Ẹ̀yin Òbí Ẹ Jẹ́ Àpẹẹrẹ Rere Fáwọn Ọmọ Yín
“ÌWÉ ìròyìn kan tó ń jẹ́ Time fa ọ̀rọ̀ yọ látinú ìwé kan tó sọ nípa ọmọ títọ́, ó ní: “Ó yẹ káwọn onímọ̀ nípa ìrònú àti ìhùwàsí ẹ̀dá dáwọ́ ìwádìí wọn dúró, ìyẹn ìwádìí tí wọ́n ti ń ṣe bọ̀ láti ọgọ́rùn-ún ọdún kí wọ́n lè mọ ọ̀nà tó dára jù lọ láti gbà tọ́ ọmọ, tí ọmọ náà á sì jẹ́ ọmọ gidi. Kì í ṣe nítorí pé wọ́n ti rí ọ̀nà náà o, àmọ́ nítorí pé ọ̀nà náà kò sí.” Ìwé náà sọ pé ohun táwọn ẹlẹgbẹ́ wọn bá kà sí pàtàkì làwọn ọmọdé máa ń kà sí pàtàkì, dípò ohun táwọn òbí wọn bá ń ṣe.
Kò sírọ́ níbẹ̀ pé ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe lágbára gan-an. (Òwe 13:20; 1 Kọ́ríńtì 15:33) Ọ̀gbẹ́ni kan tó ń jẹ́ William Brown tó jẹ́ akọ̀ròyìn sọ pé: “Ohun tó jẹ àwọn ọ̀dọ́ lógún jù lọ ni káwọn ẹlẹgbẹ́ wọn tẹ́wọ́ gbà wọ́n. . . . Ohun táwọn ọ̀dọ́ kórìíra jù ni kí wọ́n yàtọ̀ sáwọn ẹgbẹ́ wọn.” Nígbà táwọn òbí kò bá ṣe ohun tó máa mú kí ilé jẹ́ ibi tó gbádùn mọ́ àwọn ọmọ wọn àti ibi tó tù wọ́n lára, tàbí tí wọn kò bá ń lo àkókò tó tó pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn, ńṣe ni wọ́n ń fàyè sílẹ̀ fáwọn ọ̀rẹ́ àwọn ọmọ wọn láti ní ipa tí kò dára lórí wọn. Àwọn ìṣòro méjèèjì tá a mẹ́nu kàn níbí yìí sì wọ́pọ̀ nínú ayé kòókòó-jàn-án jàn-án tí à ń gbé lónìí.
Síwájú sí i, ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” yìí, ohun tó ń dojú kọ ìdílé kò kéré rárá nítorí pé gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ tẹ́lẹ̀, owó, ìgbádùn, àti títẹ́ra ẹni lọ́rùn ló gba àwọn èèyàn lọ́kàn. Ṣé ó wá yẹ kó yà wá lẹ́nu pé àwọn ọmọ ń di “aṣàìgbọràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìdúróṣinṣin, aláìní ìfẹ́ni àdánidá”?—2 Tímótì 3:1-3.
Ọ̀rọ̀ náà “ìfẹ́ni àdánidá” tí Bíbélì lò túmọ̀ sí ìfẹ́ tó máa ń wà láàárín ìdílé. Ìfẹ́ yìí jẹ́ ìfẹ́ tí Ọlọ́run ti dá mọ́ni, tó ń mú káwọn òbí bójú tó àwọn ọmọ wọn tó sì ń mú káwọn ọmọ nífẹ̀ẹ́ àwọn òbí wọn gan-an. Àmọ́ nígbà táwọn òbí kò bá fi ìfẹ́ yìí hàn sáwọn ọmọ wọn, àwọn ọmọ á wá ẹlòmíràn tí wọ́n lè máa fọ̀rọ̀ lọ̀. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló sì máa ń jẹ́ pé àwọn ọ̀rẹ́ wọn làwọn tí wọ́n máa ń fọ̀rọ̀ lọ̀, tó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun táwọn ọ̀rẹ́ yẹn nífẹ̀ẹ́ sí làwọn náà á nífẹ̀ẹ́ sí, ìwà àwọn ọ̀rẹ́ yìí ni wọ́n á sì máa tẹ̀ lé. Síbẹ̀, lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn òbí lè yẹra fún irú ìṣòro yìí bí wọ́n bá ń lo àwọn ìlànà Bíbélì láti darí ìdílé wọn.—Òwe 3:5, 6.
