Àwọn Ọ̀dọ́ tí Ó ní Ọjọ́ Ọ̀la tí Ó Fọkàn Ẹni Balẹ̀
“Ó MÚNI gbọ̀n rìrì, ó sì kóninírìíra bí [ọ̀ràn ìfipábáni-lòpọ̀] èyíkéyìí yóò ti ṣe”—bí adájọ́ tí ó jẹ́ alága ìgbẹ́jọ́ kan láìpẹ́ yìí ti ṣàpèjúwe ìwà ọ̀daràn kan nìyẹn. Àjọ ìpàǹpá ọ̀dọ́langba mẹ́jọ, tí ọjọ́ orí wọ́n bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 14 sí 18, ba de obìnrin arìnrìn-àjò afẹ́ kan ní àgbègbè àárín gbùngbùn ìlú London, wọ́n bá a ṣe léraléra, lẹ́yìn náà, wọ́n gbé e jù sínú ipa odò tí ó wà nítòsí, bí ó tilẹ̀ sọ pé òun kò mọ bí a ṣe ń lúwẹ̀ẹ́. Lọ́nà tí ó yéni, ìyá ọ̀kan lára àwọn ọ̀dọ́langba náà sọ pé òun ṣàìsàn nígbà tí òun rí ohun tí ọmọ òun ṣe lórí tẹlifíṣọ̀n nígbà tí wọ́n ń sọ̀ròyìn.
Lọ́nà tí ó bani nínú jẹ́, ìṣẹ̀lẹ̀ yí gbé ohun tí ń ṣẹlẹ̀ nínú àwùjọ lónìí yọ. Ìwà òkú òǹrorò ti wá di ohun tí ó wọ́pọ̀, yálà nínú ìgbòkègbodò ìwà ọ̀daràn, gbọ́nmisi-omi-ò-to láàárín ilé, tàbí ìforígbárí ẹ̀yà ìran ní àgbègbè Balkans, àárín gbùngbùn àti ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà, àti níbòmíràn. Àwọn ọ̀dọ́ ń dàgbà nínú irú ipò bẹ́ẹ̀, tàbí kí wọ́n máa gbọ́ nípa wọn nígbà gbogbo. Abájọ nígbà náà tí ọ̀pọ̀ nínú wọn fi ya panakí, tí wọn kò fi “ìfẹ́ni àdánidá” hàn, tí wọ́n sì jẹ́ “aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu.”—Tímótì Kejì 3:3.
“Òǹrorò”
Nígbà tí Kristẹni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà rẹ̀ kejì sí Tímótì, alàgbà ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, Róòmù ni agbára ayé tí ń ṣàkóso nígbà náà. Ìwà òǹrorò àti ìwà ẹhànnà kún inú gbọ̀ngàn ìṣeré àwọn ará Róòmù. Síbẹ̀, Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ pé ní ọjọ́ iwájú, àwọn àkókò yóò “nira láti bá lò.” (Tímótì Kejì 3:1) Ó dùn mọ́ni pé, ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí ó ṣàpèjúwe àwọn àkókò yí gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó “nira láti bá lò” ní èrò pé wọ́n jẹ́ “òǹrorò” nínú. Ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí ó ṣẹlẹ̀ nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù lórí ilẹ̀ ayé, ní èyí tí ó lé ní 30 ọdún ṣáájú, fi ohun tí ń bẹ lẹ́yìn díẹ̀ nínú àwọn ìwà òǹrorò ọjọ́ rẹ̀ hàn.
