“A Rà Yín Pẹlu Iye-owo Kan”
“A rà yín pẹlu iye-owo kan. Ni gbogbo ọna, ẹ fi ògo fun Ọlọrun ninu ara yin ẹyin eniyan.”—1 KỌRINTI 6:20, NW.
1, 2. (a) Ki ni o ṣí “awọn ọna abajade kuro lọwọ iku” silẹ? (b) Ki ni a nilati ṣe lati mú ki ẹbọ Kristi fẹsẹmulẹ lọna ofin, gẹgẹ bi a ti ṣapẹẹrẹ rẹ̀ nipa ki ni?
“ỌLỌRUN otitọ wà fun wa gẹgẹbi Ọlọrun awọn iṣe igbala,” ni onisaamu wi, “ti Jehofa Oluwa Ọba-alaṣẹ si ni awọn ọna abajade kuro lọwọ ikú.” (Saamu 68:20, NW) Ẹbọ Jesu Kristi ṣi ọna yẹn silẹ. Ṣugbọn ki a to le fidi ẹbọ yẹn mulẹ lọna ofin, Kristi nilati farahàn funraarẹ niwaju Ọlọrun.
2 Eyi ni a ṣapẹẹrẹ rẹ̀ ni Ọjọ Ètùtù nigba ti alufaa agba wọnu ibi Mimọ Julọ. (Lefitiku 16:12-15) Apọsteli Pọọlu kọwe pe, “ṣugbọn nigba ti Kristi de bi olori alufa . . . , kì í ṣe nipasẹ ẹjẹ ewurẹ ati ọmọ malu, ṣugbọn nipa ẹjẹ oun tikaraarẹ o wọ ibi mimọ lẹẹkanṣoṣo, lẹhin ti o ti ri idande ainipẹkun gba fun wa. Nitori Kristi ko wọ ibi mimọ ti a fi ọwọ ṣe lọ tí í ṣe apẹẹrẹ ti otitọ; ṣugbọn o lọ si ọrun paapaa, nisinsinyi lati farahan niwaju Ọlọrun fun wa.”—Heberu 9:11, 12, 24.
Agbara Ẹ̀jẹ̀
3. (a) Bawo ni awọn olujọsin Jehofa ṣe wo ẹ̀jẹ̀, èésìtiṣe? (b) Ki ni o fihan pe ẹjẹ ni agbara ti ofin lati ṣètùtù fun ẹṣẹ?
3 Ipa wo ni ẹ̀jẹ̀ Kristi kó ninu ìgbàlà wa? Lati ọjọ Noa, awọn olujọsin tootọ ti wo ẹjẹ gẹgẹbi ohun mimọ. (Jẹnẹsisi 9:4-6) Ẹjẹ kó ipa pataki ninu ọna iwalaaye, nitori Bibeli wipe “ọkàn [tabi ẹmi] ẹran ara wa ninu ẹ̀jẹ̀.” (Lefitiku 17:11, NW) Nitori naa Ofin Mose beere pe nigba ti a ba fi ẹran rubọ, ẹ̀jẹ̀ rẹ ni ki a da jade niwaju Jehofa. Nigbamiran ẹ̀jẹ̀ ni a ńtọ́ sori awọn ìwo pẹpẹ naa. Ni kedere, agbara ètùtù ti irubọ wa ninu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. (Lefitiku 8:15; 9:9) “O si fẹ́rẹ̀ jẹ́ ohun gbogbo ni a nfi ẹ̀jẹ̀ wẹ̀ nù gẹgẹbi ofin; ati láìsí ìtàjẹ̀ silẹ ko si ìdáríjì.”—Heberu 9:22.
4. (a) Ete wo ni kíká ti Ọlọrun ká ìlò ẹ̀jẹ̀ lọ́wọ́kò ṣiṣẹ fun? (b) Ki ni o ṣe pataki ninu ọna ti a gba pa Jesu?
