Bí Jésù Kristi Ṣe Lè Ràn Wá Lọ́wọ́
OHUN tí Jésù Kristi ṣe láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ nígbà tó wà láyé kàmàmà. Ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ òótọ́ débi pé nígbà tí ẹnì kan tí gbogbo ẹ̀ ṣojú ẹ̀ sọ onírúurú ohun tó rí nínú ìgbésí ayé Jésù tán, ó tún sọ pé: “Ní ti tòótọ́, ọ̀pọ̀ nǹkan mìíràn wà pẹ̀lú tí Jésù ṣe, tí ó jẹ́ pé, bí a bá ní láti kọ̀wé kúlẹ̀kúlẹ̀ wọn ní kíkún, mo rò pé, ayé tìkára rẹ̀ kò ní lè gba àwọn àkájọ ìwé tí a bá kọ.” (Jòhánù 21:25) Níwọ̀n bí Jésù ti ṣe ohun tó pọ̀ gan-an tó bẹ́ẹ̀ ní ayé, a lè wá béèrè pé: ‘Báwo ló ṣe lè jẹ́ olùrànlọ́wọ́ wa ní ọ̀run? Ǹjẹ́ a lè jàǹfààní ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ Jésù nísinsìnyí?’
Ìdáhùn ìbéèrè wọ̀nyẹn ń mọ́kàn yọ̀ gan-an, ó sì tún ń fún ìdánilójú ẹni lókun. Bíbélì sọ fún wa pé, Kristi wọlé “sí ọ̀run, nísinsìnyí láti fara hàn níwájú Ọlọ́run fúnra rẹ̀ fún wa.” (Hébérù 9:24) Kí ló ṣe fún wa? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé: “[Kristi] wọlé sínú ibi mímọ́ [“ní ọ̀run fúnra rẹ̀”], rárá, kì í ṣe pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ àwọn ewúrẹ́ àti ti àwọn ẹgbọrọ akọ màlúù, bí kò ṣe pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ òun fúnra rẹ̀, lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún tún un ṣe mọ́ láé, ó sì gba ìdáǹdè àìnípẹ̀kun fún wa.”— Hébérù 9:12; 1 Jòhánù 2:2.
Ìròyìn rere mà lèyí o! Dípò kí gígòkè tí Jésù gòkè re ọ̀run mú kí iṣẹ́ àgbàyanu tó ń ṣe nítorí àwọn èèyàn wá sópin, ńṣe ló jẹ́ kó lè ṣe púpọ̀ sí i fáráyé. Èyí jẹ́ nítorí pé Ọlọ́run lo inúrere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ tó kàmàmà, ó sì yan Jésù láti sìn bí “ìránṣẹ́ gbogbo ènìyàn”—àlùfáà àgbà—“ní ọwọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọba Ọlọ́lá ní ọ̀run.”—Hébérù 8:1, 2.
“Ìránṣẹ́ Gbogbo Ènìyàn”
Ohun tí a ń sọ ni pé, Jésù á jẹ́ ìránṣẹ́ fún gbogbo aráyé. Á máa ṣe irú iṣẹ́ tí àlùfáà àgbà Ísírẹ́lì máa ń ṣe nítorí àwọn olùjọ́sìn Ọlọ́run ní ayé àtijọ́. Kí sì ni iṣẹ́ náà? Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé: “Olúkúlùkù àlùfáà àgbà ni a yàn sípò láti fi àwọn ẹ̀bùn àti ohun ẹbọ rúbọ; nípa bẹ́ẹ̀, ó pọndandan fún ẹni yìí [Jésù Kristi tó gòkè lọ sí ọ̀run] pẹ̀lú láti ní ohun kan láti fi rúbọ.”—Hébérù 8:3.
Jésù ní ohun kan láti fi rúbọ, ohun náà sì níyelórí ju ohun tí àlùfáà àgbà ń fi rúbọ láyé àtijọ́ lọ. “Bí ẹ̀jẹ̀ àwọn ewúrẹ́ àti ti àwọn akọ màlúù” bá lè sọ Ísírẹ́lì ìgbàanì di mímọ́ dé àyè kan nípa tẹ̀mí, “mélòómélòó ni ẹ̀jẹ̀ Kristi . . . yóò wẹ ẹ̀rí-ọkàn wa mọ́ kúrò nínú àwọn òkú iṣẹ́ kí a lè ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún Ọlọ́run alààyè?”—Hébérù 9:13, 14.
