Ẹ̀yin Òbí, Àwọn Ọmọ Yín Nílò Àfiyèsí Àrà-Ọ̀tọ̀
“Àwọn ọmọ rẹ yóò dàbí igi ólífì yí tábìlì rẹ ká.”—ORIN DAFIDI 128:3.
1. Báwo ni a ṣe lè fi títọ́ àwọn ohun ọ̀gbìn àti títọ́ àwọn ọmọ dàgbà wéra?
NÍ Ọ̀PỌ̀LỌPỌ̀ ọ̀nà, àwọn ọmọdé ń dàgbà wọ́n sì ń gasókè bí àwọn ohun ọ̀gbìn. Nítorí náà, kò yanilẹ́nu pé Bibeli sọ̀rọ̀ nípa ìyàwó ọkùnrin kan gẹ́gẹ́ bí “àjàrà rere eléso” tí ó si fi àwọn ọmọ wé “igi ólífì yí tábìlì [rẹ̀] ká.” (Orin Dafidi 128:3) Àgbẹ̀ kan yóò sọ fún ọ pé títọ́ èso àwọn ohun ọ̀gbìn kékeré dàgbà kò rọrùn, ní pàtàkì nígbà tí ipò ojú ọjọ́ àti ilẹ̀ kò bá báradé. Bákan náà, ní àwọn “ìkẹyìn ọjọ́” lílekoko wọ̀nyí, ó ṣòro gidigidi láti tọ́ àwọn ọmọ di àgbàlagbà tí a túnṣebọ̀sípò dáradára, tí wọ́n sì jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọrun.—2 Timoteu 3:1-5.
2. Kí ni a sábà máa ń nílò láti mú irè dídára jáde?
2 Láti kórè èso dídára, àgbẹ̀ kan nílò ilẹ̀ tí ó lẹ́tù lójú, oòrùn lílọ́wọ́ọ́wọ́, àti omi. Ní àfikún sí ríroko àti títu èpò, ó gbọ́dọ̀ mú kí àwọn oògùn apakòkòrò àti àwọn àbójútó onídàáàbòbò mìíràn wà lárọ̀ọ́wọ́tó. Àwọn àkókò tí ó ṣòro lè wà nígbà ìdàgbàsókè, títí lọ dé ìgbà ìkórè. Ẹ wo bí yóò ti burú tó bí irè-oko náà bá lọ bàjẹ́! Síbẹ̀, ẹ wo bí aroko kan ti lè ní ìtẹ́lọ́rùn tó nígbà tí ó bá kórè èso dídára lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àṣekára!—Isaiah 60:20-22; 61:3.
3. Kí ni ìfiwéra tí ó wà láàárín ìjẹ́pàtàkì àwọn ohun ọ̀gbìn àti àwọn ọmọ, irú àfiyèsí wo sì ni àwọn ọmọ níláti rígbà?
3 Dájúdájú ìgbésí-ayé ẹ̀dá tí ó jẹ́ aláṣeyọrísírere, tí ó sì ṣàǹfààní ṣéyebíye lọ́pọ̀lọpọ̀ ju ìkórè àgbẹ̀ kan lọ. Kò yanilẹ́nu nígbà náà pé títọ́ ọmọ kan dàgbà lọ́nà yíyọrísírere lè gba àkókò àti ìsapá tí ó tilẹ̀ pọ̀ síi ju títọ́ irè-oko púpọ̀ yanturu dàgbà. (Deuteronomi 11:18-21) Ọmọ kékeré kan tí a gbìn sínú ọgbà-ọ̀gbìn ìgbésí-ayé, lè dàgbà kí ó sì yọ ìtànná òdòdó nípa tẹ̀mí àní nínú ayé kan tí ó kún fún ọ̀pá ìdíyelé ìwàhíhù tí ìfàsẹ́yìn ti débá, bí a bá ń bomirin ín tí a sì ń fi ìfẹ́ ṣìkẹ́ rẹ̀ tí a sì fún un ní ààlà ìpínlẹ̀ tí ó ṣàǹfààní. Ṣùgbọ́n bí a kò bá fi ọwọ́ tí ó dára mú un tàbí tí a tẹ̀ ẹ́ lóríba, ọmọ náà yóò rọ nínú ó sì ṣeéṣe kí ó kú nípa tẹ̀mí. (Kolosse 3:21; fiwé Jeremiah 2:21; 12:2.) Níti tòótọ́, gbogbo àwọn ọmọdé nílò àfiyèsí àrà-ọ̀tọ̀!
