‘Gbigbani Niyanju Lori Ipilẹ Ifẹ’
NI NǸKAN bii 60 si 61 C.E., ẹrú kan ti ó fẹsẹ̀fẹ fi Roomu silẹ ó sì bẹrẹ irin-ajo onibusọ 900 kan lọ si ile ni Kolose, ilu nla kan ni guusu iwọ-oorun Asia Kekere. Ó mú ihin-iṣẹ àfọwọ́kọ kan, ti a kọ lati ọwọ ẹni ti kì í ṣe ẹlomiran ju apọsiteli Pọọlu lọ dání fun oluwa rẹ̀. Lonii, lẹta yẹn jẹ́ apakan Bibeli orukọ ẹni ti ó gbà á ni o sì ń jẹ́, Filemoni.
Lẹta naa sí Filemoni jẹ́, àgbà-iṣẹ́ niti ironu ọlọgbọn-ẹwẹ, ayinileropada. Bi o ti wu ki o ri, eyi ti o ṣe pataki ju ni pe, ó ni ọpọlọpọ awọn ẹ̀kọ́ ti ó ṣee múlò fun awọn Kristẹni lonii ninu, eyi ti ọ̀kan ninu rẹ̀ jẹ́ iniyelori gbigba ẹnikinni keji niyanju lori ipilẹ ifẹ Kristẹni. Ẹ jẹ ki a wo lẹta kukuru ṣugbọn ti ó ni agbara ìdarí alagbara yii fínnífínní sii.
Olùfẹsẹ̀fẹẹ Kan Pada
Filemoni jẹ́ Kristẹni kan, mẹmba ìjọ Kristẹni kan ti a nifẹẹ gidigidi. (Filemoni 4, 5) Họwu, ìjọ ti ó wà nibẹ lo ile rẹ̀ gẹgẹ bi ibi ipade! (Ẹsẹ 2) Siwaju sii, Filemoni ni ó jẹ́ ojulumọ apọsiteli Pọọlu fúnraarẹ̀; ó lè jẹ́ pe apọsiteli naa jẹ́ ohun eelo ninu dídi Kristẹni rẹ̀. Loootọ, Pọọlu fihan pe oun gẹgẹ bi ẹnikan kò waasu ni Kolose. (Kolose 2:1) Bi o ti wu ki o ri, ó lo ọdun meji ni Efesu, ni wiwaasu dé iwọn àyè ti o fi jẹ́ pe “gbogbo awọn tí ń gbé Asia [eyi ti o ni Kolose ninu] gbọ́ ọrọ Jesu Oluwa.” (Iṣe 19:10) Filemoni ni ó ṣeeṣe ki ó wà laaarin awọn olùgbọ́ ti wọn dahun pada naa.
Lọna kan ṣáá, bii ọpọlọpọ awọn ọkunrin ọlọ́rọ̀ ti sáà akoko yẹn, Filemoni jẹ́ olówó ẹrú. Ni akoko igbaani, jíjẹ́ ẹrú ki i fi ìgbà gbogbo rẹni silẹ. Laaarin awọn Juu, tita ara-ẹni tabi awọn mẹmba idile ẹni si oko ẹrú jẹ́ ọ̀nà ti a tẹwọgba fun sisan gbèsè. (Lefitiku 25:39, 40) The International Standard Bible Encyclopedia sọrọ nipa ìgbà awọn ará Roomu pe: “Ọpọ iye awọn eniyan ta araawọn soko ẹrú fun oniruuru idi, leke gbogbo rẹ̀ lati wọnu igbesi-aye kan ti ó tubọ ṣe gbẹdẹmukẹ tí ó sì tubọ láàbò ju gbigbe gẹgẹ bi òtòṣì eniyan, ti a bí ni ominira, lati rí awọn iṣẹ akanṣe, ati lati gun àkàbà ẹgbẹ-oun-ọgba. . . . Ọpọlọpọ ti wọn kì í ṣe ará Roomu ta araawọn fun awọn ara-ilu Roomu pẹlu ireti ti a dalare naa, ti a fi ofin Roomu dari, ti didi ara-ilu Roomu funraawọn nigba ti a bá dá wọn kalẹ lominira [sọ dominira].”
