Òòfà Agbára Ìdánilọ́rùn—Iyì Ènìyàn Tàbí Ògo Ọlọ́run?
XENOPHON, olókìkí ọ̀gágun ilẹ̀ Gíríìkì, kọ̀wé pé: “Alákòóso kan gbọ́dọ̀ ta àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ yọ, kì í ṣe ní ti pé ó sàn jù wọ́n lọ nìkan, ṣùgbọ́n ní ti pé ó tún ní ipa lílágbára lórí wọn.” Lónìí, ọ̀pọ̀ ènìyàn yóò pe irú “ipa lílágbára” bẹ́ẹ̀ ní òòfà agbára ìdánilọ́rùn.
Ó dájú pé kì í ṣe gbogbo alákòóso ènìyàn ló ní òòfà agbára ìdánilọ́rùn. Ṣùgbọ́n àwọn tí wọ́n ní i lò ó láti mú kí àwọn ènìyàn fara jìn pátápátá fún wọn àti láti fọgbọ́n darí àwọn gbáàtúù fún àǹfààní ti ara wọn. Ó ṣeé ṣe kí Adolf Hitler jẹ́ àpẹẹrẹ tí ó burú jù lọ ti ẹnu àìpẹ́ yìí. William L. Shirer kọ ọ́ nínú ìwé rẹ̀, The Rise and Fall of the Third Reich, pé: “[Ní 1933], lójú ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ará Germany, Hitler ni—tàbí kò ní pẹ́ di—aṣáájú tí ó ní òòfà agbára ìdánilọ́rùn. Fún ọdún méjìlá onírúkèrúdò tí ó tẹ̀ lé e, wọ́n ń tẹ̀ lé e láìronúwò, bíi pé ọwọ́ rẹ̀ ní ìdájọ́ àtọ̀runwá wà.”
Ìtàn ìsìn pẹ̀lú kún fún àwọn aṣáájú tí wọ́n ní òòfà agbára ìdánilọ́rùn, tí wọ́n ń sún àwọn ènìyàn láti fara jìn fún wọn, ṣùgbọ́n tí wọ́n kó àgbákò bá àwọn ọmọlẹ́yìn wọn. Jésù kìlọ̀ pé: “Ẹ ṣọ́ra kí ẹnikẹ́ni má ṣì yín lọ́nà, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn yóò wá lórúkọ mi, wọ́n óò wí pé ‘Èmi ni Kristi náà’, wọn óò sì ṣi ènìyàn lọ́nà.” (Mátíù 24:4, 5, Phillips) Kì í ṣe ọ̀rúndún kìíní nìkan ni àwọn èké Kristi tí wọ́n ní òòfà agbára ìdánilọ́rùn fara hàn. Ní àwọn ọdún 1970, Jim Jones pòkìkí pé òun ni “mèsáyà ìsìn People’s Temple.” A ṣàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “àlùfáà tí ó ní òòfà agbára ìdánilọ́rùn” tí ó ní “agbára ṣíṣàjèjì lórí àwọn ènìyàn,” ní 1978 ẹ̀wẹ̀, ó súnná sí ọ̀kan lára ìfọwọ́ ara ẹni para ẹni tí ó pọ̀ jù lọ nínú ìtàn.a
Ó hàn kedere pé òòfà agbára ìdánilọ́rùn lè jẹ́ ẹ̀bùn tí ó léwu. Ṣùgbọ́n, Bíbélì mẹ́nu kan irú ẹ̀bùn kan, tàbí àwọn ẹ̀bùn, tí ó yàtọ̀ pátápátá, tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó gbogbo ènìyàn fún àǹfààní gbogbo ènìyàn. Khaʹri·sma ni ọ̀rọ̀ Gíríìkì fún ẹ̀bùn yìí, ó sì fara hàn ní ìgbà 17 nínú Bíbélì. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan, tí ó jẹ́ Gíríìkì, túmọ̀ rẹ̀ sí, ‘ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ kan tí a kò lẹ́tọ̀ọ́ sí, ohun kan tí a fún ènìyàn tí kò ṣiṣẹ́ fún, tí kò sì lẹ́tọ̀ọ́ sí, ohun kan tí ó wá láti inú oore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, tí ìsapá ẹnì kan kò lè mú kí ó tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ tàbí kí ó di tirẹ̀.’