Àfiyèsí Ojoojúmọ́ Láti Ìgbà Ọmọdé Jòjòló
4. Irú àfiyèsí wo ni àwọn ọmọ nílò “láti ìgbà ọmọdé jòjòló”?
4 Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ àfiyèsí ìgbà gbogbo ni àwọn òbí níláti fún àwọn ọmọ àṣẹ̀ṣẹ̀bí. Bí ó ti wù kí ó rí, ọmọ-ọwọ́ náà ha nílò kìkì àfiyèsí nípa tí ara tàbí ti ohun-ìní nígbà gbogbo bí? Aposteli Paulu kọ̀wé sí Timoteu, ìránṣẹ́ Ọlọrun náà pé: “Láti ìgbà ọmọdé jòjòló ni iwọ ti mọ ìwé mímọ́, èyí tí ó lè sọ ọ́ di ọlọgbọ́n fun ìgbàlà.” (2 Timoteu 3:15, NW) Nítorí náà àfiyèsí àwọn òbí rẹ̀ tí Timoteu rígbà, àní láti ìgbà ọmọdé jòjòló pàápàá, jẹ́ tẹ̀mí. Ṣùgbọ́n àkókò wo ni ìgbà ọmọdé jòjòló bẹ̀rẹ̀?
5, 6. (a) Kí ni Bibeli sọ nípa ọmọ tí a kò tíì bí? (b) Kí ni ó fihàn pé àwọn òbí níláti ṣàníyàn nípa ire ọmọ tí a kò tíì bí?
5 Ọ̀rọ̀ Griki náà tí Paulu lò níhìn-ín (breʹphos) ni a tún ń lò fún ọmọ kan tí a kò tíì bí. Elisabeti, ìyá Johannu Arinibọmi, sọ fún ìbátan rẹ̀ Maria pé: “Bí ohùn kíkí rẹ ti bọ́ sí mi ní etí, ọlẹ̀ [breʹphos] sọ nínú mi fún ayọ̀.” (Luku 1:44) Nípa báyìí, àwọn ọmọ tí a kò tíì bí pàápàá ni a pè ní ọmọdé jòjòló, Bibeli sì fihàn pé wọ́n lè dáhùnpadà sí ìgbòkègbodò tí ń wáyé lẹ́yìn òde ilé ọlẹ̀. Nítorí náà àbójútó ṣáájú ìbímọ tí a sábà máa ń fún ní ìṣírí lónìí ha níláti ní àfiyèsí fún ire tẹ̀mí ti ọmọdé jòjòló náà tí a kò tíì bí nínú bí?
6 Èyí jẹ́ ohun kan láti gbéyẹ̀wò, níwọ̀n bí ẹ̀rí ti fihàn pé àwọn ọmọ tí a kò tíì bí lè jàǹfààní láti inú àwọn ohun tí wọ́n ń gbọ́ tàbí kí ó nípalórí wọn lọ́nà tí kò báradé. Olùdarí orin kan rí i pé onírúurú àkójọ orin tí òun fi ń dánrawò dún bí èyí tí òun mọ̀ dunjú lọ́nà tí ó ṣàjèjì, ní pàtàkì apá tí ó jẹ́ ti gìtá tí ń lu ohùn ìsàlẹ̀. Nígbà tí ó dárúkọ àwọn àkójọ orin náà fún ìyá rẹ̀, tí ó ń fi lílu gìtá olóhùn ìsàlẹ̀ ṣiṣẹ́ ṣe, ó sọ pé ìwọ̀nyẹn jẹ́ àwọn àkójọ orin náà gan-an tí òun ti ń fidánrawò nígbà tí òun lóyún rẹ̀ sínú. Bákan náà, ọmọ tí a kò tíì bí ni a lè nípa lélórí lọ́nà òdì nígbà tí àwọn ìyá wọn bá sọ ọ́ di àṣà láti máa wo ọ̀wọ́ eré àwòkẹ́kọ̀ọ́ afanimọ́ra lórí àjọṣepọ̀ ẹ̀dá lórí tẹlifíṣọ̀n. Nípa báyìí, àkànṣe ìwé ìṣègùn kan sọ̀rọ̀ nípa “àwọn ọlẹ̀ tí ọ̀wọ́ eré àwòkẹ́kọ̀ọ́ afanimọ́ra lórí àjọṣepọ̀ ẹ̀dá ti di bárakú fún.”
7. (a) Báwo ni ọ̀pọ̀ àwọn òbí ṣe fun ire ti ọmọ tí a kò tíì bí ní àfiyèsí? (b) Àwọn agbára ìṣe wo ni ọmọ kan ní?