Jésù ṣẹ̀ṣẹ̀ bá ọkọ̀ òkun dé sí èbúté ìlà oòrùn Òkun Gálílì ni. Bí ó ti ń gbẹ́sẹ̀ sílẹ̀, àwọn ọkùnrin méjì kò ó lójú. Ìrísí ẹhànnà àti igbe tí wọ́n ń ké mú un ṣe kedere pé nǹkan kan ń dààmú wọn gidigidi. Wọ́n “rorò lọ́nà kíkàmàmà,” ní ti gidi, ẹ̀mí èṣù ti bà lé wọn.a Igbe tí wọ́n ń ké jáde wá láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀mí búburú tí ń ṣàkóso ìgbésẹ̀ oníwà ipá wọn. Àwọn ọkùnrin náà lọgun pé: “Kí ní pa tàwa tìrẹ pọ̀, Ọmọkùnrin Ọlọ́run? Ìwọ ha wá síhìn-ín láti mú wa joró ṣáájú àkókò tí a yàn kalẹ̀?” Àwọn ẹ̀mí búburú tí ó bà lé àwọn méjèèjì mọ̀ dáradára pé Ọlọ́run ti yan àkókò kan tí yóò mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ sórí àwọn ẹ̀mí èṣù. Èyí yóò túmọ̀ sí ìparun ayérayé fún wọn. Ṣùgbọ́n títí di ìgbà yẹn, wọn yóò lo agbára wọn tí ó ju ti ènìyàn lọ láti fi dá ìwà ipá rírorò sílẹ̀. Kìkì ìgbésẹ̀ oníyanu tí Jésù gbé láti lé àwọn ẹ̀mí èṣù wọ̀nyẹn jáde ni ó mú ìtura wá fún àwọn ọkùnrin méjèèjì.—Mátíù 8:28-32; Júúdà 6.
Nígbà tí àwọn ènìyàn lónìí, títí kan àwọn èwe, bá hùwà bí asínwín, a óò ṣe dáradára láti rántí ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn. Èé ṣe? Nítorí ní ọ̀rúndún ogún yìí, a dojú kọ ewu tí ó jọ èyí, gẹ́gẹ́ bí Ìṣípayá, ìwé tí ó kẹ́yìn nínú Bíbélì, ti ṣàlàyé: “Ègbé ni fún ilẹ̀ ayé àti fún òkun, nítorí Èṣù ti sọ̀kalẹ̀ wá bá yín, ó ní ìbínú ńlá, ní mímọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú ni òun ní.” (Ìṣípayá 12:12) Jọ̀wọ́ kíyè sí i pé “ìbínú ńlá” bá ìtẹ́lógo Sátánì yí rìn, nítorí tí ó mọ̀ pé àkókò tí òun ní kúrú.
Lábẹ́ Ìkọlù
Gẹ́gẹ́ bí a ti mẹ́nu kàn án lọ́pọ̀ ìgbà ní àwọn ojú ewé ìwé ìròyìn yí, ọdún 1914 ni a gbé Kristi Jésù gorí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀run. Kíá ni Jésù gbégbèésẹ̀ lòdì sí Sátánì, olórí ọ̀tá Ọlọ́run. Nípa bẹ́ẹ̀, a lé Èṣù àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ dà nù kúrò lọ́run, wọ́n sì wá darí gbogbo àfiyèsí wọn sí ayé yìí. (Ìṣípayá 12:7-9) Bí a ti dín àgbègbè tí ó ń lo agbára lé lórí kù gidigidi, Sátánì “ń rìn káàkiri bíi kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń wá ọ̀nà láti pa ẹnì kan jẹ.” (Pétérù Kíní 5:8) Àwọn wo ni ó rọrùn fún un láti fi ṣe ẹran ìjẹ? Kò ha ṣe kedere pé ní pàtàkì yóò jẹ́ àwọn tí kò nírìírí nínú ìgbésí ayé àti nínú àjọṣepọ̀ ẹ̀dá ènìyàn? Nítorí èyí ni Èṣù ṣe dójú sọ àwọn ọ̀dọ́ lónìí. Nípasẹ̀ ọ̀pọ̀ jù lọ orin tí wọ́n ń gbọ́ àti fàájì tí wọ́n ń lépa, wọ́n ń kó sọ́wọ́ afọgbọ́n àyínìke darí ẹni, tí a kò lè fojú rí yìí.—Éfésù 6:11, 12.
