Mímọyì Ipa Tó Ṣàrà Ọ̀tọ̀ Tí Jésù Kó Nínú Mímú Ìfẹ́ Ọlọ́run Ṣẹ
“Èmi ni ọ̀nà àti òtítọ́ àti ìyè. Kò sí ẹni tí ń wá sọ́dọ̀ Baba bí kò ṣe nípasẹ̀ mi.”—JÒH. 14:6.
1, 2. Kí nìdí tó fi yẹ ká fẹ́ láti ṣàyẹ̀wò ipa tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tí Jésù ń kó nínú mímú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ?
ỌJỌ́ pẹ́ tí ọ̀pọ̀ èèyàn ti máa ń sapá láti dá yàtọ̀ láàárín àwọn tó yí wọn ká, àmọ́ ìwọ̀nba làwọn tó ń kẹ́sẹ járí. Ní ti gidi, àwọn èèyàn tí ò tó nǹkan ló lè sọ pé àwọn dá yàtọ̀ lóòótọ́. Àmọ́, onírúurú ọ̀nà ni Jésù Kristi, Ọmọ Ọlọ́run fi dá yàtọ̀ gedegbe.
2 Kí nìdí tó fi yẹ ká nífẹ̀ẹ́ sí ipa tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tí Jésù ń kó nínú mímú ìfẹ́ Jèhófà ṣẹ? Ìdí ni pé, ó ní í ṣe pẹ̀lú àjọṣe àwa àti Jèhófà, Baba wa ọ̀run. Jésù sọ pé: “Èmi ni ọ̀nà àti òtítọ́ àti ìyè. Kò sí ẹni tí ń wá sọ́dọ̀ Baba bí kò ṣe nípasẹ̀ mi.” (Jòh. 14:6; 17:3) Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò àwọn ọ̀nà kan tí Jésù gbà dá yàtọ̀ gedegbe. Ìyẹn á jẹ́ ká lè mọyì ipa tó ń kó nínú mímú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ.
“Ọmọ Bíbí Kan Ṣoṣo”
3, 4. (a) Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Jésù ṣàrà ọ̀tọ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọmọ bíbí kan ṣoṣo? (b) Báwo ni ipa tí Jésù kó nínú ìṣẹ̀dá ṣe ṣàrà ọ̀tọ̀?
3 Jésù kì í wulẹ̀ ṣe “ọmọ Ọlọ́run” bí Sátánì ṣe pè é nígbà tó ń dán an wò. (Mát. 4:3, 6) Bíbélì pè é ní “Ọmọ bíbí kan ṣoṣo ti Ọlọ́run.” (Jòh. 3:16, 18) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “bíbí kan ṣoṣo” tún lè túmọ̀ sí “ọ̀kan ṣoṣo irú ẹ̀,” “ẹni tí kò sírú ẹ̀” tàbí “tí kò lẹ́gbẹ́,” ó sì lè túmọ̀ sí “ohun tó ṣàrà ọ̀tọ̀.” Jèhófà ní ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn ọmọ tó jẹ́ ẹ̀dá ẹ̀mí. Báwo ni Jésù ṣe wá jẹ́ “ẹni tí kò sírú ẹ̀” tàbí “tí kò lẹ́gbẹ́”?
4 Jésù ṣàrà ọ̀tọ̀ ní ti pé òun nìkan ni Bàbá rẹ̀ fọwọ́ ara rẹ̀ dá. Àkọ́bí Ọmọ ni, kódà òun ni “àkọ́bí nínú gbogbo ìṣẹ̀dá.” (Kól. 1:15) Òun ni “ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìṣẹ̀dá láti ọwọ́ Ọlọ́run.” (Ìṣí. 3: 14) Ipa tí Ọmọ bíbí kan ṣoṣo yìí kó nínú ìṣẹ̀dá tún ṣàrà ọ̀tọ̀. Òun kọ́ ni Ẹlẹ́dàá tàbí Olùpilẹ̀ṣẹ̀ ìṣẹ̀dá, àmọ́ òun ni Jèhófà fi ṣe aṣojú, tàbí ẹni tó tipasẹ̀ rẹ̀ dá gbogbo nǹkan yòókù. (Ka Jòhánù 1:3.) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ní ti gidi, fún àwa, Ọlọ́run kan ní ń bẹ, Baba, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ohun gbogbo ti wá, àti àwa fún un; Olúwa kan ni ó sì ń bẹ, Jésù Kristi, nípasẹ̀ ẹni tí ohun gbogbo fi wà, àti àwa nípasẹ̀ rẹ̀.”—1 Kọ́r. 8:6.