7 Ní mímọ àǹfààní tí ń bẹ nínú ìdáhùnpadà gbígbéṣẹ́ ti àwọn ọmọdé jòjòló, ọ̀pọ̀ àwọn òbí bẹ̀rẹ̀ síí kàwé, sọ̀rọ̀, tí wọ́n sì ń kọrin fún ọmọ wọn àní kí wọ́n tó bí wọn. Ìwọ lè ṣe bákan náà. Nígbà tí ọmọdé jòjòló rẹ lè má lóye àwọn ọ̀rọ̀ náà, ó ṣeéṣe pé òun yóò jàǹfààní láti inú ohùn rẹ tí ń máratuni àti ìró rẹ tí ó jẹ́ onífẹ̀ẹ́. Lẹ́yìn ìbí, ọmọ náà yóò bẹ̀rẹ̀ síí lóye àwọn ọ̀rọ̀ rẹ, bóyá ní kíákíá ju bí o ti rò lọ. Ní kìkì ọdún méjì tàbí mẹ́ta, ọmọ kan ń kọ́ èdè dídíjú kan kìkì nípa dídi ẹni tí a ṣípayá sí i. Ọmọ-ọwọ́ kan tún lè bẹ̀rẹ̀ síí kẹ́kọ̀ọ́ “èdè mímọ́gaara” ti òtítọ́ Bibeli.—Sefaniah 3:9.
8. (a) Kí ni ẹ̀rí fihàn pé Bibeli ní lọ́kàn nígbà tí ó sọ pé Timoteu mọ ìwé mímọ́ “láti ìgbà ọmọdé jòjòló”? (b) Kí ni ó jásí òtítọ́ nípa Timoteu?
8 Kí ni Paulu nílọ́kàn nígbà tí ó sọ pé Timoteu ‘mọ ìwé mímọ́ láti ìgbà ọmọdé jòjòló’? Ẹ̀rí fihàn pé ó ní in lọ́kàn pé Timoteu ti gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tẹ̀mí láti ìgbà ọmọ-ọwọ́, kìí wulẹ̀ ṣe láti ìgbà tí ó ti di ọmọdé. Èyí wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ Griki náà breʹphos, èyí tí ń tọ́ka sí àwọn ọmọ àṣẹ̀ṣẹ̀bí ní gbogbogbòò. (Luku 2:12, 16; Iṣe 7:19) Timoteu gba ìtọ́ni tẹ̀mí láti ọ̀dọ̀ ìyá rẹ̀ Eunike àti ìyá ìyá rẹ̀ Loide tipẹ́tipẹ́ sẹ́yìn sí ìgbà tí òun lè rántí mọ. (2 Timoteu 1:5) Dájúdájú àṣàyàn ọ̀rọ̀ náà, ‘Láti kékeré ni a tií pẹ̀ka ìrókò’ jẹ́ òtítọ́ níti Timoteu. A ti ‘kọ́ ọ ní ọ̀nà tí yóò tọ̀,’ àti, gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí, ó di ìránṣẹ́ dídára fún Ọlọrun.—Owe 22:6; Filippi 2:19-22.
Àbójútó Àrà-Ọ̀tọ̀ tí A Nílò
9. (a) Kí ni àwọn òbí níláti yẹra fún ní ṣíṣe, èésìtiṣe? (b) Bí ọmọ kan ti ń dàgbà, kí ni ó yẹ kí àwọn òbí ṣe, àpẹẹrẹ wo ni wọ́n sì níláti kọbiara sí?
9 Àwọn ọmọdé pẹ̀lú dàbí àwọn ohun ọ̀gbìn níti pé kìí ṣe gbogbo wọn ni wọ́n ní àwọn ànímọ́ kan náà, bẹ́ẹ̀ sì ni gbogbo wọn kìí hùwàpadà bákan náà sí àwọn ọ̀nà ìgbàṣàbójútó. Àwọn òbí ọlọgbọ́n yóò bọ̀wọ̀ fún àwọn ìyàtọ̀ náà wọn yóò sì yẹra fún fífi ọmọ kan wé òmíràn. (Fiwé Galatia 6:4.) Bí àwọn ọmọ yín bá níláti dàgbà di géńdé ọmọlúwàbí, ẹ níláti ṣàkíyèsí àkópọ̀ ànímọ́ ìwà wọn tí ó yàtọ̀síra, ní jíjẹ́ kí èyí tí ó dára dàgbà àti fífa èyí tí ó burú tu. Bí o bá ṣàkíyèsí àìlera tàbí ìtẹ̀sí tí kò yẹ kan ńkọ́, bóyá síhà ìwà-àìṣòótọ́, ìfẹ́ ọrọ̀-àlùmọ́ọ́nì, tàbí ìmọtara-ẹni-nìkan? Fi inúrere ṣàtúnṣe rẹ̀, àní gẹ́gẹ́ bí Jesu ti ṣàtúnṣe àìlera àwọn aposteli rẹ̀. (Marku 9:33-37) Ní pàtàkì, gbóríyìn fún ọmọ kọ̀ọ̀kan déédéé fún okun àti ànímọ́ ìwà rere rẹ̀.