Àní nígbà tí àwọn ọ̀dọ́ bá gbìyànjú láti ṣàṣeyọrí nínú ìgbésí ayé pàápàá, wọ́n máa ń bá ìdílọ́wọ́ pàdé. Láti ìgbà tí Ogun Àgbáyé Kejì ti parí, àwọn ènìyàn ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè tí wọ́n ń bá ara wọn jagun tẹ́lẹ̀ rí ti gbìyànjú láti ṣàtúnṣe nípa pípèsè ìgbésí ayé ọlọ́rọ̀ fún ìdílé wọn. Kíkọ́rọ̀jọ, fàájì tí a kò kó níjàánu, àti eré ìnàjú ti di olórí góńgó wọn. Ní ìyọrísí rẹ̀, ọ̀pọ̀ ti jìyà. Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ fún Tímótì pé: “Àwọn wọnnì tí wọ́n [pinnu] láti di ọlọ́rọ̀ máa ń ṣubú sínú ìdẹwò àti ìdẹkùn àti ọ̀pọ̀ àwọn ìfẹ́ ọkàn òpònú àti aṣenilọ́ṣẹ́ . . . Nítorí ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò onírúurú ohun aṣeniléṣe gbogbo, àti nípa nínàgà fún ìfẹ́ yìí . . . àwọn kan . . . ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrora gún ara wọn káàkiri.” (Tímótì Kíní 6:9, 10) Ní gbogbogbòò, a rí àwọn ènìyàn àwùjọ onífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì òde òní tí wọ́n ti fi ìrora ọrọ̀ ajé, ìṣúnná owó, àti ti èrò ìmọ̀lára gún ara wọn káàkiri. Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ tí wọ́n ti kó sínú ìtànjẹ olórí ọ̀tá Ọlọ́run yìí wà lára wọn.
Ṣùgbọ́n, lọ́nà tí ó múni láyọ̀, ìròyìn rere ń bẹ. Ó sì kan àwọn ọ̀dọ́, àwọn tí wọ́n ní ọjọ́ ọ̀la tí ó fọkàn ẹni balẹ̀ níwájú wọn. Báwo ni èyí ṣe lè rí bẹ́ẹ̀?
Wá Kiri, Ìwọ Yóò sì Rí
Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ní ọ̀pá ìdiwọ̀n gíga. Wọ́n kọ ọ̀pá ìdiwọ̀n tí ń jó rẹ̀yìn, tí ó wọ́pọ̀ láàárín àwọn àgbàlagbà. Wọ́n kórìíra ìwà àìṣèdájọ́ òdodo àti àìgbatẹnirò ti àwọn òṣèlú àti oníṣòwò tí ebi agbára ń pa. Bí o bá jẹ́ ọ̀dọ́, ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé bí ìmọ̀lára rẹ ṣe rí nìyí.
Gbé ìrírí Cedric, ọ̀dọ́kùnrin kan tí ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ogún ọdún, tí ìrírí rẹ̀ kò ṣàrà ọ̀tọ̀ yẹ̀ wò.b Nígbà tí ó wà ní ọmọdé, ó bẹ̀rù ohun púpọ̀, títí kan ikú. Ohun tí ète ìgbésí ayé jẹ́ kọ ọ́ lóminú. Nígbà tí kò rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè rẹ̀ nígbà tí ó fi máa pé ọmọ ọdún 15, ó yíjú sí ríronú lórí ìtumọ̀ ìgbésí ayé láwùjọ àwọn èwe mìíràn tí ń ronú lórí ipò nǹkan pípé pérépéré. Ó rántí pé: “A máa ń fa igbó, a sì máa ń jókòó yíká ní sísọ̀rọ̀ ṣáá fún ọ̀pọ̀ wákàtí. Wà á máa ronú pé bíi tìrẹ ni gbogbo àwọn yòó kù ṣe ń ronú, ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó mọ ojútùú.”