Ọ̀nà tí Jésù gbà jẹ́ ìránṣẹ́ gbogbo ènìyàn ta yọ gan-an, nítorí pé a ti fún un ní àìleèkú. Ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, “ó ti di dandan fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ láti di àlùfáà ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé nítorí tí ikú ṣèdíwọ́ fún wọn láti máa bá a lọ ní jíjẹ́ bẹ́ẹ̀.” Àmọ́, Jésù wá ńkọ́? Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Òun . . . ní iṣẹ́ àlùfáà rẹ̀ láìsí àwọn arọ́pò kankan. Nítorí náà, ó lè gba àwọn tí ń tọ Ọlọ́run wá nípasẹ̀ rẹ̀ là pátápátá pẹ̀lú, nítorí tí òun wà láàyè nígbà gbogbo láti jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún wọn.” (Hébérù 7:23-25; Róòmù 6:9) Lóòótọ́ ni, a ní ìránṣẹ́ kan lọ́wọ́ ọ̀tún Ọlọ́run, ẹni tó ‘wà láàyè nígbà gbogbo láti jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún wa.’ Ìwọ sáà ronú nípa ohun tí ìyẹn túmọ̀ sí fún wa lónìí!
Nígbà tí Jésù wà láyé, àwọn èèyàn máa ń rọ́ lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ pé kó ran àwọn lọ́wọ́, nígbà míì wọ́n máa ń rin ọ̀nà jíjìn gan-an láti lè rí ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ gbà. (Mátíù 4:24, 25) Bí Jésù ṣe wà ní ọ̀run yẹn, àrọ́wọ́tó àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè ló wà. Láti ọ̀run tó wà tó ti ń rí wa yẹn, ìgbà gbogbo ló wà lárọ̀ọ́wọ́tó gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ gbogbo ènìyàn.
Irú Àlùfáà Àgbà Wo Ni Jésù?
Àpèjúwe tí ìwé Ìhìn Rere ṣe nípa Jésù Kristi mú ká gbà gbọ́ pé ó ń ran èèyàn lọ́wọ́, ó sì ní ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́. Irú ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ tó ní mà ga o! Ní ìgbà bíi mélòó kan, àwọn èèyàn lọ bá a ní àkókò tó fẹ́ fi gbọ́ tara rẹ̀ nígbà tí òun àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ fẹ́ sinmi. Dípò kó ronú pé wọ́n ń dí òun lọ́wọ́ láti gbádùn ara òun láìsí ìyọlẹ́nu àti ariwo, “àánú wọ́n ṣe é,” ìyẹn gbogbo àwọn tó fẹ́ kó ran àwọn lọ́wọ́. Kódà, nígbà tí ó ti rẹ Jésù, tí ebi ń pa á, tí òùngbẹ ń gbẹ ẹ́, “ó . . . fi inú rere gbà wọ́n” ó sì ṣe tán láti gbàgbé oúnjẹ kóun sáà ti lè ṣèrànwọ́ fún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí wọ́n fẹ́ ronú pìwà dà tọkàntọkàn yìí.—Máàkù 6:31-34; Lúùkù 9:11-17; Jòhánù 4:4-6, 31-34.
Nítorí pé àánú àwọn èèyàn ṣe Jésù ló ṣe gbégbèésẹ̀ pàtó láti yanjú ìṣòro àwọn èèyàn nípa ti ara, ní ti ìmí ẹ̀dùn, àti nípa tẹ̀mí. (Mátíù 9:35-38; Máàkù 6:35-44) Síwájú sí i, ó kọ́ wọn láti wá ìtura àti ìtùnú pípẹ́ títí. (Jòhánù 4:7-30, 39-42) Fún àpẹẹrẹ, ìkésíni rẹ̀ pé kí àwọn èèyàn wá sọ́dọ̀ òun tuni lára gan-an, ó ké sí wọn pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá, tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, dájúdájú, èmi yóò sì tù yín lára. Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín, kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, nítorí onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà ni èmi, ẹ ó sì rí ìtura fún ọkàn yín.”—Mátíù 11:28, 29.
Ìfẹ́ tí Jésù ní fún àwọn èèyàn pọ̀ gan-an débi pé ó wá fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún aráyé ẹlẹ́ṣẹ̀ níkẹyìn. (Róòmù 5:6-8) Látàrí èyí ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi sọ pé: “Ẹni [Jèhófà Ọlọ́run] tí kò dá Ọmọ tirẹ̀ pàápàá sí, ṣùgbọ́n tí ó jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́wọ́ fún gbogbo wa, èé ṣe tí òun kò ní tún fi inú rere fún wa ní gbogbo ohun yòókù pẹ̀lú rẹ̀? . . . Kristi Jésù ni ẹni tí ó kú, bẹ́ẹ̀ ni, jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹni tí a gbé dìde kúrò nínú òkú, ẹni tí ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run, ẹni tí ń jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún wa pẹ̀lú.”—Róòmù 8:32-34.