Ọlọ́run Ló Dá Ìdílé Sílẹ̀
Lẹ́yìn tí Ọlọ́run so Ádámù àti Éfà pọ̀, ó fún wọn láṣẹ yìí pé: “Ẹ máa so èso, kí ẹ sì di púpọ̀, kí ẹ sì kún ilẹ̀ ayé.” Bí ìdílé ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyẹn, ìyẹn bàbá, ìyá, àtàwọn ọmọ. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28; 5:3, 4; Éfésù 3:14, 15) Jèhófà ti dá àwọn ohun kan nípa ọmọ títọ́ mọ́ àwọn òbí láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti tọ́ àwọn ọmọ wọn. Àmọ́ àwa èèyàn yàtọ̀ sáwọn ẹranko, a nílò ìrànwọ́ mìíràn láfikún sí èyí tí Jèhófà ti dá mọ́ wa, ìdí sì nìyẹn tó fi pèsè àwọn ìtọ́sọ́nà tó wà lákọsílẹ̀ fáwọn òbí. Lára wọn ni ìtọ́sọ́nà lórí ìwà híhù àti ìjọsìn Ọlọ́run àti fífún ọmọ ní ìbáwí tó bójú mu.—Òwe 4:1-4.
Àwọn bàbá ni Ọlọ́run dìídì ń bá sọ̀rọ̀ nígbà tó sọ pé: “Kí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí mo ń pa láṣẹ fún ọ lónìí sì wà ní ọkàn-àyà rẹ; kí ìwọ sì fi ìtẹnumọ́ gbìn wọ́n sínú ọmọ rẹ, kí o sì máa sọ̀rọ̀ nípa wọn nígbà tí o bá jókòó nínú ilé rẹ àti nígbà tí o bá ń rìn ní ojú ọ̀nà àti nígbà tí o bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí o bá dìde.” (Diutarónómì 6:6, 7; Òwe 1:8, 9) Kíyè sí i pé àwọn òbí gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ jẹ́ kí òfin Ọlọ́run wà nínú ọkàn àwọn fúnra wọn. Kí nìdí tí èyí fi ṣe pàtàkì? Ìdí ni pé ẹ̀kọ́ tó máa mú káwọn èèyàn ṣe ohun tó dára gbọ́dọ̀ wá látinú ọkàn ẹni tó ń kọ́ wọn, kò gbọ́dọ̀ jẹ́ ọ̀rọ̀ ẹnu lásán. Àyàfi táwọn òbí bá kọ́ àwọn ọmọ látọkàn wa ni ẹ̀kọ́ náà á fi wọ àwọn ọmọ wọn lọ́kàn. Irú àwọn òbí bẹ́ẹ̀ á tún wá jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà fáwọn ọmọ wọn, nítorí pé àwọn ọmọ tètè máa ń rí àgàbàgebè àwọn òbí.—Róòmù 2:21.