Cedric ń yán hànhàn fún ohun tí yóò mú un lórí yá, bí ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ti ń ṣe. Jíjoògùnyó nìkan kò mú ìtẹ́lọ́rùn wá fún un. Kò pẹ́ kò jìnnà, ó di ẹni tí ń lọ́wọ́ nínú olè jíjà àti ṣíṣòwò oògùn olóró. Síbẹ̀, ó wá àwọn ohun amúnilóríyá mìíràn. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í lọ jí ohun tí àwọn oníbàárà bá ń fẹ́ wá á tà fún wọn. Ó jẹ́wọ́ pé: “Ó máa ń dùn mọ́ mi. Ṣùgbọ́n, n kò jẹ́ jí ohunkóhun lọ́dọ̀ mẹ̀kúnnù. Bí n bá jí ọkọ̀, mo máa ń fi sílẹ̀ ní ipò tí ó dára. Bí mo bá lọ fọ́ ilé iṣẹ́, mo ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí tí mo mọ̀ pé ètò ìbánigbófò wà lórí ilé iṣẹ́ náà. Ó ràn mí lọ́wọ́ láti wáwìíjàre ohun tí mo ṣe.” Gẹ́gẹ́ bí o ti lè retí, Cedric lọ sẹ́wọ̀n.
Cedric rántí pé: “Mark, ẹlẹ́wọ̀n bíi tèmi, bá mi sọ̀rọ̀. Ní kíkíyèsi pé mo fín àmì àgbélébùú ńlá kan sí apá mi, ó béèrè ìdí tí mo fi ṣe èyí. Ó ronú pé ó ní láti ṣe pàtàkì sí mi ní ti ìsìn.” Ọ̀sẹ̀ mélòó kan lẹ́yìn náà, Mark fún Cedric ní ẹ̀dà ìwé Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye.c “‘Iwọ Le Walaaye Titilae’—àwọn ọ̀rọ̀ ṣókí yẹn gún ọkàn mi ní kẹ́ṣẹ́ lójú ẹsẹ̀. Ohun tí ọ̀rọ̀ wa máa ń dá lé lórí nìyẹn nígbà gbogbo, ṣùgbọ́n tí kò ṣeé ṣe fún wa láti rí òkodoro rẹ̀.” Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ìjíròrò pẹ̀lú ọkàn lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ó ṣèbẹ̀wò sí ọgbà ẹ̀wọ̀n, Cedric wá rí i pé ohun tí òun ń nàgà fún ṣeé ṣe—ṣùgbọ́n kìkì ní ọ̀nà ti Ọlọ́run.
Cedric sọ pé: “Gbàrà tí mo ṣíwọ́ kíkẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ mi àtijọ́, ìtẹ̀síwájú mi yára kánkán.” Ìtẹ̀síwájú rẹ̀ nínú òye àti rírí ayọ̀ kò fi bẹ́ẹ̀ rọrùn. Ó sọ pé: “Mo ṣì ń ṣiṣẹ́ lé e lórí. Mo ní láti ṣọ́ra nípa ọ̀nà tí mo ń gbà ronú.” Bẹ́ẹ̀ ni, Cedric mọ̀ nísinsìnyí pé jíjẹ́ ẹni tí ń ronú lórí ipò nǹkan pípé pérépéré ni ó sún òun sínú pańpẹ́ Èṣù, ní ríronú pé ọwọ́ òun lè tẹ góńgó òun kìkì nípa lílọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò tí ó so mọ́ ìmóríyá.
