Mimu “Gbogbo Oniruuru Iwarere Iṣeun” Jade
“Eso imọlẹ ni gbogbo oniruuru iwarere iṣeun . . . ninu.”—EFESU 5:9, NW.
1, 2. Awujọ eniyan meji wo ni o ti wà lati akoko igbaani, bawo si ni ipo wọn ṣe yatọ lonii?
LẸHIN iṣọtẹ ninu Edeni, ni nǹkan bi ẹgbẹrun ọdun mẹfa sẹhin, ati pẹlu lẹhin Ikun omi ọjọ Noa, araye pín sí awujọ, tabi eto-ajọ meji, ọkan papọ jẹ awọn wọnni ti wọn nlakaka lati ṣiṣẹsin Jehofa, ekeji jẹ́ awọn wọnni ti wọn tẹle Satani. Njẹ awọn eto-ajọ wọnyi ṣì wà sibẹ? Dajudaju wọn wà! Wolii Aisaya mẹnukan awọn awujọ meji wọnyi o sì sọtẹlẹ nipa ipo wọn ni akoko wa: “Kiyesi i, okunkun yoo bo aye mọlẹ, ati okunkun biribiri yoo bo awọn eniyan: ṣugbọn Oluwa [“Jehofa,” NW] yoo yọ lara rẹ, a o si rí ogo rẹ̀ lara rẹ.”—Aisaya 60:1, 2.
2 Bẹẹni, iyatọ ti o wa laaarin awọn eto-ajọ mejeeji wọnyi pọ pupọ gẹgẹ bi iyatọ ti o wa laaarin okunkun ati imọlẹ. Gan an gẹgẹ bi itanṣan imọlẹ yoo si ti fa ẹni ti o ti sọnu sinu okunkun mọra, bẹẹ ni imọlẹ lati ọdọ Jehofa ti ntan ninu aye okunkun yii ṣe fa araadọta ọkẹ awọn ọlọkan rere mọra sinu eto-ajọ Ọlọrun. Gẹgẹ bi Aisaya ti nbaa lọ lati sọ: “Awọn Keferi [agutan miiran] yoo wá si imọlẹ rẹ, ati awọn ọba [awọn ẹni ami ororo ajumọ jogun Ijọba] si titan yíyọ rẹ.”—Aisaya 60:3.
3. Ni awọn ọna wo ni awọn Kristẹni ngba fi ogo Jehofa han?
3 Bawo ni awọn eniyan Jehofa ṣe fi ogo Jehofa han? Ọkan niyii, wọn nwaasu ihinrere Ijọba ọrun ti Ọlọrun fidii rẹ̀ mulẹ. (Maaku 13:10) Ṣugbọn ju iyẹn lọ, wọn ṣafarawe Jehofa, apẹẹrẹ gigajulọ ti iwarere iṣeun, ati nipa bayii nipa iwa wọn wọn fa awọn ẹni ọlọkan tutu mọra si imọlẹ naa. (Efesu 5:1) Pọọlu wipe: “Ẹyin ti jẹ okunkun nigba kan rí, ṣugbọn nisinsinyi ẹ jẹ́ imọlẹ ni isopọ pẹlu Oluwa. Ẹ maa baa lọ ni ririn gẹgẹ bi awọn ọmọ imọlẹ.” O nbaa lọ pe: “Eso imọlẹ ni gbogbo oniruuru iwarere iṣeun ati ododo ati otitọ ninu. Ẹ maa baa niṣo ni wiwadii ohun ti o ṣetẹwọgba fun Oluwa; ẹ si jawọ ninu ṣiṣajọpin pẹlu wọn ninu awọn iṣẹ aileso ti wọn jẹ́ ti okunkun.” (Efesu 5:8-11, NW) Ki ni Pọọlu ní lọkan nipa “gbogbo oniruuru iwarere iṣeun”?
