Fífi Ìfẹ́ Kristian Hàn sí Àwọn Àgbàlagbà
SAMUEL JOHNSON, òǹkọ̀wé ọ̀rúndún kejìdínlógún kan, sọ ìtàn ọ̀dọ́kùnrin kan tí ó gbàgbé ibi tí ó fi fìlà rẹ̀ sí, nígbà ìbẹ̀wò sí ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ìwà àìka nǹkan sí rẹ̀ kò fa àròyé kankan. Johnson ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé, “Ṣùgbọ́n bí a bá kíyèsí irú àìfiyèsí nǹkan bẹ́ẹ̀ lára ọkùnrin arúgbó kan, àwọn ènìyàn yóò gúnjìká wọn, wọn yóò sì sọ pé, ‘Iyè rẹ̀ ti ń rá.’”
Ìtàn Johnson fihàn pé àwọn àgbàlagbà, bóyá bíi ti àwọn àwùjọ kéréje mìíràn, máa ń nírìírí ìfinihàn lọ́nà tí kò tọ́ nígbà gbogbo. Nígbà tí bíbìkítà fún àìní àwọn arúgbó jẹ́ ìpèníjà kan, àwọn ìbùkún tí ó túbọ̀ pọ̀ síi wà fún àwọn tí ń lọ́wọ́ nínú rẹ̀. Kí ni àwọn ìpèníjà àti èrè náà, èésìtiṣe tí kókó ọ̀rọ̀ yìí fi kan àwọn ènìyàn tí ó túbọ̀ ń pọ̀ síi?
Ní ìbámu pẹ̀lú àkójọ àkọsílẹ̀ oníṣirò, ìpín 6 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn olùgbé ayé ni ọjọ́ orí wọn jẹ́ 65 tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ àti pé ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ti gòkè àgbà ìpín náà nínú ọgọ́rùn-ún ga sókè ní ìlọ́po méjì. Nínú Àjọ Ilẹ̀ Europe, tí ó ya 1993 sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí “Ọdún Àwọn Àgbàlagbà àti Ìfìmọ̀ṣọ̀kan Láàárín Àwọn Ìran ti Ilẹ̀ Europe,” ènìyàn 1 nínú 3 ni ó ti lé ní 50 ọdún. Níbẹ̀, bí ó ti rí ní ọ̀pọ̀ jùlọ àwọn ilẹ̀ onílé-iṣẹ́-ẹ̀rọ, ìlọsílẹ̀ nínú ọmọ bíbí àti ìlọsókè ìgbà ìwàláàyè mú kí ìṣètò àwọn olùgbé ìlú pọ̀ níbìkan ju òmíràn lọ. Bíbójútó àwọn ọlọ́jọ́ lórí wọ̀nyẹn lábẹ́ irú ipò bẹ́ẹ̀ jẹ́ iṣẹ́ takuntakun lọ́nà tí ó ṣe kedere. Ẹ sì wo bí àwọn nǹkan ti yàtọ̀ tó ní Ìlà-Oòrùn àtijọ́!
“Ibi Ìkó Ìmọ̀ Pamọ́sí”
Ìwé Handwörterbuch des Biblischen Altertums für gebildete Bibelleser (Ìwé Ìléwọ́ Àtijọ́ Lórí Bibeli fún Àwọn Ọ̀mọ̀wèé Olùka Bibeli) fihàn pé ní Ìlà-Oòrùn àtijọ́ “àwọn àgbàlagbà ni a wò gẹ́gẹ́ bí olùpa àwọn àṣà tí ó níyelórí ti ọgbọ́n àti ìmọ̀ gíga mọ́, nítorí ìdí èyí ni a ṣe gba àwọn ọmọdé níyànjú láti bá wọn kẹ́gbẹ́pọ̀ kí wọ́n sì kẹ́kọ̀ọ́ láti ọ̀dọ̀ wọn.” Ìwé atúmọ̀-èdè náà Smith’s Bible Dictionary ṣàlàyé pé: “Nínú ìgbésí-ayé ara-ẹni [àwọn arúgbó] ni a ń wò gẹ́gẹ́ bí ibi ìkó ìmọ̀ pamọ́sí . . . [Àwọn ọmọdé] ń yọ̀ọ̀da fún wọn láti jẹ́ kí wọ́n kọ́kọ́ sọ èrò wọn jáde.”