5. Báwo ni Ìwé Mímọ́ ṣe jẹ́ ká mọ àwọn ọ̀nà tí Jésù gbà ṣàrà ọ̀tọ̀?
5 Àmọ́ ṣá o, Jésù tún ṣàrà ọ̀tọ̀ láwọn ọ̀nà míì tó yàtọ̀ sí èyí tá a sọ tán yìí. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ orúkọ oyè tó jẹ́ ká mọ ipa tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tí Jésù kó nínú mímú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ ló wà nínú Ìwé Mímọ́. Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò àwọn orúkọ oyè márùn-ún míì tí Bíbélì fi pe Jésù nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni lédè Gíríìkì.a
“Ọ̀rọ̀ Náà”
6. Kí nìdí tó fi bá a mu láti máa pe Jésù ní “Ọ̀rọ̀ náà”?
6 Ka Jòhánù 1:14. Kí nìdí tí Bíbélì fi pe Jésù ní “Ọ̀rọ̀ náà,” tàbí Logos? Orúkọ oyè yìí jẹ́ ká mọ ohun tí Jésù ti ń ṣe látìgbà tí Ọlọ́run ti dá àwọn ẹ̀dá onílàákàyè yòókù. Bí Jèhófà ṣe ń tipasẹ̀ Ọmọ rẹ̀ báwa èèyàn sọ̀rọ̀ lórí ilẹ̀ ayé náà ló ṣe ń lò ó láti máa fáwọn ẹ̀dá ẹ̀mí yòókù nítọ̀ọ́ni àtàwọn ìsọfúnni míì. Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé òun ni Ọ̀rọ̀ tàbí Agbọ̀rọ̀sọ fún Ọlọ́run nígbà tó sọ fáwọn Júù tó ń gbọ́rọ̀ ẹ̀ pé: “Ohun tí mo fi ń kọ́ni kì í ṣe tèmi, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ti ẹni tí ó rán mi. Bí ẹnikẹ́ni bá ní ìfẹ́-ọkàn láti ṣe ìfẹ́ Rẹ̀, yóò mọ̀ nípa ẹ̀kọ́ náà bóyá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni tàbí mo ń sọ̀rọ̀ láti inú àpilẹ̀ṣe ti ara mi.” (Jòh. 7:16, 17) Kódà lẹ́yìn tí Jésù pa dà sí ọ̀run, ó ṣì ń bá a nìṣó láti máa jẹ́ orúkọ oyè náà, “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.”—Ìṣí. 19:11, 13, 16.
7. Báwo la ṣe lè fara wé àpẹẹrẹ ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tí Jésù fi lélẹ̀ nínú bó ṣe bójú tó ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “Ọ̀rọ̀ náà”?
7 Ronú nípa ìtumọ̀ orúkọ oyè yìí ná. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù ló gbọ́n jù lọ nínú gbogbo ẹ̀dá tí Jèhófà dá, kò gbẹ́kẹ̀ lé ọgbọ́n ara rẹ̀. Ohun tí Bàbá rẹ̀ bá fi rán an ló máa ń sọ. Gbogbo ìgbà ló máa ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ọ̀rọ̀ tí Jèhófà fi rán òun lòun ń sọ, kì í ṣe ọ̀rọ̀ ara òun. (Jòh. 12:50) Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ àtàtà ni Jésù fi lélẹ̀ fún wa yẹn! Ọlọ́run ti fún àwa náà ní àǹfààní tó ṣàrà ọ̀tọ̀ láti “polongo ìhìn rere àwọn ohun rere.” (Róòmù 10:15) Tá a bá fẹ́ fi hàn pé a mọyì àpẹẹrẹ ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tí Jésù fi lélẹ̀ fún wa, a ò ní máa fi òye ara wa kọ́ àwọn èèyàn. Tó bá dọ̀rọ̀ ká sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó lè gbẹ̀mí àwọn èèyàn là látinú Ìwé Mímọ́, kò ní dáa ká “ré kọjá àwọn ohun tí a ti kọ̀wé rẹ̀.”—1 Kọ́r. 4:6.