10. Kí ni àìní àwọn ọmọ ní pàtàkì, báwo sì ni a ṣe lè pèsè rẹ̀?
10 Ohun tí àwọn ọmọ nílò ní pàtàkì ni àkíyèsí ara-ẹni tí ó jẹ́ onífẹ̀ẹ́. Jesu wá àkókò láti pèsè irúfẹ́ àkànṣe àkíyèsí bẹ́ẹ̀ fún àwọn ọmọ kékeré, àní ní àwọn ọjọ́ tí ó gbẹ̀yìn iṣẹ́-òjíṣẹ́ rẹ̀ nígbà tí ọwọ́ rẹ̀ dí pàápàá. (Marku 10:13-16, 32) Ẹ̀yin òbí, ẹ tẹ̀lé àpẹẹrẹ yẹn! Ẹ fi àìmọtara-ẹni-nìkan wá àkókò láti wà pẹ̀lú àwọn ọmọ yín. Ẹ má sì ṣe jẹ́ kí ó tì yín lójú láti fi ojúlówó ìfẹ́ hàn fún wọn. Ẹ fi ọwọ́ yín gbá wọn mọ́ra, gẹ́gẹ́ bí Jesu ti ṣe. Ẹ fọwọ́ kó wọn mọ́ra kí ẹ sì fi ẹnu kò wọ́n lẹ́nu lọ́nà onífẹ̀ẹ́ àti ọlọ́yàyà. Nígbà tí a béèrè ìmọ̀ràn tí òbí àwọn ọmọ tí kò tíì dàgbà púpọ̀ tí wọ́n gbẹ̀kọ́ tí ó jíire ní fún àwọn òbí mìíràn, lára àwọn ìdáhùnpadà tí ó ṣe lemọ́lemọ́ jùlọ ni ‘Nífẹ̀ẹ́ wọn lọ́pọ̀lọpọ̀,’ ‘ẹ lo àkókò papọ̀,’ ‘ẹ mú ọ̀wọ̀ dàgbà fún tọ̀túntòsì,’ ‘ẹ fetísílẹ̀ sí wọn níti gidi,’ ‘ẹ fún wọn ní ìtọ́sọ́nà kàkà kí ó jẹ́ ọ̀rọ̀,’ kí ẹ sì ‘sọ òtítọ́ gidi.’
11. (a) Ojú wo ni ó yẹ kí àwọn òbí fi wo pípèsè àfiyèsí àrà-ọ̀tọ̀ fún àwọn ọmọ wọn? (b) Nígbà wo ni ó lè ṣeéṣe fún àwọn òbí láti gbádùn ọ̀rọ̀ àjọsọ ṣíṣeyebíye pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn?
11 Pípèsè irúfẹ́ àfiyèsí àrà-ọ̀tọ̀ bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ ayọ̀. Òbí aláṣeyọrísírere kan kọ̀wé pé: “Nígbà tí àwọn ọmọdékùnrin wa ṣì kéré, ọ̀nà tí a gbà ń múra wọn sílẹ̀ láti lọ sùn, kàwé fún wọn, wọ aṣọ ibùsùn fún wọn, àti gbígbàdúrà pẹ̀lú wọn jẹ́ ìgbádùn.” Lílo irú àwọn àkókò bẹ́ẹ̀ papọ̀ pèsè àǹfààní fún ọ̀rọ̀ àjọsọ tí ó lè fún òbí àti ọmọ ní ìṣírí. (Fiwé Romu 1:11, 12.) Tọkọtaya kan tẹ́tísílẹ̀ nígbà tí ọmọ wọn ọlọ́dún mẹ́ta béèrè pé kí Ọlọrun bùkún “Wally.” Ó gbàdúrà fún “Wally” ní àwọn alẹ́ tí ó tẹ̀lé e, àwọn òbí náà sì ní ìṣírí ńláǹlà nígbà tí wọ́n mọ̀ pé àwọn ará tí ń bẹ ní Malawi, tí wọ́n ń jìyà inúnibíni nígbà náà ni ó nílọ́kàn. Obìnrin kan sọ pé: ‘Nígbà tí mo jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rin péré, ìyá mi ràn mí lọ́wọ́ láti há àwọn ẹsẹ̀ ìwé mímọ́ sórí kí n sì kọ àwọn orin Ìjọba nígbà tí mo bá dúró sórí àga kan láti nu àwọn àwo bí òun ti ń fọ̀ wọ́n.’ Ìwọ ha lè ronú nípa àwọn àkókò nígbà tí o lè gbádùn ọ̀rọ̀ àjọsọ ṣíṣeyebíye pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ kékeré bí?