Àlùfáà Àgbà Tó Lè Báni Kẹ́dùn
Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn, ebi pa Jésù, òùngbẹ gbẹ ẹ́, àárẹ̀ mú un, ó jẹ̀rora, ó jìyà, ó sì kú. Másùnmáwo àti wàhálà tó fara dà múra rẹ̀ sílẹ̀ lọ́nà tí kò láfiwé láti lè sìn gẹ́gẹ́ bí Àlùfáà Àgbà fún aráyé tí ìyà ń jẹ. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ó di dandan fún [Jésù] láti dà bí ‘àwọn arákùnrin’ rẹ̀ lọ́nà gbogbo, kí ó lè di àlùfáà àgbà tí ó jẹ́ aláàánú àti olùṣòtítọ́ nínú àwọn ohun tí ó jẹ mọ́ ti Ọlọ́run, kí ó bàa lè rú ẹbọ ìpẹ̀tù fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn. Nítorí níwọ̀n bí òun fúnra rẹ̀ ti jìyà nígbà tí a ń dán an wò, ó lè wá ṣe àrànṣe fún àwọn tí a ń dán wò.”—Hébérù 2:17, 18; 13:8.
Jésù fi hàn pé òun tóótun àti pé òun fẹ́ láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n ṣé ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé ó ní láti máa pàrọwà sí Ọlọ́run tó le koko mọ́ èèyàn, tí kò láàánú lójú, tó sì ń lọ́ra láti dárí jini? Rárá o, nítorí pé Bíbélì mú un dá wa lójú pé, “Ẹni rere ni . . . Jèhófà, [ó] sì ṣe tán láti dárí jini.” Ó tún sọ pé: “Bí a bá jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, òun jẹ́ aṣeégbíyèlé àti olódodo tí yóò fi dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, tí yóò sì wẹ̀ wá mọ́ kúrò nínú gbogbo àìṣòdodo.” (Sáàmù 86:5; 1 Jòhánù 1:9) Ká sòótọ́, àwọn ọ̀rọ̀ àti ìwà oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ tí Jésù ń hù jẹ́ àfihàn ìyọ́nú, àánú, àti ìfẹ́ tí Bàbá rẹ̀ pẹ̀lú ní.— Jòhánù 5:19; 8:28; 14:9, 10.
Báwo ni Jésù ṣe mú ìtura bá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ronú pìwà dà? Nípa ríràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn nínú ìsapá àtọkànwá wọn láti mú inú Ọlọ́run dùn. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé sí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró bí tirẹ̀, ó ṣàkópọ̀ ọ̀ràn náà nípa sísọ pé: “Nítorí náà, níwọ̀n bí a ti ní àlùfáà àgbà títóbi, ẹni tí ó ti la ọ̀run kọjá, Jésù Ọmọ Ọlọ́run, ẹ jẹ́ kí a rọ̀ mọ́ ìjẹ́wọ́ wa nípa rẹ̀. Nítorí àwa ní gẹ́gẹ́ bí àlùfáà àgbà, kì í ṣe ẹni tí kò lè báni kẹ́dùn fún àwọn àìlera wa, bí kò ṣe ẹni tí a ti dán wò ní gbogbo ọ̀nà bí àwa fúnra wa, ṣùgbọ́n tí kò ní ẹ̀ṣẹ̀. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a sún mọ́ ìtẹ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí pẹ̀lú òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ, kí a lè rí àánú gbà, kí a sì rí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí fún ìrànlọ́wọ́ ní àkókò tí ó tọ́.”—Hébérù 4:14-16.
“Ìrànlọ́wọ́ Ní Àkókò Tí Ó Tọ́”
Àmọ́, kí ni a lè ṣe táa bá ní àwọn ìṣòro tí a rò pé ó le ju agbára wa lọ, bí àìsàn burúkú, kí ẹ̀rí-ọkàn máa dani láàmú, ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn, àti ìsoríkọ́? A lè lo ìpèsè tí Jésù alára gbára lé ní gbogbo ìgbà—àǹfààní iyebíye ti gbígbàdúrà. Fún àpẹẹrẹ, ní alẹ́ ọjọ́ tó ṣáájú ọjọ́ tó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún wa, “ó ń bá a lọ ní títúbọ̀ fi taratara gbàdúrà; òógùn rẹ̀ sì wá dà bí ẹ̀kán ẹ̀jẹ̀ tí ń jábọ́ sí ilẹ̀.” (Lúùkù 22:44) Bẹ́ẹ̀ ni, Jésù mọ bó ṣe ń rí tí a bá gbàdúrà sí Ọlọ́run kíkankíkan. Ó “ṣe ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ àti ìtọrọ pẹ̀lú sí Ẹni tí ó lè gbà á là kúrò nínú ikú, pẹ̀lú igbe ẹkún kíkankíkan àti omijé, a sì gbọ́ ọ pẹ̀lú ojú rere nítorí ìbẹ̀rù rẹ̀ fún Ọlọ́run.”—Hébérù 5:7.