Nítorí náà, ní èrò Ìwé Mímọ́, khaʹri·sma jẹ́ ẹ̀bùn kan tí a gbà, ọpẹ́lọpẹ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ẹ̀bùn wọ̀nyí, tí Ọlọ́run fi inú rere fún wa? Báwo ni a sì ṣe lè lò wọ́n láti mú ìyìn wá fún un? Ẹ jẹ́ kí a gbé mẹ́ta lára àwọn ẹ̀bùn olóore ọ̀fẹ́ wọ̀nyí yẹ̀ wò.
Ìyè Àìnípẹ̀kun
Láìsí àní-àní, èyí tí ó tóbi jù lọ nínú gbogbo ẹ̀bùn náà ni ẹ̀bùn ìyè àìnípẹ̀kun. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí ìjọ Róòmù pé: “Owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san ni ikú, ṣùgbọ́n ẹ̀bùn [khaʹri·sma] tí Ọlọ́run ń fi fúnni ni ìyè àìnípẹ̀kun nípasẹ̀ Kristi Jésù Olúwa wa.” (Róòmù 6:23) Ó yẹ láti ṣàkíyèsí pé “owó ọ̀yà” (ikú) jẹ́ ohun tí a ṣiṣẹ́ fún látàrí àbùdá ẹ̀ṣẹ̀ tí a ní, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe ìfẹ́ inú wa. Ní òdì kejì ẹ̀wẹ̀, ìyè àìnípẹ̀kun tí Ọlọ́run mú kí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó jẹ́ ohun kan tí a kò lẹ́tọ̀ọ́ sí rárá, tí kò lè tẹ̀ wá lọ́wọ́ bí a bá gbé e karí ìtóótun wa.
A gbọ́dọ̀ ṣìkẹ́ ẹ̀bùn ìyè àìnípẹ̀kun náà, kí a sì ṣàjọpín rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. A lè ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti mọ Jèhófà, láti sìn ín, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ jàǹfààní ẹ̀bùn ìyè àìnípẹ̀kun. Ìṣípayá 22:17 sọ pé: “Àti ẹ̀mí àti ìyàwó ń bá a nìṣó ní sísọ pé: ‘Máa bọ̀!’ Kí ẹnikẹ́ni tí ń gbọ́ sì wí pé: ‘Máa bọ̀!’ Kí ẹnikẹ́ni tí òùngbẹ ń gbẹ sì máa bọ̀; kí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ bẹ́ẹ̀ gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.”
Báwo ni a ṣe lè darí àwọn ẹlòmíràn sídìí omi tí ń fúnni ní ìyè yìí? Ní pàtàkì, nípa lílo Bíbélì lọ́nà tí ó gbéṣẹ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Òtítọ́ ni pé ní àwọn apá ibì kan lórí ilẹ̀ ayé, àwọn ènìyàn kì í fi bẹ́ẹ̀ ka àwọn ohun tẹ̀mí tàbí kí wọ́n ronú nípa rẹ̀; síbẹ̀síbẹ̀, àwọn àǹfààní máa ń wà nígbà gbogbo láti “jí etí” ẹnì kan. (Aísáyà 50:4) Ní ti èyí, a lè nígbẹ̀ẹ́kẹ̀lé nínú ipá ìsúnniṣe tí Bíbélì ní, “nítorí tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára.” (Hébérù 4:12) Yálà ọgbọ́n tí ó gbéṣẹ́ láti inú Bíbélì, ìtùnú àti ìrètí tí ó fi fúnni, tàbí àlàyé tí ó ṣe nípa ète ìgbésí ayé ni, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè wọ ọkàn-àyà àwọn ènìyàn, kí ó sì mú wọn bẹ̀rẹ̀ sí í rìn ní ọ̀nà ìyè.—2 Tímótì 3:16, 17.
