ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 2 TẸSALÓNÍKÀ 1-3
A Ó Fi Arúfin Náà Hàn
Kí ni Pọ́ọ̀lù ń tọ́ka sí nínú àwọn ẹsẹ yìí?
“Ohun tó ń ṣèdíwọ́” (ẹsẹ 6)—ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àwọn àpọ́sítélì
“Fara hàn” (ẹsẹ 6)—Lẹ́yìn ikú àwọn àpọ́sítélì, àwọn Kristẹni apẹ̀yìndà wá sójú táyé pẹ̀lú àgàbàgebè wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn èèyàn ní àwọn ẹ̀kọ́ èké ní gbangba
“Àṣírí ìwà ìkà yìí” (ẹsẹ 7)—Nígbà ayé Pọ́ọ̀lù, àwọn èèyàn ò mọ ẹni tí “arúfin náà” jẹ́
“Arúfin náà” (ẹsẹ 8)—Lónìí, òun ni gbogbo àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì
‘Jésù Olúwa máa pa [arúfin náà] nígbà tó bá ṣe kedere pé ó ti wà níhìn-ín’ (ẹsẹ 8)—Jésù máa jẹ́ kó ṣe kedere pé òun ni Ọba ní ọ̀run nígbà tó bá pa ètò nǹkan burúkú Sátánì yìí run, títí kan “arúfin náà”
Báwo ni ẹsẹ yìí ṣe fún ẹ níṣìírí láti máa fi ìtara wàásù, kó o sì gbà pé iṣẹ́ náà jẹ́ kánjúkánjú?