12. Kí ni yóò bá ọgbọ́n mu fún àwọn òbí Kristian láti pèsè fún àwọn ọmọ wọn, àwọn ọ̀nà wo sì ni wọ́n lè gbà?
12 Àwọn Kristian ọlọgbọ́n ṣètò fún ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́ déédéé. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o lè lo ọ̀nà ìbéèrè àti ìdáhùn gẹ́gẹ́ bí àṣà, ìwọ ha lè fikún ọ̀rọ̀ àjọsọ gbígbádùnmọ́ni nípa yíyíwọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ padà, pàápàá fún àwọn ọmọ tí wọ́n túbọ̀ kéré? O lè fi yíya àwòrán àwọn ìrísí ìran inú Bibeli, sísọ àwọn ìtàn Bibeli, tàbí fífetísílẹ̀ sí àlàyé tí o sọ pé kí ọmọ kan múra rẹ̀ sílẹ̀ kún un. Jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun gbádùnmọ́ àwọn ọmọ rẹ bí ó bá ti lè ṣeéṣe tó kí wọ́n baà lè mú ìyánhànhàn dàgbà fún un. (1 Peteru 2:2, 3) Bàbá kan sọ pé: ‘Nígbà tí àwọn ọmọ náà ṣì kéré, a ń rákòrò pẹ̀lú wọn a sì ń faraṣàpèjúwe àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀rọ̀ ìtàn tí ó wémọ́ àwọn ènìyàn gbígbajúmọ̀ nínú Bibeli. Àwọn ọmọ náà nífẹ̀ẹ́ sí i.’
13. Kí ni àǹfààní àwọn àkókò ìdánrawò, kí sì ni ohun tí o lè fidánrawò ní àwọn àkókò wọ̀nyí?
13 Àwọn àkókò ìfidánrawò tún ń yọrísí ọ̀rọ̀ àjọsọ ṣíṣeyebíye nítorí pé wọ́n ń ran àwọn ọmọ kékeré lọ́wọ́ láti múrasílẹ̀ fún àwọn ipò tòótọ́ gidi nínú ìgbésí-ayé. Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Kusserow—tí gbogbo wọn tí wọ́n jẹ́ 11 dúró bí olùṣòtítọ́ sí Ọlọrun nígbà inúnibíni Nazi—sọ nípa àwọn òbí rẹ̀ pé: “Wọ́n fi bí a ṣe níláti hùwà àti bí a ṣe níláti fi Bibeli gbèjà araawa hàn wá. [1 Peteru 3:15] Lọ́pọ̀ ìgbà ni a máa ń ní àkókò ìfidánrawò, ní bíbéèrè àwọn ìbéèrè àti fífúnni ní ìdáhùn.” Èéṣe tí ìwọ kò fi ṣe ohun kan náà? Ìwọ lè fi àwọn ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ dánrawò, kí òbí ṣe bí onílé. Tàbí àkókò ìdánrawò náà lè níí ṣe pẹ̀lú àwọn ìdẹwò tòótọ́ gidi nínú ìgbésí-ayé. (Owe 1:10-15) Ẹnìkan ṣàlàyé pé, “Fífi àwọn ipò lílekoko dánrawò lè gbé ìjáfáfá àti ìgbọ́kànlé ọmọ kan ró. Ìdánrawò náà lè ní nínú ṣíṣe bí ọ̀rẹ́ kan tí ń nawọ́ sìgá, ọtí, tàbí oògùn sí ọmọ rẹ.” Àwọn àkókò wọ̀nyí lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fòyemọ bí ọmọ rẹ yóò ṣe dáhùnpadà nínú irú àwọn ipò bẹ́ẹ̀.
14. Èéṣe tí àwọn ìjíròrò onífẹ̀ẹ́ àti oníyọ̀ọ́nú pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ fi ṣe pàtàkì tóbẹ́ẹ̀?
