Ǹjẹ́ Ò Ń ‘Nàgà fún Iṣẹ́ Àtàtà’?
ỌKÀN Fernandoa ò balẹ̀, nígbà táwọn alàgbà méjì ní àwọn fẹ́ rí i lóun nìkan. Lẹ́yìn ìgbà mélòó kan tí alábòójútó àyíká bẹ ìjọ wọn wò, àwọn alàgbà ti sọ ohun tí Fernando máa ṣe kó lè tóótun fún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn púpọ̀ sí i nínú ìjọ. Àmọ́, bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, Fernando bẹ̀rẹ̀ sí í rò ó pé bóyá lòun á lè di alàgbà. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, alábòójútó àyíká tún bẹ ìjọ wọn wò. Kí làwọn alàgbà máa sọ lọ́tẹ̀ yìí?
Fernando tẹ́tí sílẹ̀ nígbà tí ọ̀kan lára àwọn alàgbà náà ń bá a sọ̀rọ̀. Arákùnrin náà tọ́ka sí 1 Tímótì 3:1, ó wá sọ fún un pé ètò Ọlọ́run ti fọwọ́ sí i pé kó o máa sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà. Ẹnu ya Fernando gan-an, ó sì béèrè pé, “Kí lẹ sọ yẹn ná?” Arákùnrin náà tún ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ, Fernando sì rẹ́rìn-ín músẹ́. Inú gbogbo àwọn ará dùn nígbà tí wọ́n ṣe ìfilọ̀ rẹ̀ fún ìjọ.
Ǹjẹ́ ó burú tó bá wu ẹnì kan kó láǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ? Kò sóhun tó burú níbẹ̀. Ìwé 1 Tímótì 3:1 sọ pé: “Bí ọkùnrin èyíkéyìí bá ń nàgà fún ipò iṣẹ́ alábòójútó, iṣẹ́ àtàtà ni ó ń fẹ́.” Ọ̀pọ̀ Kristẹni ọkùnrin ni wọ́n ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí, wọ́n ń sapá láti tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí kí wọ́n lè tóótun fún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ. Èyí ló mú kí àwọn èèyàn Ọlọ́run ní ẹgbẹẹ̀gbẹ̀rún àwọn ọkùnrin tí wọ́n kúnjú ìwọ̀n tí wọ́n ń sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. Àmọ́, torí pé ìjọ túbọ̀ ń pọ̀ sí i, a nílò ọ̀pọ̀ arákùnrin tí wọ́n máa fẹ́ láti sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà nínú ìjọ. Báwo ló ṣe yẹ kí arákùnrin kan fi hàn pé ó wu òun láti sìn nínú ìjọ? Ǹjẹ́ ó yẹ kí àwọn tó wù láti di alàgbà máa ṣàníyàn nípa rẹ̀ bíi ti Fernando?
KÍ LÓ TÚMỌ̀ SÍ LÁTI “NÀGÀ FÚN” IṢẸ́ ALÁBÒÓJÚTÓ?
Nígbà tí Bíbélì sọ pé “nàgà fún,” ọ̀rọ̀ náà tú ọ̀rọ̀ ìṣe kan lédè Gíríìkì, ohun tí ìyẹn sì túmọ̀ sí lédè Yorùbá ní nínú kí èèyàn fẹ́ nǹkan lójú méjèèjì, kéèyàn máa nawọ́ kọ́wọ́ rẹ̀ lè tó nǹkan kan. O lè fọkàn yàwòrán ẹnì kan tó ń nàgà, tó tiẹ̀ tún ń fò kó lè já èso kan tó ti pọ́n lórí igi. Àmọ́, nínàgà fún “iṣẹ́ alábòójútó” nínú ìjọ yàtọ̀ pátápátá sí èyí, kì í ṣe ohun tí èèyàn á máa fi ìwọra wá. Kí nìdí? Ìdí ni pé ohun tó yẹ kó mú kí ẹnì kan fẹ́ láti di alàgbà gbọ́dọ́ jẹ́ torí pé ó fẹ́ ṣe “iṣẹ́ àtàtà,” kò gbọ́dọ̀ jẹ́ torí pé ó fẹ́ du ipò.