Ní àfikún sí i, àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a gbé karí Bíbélì lè ràn wá lọ́wọ́ láti sọ pé, “Máa bọ̀!” Wòlíì Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé ní àkókò òkùnkùn tẹ̀mí yìí, “Jèhófà yóò tàn” sára àwọn ènìyàn rẹ̀. (Aísáyà 60:2) Àwọn ìtẹ̀jáde Watch Tower Society ṣàgbéyọ ìbùkún tí ó ń wá láti ọ̀dọ̀ Jèhófà yìí, lọ́dọọdún, wọ́n sì ń darí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn sọ́dọ̀ Jèhófà, Orísun ìlàlóye tẹ̀mí. Jálẹ̀ gbogbo ojú ìwé wọn, a kò gbé ògo ènìyàn ga. Gẹ́gẹ́ bí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ sí Ilé Ìṣọ́ ṣe sọ, “ète Ilé Ìṣọ́ ni láti gbé Jèhófà Ọlọ́run ga gẹ́gẹ́ bí Olúwa Ọba Aláṣẹ àgbáyé. . . . Ó ń gbani níyànjú láti ní ìgbàgbọ́ nínú Ọba ti Ọlọ́run, Jésù Kristi, tí ń ṣàkóso lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, ẹni tí ìtasílẹ̀ ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún aráyé láti jèrè ìyè àìnípẹ̀kun.”
Kristẹni kan tí ó jẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, tí ó ti ní àwọn àṣeyọrí gbígbàfiyèsí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún, sọ̀rọ̀ nípa ìníyelórí Ilé Ìṣọ́ àti Jí! ní ríran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti sún mọ́ Ọlọ́run, ó wí pé: “Nígbà tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mi bá bẹ̀rẹ̀ sí í ka Ilé Ìṣọ́ àti Jí!, tí wọ́n sì ń gbádùn wọn, wọ́n máa ń yára tẹ̀ síwájú. Mo rí àwọn ìwé ìròyìn náà bí àrànṣe tí kò ṣeé díye lé, tí ó ń ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti mọ Jèhófà.”
Àwọn Àǹfààní Iṣẹ́ Ìsìn
Tímótì jẹ́ Kristẹni ọmọ ẹ̀yìn tí a fún ní ẹ̀bùn mìíràn tí ó yẹ láti fún ní àkànṣe àfiyèsí. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wí fún un pé: “Má ṣe máa ṣàìnáání ẹ̀bùn [khaʹri·sma] tí ń bẹ nínú rẹ, èyí tí a fi fún ọ nípasẹ̀ ìsọtẹ́lẹ̀ àti nígbà tí ẹgbẹ́ àwọn àgbà ọkùnrin gbé ọwọ́ lé ọ.” (1 Tímótì 4:14) Kí ni ẹ̀bùn yìí? Ó ní í ṣe pẹ̀lú yíyàn tí a yan Tímótì gẹ́gẹ́ bí alábòójútó arìnrìn-àjò, àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tí ó ní láti bójú tó bí ẹni tí ó mọṣẹ́ níṣẹ́. Nínú àyọkà kan náà, Pọ́ọ̀lù gba Tímótì níyànjú pé: “Máa bá a lọ ní fífi ara rẹ fún ìwé kíkà ní gbangba, fún ìgbani-níyànjú, fún kíkọ́ni. Máa fiyè sí ara rẹ nígbà gbogbo àti sí ẹ̀kọ́ rẹ. Dúró nínú nǹkan wọ̀nyí, nítorí nípa ṣíṣe èyí, ìwọ yóò gba ara rẹ àti àwọn tí ń fetí sí ọ là.”—1 Tímótì 4:13, 16.
