Kọ́ Wọn Láti Ìgbà Ọmọdé Jòjòló
ÌWÁDÌÍ òde òní fi hàn pé “ọmọ inú ọlẹ̀ máa ń hùwà padà sí ohùn ní ti èrò ìmọ̀lára.” Ìwé agbéròyìnjáde Winnipeg Free Press sọ pé, àwọn olùṣèwádìí ní Yunifásítì Àríwá Carolina “rí i pé lẹ́yìn tí àwọn ìyá bá ti kàwé sétígbọ̀ọ́ àwọn ọmọ wọn nínú ilé ọlẹ̀, àwọn ọmọ àṣẹ̀ṣẹ̀bí náà máa ń hùwà padà nígbà tí a bá tún àyọkà náà kà.” Nígbà tí àwọn obìnrin bá kàwé sókè nígbà tí wọ́n bá wà nínú oyún, èyí lè túbọ̀ fi kún gbígbin ìlànà ìwà híhù sínú ọmọ náà. Bíbélì sọ pé, Tímótì ‘mọ ìwé mímọ́ láti ìgbà ọmọdé jòjòló.’ (Tímótì Kejì 3:14, 15) Kò sí àní-àní pé, ìyá rẹ̀ àti ìyá-ìyá rẹ̀ mọrírì ìníyelórí kíkọ́ ọ láti ìgbà ọmọdé jòjòló, tí ó ṣeé ṣe kí wọ́n ti fi kíkàwé sókè kún un.
Òǹkọ̀wé Jim Trelease sọ pé ìwé kíkà “ni òye iṣẹ́ lílágbára jù lọ nínú ìgbésí ayé, tí a ní láwùjọ wa lónìí.” A lè mú òye èdè àti ọ̀rọ̀ èdè sunwọ̀n sí i nípa kíkàwé sókè.
Ó bọ́gbọ́n mu kí o bẹ̀rẹ̀ sí í kàwé sókè, ó pẹ́ tán, gbàrà tí o bá ti ń bá ọmọ rẹ̀ jòjòló sọ̀rọ̀. Àní bí ọmọ rẹ tí o kò tí ì bí tàbí tí o ṣẹ̀ṣẹ̀ bí kò bá lóye ohun tí o ń sọ lákọ̀ọ́kọ́, àwọn àǹfààní onígbà pípẹ́ tí ó lè jẹyọ yẹ fún irú ìsapá bẹ́ẹ̀. Òwe 22:6 sọ pé: “Tọ́ ọmọdé ní ọ̀nà tí yóò tọ̀: nígbà tí ó sì dàgbà tán, kì yóò kúrò nínú rẹ̀.”
Kí ni o lè kà tí ó lè wúlò, tí ó sì lè ṣàǹfààní? Ka Bíbélì sókè sí etígbọ̀ọ́ ọmọ rẹ lójoojúmọ́. Sì ka àwọn ìtẹ̀jáde mìíràn tí ó níye lórí, irú bíi Fifetisilẹ si Olukọ Nla na, Iwe Itan Bibeli Mi, Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí, àti àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ inú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí!
Lóòótọ́, mímú ara rẹ wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní ọ̀nà yìí ń béèrè àkókò, ṣùgbọ́n ó jẹ́ àkókò kan tí a lò lọ́nà rere. Ó jẹ́ ọ̀nà gúnmọ́ kan láti fi hàn pé, o bìkítà nípa ọmọ rẹ̀ àti pé o nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.