Lọ́nà tí ó múnú ẹni dùn, ó ti pẹ́ tí Cedric ti fi ẹ̀wọ̀n sílẹ̀, ó sì ń gbádùn ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ déédéé pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn tí wọ́n ti rí ohun tí wọ́n ń wá kiri. Ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni báyìí, ó sì nírètí kan náà bíi tiwọn, ti gbígbé nínú Párádísè níhìn-ín lórí ilẹ̀ ayé. Ó tún ń wọ̀nà fún ìgbà tí gbogbo ipa tí Èṣù ń ní ní gbogbo ọ̀nà yóò wá sí òpin.
Dájúdájú, kì í ṣe àwọn ọ̀dọ́ bíi Cedric nìkan ni ó ní ọjọ́ ọ̀la tí ó fọkàn ẹni balẹ̀; àwọn òbí olùbẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó gbin ìfẹ́ fún òtítọ́ Bíbélì sínú ọkàn àwọn ọmọ wọn, ni ó tọ́ àwọn mìíràn dàgbà.
Ìdálẹ́kọ̀ọ́ Oníwà-Bí-Ọlọ́run Ń Mú Èrè Wá
Ọba Sólómọ́nì ìgbàanì kọ̀wé pé: “Tọ́ ọmọdé ní ọ̀nà tí yóò tọ̀: nígbà tí ó sì dàgbà tán, kì yóò kúrò nínú rẹ̀.” (Òwe 22:6) Èyí ti já sí òtítọ́ nínú ọ̀ràn àwọn èwe olùfọkànsìn, tí wọ́n ti yàn láti tẹ̀ lé ọ̀pá ìdiwọ̀n Bíbélì.
Sheila, Gordon, àti Sarah ṣe èyí. Wọ́n rántí pé àwọn òbí wọn gbé ìjẹ́pàtàkì ńlá karí ṣíṣègbọràn sí àṣẹ Kristi náà láti ‘lọ sọ àwọn ènìyàn di ọmọ ẹ̀yìn’ nípa wíwàásù ìhìn rere Ìjọba. (Mátíù 24:14; 28:19, 20) Sheila rántí pé: “Nínú gbogbo ìpinnu tí a bá fẹ́ ṣe, èmi àti Màmá máa ń sọ fún ara wa pé, ‘Ipa wo ni èyí yóò ní lórí iṣẹ́ ìwàásù wa?’” Ó jẹ́wọ́ pé: “A pa ọ̀pọ̀ ìdáwọ́lé wa tì, nítorí ríronú lọ́nà yí.” Ó fi kún un pé: “Ṣùgbọ́n, ẹ wo bí ìbùkún wa ti pọ̀ tó!” Àní lẹ́yìn ọ̀pọ̀ wákàtí tí wọ́n lò ní mímú ìhìn rere lọ sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn nílé, Sheila àti ìyá rẹ̀ fẹsẹ̀ rìn lọ sílé pẹ̀lú orin lẹ́nu. Ó sọ pé: “Ayọ̀ mí kún. Mo ń nímọ̀lára rẹ̀ nísinsìnyí.”
Gordon rántí ọ̀pọ̀ ìrọ̀lẹ́ Saturday tí ó gbádùn mọ́ni. Gordon rántí pé: “A ké sí mi wá sílé àwọn alàgbà ìjọ, níbi tí a ti máa ń gbádùn àwọn ìbéèrè àti ìjíròrò lórí Bíbélì. A fún wa níṣìírí láti kọ́ àwọn ẹsẹ Bíbélì sórí, láti sọ̀rọ̀ fàlàlà lórí àwọn kókó ẹ̀kọ́ inú Ìwé Mímọ́, láti sọ ìrírí tí a ní nínú iṣẹ́ ìwàásù, àti láti kọ́ bí iṣẹ́ Ìjọba ti ń gbòòrò sí i. Gbogbo ìwọ̀nyí ràn mí lọ́wọ́ láti fi ìpìlẹ̀ rere lélẹ̀ àti láti mú ìfẹ́ dàgbà fún Jèhófà Ọlọ́run.”
