogbo Adura Oluwa—Ifẹ tirẹ ni ki a ṣe, bii ti ọrun, bẹẹni ni ayé!”
Iru àjálù-ibi wo ni eyi jẹ́! Araadọta-ọkẹ, àní araadọta-ọkẹ lọna ẹgbẹẹgbẹrun, awọn eniyan ti wọn wà ninu aini gidigidi fun ireti kò ní i rárá, sibẹ o wa larọọwọto ni sẹpẹ́ fun wọn nibẹ ninu Bibeli tiwọn. Ẹ wo iyọrisi amunirẹwẹsi ti eyi jẹ́! Laisi ireti ti o yekooro lati daabobo ero-inu wọn, o ha jẹ́ ohun iyanu eyikeyii pe “iyè ríra” ti ṣamọna ọpọlọpọ tobẹẹ lati fi iwapalapala ati iwa-ipa ti o wọpọ sọ ayé di eléèérí bi? (Romu 1:28) Ó ṣe pataki pe ki awa maṣe ṣubu sinu páńpẹ́ kan-naa lae. Dipo gbigbe aṣibori ireti sọnu, a nilati maa mú un lokun ni gbogbo ìgbà.
Bi O Ṣe Lè Gbé Ireti Rẹ Ró
Ọ̀nà didara julọ lati gbé ireti ró ni lati ṣakiyesi orisun rẹ̀, Jehofa Ọlọrun. Fi taapọntaapọn, kẹkọọ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bibeli. Romu 15:4 sọ pe: “Ohunkohun ti a ti kọ tẹlẹ, a ti kọ ọ́ fun kíkọ́ wa, pe nipa suuru ati itunu iwe mimọ ki a lè ni ireti.”
Siwaju sii, a nilati rí i daju pe ireti wa fun ọjọ-ọla kìí wulẹ ṣe ohun àfinúrò kan tí kò daniloju. A nilati sọ ọ́ di gidi ninu ero-inu wa. Iwọ ha nireti lati walaaye titilae ninu Paradise lori ilẹ̀-ayé bi? Iwọ yoo ha fẹ́ lati pade awọn ololufẹẹ rẹ nigba ti a bá jí wọn dide sori ilẹ̀-ayé bi? Bi o bá ri bẹẹ, iwọ ha foju yaworan wiwa nibẹ rẹ̀ ni akoko yẹn bi? Fun apẹẹrẹ, Isaiah 65:21, 22 sọ nipa olukuluku ti ń kọ́ ile tirẹ̀ funraarẹ ti o sì ń gbé inu rẹ̀. Iwọ ha lè di oju rẹ ki o sì ronu araarẹ ti o ń ṣiṣẹ lori orule ile rẹ titun, ti o ń gbá patako kekere ti o kẹhin wọlẹ bi? Ṣá ronu nipa wiwo iyọrisi gbogbo iwewee ati laalaa rẹ ni ayika. Awọn ìró ohùn ọlọ́yàyà ti ilé kíkọ́ rọlẹ̀ wọ̀ọ̀; iwọ yẹ oju ilẹ naa wò bi ojiji ọ̀sán ti ṣẹ́bò ó lori. Afẹfẹlẹlẹ mú ki awọn igi maa mì rìyẹ̀rìyẹ̀ ti wọn sì ń tù ọ́ lara kuro lọwọ ooru iṣẹ rẹ. Ẹ̀rín kèékèé awọn ọmọde, ti o dapọ pẹlu igbe awọn ẹyẹ, ń ta si ọ leti. Ijumọsọrọpọ awọn ololufẹẹ rẹ de etígbọ̀ọ́ rẹ nibi ti o wa lori orule.