4 Kò yà wá lẹ́nu, nigba naa, pe labẹ Ofin ìlòkulo ẹjẹ eyikeyii ni o yẹ fun ìjìyà iku! (Lefitiku 17:10) Gbogbo wa ni a mọ pe nigba ti ohun agbẹmiiro kan ba di wíwọ́n tabi bi a bá ká ìlò rẹ lọwọ kò, iniyelori rẹ yoo pọ sii. Lilo rẹ̀ tí Jehofa kó níjàánu mú un ṣekedere pe ẹ̀jẹ̀ ni a ó wò kii ṣe gẹgẹbi ohun ti ko niye lori lọna ara ọ̀tọ̀, ṣugbọn gẹgẹbi ohun ti o ṣeyebiye ti o niye lori. (Iṣe 15:29; Heberu 10:29) Eyi wà ni ìbámu pẹlu ète ti a gbega tí ẹjẹ Kristi yóò ṣiṣẹ́ fún. Lọna bíbáamu rẹ́gí, oun kú ni ọna ti o mu ki a ta ẹ̀jẹ̀ rẹ silẹ. Nipa bayii, o hàn gbangba pe kii ṣe ara eniyan rẹ nikan ni Jesu fi rubọ ṣugbọn o tú ọkàn rẹ jade, o fi iwalaaye rẹ gan-an rubọ gẹgẹbi ẹda-eniyan pipe! (Aisaya 53:12) Jesu ko padanu ẹtọ rẹ̀ lọna ti ofin si iwalaaye yẹn nitori àìpé, nitori naa ẹ̀jẹ̀ rẹ ti a tú jade ṣeyebiye gidigidi a sì lè gbe e kalẹ niwaju Ọlọrun fun ètùtù fun ẹ̀ṣẹ̀ aráyé.
5. (a) Ki ni Jesu gbe lọ si ọrun, èésìtiṣe? (b) Bawo ni o ṣe han gbangba pe Ọlọrun tẹwọgba ẹbọ Kristi?
5 Kristi ko le gbe ẹ̀jẹ̀ gidi rẹ lọ si ọrun. (1 Kọrinti 15:50) Kàkà bẹẹ, oun gbe ohun ti ẹ̀jẹ̀ naa ṣapẹẹrẹ: ìtóye ẹbọ iwalaaye eniyan pipe rẹ̀ lọna ofin. Niwaju Ọlọrun funraarẹ, oun gbé iwalaaye yẹn kalẹ lọna àṣà gẹgẹbi irapada ní pàṣípààrọ̀ fun aráyé ẹlẹṣẹ. Títẹ́wọ́gbà ti Jehofa tẹ́wọ́gba ẹbọ yẹn ni o han kedere ni Pẹntikọsti 33 C.E., nigba ti ẹmi mimọ bà sori 120 awọn ọmọ-ẹhin ni Jerusalẹmu. (Iṣe 2:1-4) Gẹgẹ bi a ti le sọ pe o jẹ, Kristi di ẹni tí ó ni ìran eniyan nipa rírà nisinsinyi (Galatia 3:13; 4:5; 2 Peteru 2:1) Fun idi yi, awọn èrè-ẹ̀san irapada le ṣàn de ọ̀dọ̀ aráyé.
Awọn Olùjàǹfààní Àkọ́kọ́ lati Inu Irapada Náà
6. Awọn iṣeto wo ni Ọlọrun ti ṣe fun fifi awọn àǹfààní irapada Kristi silo?
6 Bi o ti wu ki o ri, eyi ko tumọsi pe aráyé ni a o yọnda ìjẹ́pípé ti ara ìyára fun lọ́gán, nitori àyàfi bi a ba sẹpa ìwà ẹ̀dá eniyan ẹlẹṣẹ, ìjẹ́pípé ti ara ìyára ki yóò ṣeéṣe. (Roomu 7:18-24) Bawo ati nigba wo ni a o to sẹpa ipo ẹṣẹ? Ọlọrun kọkọ ṣeto fun 144,000 awọn ‘alufaa ti ọrun si Ọlọrun wa lati jọba lori ilẹ-aye’ pẹlu Kristi Jesu. (Iṣipaya 5:9, 10; 7:4; 14:1-3) Nipasẹ wọn awọn àǹfààní irapada naa ni a fi silo fun araye ni diẹdiẹ la sáà akoko ẹgbẹrun ọdun já.—1 Kọrinti 15:24-26; Iṣipaya 21:3, 4.
