Lo Ẹ̀mí Ìtọpinpin Rẹ Lọ́nà Tó Tọ́
“Àwa èèyàn jẹ́ ẹ̀dá tó máa ń béèrè ìbéèrè. Látìgbà tí wọ́n ti bí wa la ti máa ń bẹ̀rẹ̀ sí í béèrè àwọn ìbéèrè . . . A tiẹ̀ lè kúkú sọ pé àtìgbà téèyàn ti dáyé ni ìbéèrè àti ìdáhùn ti wà.” —Akéwì ọmọ ilẹ̀ Mẹ́síkò tó ń jẹ́ Octavio Paz.
KÍ LÓ ń mú kí alásè ronú àrà míì tó máa fi oúnjẹ dá? Kí ló ń mú káwọn olùṣàwárí gbéra ìrìn àjò lọ síbi tó jìnnà réré tí wọn kò mọ̀ rí? Kí ló ń mú kí ọmọ kan máa béèrè oríṣiríṣi ìbéèrè? Ẹ̀mí ìtọpinpin ló sábà máa ń fà á.
Ìwọ ńkọ́? Ṣé àwọn èrò míì tó yàtọ̀ sí ti tẹ́lẹ̀ tàbí wíwá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè tó jọni lójú máa ń mú kó o fẹ́ tọ pinpin nǹkan? Bí àpẹẹrẹ, látìgbà tá a ti wà lọ́mọdé lẹ̀mí ìtọpinpin ti ń mú ká béèrè àwọn ìbéèrè bíi: Báwo làwọn ohun alààyè ṣe wáyé? Kí nìdí tá a fi wà láyé? Ǹjẹ́ Ọlọ́run wà? A sì tún máa ń fẹ́ mọ ìdí táwọn nǹkan fi ń ṣẹlẹ̀. Tí èrò kan bá jọ wá lójú, a máa ń sapá láti ṣe gbogbo ìwádìí tá a bá lè ṣe nípa rẹ̀. Nítorí náà, títọ pinpin nǹkan lè jẹ́ kéèyàn mọ ọ̀pọ̀ ohun tó yani lẹ́nu. Àmọ́ ṣá o, ó tún lè kó èèyàn sí ìjàngbọ̀n tàbí kò tiẹ̀ dá wàhálà sílẹ̀.
Ó Gba Ìṣọ́ra àti Ìwọ̀ntúnwọ̀nsì
Ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ nínú wa ló ti gbọ́ òwe kan tó sọ pé: Ẹni tó bá ń wá ìwákúwàá, á rí ìríkúrìí. Tó fi hàn pé ewu wà nínú títọ pinpin nǹkan tí kò tọ́. Bí àpẹẹrẹ, ìtọpinpin lè mú kí ọmọ kan lọ tọwọ́ bọ iná, èyí á sì pa á lára. Ní ìdà kejì, títọ pinpin nǹkan lè jẹ́ kí ìmọ̀ wa pọ̀ sí i, ká sì tún rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè tó ń jẹ wá lọ́kàn. Ṣùgbọ́n, ṣé ó mọ́gbọ́n dání ká kàn máa tọ pinpin ohunkóhun tó bá ṣáà ti ṣe wá ní kàyéfì?
Ó dájú pé àwọn ohun kan wà tí kò yẹ ká wá ọ̀nà àtimọ̀, torí pé ó léwu fún wa. Bí àpẹẹrẹ, kò yẹ kí ẹ̀mí ìtọpinpin gbé èèyàn débi wíwo àwòrán oníṣekúṣe, ṣíṣèwádìí nípa ẹgbẹ́ òkùnkùn tàbí ẹ̀kọ́ àwọn agbawèrèmẹ́sìn nítorí wọ́n jẹ́ ohun tó lè kó wa sí yọ́yọ́. Lórí irú nǹkan báwọ̀nyí àtàwọn míì, á dára ká máa fara wé onísáàmù kan tó gbàdúrà pé: “Mú kí ojú mi kọjá lọ láìrí ohun tí kò ní láárí.”—Sáàmù 119:37.