14 Nígbà tí o bá ń ní ọ̀rọ̀ àjọsọ pẹ̀lú ọmọ rẹ, fọ̀rànlọ̀ ọ́ ní irú ọ̀nà oníyọ̀ọ́nú kan náà gẹ́gẹ́ bí òǹkọ̀wé àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ti ṣe: “Ọmọ mi, máṣe gbàgbé òfin mi; sì jẹ́ kí àyà rẹ kí ó pa òfin mi mọ́. Nítorí ọjọ́ gígùn, àti ẹ̀mí gígùn, àti àlááfíà ni wọn ó fi kún un fún ọ.” (Owe 3:1, 2) Kì yóò ha wọ ọmọ rẹ lọ́kàn ṣinṣin bí o bá fi tìfẹ́tìfẹ́ ṣàlàyé pé o ń béèrè fún ìgbọràn nítorí pé èyí yóò yọrísí àlááfíà àti ọjọ́ gígùn fún un—ní tòótọ́, ìyè ayérayé nínú ayé titun alálàáfíà ti Ọlọrun? Fi àkópọ̀ ìwà àwọn ọmọ rẹ kékeré sọ́kàn bí o ti ń bá wọn ronú láti inú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Ṣe èyí tàdúràtàdúrà, Jehofa yóò sì bùkún ìsapá rẹ. Irú ìjíròrò onífẹ̀ẹ́ àti oníyọ̀ọ́nú bẹ́ẹ̀ tí a gbékarí Bibeli ni ó ṣeéṣe kí ó ní ìyọrísí rere kí ó sì mú àwọn àǹfààní tí ó tọ́jọ́ wá.—Owe 22:6.
15. Báwo ni àwọn òbí ṣe lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti yanjú àwọn ìṣòro?
15 Kódà bí irú ọ̀rọ̀ àjọsọ bẹ́ẹ̀ kò bá wáyé ní àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ yín tí ẹ wéwèé, ẹ máṣe jẹ́ kí àwọn ọ̀ràn mìíràn pín ọkàn yín níyà. Ẹ fetísílẹ̀ dáradára sí ọ̀nà tí ọmọ yín gbà sọ èrò rẹ̀ jáde, kìí ṣe sí ohun tí ó sọ nìkan. Ògbógi kan sọ pé, “Wo ọmọ rẹ. Fún un ní àfiyèsí rẹ kíkún. O gbọ́dọ̀ lóye, kìí wulẹ̀ ṣe láti gbọ́. Àwọn òbí tí wọ́n bá ṣe àkànṣe ìsapá yẹn lè mú ìyàtọ̀ ńláǹlà wá nínú ìgbésí-ayé àwọn ọmọ wọn.” Àwọn ọmọ lónìí sábà máa ń ṣalábàápàdé àwọn ìṣòro lílekoko ní ilé-ẹ̀kọ́ àti níbòmíràn. Gẹ́gẹ́ bí òbí, jẹ́ kí ọmọ náà sọ ti inú rẹ̀ jáde, kí o sì ràn án lọ́wọ́ láti wo àwọn ọ̀ràn bí Ọlọrun yóò ti wò ó. Bí ọ̀nà àtiyanjú àwọn ìṣòro kò bá dá ọ lójú, ṣe ìwádìí jinlẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́ àti àwọn ìtẹ̀jáde tí a pèsè nípasẹ̀ “olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú náà.” (Matteu 24:45, NW) Ní gbogbo ọ̀nà pátá, fún ọmọ rẹ ní gbogbo àfiyèsí àrà-ọ̀tọ̀ tí ó nílò láti yanjú ìṣòro náà.
Ṣìkẹ́ Àkókò tí Ẹ Lò Papọ̀
16, 17. (a) Èéṣe tí àwọn ọ̀dọ́ ní pàtàkì fi nílò àfiyèsí àrà-ọ̀tọ̀ àti ìtọ́ni lónìí? (b) Kí ni àwọn ọmọ níláti mọ̀ nígbà tí àwọn òbí wọn bá bá wọn wí?