Bi o ti wu ki o ri, iṣoro kan dide, nigba ti ọ̀kan ninu awọn ẹrú Filemoni, ọkunrin kan ti a pè ni Onesimu, kọ̀ ọ́ silẹ ó sì salọ si Roomu, ó ṣeeṣe ki o tilẹ jí owo lápò Filemoni lati fi gbọ́ ti ìsálọ rẹ̀. (Ẹsẹ 18) Ni Roomu, Onesimu ṣalabaapade apọsiteli Pọọlu, ẹni ti o jẹ́ ẹlẹ́wọ̀n nibẹ.
Ẹrú “alaiwulo tẹlẹri” naa ti ó ti sá fun ìsìn-ẹrú di Kristẹni kan nisinsinyi. Ó fi araarẹ̀ si ikawọ Pọọlu ó sì ṣe awọn iṣẹ-isin wiwulo fun apọsiteli Pọọlu ti a fi sẹwọn naa. Kò yani lẹnu pe Onesimu rí àyè kan ninu “ìfẹ́ni oníkẹ̀ẹ́ ti” Pọọlu fúnraarẹ̀ ti ó sì di “arakunrin olufẹ” fun Pọọlu!—Ẹsẹ 11, 12, 16, NW.
Pọọlu ìbá ti fẹ́ lati jẹ́ ki Onesimu duro lọdọ rẹ̀. Ṣugbọn Filemoni ní ẹ̀tọ́ ofin gẹgẹ bi olówó Onesimu. Onesimu ni a tipa bẹẹ rọ̀ lati pada sẹnu iṣẹ-isin ọ̀gá rẹ̀ labẹ òfin. Bawo, nigba naa ni Filemoni yoo ṣe gbà á? Oun yoo ha fi ibinu beere fun ẹ̀tọ́ rẹ̀ lati fi ijiya mimuna jẹ ẹ́ bi? Oun yoo ha pe ijotitọ ijẹwọ Onesimu gẹgẹ bii Kristẹni ẹlẹgbẹ rẹ̀ nija bi?
Yiyanju Awọn Ọ̀ràn Pẹlu Ifẹ
Pọọlu ni a sún lati kọwe si Filemoni nipa Onesimu. Ó kọ lẹta naa funraarẹ, lai lo akọwe kan gẹgẹ bi àṣà rẹ̀. (Ẹsẹ 19) Lo iwọnba iṣẹju diẹ lati ka lẹta kukuru ti Filemoni latokedelẹ. Iwọ yoo ṣakiyesi pe lẹhin sisọ ẹni ti oun jẹ́ ati didaniyan “inurere ailẹtọọsi ati alaafia” fun Filemoni ati agbo ile rẹ̀, Pọọlu gboriyin fún Filemoni fun ‘ifẹ ati igbagbọ rẹ̀ siha Oluwa Jesu ati siha gbogbo awọn eniyan mímọ́.’—Ẹsẹ 1-7, NW.
Ó ti lè rọrun fun Pọọlu lati lo ọla-aṣẹ rẹ̀ gẹgẹ bi apọsiteli ki ó sì ‘paṣẹ fun Filemoni lati ṣe ohun ti ó bojumu,’ ṣugbọn kaka bẹẹ Pọọlu ‘gbani niyanju lori ipilẹ ifẹ.’ Ó jẹrii si otitọ naa pe Filemoni ti di arakunrin Kristẹni kan nitootọ, ẹni kan ti o ti fi araarẹ̀ hàn gẹgẹ bi ẹni ti ó wulo fun Pọọlu. Apọsiteli naa gbà pe: “Ìbá wù mi lati dá [Onesimu] duro sọdọ araami pe dipo iwọ oun ìbá maa ba a niṣo ni ṣiṣeranṣẹ fun mi ninu ìdè ẹ̀wọ̀n ti mo mú mọra nitori ihinrere. Ṣugbọn,” ni Pọọlu ń bá ọrọ rẹ̀ lọ, “laisi ilohunsi rẹ emi kò fẹ́ ṣe ohunkohun, kí iṣarasihuwa daradara rẹ baa lè jẹ́, kì í ṣe bi àfipáṣe, bikoṣe lati inu omiira ifẹ-inu tìrẹ funraarẹ.”—Ẹsẹ 8-14, NW.