Àwọn alàgbà lónìí pẹ̀lú ní láti ṣìkẹ́ àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn wọn. Gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ṣe fi hàn, ọ̀nà kan tí wọ́n lè gbà ṣe èyí jẹ́ nípa ‘fífiyèsí ẹ̀kọ́ wọn.’ Dípò kí wọ́n máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn aṣáájú nínú ayé, tí wọ́n ní òòfà agbára ìdánilọ́rùn, wọ́n ń darí àfiyèsí sí Ọlọ́run, kì í ṣe sí ara wọn. Jésù, tí ó jẹ́ Àwòkọ́ṣe wọn, jẹ́ olùkọ́ títayọ lọ́lá, tí kò sí iyè méjì pé ó ní àkópọ̀ ìwà tí ń fani mọ́ra, ṣùgbọ́n ó fi ògo fún Bàbá rẹ̀ tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀. Ó polongo pé: “Ohun tí mo fi ń kọ́ni kì í ṣe tèmi, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ti ẹni tí ó rán mi.”—Jòhánù 5:41; 7:16.
Jésù fi ògo fún Bàbá rẹ̀ ọ̀run nípa lílo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ọlá àṣẹ fún ẹ̀kọ́ rẹ̀. (Mátíù 19:4-6; 22:31, 32, 37-40) Pọ́ọ̀lù pẹ̀lú tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì kí àwọn alábòójútó ‘di ọ̀rọ̀ ṣíṣeégbíyèlé mú ṣinṣin ní ti ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wọn.’ (Títù 1:9) Nípa gbígbé àwọn ọ̀rọ̀ wọn karí Ìwé Mímọ́, lọ́nà yìí, àwọn alàgbà yóò máa sọ bí Jésù ti sọ pé: “Àwọn nǹkan tí mo ń sọ fún yín ni èmi kò sọ láti inú àpilẹ̀ṣe ti ara mi.”—Jòhánù 14:10.
Báwo ni àwọn alàgbà ṣe lè “di ọ̀rọ̀ ṣíṣeégbíyèlé mú ṣinṣin”? Nípa gbígbé àwọn àwíyé wọn àti àwọn iṣẹ́ tí a ń yàn fún wọn ní àwọn ìpàdé karí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kí wọ́n ṣàlàyé, kí wọ́n sì tẹnu mọ́ àwọn ẹsẹ Bíbélì tí wọ́n lò. Àwọn àpèjúwe gbígbàfiyèsí tàbí àwọn ìtàn tí ń panilẹ́rìn-ín, ní pàtàkì bí a bá jẹ́ kí àṣejù wọ̀ ọ́, lè gbé ọkàn àwùjọ kúrò nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kí ó sì pe àfiyèsí sí ẹ̀bùn olùbánisọ̀rọ̀ náà. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, àwọn ẹsẹ Bíbélì ni yóò dé ọkàn àwùjọ, tí yóò sì sún wọn ṣiṣẹ́. (Sáàmù 19:7–9; 119:40; fi wé Lúùkù 24:32.) Irú àwọn àwíyé bẹ́ẹ̀ máa ń pe ìwọ̀nba àfiyèsí sí ènìyàn, wọ́n sì ń fi ògo púpọ̀ fún Ọlọ́run.
Ọ̀nà mìíràn tí àwọn alàgbà lè gbà di olùkọ́ tí ó túbọ̀ gbéṣẹ́ jẹ́ nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ ara wọn. Bí Pọ́ọ̀lù ṣe ran Tímótì lọ́wọ́, alàgbà kan lè ran òmíràn lọ́wọ́ lọ́nà kan náà. “Irin ni a fi ń pọ́n irin. Bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn kan ṣe máa ń pọ́n ojú òmíràn.” (Òwe 27:17; Fílípì 2:3) Àwọn alàgbà ń jàǹfààní nípa ṣíṣàjọpín èrò àti àbá. Alàgbà kan tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn sípò ṣàlàyé pé: “Alàgbà onírìírí kan fara balẹ̀ fi bí ó ṣe ń múra àwíyé ìtagbangba hàn mí. Nínú ìmúrasílẹ̀ rẹ̀, ó máa ń fi àwọn ìbéèrè mọ̀ ọ́n sínú, àkàwé, àpẹẹrẹ, tàbí àwọn ìrírí kúkúrú, àti àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí ó ti ṣèwádìí lé lórí dáradára kún un. Ó ti kọ́ mi bí mo ṣe lè fi onírúurú nǹkan kún àwọn àwíyé mi, kí ó má baà jẹ́ ọ̀rọ̀ tí kò tani jí, tí ó tètè ń súni.”