Fifoju-inu yaworan iru akoko alayọ bẹẹ kìí ṣe aba-imefo asán; kaka bẹẹ, ironujinlẹ lori asọtẹlẹ ti o daju pe yoo ni imuṣẹ ni. (2 Korinti 4:18) Bi ifojusọna yẹn bá ti jẹ́ gidi si ọ tó, bẹẹ ni ireti rẹ pe iwọ yoo wà nibẹ yoo ti lagbara tó. Iru ireti gbọnyingbọnyin, ti o jẹ gidi bẹẹ yoo daabobo ọ kuro lọwọ ‘titiju ihinrere,’ ti o lè mu ọ yẹ iṣẹ-ayanfunni ti ṣiṣajọpin rẹ̀ pẹlu awọn ẹlomiran silẹ. (Romu 1:16) Ni odikeji, iwọ yoo fẹ́ lati ‘ṣogo ninu ireti’ gẹgẹ bi aposteli Paulu ti ṣe, nipa fifi tigboyatigboya ṣajọpin rẹ̀ pẹlu awọn ẹlomiran.—Heberu 3:6.
Ohun ti o funni ni ireti ju ọjọ-ọla ayeraye lọ. Awọn orisun ireti ń bẹ ni lọ́ọ́lọ́ọ́ yii pẹlu. Bawo ni o ṣe rí bẹẹ? Aṣaaju-oṣelu Romu ọrundun karun-un C.E. ti a ń pe ni Cassiodorus sọ pe: “Ẹni ti o mọ anfaani ohun ti o ti ṣẹlẹ ná gba ireti nipa ọjọ-ọla.” Eyi ti jẹ́ awọn ọ̀rọ̀ ọlọgbọn tó! Itunu wo ni awa yoo rí ninu awọn ileri ibukun ọjọ-ọla bi awa kò bá lè mọriri awọn ibukun ti a ń gbadun ni lọwọlọwọ?
Adura tun ń gbé ireti ró nisinsinyi. Yatọ si gbigbadura fun ọjọ-ọla onigba pipẹ, a nilati gbadura fun awọn aini wa ti isinsinyi. A lè nireti ki a sì gbadura fun ipo-ibatan sisunwọn sii pẹlu awọn mẹmba idile ati awọn Kristian ẹlẹgbẹ wa, fun ounjẹ wa tẹmi ti yoo tẹle e, àní lati kaju awọn aini wa nipa ti ara paapaa. (Orin Dafidi 25:4; Matteu 6:11) Fifi iru awọn ireti bẹẹ sọwọ Jehofa yoo ràn wá lọwọ lati farada a lojoojumọ. (Orin Dafidi 55:22) Bi a ti ń farada a, ifarada wa funraarẹ yoo tun fun aṣibori ireti lokun.—Romu 5:3-5.
Wiwo Awọn Eniyan Pẹlu Oju-Iwoye Ti O Kun fun Ireti
Ironu òdì dabi ìpẹtà lara aṣibori ireti naa. Ó jẹ́ amóhundípẹtà, ati ni kẹrẹkẹrẹ ó lè sọ aṣibori naa di alaiwulo. Iwọ ha ti kẹkọọ lati dá èrò òdì mọ ki o sì gbejako o bi? Maṣe jẹ ki a tàn ọ́ jẹ nipasẹ èrò àṣìrò naa pe iṣarasihuwa alainigbọkanle, onilameyitọ, ẹlẹmii-nnkan-yoo-buru jẹ ọ̀kan naa pẹlu ọgbọn-oye. Niti gasikiya, èrò òdì kò beere ọgbọn-oye pupọ.
O ti maa ń rọrun ju lati ní iṣarasihuwa ainireti nipa awọn eniyan ẹlẹgbẹ wa. Awọn kan, nitori awọn iriri aronilara ni ìgbà atijọ, ti sọ̀rètínù niti riri iranlọwọ tabi itunu gbà lae lati ọ̀dọ̀ awọn eniyan. “Èsìsì kìí jóni lẹẹmeji” ni akọle ti wọn ń tẹle. Wọn tilẹ lè lọ́tìkọ̀ lati lọ sọdọ awọn Kristian alagba fun iranlọwọ pẹlu awọn iṣoro wọn.