Ọ̀wọ̀ fún àwọn arúgbó ni a gbéyọ nínú Òfin Mose nínú Lefitiku 19:32 pé: “Kí ìwọ kí ó sì dìde dúró níwájú orí-ewú, kí o sì bọ̀wọ̀ fún ojú arúgbó.” Nítorí náà àwọn arúgbó wà ní ipò aláǹfààní kan láwùjọ a sì ń wò wọ́n gẹ́gẹ́ bí àwọn ohun ìní tí ó níyelórí. Èyí ní kedere ní ọ̀nà tí Rutu ọmọbìnrin Moabu náà gbà wo ìyá-ọkọ rẹ̀ Naomi, ọmọ Israeli.
Rutu pinnu pẹ̀lú ìdúróṣinṣin láti tẹ̀lé Naomi láti Moabu lọ sí Israeli, lẹ́yìn náà ó fi ìṣọ́ra fetísílẹ̀ sí ìmọ̀ràn Naomi. Gbàrà tí wọ́n ti gúnlẹ̀ sí Betlehemu, Naomi ni ó kíyèsi pe ọwọ́ Jehofa ń darí àwọn ọ̀ràn tí ó sì fún Rutu ní ìtọ́ni bí yóò ti hùwà. (Rutu 2:20; 3:3, 4 18) Ìgbésí-ayé Rutu ni a nípa lé lórí lọ́nà ti ìṣàkóso Ọlọrun bí ó tí ń kẹ́kọ̀ọ́ láti ọ̀dọ̀ Naomi tí ó nírìírí náà. Ìyá ọkọ rẹ̀ fi ẹ̀rí jíjẹ́ ibi ìkó ìmọ̀ pamọ́ sí hàn.
Ní ọ̀nà kan náà, àwọn Kristian ọ̀dọ́bìnrin lónìí lè jàǹfààní nípa kíkẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn àgbà obìnrin nínú ìjọ. Bóyá arábìnrin kan ń ronú láti ṣègbéyàwó tàbí ìṣòro ara-ẹni kan tí ó lekoko ń bá a fínra. Ẹ wo bí yóò ti lọ́gbọ́n nínú tó láti wá ìmọ̀ràn àti ìtìlẹ́yìn arábìnrin àgbàlagbà kan tí ó dàgbàdénú tí ó ní ìrírí irú ọ̀ràn náà!
Síwájú síi, ẹgbẹ́ àwọn alàgbà lè jàǹfààní nípa gbígbọ́ ìrírí láti ẹnu àwọn arúgbó tí ń bẹ ní àárín wọn. A lè kẹ́kọ̀ọ́ láti inú ìkùnà Loti láti ṣe èyí. Gbólóhùn asọ̀ tí ó wáyé láàárín àwọn darandaran Abrahamu àti ti Loti béèrè fún ìpinnu kan tí yóò kan gbogbo wọn. Loti ṣe yíyàn tí kò lọ́gbọ́n nínú. Ẹ wo bí ìbá ti dára jù tó láti béèrè fún ìmọ̀ràn Abrahamu lákọ̀ọ́kọ́! Loti ìbá ti gba ìtọ́sọ́nà tí ó bọ́gbọ́nmu ìbá sì ti yọ ìdílé rẹ̀ kúrò nínú ìbànújẹ́ tí ó jẹ jáde láti inú yíyàn tí ó fi ìwàǹwára ṣe. (Genesisi 13:7-13; 14:12; 19:4, 5, 9, 26, 29) O ha máa ń fetísílẹ̀ dáradára sí ohun tí àwọn alàgbà tí ó dàgbàdénú bá sọ kí o tó dé orí ìpinnu tìrẹ lórí ìbéèrè kan bí?
