Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Ońṣẹ́ Àlàáfíà Ọlọ́run” ti 1996
1 Dájúdájú, ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọpọ̀ àgbègbè ọdún yìí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti pa àlàáfíà Ọlọ́run tí a ní mọ́, yóò sì ṣàlàyé ipa iṣẹ́ wa nínú ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti rí irú àlàáfíà bẹ́ẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣèfilọ̀ rẹ̀ nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti May 1996, ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni “Àwọn Ońṣẹ́ Àlàáfíà Ọlọ́run.” O ha ti ṣe àwọn ètò rẹ, kí o má baà pa ìtòlẹ́sẹẹsẹ èyíkéyìí jẹ?
2 Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ọlọ́jọ́ Mẹ́ta: A mọ̀ pé ẹ óò gbádùn àpéjọpọ̀ ọdún yìí dáradára, ẹ óò sì padà sílé pẹ̀lú agbára àkọ̀tun. (2 Kro. 7:10) A óò tún ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọlọ́jọ́ mẹ́ta ni ọdún yìí. Ìwọ́ ha ti ṣètò láti gba ìsinmi kúrò lẹ́nu iṣẹ́, kí ó baà lè ṣeé ṣe fún ọ láti wà níbẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta àpéjọpọ̀ náà? Díẹ̀ lára àwọn àpéjọpọ̀ àkọ́kọ́ yóò wáyé ṣáájú kí a tó gba ọlidé ní ilé ẹ̀kọ́. Bí o bá ní àwọn ọmọ tí ń lọ sí ilé ẹ̀kọ́, o ha ti fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ sọ fún àwọn olùkọ́ wọn pé wọn kò ní wá sí ilé ẹ̀kọ́ ní ọjọ́ Friday, nítorí apá pàtàkì ìjọsìn wọn yìí bí?
3 Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti May 1996 ṣètòlẹ́sẹẹsẹ àwọn ọjọ́ àti ọ̀gangan ibi àpéjọpọ̀ 104 ní Nàìjíríà. Nísinsìnyí, akọ̀wé ìjọ yín yóò ti fi èyí tí a yan ìjọ yín sí tó yín létí. Ní àpéjọpọ̀ àgbègbè Ọ̀tà 7 àti Uli 7, a óò tú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà sí Èdè Àwọn Adití.
4 Ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà yóò bẹ̀rẹ̀ ní 9:20 òwúrọ̀ Friday, yóò sì parí ní nǹkan bíi 3:30 ìrọ̀lẹ́ Sunday. Ní Saturday àti Sunday, ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà yóò bẹ̀rẹ̀ ní 9:00 òwúrọ̀. Àwa yóò ha fi inú rere hàn sí àwọn ará wa tí wọ́n ti dàgbà tàbí tí wọ́n ṣàìlera, nípa fífi àwọn ìjókòó tí ó wà ní àwọn ibi tí ó túbọ̀ rọni lọ́rùn, tí ń tuni lára, sílẹ̀ fún wọn bí? Rántí pé, “ìfẹ́ . . . kì í wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan.”—1 Kọr. 13:4, 5; Flp. 2:4.
5 Ìwọ Yóò Ha Di Ẹni Tí A Pọ́n Bí? Lẹ́yìn ṣíṣàyọlò Òwe 27:17, “Irin a máa pọ́n irin,” Ilé-Ìṣọ́nà August 15, 1993 sọ pé: “A dabi àwọn irin-iṣẹ tí ó nilo pípọ́n deedee. Niwọn bi o ti jẹ́ pe fifi ifẹ hàn sí Jehofa ati ṣiṣe awọn ìpinnu ti a gbekari igbagbọ wa tumọsi yiyatọ si ayé, lati ìgbà de ìgbà ni a nilati maa gba ọ̀nà ti o yatọ, ki a sọ bẹẹ, si ti awọn eniyan púpọ̀ julọ.” Báwo ni a ṣe lè lo ìmọ̀ràn yẹn?
6 A yàtọ̀ pátápátá sí ayé, a sì ní láti máa bá a lọ láti yàtọ̀. A ní láti máa bá ìsapá lemọ́lemọ́ láti ṣàṣeparí èyí lọ, bí a óò bá jẹ́ onítara fún iṣẹ́ àtàtà. (Títù 2:14) Ìdí nìyẹn tí ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ Ilé Ìṣọ́ tí a ṣàyọlò rẹ̀ lókè yìí fi ń bá a lọ láti sọ pé: “Nigba ti a bá wà pẹlu awọn ẹlomiran ti wọn nifẹẹ Jehofa, a ń pọ́n ara wa—a ń ru ara wa si ifẹ àti si iṣẹ rere.” Àpéjọpọ̀ àgbègbè jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìpèsè Jèhófà láti ràn wá lọ́wọ́ láti wà lójúfò ṣámúṣámú nípa tẹ̀mí. A kò lè pa apá èyíkéyìí nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà jẹ láìṣèpalára fún wa.