16 Àwọn ọ̀dọ́ nílò àfiyèsí àrà-ọ̀tọ̀ púpọ̀ síi lónìí ju ti ìgbàkígbà rí lọ nítorí pé a ń gbé ní “ìkẹyìn ọjọ́,” ìwọ̀nyí sì jẹ́ “ìgbà ewu.” (2 Timoteu 3:1-5; Matteu 24:3-14) Àwọn òbí àti àwọn ọmọ bákan náà nílò ààbò tí ọgbọ́n tòótọ́ tí ń “fi ìyè fún àwọn tí ó ní in” mú kí ó ṣeéṣe. (Oniwasu 7:12) Níwọ̀n bí ọgbọ́n Ọlọrun ti wémọ́ ìfisílò ìmọ̀ tí a gbékarí Bibeli lọ́nà yíyẹ, àwọn ọmọ nílò ìtọ́ni déédéé nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Nítorí náà, kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ kékeré. Sọ fún wọn nípa Jehofa, fìṣọ́ra ṣàlàyé àwọn ohun tí ó béèrè fún, kí o sì jẹ́ kí wọ́n ní ìfojúsọ́nà aláyọ̀ fún ìmúṣẹ àwọn ìlérí rẹ̀ títóbilọ́lá. Sọ̀rọ̀ nípa irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ nínú ilé, bí o ti ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ ní ẹ̀gbẹ́ rẹ—nítòótọ́, ní gbogbo àkókò bíbáamuwẹ́kú.—Deuteronomi 6:4-7.
17 Àwọn àgbẹ̀ mọ̀ pé kìí ṣe gbogbo ohun ọ̀gbìn ní ń hù dáradára lábẹ́ àwọn ipò kan náà. Àwọn ohun ọ̀gbìn nílò àbójútó àrà-ọ̀tọ̀. Bákan náà, ọmọ kọ̀ọ̀kan ni ó yàtọ̀síra tí wọ́n sì nílò àfiyèsí, ìtọ́ni, àti ìbáwí àrà-ọ̀tọ̀. Fún àpẹẹrẹ, wíwò tí òbí kan bá wo ọmọdé lọ́nà tí kò fi ìtẹ́wọ́gbà hàn lè ti tó láti dá ìgbésẹ̀ òdì tí ọ̀dọ́ kan fẹ́ láti gbé dúró, nígbà tí ó jẹ́ pé ọmọ mìíràn yóò nílò ìbáwí tí ó túbọ̀ lágbára. Ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ọmọ rẹ níláti mọ ìdí rẹ̀ tí inú rẹ kò fi dùn sí àwọn ọ̀rọ̀ tàbí ìgbésẹ̀ kan pàtó, àwọn òbí méjèèjì sì níláti fọwọ́sowọ́pọ̀ kí ó baà lè jẹ́ pé ìbáwí wọn wà ní ìṣọ̀kan. (Efesu 6:4) Ó ṣe pàtàkì níti gidi gan-an pé kí àwọn òbí tí wọ́n jẹ́ Kristian fúnni ní ìtọ́sọ́nà ṣíṣe kedere tí ó wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Ìwé Mímọ́.
18, 19. Ẹrù-iṣẹ́ wo ni àwọn Kristian òbí ní fún àwọn ọmọ wọn, kí ni ó sì ṣeéṣe kí ó ṣẹlẹ̀ bí wọ́n bá ṣe iṣẹ́ yẹn dáradára?
18 Àgbẹ̀ kan gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ gbígbìn àti ríroko ní àkókò yíyẹ. Bí ó bá fi ọ̀ràn falẹ̀ tàbí tí ó ṣàìnáání irúgbìn rẹ̀, agbára káká ni yóò fi rí ohunkóhun kórè. Ó dárá, àwọn ọmọ rẹ kékeré jẹ́ “àwọn ohun ọ̀gbìn” tí ń dàgbà tí ó nílò àfiyèsí àrà-ọ̀tọ̀ nísinsìnyí gan-an, kìí ṣe ní oṣù tàbí ní ọdún tí ń bọ̀. Máṣe jẹ́ kí àwọn àǹfààní ṣíṣeyebíye fò ọ́ dá láti mú ìgbéga débá ìdàgbà tẹ̀mí wọn ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun àti láti tu èpò àwọn ìrònú ti ayé tí ó lè mú kí wọ́n rọ kí wọ́n sì kú nípa tẹ̀mí kúrò nínú wọn. Ṣìkẹ́ àwọn wákàtí àti ọjọ́ tí o bá ní àǹfààní láti lò pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ, nítorí pé àwọn àkókò wọ̀nyí máa ń yára kọjá lọ. Ṣiṣẹ́ kára láti mú àwọn ànímọ́ Ọlọrun tí wọ́n nílò fún ìgbésí-ayé aláyọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ olùṣòtítọ́ fún Jehofa dàgbà nínú wọn. (Galatia 5:22, 23; Kolosse 3:12-14) Èyí kìí ṣe iṣẹ́ ẹlòmíràn kan; iṣẹ́ rẹ ni, Ọlọrun sì lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe é.
