Máa Fọgbọ́n Náwó
ÀWỌN èèyàn sábà máa ń sọ pé Bíbélì ní, “Owó ni gbòǹgbò ohun búburú gbogbo.” Àmọ́ ohun tí Bíbélì sọ ní ti gidi ni pé: “Ifẹ owo ni gbòngbo ohun buburu gbogbo.” (1 Tímótì 6:10, Bibeli Mimọ) Àwọn èèyàn kan ti bá owó dá májẹ̀mú débi pé ọrọ̀ ni wọ́n ń fi gbogbo ìgbé ayé wọn kó jọ. Àwọn kan ti sọra wọn dẹrú owó wọ́n sì ti kó sínú ọ̀pọ̀ ìṣòro líle koko. Àmọ́, béèyàn bá fọgbọ́n lo owó, ọ̀pọ̀ ohun rere lèèyàn lè gbé ṣe. Bíbélì sọ pé “owó ní ń mú ìdáhùn wá nínú ohun gbogbo.”—Oníwàásù 10:19.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì kì í ṣe ìwé tó ṣàlàyé nípa owó, ọ̀pọ̀ ìmọ̀ràn tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti máa fọgbọ́n náwó ló wà níbẹ̀. Àwọn ìlànà márùn-ún tá a tò síbí yìí làwọn agbaninímọ̀ràn lórí ọ̀ràn ìnáwó sábà máa ń dá lábàá, wọ́n sì wà níbàámu pẹ̀lú àwọn ìlànà tó ti wà tipẹ́tipẹ́ nínú Bíbélì.
Máa fowó pa mọ́. Àkọsílẹ̀ Bíbélì fi hàn pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì mọ bó ti ṣe pàtàkì tó láti máa fowó pa mọ́. Ọlọ́run sọ fún wọn pé kí wọ́n máa ya ìdámẹ́wàá sọ́tọ̀ lọ́dọọdún kí wọ́n lè máa mú un dání lọ síbi àjọyọ̀ tí wọ́n máa ń ṣe lẹ́ẹ̀kan lọ́dún. (Diutarónómì 14:22-27) Bákan náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní níyànjú láti máa ya iye kan sọ́tọ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ kí wọ́n lè máa rí nǹkan fi ṣètọrẹ fáwọn onígbàgbọ́ bíi tiwọn tí wọ́n jẹ́ aláìní. (1 Kọ́ríńtì 16:1, 2) Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn agbaninímọ̀ràn lórí ọ̀ràn ìnáwó ló máa ń sọ pé ó dáa kéèyàn máa fowó pa mọ́. Fọwọ́ pàtàkì mú fífowó pa mọ́. Gbàrà tó o bá ti gbowó oṣù ẹ, lọ tọ́jú iye tó o bá fẹ́ fi pa mọ́ lára ẹ̀ sí báńkì tàbí ibòmíràn. Ìyẹn ni ò ní jẹ́ kó o kù gììrì ná an.
Fètò sí iye tí wàá máa ná. Ọ̀nà tó bọ́gbọ́n mu jù lọ nìyí tó o lè gbà máa bójú tó owó ẹ, tàbí tó o lè gbà dín iye tó ò ń ná kù. Bó o bá ní ètò tó dáa nípa bó o ṣe lè máa náwó, wàá mọ ibi tówó ẹ ń gbà lọ, ìyẹn á sì ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti má ṣe ná kọjá iye tó yẹ kó o ná. Mọ iye tó ń wọlé fún ẹ, kó o sì rí i pé o kì í ná tó iye yẹn. Mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín ohun tó pọn dandan àti ohun tí kò pọn dandan. Ó bọ́gbọ́n mu nígbà náà pé Jésù gba àwọn tó ń gbọ́rọ̀ rẹ̀ níyànjú pé kí wọ́n “gbéṣirò lé” iye tó máa ná wọn, kí wọ́n tó dáwọ́ lé ohunkóhun. (Lúùkù 14:28) Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká má ṣe máa jẹ gbèsè láìnídìí.—Òwe 22:7.
Wéwèé ohun tó o fẹ́ ṣe. Fara balẹ̀ gbé àwọn nǹkan tó o fẹ́ ṣe lọ́jọ́ iwájú yẹ̀ wò. Bí àpẹẹrẹ, bó o bá ń wéwèé láti ra odindi ilé tàbí apá díẹ̀ lára ilé ńlá kan, ó lè jẹ́ ohun tó bọ́gbọ́n mu pé kó o gba owó èlé tí kò ní fún ẹ lọ́rùn. Bákan náà, olórí ìdílé kan lè rí i pé ó pọn dandan láti gbàwé ìbánigbófò lórí ẹ̀mí, ìlera, jàǹbá, tàbí irú ìbánigbófò míì torí àtidáàbò bo aya àtàwọn ọmọ. Lára àwọn nǹkan tó o tún lè máa gbèrò àtiṣe torí ọjọ́ iwájú ni bí wàá ṣe múra sílẹ̀ de ìgbà tó o máa fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́. Òwe 21:5 rán wa létí pé “àwọn ìwéwèé ẹni aláápọn máa ń yọrí sí àǹfààní.”