Bibeli ràn wá lọwọ lati fi oju ti o tubọ wà deedee wo awọn eniyan. Loootọ, kò bá ọgbọn mu lati fi gbogbo ireti wa sinu eniyan. (Orin Dafidi 146:3, 4) Ṣugbọn ninu ijọ Kristian, awọn alagba ń ṣiṣẹ gẹgẹ bi “ẹbun ninu awọn ọkunrin” lati ọ̀dọ̀ Jehofa. (Efesu 4:8, 11, NW) Wọn jẹ́ Kristian olufẹri-ọkan ṣiṣẹ, oniriiri ti wọn fi tootọ-inu tootọ-inu fẹ́ lati dabi “ibi ilumọ kuro loju ẹfuufu, ati aabo kuro lọwọ ìjì.”—Isaiah 32:2.
Ọpọlọpọ miiran sii ninu ijọ Kristian tun bikita gidigidi nipa jijẹ orisun ireti. Ṣá ronu nipa bi ọgọrọọrun ẹgbẹẹgbẹrun wọn ti ń huwa nisinsinyi gan-an gẹgẹ bi iya, baba, arabinrin, arakunrin, ati ọmọ fun awọn wọnni ti wọn ti padanu awọn idile tiwọn; ronu nipa bi pupọ sii ti ń huwa gẹgẹ bi ọ̀rẹ́ “ti o fi ara mọ́ni ju arakunrin lọ” fun awọn wọnni ti wọn wà ninu idaamu.—Owe 18:24; Marku 10:30.
Bi o bá ti gbadura si Jehofa fun iranlọwọ, maṣe sọ̀rètínù. Ó lè ti dahun adura rẹ ná; alagba kan tabi Kristian ogboṣaṣa miiran kan lè wà nisinsinyi gan-an ti o ṣetan lati ràn ọ́ lọwọ ni gbàrà ti o bá ti sọ aini rẹ di mímọ̀. Ireti ti o wa deedee ninu awọn eniyan maa ń ràn wá lọwọ lati maṣe fasẹhin kuro lọdọ gbogbo eniyan ki a sì ya araawa láṣo, eyi ti o lè jalẹ si iwa onimọtara-ẹni-nikan, ti kò bá ọgbọn mu.—Owe 18:1.
Siwaju sii, bi a bá ni iṣoro pẹlu Kristian ẹlẹgbẹ wa kan, a kò nilati bojuto o pẹlu iṣarasihuwa ainireti, ti ó jẹ́ ti òdì. Ó ṣetan, “ifẹ . . . a maa reti ohun gbogbo.” (1 Korinti 13:4-7) Gbiyanju lati wo awọn Kristian arakunrin ati arabinrin gẹgẹ bi Jehofa ti ń wò wọn—pẹlu ireti. Ko ọgangan afiyesi jọ sori awọn animọ rere wọn, gbẹkẹle wọn, ki o sì jẹ ẹni ti ọkàn rẹ̀ dari si wíwá ojutuu. Iru ireti bẹẹ ń daabobo wá kuro lọwọ aáwọ̀ ati ìjà, ti kò ṣanfaani fun ẹnikẹni.
Maṣe juwọsilẹ fun ainireti inu ayé ogbologboo ti ń kú lọ yii. Ireti wà nibẹ—fun ọjọ-ọla ayeraye wa ati fun ojutuu si ọpọlọpọ iṣoro ti o kàn wá gbọ̀ngbọ̀n. Iwọ yoo ha di ireti mú ṣinṣin bi? Ni wiwọ ireti igbala bi aṣibori ti ń daaboboni, kò si iranṣẹ Jehofa kankan ti o jẹ́ aláìlólùrànlọ́wọ́ nitootọ—kò sí bi ipo-ayika naa ti lè lekoko tó. Bi a kò bá bọ́hùn funraawa, kò sí ohunkohun ni ọrun tabi lori ilẹ̀-ayé ti o lè já ireti ti Jehofa ti fifun wa gbà lọ.—Fiwe Romu 8:38, 39.