Kí arákùnrin kan tó lè ṣe iṣẹ́ àtàtà yìí, ó gbọ́dọ̀ dójú ìlà àwọn ohun tí Bíbélì sọ nínú 1 Tímótì 3:2-7 àti Títù 1:5-9. Alàgbà kan tó ti ń sìn tipẹ́ torúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Raymond, sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìlànà gíga yìí, ó ní: “Ní tèmi o, ohun tó ṣe pàtàkì jù ni irú ẹni tí a jẹ́. Ó ṣe pàtàkì kéèyàn mọ̀rọ̀ọ́ sọ, kéèyàn sì lè kọ́ni, àmọ́ a ò lè fi rọ́pò àwọn ìwà bíi kéèyàn jẹ́ aláìlẹ́gàn, oníwọ̀ntúnwọ̀nsì nínú ìwà, ẹni tí ó yè kooro ní èrò inú, tí ó wà létòletò, tí ó ní ẹ̀mí aájò àlejò, tí ó sì jẹ́ afòyebánilò.”
Arákùnrin tó bá wù lóòótọ́ láti di alàgbà gbọ́dọ̀ máa fi hàn pé òun jẹ́ aláìlẹ́gàn nípa yíyẹra fún ohunkóhun tó bá jẹ mọ́ ìwà àìṣòótọ́ àti ìwà àìmọ́. Ó gbọ́dọ̀ jẹ́ oníwọ̀ntúnwọ̀nsì nínú ìwà, ẹni tí ó yè kooro ní èrò inú, ó gbọ́dọ̀ wà létòletò, kí ó sì jẹ́ afòyebánilò. Tí ó bá ṣe èyí, àwọn tí wọ́n jọ ń sin Jèhófà máa fọkàn tán an, wọ́n á rí i pé ó lè mú ipò iwájú nínú ìjọ àti ẹni tí wọ́n lè lọ bá tí wọ́n bá ní ìṣòro. Tí arákùnrin náà bá ní ẹ̀mí aájò àlejò, orísun ìṣírí ló máa jẹ́ fún àwọn ọ̀dọ́ nínú ìjọ àti fún àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi. Torí pé ó nífẹ̀ẹ́ ohun rere, ó máa ń tu àwọn tó ń ṣàìsàn àti àwọn àgbàlagbà nínú. Ó máa sapá láti ní àwọn ìwà yìí kó lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, kì í ṣe torí kí wọ́n lè yàn án sí ipò alàgbà.b
Ìgbìmọ̀ alàgbà ṣe tán láti fúnni ní ìmọ̀ràn àti ìṣírí, àmọ́ ọwọ́ ẹni tó ń nàgà fún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ ló kù sí láti dójú ìlà ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ. Arákùnrin Henry tó ti ń sìn tipẹ́ gẹ́gẹ́ bí alàgbà sọ pé: “Tó o bá ń nàgà fún àǹfààní èyíkéyìí nínú ìjọ, sapá gan-an kó o lè fi hàn pé òótọ́ lo kúnjú ìwọ̀n.” Ó mẹ́nu kan ìwé Oníwàásù 9:10, ó sì sọ pé: “‘Gbogbo ohun tí ọwọ́ rẹ bá rí láti ṣe, fi agbára rẹ ṣe é.’ Sapá láti ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí tí àwọn alàgbà bá yàn fún ẹ dáadáa. Fọwọ́ pàtàkì mú gbogbo iṣẹ́ tí wọ́n bá sọ pé kó o ṣe nínú ìjọ, tó fi mọ́ ilẹ̀ gbígbá. Tó bá yá, ó máa ṣe kedere pé ò ń gbìyànjú gan-an.” Tó bá wù ẹ́ pé kó o di alàgbà lọ́jọ́ kan, máa ṣiṣẹ́ kára kó o sì jẹ́ ẹni tó ṣeé fọkàn tán nínú gbogbo iṣẹ́ ìsìn mímọ́ tó ò ń ṣe. O gbọ́dọ̀ ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, má ṣe ní ẹ̀mí ìgbéraga.—Mát. 23:8-12.
MÁ ṢE FÀYÈ GBA ÈRÒ ÒDÌ ÀTI ÌWÀ Ẹ̀TÀN
Àwọn míì tó ń wù láti ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ lè máa dọ́gbọ́n sọ ọ́ jáde pé ó wu àwọn láti di alàgbà tàbí kí wọ́n máa dọ́gbọ́n ṣe àwọn nǹkan kan kí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà lè pe àfiyèsí sí wọn. Inú àwọn míì kì í sì í dùn táwọn alàgbà bá fún wọn nímọ̀ràn. Ńṣe ló yẹ káwọn tó bá ń hu irú ìwà yìí bi ara wọn pé, ‘Ṣé ire ara mi ni mò ń wá, àbí mo fẹ́ máa fi ìrẹ̀lẹ̀ bójú tó àwọn àgùntàn Jèhófà?’