Kẹ́kọ̀ọ́. Fi kún ìmọ̀ tó o ní nípa kíkọ́ àwọn nǹkan tuntun, máa tọ́jú ara ẹ, kó o sì máa ṣe ohun táá fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀. Àwọn ìdáwọ́lé tó máa ṣe ẹ́ láǹfààní nìyẹn. Má ṣe jẹ́ kó sú ẹ láti máa kẹ́kọ̀ọ́. Ohun pàtàkì ni Bíbélì ka “ọgbọ́n tí ó gbéṣẹ́ àti agbára láti ronú” sí, ó sì rọ̀ wá láti ní irú ọgbọ́n bẹ́ẹ̀.—Òwe 3:21, 22; Oníwàásù 10:10.
Wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì. Nínú ọ̀kan-ò-jọ̀kan ìwádìí táwọn èèyàn ti ṣe, ó ti wá hàn kedere pé àwọn tí ọ̀ràn èèyàn ẹlẹgbẹ́ wọn bá ń jẹ lógún máa ń láyọ̀ ju àwọn tó bá ń lépa owó lọ. Ojúkòkòrò ò tiẹ̀ jẹ́ káwọn kan gbádùn. Lọ́nà wo? Lẹ́yìn tọ́wọ́ wọn bá ti tẹ oúnjẹ, aṣọ àti ibùgbé tán, wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí í lépa ọrọ̀. Síbẹ̀, bá a bá yọwọ́ oúnjẹ, aṣọ àti ibùgbé, kí ló tún kù téèyàn ń fẹ́? Abájọ tí òǹkọ̀wé Bíbélì tá a fa ọrọ̀ rẹ̀ yọ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí fi kọ̀wé pé: “Bí a bá ti ní ohun ìgbẹ́mìíró àti aṣọ, àwa yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí.” (1 Tímótì 6:8) Bá a bá ń jẹ́ kóun tá a ní tẹ́ wa lọ́rùn, a ò ní nífẹ̀ẹ́ owó, a ò sì ní kó sínú àwọn ìṣòro tí ìfẹ́ owó máa ń mú wá.
Ká sòótọ́, ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò ohun búburú gbogbo. Owó máa di ọ̀gá ẹ bó o bá gbà fún un. Àmọ́, bó o bá lo owó bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ, ó lè fún ẹ lómìnira láti máa lépa àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nígbèésí ayé ẹ̀dá, irú bí àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú ìdílé, àwọn ọ̀rẹ́ àti Ọlọ́run. Síbẹ̀, nínú ayé yìí, ó dà bíi pé kò sí béèyàn ṣe lè bọ́ lọ́wọ́ wàhálà owó. Ṣé gbogbo ìgbà ni àìlówólọ́wọ́ á má dá ìjayà sílẹ̀? Ṣé òṣì máa tán nílẹ̀ ṣá? Èyí tó kàn nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ yìí máa dáhùn ìbéèrè náà.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]
Mọ iye tó ń wọlé fún ẹ, kó o sì rí i pé o kì í ná tó iye yẹn
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]
Mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín ohun tó pọn dandan àti ohun tí kò pọn dandan
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]
Bá a bá yọwọ́ oúnjẹ, aṣọ àti ibùgbé, kí ló tún kù téèyàn ń fẹ́?
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ójú ìwé 7]
KỌ́ ÀWỌN ỌMỌ RẸ BÍ WỌ́N ṢE LÈ MÁA ṢỌ́WÓ NÁ
Níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ àwọn àgbàlagbà ti ń kó sí ìṣòro owó lóde òní, àwọn ògbógi ti bẹ̀rẹ̀ sí í rọ àwọn òbí pé láti kékeré ni kí wọ́n ti máa kọ́ àwọn ọmọ wọn béèyàn ṣe ń náwó. Ìwọ bi ọ̀pọ̀ àwọn ọmọdé pé ibo lowó ti ń wá, ó ṣeé ṣe kí wọ́n dáhùn pé, látọ̀dọ̀ “Dádì” tàbí láti “báńkì.” Bó o bá jẹ́ káwọn ọmọ ẹ mọ bówó ti ṣe pàtàkì tó, bí wọ́n ṣe lè fìyàtọ̀ sáàárín ohun tó pọn dandan àtohun tí kò pọn dandan, bí wọ́n ṣe lè máa fowó pa mọ́, àti bí wọ́n ṣe lè máa fowó ṣòwò, o lè tipa bẹ́ẹ̀ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti sá fún wàhálà tí gbèsè ń kóni sí àti ìjayà nítorí àìlówólọ́wọ́. Àwọn àbá díẹ̀ nìwọ̀nyí.
1. Máa fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, ìwà tó ò ń hù làwọn ọmọ ẹ á máa tẹ̀ lé kì í ṣe ohun tó o bá sọ.
2. Pinnu iye tẹ́ ó máa ná. Jíròrò iye tíwọ àtàwọn ọmọ lè ná. Máà jẹ́ kó sú ẹ láti sọ pé iye tí wọ́n ná ti tó, kó o sì dúró ti ohun tó o sọ.
3. Jẹ́ kí wọ́n pinnu bí wọ́n á ṣe máa náwó. Bí wọ́n bá gba owó oúnjẹ tàbí tí wọ́n bá rówó gbà lẹ́nu iṣẹ́ kan, fún wọn láwọn ìlànà tí wọ́n á máa tẹ̀ lé. Kó o wá yọ̀ǹda fún wọn láti dá àwọn ìpinnu díẹ̀ ṣe.
4. Kọ́ wọn láti máa ṣàjọpín ohun tí wọ́n ní. Fáwọn ọmọ rẹ níṣìírí láti máa ṣàjọpín ohun tí wọ́n ní pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì kí wọ́n sì máa ya ohun kan sọ́tọ̀ déédéé láti fi ti iṣẹ́ Ọlọ́run lẹ́yìn.