Gbogbo àwa tí a ń gbádùn àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn, yálà a jẹ́ alàgbà, ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, tàbí aṣáájú ọ̀nà, ní láti ṣìkẹ́ ẹ̀bùn wa. Kété kí Pọ́ọ̀lù tó kú, ó rán Tímótì létí ‘láti máa ru ẹ̀bùn [khaʹri·sma] Ọlọ́run tí ń bẹ nínú rẹ̀ sókè bí iná,’ èyí tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ẹ̀bùn àkànṣe ti ẹ̀mí mímọ́ nínú ọ̀ràn ti Tímótì. (2 Tímótì 1:6) Nínú agboolé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, lọ́pọ̀ ìgbà, iná wulẹ̀ máa ń jẹ́ ẹ̀yìn iná tí ń kẹ̀. Ó ṣeé ṣe láti ‘ru ú sókè’ láti mú iná rẹ̀ jó sí i, kí ilé sì móoru. Nípa bẹ́ẹ̀, a rọ̀ wá láti fi ọkàn sí àwọn iṣẹ́ àyànfúnni wa, kí a sì lo agbára wa nínú rẹ̀, kí a máa ru ẹ̀bùn ẹ̀mí èyíkéyìí tí wọ́n bá fi síkàáwọ́ wa sókè bí iná.
Àwọn Ẹ̀bùn Ẹ̀mí Tí A Ní Láti Ṣàjọpín
Ìfẹ́ tí Pọ́ọ̀lù ní fún àwọn arákùnrin rẹ̀ ní Róòmù sún un láti kọ̀wé pé: “Nítorí aáyun ń yun mí láti rí yín, kí n lè fi ẹ̀bùn [khaʹri·sma] ẹ̀mí díẹ̀ fún yín, kí a lè fìdí yín múlẹ̀ gbọn-in; tàbí, kí a kúkú wí pé, kí pàṣípààrọ̀ ìṣírí lè wà láàárín yín, láti ọ̀dọ̀ ẹnì kọ̀ọ̀kan nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ ẹnì kejì, tiyín àti tèmi.” (Róòmù 1:11, 12) Pọ́ọ̀lù wo agbára tí a ní láti gbé ìgbàgbọ́ àwọn ẹlòmíràn ró nípa bíbá wọn sọ̀rọ̀ bí ẹ̀bùn ẹ̀mí. Ṣíṣe pàṣípààrọ̀ irú àwọn ẹ̀bùn ẹ̀mí bẹ́ẹ̀ yóò yọrí sí fífún ìgbàgbọ́ lókun, àti fífún ẹnì kìíní-kejì ní ìṣírí.
Dájúdájú a nílò èyí. Nínú ètò búburú tí a ń gbé yìí, gbogbo wa ń dojú kọ másùnmáwo lọ́nà kan ṣáá. Ṣùgbọ́n, ṣíṣe pàṣípààrọ̀ ìṣírí déédéé lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa forí tì í. Èrò ṣíṣe pàṣípààrọ̀—fífúnni àti gbígbà—ṣe pàtàkì fún bíbá a lọ ní níní okun tẹ̀mí. Òtítọ́ ni pé gbogbo wa nílò ìṣírí lóòrèkóòrè, ṣùgbọ́n gbogbo wa lè gbé ẹnì kìíní-kejì ró bákan náà.
Bí a bá wà lójúfò láti kíyèsí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa tí ó sorí kọ́, ó lè ṣeé ṣe fún wa láti ‘tu àwọn tí ó wà nínú ìpọ́njú èyíkéyìí nínú pẹ̀lú ìtùnú tí Ọlọ́run fi ń tu àwa tìkára wa nínú.’ (2 Kọ́ríńtì 1:3-5) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì fún ìtùnú (pa·raʹkle·sis) túmọ̀ ní ṣangiliti sí “pípè sí ẹ̀gbẹ́ ẹni.” Bí a bá wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ arákùnrin wa tàbí arábìnrin wa láti pèsè ìrànlọ́wọ́ fún un, nígbà tí ó bá nílò rẹ̀, kò sí àní-àní pé àwa pẹ̀lú yóò rí ìtìlẹ́yìn onífẹ̀ẹ́ kan náà gbà bí a bá nílò rẹ̀.—Oníwàásù 4:9, 10; fi wé Ìṣe 9:36-41.
