Kí Ló Lè Ràn Wá Lọ́wọ́ Láti Fi Ọwọ́ Títọ̀nà Mú Òtítọ́?
ỌKÙNRIN kan tó ń bá ilé iṣẹ́ ìwé ìròyìn kan ṣe lámèyítọ́ eré orí ìtàgé lọ wo eré kan báyìí lọ́jọ́ kan. Kò fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí eré náà, ó sì wá kọ̀wé lẹ́yìn náà pé: “Tó bá jẹ́ ohun tí kò ní láárí rárá lo fẹ́ wò, ṣáà lọ wo eré yìí.” Nígbà tó yá, àwọn onígbọ̀wọ́ eré náà polówó rẹ̀, wọ́n sì fa ọ̀rọ̀ yọ látinú ohun tí ẹni tó ń ṣe lámèyítọ́ náà wí. Ohun tí wọ́n fà yọ níbẹ̀ ni pé: “Ṣáà lọ wo eré yìí”! Lóòótọ́, ohun tí ẹni tó ṣe lámèyítọ́ yìí sọ gan-an ni wọ́n fà yọ, àmọ́ wọ́n fà á yọ láìgbé ìdí tí ọ̀rọ̀ náà fi wáyé yẹ̀ wò, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ yí ohun tó ní lọ́kàn padà pátápátá.
Àpẹẹrẹ yẹn jẹ́ ká rí bí wíwo ọ̀rọ̀ tó yí gbólóhùn kan ká ti ṣe pàtàkì tó. Fífa ọ̀rọ̀ yọ láìgbé ohun tó yí i ká yẹ̀ wò lè yí ìtumọ̀ rẹ̀ po, gẹ́gẹ́ bí Sátánì ṣe yí ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́ po nígbà tó ń gbìyànjú láti ṣi Jésù lọ́nà. (Mátíù 4:1-11) Ṣùgbọ́n ńṣe ni gbígbé àyíká gbólóhùn kan yẹ̀ wò ń jẹ́ ká lóye ìtumọ̀ rẹ̀ dáadáa. Nítorí náà, nígbà tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa ẹsẹ Bíbélì kan, ó máa ń mọ́gbọ́n dání láti wo ohun tó yí ẹsẹ náà ká kí a lè lóye ohun tí òǹkọ̀wé náà ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ gan-an.
Fí Ọwọ́ Tí Ó Tọ́ Mú Un
Àyíká ọ̀rọ̀ ń tọ́ka sí àwọn ọ̀rọ̀ tá a kọ tàbí èyí tá a sọ ṣáájú ọ̀rọ̀ tàbí lẹ́yìn ọ̀rọ̀ kan tàbí àyọkà kan pàtó, ó sì sábà máa ń nípa lórí ìtumọ̀ rẹ̀. Àyíká ọ̀rọ̀ tún lè jẹ́ àwọn ipò tàbí àwọn òkodoro òtítọ́ tó yí ìṣẹ̀lẹ̀ kan pàtó, ipò kan pàtó, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ká. Nínú èrò kejì yìí, ohun tó máa jẹ́ ọ̀rọ̀ mìíràn fún “àyíká ọ̀rọ̀” ni “àlàyé ohun tó pilẹ̀ ọ̀rọ̀ kan.” Gbígbé àyíká ọ̀rọ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan yẹ̀ wò ṣe pàtàkì gan-an lójú ìwòye ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sí Tímótì pé: “Sa gbogbo ipá rẹ láti fi ara rẹ hàn fún Ọlọ́run ní ẹni tí a tẹ́wọ́ gbà, aṣiṣẹ́ tí kò ní ohun kankan láti tì í lójú, tí ń fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́.” (2 Tímótì 2:15) Láti lè fi ọwọ́ tí ó tọ́ mú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, a ní láti lóye rẹ̀ dáadáa ká sì máa fòótọ́ ọkàn ṣàlàyé rẹ̀ fáwọn èèyàn lọ́nà tó péye. Ọ̀wọ̀ tá a ní fún Jèhófà, Ẹni tó ni Bíbélì, yóò sún wa láti gbìyànjú láti ṣe bẹ́ẹ̀, gbígbé àyíká ọ̀rọ̀ yẹ̀ wò ni yóò sì jẹ́ ìrànwọ́ pàtàkì.