7 Ọlọgbọ́n Ènìyàn Yóò Fetí Sílẹ̀: Fífetí sílẹ̀ jẹ́ ọnà kan tí a ní láti mú dàgbà. A máa ń sọ pé, kìkì ìdajì nínú ohun tí ènìyàn gbọ́ ni ó máa ń rántí—láìka bí ó ṣe rò pé òún fetí sílẹ̀ dáradára tó sí. Níwọ̀n bí a ti ń gbé nínú sànmánì onípìn-ínyà ọkàn, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, a lè ní ìṣòro pípọkàn pọ̀ fún sáà àkókò gígùn. A ha lè gbìyànjú láti mú àkókò àfiyèsí wa túbọ̀ gùn sí i, pàápàá jù lọ, nígbà tí a bá jókòó láàárín àwùjọ ńlá, tí a ń tẹ́tí sílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ tí ẹnì kan ń sọ? Bí a bá ní kí o ṣe àkópọ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, lẹ́yìn tí o bá padà sílé láti àpéjọpọ̀, yóò ha ṣeé ṣe fún ọ láti ṣe bẹ́ẹ̀ bí? Báwo ni gbogbo wá ṣe lè mú kí agbára ìfetísílẹ̀ wa sunwọ̀n sí i, kí a sì tẹ́tí sílẹ̀ dáradára sí apá kọ̀ọ̀kan ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọpọ̀ náà?
8 Ọkàn-ìfẹ́ mímú hánhán ṣe kókó, nítorí ẹ̀bùn ìrántí tí Ọlọ́run fi jíǹkí wa kò lè ṣiṣẹ́ dáradára láìsí i. Fún àpẹẹrẹ, bí ènìyàn bá ṣe fi ìfẹ́ hàn nínú kókó ẹ̀kọ́ kan tó, bẹ́ẹ̀ náà ni yóò ṣe rọrùn fún un tó láti rántí àwọn kókó inú ọ̀rọ̀ àsọyé tàbí apá ìtòlẹ́sẹẹsẹ kan. Síbẹ̀, púpọ̀ sinmi lórí fífún tí a ń fún àwọn ohun tí a láǹfààní láti gbọ́ ní àwọn àpéjọpọ̀ àgbègbè ní àfiyèsí tí ó ju ti àtẹ̀yìnwá lọ. Ọkàn-ìfẹ́ mímú hánhán tí a ní nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọpọ̀ kọ̀ọ̀kan àti àfiyèsí tí a fún un, ní í ṣe pẹ̀lú ipò tẹ̀mí wa ti lọ́ọ́lọ́ọ́ àti ìfojúsọ́nà wa ọjọ́ iwájú. Kò nira láti mọ̀ pé, kò ní ṣeé ṣe fún wa láti fetí sílẹ̀ ní kíkún, bí a bá gbìyànjú láti tẹ́tí sí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà láti yàrá ilé gbígbé tí a fi wá wọ̀ sí ní Ilẹ̀ Àpéjọ, gẹ́gẹ́ bí àwọn kan ti ṣe ní ìgbà tí ó kọjá. Nítorí náà, gbogbo àwùjọ gbọ́dọ̀ kóra jọ pọ̀ sábẹ́ gbọ̀ngàn àpéjọ, kí ẹ sì máa fọkàn bá ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà lọ pẹ́kípẹ́kí. Ní àwọn àpéjọpọ̀, a ń kọ́ wa ní àwọn ọ̀nà Jèhófà, a sì ń fún wa nítọ̀ọ́ni fún ṣíṣàṣeparí iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà. (1 Tim. 4:16) Ronú pé o jẹ́ ọkọ̀ ojú omi tí ó wà ní agbami òkun, tí ń ru gùdù. Àwọn ìlérí Jèhófà jẹ́ ìdákọ̀ró lílágbára ti ìrètí. Bí ẹnì kan kò bá fetí sílẹ̀ sí àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ Kristẹni, tí ó sì jẹ́ kí èrò inú rẹ̀ sú lọ, ó lè pàdánù àwọn kókó pàtàkì inú ìmọ̀ràn àti ìtọ́ni tí ó lè yọ ọ́ nínú jíjìyà ọkọ̀ rírì nípa tẹ̀mí.—Heb. 2:1; 6:19.
9 Ní ibi púpọ̀ lórí ilẹ̀ ayé, àwọn ará wa ń sapá gidigidi láti lè pésẹ̀ sí àwọn ìpàdé. Ó máa ń wúni lórí láti rí i bí wọ́n ti ń fetí sílẹ̀ dáradára ní àwọn àpéjọpọ̀. Ṣùgbọ́n, ní àwọn ibòmíràn, àwọn kan ti pín ọkàn àwọn ẹlòmíràn níyà nípa wíwọ́ kiri ilẹ̀ àpéjọpọ̀ nígbà tí ọ̀rọ̀ ń lọ lọ́wọ́. Àwọn mìíràn ń pẹ́ dé. Ní àwọn àpéjọpọ̀ kan tí a ṣe kọjá, ó ṣòro gidigidi láti gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí a fi ṣí ìpàdé, nítorí ọ̀pọ̀ tí ń rìn gbéregbère ní ilẹ̀ àpéjọpọ̀ àti ní ẹ̀yìn ibi ìjókòó. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn wọ̀nyí kì í ṣe àwọn arákùnrin tí ó wà lẹ́nu iṣẹ́ tàbí àwọn màmá tí ń bójú tó àwọn ọmọ wọn kéékèèké. Ọ̀pọ̀ jù lọ ìyọlẹ́nu náà ń wá láti ọ̀dọ̀ àwọn tí ń ṣèbẹ̀wò kiri. Ní ọdún yìí, Ẹ̀ka Iṣẹ́ Tí Ń Bójú Tó Èrò yóò lo òye láti túbọ̀ fún ìṣòro náà ní àfiyèsí, a sì nírètí pé, gbogbo wa ni yóò ti wà níjokòó nígbà ti alága bá ké sí wa láti ṣe bẹ́ẹ̀. A óò mọrírì ìfọwọ́sowọ́pọ̀ yín gidigidi nínú ọ̀ràn yìí.