Ìbẹ̀wò onífẹ̀ẹ́ ti olùṣọ́ àgùntàn tí àwọn alàgbà ń ṣe pẹ̀lú ń ṣàǹfààní ńlá. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìgbà kan wà tí a ń ṣèbẹ̀wò láti fúnni ní ìmọ̀ràn tí a gbé karí Ìwé Mímọ́ lórí ọ̀ràn tí ń béèrè àfiyèsí, ọ̀pọ̀ jù lọ ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn jẹ́ àkókò fún fífúnni níṣìírí, àkókò ‘títu ọkàn-àyà nínú.’ (Kólósè 2:2) Nígbà tí àwọn alábòójútó bá ṣe irú ìbẹ̀wò tí ń fún ìgbàgbọ́ lókun bẹ́ẹ̀, wọ́n ń fúnni ní ẹ̀bùn ẹ̀mí ní tòótọ́. Bí Pọ́ọ̀lù, wọ́n yóò rí irú fífúnni ní nǹkan lọ́nà tí kò lẹ́gbẹ́ yìí gẹ́gẹ́ bí èyí tí ń mérè wá, ‘aáyun’ àwọn arákùnrin wọn yóò sì máa yun wọ́n.—Róòmù 1:11.
Bí ọ̀ràn alàgbà kan ní Sípéènì, tí ó sọ ìrírí tí ó tẹ̀ lé e yìí, ti rí nìyẹn: “Ricardo, ọmọdékùnrin ọlọ́dún 11 kan, dàbí ẹni tí kò fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí àwọn ìpàdé àti nínú ìjọ lápapọ̀. Nítorí náà, mo sọ fún àwọn òbí Ricardo láti fún mi láyè láti bẹ ọmọ wọn wò, kíá ni wọ́n sì gbà fún mi láti ṣe bẹ́ẹ̀. Orí òkè ni wọ́n ń gbé, nǹkan bí ìrìn àjò wákàtí kan sí ilé mi, nínú ọkọ̀. Ó ṣe kedere pé inú Ricardo dùn láti rí ìfẹ́ tí mo ní nínú rẹ̀, ó sì dáhùn padà lójú ẹsẹ̀. Kò pẹ́ tí ó fi di akéde tí kò tí ì ṣe batisí àti mẹ́ńbà aláápọn nínú ìjọ. Àkópọ̀ ìwà tí ó túbọ̀ ń fi ayọ̀ hàn, tí ó sì lọ́yàyà rọ́pò ìwà àìkìítúraká tí ó ní tẹ́lẹ̀. Àwọn bí mélòó kan nínú ìjọ béèrè pé: ‘Kí ní ṣẹlẹ̀ sí Ricardo?’ Ó jọ bí pé ìgbà àkọ́kọ́ tí wọn yóò ṣàkíyèsí rẹ̀ nìyí. Ní ríronú sẹ́yìn lórí ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn ṣíṣe kókó yẹn, mo nímọ̀lára pé àǹfààní tí mo jẹ ju ti Ricardo. Ojú rẹ̀ máa ń kún fún ayọ̀, nígbà tí ó bá wọ Gbọ̀ngàn Ìjọba, ó sì máa ń sáré wá kí mi. Ohun ayọ̀ ni láti rí bí ó ti ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí.”