Àwọn tó ń wù láti di alàgbà nínú ìjọ tún gbọ́dọ̀ “di àpẹẹrẹ fún agbo.” (1 Pét. 5:1-3) Ẹni tó fẹ́ di àpẹẹrẹ fún ìjọ kò gbọ́dọ̀ jẹ́ oníbékebèke nínú èrò àti nínú ìwà. Ó ní láti máa fi sùúrù fara dà á yálà wọ́n yàn án tàbí wọn kò tíì yàn án. Ti pé ẹnì kan di alàgbà kò sọ pé ó ti di ẹni pípé. (Núm. 12:3; Sm. 106:32, 33) Yàtọ̀ síyẹn, arákùnrin kan lè máà ní ‘ohunkóhun lòdì sí ara rẹ̀,’ àmọ́ àwọn míì lè ní ohun kan lòdì sí i fún àwọn ìdí kan. (1 Kọ́r. 4:4) Torí náà, tí àwọn alàgbà bá fún ẹ nímọ̀ràn onífẹ̀ẹ́ tí wọ́n gbé ka Bíbélì, fara balẹ̀ tẹ́tí sí ohun tí wọ́n ń sọ, má ṣe jẹ́ kínú bí ẹ, kó o sì fi ìmọ̀ràn tí wọ́n bá fún ẹ sílò.
TÍ OHUN TÓ O FẸ́ Ò BÁ TÈTÈ DÉ ŃKỌ́?
Lójú àwọn arákùnrin kan, wọ́n gbà pé àwọn dúró pẹ́ gan-an káwọn tó di alàgbà. Tó bá tó bí ọdún mélòó kan tí o ti ń “nàgà fún ipò iṣẹ́ alábòójútó,” ǹjẹ́ o máa ń ṣàníyàn nípa ẹ̀ nígbà míì? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, fiyè sí ohun tí Bíbélì sọ, ó ní: “Ìfojúsọ́nà tí a sún síwájú ń mú ọkàn-àyà ṣàìsàn, ṣùgbọ́n igi ìyè ni ohun tí a fọkàn fẹ́ nígbà tí ó bá dé ní ti tòótọ́.”—Òwe 13:12.
Tí ohun téèyàn ń fojú sùn ò bá tètè tẹni lọ́wọ́, ó lè mú kéèyàn ba ọkàn jẹ́. Bó ṣe rí lára Ábúráhámù náà nìyẹn. Jèhófà ṣèlérí fún un pé ó máa bí ọmọkùnrin, àmọ́ ọ̀pọ̀ ọdún kọjá tí òun àti Sárà kò bímọ. (Jẹ́n. 12:1-3, 7) Nígbà tí Ábúráhámù rí i pé òun ti ń darúgbó, ó ké jáde pé: “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, kí ni ìwọ yóò fi fún mi, bí èmi ti ń bá a lọ láìbímọ . . . Ìwọ kò tíì fi irú-ọmọ kankan fún mi.” Jèhófà fi Ábúráhámù lọ́kàn balẹ̀ pé ìlérí tí òun ṣe fún un pé ó máa bí ọmọkùnrin yóò ní ìmúṣẹ. Àmọ́, ó kéré tán ọdún mẹ́rìnlá ṣì kọjá lẹ́yìn ìyẹn kí Ọlọ́run tó mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ.—Jẹ́n. 15:2-4; 16:16; 21:5.
Ní gbogbo ìgbà tí Ábúráhámù fi ń dúró yìí, ǹjẹ́ ó pàdánù ayọ̀ tó ń ní lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà? Rárá o. Kò ṣiyè méjì rárá pé ìlérí Ọlọ́run máa ṣẹ. Ó ń bá a nìṣó láti fojú sọ́nà fún ìgbà tí ìlérí náà máa ṣẹ. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Lẹ́yìn tí Ábúráhámù ti fi sùúrù hàn, ó rí ìlérí yìí gbà.” (Héb. 6:15) Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, Ọlọ́run Olódùmarè bù kún ọkùnrin olóòótọ́ yìí ju bí ó ti rò lọ. Kí lo kọ́ lára Ábúráhámù?
Tó bá wù ẹ́ láti di alàgbà àmọ́ tí àfojúsùn yìí ò tíì tẹ̀ ọ́ lọ́wọ́, máa báa nìṣó láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Má ṣe pàdánù ayọ̀ rẹ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Alàgbà kan tó ń jẹ́ Warren, tó ti ran ọ̀pọ̀ arákùnrin lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí sọ pé: “Ó máa ń gba ọ̀pọ̀ àkókò kó tó hàn pé arákùnrin kan ti kúnjú ìwọ̀n láti di alàgbà. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, àwọn ohun tí arákùnrin kan mọ̀ ọ́n ṣe àti ìwà rẹ̀ á bẹ̀rẹ̀ sí í hàn díẹ̀díẹ̀ nínú bó ṣe ń ṣe nǹkan àti ọwọ́ tó fi mú iṣẹ́ tí wọ́n fún un. Àwọn míì rò pé ìgbà tọ́wọ́ àwọn bá tẹ àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tí wọ́n fojú sùn nìkan làwọn tó lè sọ pé àwọn ṣe àṣeyọrí nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Irú èrò yìí ò tọ̀nà, ó sì lè gbani lọ́kàn ju bó ti yẹ lọ. Tó o bá ń sin Jèhófà tọkàntọkàn níbikíbi tó o bá wà, tó o sì ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe, o ti ṣàṣeyọrí nìyẹn.”