10 Àwọn ìmọ̀ràn gbígbéṣẹ́ wo ní yóò ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ fiyè sí ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọpọ̀, kí a sì rántí púpọ̀ nínú ohun tí a gbọ́? Ó ṣe pàtàkì láti tún àwọn ohun tí a ti sọ ní àwọn ọdún tí ó ti kọjá sọ: (a) Pọkàn pọ̀ sórí ìdí pàtàkì tí a fi lọ sí ilẹ̀ àpéjọpọ̀. Kì í ṣe láti lọ́wọ́ nínú eré ìnàjú, bí kò ṣe láti fetí sílẹ̀, kí a sì kẹ́kọ̀ọ́. (Diu. 31:12) Gbìyànjú láti sùn dáradára ní alaalẹ́. Bí ó bá ti rẹ̀ ọ́ gan-an nígbà tí o dé sí àpéjọpọ̀, yóò ṣòro fún ọ láti pọkàn pọ̀. (b) Fún ara rẹ ní ọ̀pọ̀ àkókò láti wá ibi gbé ọkọ̀ rẹ sí, kí o sì wà lórí ìjókòó kí ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó bẹ̀rẹ̀. Kíkánjú lọ sórí ìjókòó, nígbà tí àkókò ti lọ tán, sábà máa ń yọrí sí pípàdánù díẹ̀ lára apá tí a fi ṣí ìpàdé. (d) Ṣe àkọsílẹ̀ àwọn kókó pàtàkì. Ṣíṣe àkọsílẹ̀ gígùn jàn-ànrànjan-anran lè ṣèdíwọ́ fún ọ láti fetí sílẹ̀ dáradára. Nígbà tí o bá ń ṣàkọsílẹ̀, rí i dájú pé o kò pàdánù àwọn kókó mìíràn, nítorí tí o ń pọkàn pọ̀ sórí ohun tí o ń kọ. (e) Nígbà tí a bá ṣe ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ apá ìtòlẹ́sẹẹsẹ kan, fi ìháragàgà wọ̀nà fún un. Bi ara rẹ léèrè pé, ‘Kí ni mo lè rí kọ́ nínú apá yìí tí yóò fi kún ìmọrírì mi àti ìfẹ́ mi fún Jèhófà? Báwo ni ìsọfúnni náà yóò ṣe ràn mí lọ́wọ́ láti túbọ̀ mú àkópọ̀ ìwà tuntun dàgbà ní kíkún sí i? Báwo ni èyí yóò ṣe ràn mí lọ́wọ́ láti sunwọ̀n sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi?’
11 Àwọn Ìwà Tí Ń Ṣe Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa Lọ́ṣọ̀ọ́: Pọ́ọ̀lù fún Títù níṣìírí láti fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí “àpẹẹrẹ àwọn iṣẹ́ àtàtà.” Nípa fífi àìdíbàjẹ́ hàn nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀, Títù yóò ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti “ṣe ẹ̀kọ́ Olùgbàlà wa, Ọlọ́run, ní ọ̀ṣọ́ nínú ohun gbogbo.” (Títù 2:7, 10) Lọ́dọọdún, a máa ń gba ìránnilétí onínúure nípa ìdí tí ìṣe oníwà-bí-Ọlọ́run fi ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀ nígbà tí a bá ń rìnrìn àjò lọ sí àpéjọpọ̀, tí a sì ń darí bọ̀, àti nígbà tí a bá wà ní àwọn ibi tí a fi wá wọ̀ sí, àti ní ilẹ̀ àpéjọpọ̀ náà gan-an. Ní èṣí, a tún rí àwọn ọ̀rọ̀ tí ń mọ́kàn yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà, tí a óò fẹ́ láti ṣàjọpín pẹ̀lú yín.
12 Onílé kan sọ pé: “Ó máa ń dùn mọ́ mi nínú nígbà gbogbo láti gba àwọn Ẹlẹ́rìí sílé, nítorí pé wọ́n ní sùúrù, wọ́n ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀, wọ́n sì máa ń bójú tó àwọn ọmọ wọn dáradára.” Akọ̀wé hòtẹ́ẹ̀lì kan sọ pé, iṣẹ́ òún máa “ń rọrùn gan-an nígbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí bá ń dé sí tàbí jáde ní hòtẹ́ẹ̀lì náà, nítorí, bí wọ́n tilẹ̀ ní láti tò sórí ìlà, wọ́n máa ń hùwà bí ọmọlúwàbí, wọ́n máa ń mú sùúrù, wọ́n sì máa ń gba tẹni rò.” Ìwà àwọn èwe Ẹlẹ́rìí tí wọ́n wọ̀ sí ibì kan náà pẹ̀lú obìnrin kan wú u lórí tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi béèrè fún àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ díẹ̀ nípa ètò àjọ wa.