7. (a) Ki ni majẹmu titun naa, awọn wo si ni wọn jọ wà ninu rẹ̀, ete wo ni o sì ṣiṣẹ fun? (b) Èéṣe ti iku fi nilati ṣẹlẹ lati mu ki majẹmu titun ṣeeṣe, ipa wo si ni ẹ̀jẹ̀ Kristi kó?
7 Ṣaájú ìyẹn, 144,000 awọn ọba ati alufa ni a “ràpadà lati inu awọn eniyan wa.” (Iṣipaya 14:4) Eyi ni a ṣaṣepari rẹ̀ nipasẹ “majẹmu titun kan.” Majẹmu yìí jẹ àdéhùn láàárín Jehofa Ọlọrun ati Israẹli tẹmi ti Ọlọrun ki awọn mẹmba rẹ lè ṣiṣẹsin gẹgẹbi ọba ati alufaa (Jeremaya 31:31-34; Galatia 6:16; Heberu 8:6-13; 1 Peteru 2:9) Sibẹ, bawo ni majẹmu láàárín Ọlọrun ati eniyan aláìpé ṣe ṣeeṣe? Pọọlu ṣalaye: “Nitori nibi ti majẹmu bá wà [láàárín Ọlọrun ati eniyan aláìpé], ikú ẹni ti o ṣe é ko le ṣe àìsí pẹlu. Nitori ìwé ogún ni agbara nigba ti eniyan ba ku: nitori ko ni agbara rara nigba ti ẹni ti o ṣe é ba nbẹ láàyè.”—Heberu 9:16, 17.
8, 9. Bawo ni irapada ṣe tan mọ majẹmu titun naa?
8 Fún ìdí yìí, ẹbọ irapada jẹ́ ìpìlẹ̀ fun majẹmu titun naa, eyi ti Jesu jẹ Onilaja fun. Pọọlu kọwe pe: “Ọlọrun kan ni nbẹ, onílàjà kan láàárín Ọlọrun ati eniyan, oun paapaa eniyan, ani Kristi Jesu; ẹni ti o fi ara rẹ ṣe irapada [“ṣíṣerẹ́gí,” NW] fun gbogbo eniyan, ẹ̀rí ni akoko rẹ.” (1 Timoti 2:5, 6) Awọn ọrọ wọnni ni pataki ṣe é fisilo fun awọn 144,000, awọn ẹni ti a ba dá majẹmu titun.
9 Nigba ti Ọlọrun dá majẹmu pẹlu Israẹli ti ara, ko fẹsẹmulẹ lọna ofin titi di igba ti a ta ẹ̀jẹ̀ ẹran silẹ ninu ìrúbọ. (Heberu 9:18-21) Lọna ti o farajọra, fun majẹmu titun lati wa lẹnu iṣẹ, Kristi nilati ta ‘ẹ̀jẹ̀ majẹmu’ silẹ. (Matiu 26:28; Luuku 22:20) Pẹlu Kristi ti nṣiṣẹ gẹgẹbi Alufaa Agba ati “alarina majẹmu titun,” Ọlọrun fi ìtóye ẹ̀jẹ̀ Jesu silo fun awọn wọnni ti oun mu wa sinu majẹmu titun naa, o fi ododo ẹda-eniyan fun wọn lọna ofin. (Heberu 9:15; Roomu 3:24; 8:1, 2) Nigba naa Ọlọrun le mu wọn wọnu majẹmu titun naa lati jẹ ọba ati alufaa ti ọrun! Gẹgẹ bi Alarina ati Alufaa Agba wọn, Jesu tì wọn lẹhin ninu didi ìdúró rere mú niwaju Ọlọrun.—Heberu 2:16; 1 Johanu 2:1, 2.