Bákan náà, àwọn ohun kan wà tí kò burú láti mọ̀, àmọ́ tí kò pọn dandan láti mọ̀, tó sì jẹ́ fífi àkókò ẹni ṣòfò. Àbí, àǹfààní wo ló wà nínú wíwá fìn-ín ìdí kókò nípa gbajúmọ̀ òṣèré orí ìtàgé kan tàbí ẹni olókìkí kan, fífẹ́ láti máa mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ẹgbẹ́ eléré ìdárayá kan tàbí nípa èèyàn kan tó jẹ́ eléré ìdárayá, tàbí kéèyàn fẹ́ máa mọ gbogbo nǹkan nípa ohun èèlò abánáṣiṣẹ́ tàbí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe jáde? Ọ̀pọ̀ èèyàn ni mímọ tìfun-tẹ̀dọ̀ nǹkan wọ̀nyí kì í ṣe láǹfààní kankan.
Àpẹẹrẹ Rere Kan
Síbẹ̀, títọ pinpin nǹkan ṣì láǹfààní tirẹ̀. Wo ọ̀ràn ọ̀gbẹ́ni ọmọ ilẹ̀ Jámánì kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Alexander von Humboldt, tó gbáyé ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún. Ó jẹ́ olùṣàwárí àti onímọ̀ nípa ìṣẹ̀dá, orúkọ rẹ̀ sì ni wọ́n fi sọ ìgbì òkun kan tí wọ́n ń pè ní Humboldt Current tó máa ń wà nítòsí etíkun ìwọ̀ oòrùn Amẹ́ríkà ti Gúúsù.
Nígbà kan Humboldt sọ pé: “Láti kékeré mi ló ti máa ń wù mí gan-an láti rìnrìn àjò lọ sáwọn agbègbè tó jìnnà réré, táwọn ará Yúróòpù kì í fi bẹ́ẹ̀ lọ.” Ó wá sọ ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀, ó ní “ó jẹ́ ohun tọ́kàn mi máa ń fà sí lemọ́lemọ́.” Nígbà tó wà ní ọmọ ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n, ó rìnrìn àjò ìwádìí kan tó gba ọdún márùn-un lọ sí Amẹ́ríkà Àárín àti Amẹ́ríkà ti Gúúsù. Ó ṣàkójọ àwọn ohun tó rí nígbà ìrìn àjò rẹ̀ sínú àwọn ìwé tó tó ọgbọ̀n ìdìpọ̀.
Gbogbo ohun tí ọ̀gbẹ́ni Humboldt rí ló kọ sílẹ̀, títí kan ìgbóná-òun-ìtutù òkun, àwọn ẹja tó ń gbénú òkun, àtàwọn irúgbìn tó rí lọ́nà. Ó gun àwọn òkè, ó wo àwọn odò lóríṣiríṣi, ó sì tún rìnrìn àjò lórí onírúurú agbami òkun. Ìwádìí tí ọ̀gbẹ́ni Humboldt ṣe ló sì jẹ́ ìpìlẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ẹ̀ka ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì òde òní. Ẹ̀mí ìtọpinpin tí ọ̀gbẹ́ni Humboldt ní ló sì bẹ̀rẹ̀ gbogbo rẹ̀, èyí tó wá sọ ọ́ dẹni tó ń fi gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀ wá àfikún ìmọ̀ kiri. Òǹkọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà kan tó ń jẹ́ Ralph Waldo Emerson sọ̀rọ̀ nípa ọ̀gbẹ́ni yìí, ó ní: “Humboldt jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àkàndá èèyàn inú ayé . . . tọ́rọ̀ rẹ̀ máa ń jẹ yọ látìgbàdégbà, èyí tó ń jẹ́ ká mọ bí ọpọlọ àti ọkàn èèyàn ṣe lágbára tó àtohun tí wọ́n lè gbé ṣe.”