Jésù mọ bó ṣe máa ń rí lára èèyàn tí wọ́n bá “gbọ́ ọ pẹ̀lú ojú rere,” tí wọ́n sì fún un lókun. (Lúùkù 22:43) Síwájú sí i, ó ṣèlérí pé: “Bí ẹ bá béèrè fún ohunkóhun lọ́wọ́ Baba, yóò fi í fún yín ní orúkọ mi. . . . Ẹ béèrè, ẹ ó sì rí gbà, kí a lè sọ ìdùnnú yín di kíkún.” (Jòhánù 16:23, 24) Nítorí náà, a lè tọrọ nǹkan lọ́wọ́ Ọlọ́run, ká sì ní ìdánilójú pé yóò jẹ́ kí Ọmọ rẹ̀ lo àṣẹ tó ní àti ìtóye ẹbọ ìràpadà rẹ̀ nítorí tiwa.—Mátíù 28:18.
A lè ní ìdánilójú pé pẹ̀lú agbára tí Jésù ní ní ọ̀run, yóò pèsè irú ìrànlọ́wọ́ tó yẹ ní àkókò tó yẹ. Fún àpẹẹrẹ, bí a bá dẹ́ṣẹ̀, tó sì dùn wá dọ́kàn, a lè rí ìtùnú nínú ìdánilójú náà pé “àwa ní olùrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ Baba, Jésù Kristi, ẹni tí í ṣe olódodo.” (1 Jòhánù 2:1, 2) Olùrànlọ́wọ́ àti Olùtùnú wa tó wà ní ọ̀run yóò bẹ̀bẹ̀ fún wa kí àdúrà tí a ń gbà ní orúkọ rẹ̀ àti ní ìbámu pẹ̀lú ohun tó wà nínú Ìwé Mímọ́ lè gbà.—Jòhánù 14:13, 14; 1 Jòhánù 5:14, 15.
Fífi Ìmọrírì Hàn fún Ìrànlọ́wọ́ Kristi
Ohun tó yẹ ká ṣe kọjá wíwulẹ̀ máa rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Ọlọ́run nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀. A lè sọ pé pẹ̀lú ìtóye ẹbọ ìràpadà rẹ̀, “Kristi nípa rírà” di ‘olúwa tí ó ra’ ìran ènìyàn. (Gálátíà 3:13; 4:5; 2 Pétérù 2:1) A lè fi ìmoore wa hàn fún ohun gbogbo tí Kristi ń ṣe nítorí tiwa nípa jíjẹ́wọ́ pé òun ló ni wá, kí a sì fìdùnnú dáhùn sí ìpè rẹ̀ pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ níní ara rẹ̀, kí ó sì gbé òpó igi oró rẹ̀ láti ọjọ́ dé ọjọ́, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn nígbà gbogbo.” (Lúùkù 9:23) ‘Sísẹ́ níní ara ẹni’ kì í kàn ṣe wíwulẹ̀ fẹnu lásán sọ pé ẹlòmíràn lo ni mí. Ó ṣe tán, Kristi “kú fún gbogbo wọn kí àwọn tí ó wà láàyè má ṣe tún wà láàyè fún ara wọn mọ́, bí kò ṣe fún ẹni tí ó kú fún wọn.” (2 Kọ́ríńtì 5:14, 15) Nítorí náà, fífi ìmọrírì hàn fún ìràpadà náà yóò ní ipa jíjinlẹ̀ lórí èrò wa, góńgó wa, àti ọ̀nà ìṣeǹkan wa. Ó yẹ kí gbèsè ayérayé tí a jẹ “Kristi Jésù, ẹni tí ó fi ara rẹ̀ fúnni nítorí wa,” sún wa láti fẹ́ mọ̀ sí i nípa rẹ̀ àti Bàbá rẹ̀, Jèhófà Ọlọ́run. Ó yẹ kí a tún fẹ́ láti dàgbà nínú ìgbàgbọ́, kí á máa fi àwọn ìlànà Ọlọ́run tó ń ṣeni láǹfààní sílò, kí a sì jẹ́ “onítara fún iṣẹ́ àtàtà.”—Títù 2:13, 14; Jòhánù 17:3.