Àìmọye àwọn arúgbó ni wọ́n ní ìtara pípẹ́títí fún iṣẹ́ Jehofa, bí Simeoni àti Anna ti ṣe ní ọ̀rúndún kìn-ín-ní. (Luku 2:25, 36, 37) Ó jẹ́ àmì ọ̀wọ̀ àti fífi ìṣarasíhùwà ìṣàbójútó hàn fún irú àwọn àgbàlagbà bẹ́ẹ̀ láti jẹ́ kí wọ́n kópa nínú àwọn ìgbòkègbodò ìjọ dé ibi tí agbára wọn bá lè gbé e dé, àní títí fi di ọjọ́ ogbó wọn pàápàá. Bóyá ọ̀dọ́ kan nílò ìrànlọ́wọ́ ní mímúra iṣẹ́ àyànfúnni kan sílẹ̀ fún Ilé-Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́-Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọrun. Alàgbà kan tí ó gbọ́n lè parí èrò sí pé olùrànlọ́wọ́ tí ó dára jù yóò jẹ́ mẹ́ḿbà ìjọ kan tí ó jẹ́ arúgbó, ẹni tí ó ní ọgbọ́n oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́, tí ó lẹ́mìí ìṣoore, tí ọwọ́ rẹ̀ sì dilẹ̀.
Bí ó ti wù kí ó rí, fífún àìní àrà-ọ̀tọ̀ ti àwọn arúgbó ní àfiyèsí ní nínú jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ọ̀pọ̀ ni ìdánìkanwà, ìbẹ̀rù ìwà-ipá, àti àwọn ìṣòro ìnáwó ń dà láàmú. Síwájú síi, bí àwọn àgbàlagbà bá ti di aláìlera, àwọn ìṣòro wọ̀nyí ni ìlera tí ń dínkù àti ìjákulẹ̀ níti bí okunra wọn ṣe ń jó rẹ̀yìn máa ń mú peléke síi. Wọ́n nílò àfiyèsí tí ó túbọ̀ pọ̀ síi. Báwo ni ẹnìkọ̀ọ̀kan àti ìjọ lápapọ̀ ṣe níláti hùwàpadà?
“Fi Ìfọkànsìn Ọlọrun Ṣèwàhù”
Ní ọ̀rúndún kìn-ín-ní, Paulu lábẹ́ ìmísí kọ̀wé ní 1 Timoteu 5:4, 16 (NW) pé: “Bí opó èyíkéyìí bá ní awọn ọmọ tabi awọn ọmọ-ọmọ, kí awọn wọnyi kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ lati máa fi ìfọkànsin Ọlọrun ṣèwàhù ninu agbo ilé tiwọn kí wọ́n sì máa san ìsanfidípò yíyẹ fún awọn òbí wọn ati awọn òbí wọn àgbà, nitori tí èyí ṣe ìtẹ́wọ́gbà lójú Ọlọrun. Bí obìnrin èyíkéyìí tí ó gbàgbọ́ bá ní awọn opó, kí ó mú ìtura àlàáfíà bá wọn, kí ìjọ má sì ṣe wà lábẹ́ ẹrù-ìnira naa. Nígbà naa ìjọ yoo lè mú ìtura àlàáfíà bá awọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ opó níti gàsíkíá.” Bíbójútó àwọn arúgbó jẹ́ ẹrù-iṣẹ́ ìdílé. Bí àgbàlagbà kan tí ó jẹ́ mẹ́ḿbà ìjọ bá nílò ìrànlọ́wọ́ lẹ́yìn tí ìdílé rẹ́ ti sa gbogbo ipá wọn, ẹrù-iṣẹ́ náà di ti ìjọ. Ìlànà yìí kó tíì yípadà.