Kò sí àní-àní pé, ìbùkún jìngbìnnì ń bẹ nínú ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn, bí èyí. Irú ìbẹ̀wò bẹ́ẹ̀ wà ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀bẹ̀ Jésù pé: “Máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn àgùntàn mi kéékèèké.” (Jòhánù 21:16) Dájúdájú, kì í ṣe àwọn alàgbà nìkan ni ó lè fúnni ní irú ẹ̀bùn ẹ̀mí bẹ́ẹ̀. Olúkúlùkù nínú ìjọ ni ó lè ru àwọn ẹlòmíràn sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà. (Hébérù 10:23, 24) Bí a ti ń fokùn so àwọn apọ́nkè tí ń pọ́n orí òkè pọ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ìdè tẹ̀mí so àwa náà pọ̀. Láìṣeéyẹ̀sílẹ̀, ohun tí a ń sọ, tí a sì ń ṣe ń nípa lórí àwọn yòókù. Òdì ọ̀rọ̀ tàbí ṣíṣelámèyítọ́ ẹni lọ́nà lílekoko lè dẹ ìdè tí ó so wá pọ̀. (Éfésù 4:29; Jákọ́bù 3:8) Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ọ̀rọ̀ oníṣìírí tí a fìṣọ́ra yàn, àti ìrànlọ́wọ́ onífẹ̀ẹ́, lè ran àwọn ará wa lọ́wọ́ láti borí ìṣòro wọn. Ní ọ̀nà yìí, a óò máa ṣàjọpín ẹ̀bùn ẹ̀mí, tí ìníyelórí rẹ̀ kò lópin.—Òwe 12:25.
Gbígbé Ògo Ọlọ́run Yọ Lọ́nà Tí Ó Túbọ̀ Pọ̀ Sí I
Ó ṣe kedere pé gbogbo Kristẹni ni ó ní ìwọ̀n òòfà agbára ìdánilọ́rùn. A ti fi ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun tí kò ṣeé fowó rà jíǹkí wa. A tún ní ẹ̀bùn ẹ̀mí tí a lè ṣàjọpín pẹ̀lú ara wa. A sì lè làkàkà láti ru àwọn ẹlòmíràn sókè tàbí láti sún wọn ṣe ohun tí ó tọ́. Àwọn mìíràn ní àfikún ẹ̀bùn ní ọ̀nà ti àǹfààní iṣẹ́ ìsìn. Gbogbo ẹ̀bùn wọ̀nyí jẹ́ ẹ̀rí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run. Níwọ̀n bí ẹ̀bùn èyíkéyìí tí a lè ní ti wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, a kò ní ìdí kankan láti ṣògo.—1 Kọ́ríńtì 4:7.
Gẹ́gẹ́ bí Kristẹni, yóò dára láti bi ara wa pé, ‘Èmi yóò ha lo ìwọ̀n òòfà agbára ìdánilọ́rùn èyíkéyìí tí mo lè ní láti fi mú ògo wá fún Jèhófà, Olùfúnni ní “gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé”? (Jákọ́bù 1:17) Èmi yóò ha fara wé Jésù, kí n sì ṣèránṣẹ́ fún àwọn ẹlòmíràn débi tí agbára àti ipò mi yọ̀ǹda?’
Àpọ́sítélì Pétérù ṣàkópọ̀ ojúṣe wa ní ọ̀nà yìí: “Níwọ̀n yíyẹ gẹ́gẹ́ bí olúkúlùkù ti rí ẹ̀bùn [khaʹri·sma] kan gbà, ẹ lò ó fún ṣíṣe ìránṣẹ́ fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì gẹ́gẹ́ bí ìríjú àtàtà fún inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run tí a fi hàn ní onírúurú ọ̀nà. Bí ẹnikẹ́ni bá ń sọ̀rọ̀, kí ó sọ̀rọ̀ bí pé àwọn ọ̀rọ̀ ìkéde ọlọ́wọ̀ Ọlọ́run ni; bí ẹnikẹ́ni bá ń ṣe ìránṣẹ́, kí ó ṣe ìránṣẹ́ bí ẹni tí ó gbára lé okun tí Ọlọ́run ń pèsè; kí a lè yin Ọlọ́run lógo nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ Jésù Kristi.”—1 Pétérù 4:10, 11.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àròpọ̀ 913 ènìyàn ló kú, tí Jim Jones fúnra rẹ̀ wà lára wọn.
[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 23]
Corbis-Bettmann
UPI/Corbis-Bettmann