Ohun Tó Mú Kí Wọ́n Kọ Tímótì Kejì
Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká gbé ìwé Tímótì Kejì nínú Bíbélì yẹ̀ wò.a Ká tó bẹ̀rẹ̀ àyẹ̀wò wa, a lè kọ́kọ́ wádìí ohun tó mú kí wọ́n kọ ìwé náà. Tá ló kọ Tímótì Kejì? Ìgbà wo ló kọ ọ́? Abẹ́ ipò wo ló ti kọ ọ́? Lẹ́yìn náà, a lè béèrè pé, Ipò wo ni “Tímótì” tá a fi orúkọ rẹ̀ pe ìwé náà wà? Èé ṣe tó fi nílò ìsọfúnni tó wà nínú ìwé náà? Ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí yóò jẹ́ ká túbọ̀ mọrírì ìwé náà yóò sì mú ká lè rí bá a ṣe lè jàǹfààní nínú rẹ̀.
Àwọn ẹsẹ tó bẹ̀rẹ̀ Tímótì Kejì fi hàn pé ìwé náà jẹ́ lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sí Tímótì. Àwọn ẹsẹ yòókù fi hàn pé àkókò tí Pọ́ọ̀lù wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n nítorí ìhìn rere ló kọ ọ́. Nítorí pé ọ̀pọ̀ èèyàn ti pa Pọ́ọ̀lù tì, ó ronú pé ọjọ́ ikú òun ti sún mọ́lé. (2 Tímótì 1:15, 16; 2:8-10; 4:6-8 ) Nítorí náà, ó ní láti jẹ́ pé ìgbà kejì tó wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n ní Róòmù ló kọ ìwé náà, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ nǹkan bí ọdún 65 Sànmánì Tiwa. Kété lẹ́yìn ìyẹn ni Nérò dájọ́ ikú fún un.
Ìdí tá a fi kọ Tímótì Kejì nìyẹn o. Síbẹ̀, ó yẹ ká kíyè sí i pé kì í ṣe torí kí Pọ́ọ̀lù lè ro ẹjọ́ àwọn ìṣòro tó ní fún Tímótì ló ṣe kọ̀wé yẹn sí i. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló ń sọ nípa àwọn àkókò líle koko tó ń bẹ níwájú fún Tímótì, tó sì ń gba ọ̀rẹ́ rẹ̀ yìí níyànjú pé kó má ṣe ní ìpínyà ọkàn, kó máa bá a lọ ní “gbígba agbára,” kó sì fi ìtọ́ni Pọ́ọ̀lù tó àwọn ẹlòmíràn létí. Àwọn wọ̀nyí ẹ̀wẹ̀ yóò tóótun tẹ́rùntẹ́rùn láti ran àwọn mìíràn lọ́wọ́. (2 Tímótì 2:1-7) Àpẹẹrẹ àtàtà gbáà nìyí nípa ẹni tí kò mọ tara rẹ̀ nìkan, tí ire àwọn ẹlòmíràn ṣì ń jẹ ẹ́ lógún kódà lákòókò tí nǹkan ò rọgbọ rárá! Ìmọ̀ràn àtàtà ló sì jẹ́ fún àwa náà lóde òní!
Pọ́ọ̀lù pe Tímótì ní “olùfẹ́ ọ̀wọ́n ọmọ.” (2 Tímótì 1:2) Ọ̀pọ̀ ìgbà la fi hàn nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì pe ọ̀dọ́kùnrin náà jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ fún Pọ́ọ̀lù. (Ìṣe 16:1-5; Róòmù 16:21; 1 Kọ́ríńtì 4:17) Ó dà bíi pé Tímótì ti lé lẹ́ni ọgbọ̀n ọdún dáadáa nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà yìí sí i, àmọ́ síbẹ̀ ojú èwe ló fi wò ó. (1 Tímótì 4:12) Àmọ́ ó ti ní àkọsílẹ̀ tó dáa gan-an nípa ìṣòtítọ́ rẹ̀, nítorí pé ó ti ‘sìnrú pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù’ bóyá fún nǹkan bí ọdún mẹ́rìnlá. (Fílípì 2:19-22) Bó tiẹ̀ sì ṣe dà bíi pé Tímótì ṣì jẹ́ ọ̀dọ́ yìí, Pọ́ọ̀lù ní kó máa gba àwọn alàgbà yòókù nímọ̀ràn pé kí wọ́n “má jà lórí ọ̀rọ̀” bí kò ṣe pé kí wọ́n pọkàn pọ̀ sórí àwọn nǹkan pàtàkì, bí ìgbàgbọ́ àti ìfaradà. (2 Tímótì 2:14) Ó tún sọ pé kí Tímótì bójú tó ọ̀ràn yíyan àwọn alábòójútó ìjọ àti àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ sípò. (1 Tímótì 5:22) Àmọ́ ṣá o, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé kò ní ìgboyà tó láti máa lo ọlá àṣẹ tá a gbé lé e lọ́wọ́.—2 Tímótì 1:6, 7.