Pọọlu tipa bayii rọ Filemoni lati gba ẹrú rẹ̀ tẹlẹri pada gẹgẹ bi arakunrin kan. “Fi inurere tẹwọgba a ni ọna ti iwọ ìbá fi gbà mi,” ni Pọọlu kọwe. Kì í ṣe pe a o fi dandan dá Onesimu silẹ kuro ninu ìsìn-ẹrú. Pọọlu kò gbiyanju lati yí eto ẹgbẹ-oun-ọgba ti ó wà ni ọjọ rẹ̀ pada. (Fiwe Efesu 6:9; Kolose 4:1; 1 Timoti 6:2.) Bi o tilẹ ri bẹẹ, ipo ibatan ẹrú-òun-ọ̀gá ni a o mú rọrun laiṣiyemeji nipasẹ ìdè Kristẹni ti ó wà laaarin Onesimu ati Filemoni nisinsinyi. Filemoni yoo wo Onesimu “gẹgẹ bi ẹni ti o ju ẹrú lọ, gẹgẹ bi arakunrin olufẹ.”—Ẹsẹ 15-17, NW.
Ki ni, bi o ti wu ki o ri, nipa gbèsè ti Onesimu ti lè jẹ, boya gẹgẹ bi iyọrisi iwa olè? Lẹẹkan sii, Pọọlu fi ọ̀ràn lọ ipo ọ̀rẹ́ pẹlu Filemoni, ni wiwi pe: “Bí oun bá ti ṣe aitọ kankan si ọ tabi o jẹ ọ́ ni gbèsè ohunkohun, ka eyi si mi lọrun.” Pọọlu fi igbọkanle han pe Filemoni yoo fi ẹmi idariji hàn, ni lilọ rekọja awọn ibeere ti Pọọlu ṣe. Niwọn bi Pọọlu ti reti lati di ẹni ti a dasilẹ laipẹ, oun tilẹ ṣeto lati gbadun alejo ṣiṣe Filemoni ni ọjọ-ọla ti o sunmọle. Lẹhin fifunni ni awọn ikini diẹ siwaju sii ati dídàníyàn “inurere ailẹtọọsi ti Jesu Kristi Oluwa” fun Filemoni, Pọọlu pari lẹta rẹ̀.—Ẹsẹ 18-25, NW.
Ẹ̀kọ́ fun Awọn Kristẹni Lonii
Iwe Filemoni kún fun awọn ẹ̀kọ́ ti wọn ṣee múlò fun awọn Kristẹni lonii. Fun ohun kan, ó rán wa létí aini naa lati jẹ́ adarijini, ani nigba ti onigbagbọ ẹlẹgbẹ wa kan bá ti ṣẹ̀ wá lọna wiwuwo. “Bi ẹyin bá fi ẹṣẹ awọn eniyan jì wọn,” ni Jesu Kristi wí, “Baba yin ti ń bẹ ni ọrun yoo fi ẹṣẹ tiyin jì yin.”—Matiu 6:14.
Awọn wọnni ti wọn wà ni ipo aṣẹ laaarin ìjọ Kristẹni lonii lè janfaani ni pataki lati inu iwe Filemoni. Ó yẹ ni fifiyesi pe Pọọlu fà sẹhin kuro ninu lilo ọla-aṣẹ ipo apọsiteli rẹ̀ lati paṣẹ fun Filemoni lati ṣe ohun ti ó bojumu. Siwaju sii, Pọọlu kò fi dandan beere pe ki a yọnda fun Onesimu lati duro ni Roomu ninu iṣẹ-isin Pọọlu. Pọọlu bọwọ fun awọn ẹ̀tọ́ ohun ìní awọn ẹlomiran. Oun tún mọriri pe nigba ti ọ̀nà ìgbàbójútó ọran pẹlu àṣẹ oníkùmọ̀ ti lè yọrisi gbígbà, yoo dara jù fun Filemoni lati gbegbeesẹ lati inu ọkan-aya rẹ̀ wá. Ó ṣe ifọranlọ ti a gbekari ifẹ ki ó baa lè fa idahunpada atọkanwa yọ.
Nitori naa awọn alagba Kristẹni lonii kò gbọdọ maa “jẹ gàba lori awọn wọnni ti wọn jẹ́ ogún Ọlọrun” nipa ṣiṣi agbara wọn lò tabi nipa lilo ọ̀nà ibalo lilekoko, àṣẹ oníkùmọ̀ pẹlu agbo. (1 Peteru 5:1-3, NW) Jesu wi pe: “Ẹyin mọ pe awọn ọba Keferi a maa lo agbara lori wọn, ati awọn ẹni-nla ninu wọn a maa fi ọlá tẹri wọn ba. Ṣugbọn ki yoo rí bẹẹ laaarin yin.” (Matiu 20:25, 26) Awọn alaboojuto ni gbogbogboo rí i pe awọn mẹmba agbo a maa fi pupọpupọ dahun pada si fifi ìfẹ́ rọni ju awọn aṣẹ lọ. Awọn wọnni ti wọn ń jiya lati inu ikarisọ mọriri awọn alaboojuto ti wọn yoo fi inurere wá akoko lati fetisilẹ si awọn isoro wọn ki wọn sì funni ni imọran olóye.