Bíbélì sọ fáwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni pé láti kékeré jòjòló ni kí wọ́n ti “ma tọ́ [àwọn ọmọ] wọn ninu ẹkọ́ ati ikilọ Oluwa.” (Éfésù 6:4 Bibeli Mimọ; 2 Tímótì 3:15) Láti kékeré jòjòló kẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni o! Ìyá kan kọ̀wé pé: “Nígbà míì, àwa òbí máa ń fojú kéré àwọn ọmọ wa. A máa ń rò pé wọ́n ṣì kéré. Àmọ́ tá a bá kọ́ wọn ni nǹkan kan, wọ́n á mọ̀ ọ́n. Àwa òbí gbọ́dọ̀ lo àǹfààní yìí.” Bó ṣe rí nìyẹn o, àwọn ọmọdé máa ń fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́, tó bá sì jẹ́ àwọn òbí tó ń sin Ọlọ́run tọkàntọkàn ló kọ́ wọn, àwọn ọmọ náà á tún mọ béèyàn ṣe ń nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àtàwọn èèyàn. Àwọn òfin táwọn òbí bá sì gbé kalẹ̀ máa ń fi irú àwọn ọmọ bẹ́ẹ̀ lọ́kàn balẹ̀. Nítorí náà, àwọn òbí tó fẹ́ ṣàṣeyọrí yóò sapá láti jẹ́ ọ̀rẹ́ àwọn ọmọ wọn, wọ́n á máa bá wọn sọ̀rọ̀ dáadáa, wọ́n á máa ní sùúrù tí wọ́n bá ń kọ́ wọn, àmọ́ wọn ò ní gbàgbàkugbà, èyí á sì mú kí ilé jẹ́ ibi tí ọkàn àwọn ọmọ á ti balẹ̀ tí wọ́n á sì máa ṣe dáadáa.a
Dáàbò Bo Àwọn Ọmọ Rẹ
Nínú lẹ́tà kan tí olùkọ́ àgbà iléèwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ kan nílẹ̀ Jámánì kọ sáwọn òbí, ó ní: “A fẹ́ láti rọ ẹ̀yin òbí wa ọ̀wọ́n pé kẹ́yin náà túbọ̀ máa kópa gan-an nínú títọ́ àwọn ọmọ yín, kẹ́ ẹ má sì ṣe fi ohun tó yẹ kí ẹyin fúnra yín ṣe káwọn ọmọ yín lè ní ìwà rere sílẹ̀ fún tẹlifíṣọ̀n tàbí àwọn èèyànkéèyàn.”
Kéèyàn fọmọ rẹ̀ sílẹ̀ fún tẹlifíṣọ̀n tàbí kí ọmọ máa bá àwọn ọmọkọ́mọ rìn kò yàtọ̀ sí pé èèyàn ń fàyè gba ẹ̀mí ayé láti nípa lórí ọ̀nà téèyàn ń gbà tọ́ ọmọ náà. (Éfésù 2:1, 2) Ẹ̀mí ayé lòdì sí ẹ̀mí Ọlọ́run pátápátá. Bíi ìjì líle ló rí, ńṣe ló máa ń gbé àwọn èrò tó ‘jẹ́ ti ayé, ti ẹranko, àti ti ẹ̀mí èṣù’ wá sínú ọkàn àwọn tí kò gbọ́n tàbí àwọn tó jẹ́ òmùgọ̀. (Jákọ́bù 3:15) Tó bá wá yá, irú àwọn èrò búburú bẹ́ẹ̀ á wá sọ ọkàn ẹni náà dìdàkudà. Jésù fi àkàwé kan ṣàlàyé ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà táwọn èrò tí kò tọ́ bá ti sọ ọkàn ẹni dìdàkudà, ó ní: “Ẹni rere a máa mú ohun rere jáde wá láti inú ìṣúra rere ọkàn-àyà rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni burúkú a máa mú ohun tí í ṣe burúkú jáde wá láti inú ìṣúra burúkú rẹ̀; nítorí lára ọ̀pọ̀ yanturu tí ń bẹ nínú ọkàn-àyà ni ẹnu rẹ̀ ń sọ.” (Lúùkù 6:45) Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi gbà wá níyànjú pé: “Ju gbogbo ohun mìíràn tí a ní láti ṣọ́, fi ìṣọ́ ṣọ́ ọkàn-àyà rẹ, nítorí láti inú rẹ̀ ni àwọn orísun ìyè ti wá.”—Òwe 4:23.
Lóòótọ́, ọmọdé lọmọ́dé á máa jẹ́, àwọn ọmọ kan sì máa ń ya olórí kunkun, kódà àwọn kan máa ń ya pòkíì. (Jẹ́nẹ́sísì 8:21) Kí làwọn òbí lè ṣe tí wọ́n bá nírú ọmọ bẹ́ẹ̀? Bíbélì sọ pé: “Ọkàn-àyà ọmọdékùnrin ni ìwà òmùgọ̀ dì sí; ọ̀pá ìbáwí ni yóò mú un jìnnà réré sí i.” (Òwe 22:15) Ìwà òǹrorò làwọn kan ka nína ọmọ sí, wọ́n sì ní kò bóde mu mọ́. Ká sòótọ́ o, Bíbélì kò fára mọ́ kéèyàn máa sọ̀rọ̀ burúkú sí ọmọ tàbí kéèyàn máa lu ọmọ nílùkulù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé nígbà míì “ọ̀pá ìbáwí” máa ń túmọ̀ sí kéèyàn na ọmọ, àmọ́ àṣẹ táwọn òbí ní lórí ọmọ ló dìídì túmọ̀ sí. Èyí jẹ́ àṣẹ tí wọ́n ń lò láìgba gbẹ̀rẹ́, àmọ́ lọ́nà tó fi ìfẹ́ hàn tó sì bójú mu kó lè dára fáwọn ọmọ náà títí ayé.—Hébérù 12:7-11.