13 Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, a ṣì nílò láti ṣe àtúnṣe ní àwọn àgbègbè kan. A óò fẹ́ láti ṣàjọpín díẹ̀ lára àwọn àkíyèsí tí a ti fi ránṣẹ́ sí Society pẹ̀lú yín. Alábòójútó arìnrìn àjò kan sọ pé àwọn ọmọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣì nílò àbójútó púpọ̀ sí i. A ti rí àwọn kan tí wọ́n ń sáré kiri, tí wọ́n sì ń pariwo gèè, ní àwọn ibi tí a fi wọ́n wọ̀ sí, tí wọ́n sì ń tipa báyìí dí àwọn àlejò míràn lọ́wọ́. Ó yẹ kí a kọ́ àwọn ọmọ wa láti lóye pé ìwà Kristẹni kì í ṣe fún àkókò kan. Kò dópin nígbà tí a bá fi ilẹ̀ àpéjọpọ̀ sílẹ̀. Ó gbọ́dọ̀ wà jálẹ̀ gbogbo wákàtí ọjọ́. Ìwà wa ní àwọn ibi tí a fi wá wọ̀ sí, àti ní ojú pópó, gbọ́dọ̀ lọ́lá, gan-an gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí a bá wà lórí ìjókòó pẹ̀lú àwọn ará wa, nígbà tí ọ̀rọ̀ ń lọ lọ́wọ́, tí Jèhófà ń kọ́ wa.—Aisa. 54:13; 1 Pet. 2:12.
14 Kíkọ́ àti bíbójú tó àwọn Ilẹ̀ Àpéjọ, àti bíbójú tó onírúurú ọ̀ràn míràn, ń náni lówó ńlá. Ọrẹ àtinúwá wa ń kájú àwọn ìnáwó wọ̀nyí. Arábìnrin kan tí ó ní àwọn ọmọ ọ̀dọ́langba mú owó tí kò tó nǹkan wá sí àpéjọpọ̀. Ṣùgbọ́n, òun àti àwọn ọmọ náà ṣì fi ọrẹ kékeré ṣèrànwọ́. Ohun tí olúkúlùkù pinnu láti ṣe nínú ọ̀ràn yìí jẹ́ ọ̀ràn ara ẹni, ṣùgbọ́n a mọ̀ pé ẹ mọrírì irú ìránnilétí bẹ́ẹ̀.—Ìṣe 20:35; 2 Kọr. 9:7.
15 A Ń Mọ̀ Wá Nípa Ọ̀nà Tí A Gbà Ń Wọṣọ: Ọ̀nà tí a gbà ń wọṣọ ń sọ púpọ̀ nípa wa àti nípa ìmọ̀lára wa nípa àwọn ẹlòmíràn. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọ̀dọ́langba àti ọ̀pọ̀ àwọn àgbàlagbà ni ó jẹ́ pé àwọn àṣà ìwọṣọ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé, tí ó rí wúruwùru, ni ó yí wọn ká ní ilé ẹ̀kọ́ tàbí níbi iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wọn. Lọ́dọọdún, àwọn àṣà ìwọṣọ túbọ̀ ń di àṣerégèé, tí ó sì ń tini lójú pàápàá. Bí a kò bá ṣọ́ra, àwọn ojúgbà wa nínú ayé lè nípa lórí wa láti wọṣọ bí wọ́n ṣe ń wọṣọ. Ọ̀pọ̀ àṣà aṣọ ni kò bójú mu láti wọ̀ ní àwọn ìpàdé tí a ti ń jọ́sìn. Ìwé kúkurú kan tí a rí gbà lẹ́yìn ọ̀kan lára àwọn àpéjọpọ̀ tí a ṣe léṣìí, fi ìmọrírì hàn fún ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà, ṣùgbọ́n, ó fi kún un pé: “Mo ṣe kàyéfì nípa ìdí tí ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́mọbìnrin fí wọ àwọn aṣọ péńpé, àwọn aṣọ tí kò bo àyà, àti àwọn tí a là dókè jù.” Ó dájú pé gbogbo wa ní ń fẹ́ láti wọṣọ lọ́nà tí ó yẹ àwọn Kristẹni òjíṣẹ́, ní àpéjọpọ̀ àti nígbà tí a bá ń gba fàájì lẹ́yìn ìtòlẹ́sẹẹsẹ. Ní gbogbo ìgbà, ó dára kí á máa ronú lórí ìmọ̀ràn àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún àwọn Kristẹni, láti “fi aṣọ tí ó wà létòletò ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́, pẹ̀lú ìmẹ̀tọ́mọ̀wà àti ìyèkooro èrò inú.”—1 Tim. 2:9.