“Àmín”
8, 9. (a) Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà “àmín,” kí sì nìdí tí Bíbélì fi pe Jésù ní “Àmín”? (b) Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun ni “Àmín”?
8 Ka Ìṣípayá 3:14. Kí nìdí tí Bíbélì fi pe Jésù ní “Àmín”? Gbólóhùn náà “àmín” tá a mú látinú èdè Hébérù túmọ̀ sí “bẹ́ẹ̀ ni kó rí” tàbí “dájúdájú.” Ọ̀rọ̀ Hébérù míì tó tún bá a mu túmọ̀ sí “jẹ́ olóòótọ́” tàbí “ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé.” Ọ̀rọ̀ yìí náà ni Bíbélì fi ṣàpèjúwe bí Jèhófà ṣe jólóòótọ́ tó. (Diu. 7:9; Aísá. 49:7) Lọ́nà wo la wá fi lè sọ pé Jésù ṣàrà ọ̀tọ̀ nítorí pé Bíbélì pè é ní “Àmín”? Wo bí ìwé 2 Kọ́ríńtì 1:19, 20 ṣe dáhùn ìbéèrè yìí, ó ní: “Ọmọ Ọlọ́run, Kristi Jésù, tí a wàásù rẹ̀ láàárín yín. . . , kò di Bẹ́ẹ̀ ni, síbẹ̀ kí ó sì jẹ́ Bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n Bẹ́ẹ̀ ni ti di Bẹ́ẹ̀ ni nínú ọ̀ran tirẹ̀. Nítorí bí ó ti wù kí àwọn ìlérí Ọlọ́run pọ̀ tó, wọ́n ti di Bẹ́ẹ̀ ni nípasẹ̀ rẹ̀. Nítorí náà nípasẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ni a ń ṣe ‘Àmín’ sí Ọlọ́run fún ògo.”
9 Jésù ni “Àmín” sí gbogbo ìlérí tí Ọlọ́run ṣe. Bó ṣe gbé ayé láìlẹ́ṣẹ̀ lọ́rùn tó sì kú ikú ìrúbọ fi hàn pé òótọ́ làwọn ọ̀rọ̀ Jèhófà, ó sì mú gbogbo ìlérí Jèhófà Ọlọ́run ṣẹ. Jíjẹ́ tí Jésù jẹ́ olóòótọ́ tún fi hàn pé irọ́ ni ohun tí Sátánì sọ nínú ìwé Jóòbù, pé tójú bá pọ́n àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run, tí ìyà jẹ wọ́n, tí wọ́n sì tún rí àdánwò, wọ́n máa kọ Ọlọ́run sílẹ̀. (Jóòbù 1:6-12; 2:2-7) Nínú gbogbo ìṣẹ̀dá Ọlọ́run, àkọ́bí Ọmọ Ọlọ́run ti fi hàn pé irọ́ gbuu ni Sátánì pa. Yàtọ̀ síyẹn, Jésù fìdí ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro múlẹ̀ nínú ọ̀ràn pàtàkì tó ní í ṣe pẹ̀lú ẹ̀tọ́ tí Jèhófà, Bàbá rẹ̀ ní láti jẹ́ ọba aláṣẹ láyé àti lọ́run.
10. Báwo la ṣe lè fara wé Jésù nínú bó ṣe ń fi hàn lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ pé òun ni “Àmín”?
10 Báwo la ṣe lè fara wé Jésù nínú bó ṣe fi hàn lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ pé òun ni “Àmín”? A lè fara wé e nípa bíbá a nìṣó láti jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà àti nípa títi ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ lẹ́yìn. Ìyẹn á fi hàn pé à ń ṣègbọràn sóhun tó wà nínú ìwé Òwe 27:11 tó sọ pé: “Ọmọ mi, jẹ́ ọlọ́gbọ́n, kí o sì mú ọkàn-àyà mi yọ̀, kí n lè fún ẹni tí ń ṣáátá mi lésì.”