4. Ki ni iwarere iṣeun, bawo ni a sì ṣe nri i ninu Kristẹni kan?
4 Gẹgẹ bi ọrọ-ẹkọ wa iṣaaju ti fihan, iwarere iṣeun jẹ́ animọ tabi ipo iwarere gigalọla, iwa mimọ. Jesu sọ pe Jehofa nikanṣoṣo ni ẹni rere ni itumọ pipe. (Maaku 10:18) Bi o tilẹ ri bẹẹ, Kristẹni kan le ṣafarawe Jehofa nipa mimu iwarere iṣeun ti o jẹ eso ti ẹmi dagba. (Galatia 5:22) Ni ṣiṣalaye lori a·ga·thosʹ, ọrọ Giriiki naa fun “rere,” Vine’s Expository Dictionary of Old and New Testament Words sọ pe, “[Ó] ṣapejuwe eyi ti, bi o ti jẹ pe o dara ninu iwa tabi ohun ti o jẹ ninu, o ṣanfaani ninu iyọrisi rẹ.” Kristẹni kan ti nmu iwarere iṣeun dagba nigba naa yoo jẹ ẹni rere yoo si maa ṣe rere. (Fiwe Deutaronomi 12:28.) Oun yoo tun yẹra fun awọn nǹkan ti o tako iwarere iṣeun, “awọn iṣẹ aileso ti wọn jẹ ti okunkun.” Awọn ọna oriṣiriṣi ti Kristẹni kan le gba fi iwarere iṣeun han ninu iwa rẹ ni ‘oniruuru iwarere iṣeun’ ti Pọọlu mẹnukan. Ki ni diẹ ninu iwọnyi?
“Maa Baa Lọ Ni Ṣiṣe Rere”
5. Ki ni iru iwarere iṣeun kan, eesitiṣe ti Kristẹni kan fi nilati mu un dagba?
5 Pọọlu tọka sí ọkan ninu iwọnyi ninu lẹta rẹ si awọn ara Roomu. Ni sisọrọ nipa itẹriba fun “awọn alaṣẹ onipo gigaju,” o wipe: “Iwọ, nigba naa, ha fẹ lati ṣaini ibẹru alaṣẹ? Maa ṣe rere, iwọ yoo si gba iyin lati ọdọ rẹ̀.” “Rere” ti o tọka sí jẹ igbọran si awọn ofin ati iṣeto awọn alaṣẹ aye. Eeṣe ti Kristẹni kan fi nilati tẹriba fun iwọnyi? Ki o baa le yẹra fun iforigbari ti kò pọndandan pẹlu awọn alaṣẹ, ni titipa bẹẹ dagbale ewu ijiya ati—eyi ti o ṣe pataki ju—ki o baa le pa ẹri ọkan rere mọ niwaju Ọlọrun. (Roomu 13:1-7, NW) Nigba ti o npa igbọran rẹ ipilẹṣẹ fun Jehofa mọ, Kristẹni kan ‘bọla fun ọba,’ oun kii ditẹ lodisi awọn alaṣẹ ti Jehofa fayegba lati wa. (1 Peteru 2:13-17) Ni ọna yii, awọn Kristẹni jẹ awọn aladuugbo rere, awọn ara ilu rere, ati awọn apẹẹrẹ rere.
Gba Ti Awọn Ẹlomiran Rò
6. (a) Ki ni iha iwarere iṣeun miiran? (b) Awọn wo ni a mẹnukan ninu Bibeli gẹgẹ bi awọn ti wọn lẹtọọsi ìgbatẹnirò wa?
6 Iwarere iṣeun Jehofa ni a nfihan ninu pipese ti o npese “ojo lati ọrun wa, ati akoko eso” fun gbogbo awọn olugbe ilẹ-aye. Eyi yọrisi ‘ẹkunrẹrẹ ounjẹ ati imoriyagaga rere’ o sì fihan pé o jẹ Ọlọrun agbatẹnirò nitootọ. (Iṣe 14:17) Awa le ṣafarawe rẹ ni ọna yii nipa fifi ìgbatẹnirò han fun awọn ẹlomiran ni ọna kekere ati nla. Ni pato, fun ta ni? Pọọlu ni pataki tọka si awọn alagba, “awọn wọnni ti nṣiṣẹ kára laaarin yin ti wọn si nṣakoso yin ninu Oluwa ti wọn sì ńṣí yin leti.” Ó rọ awọn Kristẹni lati fun awọn wọnyi “ju ifiyesi ara ọtọ lọ ninu ifẹ nitori iṣẹ wọn.” (1 Tẹsalonika 5:12, 13, NW) Bawo ni a ṣe le ṣe eyi? Nipa fifọwọsowọpọ ni kikun pẹlu wọn—fun apẹẹrẹ, nipa ṣiṣajọpin ninu iṣẹ ṣiṣekoko ninu Gbọngan Ijọba. Nigba ti a saba maa nni imọlara ominira lati lọ sọdọ awọn alagba fun iranlọwọ nigba ti a bá nilo rẹ, awa ko nilati jẹ́ afidandangbọn beere lọna ainironu. Kaka bẹẹ, ni awọn ọna eyikeyii ti a le gbà, awa ngbiyanju lati mu ẹrù awọn oluṣọ agutan oṣiṣẹ kára wọnyi fuyẹ, ọpọ ninu awọn ti wọn ni ẹru iṣẹ idile ni afikun si iṣẹ ti a yan fun wọn ninu ijọ wọn.