16 Ta ni yóò pinnu aṣọ ìwọ̀ntúnwọ̀nsì, “tí ó wà létòletò?” Jíjẹ́ oníwọ̀ntúnwọ̀nsì túmọ̀ sí “ẹni tí kì í ṣe aṣa tàbí ògbójúgbóyà.” Ìwé atúmọ̀ èdè tún túmọ̀ ìwọ̀ntúnwọ̀nsì sí “àìdíbọ́n.” Society àti àwọn alàgbà kọ́ ni yóò gbé òfin kalẹ̀ nípa ìwọṣọ tàbí ìmúra. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, kò ha yẹ kí irú àṣà aṣọ tí kò wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì tàbí bójú mu ṣe kedere sí Kristẹni bí? (Fi wé Fílípì 1:10.) Ìmúra àti ìwọṣọ wa kò gbọdọ̀ fa àfiyèsí tí kò yẹ mọ́ra. Ó yẹ kí ìrísí wa tẹ́ni lọ́rùn, kí ó má jẹ́ ti ayé tàbí èyí tí ń múni bínú. Gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ ìhìn rere, wíwọṣọ àti mímúra lọ́nà tí ó bójú mu, ní àwọn àkókò tí a bá wà ní ilẹ̀ àpéjọpọ̀ àgbègbè, ń bọlá fún Jèhófà, ó sì ń fi ètò àjọ náà hàn lọ́nà rere. Nítorí náà, àwọn òbí yóò fi àpẹẹrẹ lélẹ̀, lẹ́yìn náà, wọn yóò sì rí i dájú pé àwọn ọmọ wọ́n wọṣọ tí ó bójú mu fún àkókò náà. Àwọn alàgbà yóò fẹ́ láti fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀, kí wọ́n sì múra tán láti fúnni nímọ̀ràn onínúure, bí ó bá pọn dandan.
17 Kámẹ́rà àti Àwọn Ohun Tí Ń Gba Ohùn Tàbí Àwòrán Sílẹ̀: A kò lòdì sí lílo kámẹ́rà àti àwọn ohun èèlò míràn tí ń gba ohùn tàbí àwòrán sílẹ̀, níwọ̀n bí a bá ti gba ti àwọn mìíràn tí ó wà níjokòó rò. Bí a bá ń yàwòrán kiri nígbà tí ọ̀rọ̀ ń lọ lọ́wọ́, kì í ṣe pé a óò pín ọkàn àwọn ẹlòmíràn, tí wọ́n ń gbìyànjú láti fetí sílẹ̀, níyà nìkan ni, ṣùgbọ́n, àwa fúnra wa yóò pàdánù díẹ̀ lára ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà. A sábà máa ń jàǹfààní púpọ̀ sí i láti inú àpéjọpọ̀, nípa fífetí sílẹ̀ dáradára sí àwọn olùbánisọ̀rọ̀pọ̀ àti ṣíṣe àkọsílẹ̀ mímọ níwọ̀n. A lè máa gba ohùn tàbí àwòrán sílẹ̀ fún arákùnrin tàbí arábìnrin kan tí àìsàn há mọ́lé; ṣùgbọ́n, fún lílò ara wa, a lè rí i pé lẹ́yìn tí a ti padà sílé, a kò rí àyè láti gbọ́ ọ̀pọ̀ ohun tí a ti gbà sílẹ̀, lẹ́yìn lílo ọ̀pọ̀ wákàtí láti gba ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà sílẹ̀. A kò gbọdọ̀ so ohun èlò èyíkéyìí tí a fi ń gba ohùn tàbí àwòrán sílẹ̀ mọ́ iná tàbí mọ́ ẹ̀rọ tí a fi ń bá gbogbo àwùjọ sọ̀rọ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni a kò gbọdọ̀ fi ohun èlò dí àwọn ọ̀nà àbákọjá tí ó wà láàárín ìjókòó, àwọn ọ̀nà àrìnlọrìnbọ̀, tàbí fi dí àwọn ẹlòmíràn lójú.
18 Àyè Ìjókòó: A ń bá a lọ láti ṣe dáradára sí i ní ti ọ̀ràn gbígba àyè sílẹ̀. Ní èṣí, ọ̀pọ̀ jù lọ lára yín tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà náà: O LÈ GBA ÀYÈ SÍLẸ̀ FÚN KÌKÌ MẸ́ḾBÀ ÌDÍLÉ RẸ ÀTI ẸNIKẸ́NI TÍ Ó BÁ Ọ WÁ NÍNÚ ỌKỌ̀ AYỌ́KẸ́LẸ́ RẸ. Ó ṣeé ṣe kí o ri pé kò fi bẹ́ẹ̀ sí wàhálà nítorí pé ọ̀pọ̀ ń tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tí ó ṣe kedere wọ̀nyí. Lọ́nà tí ó túbọ̀ ṣe pàtàkì jù lọ, ìfọwọ́sowọ́pọ̀ rẹ dùn mọ́ Jèhófà àti ‘ẹrú olùṣòtítọ́,’ tí ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí, nínú.—Mat. 24:45.
