Ẹ̀KỌ́ 37
Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Iṣẹ́ àti Owó
Ṣé ọ̀rọ̀ owó tàbí iṣẹ́ máa ń kó ìdààmú bá ẹ? Kì í rọrùn láti gbọ́ bùkátà ká sì tún máa sin Jèhófà bó ṣe yẹ. Bíbélì jẹ́ ká mọ ohun tá a lè ṣe tí ọ̀rọ̀ iṣẹ́ àti owó kò fi ní mú ká pa ìjọsìn Ọlọ́run tì.
1. Kí ni Bíbélì sọ nípa iṣẹ́?
Ọlọ́run fẹ́ ká máa gbádùn iṣẹ́ wa. Bíbélì sọ pé: “Kò sóhun tó dáa fún èèyàn ju pé kó . . . gbádùn iṣẹ́ àṣekára rẹ̀.” (Oníwàásù 2:24) Òṣìṣẹ́ kára ni Jèhófà. Táwa náà bá ń ṣiṣẹ́ kára bíi ti Jèhófà, a máa múnú ẹ̀ dùn, inú tiwa náà á sì máa dùn.
Iṣẹ́ ṣe pàtàkì gan-an. Àmọ́, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí iṣẹ́ ṣe pàtàkì sí wa débi tá ò fi ní ráyè máa sin Jèhófà bó ṣe yẹ. (Jòhánù 6:27) Jèhófà ṣèlérí pé tá a bá ń fi ìjọsìn òun sí ipò àkọ́kọ́, òun á máa tọ́jú wa.
2. Kí ni Bíbélì sọ nípa owó?
Òótọ́ ni pé Bíbélì sọ pé ‘owó jẹ́ ààbò.’ Àmọ́ ó tún jẹ́ ká mọ̀ pé owó nìkan ò lè fún wa láyọ̀. (Oníwàásù 7:12) Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi gbà wá níyànjú pé ká ‘jẹ́ kí àwọn nǹkan tó wà báyìí tẹ́ wa lọ́rùn.’ (Ka Hébérù 13:5.) Tá a bá ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú àwọn ohun tá a ní, a ò ní kóra wa sí wàhálà torí pé a ṣáà fẹ́ ní nǹkan púpọ̀ sí i. Yàtọ̀ síyẹn, a ò ní lọ jẹ gbèsè láìjẹ́ pé ó pọn dandan. (Òwe 22:7) A ò sì ní máa ta tẹ́tẹ́, tàbí ká kó ara wa síṣòro níbi tá a ti ń wá bá a ṣe máa dolówó òjijì.
3. Báwo la ṣe lè lo owó lọ́nà tó dáa?
Ọ̀làwọ́ ni Jèhófà Ọlọ́run wa, táwa náà bá ‘jẹ́ ọ̀làwọ́, tá a sì ṣe tán láti máa fúnni,” ńṣe là ń fìwà jọ ọ́. (1 Tímótì 6:18) Ọ̀kan lára ọ̀nà tá a le gbà lo owó wa lọ́nà tó dáa ni pé ká máa ṣètìlẹyìn nínú ìjọ, ká sì máa ran àwọn aláìní lọ́wọ́, ní pàtàkì àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà. Kì í ṣe iye tá a fún àwọn èèyàn ló ṣe pàtàkì jù sí Jèhófà, bí kò ṣe ohun tó wà lọ́kàn wa tá a fi fún wọn. Tá a bá ń ṣoore fáwọn èèyàn tọkàntọkàn, inú wa máa dùn, inú Jèhófà náà á sì dùn sí wa.—Ka Ìṣe 20:35.
KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀
Jẹ́ ká wo ìdí tí kò fi yẹ ká jẹ́ kí iṣẹ́ mú ká pa ìjọsìn Jèhófà tì àti ìdí tó fi yẹ ká ní ìtẹ́lọ́rùn.
4. Fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ rẹ, má sì pa ìjọsìn Jèhófà tì
Ó yẹ kí ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà máa hàn nínú gbogbo ohun tá à ń ṣe, títí kan ọwọ́ tá a fi mú iṣẹ́. Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí.
Nínú fídíò yẹn, kí ló wú ẹ lórí nípa ìwà Jason àti ọwọ́ tó fi mú iṣẹ́?
Kí ló ran Jason lọ́wọ́ tí kò fi jẹ́ kí iṣẹ́ dí ìjọsìn ẹ̀ lọ́wọ́?