7. Ni awọn ọna wo ni a le gba fi ìgbatẹnirò han fun awọn ẹni ọlọjọ ori?
7 Awọn ti wọn ti dagba nipa ti ara pẹlu lẹtọọsi ìgbatẹnirò wa. Aṣẹ pato kan ninu Ofin Mose ni pe: “Ki iwọ ki o si dide duro niwaju ori ewu, ki o sì bọwọ fun ojú arugbo, ki o si bẹru Ọlọrun rẹ: emi ni Oluwa [“Jehofa,” NW].” (Lefitiku 19:32) Bawo ni a ṣe le fi ìgbatẹnirò yii han? Yoo dara bi awọn ọdọ ba le yọnda ara wọn lati ràn wọn lọwọ pẹlu rira nǹkan tabi pẹlu awọn iṣẹ ile pẹẹpẹẹpẹ miiran. Awọn alagba le fi ìgbatẹnirò wadii lati ri bi awọn agbalagba eyikeyii ba nilo iranlọwọ lati wá si awọn ipade. Ni awọn apejọ, awọn ọdọ, ti wọn lagbara yoo yẹra fun títi awọn agbalagba ti wọn rọra nrin ninu igbidanwo ainisuuru lati kọja, wọn yoo si ni suuru bi ẹni ọlọjọ ogbo kan ba lọra diẹ ni jijokoo tabi gbigba ounjẹ.
8. Bawo ni a ṣe le fi ìgbatẹnirò han fun awọn awujọ yiyẹ miiran ti a fihan lọ́tọ̀ ninu Bibeli?
8 Onisaamu naa mẹnukan awujọ miiran ti o nilo ìgbatẹnirò: “Alayọ ni ẹnikẹni ti nhuwa pẹlu ìgbatẹnirò si ẹni rirẹlẹ.” (Saamu 41:1, NW) Ó lè rọrun lati jẹ agbatẹnirò fun awọn ayọri ọla tabi ọlọrọ, ṣugbọn ki ni nipa awọn ẹni rirẹlẹ tabi alaini? Onkọwe Bibeli naa Jakọbu fihan pe fifi ìgbatẹnirò aláìṣègbè han fun awọn wọnyi jẹ́ idanwo iwa ododo ati ifẹ Kristẹni wa. Njẹ ki awa yege idanwo yii nipa jijẹ onironu si gbogbo eniyan laika awọn ipo wọn sí.—Filipi 2:3, 4; Jakọbu 2:2-4, 8, 9.
“Maa Baa Lọ Ni Didi Alaanu”
9, 10. Eeṣe ti awọn Kristẹni fi nilati jẹ́ alaaanu, bawo si ni a ṣe le fi iru iwarere iṣeun yii han?