19 Tíkẹ́ẹ̀tì Oúnjẹ: A rọ̀ wá láti ra tíkẹ́ẹ̀tì oúnjẹ ṣáájú àpéjọpọ̀ náà. Kí ni ète èyí? Títa tíkẹ́ẹ̀tì oúnjẹ ṣáájú àkókò ń pèsè owó fún àpéjọpọ̀ náà fún ríra àwọn oúnjẹ tí ó ṣe kókó sílẹ̀. A ní láti ra ìrẹsì, iṣu, gaàrí, màlúù, adìyẹ, ẹ̀wà, ẹ̀fọ́, àti àwọn oúnjẹ mìíràn sílẹ̀, láti baà lè ní wọn lọ́wọ́ fún ọ̀wọ́ àwọn àpéjọpọ̀ àgbègbè náà. Bí ó ti sábà máa ń jẹ́, owó oúnjẹ máa ń ga sókè gan-an bí àkókò ọlidé ti ń sún mọ́lé ní December. Alábòójútó ìpèsè oúnjẹ fún àwọn àpéjọpọ̀ ní láti ra oúnjẹ ní àràpọ̀ ṣáájú àkókò, ó sì nílò owó láti ṣe èyí. Society ń ní ìṣòro fífi owó tí ó pọ̀ tó sílẹ̀ láti fi ṣe èyí, nítorí ọ̀pọ̀ àpéjọpọ̀ tí a ń ṣe nísinsìnyí ní orílẹ̀-èdè yìí. Ìdí nìyẹn tí a fi fún yín níṣìírí láti ra tíkẹ́ẹ̀tì oúnjẹ sílẹ̀ lọ́dọ̀ Ìgbìmọ̀ Àpéjọpọ̀. A óò wá lo owó náà láti fi ra oúnjẹ sílẹ̀. Ẹ óò jàǹfààní ríra oúnjẹ tí kò wọ́n, ní kafitéríà àti àwọn ilé ìpápánu ní àwọn àpéjọpọ̀, níwọ̀n bí a ti lè ra oúnjẹ nígbà tí wọn kò fi bẹ́ẹ̀ wọ́nwó.
20 Nítorí náà, a rọ alábòójútó olùṣalága àti akọ̀wé ìjọ kọ̀ọ̀kan láti ṣètò fún ríra tíkẹ́ẹ̀tì oúnjẹ sílẹ̀. Olùṣekòkáárí àpéjọpọ̀ nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan lè báni ṣe èyí. Àwọn akéde lè fi owó sílẹ̀ fún àwọn tíkẹ́ẹ̀tì, gbàrà tí a bá ti jíròrò ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yìí ní September. A gbọ́dọ̀ pa àkọsílẹ̀ mọ́. Nígbà tí a bá ra àwọn tíkẹ́ẹ̀tì náà lọ́dọ̀ Ìgbìmọ̀ Àpéjọpọ̀, a óò fi wọ́n fún àwọn akéde tí ó sanwó fún wọn. Àwọn akéde ní láti pa wọ́n mọ́ bí owó, kí wọ́n sì tọ́jú wọn dáradára. Àwọn akéde lè lo àwọn tíkẹ́ẹ̀tì oúnjẹ náà ní kafitéríà àti àwọn ilé ìpápánu, gbàrà tí wọ́n bá ti dé sí àpéjọpọ̀. A rọ gbogbo akéde láti ra tíkẹ́ẹ̀tì oúnjẹ sílẹ̀, ó kéré tán, fún ọjọ́ méjì àkọ́kọ́ àpéjọpọ̀ náà. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò mú un rọrùn láti ra oúnjẹ ní àràpọ̀ ṣáájú kí àwọn àpéjọpọ̀ tó bẹ̀rẹ̀.
21 Ṣíṣe Ìtọrẹ Oúnjẹ: A rọ̀ wá láti fi àwọn oúnjẹ tọrẹ fún àwọn àpéjọpọ̀ àgbègbè. Èyí lè ní oríṣiríṣi oúnjẹ tí a ń jẹ nínú, bí iṣu, ìrẹsì, gaàrí, ọ̀gẹ̀dẹ̀ àgbagbà, ẹ̀wà, ata, tòmátì, èso, ẹ̀fọ́, màlúù, adìyẹ, àti oúnjẹ mìíràn tí a lè fẹ́ láti fi tọrẹ. Ọ̀nà dídára nìyí láti ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ Ìjọba náà. Gbogbo oúnjẹ wọ̀nyí ni Ẹ̀ka Ìpèsè Oúnjẹ ń lò. Fífi tí o fi irú àwọn oúnjẹ bẹ́ẹ̀ tọrẹ yóò ran àpéjọpọ̀ náà lọ́wọ́ láti kájú ìnáwó rẹ̀ àti láti pèsè oúnjẹ ọ̀fẹ́ fún àwọn tí wọ́n wà nínú iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà.
22 A ní láti ṣètò nínú ìjọ fún fífi irú àwọn oúnjẹ bẹ́ẹ̀ tọrẹ àti gbígbé wọn lọ sí Ilẹ̀ Àpéjọpọ̀, gbàrà tí a bá ti jíròrò ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yìí. Àmọ́ ṣáá o, a ní láti gbé àwọn oúnjẹ tí ó lè bà jẹ́ lọ lákòókò tí ó yẹ, kí wọ́n má baà bà jẹ́ ṣáájú àpéjọpọ̀ àkọ́kọ́. Bí Ìgbìmọ̀ Àpéjọpọ̀ kò bá tí ì fún yín ní ìtọ́ni pàtó lórí ìgbà tí ó yẹ kí ẹ gbé àwọn oúnjẹ náà wá, ẹ lè kàn sí wọn. Àwọn akéde lè gbé oúnjẹ èyíkéyìí tí wọ́n bá gbé wá, nígbà tí wọ́n bá ń bọ̀ wá sí àpéjọpọ̀ náà, lọ ní tààràtà sí ilé ìkóúnjẹsí.
23 A tún fẹ́ láti fún yín níṣìírí láti máa bá a lọ láti ṣètìlẹ́yìn fún ìṣèto gbígbọ́ oúnjẹ ní àpéjọpọ̀. Àṣà náà ti jẹ́ láti ké sí àwọn ìjọ tí àpéjọpọ̀ yẹn kì í ṣe tiwọn, láti gbọ́ oúnjẹ. Nígbà tí a bá ké sí ìjọ yín fún ìṣètò yìí, gbogbo akéde nínú ìjọ ní láti sakun láti ṣètìlẹ́yìn lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́.