Kíkó awọn Ohun Ori Ilẹ-aye Jọ
10, 11. (a) Bawo ni irapada ṣe nasẹ rekọja awọn Kristian ẹni ami-ororo? (b) Awọn wo ni ogunlọ́gọ̀ nla, iduro wo ni wọn si ni pẹlu Ọlọrun?
10 O ha jẹ awọn Kristian ẹni àmì-òróró nikan ni wọn lè niriiri ìtúsílẹ̀ nipa irapada, ìdáríjì awọn ẹṣẹ wọn? Bẹẹkọ, Ọlọrun nba ohun gbogbo miiran làjà nipa wiwa alaafia nipasẹ ẹ̀jẹ̀ ti a ta silẹ lori opo-igi ìdálóró, gẹgẹbi Kolose 1:14, 20 ṣe fihan. Eyi ní awọn nnkan ninu awọn ọrun (awọn 144,000) ati pẹlu awọn nnkan lori ilẹ-aye ninu. Eyi ti a mẹnukan gbẹhin ni awọn wọnni ti wọn wa ni ìlà fun iye ti ori ilẹ-aye, awọn ẹda-eniyan ti wọn yoo gbadun iwalaaye pipe ninu Paradise lori ilẹ-aye. Ni pataki lati 1935 ni isapa onifọwọsowọpọ ti wà lati kó iru awọn ẹni bẹẹ jọ. Iṣipaya 7:9-17, (NW) ṣapejuwe wọn gẹgẹbi “ogunlọ́gọ̀ nla” ti igbala wọn jẹ ti Ọlọrun ati Ọdọ agutan naa. O ṣì yẹ fun wọn lati la “ipọnju nla” já ki a si ṣamọna’ wọn lọ ‘si orisun omi iye,’ nitori Iṣipaya 20:5 fihan pe iru awọn ẹni bẹẹ yoo walaaye ni kíkún, wọn o ni iwalaaye ẹda-eniyan pipe, nigba ti o ba fi maa di opin Ijọba Ẹgbẹrun Ọdun ti Kristi. Awọn wọnni ti wọn ba yege ìdánwò ikẹhin ninu ipo ẹda-eniyan pipe wọn ni a o polongo gẹgẹbi olododo fun iye ayeraye lori ilẹ-aye.—Iṣipaya 20:7, 8.
11 Bi eyiini tilẹ ri bẹẹ, ni ọna imurasilẹ kan, ni lọwọlọwọ ogunlọ́gọ̀ nla ti “fọ aṣọ wọn, wọ́n si sọ wọn di funfun ninu ẹ̀jẹ̀ ọdọ àgùtàn naa.” (Iṣipaya 7:14) Kristi ko gbegbeesẹ gẹgẹbi Alarina majẹmu titun síhà ọdọ wọn, sibẹ wọn jàǹfààní lati inu majẹmu yii nipasẹ iṣẹ Ijọba Ọlọrun. Bi o ti wu ki o ri, Kristi ṣì nṣiṣẹ síhà ọdọ wọn gẹgẹ bi Alufaa Agba, nipasẹ ẹni tí Jehofa le, ti o si nfi irapada naa silo dé iwọn àyè pipolongo wọn nisinsinyi gẹgẹbi ọrẹ Ọlọrun. (Fiwe Jakọbu 2:23.) Láàárín Ẹgbẹrundun naa, diẹdiẹ ní a o sọ wọn “di ominira kuro ninu ìsọdẹrú si ìdibàjẹ́ [titi ti wọn yoo fi] ni ògo ominira awọn ọmọ Ọlọrun nikẹhin.”—Roomu 8:21.