Lẹta Pọọlu rán awọn alagba létí siwaju sii nipa iniyelori igboriyin funni ati ọgbọ́n-ẹ̀wẹ́. Ó bẹrẹ nipa jijẹwọ pe ‘awọn ifẹni oníkẹ̀ẹ́ ti awọn ẹni mímọ́ ni a tù lara nipasẹ’ Filemoni. (Ẹsẹ 7, NW) Igboriyin funni olootọ-ọkan yii laiṣiyemeji fi Filemoni sinu itẹsi èrò oníṣìípayá ọkàn. Bakan naa lonii, imọran tabi amọran niye ìgbà ni a lè mú tunilara pẹlu igboriyin funni olotiitọ-ọkan, ati ọlọyaya. Iru imọran bẹẹ kò sì gbọdọ jẹ́, eyi ti ó ṣe ṣàkó tabi aláìlọ́gbọ́n-ẹ̀wẹ́, ṣugbọn ti “a fi iyọ̀ dùn” lọna ọ̀làwọ́ ki ó baa lè tubọ dùn yùngbà mọ́ olùgbọ́.—Kolose 4:6.
Pọọlu siwaju sii sọ igbọkanle jade pe Filemoni yoo ṣe ohun ti ó tọ́, ni wiwi pe: “Ni gbigbẹkẹle ìṣègbọràn rẹ, emi ń kọwe si ọ, ni mímọ̀ pe iwọ yoo tilẹ ṣe ju awọn ohun ti mo wí lọ.” (Ẹsẹ 21, NW) Ẹyin alagba, ẹ ha fi igbọkanle kan naa han ninu awọn Kristẹni ẹlẹgbẹ yin bi? Eyi kò ha ràn wọn lọwọ lati fẹ́ lati ṣe ohun ti ó tọ́ bi?
Lọna ti o fanilọkan mọra, awọn obi niye ìgbà rii pe fifi igbọkanle han ninu awọn ọmọ wọn tún ní ipa rere kan. Nipa mímọ iniyelori igbọran onimuuratan—ifẹ lati ṣe rekọja dídé oju awọn ohun ti a beere fun—awọn obi lè fun awọn ọmọ wọn ni iwọn ọlá. Aṣẹ tabi ohun ti awọn obi beere fun, gbọdọ jẹ́ eyi ti a fi ìró ohùn oninuure, onifẹẹ ṣe, nigba ti ó bá ṣeeṣe. Ẹmi igbatẹniro ni ó yẹ ki a fihan, ki a funni ni awọn idi. Awọn obi gbọdọ fi tọyayatọyaya gboriyin fun awọn ọmọ wọn nigba ti iru igboriyin funni bẹẹ bá yẹ ki wọn sì yẹra fun jíjẹ́ ẹni ti ó lekoko mọ wọn jù, ni pataki ni gbangba.
Ni oju ọna ironu kan naa, awọn ọkọ lè fi awọn animọ ilọgbọn-ninu ati inurere han, ni mimuratan lati yin awọn aya wọn. Eyi mú ki itẹriba ti aya gbadunmọni ki ó sì jẹ́ orisun itura ati ayọ!—Owe 31:28; Efesu 5:28.
Bi Filemoni ṣe huwa pada ní pàtó si lẹta Pọọlu ni a kò sọ. Bi o ti wu ki o ri, awa kò lè finuro o pe àgbésódì ni igbọkanle Pọọlu ninu rẹ̀ jẹ́. Ǹjẹ́ ki awọn Kristẹni alagba, obi, ati ọkọ lonii ri aṣeyọri bakan naa ninu awọn ibalo wọn, kì í ṣe nipa fifi ọ̀ranyàn muni, pípàṣẹ, tabi fifi agbara muni, ṣugbọn nipa “gbigbani niyanju lori ipilẹ ifẹ.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Dipo fifọran lọ ọla-aṣẹ rẹ̀ gẹgẹ bi apọsiteli, Pọọlu gba Filemoni niyanju lori ipilẹ ifẹ Kristẹni