Kí ni ó ti ran àwọn Kristian lọ́wọ́ láti fi ìfẹ́ Kristian hàn sí àwọn àgbàlagbà nípa fífi ìfọkànsin Ọlọrun ṣèwàhù ninu agbo ilé tiwọn? Kíyèsí àwọn ọ̀rọ̀ tí ó tẹ̀lé e láti ẹnu àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n ní ìrírí nípa títọ́jú àwọn àgbàlagbà ọlọ́jọ́ lórí.
Fífiyè Déédéé sí Àwọn Àìní Tẹ̀mí
Felix, tí ó ran aya rẹ̀ lọ́wọ́ láti bójútó àwọn òbí rẹ̀ rántí pé, “Ṣíṣe àyẹ̀wò ẹsẹ ojoojúmọ́ papọ̀ jẹ́ ìrànlọ́wọ́ tí ó níyelórí gan-an. Àwọn ìrírí ti ara-ẹni àti àwọn ìfẹ́-ọkàn mímúná ni a papọ̀ mọ́ àwọn ìlànà Jehofa.” Nítòótọ́, ní dídìde sí ìpèníjà ti títọ́jú àwọn ìbátan tí wọ́n jẹ́ àgbàlagbà, kókó pàtàkì kan ni fífi àfiyèsí tí ó yẹ sí ìdàgbà wọn nípa tẹ̀mí. Èyí bọ́gbọ́nmu ní ojú-ìwòye ọ̀rọ̀ Jesu ní Matteu 5:3 pé: “Alábùkún fún ni àwọn òtòṣì ní ẹ̀mí.” Ẹsẹ ojoojúmọ́ ni a lè fẹ̀ lójú síi nípa ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bibeli kíkà, nípa jíjíròrò àwọn ìtẹ̀jáde tí a gbékarí Bibeli, àti nípa àdúrà. Peter sọ pé, “Ó dàbí ẹni pé àwọn àgbàlagbà fẹ́ràn ìṣedéédéé dé ìwọ̀n kan.”
Bẹ́ẹ̀ni, ìṣedéédéé ṣe kókó nínú ọ̀rọ̀ tẹ̀mí. Àwọn àgbàlagbà mọrírì àṣetúnṣe kìí ṣe kìkì nínú ohun tẹ̀mí nìkan ṣùgbọ́n nínú ìgbésí-ayé ojoojúmọ́ pẹ̀lú. Àwọn tí wọ́n tilẹ̀ ní àìlera ráńpẹ́ pàápàá ni a lè fọ̀yàyà fún ní ìṣírí láti “dìde lórí ibùsùn kí wọn sì múra dáradára lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan,” ni ọ̀rọ̀ àkíyèsí Ursula. Dájúdájú, a fẹ́ láti yẹra fún dídàbí ẹni ń pàṣẹ fún àwọn arúgbó. Doris gbà pé ìgbìyànjú tí òun ṣe pẹ̀lú ọkàn tí ó dára ni a sábà máa ń gbà sódì. “Mo ṣe onírúurú àṣìṣe. Ní ọjọ́ kan mo ní kí baba mi máa pààrọ̀ ẹ̀wù rẹ̀ lójoojúmọ́. Nígbà náà ni mama mi rán mi létí pé: ‘Ọkọ mi ni síbẹ̀síbẹ̀!’”