9 Iru iwarere iṣeun kan siwaju sii ni a ri ninu awọn owe Jesu. Ninu ọkan lara iwọnyi, Jesu sọ nipa ara Samaria kan ti o ṣalabaapade ọkunrin kan ti a ti jà lole, ti a lu pátipàti, ti a sì fisilẹ sẹba oju ọna. Ọmọ Lefi kan ati alufaa kan ti rin kọja ọkunrin ti a ṣeleṣe naa, ni kikọ lati ran an lọwọ. Ṣugbọn ara Samaria naa duro o sì fun un ni iranlọwọ, ni ṣiṣe ju ohun ti a ti le reti de aye kan. Itan naa ni a saba maa npe ni owe ara Samaria Rere lede Gẹẹsi. Iru iwarere iṣeun wo ni ara Samaria naa fihan? Aanu. Nigba ti Jesu beere lọwọ olugbọ rẹ lati fi ẹni ti o jẹ aladuugbo ọkunrin ti a ṣálọ́gbẹ́ naa han, idahun ti o tọ́ ti a fun un ni pe: “Ẹni ti o ṣaanu fun un ni.”—Luuku 10:37.
10 Awọn Kristẹni alaaanu maa nṣafarawe Jehofa, ẹni ti Mose sọ fun awọn ọmọ Isirẹli nipa rẹ pe: “Ọlọrun alaaanu ni Oluwa [“Jehofa,” NW] Ọlọrun rẹ; oun kii yoo kọ̀ ọ́ silẹ, bẹẹ ni ki yoo run ọ́, bẹẹ ni ki yoo gbagbe majẹmu awọn baba rẹ, ti o ti bura fun wọn.” (Deutaronomi 4:31) Jesu fi bi aanu Ọlọrun ṣe nilati nipa lori wa han: “Njẹ ki ẹyin ki o ní aanu, gẹgẹ bi Baba yin si ti ní aanu.” (Luuku 6:36) Bawo ni awa ṣe le fi aanu han? Gẹgẹ bi owe Jesu ti fihan, ọna kan ni nipa mimuratan lati ran ẹnikeji wa lọwọ, ani bi o ba tilẹ wémọ́ ewu tabi ṣairọgbọ. Ẹni rere kan ki yoo dagunla si ijiya arakunrin rẹ̀ bi o ba wà ni ipo lati ṣe ohun kan nipa rẹ̀.—Jakọbu 2:15, 16.
11, 12. Gẹgẹ bi owe Jesu ti awọn ẹru ti wí, ki ni aanu ni ninu, bawo si ni a ṣe le fi eyi han lonii?
11 Omiran ninu awọn owe Jesu fihan pe iwarere iṣeun alaaanu ní imuratan lati dariji awọn ẹlomiran nínú. O sọ nipa ẹru kan ti o jẹ ọga rẹ̀ ni gbese ẹgbẹrun mẹwaa talẹnti. Nigba ti ko le san an pada, ẹru naa bẹbẹ fun aanu, ọga rẹ sì fi aanu dari gbese gigadabu ti 60,000,000 owo denari jì í. Ṣugbọn ẹru naa jade lọ o sì ri ẹru miiran ti ó jẹ ẹ ni kiki ọgọrun un owo denari. Ẹru naa ti a dariji fi ailaaanu sọ onigbese rẹ̀ sinu ẹwọn titi di igba ti oun yoo le sanwo. Ni kedere, ẹru alailaaanu naa kii ṣe ẹni rere. Nigba ti ọga naa sì gbọ ohun ti ó ṣẹlẹ, o da a lẹbi tikanratikanra.—Matiu 18:23-35.
12 A wà ninu ipo ti o farajọ ti ẹru ti a dariji yẹn. Lori ipilẹ ẹbọ Jesu, Jehofa ti dari gbese ẹṣẹ gigadabu kan ti a ti dá jì wa. Dajudaju, nigba naa, awa nilati muratan lati dariji awọn ẹlomiran. Jesu sọ pe awa nilati muratan lati dariji “titi di igba aadọrin lé meje,” iyẹn ni pe lailopin. (Matiu 5:7; 6:12, 14, 15; 18:21, 22, NW) Fun idi yii, Kristẹni alaaanu kan ki yoo di eniyan sinu. Oun ki yoo di kùnrùngbùn sinu tabi kọ̀ lati sọrọ si Kristẹni ẹlẹgbẹ rẹ̀ kan nitori awọn imọlara buburu. Iru aini aanu bẹẹ kii ṣe ami iwarere iṣeun Kristẹni.