“Alárinà Májẹ̀mú Tuntun”
11, 12. Báwo ni ipa tí Jésù kó gẹ́gẹ́ bí Alárinà ṣe ṣàrà ọ̀tọ̀?
11 Ka 1 Tímótì 2:5, 6. Jésù ni “alárinà kan láàárín Ọlọ́run àti àwọn ènìyàn.” Òun ni “alárinà májẹ̀mú tuntun.” (Héb. 9:15; 12:24) Àmọ́, Bíbélì tún pe Mósè ní alárinà, ìyẹn alárinà Májẹ̀mú Òfin. (Gál. 3:19) Báwo wá ni ipa tí Jésù kó gẹ́gẹ́ bí Alárinà ṣe ṣàrà ọ̀tọ̀?
12 Gbólóhùn tá a tú sí “alárinà” yìí ní í ṣe pẹ̀lú òfin. Ó fi hàn pé Jésù ni Alárinà ní ìbámu pẹ̀lú òfin (tàbí agbẹjọ́rò, lọ́nà kan) fún májẹ̀mú tuntun tó jẹ́ kó ṣeé ṣe láti bí orílẹ̀-èdè tuntun, ìyẹn “Ísírẹ́lì Ọlọ́run.” (Gál. 6:16) Àwọn Kristẹni tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn, tí wọ́n jẹ́ “ẹgbẹ́ àlùfáà aládé” ní ọ̀run ló para pọ̀ di orílẹ̀-èdè náà. (1 Pét. 2:9; Ẹ́kís. 19:6) Májẹ̀mú Òfin àti Mósè tó jẹ́ alárinà rẹ̀ kò lè mú irú orílẹ̀-èdè yẹn jáde.
13. Kí ni ipa tí Jésù kó gẹ́gẹ́ bí Alárinà ní nínú?
13 Kí ni ipa tí Jésù kó gẹ́gẹ́ bí Alárinà ní nínú? Jèhófà lo ẹ̀jẹ̀ Jésù fún gbogbo àwọn tó wá sínú májẹ̀mú tuntun torí pé ẹ̀jẹ̀ Jésù níye lórí. Jèhófà tipa báyìí fi òdodo jíǹkí wọn níbàámu pẹ̀lú òfin. (Róòmù 3:24; Héb. 9:15) Ìgbà yẹn ni Ọlọ́run tó lè dá májẹ̀mú tuntun pẹ̀lú wọn, kí wọ́n lè di ọba àti àlùfáà ní ọ̀run. Torí pé Jésù ni Alárinà wọn, òun ló jẹ́ kí wọ́n lè ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run.—Héb. 2:16.
14. Yálà ọ̀run là ń lọ tàbí a máa wà lórí ilẹ̀ ayé, kí nìdí tó fi yẹ kí gbogbo àwa Kristẹni mọyì ipa tí Jésù kó gẹ́gẹ́ bí Alárinà?
14 Àwọn tí ò sí nínú májẹ̀mú tuntun yẹn ńkọ́, ìyẹn àwọn tí ò ní lọ sọ́rùn àmọ́ tí wọ́n ń fojú sọ́nà láti máa gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé? Bí wọn ò tiẹ̀ sí nínú májẹ̀mú tuntun, wọ́n ń jàǹfààní rẹ̀. Wọ́n ń rí ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn gbà, Ọlọ́run sì polongo wọn ní olódodo gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ rẹ̀. (Ják. 2:23; 1 Jòh. 2:1, 2) Yálà ọ̀run là ń lọ tàbí a máa wà lórí ilẹ̀ ayé, ó ṣe pàtàkì pé kí gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan fi hàn pé a mọyì ipa tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tí Jésù kó gẹ́gẹ́ bí Alárinà májẹ̀mú tuntun.
