Àmì Kí Ni Gbogbo Nǹkan Wọ̀nyí Jẹ́?
BÍ O bá yiiri bí ìwà àwọn èèyàn ṣe rí lẹ́nu ọdún mélòó kan sẹ́yìn wò, wàá rí àṣà kan tó hàn kedere. Láìsí àní-àní, ìwà ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ń burú sí i ni. Kí ni èyí túmọ̀ sí gan-an?
Bí àwọn kan ṣe sọ, ṣé ohun tó túmọ̀ sí ni pé ọ̀làjú tó gbòde àti aráyé lápapọ̀ wà nínú ewu, pé ìparun pátápátá sún mọ́lé ni bí? Àbí ṣé irú àwọn ìyípadà bẹ́ẹ̀ wulẹ̀ jẹ́ ara lílọ síwá sẹ́yìn tó máa ń ṣẹlẹ̀ nínú ìtàn ẹ̀dá ni?
Ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn rò nìyẹn. Wọ́n rò pé àṣà tó kàn gbòde ni ìwà àwọn èèyàn tó ń burú sí i yìí, pé bó ṣe ń ṣẹlẹ̀ bọ̀ látẹ̀yìnwá nìyẹn, bí ọ̀pọ̀ èyí tó ń wá tó ń lọ nínú ìtàn. Wọ́n ń retí kí nǹkan yí padà tó bá yá, tí àwọn èèyàn á tún bẹ̀rẹ̀ sí hùwà dáadáa. Ǹjẹ́ èrò wọ́n tọ̀nà?
“Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn”
Ẹ jẹ́ ká wò ó bóyá òótọ́ ni, nípa ṣíṣàyẹ̀wò ìwé kan tí àwọn èèyàn tẹ́wọ́ gbà pé ó ti ń ṣàlàyé ọ̀ràn ìwà rere láti ọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn—ìwé náà ni Bíbélì, tí í ṣe Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ìlàlóye gbáà ló jẹ́ láti gbé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé ìsinyìí yẹ̀ wò lójú àwọn àpèjúwe alásọtẹ́lẹ̀ tí Bíbélì ṣe nípa sànmánì tó pabanbarì nínú ìtàn aráyé. Àkókò yìí ló pè ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” tàbí “ìparí ètò àwọn nǹkan.” (2 Tímótì 3:1; Mátíù 24:3) Ohun tí ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí ni pé àkókò yìí ló máa sàmì sí òpin sáà ìṣẹ̀lẹ̀ kan, yóò sì sàmì sí ìbẹ̀rẹ̀ tuntun mìíràn.
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ pé, “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” ni yóò jẹ́ àmì àwọn ọjọ́ ìkẹyìn. Láti ran àwọn tí wọ́n ń fojú sílẹ̀ lọ́wọ́ láti mọ àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, Bíbélì ṣe àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé kan tí gbogbo wọn lápapọ̀ ṣàpèjúwe tó ṣe kedere, tàbí fi àmì alápá púpọ̀ hàn, nípa sáà aláìlẹ́gbẹ́ yìí.
Ìwàkiwà Táwọn Èèyàn Yóò Máa Hù
Ṣàkíyèsí ọ̀kan lára apá tí àmì náà ní tó hàn gbangba lónìí: ‘Àwọn ènìyàn yóò ní ìrísí fífọkànsin Ọlọ́run ṣùgbọ́n wọn yóò já sí èké ní ti agbára rẹ̀.’ (2 Tímótì 3:2, 5) Kò tíì sí sáà kankan nínú ìtàn tí irú ìwà àìka ẹ̀sìn kún rárá tí le tó ti ìsinsìnyí. Àwọn èèyàn púpọ̀ ni ò wo Ọlọ́run bí aláṣẹ kan ṣoṣo tó wà, ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn ni ò sì gbà pé Bíbélì ni orísun òtítọ́ kan ṣoṣo tó wà. Òótọ́ ni pé àwọn ìsìn ṣì wà lónìí, àmọ́ púpọ̀ wọn ni kì í fi bẹ́ẹ̀ sún àwọn èèyàn hùwà rere. Ìbòjú lásán ni wọ́n fi ń ṣe.