Ọlawọ ati Olufẹ Alejo Ṣiṣe
13. Ki tun ni ohun ti iwarere iṣeun ni ninu?
13 Iwarere iṣeun ni a tun nfihan nipa iwa ọlawọ ati ẹmi alejo ṣiṣe. Ni akoko kan ọdọmọkunrin kan wá sọdọ Jesu fun imọran. O sọ pe: “Olukọni rere, ohun rere ki ni emi yoo ṣe, ki emi ki o le ni iye ainipẹkun?” Jesu sọ fun un pe ó nilati pa awọn ofin Ọlọrun mọ titilọ. Bẹẹni, igbọran si awọn aṣẹ Jehofa jẹ́ iha iwarere iṣeun kan. Ọdọmọkunrin naa ronu pe oun ti nṣe eyi tẹlẹ gẹgẹ bi oun ti le ṣe tó. Ni kedere, fun awọn aladuugbo rẹ̀ o jọ pe oun ti jẹ ẹni rere tẹlẹ, sibẹ oun nimọlara aini ohun kan. Nitori naa Jesu sọ pe: “Bi iwọ ba nfẹ pé, lọ ta ohun ti o ni, ki o si fi tọrẹ fun awọn talaka, iwọ o sì ni iṣura ni ọrun, sì wá ki o maa tọ̀ mi lẹhin.” (Matiu 19:16-22) Ọdọmọkunrin naa lọ kuro pẹlu ibanujẹ. Oun jẹ ọlọrọ gan an. Bi oun ba nilati tẹle imọran Jesu, oun iba ti fihan pe oun kii ṣe onifẹẹ ọrọ alumọọni. Oun iba si ti ṣe iṣe rere ti iwa ọlawọ alainimọtara ẹni nikan nitootọ.
14. Imọran rere wo ni Jehofa ati Jesu fi funni nipa iwa ọlawọ?
14 Jehofa rọ awọn ọmọ Isirẹli lati jẹ ọlawọ. Fun apẹẹrẹ, a kà pé: “Iwọ ni gbogbo ọna gbọdọ fifun [aladuugbo rẹ ti òṣì nta], ọkan-aya rẹ ko si nilati ṣahun ni fifi fun un, nitori pe nitori eyi ni Jehofa Ọlọrun rẹ yoo bukun fun ọ ninu iṣe rẹ gbogbo ati ninu idawọle rẹ gbogbo.” (Deutaronomi 15:10, NW; Owe 11:25) Jesu Kristi funraarẹ rọni lati ni iwa ọlawọ: “Ẹ fifunni, a o si fifun yin; oṣuwọn daradara, akimọlẹ, ati amipọ, akunwọsilẹ, ni a o wọn si aya yin.” (Luuku 6:38) Ju bẹẹ lọ, Jesu funraarẹ jẹ ọlawọ gan an. Ni akoko kan, o ya akoko sọtọ lati sinmi fun igba diẹ. Awọn ogunlọgọ rí ibi ti o wà wọn si wa sọdọ rẹ. Jesu fi iwa ọlawọ gbagbe nipa isinmi o sì lo araarẹ nitori ti awọn ogunlọgọ naa. Lẹhin naa, o fi ẹmi alejo ṣiṣe titayọ han ni pipese ounjẹ fun ogunlọgọ nla yẹn.—Maaku 6:30-44.
15. Bawo ni awọn ọmọlẹhin Jesu ṣe fi apẹẹrẹ titayọ lelẹ ninu fifi iwa ọlawọ han?
15 Ni jijẹ oloootọ si imọran Jehofa ati ti Jesu, ọpọlọpọ awọn ọmọ-ẹhin Jesu ni a mọ si ọlọlawọ ati olufẹ alejo ṣiṣe lọna titayọ. Ni awọn ọjọ akọkọ ti ijọ Kristẹni, ọpọ iye awọn wọnni ti wọn ti wá lati ṣe ayẹyẹ Pẹntikọsi ni 33 C.E. gbọ́ iwaasu awọn apọsiteli naa wọn si di onigbagbọ. Ni diduro lẹhin ase naa ki wọn baa le kẹkọọ sii, ipese ounjẹ fẹ́ri lọwọ wọn. Nitori naa, awọn onigbagbọ adugbo ta ohun ìní wọn wọn si ṣetọrẹ owó lati ti awọn arakunrin wọn titun lẹhin ki awọn wọnyi ba le fẹsẹmulẹ daradara sii ninu igbagbọ. Ẹ wo iru iwa ọlawọ ti eyi jẹ!—Iṣe 4:32-35; tun wo Iṣe 16:15; Roomu 15:26.