19 Fún àwọn ọmọ rẹ ní ogún-ìní dídọ́ṣọ̀ nípa tẹ̀mí. Kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun pẹ̀lú wọn, kí o sì gbádùn eré-ìtura gbígbámúṣé pẹ̀lú wọn. Mú àwọn ọmọ rẹ kékeré lọ sí àwọn ìpàdé Kristian, kí o sì mú wọn dání lọ sẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba. Mú irú ìwà ànímọ́ tí ó ṣètẹ́wọ́gbà lójú Jehofa dàgbà nínú àwọn ọmọ rẹ olùfẹ́, ó sì ṣeéṣe jùlọ pé kí wọ́n mú ayọ̀ ńlá wá fún ọ nínú ìgbésí-ayé wọn lẹ́yìnwá ọ̀la. Nítòótọ́, “bàbá olódodo ni yóò yọ̀ gidigidi: ẹni tí ó sì bí ọmọ ọlọgbọ́n, yóò ní ayọ̀ nínú rẹ̀. Bàbá rẹ àti ìyá rẹ yóò yọ̀, inú ẹni tí ó bí ọ yóò dùn.”—Owe 23:24, 25.
Èrè Dídọ́ṣọ̀
20. Kí ni kọ́kọ́rọ́ náà sí jíjẹ́ òbí aláṣeyọrísírere fún àwọn ọmọ tí kò tíì pé ogún ọdún?
20 Títọ́ àwọn ọmọ jẹ́ iṣẹ́ àyànfúnni dídíjú, tí ń gba àkókò gígùn. Títọ́ àwọn ‘igi ólífì tí ó yí tábìlì rẹ ká’ wọ̀nyí dàgbà láti di àwọn àgbàlagbà olùbẹ̀rù Ọlọrun tí wọ́n ń so èso Ìjọba náà ni a ti pè ní ìdáwọ́lé oní-20 ọdún. (Orin Dafidi 128:3; Johannu 15:8) Ìdáwọ́lé yìí sábà máa ń lekoko síi nígbà tí àwọn ọmọ kò bá tíì pé ogún ọdún, nígbà tí àwọn ìkìmọ́lẹ̀ tí ń bẹ lórí wọn sábà máa ń pọ̀ síi tí àwọn òbí sì máa ń rí i gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó pọndandan láti mú ìsapá wọn pọ̀ síi. Ṣùgbọ́n kọ́kọ́rọ́ náà sí àṣeyọrísírere ṣì jẹ́ ọ̀kan náà síbẹ̀—jíjẹ́ olùtẹ́tísílẹ̀, ọlọ́yàyà, àti olóye. Rántí pé àwọn ọmọ rẹ nílò àfiyèsí ara-ẹni níti gidi. O lè fún wọn ní irú àfiyèsí bẹ́ẹ̀ nípa fífi ojúlówó àníyàn onífẹ̀ẹ́ hàn fún ire wọn. Láti ràn wọ́n lọ́wọ́, o gbọ́dọ̀ lo ara rẹ nípa pípèsè àkókò, ìfẹ́, àti àníyàn tí wọ́n nílò níti gidi.
21. Kí ni ó lè jẹ́ èrè náà fún fífún àwọn ọmọ ní àfiyèsí àrà-ọ̀tọ̀?
21 Èrè náà fún ìsapá rẹ láti bójútó ìṣùpọ̀ èso ṣíṣeyebíye tí Jehofa ti fisíkàáwọ́ rẹ lè mú ìtẹ́lọ́rùn wá lọ́pọ̀lọpọ̀ ju ìkórè yanturu ti àgbẹ̀ èyíkéyìí lọ. (Orin Dafidi 127:3-5) Wàyí o, nígbà náà ẹ̀yin òbí ẹ máa báa lọ láti fún àwọn ọmọ yín ní àfiyèsí àrà-ọ̀tọ̀. Ẹ ṣe bẹ́ẹ̀ fún ire wọn àti ògo Baba wa ọ̀run, Jehofa.
Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?
◻ Báwo ni a ṣe lè fi títọ́ àwọn ohun ọ̀gbìn àti títọ́ àwọn ọmọ dàgbà wéra?
◻ Irú àfiyèsí wo ni ó yẹ kí ọmọ kan rígbà lójoojúmọ́ láti ìgbà ọmọdé jòjòló?
◻ Àbójútó àrà-ọ̀tọ̀ wo ni àwọn ọmọ nílò, báwo sì ni a ṣe lè fi í fúnni?
◻ Èéṣe tí ó fi yẹ kí o fún àwọn ọmọ rẹ ní àfiyèsí àrà-ọ̀tọ̀?