Bíbélì sọ nípa apá mìíràn tí àmì náà ní pé: “Àwọn ènìyàn yóò jẹ́ . . . aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò,” àti pé “nítorí pípọ̀ sí i ìwà àìlófin, ìfẹ́ ọ̀pọ̀ jù lọ yóò di tútù.” (2 Tímótì 3:2, 3; Mátíù 24:12) Ọ̀rọ̀ èdè Gíríìkì tí a tú sí “òǹrorò” tún túmọ̀ sí, “aláìní ìbánikẹ́dùn àti aláìláàánú.” Láyé ìsinyìí, ńṣe làwọn ọmọdé pàápàá túbọ̀ ń hùwà “òǹrorò,” wọ́n sì ń hu àwọn ìwà jàgídíjàgan tó bùáyà.
Síwájú sí i, ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ àti ètò ọrọ̀ ajé tó ń yára lọ sókè sí i àti ìwọra tó ń bá wọn rìn ti ń mú kí àwọn èèyàn púpọ̀ sí i gbé ìwà ọmọlúwàbí ayé ọjọ́un jù sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan. Láìgba tàwọn ẹlòmíràn rò, ọ̀nàkọnà ni wọ́n ń gbà láti kó nǹkan jọ bó bá ṣe lè pọ̀ tó, bó tiẹ̀ jẹ́ lọ́nà àìṣòótọ́ pàápàá, kí wọ́n sáà ti tẹ́ ìfẹ́ ìmọtara-ẹni-nìkan wọn lọ́rùn ni. Iye àwọn tó ń ta tẹ́tẹ́ tó ń pọ̀ sí i tún jẹ́ ẹ̀rí míì nípa ìmọtara-ẹni-nìkan, àkọsílẹ̀ nípa bí ìwà ọ̀daràn ṣe ń pọ̀ sí i lẹ́nu ọdún mélòó kan sẹ́yìn tún jẹ́ ẹ̀rí tó ṣe kedere nípa rẹ̀.
Apá kan rẹ̀ tó wọ́pọ̀ gan-an lákòókò wa yìí nìyí: “Àwọn èèyàn yóò jẹ́ . . . olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run.” (2 Tímótì 3:2, 4) Àpẹẹrẹ kan nípa èyí ni pé àwọn èèyàn ń fẹ́ máa ṣe fàájì yàà, ṣùgbọ́n wọn ò fẹ́ máa gbé títí lọ pẹ̀lú ẹnì kan tí wọ́n bá ṣègbéyàwó. Ìyọrísí ẹ̀ ni pé ọ̀pọ̀ ìdílé ń tú ká, kò sí ayọ̀ nínú ìdílé, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìfararora láàárín àwọn ọmọ àti ìdílé wọn mọ́, àwọn òbí anìkàntọ́mọ ń pọ̀ sí i, àrùn abẹ́ pẹ̀lú ń ràn kálẹ̀.
Apá mìíràn tí àmì náà ní ni pé, “àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó.” (2 Tímótì 3:2) Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn èdè Jámánì náà, Die Zeit, ti sọ, “lájorí ohun tó wà lọ́kàn àwọn èèyàn nínú ètò [ọrọ̀ ajé òde òní] ni ìmọtara-ẹni-nìkan.” Ju ti ìgbàkigbà rí lọ, lílépa owó ló wà ní góńgó ẹ̀mí ọ̀pọ̀ èèyàn. Bí wọ́n sì ṣe ń lépa ìfẹ́ tara wọn kiri ni wọ́n ń gbé àwọn ìwà rere mìíràn jù sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan.