Máa Ṣe Eré Ìnàjú Pẹ̀lú Àwọn Ọmọ Rẹ
Gbogbo wa la mọ̀ pé káwọn ọmọ tó lè dàgbà dáadáa, wọ́n ní láti ṣeré, wọ́n sì tún nílò ohun tó lè dá wọn lára yá. Àwọn òbí tó gbọ́n máa ń lo àǹfààní tí wọ́n bá ní láti mú kí àjọṣe àárín àwọn àtàwọn ọmọ wọn túbọ̀ dán mọ́rán nípá ṣíṣe eré ìnàjú pẹ̀lú wọn nígbàkigbà tó bá ṣeé ṣe. Kì í ṣe pé èyí á jẹ́ káwọn òbí lè tọ́ àwọn ọmọ wọn sọ́nà nínú bí wọ́n á ṣe máa yan eré ìnàjú tó dára nìkan ni, àmọ́ á tún jẹ́ kí wọ́n lè fi han àwọn ọmọ náà pé ó máa ń wu àwọn láti máa wà pẹ̀lú wọn.
Bàbá kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ pé òun sábà máa ń bá ọmọ òun ọkùnrin gbá bọ́ọ̀lù nígbà tóun bá ti ibi iṣẹ́ dé. Ìyá kan sọ pé òun àtàwọn ọmọ òun jọ máa ń ta ayò, àwọn sì máa ń gbádùn rẹ̀ gan-an. Obìnrin kan sì rántí pé òun àti ìdílé òun jọ máa ń gbádùn gígun kẹ̀kẹ́ pa pọ̀ nígbà tó wà lọ́mọdé. Gbogbo àwọn ọmọ wọ̀nyí ló ti dàgbà báyìí, àmọ́ ìfẹ́ tí wọ́n ní sáwọn òbí wọn àti sí Jèhófà kò dín kù rárá, ńṣe ló ń lágbára sí i.
Láìsí àní-àní, àwọn òbí tó bá ń fi hàn nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe pé àwọn nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn, tó sì máa ń wù wọ́n láti wà pẹ̀lú àwọn ọmọ náà máa ń ní ipa tó dára gan-an lórí wọn, èyí tó sì máa ń ṣe àwọn ọmọ náà láǹfààní títí ayé wọn. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ lára àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege ní kíláàsì kan nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì, ìyẹn Watchtower Bible School of Gilead ló sọ pé àpẹẹrẹ àwọn òbí àwọn àti ìṣírí táwọn rí gbà látọ̀dọ̀ wọn ló jẹ́ káwọn yan iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún láàyò. Ogún tó dára gbáà lèyí jẹ́ fáwọn ọmọ, ìbùkún ńlá sì ni fáwọn òbí pẹ̀lú! Lóòótọ́, kì í ṣe gbogbo ọmọ ló lè ṣeé ṣe fún láti ṣe iṣẹ́-òjíṣẹ́ alákòókò kíkún nígbà tí wọ́n bá dàgbà, àmọ́ gbogbo ọmọ ló máa jàǹfààní lára àwọn òbí tó bá bẹ̀rù Ọlọ́run, tí wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ wọn tímọ́tímọ́, tí wọ́n sì jẹ́ àpẹẹrẹ tó dára fún wọn, wọ́n á sì bọlá fáwọn òbí náà.—Òwe 22:6; Éfésù 6:2, 3.