12. Lori ipilẹ wo ni Ọlọrun gba ba awọn eniyan oluṣotitọ lò ni awọn akoko ti wọn ṣaaju igba Kristian?
12 Niti ìdúró wọn pẹlu Ọlọrun, o le jọ bi ẹni pe awọn wọnni ti wọn jẹ ti ogunlọ́gọ̀ ńlá fi diẹ yatọ si awọn olùjọsìn ṣaaju akoko Kristian. Bi o ti wu ki o ri, Ọlọrun ba awọn ti a sọ kẹhin yii lò pẹlu ipese irapada ọjọ iwaju lọkan. (Roomu 3:25, 26) Wọn ngbadun idariji awọn ẹṣẹ wọn kiki ni ọna ti isinsinyi nikan. (Saamu 32:1, 2) Dipo titu wọn silẹ kuro ninu “ìmọ̀ ẹṣẹ,” ni kikun awọn ẹbọ ẹran fa “iranti ẹṣẹ.”—Heberu 10:1-3.
13. Àǹfààní wo ni a ni lori awọn iranṣẹ Ọlọrun ṣaaju igba Kristian?
13 Eyi yatọ pẹlu awọn Kristian tootọ loni. Wọn njọsin lori ipilẹ irapada kan ti a ti san! Nipasẹ Alufaa Agba wọn, wọ́n “sunmọ ìtẹ́ inurere ailẹtọọsi pẹlu ominira ọ̀rọ̀ sisọ.” (Heberu 4:14-16, NW) Didi ẹni ti o ba Ọlọrun làjà kii ṣe iṣẹlẹ kan ti a nreti ṣugbọn o jẹ ohun ti o nṣẹlẹ lọwọlọwọ! (2 Kọrinti 5:20) Nigba ti wọn ba ṣàṣìṣe, wọn le ri ìdáríjì tootọ gbà. (Efesu 1:7) Wọn ngbadun ẹri-ọkan mimọ gaara nitootọ. (Heberu 9:9; 10:22; 1 Peteru 3:21) Awọn ibukun wọnyi jẹ ìtọ́wò iṣaaju ti ominira ológo awọn ọmọ Ọlọrun ti awọn iranṣẹ Jehofa yoo gbadun ní ọjọ iwaju!
Ijinlẹ Ọgbọn ati Ifẹ Ọlọrun
14, 15. Bawo ni irapada ṣe tẹnumọ ọgbọn àwámárídìí Jehofa, pẹlu iwa-ododo ati ifẹ rẹ?
14 Iru ẹ̀bùn àgbàyanu wo lati ọdọ Jehofa wá ni irapada jẹ! O tètè ṣeé loye, sibẹ o jinlẹ̀ to lati fi eniyan ọlọgbọnloye julọ sinu ibẹru ọlọ́wọ̀. Kekere ni àtúnyẹ̀wò wa nipa ìṣiṣẹ́ irapada naa jẹ. Sibẹ, awa gbóhùn soke pẹlu apọsteli Pọọlu pe: “Áà! ìjìnlẹ̀ ọrọ̀ ati ọgbọn ati ìmọ̀ Ọlọrun! Àwámárídìí ìdájọ́ rẹ ti ri, ọna rẹ si ju àwárí lọ!” (Roomu 11:33) Ọgbọn Jehofa ni a fihan niti pe oun le gba araye silẹ ati lati dá ipo ọba-alaṣẹ rẹ lare. Nipasẹ irapada naa, “a ti fi ododo Ọlọrun han gbangba . . . Ọlọrun gbe [Kristi] kalẹ gẹgẹbi ẹbọ fun ètùtù ìpẹ̀tù nipasẹ igbagbọ ninu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.”—Roomu 3:21-26, NW.