Ohun Kan Tó Yẹ Ká Ṣèwádìí
Ó dájú pé ìwọ̀nba kéréje nínú wa ló máa lè dẹni tó ń ṣèwádìí káàkiri ayé tàbí ká ṣàwárí ohun kan tó máa jẹ́ ẹ̀kọ́ fáwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì. Àmọ́, ohun pàtàkì kan wà tó gba pé kéèyàn sapá kó tó lè mọ̀ ọ́n, tó sì lérè nínú ju èyí tá a máa rí nínú ṣíṣe ohunkóhun mìíràn. Jésù Kristi jẹ́ ká mọ ohun tó jẹ́ nínú àdúrà kan tó gbà sí Bàbá rẹ̀ ọ̀run. Ó ní: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.”—Jòhánù 17:3.
Téèyàn bá ṣèwádìí tó sì ní ìmọ̀ Ọlọ́run tòótọ́, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ Jésù Kristi, ìyẹn yóò ṣàǹfààní ju èyí téèyàn lè rí nínú ṣíṣe ohunkóhun mìíràn lọ. Ǹjẹ́ o rántí ìbéèrè nípa bí ohun alààyè ṣe wáyé tó wà ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí? Láfikún sáwọn ìbéèrè yẹn, a tún lè béèrè pé: Kí nìdí tí ìyà tó ń jẹ aráyé fi pọ̀ tó báyìí? Ṣé àwọn èèyàn máa pa ayé run pátápátá ni? Àbí kí ni Ọlọ́run máa ṣe tírú nǹkan bẹ́ẹ̀ kò fi ní ṣẹlẹ̀? Àmọ́ ṣá o, rírí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yẹn ju pé èèyàn kàn ń tọ pinpin láti mọ nǹkan kan lásán lọ. Jésù sọ pé yóò jẹ́ ká ní “ìyè àìnípẹ̀kun.” Báwo nìyẹn ṣe dá wa lójú?
Bíbélì jẹ́ Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sì sọ nípa Bíbélì pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́, fún bíbániwí nínú òdodo, kí ènìyàn Ọlọ́run lè pegedé ní kíkún, tí a mú gbára dì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.”—2 Tímótì 3:16, 17.
Rò ó wò ná, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé, Bíbélì ń jẹ́ ká ní ìmọ̀ tó lè mú wa gbára dì tàbí tó lè jẹ́ ká dẹni tó ń ṣe iṣẹ́ rere gbogbo. Ó lè jẹ́ káwa náà máa firú ojú tí Ọlọ́run fi ń wo àwọn nǹkan wò wọ́n. A sì mọ̀ pé ìmọ̀ àti ọgbọ́n Ọlọ́run ju tàwa ẹ̀dá lọ fíìfíì. Ọlọ́run mí sí wòlíì Aísáyà láti kọ ọ̀rọ̀ pàtàkì yìí: “‘Ìrònú yín kì í ṣe ìrònú mi, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi kì í ṣe ọ̀nà yín,’ ni àsọjáde Jèhófà. ‘Nítorí gẹ́gẹ́ bí ọ̀run ti ga ju ilẹ̀ ayé, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi ga ju ọ̀nà yín, bẹ́ẹ̀ sì ni ìrònú mi ga ju ìrònú yín.’”—Aísáyà 55:8, 9.
Ṣé wàá fẹ́ mọ nípa àwọn ọ̀nà àti èrò Ọlọ́run tó ga fíìfíì ju tàwa èèyàn lọ? Ǹjẹ́ ẹ̀mí ìtọpinpin rẹ ń mú kó o wádìí ohun tí Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ nípa àwọn ọ̀nà àti èrò Ọlọ́run? Ṣé ó wù ẹ́ láti kọ́ nípa ohun tí Ọlọ́run máa ṣe láti fòpin sí gbogbo ìjìyà àti nípa àwọn ohun rere tó máa ṣe fáwọn onígbọràn? Bíbélì rọ̀ ọ́ pé: “Tọ́ ọ wò, kí [o] sì rí i pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere; aláyọ̀ ni abarapá ọkùnrin tí ó sá di í.”—Sáàmù 34:8.
Òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè yí ìgbésí ayé ẹni padà, kó sì jẹ́ kí ojú ẹni là sí ẹ̀kọ́ òtítọ́ bí ìgbà tí afọ́jú bẹ̀rẹ̀ sí í rí ìmọ́lẹ̀. Ìyẹn ló mú kí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù polongo pé: “Ìjìnlẹ̀ àwọn ọrọ̀ àti ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run mà pọ̀ o! Àwọn ìdájọ́ rẹ̀ ti jẹ́ àwámáridìí tó, àwọn ọ̀nà rẹ̀ sì ré kọjá àwákàn!” (Róòmù 11:33) Ohun kan tó dájú ni pé, títí láé la ó máa rí ẹ̀kọ́ kọ́ nípa bí ìmọ̀ àti ọgbọ́n Ọlọ́run ṣe pọ̀ tó. Kò sì ní sú wa rárá nígbà yẹn, torí pé gbogbo ìgbà la ó máa rí nǹkan tuntun kọ́.
Má Ṣe Jẹ́ Kó Pòórá!
Lóòótọ́ ọ̀pọ̀ nínú wa kò ní di olùṣàwárí tó lókìkí tàbí ẹni tó dá nǹkan tuntun sílẹ̀. Bákan náà, ó ṣeé ṣe ká má sì lè mọ gbogbo ohun tó wù wá láti mọ̀ níwọ̀nba àkókò kúkúrú tá a ń lò láyé yìí. Àmọ́ má tìtorí ìyẹn ṣíwọ́ títọ pinpin ohun tó yẹ. Má sì ṣe jẹ́ kí ìfẹ́ láti ní ìmọ̀, èyí tí Ọlọ́run dá mọ́ wa tìfẹ́tìfẹ́ pòórá lọ́kàn rẹ.
Lo ẹ̀bùn tí Ọlọ́run dá mọ wa yìí dáadáa, kó o jẹ́ kó mú ọ ní ìmọ̀ pípéye nípa Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá láyọ̀ nísinsìnyí, ìgbésí ayé rẹ yóò nítumọ̀, wàá sì tún nírètí àtimáa gbé irú ìgbésí ayé bẹ́ẹ̀ lọ títí láé. Bíbélì sọ pé: “Ohun gbogbo ni [Ọlọ́run] ti ṣe rèterète ní ìgbà tirẹ̀. Àní àkókò tí ó lọ kánrin ni ó ti fi sínú ọkàn-àyà wọn, kí aráyé má bàa rídìí iṣẹ́ tí Ọlọ́run tòótọ́ ti ṣe láé láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin.”—Oníwàásù 3:11.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Ǹjẹ́ O Mọ̀ Pé . . .
• Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ṣáájú kí ọ̀gbẹ́ni Columbus àti Magellan tó sọ pé ńṣe layé rí roboto, ni Bíbélì ti sọ pé ayé yìí kì í ṣe pẹrẹsẹ pé roboto ni?—Aísáyà 40:22.
• Tipẹ́tipẹ́ ṣáájú káwọn tó ń rìnrìn àjò lọ sí gbalasa òfuurufú tó rí i pé kò sí ohunkóhun tó gbé ayé dúró, ni Bíbélì ti sọ pé ayé rọ̀ sórí òfo?—Jóòbù 26:7.
• Nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tàlá [2,500] ọdún ṣáájú kí oníṣègùn ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan tó ń jẹ́ William Harvey tó rí ọ̀nà tí ẹ̀jẹ̀ gbà ń ṣàn kiri inú ara, ni Bíbélì ti sọ pé ọkàn-àyà wa jẹ́ orísun ìyè?—Òwe 4:23.
• Ó ti tó bí ẹgbẹ̀ẹ́dógún [3,000] ọdún báyìí tí Bíbélì ti fi hàn lọ́nà tó rọrùn pé, ìyípoyípo omi jẹ́ ara àwọn ohun tó ń mú kí ohun alààyè lè wà nínú ayé?—Oníwàásù 1:7.
Ẹ ò rí í pé nǹkan àgbàyanu ló jẹ́ pé Bíbélì ti sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tó bá ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì mu yìí tipẹ́tipẹ́ kó tó yé àwọn èèyàn tàbí kí wọ́n tó ṣàwárí wọn? Dájúdájú ọ̀pọ̀ ìṣúra iyebíye tó wúlò fún ìwàláàyè wa ló wà nínú Bíbélì tó yẹ kó o ṣàwárí.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Alexander von Humboldt