Àwọn Ohun Tó Ń Ṣẹlẹ̀ Láyé
Láfikún sí ṣíṣàpèjúwe bí ìwà àwọn èèyàn ṣe máa burú sí i, Bíbélì tún sọ tẹ́lẹ̀ pé, àwọn rògbòdìyàn tó burú jáì, tí yóò da aráyé láàmú yóò wà lára àmì àwọn ọjọ́ ìkẹyìn. Fún àpẹẹrẹ, ó sọ pé, “orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè, àti ìjọba sí ìjọba; ìsẹ̀lẹ̀ ńláǹlà yóò sì wà, àti àwọn àjàkálẹ̀ àrùn àti àìtó oúnjẹ láti ibì kan dé ibòmíràn.”—Lúùkù 21:10, 11.
Kò tíì sí sáà kankan nínú ìtàn aráyé tí ọ̀pọ̀ èèyàn ti fojú winá àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ aburú tó ń gbo ayé gan-an láàárín àkókò kúkúrú àyàfi ní ọ̀rúndún ogún nìkan. Fún àpẹẹrẹ, ó lé ní ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù èèyàn tó ṣòfò ẹ̀mí nínú ogun ní sáà náà, iye yìí sì pọ̀ gan-an ju àpapọ̀ iye àwọn tó kú nínú àwọn ogun tó ti jà ní àwọn ọ̀rúndún mélòó kan ṣáájú. Inú ọ̀rúndún ogún ni ogun méjì ti jà, tó sì yàtọ̀ sí ogun èyíkéyìí, àní wọ́n yàtọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí wọ́n fi pè wọ́n ní ogun àgbáyé. Ogun àgbáyé bí ìwọ̀nyẹn ò ṣẹlẹ̀ rí.
Agbára Búburú Kan Ló Ń Tì Wọ́n Gbọ̀n-ọ́ngbọ̀n-ọ́n
Bíbélì tún sọ pé ẹ̀dá ẹ̀mí búburú, tó lágbára kan wà, “ẹni tí a ń pè ní Èṣù àti Sátánì,” tí ète rẹ̀ jẹ́ láti tan àwọn èèyàn kí wọ́n yéé hùwà ọmọlúwàbí ṣùgbọ́n kí wọ́n máa hùwà burúkú. Ó sọ pé ní sáà àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, ó ti sọ̀ kalẹ̀ wá sí ayé, “ó ní ìbínú ńlá, ó mọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú ni òun ní.”—Ìṣípayá 12:9, 12.
Bíbélì ṣàpèjúwe Èṣù bí “olùṣàkóso ọlá àṣẹ afẹ́fẹ́, ẹ̀mí tí ń ṣiṣẹ́ nísinsìnyí nínú àwọn ọmọ àìgbọ́ràn.” (Éfésù 2:2) Èyí wá túmọ̀ sí pé Èṣù ní agbára tó fi ń darí ọ̀pọ̀ èèyàn, láìjẹ́ pé àwọn fúnra wọn fura, bí ìgbà tí òórùn burúkú tú sáfẹ́fẹ́ téèyàn ò sì mọ̀ ni.
Fún àpẹẹrẹ, a ń rí ìdarí Sátánì nínú ọ̀pọ̀ àwọn ohun ìgbàlódé tó ń gbé ìsọfúnni wá, àwọn bíi: fídíò, sinimá, tẹlifíṣọ̀n, Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìpolówó, ìwé, àti ìwé ìròyìn. Ọ̀pọ̀ nǹkan tí wọ́n ń ṣe, pàápàá àwọn tí wọ́n ṣe nítorí àwọn ọ̀dọ́ tí ò fura, ni àwọn àṣà burúkú àti èyí tí ń kóni nírìíra kún inú wọn, àwọn àṣà bí ẹ̀tanú sí ẹ̀yà míì, wíwọ ẹgbẹ́ òkùnkùn, ìṣekúṣe, àti àwọn ìwà ẹhànnà.
Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún ọ̀pọ̀ àwọn olóòótọ́ ọkàn tí wọ́n ń rí bí gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé tí a wà yìí ṣe bá àpèjúwe tí Bíbélì ṣe nípa àwọn ọjọ́ ìkẹyìn mu. Lóòótọ́, àwọn ohun kan ti ṣẹlẹ̀ nínú ìtàn ṣáájú ọ̀rúndún ogún, tó jọ pé ó bá àpèjúwe tí Bíbélì ṣe mu díẹ̀. Ṣùgbọ́n, ní ọ̀rúndún ogún àti ní ọ̀rúndún kọkànlélógún táa wà nísinsìnyí nìkan la ti lè rí gbogbo apá tí àwọn àmì náà ní.
Sáà Ìṣẹ̀lẹ̀ Tuntun Tó Ń Bọ̀
Àwọn tó gbà gbọ́ pé a ó pa gbogbo ìran ènìyàn run àti àwọn tó ń sọ pé nǹkan á máa bá a lọ bó ṣe ń lọ ò tọ̀nà o. Kàkà bẹ́ẹ̀, Bíbélì sọ kedere pé a ó fi ohun tuntun kan rọ́pò ètò àwọn nǹkan tó wà láyé ìsinyìí.
Lẹ́yìn tí Jésù sọ àwọn ohun mélòó kan tí yóò jẹ́ àmì àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, ó wí pé: “Lọ́nà yìí, ẹ̀yin pẹ̀lú, nígbà tí ẹ bá rí nǹkan wọ̀nyí tí ń ṣẹlẹ̀, kí ẹ mọ̀ pé ìjọba Ọlọ́run sún mọ́lé.” (Lúùkù 21:31) Ìjọba ọ̀run ti Ọlọ́run ni ẹṣin ọ̀rọ̀ ìwàásù Jésù. (Mátíù 6:9, 10) Ọlọ́run sì yàn án láti jẹ́ Ọba Ìjọba náà, tó jẹ́ ìjọba kan tí yóò bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso ilẹ̀ ayé láìpẹ́ sígbà táa wà yìí.—Lúùkù 8:1; Ìṣípayá 11:15; 20:1-6.
Lópin àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, Ìjọba ọ̀run ti Ọlọ́run tí yóò wà lábẹ́ àkóso Kristi yóò pa gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ run, ìyẹn Èṣù àti àwọn tó ń tẹ̀ lé e, ìjọba yìí yóò sì fi ayé tuntun òdodo rọ́pò àwùjọ ènìyàn oníwàkiwà òde òní. (Dáníẹ́lì 2:44) Nínú ayé tuntun táà ń sọ yìí, àwọn olódodo yóò gbádùn ìyè ayérayé nínú ayé tí a sọ di párádísè.—Lúùkù 23:43; 2 Pétérù 3:13; Ìṣípayá 21:3, 4.
Àwọn tí wọ́n kórìíra ìwà burúkú táwọn èèyàn ń hù lóde òní, tí wọ́n sì lóye pé àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nísinsìnyí jẹ́ ìmúṣẹ àmì alápá púpọ̀ tí a sọ nípa àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, lè máa wọ̀nà fún ọjọ́ iwájú tó lárinrin. Nítorí èyí, a dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run Olódùmarè, tó bìkítà nípa àwa ẹ̀dá ènìyàn, tó sì ní ète ológo fún ohun tó dá, ìyẹn ilẹ̀ ayé.—Sáàmù 37:10, 11, 29; 1 Pétérù 5:6, 7.
Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ké sí ọ láti wá kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Ẹlẹ́dàá wa onífẹ̀ẹ́ àti nípa ìfojúsọ́nà fún ìwàláàyè nínú ayé tí àwọn ọmọlúwàbí yóò máa gbé, tó ṣèlérí fún olúkúlùkù ẹni tó bá ń wá a. Bí Bíbélì ṣe sọ, “èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.”—Jòhánù 17:3.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Àwọn olódodo yóò gbádùn ìyè ayérayé nínú párádísè ilẹ̀ ayé