Sarah ní ìrántí tí ó gbádùn mọ́ni nípa àwọn ìrọ̀lẹ́ tí ó lò ní ṣíṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ Àwọn Ẹlẹ́rìí. “A máa ń jẹun pa pọ̀. Láti kágbá ìbẹ̀wò náà nílẹ̀, a máa ń lu dùùrù olóhùn gooro láti fi gbe àwọn tí ń kọrin Ìjọba Ọlọ́run lẹ́sẹ̀. Ní tòótọ́, orin ràn wá lọ́wọ́ gidigidi, ní pàtàkì ní àwọn ọdún tí a lò ní ilé ẹ̀kọ́, nítorí ó fún wa láǹfààní láti ṣe nǹkan pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé.”
Dájúdájú, kì í ṣe gbogbo ọ̀dọ́ tí ń wá láti wu Jèhófà ni ó ní ipò ìdílé tí ó dára. Bí ó ti wù kí ó rí, ìbákẹ́gbẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn ìdílé Ẹlẹ́rìí mìíràn nínú ìjọ ń fún wọn ní ààbò àti ìmọ̀lára pé wọ́n jẹ́ ọ̀kan lára wọn.
To Ìṣúra Ìpìlẹ̀ Tí Ó Fọkàn Ẹni Balẹ̀ Jọ fún Ọjọ́ Ọ̀la
Àwọn ọ̀dọ́ ènìyàn lónìí ní yíyàn kan láti ṣe. Wọ́n lè máa bá a lọ pẹ̀lú ayé búburú yìí bí ó ti ń forí lé ìparun nínú “ìpọ́njú ńlá” tí ń bọ̀, tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀. Tàbí kí wọ́n “gbé ìrètí wọn lé Ọlọ́run . . . kí wọn kí ó pa òfin rẹ̀ mọ́,” gẹ́gẹ́ bí orin Ásáfù onísáàmù náà. Ìgbọràn sí Ọlọ́run yóò mú kí wọ́n yẹra fún dídi “ìran agídí àti ọlọ̀tẹ̀; ìran tí kò fi ọkàn wọn lé òtítọ́, àti ẹ̀mí ẹni tí kò bá Ọlọ́run dúró ṣinṣin.”—Mátíù 24:21; Orin Dáfídì 78:6-8.
Nínú ìjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ó lé ní 80,000 kárí ayé, ìwọ yóò rí ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ tí o lè fẹ́ràn. Wọ́n ti kọbi ara sí ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù sí Tímótì ọ̀dọ́ “láti máa ṣe rere, láti jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú àwọn iṣẹ́ àtàtà, láti jẹ́ aláìṣahun, kí wọ́n múra tán láti ṣe àjọpín, kí wọ́n máa fi àìséwu to ìṣúra ìpìlẹ̀ tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ jọ fún ara wọn de ẹ̀yìn ọ̀la.” Nítorí èyí, wọ́n ti di “ìyè tòótọ́ gidi mú gírígírí” nísinsìnyí. (Tímótì Kíní 6:18, 19) Ṣèwádìí sí i nípa àwọn ojúlówó Kristẹni wọ̀nyí nípa lílọ sí àwọn ìpàdé wọn. Nígbà náà, ìwọ pẹ̀lú lè ní ìrètí ọjọ́ ọ̀la tí ń fọkàn ẹni balẹ̀.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a “Òǹrorò” tú ọ̀rọ̀ Gíríìkì kan náà tí a lò nínú Mátíù 8:28 àti nínú Tímótì Kejì 3:1.
b A ti yí àwọn orúkọ pa dà.
c Tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Àwọn ẹ̀mí búburú ni ó wà lẹ́yìn àwọn ọkùnrin tí ó “rorò lọ́nà kíkàmàmà” tí Jésù wò sàn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Kíkọ́ ‘ìpìlẹ̀ tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ fún ẹ̀yìn ọ̀la’