24 Ní àfikún sí ìpèsè jíjẹun ní kafitéríà àti ilé ìpápánu, bí àwọn akéde bá fẹ́ láti jẹ oúnjẹ tí wọ́n gbé wá láti ilé nínú gbọ̀ngàn àpéjọ, ní àkókò ìjẹun, a yọ̀ọ̀da fún wọn láti ṣe bẹ́ẹ̀. Pẹ̀lúpẹ̀lù, bí àwọn kan bá fẹ́ láti ra oúnjẹ láti kafitéríà tàbí láti ilé ìpápánu, kí wọ́n sì gbé oúnjẹ náà sínú abọ́ ti ara wọn láti jẹ nínú gbọ̀ngàn àpéjọ, a lè yọ̀ọ̀da fún ìyẹn. Ohun tí ó ṣe pàtàkì ni pé, kí olúkúlùkù palẹ̀ mọ́ lẹ́yìn oúnjẹ. Ìṣètò àpéjọpọ̀ yóò pèsè apẹ̀rẹ̀ ìdọ̀tí tí ó pọ̀ tó fún àwọn akéde láti da pàǹtí sí, a óò sì pèsè àwọn ohun èlò ìmọ́tótó tí ó pọ̀ tó. Bí ó bá pọn dandan fún ọ láti gbé àwọn kúlà kékeré wá, a gbà ọ́ láyè láti ṣe bẹ́ẹ̀ bí wọn yóò bá wọlé sábẹ́ ìjókòó rẹ. Ṣùgbọ́n, a kò gbọdọ̀ gbé àwọn kúlà gbẹ̀ǹgbẹ̀gbẹ̀ǹgbẹ̀, irú èyí tí a ń gbé lọ sí àjò ìgbafẹ́, tàbí mú ọtí wá sínú gbọ̀ngàn àpéjọ. A gbọ́dọ̀ yẹra fún jíjẹ oúnjẹ tàbí ìpápánu nígbà tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ń lọ lọ́wọ́. Èyí yóò jẹ́ àìfọ̀wọ̀ hàn fún oúnjẹ tẹ̀mí tí a ń pèsè.
25 Láìpẹ́, àkọ́kọ́ nínú àwọn Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Ońṣẹ́ Àlàáfíà Ọlọ́run” yóò bẹ̀rẹ̀. O ha ti parí àwọn ìmúrasílẹ̀ rẹ láti lọ, o ha sì ti ṣe tán láti gbádùn ọjọ́ mẹ́ta ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ aláyọ̀ àti àwọn ohun rere nípa tẹ̀mí bí? Àdúrà àtọkànwá wa ni pé, kí Jèhófà bù kún àwọn ìsapá rẹ láti lọ sí àpéjọpọ̀ ọdún yìí.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]
Àwọn Ìránnilétí Àpéjọpọ̀ Àgbègbè
Ìbatisí: Àwọn tí yóò ṣe batisí ní láti wà lórí ìjókòó wọn ní apá tí a yà sọ́tọ̀ fún wọn, ṣáájú kí ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó bẹ̀rẹ̀ ní òwúrọ̀ Saturday. A ti kíyè sí i pé àwọn kan ń wọ àwọn aṣọ kan tí kò buyì kúnni, tí ó sì ń tàbùkù sí àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Olúkúlùkù ẹni tí ó wéwèé láti ṣe batisí ní láti mú aṣọ ìwẹ̀ tí ó bójú mu àti aṣọ ìnura wá. Àwọn alàgbà ìjọ tí ń ṣàtúnyẹ̀wò àwọn ìbéèrè láti inú ìwé Iṣetojọ pẹ̀lú àwọn tí wọ́n fẹ́ ṣe batisí, yóò fẹ́ láti rí i dájú pé ẹnì kọ̀ọ̀kan wọ́n lóye àwọn kókó wọ̀nyí dáradára. Lẹ́yìn ọ̀rọ̀ ìbatisí, tí olùbánisọ̀rọ̀ sì ti gbàdúrà, alága ìjókòó yóò pèsè ìtọ́ni ráńpẹ́ fún àwọn tí ó fẹ́ ṣe batisí, lẹ́yìn náà, yóò sì pe orin. Lẹ́yìn ìlà tí ó kẹ́yìn, àwọn olùṣàbójútó èrò yóò darí àwọn tí ó fẹ́ ṣe batisí lọ sí odò ìrìbọmi. Níwọ̀n bí ìbatisí ní ìṣàpẹẹrẹ ìyàsímímọ́ ẹnì kan ti jẹ́ ọ̀ràn kan tí ó kanni gbọ̀ngbọ̀n, tí ó sì jẹ́ ti ara ẹni, láàárín ẹni náà àti Jèhófà, kò sí àyè fún ohun tí a pè ní ìbatisí alájùmọ̀ṣe, nínú èyí tí àwọn ẹni méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tí ó fẹ́ ṣe batisí ti wà mọ́ ara wọn tàbí di ọwọ́ ara wọn mú nígbà tí a ń batisí wọn. Jọ̀wọ́ kíyè sí i pé Ìwé Mímọ́ kò sọ pé kí àwọn arábìnrin bo orí wọn tàbí kí wọ́n má bo orí wọn nígbà tí a bá ń batisí wọn. Yíyàn méjèèjì ṣètẹ́wọ́gbà.