15 Ko si ariwisi kankan ti a le ṣe lodisi Ọlọrun fun didari awọn ẹṣẹ ti o ti kọja jì awọn olùjọ́sin ṣaaju akoko Kristian. Siwaju sii pẹlu, ko si ariwisi kankan ti a le ṣe lodisi Jehofa fun pipolongo awọn ẹni ami-ororo ní olododo gẹgẹbi awọn ọmọkunrin rẹ tabi ogunlọgọ ńlá gẹgẹbi awọn ọrẹ rẹ̀. (Roomu 8:33) Pẹlu iyebiye ti o ná an, Ọlọrun tẹle ofin tabi duro ṣánṣán lọna pipe, ninu ibalo rẹ̀, ni jija irọ́ ti Eṣu pa pe Jehofa jẹ́ oluṣakoso alaiṣedajọ òdodo! Ifẹ aimọtara-ẹni nikan Ọlọrun fun awọn iṣẹda rẹ̀ ni a ti ṣaṣefihan rẹ̀ lọna kan naa rekọja iyemeji.—Roomu 5:8-11.
16. (a) Ọna wo ni irapada gbà fi pese fun yíyanjú àríyànjiyàn ìwàtítọ́ awọn iranṣẹ Ọlọrun? (b) Bawo ni irapada ṣe fun wa ni ìpìlẹ̀ fun igbagbọ ninu aye titun ododo kan ti nbọ?
16 Ọna ti a gba pese irapada naa tun yanju awọn àríyànjiyàn naa ti o ni ìwàtítọ́ awọn iranṣẹ Ọlọrun nínú. Iṣegbọran Jesu nikanṣoṣo ṣaṣepari iyẹn. (Owe 27:11; Roomu 5:18, 19) Ṣugbọn ni afikun si iyẹn ni ipa-ọna igbesi-aye 144,000, awọn Kristian ti wọn duro bi oloootọ titi dé iku laika àtakò Satani si! (Iṣipaya 2:10) Irapada naa mu ki o ṣeeṣe fun awọn wọnyi lati gba aileku—iwalaaye ti a ko le parun gẹgẹbi èrè wọn! (1 Kọrinti 15:53; Heberu 7:16) Eyi mu ki ohun ti Satani sọ pe awọn iranṣẹ Ọlọrun ko ṣeegbẹkẹle jasi èké! Irapada tun fun wa ni ìpìlẹ̀ fun igbagbọ ninu awọn ileri Ọlọrun ti o ṣee gbarale. Awa le kiyesi iwewee ti a ṣe fun igbala ti a ‘fidi rẹ múlẹ̀ labẹ ofin’ nipasẹ ẹbọ irapada naa. (Heberu 8:6, NW) Aye titun ododo kan ni a tipa bayii mu dajuṣaka!—Heberu 6:16-19.
Maṣe sọ Ète Rẹ̀ Nù
17. (a) Bawo ni awọn kan ṣe fihan pe wọn ti sọ ete irapada naa nù? (b) Ki ni o le sun wa lati wà ni mimọ niti ìwàhíhù?
17 Lati jere lati inu irapada naa, o pọndandan pe ki ẹnikan gba imọ sinu, ki o lo igbagbọ, ki o si gbe ni ibamu pẹlu awọn ọpa idiwọn Bibeli. (Johanu 3:16; 17:3) Ṣugbọn, iwọnba diẹ ni ifiwera ni wọn muratan lati ṣe bẹẹ. (Matiu 7:13, 14) Ani laaarin awọn Kristian tootọ paapaa, awọn kan le “tẹwọgba inurere ailẹtọsi Ọlọrun ki wọn si sọ ete rẹ nu.” (2 Kọrinti 6:1, NW) Fun apẹẹrẹ, la awọn ọdun já ẹgbẹgbẹrun ni a ti yọ lẹgbẹ fun ìwà ibalopọ-takọtabo ti ko yẹ. Bawo ni o ti tinilójú tó ni oju-iwoye ohun ti Jehofa ati Kristi ti ṣe fun wa! Ko ha yẹ ki imọriri fun irapada sun ẹnikan lati yẹra fun didi ẹni ti o “gbagbe pe a ti wẹ oun nù kuro ninu ẹṣẹ rẹ atijọ”? (2 Peteru 1:9) Lọna ti o bamu, nigba naa, Pọọlu rán awọn Kristian leti pe: “A rà yín pẹlu iye-owo kan. Ni gbogbo ọna, ẹ fi ògo fun Ọlọrun ninu ara yin ẹyin eniyan.” (1 Kọrinti 6:20, NW) Riranti eyi fun wa ni isunniṣe alagbara lati wa ni mimọ niti iwahihu!—1 Peteru 1:14-19.