16. Darukọ diẹ lara awọn ọna ti awa lonii le gba jẹ olufẹ alejo ṣiṣe ati ọlọlawọ.
16 Lonii, iru ẹmi ọlawọ kan naa bii ti Kristi ni a ńrí nigba ti awọn Kristẹni ba ṣetọrẹ akoko ati owo fun awọn ijọ adugbo wọn ati fun iṣẹ iwaasu yika aye. O han kedere nigba ti wọn ba wá lati pese itura fun awọn arakunrin ti wọn njiya lọwọ ìjábá adanida tabi ogun. A fihan nigba ti a ba ṣetọju alaboojuto ayika nigba ibẹwo deedee rẹ. Tabi nigba ti a ba kesi “awọn ọmọkunrin alaini baba” (ati awọn ọmọbinrin alaini baba) lọna ọlawọ lati ṣajọpin ninu ere inaju ati ikẹkọọ Bibeli pẹlu awọn idile Kristẹni miiran, eyi tun jẹ ẹmi alejo ṣiṣe, ifihan iwarere iṣeun Kristẹni.—Saamu 68:5.
Sisọ Otitọ
17. Eeṣe ti sisọ otitọ fi jẹ ipenija kan lonii?
17 Nigba ti Pọọlu ṣapejuwe awọn eso imọlẹ, o so iwarere iṣeun pọ mọ iwa ododo ati otitọ, yoo si tọna lati wipe sisọ otitọ jẹ iru iwarere iṣeun miiran. Awọn eniyan rere kii pa irọ. Bi o tilẹ ri bẹẹ, sisọ otitọ jẹ ipenija akanṣe lonii nigba ti irọ pipa wọpọ gan an. Ọpọlọpọ awọn eniyan maa npurọ nigba ti wọn ba nkọ ọrọ kun iwe owo ori iṣẹ aje wọn. Awọn ẹni agbasiṣẹ ma npurọ nipa iṣẹ ti wọn nṣe. Awọn akẹkọọ maa nfi irọ lu jibiti ninu ẹkọ ati idanwo wọn. Awọn oniṣowo npurọ nigba ti wọn baa nṣe adehun iṣẹ aje. Awọn ọmọ npurọ lati bọ́ lọwọ ijiya. Awọn olofoofo abanijẹ nfi irọ ba orukọ rere awọn ẹlomiran jẹ.
18. Oju wo ni Jehofa fi nwo awọn opurọ?
18 Irọ pipa jẹ irira si Jehofa. Ninu ‘awọn nǹkan meje, ti o korira ni “ete eke” ati “ẹlẹrii eke ti nsọ eke jade.” (Owe 6:16-19) “Awọn eke gbogbo” ni a ṣakọsilẹ wọn saaarin awọn ojo, apaniyan, agbere, ti wọn kò ni ni aye kankan ninu aye titun Ọlọrun. (Iṣipaya 21:8) Siwaju sii, owe sọ fun wa pe: “Ẹni ti nrin ninu iduroṣanṣan rẹ̀ nbẹru Jehofa, ṣugbọn ẹni ti o wọ́ ni ọna rẹ nṣainaani Rẹ̀.” (Owe 14:2, NW) Opurọ kan wọ́ ni awọn ọna rẹ̀. Fun idi yii, opurọ kan funni ni ẹri ṣiṣainaani Jehofa. Ẹ wo ironu buburu ti eyi jẹ! Ẹ jẹ ki a maa sọ otitọ nigba gbogbo, ani bi o ba tilẹ jalẹ si mimu wa di ẹni ti a báwí tabi mu padanu niti iṣunna owo. (Owe 16:6; Efesu 4:25) Awọn wọnni ti wọn nsọ otitọ ṣafarawe Jehofa, “Ọlọrun otitọ.”—Saamu 31:5.