“Àlùfáà Àgbà”
15. Báwo ni ipa tí Jésù kó gẹ́gẹ́ bí Àlùfáà Àgbà ṣe yàtọ̀ sí ti gbogbo àwọn èèyàn tó ti ṣe àlùfáà àgbà rí?
15 Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti ṣe àlùfáà àgbà rí, àmọ́ ká sòótọ́, ipa tí Jésù kó gẹ́gẹ́ bí Àlùfáà Àgbà tún ṣàrà ọ̀tọ̀. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀? Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé: “Òun kò nílò láti máa rú àwọn ẹbọ lójoojúmọ́, lákọ̀ọ́kọ́ fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tirẹ̀ àti lẹ́yìn náà fún ti àwọn ènìyàn, gẹ́gẹ́ bí àlùfáà àgbà wọnnì ti ń ṣe: (nítorí èyí ni ó ṣe lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún tún un ṣe mọ́ láé nígbà tó fi ara rẹ̀ rúbọ;) nítorí tí Òfin ń yan àwọn ènìyàn tí wọ́n ní àìlera sípò gẹ́gẹ́ bí àlùfáà àgbà, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ìbúra tí a ṣe tí ó wá lẹ́yìn Òfin yan Ọmọ sípò, ẹni tí a sọ di pípé títí láé.”—Héb. 7: 27, 28.b
16. Kí nìdí tí ẹbọ tí Jésù rú fi ṣàrà ọ̀tọ̀ lóòótọ́?
16 Ẹni pípé ni Jésù, bẹ́ẹ̀ náà sì ni Ádámù kó tó dẹ́ṣẹ̀. (1 Kọ́r. 15:45) Torí náà, Jésù nìkan ni èèyàn tó lè rú ẹbọ pípé, tí kò kù síbì kan, ìyẹn ẹbọ tí kò nílò àtúnṣe. Ojoojúmọ́ làwọn èèyàn máa ń rúbọ, nígbà tí wọ́n ń tẹ̀ lé Òfin Mósè. Òjìji sì ni gbogbo ẹbọ tí wọn ń rú wọ̀nyẹn àtàwọn iṣẹ́ táwọn àlùfáà ń ṣe jẹ́ fún àwọn nǹkan ti Jésù máa ṣe láṣeparí. (Héb. 8:5; 10:1) Torí náà, ipa tí Jésù kó gẹ́gẹ́ bí Àlùfáà Àgbà ṣàrà ọ̀tọ̀ ní ti pé ohun tó ṣe láṣeparí pọ̀ ju tàwọn àlùfáà àgbà yòókù lọ àti pé kò tún ní tún un ṣe mọ́.
17. Kí nìdí tó fi yẹ ká mọyì ipa tí Jésù kó gẹ́gẹ́ bí Àlùfáà Àgbà, báwo la sì ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?
17 A nílò àwọn nǹkan tí Jésù ṣe, gẹ́gẹ́ bí Àlùfáà Àgbà, ká lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run. Ẹ ò rí i pé Àlùfáà Àgbà tá a ní yìí ta yọ! Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Àwa ní gẹ́gẹ́ bí àlùfáà àgbà, kì í ṣe ẹni tí kò lè báni kẹ́dùn fún àwọn àìlera wa, bí kò ṣe ẹni tí a ti dán wò ní gbogbo ọ̀nà bí àwa fúnra wa, ṣùgbọ́n tí kò ní ẹ̀ṣẹ̀.” (Héb. 4:15) Tá a bá fẹ́ fi hàn pé a mọyì àǹfààní yìí ní ti gidi, kò yẹ ká “tún wà láàyè fún ara [wa] mọ́, bí kò ṣe fún ẹni tí ó kú fún [wa].”—2 Kọ́r. 5:14, 15; Lúùkù 9:23.
“Irú Ọmọ” Náà
18. Àsọtẹ́lẹ̀ wo ni Ọlọ́run sọ lẹ́yìn tí Ádámù dẹ́ṣẹ̀, kí la sì wá mọ̀ nípa àsọtẹ́lẹ̀ yìí nígbà tó yá?