Àwọn àgbàlagbà ti fìgbà kan rí jẹ́ ọ̀dọ́, ṣùgbọ́n fún àwọn ọ̀dọ́ láti fi ara wọn sí ipò àwọn arúgbó jẹ́ iṣẹ́ kan tí ó nira. Síbẹ̀, ìyẹn ni kọ́kọ́rọ́ náà sí lílóye àìní àrà-ọ̀tọ̀ wọn. Ọjọ́ ogbó ń mú ìjákulẹ̀ wá. Gerhard ṣàlàyé pé: “Baba ìyàwó mi bínú sí ara rẹ̀ nítorí tí kò le ṣe gbogbo ohun tí ó máa ń ṣe tẹ́lẹ̀. Títẹ́wọ́gba ipò ọ̀ràn náà jẹ́ ìṣòro gidigidi. Àkópọ̀ ànímọ́ rẹ̀ yípadà.”
Lábẹ́ àwọn ipò tí ó ń yípadà, kò ṣàjèjì kí àgbàlagbà kan fi ìrunú rẹ̀ hàn nípa bíbu ẹnu-àtẹ́ lu àwọn yòókù, pàápàá àwọn tí ń ṣe ìtọ́jú rẹ̀. Ìdí rẹ̀ kò nira. Àfiyèsí onífẹ̀ẹ́ wọn ń rán an létí okunra rẹ̀ tí ń dínkù. Báwo ni o ṣe níláti hùwàpadà sí ìtẹ́ḿbẹ́lú tàbí ìráhùn tí kò tọ́ yìí?
Rántí, irú ìmọ̀lára òdì báyìí kò fi ojú-ìwòye Jehofa nípa ìsapá rẹ hàn. Tẹ̀síwájú láti máa ṣe rere, kí o sì di ẹ̀rí-ọkàn tí ó mọ́ mú, àní bí o bá tilẹ̀ ń gbá àwọn àròyé tí kò tọ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. (Fiwe 1 Peteru 2:19.) Ìjọ àdúgbò lè ṣe àtìlẹ́yìn púpọ̀.
Ohun tí Ìjọ Lè Ṣe
Ọ̀pọ̀ ìjọ ní ìdí láti dúpẹ́ gidigidi fún ìsapá àtẹ̀yìnwá àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa ọ̀wọ́n tí wọ́n jẹ́ àgbàlagbà. Ó ṣeéṣe kí ó jẹ́ pé àwọn ni wọn fi ìpìlẹ̀ ìjọ náà lélẹ̀, tí wọ́n gbé e ró láti ìgbà akéde díẹ̀ péré ní àwọn ẹ̀wádún mélòókan sẹ́yìn. Níbo ní ìjọ náà ìbá wà láìsí ìgbòkègbodò onítara wọn àtẹ̀yìnwá àti bóyá, ìtìlẹ́yìn ìnáwó ìsinsìnyí?
Nígbà tí ìtọ́jú tí ó pọ̀ síi bá di dandan níti ọ̀ràn akéde kan tí ó jẹ́ arúgbó, àwọn ìbátan kó níláti dánìkan bójútó ẹrù-iṣẹ́ náà. Àwọn mìíràn lè ṣèrànwọ́ nípa jíjẹ́ iṣẹ́ fún wọn, gbígbọ́únjẹ, mímú nǹkan wà ní tónítóní, mímú arúgbó náà rìn kiri, fífọkọ̀ gbé e wá sí ìpàdé Kristian, tàbí wíwulẹ̀ ní ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Gbogbo ènìyàn lè kópa nínú rẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìjáfáfá àti ọ̀nà ìgbàṣiṣẹ́ déédéé ni a lè ní bí a bá lo ìsapá àpawọ́pọ̀ṣe.
Ìmúṣiṣẹ́ṣọ̀kan ni ohun kan tí àwọn alàgbà lè fi sọ́kàn nígbà tí wọ́n bá ń ṣètò àwọn ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùtàn. Àwọn ìjọ kan jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ nínú èyí, àwọn alàgbà ń rí síi pé a ṣe ìbẹ̀wò olùṣọ́-àgùtàn déédéé sọ́dọ̀ àwọn arúgbó àti àwọn aláìlera, àní àwọn wọnnì tí àwọn ìdílé wọn ń bójútó dáradára pàápàá. Bí ó ti wù kí ó rí, ó dàbí ẹni pé àwọn ìjọ mìíràn níláti túbọ̀ mọ ohun tí ó jẹ́ ojúṣe wọn fún àwọn àgbàlagbà.