Arákùnrin kan ti dúró fún ohun tó lé ní ọdún mẹ́wàá kó tó di alàgbà. Ó mẹ́nu kan àpèjúwe kan tí a mọ̀ dáadáa ní orí kìíní ìwé Ìsíkíẹ́lì, ó sọ ohun tó kọ́ nínú orí Bíbélì yìí, ó ní: “Jèhófà ń darí kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀, ìyẹn ètò rẹ̀ bí ó ṣe fẹ́ kó sáré tó. Ohun tó ṣe pàtàkì jù ni ìgbà tí Jèhófà bá rí i pé a kúnjú ìwọ̀n, kì í ṣe ìgbà tí a rò pé a kúnjú ìwọ̀n lójú ara wa. Ní ti kéèyàn di alàgbà, kì í ṣe ohun tí mo fẹ́ tàbí ohun tó wù mí láti dà ló ṣe pàtàkì jù. Ó lè jẹ́ pé ohun tí mo fẹ́ kọ́ ni Jèhófà fẹ́.”
Tó bá wù ẹ́ láti ṣe iṣẹ́ àtàtà, ìyẹn láti sìn bí alàgbà lọ́jọ́ kan, ńṣe ni kó o máa ṣe ohun tó máa fi kún ayọ̀ ìjọ. Tó bá dà bíi pé àǹfààní tí o fẹ́ kò tètè dé, má ṣàníyàn, ńṣe ni kó o mú sùúrù. Raymond tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Tó o bá ń kánjú, o ò lè ní ìtẹ́lọ́rùn. Àwọn tó bá ń ṣàníyàn kì í rí àwọn ìbùkún àgbàyanu téèyàn máa ń rí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.” Ohun míì tó o lè ṣe ni pé kí o túbọ̀ máa fi èso ti ẹ̀mí ṣèwà hù, pàápàá jù lọ sùúrù. Sapá láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kí àjọṣe tó o ní pẹ̀lú Jèhófà lè sunwọ̀n sí i. Máa ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere, kó o sì máa kọ́ àwọn tó fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nínú ìdílé rẹ, máa múpò iwájú nínú àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí àti nínú ìjọsìn ìdílé. Tó o bá wà pẹ̀lú àwọn arákùnrin àti arábìnrin rẹ, máa gbádùn àkókò tí ẹ jọ ń lò pa pọ̀. Bó o ṣe ń tẹ̀ síwájú kí ọwọ́ rẹ lè tẹ àfojúsùn rẹ, wàá máa láyọ̀ bí o ti ń sin Jèhófà.
Àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ ló jẹ́ látọ̀dọ̀ Jèhófà téèyàn bá tóótun fún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ. Jèhófà tàbí ètò rẹ̀ kò fẹ́ kí nǹkan sú wa tàbí ká banú jẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Jèhófà máa ń bù kún àwọn tó ń fi ọkàn mímọ́ sìn ín. Tí Jèhófà bá bù kún àwọn èèyàn, ‘kì í fi ìrora kún un.’—Òwe 10:22.
Kódà tó bá ti pẹ́ tó ti ń wù ẹ́ pé kó o ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ, o ṣì lè mú kí àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà sunwọ̀n sí i. Bó o ti ń sapá láti ní àwọn ìwà táá mú kó o kúnjú ìwọ̀n, tó ò ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe nínú ìjọ, tí o kò sì pa ìdílé rẹ tì, Jèhófà kò ní gbàgbé gbogbo ohun tó ò ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Ǹjẹ́ kí inú rẹ máa dùn bí o ti ń sin Jèhófà, kó o sì máa láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ èyíkéyìí tó o bá ń ṣe nínú ìjọ.
a A ti yí àwọn orúkọ inú àpilẹ̀kọ yìí pa dà.
b Àwọn ìlànà tí a mẹ́nu kàn nínú àpilẹ̀kọ yìí tún kan àwọn tó wù láti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. Bíbélì sọ àwọn ohun tí wọ́n gbọ́dọ̀ dójú ìlà rẹ̀ nínú ìwé 1 Tímótì 3:8-10, 12, 13.