Ọ̀dọ́ alàgbà náà wá dojú kọ àwọn ìpèníjà líle koko kan. Ọ̀kan lára wọn ni ti àwọn méjì kan, ìyẹn Híméníọ́sì àti Fílétọ́sì, tí wọ́n “ń dojú ìgbàgbọ́ àwọn kan dé,” nípa kíkọ́ni pé “àjíǹde ti ṣẹlẹ̀.” (2 Tímótì 2:17, 18) Ó jọ pé ohun tí wọ́n gbà gbọ́ ni pé kìkì àjíǹde tẹ̀mí ló wà, àti pé ó ti ṣẹlẹ̀ fún àwọn Kristẹni. Ó lè jẹ́ ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ pé àwọn Kristẹni ti kú nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn àmọ́ wọ́n ti di ààyè nípasẹ̀ ẹ̀mí Ọlọ́run ni wọ́n ń fà yọ láìgbé àyíká ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wò. (Éfésù 2:1-6) Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ pé irú ipa àwọn apẹ̀yìndà bẹ́ẹ̀ yóò máa pọ̀ sí i. Ó kọ̀wé pé: “Sáà àkókò kan yóò wà, tí wọn kò ní gba ẹ̀kọ́ afúnni-nílera, . . . wọn yóò sì yí etí wọn kúrò nínú òtítọ́, nígbà tí ó jẹ́ pé a óò mú wọn yà sínú ìtàn èké.” (2 Tímótì 4:3, 4) Ìkìlọ̀ tí Pọ́ọ̀lù ṣe ṣáájú àkókò yẹn fi hàn pé ó jẹ́ ọ̀ràn kánjúkánjú fún Tímótì láti kọbi ara sí ìmọ̀ràn àpọ́sítélì náà.
Ìjẹ́pàtàkì Ìwé Náà Lóde Òní
Látinú ohun tá a ti ń sọ bọ̀, a rí i pé lára ìdí tí Pọ́ọ̀lù fi kọ Tímótì Kejì rèé: (1) Ó mọ̀ pé òun ò ní pẹ́ kú mọ́, ó sì gbìyànjú láti múra Tímótì sílẹ̀ de àkókò tí òun ò ní wà láàyè mọ́ láti máa fún Tímótì níṣìírí. (2) Ó fẹ́ múra Tímótì sílẹ̀ kó lè dáàbò bo àwọn ìjọ tó wà lábẹ́ àbójútó rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìpẹ̀yìndà àti àwọn ipa búburú mìíràn. (3) Ó fẹ́ gba Tímótì níyànjú pé kó jẹ́ kí ọwọ́ rẹ̀ dí nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, kó sì gbára lé ìmọ̀ pípéye nípa Ìwé Mímọ́ tó ní ìmísí bó ti ń gbógun ti ẹ̀kọ́ èké.
Mímọ ohun tó pilẹ̀ ìwé Tímótì Kejì yìí ń jẹ́ ká túbọ̀ lóye ìtumọ̀ ìwé yẹn. Bákan náà ni àwọn apẹ̀yìndà bíi Híméníọ́sì àti Fílétọ́sì ṣe wà lóde òní, tí wọ́n ń sọ èrò ti ara wọn káàkiri láti lè fi dojú ìgbàgbọ́ wa dé. Ìyẹn nìkan kọ́, “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” tí Pọ́ọ̀lù sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀ ti dé báyìí. Ọ̀pọ̀ ló ti rí i pé òótọ́ pọ́ńbélé ni ìkìlọ̀ tí Pọ́ọ̀lù fúnni pé: “Gbogbo àwọn tí ń ní ìfẹ́-ọkàn láti gbé pẹ̀lú fífọkànsin Ọlọ́run ní ìbákẹ́gbẹ́ pẹ̀lú Kristi Jésù ni a ó ṣe inúnibíni sí pẹ̀lú.” (2 Tímótì 3:1, 12) Báwo la ṣe lè dúró gbọn-in? Bíi ti Tímótì, a gbọ́dọ̀ máa kọbi ara sí ìmọ̀ràn àwọn tó ti sin Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún. Àti pé, nípa ìdákẹ́kọ̀ọ́, àdúrà, àti ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ Kristẹni a lè “máa bá a nìṣó ní gbígba agbára” nípasẹ̀ inú rere Jèhófà tí a kò lẹ́tọ̀ọ́ sí. Síwájú sí i, pẹ̀lú ìgbọ́kànlé nínú agbára ìmọ̀ pípéye, a lè kọbi ara sí ọ̀rọ̀ ìyànjú tí Pọ́ọ̀lù fúnni pé: ‘Kí a máa di àpẹẹrẹ àwọn ọ̀rọ̀ afúnni-nílera mú.’—2 Tímótì 1:13.