Arákùnrin olùṣòtítọ́ kan, tí ó ti lé ní ẹni 80 ọdún, ni ọmọbìnrin rẹ̀ àti ọkọ ọmọ rẹ̀ bójútó, àwọn ẹni tí wọ́n fi Beteli sílẹ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀, ìbẹ̀wò láti ọ̀dọ̀ àwọn mẹ́ḿbà mìíràn nínú ìjọ ṣì ṣe pàtàkì fún un. Arákùnrin náà kédàárò pé, “Nígbà tí mo ṣì máa ń bẹ àwọn aláìsàn wò, mo máa ń gbàdúrà pẹ̀lú wọn. Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó tíì gbàdúrà pẹ̀lú mi rí.” Àfiyèsí onífẹ̀ẹ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí kò yọ àwọn alàgbà sílẹ̀ nínú ojúṣe wọn láti ‘tọ́jú agbo Ọlọrun tí ń bẹ láàárín wọn.’ (1 Peteru 5:2) Síwájú síi, àwọn wọnnì tí ń tọ́jú àwọn àgbàlagbà ni ó yẹ kí a gbéró kí a sì fún ní ìṣírí láti máa bá iṣẹ́ àtàtà wọn nìṣó.
“Ó Darúgbó Ó sì Nítẹ̀ẹ́lọ́rùn”
Alexander Von Humbolt, onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ará Germany ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún, ti di arúgbó gan-an nígbà tí omidan kan bi í léèrè bóyá kò rí dídàgbà di arúgbó bí ohun tí ń dánilágara. “Òtítọ́ ní ọ̀rọ̀ rẹ,” ni ọkùnrin onímọ̀ náà dáhùn. “Ṣùgbọ́n èyí ní ọ̀nà kanṣoṣo láti gbé fún ìgbà pípẹ́.” Ní ọ̀nà kan náà, ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àti arábìnrin lónìí ń fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ níti títẹ́wọ́gba àwọn ìyọnu ọjọ ogbó ní ìsanpadà fún iyì ti gbígbé ayé pẹ́. Wọ́n ṣàgbéyọ ìṣarasíhùwà tí Abrahamu, Isaaki, Dafidi, ati Jobu fihàn, àwọn ẹni tí wọ́n ‘darúgbó tí wọ́n sì nítẹ̀ẹ́lọ́rùn.’—Genesisi 25:8, NW; 35:29; 1 Kronika 23:1; Jobu 42:17.
Ọjọ́ ogbó ń mú ìpènijà ti títẹ́wọ́gba ìrànwọ́ pẹ̀lú ìdùnnú àti fífi ìmoore hàn tinútinú wá. Ó lọ́gbọ́n nínú kí ẹnìkọ̀ọ̀kan mọ ibi tí agbára rẹ̀ mọ. Bí ó ti wù kí ó rí, èyí kò mú kí ẹni tí ó ti ń di arúgbó jẹ́ aláìṣiṣẹ́mọ́. Maria ti ju ẹni 90 ọdún lọ dáradára, ṣùgbọ́n ó ṣì ń lọ sí àwọn ìpàdé ìjọ tí ó sì ń sọ̀rọ̀ ìlóhùnsí níbẹ̀. Báwo ni ó ṣe ń ṣe é? “N kò lè kàwé mọ́, ṣùgbọ́n mo máa ń fetísílẹ̀ sí Ilé-Ìṣọ́nà (ní èdè Gẹ̀ẹ́sì) tí a ti gbà sílẹ̀ sínú kásẹ́ẹ̀tì. Mo ti lè gbàgbé nǹkan jù, ṣùgbọ́n mo sábà máa ń gbìyànjú láti sọ̀rọ̀ ìlóhùnsí.” Bíi ti Maria, jíjẹ́ kí ọwọ́ dí pẹ̀lú àwọn ohun ti ń gbéniró ń ran ẹnìkan lọ́wọ́ láti jẹ́ aláápọn àti láti pa àwọn àkópọ̀ ànímọ́ Kristian mọ́.