18. Bawo ni Kristian kan ti o ṣubú sinu ẹṣẹ wíwúwo ṣe le lo irapada náà fun ara rẹ sibẹ?
18 Ki ni bi ẹnikan ba ti ṣubu sinu ẹṣẹ wiwuwo ṣaaju isinsinyi? Oun nilati lo àǹfààní ìdáríjì tí irapada mu ki o ṣeéṣe, ni gbígba ìrànlọ́wọ́ lati ọdọ awọn alaboojuto onifẹẹ. (Jakọbu 5:14, 15) Àní bi o ba nilo ìbáwí lilekoko paapaa, Kristian onironupiwada kan ko gbọdọ ṣiwọ iṣẹ labẹ iru ìtọ́ni bẹẹ. (Heberu 12:5) Awa ní agbayanu ìdánilójú yii ninu Bibeli: “Bi awa ba jẹwọ ẹṣẹ wa, oloootọ ati olododo ni oun lati dari ẹṣẹ wa ji wa, ati lati wẹ wa nù kuro ninu àìṣòdodo gbogbo.”—1 Johanu 1:9.
19. Oju-iwoye wo ni Kristian kan le ni niti ìwà àìtọ́ ti o ti ṣẹlẹ ṣaaju ki o tó kẹkọọ otitọ?
19 Nigba miiran awọn Kristian a maa ni ìrẹ̀wẹ̀sì lọna àìyẹ nitori iwa àìtọ́ ti igba àtijọ́. “Ṣaaju wíwá sinu otitọ,” ni arakunrin kan ti o rẹ̀wẹ̀sì kọwe, “emi ati aya mi kó àrùn abẹ ti njẹ herpes. Nigba miiran a ni imọlara àìmọ́, gẹgẹbi ẹnipe awa ko ‘yẹ’ ninu eto-ajọ mimọ ti Jehofa.” A gbà pe, lẹhin didi Kristian paapaa, awọn kan le karugbin ìrora de àyè kan lati inu awọn aṣiṣe atijọ. (Galatia 6:7) Sibẹ, ko si idi lati ni imọlara àìmọ́ ni oju Jehofa ti ẹnikan ba ti ronupiwada. “Ẹ̀jẹ̀ Kristi” le ‘wẹ ẹ̀rí-ọkàn wa mọ́ kuro ninu awọn oku iṣẹ.’—Heberu 9:14.
20. Bawo ni igbagbọ ninu irapada ṣe le tú Kristian kan silẹ kuro ninu ẹ̀bi ti ko ṣe pataki?
20 Bẹẹni, igbagbọ ninu irapada le ṣeranlọwọ lati tù wa lara kuro lọwọ awọn ẹru inira ẹbi ti kò pọndandan. Ọdọ arabinrin kan gba pe: “Mo ti ńjìjàkadì pẹlu ìwà àìmọ́ ti ìdánìkan hùwà ìbálòpọ̀ fun ohun ti o ju ọdun mọkanla lọ nisinsinyi. Mo fẹrẹẹ fi ijọ silẹ ni akoko kan, ni ninimọlara pe Jehofa ki yoo fẹ eniyan ti o jẹ ẹlẹgbin tobẹẹ lati ko èérí ba ijọ rẹ.” Sibẹ, awa gbọdọ ranti pe, Jehofa ‘dara o si muratan lati dariji’ niwọnbi awa ba ti fi tọkantọkan dojú ija kọ ìwà àìṣòdodo, laijuwọsilẹ fun un!—Saamu 86:5.