18 Jèhófà Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ nípa Olùgbàlà kan nígbà tó dà bíi pé ìran èèyàn ti pàdánù gbogbo nǹkan nínú ọgbà Édẹ́nì, lára àwọn nǹkan tí wọ́n sì pàdánù ni àjọṣe tó dán mọ́nrán tí wọ́n ní pẹ̀lú Ọlọ́run, ìyè àìnípẹ̀kun, ayọ̀ àti Párádísè. Bíbélì pe Olùgbàlà yẹn ní “irú ọmọ.” (Jẹ́n. 3:15) Irú Ọmọ tí ọ̀pọ̀ èèyàn ò tètè mọ̀ yìí ni ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ti sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ látìgbà pípẹ́ sẹ́yìn. Ó máa jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù. Ó sì máa wá láti ìlà ìdílé Dáfídì Ọba.— Jẹ́n. 21:12; 22:16-18; 28:14; 2 Sám. 7:12-16.
19, 20. (a) Ta ni Irú Ọmọ tí Ọlọ́run ṣèlérí? (b) Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Jésù nìkan kọ́ ni irú ọmọ tí Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀?
19 Ta ni Irú Ọmọ tí Ọlọ́run ṣèlérí yìí? Ìdáhùn ìbéèrè yìí wà nínú ìwé Gálátíà 3:16. (Kà á.) Àmọ́, nínú orí kan náà yẹn, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró pé: “Jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí ẹ bá jẹ́ ti Kristi, ẹ̀yin jẹ́ irú-ọmọ Ábúráhámù ní ti tòótọ́, ajogún ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìlérí.” (Gál. 3:29) Báwo ni Kristi ṣe jẹ́ Irú Ọmọ tí Ọlọ́run ṣèlérí, táwọn ẹlòmíì náà sì tún jẹ́ bẹ́ẹ̀?
20 Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló ń sọ pé àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù làwọn, àwọn kan lára wọn sì máa ń ṣe bíi wòlíì. Àwọn ẹ̀sìn kan tiẹ̀ kà á sí pàtàkì gan-an pé káwọn wòlíì wọn jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù. Àmọ́ ṣé Irú Ọmọ tí Ọlọ́run ṣèlérí náà ni gbogbo wọn? Rárá o. Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti fi hàn pé, kì í ṣe gbogbo àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù ló lè pera wọn ní Irú Ọmọ tí Ọlọ́run ṣèlérí. Ọlọ́run ò bù kún aráyé nípasẹ̀ àwọn ọmọ táwọn ọmọ Ábúráhámù yòókù bí, àmọ́ nípasẹ̀ Ísákì nìkan ni Ọlọ́run gbà bu kún aráyé. (Héb. 11:18) Ju gbogbo ẹ̀ lọ, ọkùnrin kan ṣoṣo, ìyẹn Jésù Kristi, tí Bíbélì fi hàn pé ó wá láti ìlà ìdílé Ábúráhámù, ni apá àkọ́kọ́ lára irú ọmọ tí Ọlọrun ṣèlérí yẹn.c Gbogbo àwọn tí wọ́n wá di apá kejì lára irú ọmọ Ábúráhámù láǹfààní yẹn torí pé wọ́n “jẹ́ ti Kristi.” Kò sí àníàní pé ipa tí Jésù kó nínú mímú àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣẹ ṣàrà ọ̀tọ̀ lóòótọ́.
21. Kí ló wú ẹ lórí nínú bí Jésù ṣe bójú tó ipa tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tó kó nínú mímú ìfẹ́ Jèhófà ṣẹ?
21 Kí làwọn nǹkan tá a ti rí kọ́ látinú àyẹ̀wò ṣókí tá a ṣe lórí ipa tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tí Jésù kó nínú mímú ìfẹ́ Jèhófà ṣẹ? Látìgbà tí Ọlọ́run ti dá Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo, ó dá yàtọ̀ lóòótọ́, kò sì sẹ́lẹgbẹ́ ẹ̀. Àmọ́, Ọmọ Ọlọ́run tó ṣàrà ọ̀tọ̀, tó wá di Jésù yìí, ò fìgbà kankan gbéra ga, ìfẹ́ inú Bàbá rẹ̀ ló máa ń ṣe, kì í sì í wá ògo ara rẹ̀. (Jòh. 5:41; 8:50) Àpẹẹrẹ àtàtà mà lèyí jẹ́ fún wa lónìí o! Bíi ti Jésù, ẹ jẹ́ káwa náà fi ṣe àfojúsùn wa láti máa “ṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run.”—1 Kọ́r. 10:31.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Nínú èdè Gíríìkì, wọ́n sábà máa ń kọ àwọn ọ̀rọ̀ tó fi hàn pé ọ̀rọ̀ kan ṣe pàtó sẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn kan lára àwọn orúkọ oyè wọ̀nyí. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀mọ̀wé kan sì ṣe sọ, ìyẹn fi hàn pé àwọn orúkọ oyè wọ̀nyẹn “dá yàtọ̀, ‘lọ́nà kan.’”