Àwọn Òbí Tó Ń Dá Nìkan Tọ́mọ Lè Kẹ́sẹ Járí
Lóde òní, ọ̀pọ̀ ọmọ ló jẹ́ pé òbí kan ṣoṣo ló ń tọ́ wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí ń dá kún ìṣòro ọmọ títọ́, síbẹ̀ irú àwọn òbí bẹ́ẹ̀ lè ṣàṣeyọrí. Àpẹẹrẹ Yùníìsì nínú Bíbélì, ìyẹn Kristẹni kan tó jẹ́ Júù ní ọ̀rúndún kìíní, lè fún àwọn òbí tó ń dá nìkan tọ́mọ níṣìírí. Níwọ̀n bí ọkọ Yùníìsì ti jẹ́ aláìgbàgbọ́, ó ṣeé ṣe kí ọkọ̀ rẹ̀ má tì í lẹ́yìn rárá nínú ìjọsìn tòótọ́. Síbẹ̀síbẹ̀, kíkọ́ tó kọ́ Tímótì lẹ́kọ̀ọ́ jẹ́ àpẹẹrẹ téèyàn lè tẹ̀ lé. Àpẹẹrẹ rere tí Tímótì rí láti kékeré lára ìyá rẹ̀ yìí, àti lára Lọ́ìsì tó jẹ́ ìyá ìyá rẹ̀, lágbára gan-an ju àpẹẹrẹ búburú èyíkéyìí tó ṣeé ṣe kí Tímótì máa rí lára àwọn ojúgbà rẹ̀.—Ìṣe 16:1, 2; 2 Tímótì 1:5; 3:15.
Lónìí, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ tó dàgbà nínú ìdílé tí òbí kan ti jẹ́ aláìgbàgbọ́ tàbí nínú ìdílé olóbìí kan ló ní irú àwọn ànímọ́ dáadáa tí Tímótì ní. Bí àpẹẹrẹ, inú ìdílé olóbìí kan ni Ryan tó jẹ́ ọmọ ọdún méjìlélógún báyìí tó sì jẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún ti dàgbà, pẹ̀lú ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin àti obìnrin. Ọ̀mùtí paraku ni bàbá wọn, ìgbà tí Ryan wà lọ́mọ ọdún mẹ́rin ni bàbá rẹ̀ sì ti fi ìdílé wọn sílẹ̀. Ryan sọ pé: “Màmá wa pinnu pé ìdílé wa yóò máa sin Jèhófà nìṣó, gbogbo ọkàn rẹ̀ ló sì fi tẹ̀ lé ìpinnu náà.”
Ryan sọ pé: “Bí àpẹẹrẹ, màmá wa rí i dájú pé àwọn ọmọ tá a lè kọ́ ẹ̀kọ́ tó dára lára wọn là ń bá rìn. Kì í gbà wá láyè láti bá àwọn tí Bíbélì sọ pé ó jẹ́ ẹgbẹ́ búburú rìn, yálà nínú ìjọ tàbí láàárín àwọn tí kì í ṣe Kristẹni. Ó tún jẹ́ ká ní èrò tó tọ́ nípa ẹ̀kọ́ tá à ń kọ́ nílé ẹ̀kọ́.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọwọ́ ìyá Ryan sábà máa ń dí tó sì máa ń rẹ̀ ẹ́ nítorí iṣẹ́ rẹ̀, síbẹ̀ èyí kò dí i lọ́wọ́ láti máa fìfẹ́ bójú tó àwọn ọmọ rẹ̀. Ryan sọ pé: “Ó máa ń fẹ́ láti wà pẹ̀lú wa nígbà gbogbo kó sì máa bá wa sọ̀rọ̀. Olùkọ́ tó ní sùúrù àmọ́ tí kò gba gbẹ̀rẹ́ ni, ó sì máa ń sa gbogbo ipá rẹ̀ láti rí i pé a ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé déédéé. Tó bá kan ti fífi ìlànà Bíbélì sílò, kò jẹ́ ṣe ohun tó mọ̀ pé ó lòdì.”