“Àpẹẹrẹ Àwọn Ọ̀rọ̀ Afúnni-Nílera”
Kí ni “àwọn ọ̀rọ̀ afúnni-nílera” tí Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kàn? Àwọn ẹ̀kọ́ Kristẹni tòótọ́ ló fi gbólóhùn yẹn tọ́ka sí. Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ́kọ́ kọ sí Tímótì, ó ṣàlàyé pé “àwọn ọ̀rọ̀ afúnni-nílera” jẹ́ ọ̀rọ̀ “ti Olúwa wa Jésù Kristi” ní pàtàkì. (1 Tímótì 6:3) Títẹ̀lé àpẹẹrẹ àwọn ọ̀rọ̀ afúnni-nílera máa ń jẹ́ kéèyàn ní èrò inú yíyè kooro, ìṣarasíhùwà onífẹ̀ẹ́ àti ẹ̀mí ìgbatẹnirò fún àwọn ẹlòmíràn. Níwọ̀n bí iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti àwọn ẹ̀kọ́ Jésù ti wà níbàámu pẹ̀lú gbogbo ẹ̀kọ́ mìíràn tó wà nínú Bíbélì, gbólóhùn náà “àwọn ọ̀rọ̀ afúnni-nílera” lè tọ́ka sí gbogbo ẹ̀kọ́ inú Bíbélì lápapọ̀.
Àpẹẹrẹ àwọn ọ̀rọ̀ afúnni-nílera jẹ́ “ohun ìtọ́júpamọ́ àtàtà” tó yẹ kí Tímótì, àti gbogbo Kristẹni alàgbà pẹ̀lú, máa ṣọ́. (2 Tímótì 1:13, 14) Tímótì yóò ní láti máa ‘wàásù ọ̀rọ̀ náà, kó wà lẹ́nu rẹ̀ ní kánjúkánjú ní àsìkò tí ó rọgbọ, ní àsìkò tí ó kún fún ìdààmú, kó fi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, kó báni wí kíkankíkan, kó gbani níyànjú, pẹ̀lú gbogbo ìpamọ́ra àti ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́.’ (2 Tímótì 4:2) Tá a bá rántí pé ẹ̀kọ́ àwọn apẹ̀yìndà tàn kálẹ̀ nígbà ayé Tímótì, ìdí tí Pọ́ọ̀lù fi tẹnu mọ́ ìjẹ́kánjúkánjú fífi àwọn ọ̀rọ̀ afúnni-nílera kọ́ni á yé wa. A tún rí i pé Tímótì yóò ní láti dáàbò bo agbo nípa ‘fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, bíbáni wí kíkankíkan, gbígbani níyànjú’ pẹ̀lú ìpamọ́ra, kó sì máa lo ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tó gbéṣẹ́.
Àwọn wo ni Tímótì máa wàásù ọ̀rọ̀ náà fún? Àyíká ọ̀rọ̀ náà fi hàn pé Tímótì tó jẹ́ alàgbà yóò wàásù ọ̀rọ̀ náà nínú ìjọ Kristẹni. Nítorí báwọn alátakò ṣe ń gbógun, Tímótì ní láti dúró gbọn-in nípa tẹ̀mí, kó sì máa fi ìgboyà sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, dípò kó máa sọ ìmọ̀ ọgbọ́n orí àwọn èèyàn, tàbí èrò ti ara rẹ̀, tàbí àwọn ìméfò tí kò ní láárí. Lóòótọ́, èyí lè fa àtakò látọ̀dọ̀ àwọn kan tí wọ́n ní èrò òdì. (2 Tímótì 1:6-8; 2:1-3, 23-26; 3:14, 15) Àmọ́, bí Tímótì bá ti ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù, yóò máa dènà ìpẹ̀yìndà, gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù alára ti ṣe.—Ìṣe 20:25-32.
Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ nípa wíwàásù ọ̀rọ̀ náà kan ti wíwàásù níbòmíràn yàtọ̀ sí inú ìjọ? Bẹ́ẹ̀ ni o, gẹ́gẹ́ bí ohun tí àyíká ọ̀rọ̀ náà fi hàn. Pọ́ọ̀lù tún ń bá a lọ láti sọ pé: “Àmọ́ ṣá o, ìwọ, máa pa agbára ìmòye rẹ mọ́ nínú ohun gbogbo, jìyà ibi, ṣe iṣẹ́ ajíhìnrere, ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ ní kíkún.” (2 Tímótì 4:5) Jíjíhìnrere, ìyẹn wíwàásù ìhìn rere ìgbàlà fáwọn aláìgbàgbọ́, jẹ́ apá pàtàkì nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni. (Mátíù 24:14; 28:19, 20) Gan-an gẹ́gẹ́ bá a ṣe ń wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nínú ìjọ, kódà ní “àsìkò tí ó kún fún ìdààmú,” bẹ́ẹ̀ náà la ṣe ń tẹra mọ́ wíwàásù ọ̀rọ̀ náà fáwọn tó wà lẹ́yìn òde ìjọ, kódà lábẹ́ àwọn ipò líle koko.—1 Tẹsalóníkà 1:6.
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ní ìmísí la gbé gbogbo ìwàásù àti ìkọ́ni wa kà. A ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú Bíbélì. Pọ́ọ̀lù sọ fún Tímótì pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́, fún bíbániwí nínú òdodo.” (2 Tímótì 3:16) A sábà máa ń ṣàyọlò ọ̀rọ̀ yẹn bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ láti fi hàn pé Bíbélì jẹ́ Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí. Àmọ́ kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi kọ ọ̀rọ̀ yìí?
Alàgbà kan ni Pọ́ọ̀lù ń bá sọ̀rọ̀, ìyẹn alàgbà tó jẹ́ pé ojúṣe rẹ̀ ni láti ‘fi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, láti mú àwọn nǹkan tọ́, kó sì báni wí nínú òdodo,’ nínú ìjọ. Nítorí ìdí èyí, ńṣe ló ń rán Tímótì létí pé kó gbẹ́kẹ̀ lé ọgbọ́n tó wà nínú Ọ̀rọ̀ onímìísí, tá a ti fi tọ́ Tímótì sọ́nà láti ìgbà ọmọdé. Àwọn ìgbà mìíràn wà táwọn alàgbà bíi Tímótì ní láti bá àwọn oníwà àìtọ́ wí. Nígbà tí wọ́n bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n gbọ́dọ̀ máa ní ìgbọ́kànlé nínú Bíbélì. Àti pé, níwọ̀n bí Ìwé Mímọ́ ti jẹ́ èyí tí Ọlọ́run mí sí, gbogbo ìbáwí tó wà nínú rẹ̀ ló jẹ́ ìbáwí látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ìmọ̀ràn onímìísí tó wá látọ̀dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀ ni ẹnikẹ́ni tó bá kọ ìbáwí tá a gbé karí Bíbélì ń fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn kì í ṣe èrò ènìyàn.
Ẹ ò rí i bí ìwé Tímótì Kejì ṣe kún fún ọgbọ́n Ọlọ́run tó! Ẹ sì tún wò bí ìtumọ̀ rẹ̀ ṣe túbọ̀ ṣe kedere sí i nígbà tá a gbé e yẹ̀ wò pa pọ̀ mọ́ ìdí tí Pọ́ọ̀lù fi kọ ọ́! Nínú àpilẹ̀kọ yìí, ńṣe la kàn yẹ àgbàyanu ìsọfúnni onímìísí tó wà nínú ìwé yìí wò díẹ̀. Àmọ́ ìyẹn ti fún wa ni ẹ̀rí tó pọ̀ tó láti mọ bó ti ṣèrànwọ́ tó láti máa gbé àyíká ọ̀rọ̀ ohun tá a bá kà nínú Bíbélì yẹ̀ wò. Ìyẹn yóò ràn wá lọ́wọ́ láti rí i pé a dìídì “ń fi ọwọ́ tí ó tọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́ náà.”
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún àfikún ìsọfúnni, wo ìwé Insight on the Scriptures, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde, Ìdìpọ̀ Kejì, ojú ìwé 1105 sí 1108.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Pọ́ọ̀lù fẹ́ mú Tímótì gbára dì kó lè dáàbò bo àwọn ìjọ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
Pọ́ọ̀lù rán Tímótì létí pé kí ó gbẹ́kẹ̀ lé ọgbọ́n tó wà nínú Ọ̀rọ̀ onímìísí