b Ọ̀mọ̀wé kan tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sọ pé, ọ̀rọ̀ tá a tú sí “lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún tún un ṣe mọ́ láé” jẹ́ ká mọ òótọ́ kan tó ṣe pàtàkì látinú Bíbélì, ìyẹn ni pé “òótọ́ ni Kristi kú, ikú ẹ̀ ṣàrà ọ̀tọ̀, ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ló sì kú.”
c Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Júù tó gbé ayé ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni ń rò pé Ọlọ́run máa ṣojúure sáwọn, nítorí pé àwọ́n jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù, wọ́n ń retí ẹnì kan tó máa wá gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà tàbí Kristi.—Jòh. 1:25; 7:41, 42; 8:39-41.
Ṣó O Rántí?
• Kí làwọn nǹkan tó o ti kọ́ látinú àwọn orúkọ oyè Jésù nípa àwọn nǹkan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tó ṣe? (Wo àpótí.)
• Báwo lo ṣe lè fara wé Ọmọ Jèhófà tó ṣàrà ọ̀tọ̀?
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Àwọn Orúkọ Oyè Tó Jẹ́ Ká Mọ Ipa Tó Ṣàrà Ọ̀tọ̀ Tí Jésù Kó Nínú Mímú Ìfẹ́ Ọlọ́run Ṣẹ
◼ Ọmọ Bíbí Kan Ṣoṣo. (Jòh. 1:3) Jésù nìkan ni Bàbá rẹ̀ fọwọ́ ara rẹ̀ dá.
◼ Ọ̀rọ̀ Náà. (Jòh. 1:14) Jèhófà fi Ọmọ rẹ̀ ṣe Agbọ̀rọ̀sọ láti máa sọ ìtọ́ni àtàwọn ìsọfúnni míì tó bá ń wá látọ̀dọ̀ Rẹ̀ fáwọn ẹ̀dá tó kù.
◼ Àmín. (Ìṣí. 3:14) Bí Jésù ṣe gbé ayé láìlẹ́ṣẹ̀ lọ́rùn àti ikú ìrúbọ tó kú fi hàn pé òótọ́ làwọn ọ̀rọ̀ Jèhófà, ó sì mú àwọn ìlérí Jèhófà Ọlọ́run ṣẹ.
◼ Alárinà Májẹ̀mú Tuntun. (1 Tím. 2:5, 6) Torí pé Jésù ni Alárinà òfin, ó jẹ́ kó ṣeé ṣe láti bí orílẹ̀-èdè tuntun kan, ìyẹn “Ísírẹ́lì Ọlọ́run,” àwọn Kristẹni tó máa jẹ́ “ẹgbẹ́ àlùfáà aládé” ní ọ̀run ló sì para pọ̀ di orílẹ̀-èdè náà.—Gál. 6:16; 1 Pét. 2:9.
◼ Àlùfáà Àgbà. (Héb. 7:27, 28) Jésù nìkan ni ẹni tó lè rú ẹbọ pípé, èyí tí kò nílò àtúnṣe mọ́. Ó lè wẹ ẹ̀ṣẹ̀ wa nù, kó sì gbà wá sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń fà.
◼ Irú Ọmọ Náà. (Jẹ́n. 3:15) Jésù Kristi ni ọkùnrin kan ṣoṣo tó jẹ́ apá àkọ́kọ́ lára irú ọmọ tí Ọlọ́run ṣèlérí yẹn. Gbogbo àwọn ẹlòmíì tó wá jẹ́ apá kejì lára irú ọmọ Ábúráhámù nígbà tó yá “jẹ́ ti Kristi.”—Gál. 3:29.