Lábẹ́ Ìjọba Ọlọrun, ọjọ́ ogbó kò ní sí mọ́. Ní ìgbà yẹn àwọn wọnnì tí wọ́n ti darúgbó nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí bóyá tí wọ́n tilẹ̀ kú pàápàá yóò ní ìrántí onífẹ̀ẹ́ ti ìtọ́jú àti àfiyèsí tí a fihàn sí wọn. Bí irú àwọn àgbàlagbà bẹ́ẹ̀ bá ti ń jèrè ìwàláàyè àti okùn wọn padà, dájúdájú wọn yóò ní ìfẹ́ jíjinlẹ̀ fún Jehofa wọ́n yóò sì kún fún ìmoore gidigidi fún àwọn wọnnì tí wọ́n ti dúró tì wọ́n nínú ìdánwò wọn nínú ètò ògbólógbòó yìí.—Fiwe Luku 22:28.
Kí ni nípa ti àwọn wọnnì tí ń bójútó àwọn arúgbó nísinsìnyí? Láìpẹ́, nígbà tí Ìjọba náà bá gba àkóso ní kíkún lórí ilẹ̀-ayé, wọn yóò bojúwẹ̀yìn pẹ̀lú ayọ̀ àti ìtura pé wọn kò pa ojúṣe wọn tì sẹ́gbẹ̀ẹ́kan ṣùgbọ́n wọ́n ń fi ìfọkànsìn Ọlọrun ṣèwàhù nípa fífi ìfẹ́ Kristian hàn sí àwọn àgbàlagbà.—1 Timoteu 5:4.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 30]
Àwọn Àgbàlagbà Yóò Mọrírì Àwọn Ìbẹ̀wò Rẹ
Ọ̀pọ̀ ohun rere ni a lè ṣe àṣeparí rẹ̀ nípa wíwéwèé ìbẹ̀wò, bóyá fún ìṣẹ́jú 15, sí ọ̀dọ̀ arúgbó kan lẹ́yìn ìgbòkègbodò ìwàásù. Ṣùgbọ́n kò dára láti jẹ́ kí irú ìbẹ̀wò bẹ́ẹ̀ jẹ́ ọ̀ràn èèṣì, gẹ́gẹ́ bí ìrírí tí ó tẹ̀lé e yìí ti fihàn.
Brigitte àti Hannelore ń wàásù papọ̀, ní bíbá ọkùnrin àgbàlagbà kan fọ̀rọ̀wérọ̀ ní ẹnu-ọ̀nà rẹ̀. Àwọn arábìnrin náà bá a sọ̀rọ̀ fún ìṣẹ́jú márùn-ún kí wọn to mọ̀ pé òun náà jẹ́ Ẹlẹ́rìí fún Jehofa, mẹ́ḿbà ìjọ kan náà. Ẹ wo bí ó ti tinilójú tó! Ṣùgbọ́n ìrírí náà parí sí ibi tí ó dára. Hannelore ṣe ìwéwèé ojú-ẹsẹ̀ láti bẹ arákùnrin náà wò àti láti ràn án lọ́wọ́ ní wíwá sí àwọn ìpàdé ìjọ.
Ìwọ ha mọ orúkọ àti àdírẹ́sì ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn akéde àgbàlagbà tí ń gbé ní ìpínlẹ̀ ibi tí ìwọ ti ń wàásù bí? O ha lè ṣètò láti ṣe ìbẹ̀wò ráńpẹ́? Ó ṣeéṣe kí wọ́n mọrírì rẹ̀ gan-an.