Ka Kólósè 3:23, 24, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Kí nìdí tó fi yẹ ká fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́?
Iṣẹ́ ṣe pàtàkì gan-an. Àmọ́, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí iṣẹ́ ṣe pàtàkì sí wa débi tá ò fi ní ráyè máa sin Jèhófà bó ṣe yẹ
5. A máa jàǹfààní púpọ̀ tá a bá ní ìtẹ́lọ́rùn
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń wá bí wọ́n ṣe máa lówó rẹpẹtẹ. Àmọ́ ohun tí Bíbélì sọ yàtọ̀ síyẹn. Ka 1 Tímótì 6:6-8, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Kí ni Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká ṣe?
Tá ò bá tiẹ̀ lówó púpọ̀, a lè láyọ̀. Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìdílé yìí ò fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́, kí ló ń fún wọn láyọ̀?
Tá a bá ní gbogbo ohun tá a nílò, àmọ́ tá a tún ń wá bá a ṣe máa ní sí i ńkọ́? Jésù jẹ́ ká mọ àkóbá tí èyí lè ṣe. Ka Lúùkù 12:15-21, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Kí lo rí kọ́ látinú àpèjúwe yẹn?—Wo ẹsẹ 15.
Ka Òwe 10:22 àti 1 Tímótì 6:10 kó o sì fi wéra wọn. Lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Ṣé kéèyàn sún mọ́ Ọlọ́run ló ṣe pàtàkì jù ni àbí kéèyàn lówó rẹpẹtẹ? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?
Téèyàn bá ń wá owó lójú méjèèjì, ìṣòro wo nìyẹn lè fà?
6. Jèhófà máa tọ́jú wa
Ohun tá a bá ṣe nígbà tá ò bá níṣẹ́ gidi lọ́wọ́ tá ò sì fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́ lè fi hàn bóyá a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà àbí a ò gbẹ́kẹ̀ lé e. Wo FÍDÍÒ yìí kó o lè mọ ohun tó yẹ kó o ṣe tó o bá nírú ìṣòro yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.
Nínú fídíò yẹn, ìṣòro wo ni arákùnrin yẹn ní?
Àwọn nǹkan wo ló ṣe kó lè fara da ìṣòro náà?
Ka Mátíù 6:25-34, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Ìlérí wo ni Jèhófà ṣe fún àwọn tó bá fi ìjọsìn rẹ̀ sípò àkọ́kọ́?
ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Mo gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kára kí n lè máa tọ́jú ìdílé mi. Torí náà, mi ò lè ráyè máa lọ sípàdé ìjọ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.”
Ẹsẹ Bíbélì wo ló mú kó dá ẹ lójú pé Jèhófà máa tọ́jú ẹ tó o bá fi ìjọsìn ẹ̀ sípò àkọ́kọ́?
KÓKÓ PÀTÀKÌ
Òótọ́ ni pé iṣẹ́ àti owó ṣe pàtàkì, àmọ́ a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí wọ́n mú ká pa ìjọsìn Jèhófà tì.
Kí lo rí kọ́?
Kí lo lè ṣe kó o má bàa ka iṣẹ́ sí pàtàkì ju ìjọsìn Ọlọ́run lọ?
Àǹfààní wo ló máa ṣe ẹ́ tó o bá ní ìtẹ́lọ́rùn?
Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o fọkàn tán ìlérí tí Jèhófà ṣe pé òun á máa tọ́jú àwọn èèyàn òun?
ṢÈWÁDÌÍ
Ka ìwé yìí kó o lè mọ̀ bóyá nǹkan burúkú ni Bíbélì pe owó.
“Ṣé Owó Ni Gbòǹgbò Ohun Búburú Gbogbo?” (Àpilẹ̀kọ orí ìkànnì)
Ka ìwé yìí kó o lè mọ ìlànà tí Ọlọ́run fẹ́ ká máa tẹ̀ lé tá a bá fẹ́ fún àwọn èèyàn ní nǹkan.
Ṣé ó burú láti ta tẹ́tẹ́?
Ka ìwé yìí kó o lè mọ ohun tó mú kí ọkùnrin kan tó máa ń ta tẹ́tẹ́, tó sì jẹ́ ọ̀daràn paraku yí ìgbé ayé ẹ̀ pa dà.
“Mo Fẹ́ràn Ẹṣin àti Fífi Ẹṣin Sáré Ìje” (Ilé Ìṣọ́, November 1, 2011)