Mu Iwarere Iṣeun Dagba
19. Ki ni a ńrí ninu aye, nigba miiran ti nfi iyin han fun Ẹlẹdaa naa?
19 Iwọnyi wulẹ jẹ diẹ lara ‘oniruuru’ iwarere iṣeun tí Kristẹni kan nilati mudagba. Otitọ ni pe awọn eniyan ninu aye nfi iwarere iṣeun han dé àyè kan. Fun apẹẹrẹ, awọn kan jẹ ẹlẹmii alejo ṣiṣe, awọn miiran sì jẹ alaaanu. Nitootọ, ohun ti o mu ki owe Jesu nipa ara Samaria rere pẹtẹri gan an ni pe Jesu sọ nipa ẹnikan ti kii ṣe Juu ti o fi aanu han nigba ti awọn alagba ninu ijọ awọn Juu ko ṣe bẹẹ. Ó jẹ ẹri ijafafa Ẹlẹdaa eniyan pe iru animọ bẹẹ ṣì farahan lọna adanida ninu awọn eniyan diẹ ani lẹhin ẹgbẹrun ọdun mẹfa aipe paapaa.
20, 21. (a) Eeṣe ti iwarere iṣeun ti Kristẹni fi yatọ si iwarere iṣeun eyikeyi ti a le ri ninu awọn eniyan aye? (b) Bawo ni Kristẹni kan ṣe le mu iwarere iṣeun dagba, eesitiṣe ti a fi nilati jẹ alaapọn lati ṣe bẹẹ?
20 Bi o ti wu ki o ri, fun awọn Kristẹni iwarere iṣeun ju animọ ṣakala kan ti wọn le ni tabi ṣaini lọ. Ó jẹ animọ ti wọn gbọdọ mu dagba ninu gbogbo iha rẹ̀, niwọn igba ti wọn nilati jẹ alafarawe Ọlọrun. Bawo ni eyi ti ṣeeṣe? Bibeli sọ fun wa pe awa le kẹkọọ iwarere iṣeun. “Kọ mi ni iwarere iṣeun,” ni onisaamu naa gbadura si Ọlọrun. Bawo? O nbaa lọ pe: “Nitori ninu awọn ofin rẹ ni mo ti mu igbagbọ lo.” O fikun un pe: “Iwọ dara o si nṣe rere. Kọ mi ni awọn ilana rẹ.”—Saamu 119:66, 68, NW.
21 Bẹẹni, bi a ba kẹkọọ awọn ofin Jehofa ti a sì ṣegbọran sí wọn, awa yoo mu iwarere iṣeun dagba. Maa ranti nigba gbogbo pe iwarere iṣeun jẹ eso ti ẹmi. Bi a ba wá ẹmi Jehofa nipasẹ adura, ibakẹgbẹpọ, ati ikẹkọọ Bibeli, nigba naa a o ràn wá lọwọ dajudaju lati mu animọ yii dagba. Ju bẹẹ lọ, iwarere iṣeun lagbara pupọ. O tilẹ le bori ibi. (Roomu 12:21) Bawo ni o ti ṣekoko tó, nigba naa, pe ki a maa ṣe rere si gbogbo eniyan, ni pataki si awọn Kristẹni arakunrin wa. (Galatia 6:10) Bi a ba ṣe bẹẹ, awa yoo wa ninu awọn wọnni ti wọn ngbadun “ogo ati ọlá ati alaafia” ti a ṣeleri fun “olukuluku ẹni ti nṣiṣẹ ohun ti o dara.”—Roomu 2:6-11, NW.
Iwọ Ha Le Dahun Bi?
◻ Bawo ni a ṣe le maa baa lọ ni ṣiṣe rere ni isopọ pẹlu awọn alaṣẹ onipo gigaju?
◻ Awọn miiran wo ni wọn tun lẹtọọsi igbatẹniro wa?
◻ Ni awọn ọna wo ni aanu ngba fi ara rẹ han?
◻ Awọn iṣe ọlọlawọ ati onifẹẹ alejo ṣiṣe wo ni o sami si awọn Kristẹni lonii?
◻ Bawo ni a ṣe le mu iwarere iṣeun dagba?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Ìgbatẹnirò fun awọn ẹlomiran jẹ iha iwarere iṣeun kan
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Gẹgẹ bi Olukọ Nla naa, Jesu fi ara rẹ funni lọna ọlawọ