Nígbà tí Ryan bá ronú padà sígbà tó wà lọ́mọdé, ó máa ń rí i pé ẹni tí àpẹẹrẹ rẹ̀ nípa lórí ìgbésí ayé òun àti tàwọn ẹ̀gbọ́n òun jù lọ ni màmá òun tó jẹ́ anìkàntọ́mọ, tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run gan-an tó sì nífẹ̀ẹ́ àwa ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú. Nítorí náà ẹ̀yin òbí tẹ́ ẹ jẹ́ Kristẹni, yálà ẹ lẹ́nì kejì tàbí opó ni yín, yálà onígbàgbọ́ lẹnì kejì yín tàbí aláìgbàgbọ́, ẹ má ṣe jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì tàbí ìfàsẹ́yìn tó máa ń wáyé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan mú un yín juwọ́ sílẹ̀ bẹ́ ẹ ti ń sapá láti kọ́ àwọn ọmọ yín. Nígbà míì, àwọn ọ̀dọ́ kan lè kúrò nínú òtítọ́ bíi ti ọmọ onínàákúnàá. Àmọ́ nígbà tí wọ́n bá rí i bí ayé ṣe rí, pé kò sí nǹkan kan nínú rẹ̀ àfi ìwà ìkà, wọ́n lè padà wá. Dájúdájú, “olódodo ń rìn nínú ìwà títọ́ rẹ̀. Aláyọ̀ ni àwọn ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀.”—Òwe 20:7; 23:24, 25; Lúùkù 15:11-24.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tó o bá fẹ́ rí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí kókó kọ̀ọ̀kan tá a mẹ́nu kàn yìí, wo ojú ìwé 55 sí 59 nínú ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Ọlọ́run Fúnra Rẹ̀ Ló Yan Àwọn Òbí Jésù
Nígbà tí Jèhófà ṣètò kí wọ́n bí Ọmọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí èèyàn, òun fúnra rẹ̀ ló yan àwọn tó máa jẹ́ òbí Jésù. Ó yẹ ká kíyè sí i pé tọkọtaya tó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, tí wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run, tí wọn ò sì kẹ́ Jésù bà jẹ́ ni Ọlọ́run yàn láti jẹ́ òbí fún Jésù. Àwọn òbí yìí tún kọ́ Jésù ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n sì jẹ́ kó mọyì iṣẹ́ àṣekára àti bíbójú tó ojúṣe ẹni. (Òwe 29:21; Ìdárò 3:27) Jósẹ́fù kọ́ Jésù ní iṣẹ́ káfíńtà, kò sì sí àní-àní pé Jósẹ̀fù àti Màríà ti ní láti sọ pé kí Jésù tó jẹ́ àkọ́bí wọn ran àwọn lọ́wọ́ nínú títọ́jú àwọn ọmọ wọn yòókù tí wọ́n ń lọ sí bíi mẹ́fà ó kéré tán.—Máàkù 6:3.
Nígbà àjọ̀dún ìrékọjá, o lè fojú inú wo ìdílé Jósẹ́fù bí wọ́n ṣe jọ ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ láti múra sílẹ̀ fún ìrìn àjò tí wọ́n máa ń rìn lọ sí Jerúsálẹ́mù lọ́dọọdún. Ìrìn àjò yìí jẹ́ igba [200] kìlómítà ní àlọ àti àbọ̀ láìsí irú ohun ìrìnnà tó wà lóde òní. Dájúdájú, ìdílé yìí, táwọn tó wà nínú rẹ̀ tó mẹ́sàn-án tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ní láti wà létòlétò gan-an kí wọ́n tó lè rin irú ìrìn àjò ọ̀nà jíjìn bẹ́ẹ̀. (Lúùkù 2:39, 41) Láìka gbogbo ìnira wọ̀nyí sí, kò sí àní-àní pé Jósẹ́fù àti Màríà mọyì ìrìn àjò yìí gan-an, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé wọ́n máa ń lo àkókò náà láti kọ́ àwọn ọmọ wọn nípa àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn tí àkọsílẹ̀ wọn wà nínú Bíbélì.
Bí Jésù ti ń dàgbà, ó “ń bá a lọ ní fífi ara rẹ̀ sábẹ́” àwọn òbí rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ló sì ‘ń tẹ̀ síwájú nínú ọgbọ́n tó ń dàgbà sókè ní ti ara-ìyára àti ní níní ojú rere lọ́dọ̀ Ọlọ́run àti ènìyàn.’ (Lúùkù 2:51, 52) Dájúdájú, Jósẹ́fù àti Màríà kò já Jèhófà kulẹ̀. Àpẹẹrẹ àtàtà gbáà ni wọ́n jẹ́ fáwọn òbí lónìí!—Sáàmù 127:3.