21. Bawo ni irapada ṣe le nipa lori oju ti a fi nwo awọn wọnni ti wọn ṣẹ̀ wa?
21 Irapada tun nilati nipa lori ọna ti awa ńgbà ba awọn ẹlomiran lò. Fun apẹẹrẹ, bawo ni iwọ ṣe ńhùwà pada nigba ti Kristian ẹlẹgbẹ rẹ kan ba ṣẹ ọ? Njẹ iwọ ńnawọ́ idariji jade fàlàlà bii ti Kristi bi? (Luuku 17:3, 4) Iwọ ha ‘ni iyọnu, ni didariji [awọn ẹlomiran], gẹgẹbi Ọlọrun ninu Kristi ti ndariji ọ bi’? (Efesu 4:32) Tabi iwọ ha ńnítẹ̀sí lati yàn odì tabi mu irunu dagba? Iyẹn dajudaju yoo tumọsi sisọ ete irapada naa nù.—Matiu 6:15.
22, 23. (a) Ipa wo ni irapada nilati ni lori awọn gongo-ilepa ati ọna igbesi-aye wa? (b) Ipinnu wo ni gbogbo Kristian nilati ṣe nipa irapada naa?
22 Nikẹhin, imọriri fun irapada nilati ni ipa jijinlẹ lori awọn gongo-ilepa ati ọna igbesi-aye wa. Pọọlu wipe: “A ti rà yín ni iye [“iye-owo,” NW] kan; ẹ maṣe di ẹru eniyan.” (1 Kọrinti 7:23) Njẹ awọn aini ti iṣunna-owo—ile, iṣẹ, ounjẹ, aṣọ—ha ṣì jẹ́ ìlépa igbesi-aye rẹ bi? Tabi iwọ ha nwa Ijọba naa lakọọkọ, ni lilo igbagbọ ninu ileri Ọlọrun lati pese fun ọ? (Matiu 6:25-33) Iwọ ha le ṣẹrú fun agbanisíṣẹ́ rẹ ki o si kùnà lati fi àyè ti o to silẹ fun awọn igbokegbodo ti iṣakoso Ọlọrun bi? Ranti pe, Kristi “fi ara rẹ fun wa, ki oun le wẹ awọn eniyan kan mọ fun ara rẹ fun ìní oun tikaraarẹ awọn onitara iṣẹ rere.”—Titu 2:14; 2 Kọrinti 5:15.
23 “Ọpẹ ni fun Ọlọrun nipasẹ Jesu Kristi” fun ẹbùn gigajulọ yii—Irapada! (Roomu 7:25, NW) Njẹ ki awa maṣe sọ ète irapada naa nù lae ṣugbọn ki a yọnda rẹ lati jẹ ipá gidi ninu igbesi-aye wa. Ninu ero, ninu ọrọ, ati ninu iṣe, njẹ ki awa maa fi ògo fun Ọlọrun nigba gbogbo, ki a maa ranti pẹlu imoore pe a ti rà wá pẹlu iye-owo kan.
Awọn Ibeere Àtúnyẹ̀wò
◻ Eeṣe ti a fi ka ẹ̀jẹ̀ si ohun mimọ, bawo si ni a ṣe gbé ẹ̀jẹ̀ Kristi kalẹ niwaju Ọlọrun ni ọrun?
◻ Ipa wo ni ẹ̀jẹ̀ Kristi kó ninu lilohun si majẹmu titun?
◻ Bawo ni irapada ṣe ṣàǹfààní fun awọn ẹni ami-ororo ati ogunlọ́gọ̀ ńlá?
◻ Bawo ni awa ṣe le fihan pe awa ko tíì sọ ete irapada naa nù?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Agbara ìṣètùtù tí ẹbọ kan ní wà ninu ẹ̀jẹ̀ iwalaaye
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Ẹnikan ti o mọriri ìdáríjì Ọlọrun muratan lati nawọ ìdáríjì si awọn ẹlomiran