‘Wàásù Ọ̀rọ̀ Náà ní Kánjúkánjú’
1 Bóo bá rí ohun kan tí wọ́n kọ “KÁNJÚKÁNJÚ” sára rẹ̀ gbà, ọwọ́ wo lo máa fi mú un? Ọ̀rọ̀ náà, “kánjúkánjú,” túmọ̀ sí pé “ohun náà ń béèrè àbójútó ní kíákíá.” Ìdí rẹ̀ rèé tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi fún àwa Kristẹni nítọ̀ọ́ni pé kí a “wàásù ọ̀rọ̀ náà . . . ní kánjúkánjú.” (2 Tím. 4:2) Ǹjẹ́ o ń gbégbèésẹ̀ nípa bíbójútó iṣẹ́ yìí ní kíákíá?
2 Ó ṣeé ṣe kí wọ́n ti ròyìn fún Pọ́ọ̀lù pé àwọn kan lára àwọn ará fẹ́ máa ‘ṣe ìmẹ́lẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ àmójútó wọn’ gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni. (Róòmù 12:11) Èyí ò jẹ́ kí iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe fi bẹ́ẹ̀ kẹ́sẹ járí, ayọ̀ tí wọ́n sì ń rí láti inú ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ ò fi bẹ́ẹ̀ tó nǹkan.
3 Ojú Tí Jésù Fi Wo Iṣẹ́ Òjíṣẹ́: Jésù mà ní ìdùnnú ńlá nínú ṣíṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ o! Ó wí pé: “Oúnjẹ mi ni kí n ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi àti láti parí iṣẹ́ rẹ̀.” Àpẹẹrẹ Jésù ló sún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣiṣẹ́, ìyẹn àwọn tó fún níṣìírí nípa sísọ fún wọn pé, ‘àwọn pápá ti funfun fún kíkórè.’ (Jòh. 4:34, 35) Ní gbogbo ìgbà tó fi ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà ló fi hàn pé iṣẹ́ náà jẹ́ kánjúkánjú, èyí sì hàn gbangba nígbà tó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n “bẹ Ọ̀gá ìkórè láti rán àwọn òṣìṣẹ́ jáde sínú ìkórè rẹ̀.” (Mát. 9:38) Jésù mọ̀ pé iṣẹ́ tí a yàn fún òun ni pé kí òun wàásù, ó sì pinnu pé òun ò ní jẹ́ kí ohunkóhun dí òun lọ́wọ́ ṣíṣe iṣẹ́ náà.
4 Àwa Ńkọ́? Lónìí, ìjẹ́kánjúkánjúu pé kí a máa bá iṣẹ́ ìwàásù náà nìṣó ti ga ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Lápá ibi púpọ̀ nínú ayé, pápá náà ti tó fún kíkórè. Kódà ní àwọn ilẹ̀ tó dà bíi pé a ti jẹ́rìí dáadáa níbẹ̀, ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn là ń batisí lọ́dọọdún. Bí òpin àwọn nǹkan ìsinsìnyí ṣe ń yára sún mọ́lé, ‘púpọ̀ rẹpẹtẹ ní ń bẹ fún wa láti ṣe nínú iṣẹ́ Olúwa.’ (1 Kọ́r. 15:58) Ju ti ìgbàkígbà rí lọ, ó ṣe kókó pé kí á sakun gan-an ní kíkópa nínú sísọ ìhìn Ìjọba náà fún àwọn ẹlòmíràn.
5 Ẹ jẹ́ ká jẹ́ kọ́wọ́ wa dí fún mímú ìhìn rere náà tọ àwọn ẹlòmíràn lọ, ì báà jẹ́ láti ilé dé ilé tàbí níbikíbi tí a bá ti lè rí àwọn èèyàn ní ìpínlẹ̀ wa. Nípa kíkópa nínú iṣẹ́ ìwàásù dáadáa bí a bá ti lè ṣe é tó, a ń fi hàn ní kedere pé a ti fi Ìjọba náà sí ipò kìíní nínú ìgbésí ayé wa. (Mát. 6:33) Fífi tí a bá ń fi ìjẹ́kánjúkánjú wàásù ọ̀rọ̀ náà láìyẹsẹ̀ yóò mú kí inú wa máa dùn gidigidi.