Ilé Gbígbé: A tún ń béèrè fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ gbogbogbòò ní ti ilé ibùwọ̀ tí àpéjọpọ̀ pèsè. Bí a bá ré ìṣètò Society kọjá, tí a sì gba ilé ibùwọ̀ tí àpéjọpọ̀ ti gbà tẹ́lẹ̀, a ń jin iṣẹ́ àṣekára àwọn arákùnrin wa, tí wọ́n dúnàádúrà fún iye owó tí ó tẹ́ni lọ́rùn jù, lẹ́sẹ̀. BÍ O BÁ NÍ ÌṢÒRO LÓRÍ ILÉ IBÙWỌ̀, jọ̀wọ́, má ṣe lọ́ tìkọ̀ láti mú un wá sí àfiyèsí alábòójútó Ẹ̀ka Ilé Gbígbé ní àpéjọpọ̀ náà, kí ó baà lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti yanjú ọ̀ràn náà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Akọ̀wé ìjọ ní láti rí i dájú pé àwọn fọ́ọ̀mù Special Needs Room Request ni a tètè fi ṣọwọ́ sí àdírẹ́sì àpéjọpọ̀ tí ó yẹ. Bí o bá ní láti fagi lé wíwọ̀ sí ilé ibùwọ̀ kan tí a ṣètò nípasẹ̀ ètò fún àwọn àìní àkànṣe, o ní láti fi tó onílé náà àti Ẹ̀ka Ilé Gbígbé àpéjọpọ̀ náà létí lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, kí a baà lè yan iyàrá náà fún ẹlòmíràn.
Káàdì Àyà: Jọ̀wọ́, fi káàdì àyà ti 1996 sí àyà ní àpéjọpọ̀ náà àti nígbà tí o bá ń rìnrìn àjò lọ sí ilẹ̀ àpéjọpọ̀ náà àti nígbà tí o bá ń darí bọ̀. Èyí sábà máa ń mú kí ó ṣeé ṣe fún wa láti jẹ́rìí lọ́nà rere nígbà tí a bá ń rìnrìn àjò. O ní láti gba káàdì àyà àti ike rẹ̀ nípasẹ̀ ìjọ rẹ, níwọ̀n bí wọn kì yóò ti wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní àpéjọpọ̀ náà. Má ṣe dúró títí di àwọn ọjọ́ díẹ̀ ṣáájú àpéjọpọ̀ kí o tó béèrè fún káàdì rẹ àti tí ìdílé rẹ. Rántí láti mú káàdì Advance Medical Directive/Release rẹ ti lọ́ọ́lọ́ọ́ dání.
Iṣẹ́ Ìsìn Ìyọ̀ǹda Ara Ẹni: Ìwọ ha lè ya àkókò díẹ̀ sọ́tọ̀ ní àpéjọpọ̀ náà láti ṣètìlẹ́yìn nínú ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ka iṣẹ́ bí? Ṣíṣiṣẹ́ sin àwọn ará wa, bí ó bá tilẹ̀ jẹ́ fún kìkì wákàtí díẹ̀, lè ṣèrànwọ́, kí ó sì mú ìtẹ́lọ́rùn púpọ̀ wá. Bí o bá lè ṣètìlẹ́yìn, jọ̀wọ́, fara hàn ní Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn Ìyọ̀ǹda Ara Ẹni ní àpéjọpọ̀ náà. Àwọn ọmọ tí kò tí ì pé ọmọ ọdún 16 pẹ̀lú lè ṣe ìtìlẹ́yìn dáradára nípa ṣíṣiṣẹ́ lábẹ́ ìdarí òbí kan tàbí àgbàlagbà kan tí ó ṣeé fi ẹrù iṣẹ́ lé lọ́wọ́.
Ìkìlọ̀: Wà lójúfò sí àwọn ìṣòro tí ó lè yọjú, kí o baà lè yẹra fún ìṣòro tí kò pọn dandan. Àwọn olè àti ènìyànkénìyàn sábà máa ń dọdẹ àwọn ènìyàn tí wọ́n jìnnà sí ilé. Rí i dájú pé o ti ọkọ̀ rẹ pa nígbà gbogbo, má sì ṣe fi ohunkóhun tí ojú lè tó sílẹ̀ láti dán ẹnì kan wò láti jalè. Àwọn olè àti àwọn jáwójáwó máa ń fojú sun àwọn ìkórajọpọ̀ ńlá. Kò ní bọ́gbọ́n mu láti fi ohunkóhun tí ó ṣe iyebíye sílẹ̀ lórí ìjókòó rẹ. Kò lè dá ọ lójú pé gbogbo ẹni tí ó wà ní àyíká rẹ ni ó jẹ́ Kristẹni. Èé ṣe tí ìwọ yóò fi dán ẹnikẹ́ni wò? A ti rí ìròyìn gbà nípa ìgbìdánwò àwọn ará ìta kan láti tan àwọn ọmọdé lọ. JẸ́ KÍ ÀWỌN ỌMỌ RẸ WÀ LỌ́DỌ̀ RẸ NÍGBÀ GBOGBO.