Inú ìjọ Kristẹni ni a ti ń rí oúnjẹ tẹ̀mí tó bọ́ sásìkò jẹ, ibẹ̀ la ti ń rí ìṣírí àti ìtọ́sọ́nà gbà. (Mátíù 24:45-47; Hébérù 10:21-25) Fún àpẹẹrẹ, bí ẹnikẹ́ni bá ń ṣàìsàn nípa tẹ̀mí, wọ́n lè “pe àwọn àgbà ọkùnrin [àwọn alàgbà tí a yàn sípò] ìjọ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀.” Jákọ́bù wá fi ìdánilójú náà kún un pé: “Àdúrà ìgbàgbọ́ yóò sì mú aláàárẹ̀ náà lára dá, Jèhófà yóò sì gbé e dìde. Pẹ̀lúpẹ̀lù, bí ó bá ti dá ẹ̀ṣẹ̀, a óò dárí rẹ̀ jì í.”—Jákọ́bù 5:13-15.
Láti ṣàkàwé rẹ̀: Ọkùnrin kan tó ń ṣẹ̀wọ̀n ní Gúúsù Áfíríkà kọ̀wé sí àwọn alàgbà ìjọ kan, ó fi ìmọrírì hàn fún “gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ń bá iṣẹ́ rere tí Jésù Kristi bẹ̀rẹ̀ lọ, bí wọ́n ti ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti máa tiraka kí wọ́n lè wọ Ìjọba Ọlọ́run.” Ó tún kọ̀wé pé: “Inú mi dùn gan-an nígbà tí mo gba lẹ́tà yín. Àníyàn yín nípa títún mi rà padà nípa tẹ̀mí wú mi lórí gan-an. Ìdí nìyẹn tí mo fi bẹ̀rẹ̀ sí ṣègbọràn sí ìpè Jèhófà Ọlọ́run láti ronú pìwà dà. Ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n nìyí tí mo ti ń ṣìwà hù bọ̀, tí mo sì ń rá pálá nínú òkùnkùn ìwà ẹ̀ṣẹ̀, ìwà ẹ̀tàn, àwọn ìwà àìlófin, àṣà ìṣekúṣe, àti àwọn ẹ̀sìn alárèékérekè. Lẹ́yìn tí mo pàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo wá mọ̀ lọ́kàn mi nígbẹ̀yìngbẹ́yín pé, mo ti rí ọ̀nà náà—ọ̀nà òtítọ́! Ohun tí mo ní láti ṣe ni pé kí ń máa tọ ọ̀nà náà.”
Ìrànlọ́wọ́ Sí I Láìpẹ́
Ipò ayé tó ń bà jẹ́ sí i ń fi hàn kedere pé a ń gbé ní sáà àkókò pàtàkì tí yóò ṣáájú ìgbà tí “ìpọ́njú ńlá” máa bẹ́ sílẹ̀. Ní báyìí, àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá láti inú gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹ̀yà, àwọn ènìyàn, àti ahọ́n ‘ń fọ aṣọ wọn, wọ́n sì ń sọ wọ́n di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.’ (Ìṣípayá 7:9, 13, 14; 2 Tímótì 3:1-5) Nípa lílo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù, a ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n, a sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lè wọnú àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run—ní gidi, wọ́n ń di ọ̀rẹ́ rẹ̀.—Jákọ́bù 2:23.
Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, Jésù Kristi, “yóò máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn [àwọn tí ó la ìpọ́njú ńlá náà já], yóò sì máa ṣamọ̀nà wọn lọ sí àwọn ìsun omi ìyè. Ọlọ́run yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn.” (Ìṣípayá 7:17) Nígbà náà, Kristi yóò ṣe iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Àlùfáà Àgbà parí. Yóò ran gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ Ọlọ́run lọ́wọ́ láti jàǹfààní ní kíkún láti inú “àwọn ìsun omi ìyè”—nípa tẹ̀mí, nípa tara, ní tèrò orí, àti ní ti ìmí ẹ̀dùn. Ohun tí Jésù bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 33 Sànmánì Tiwa àti ohun tó ti ń ṣe lọ́run láti ìgbà yẹn wá ni yóò wá ṣe dé ìjẹ́pípé.
Nítorí náà, má ṣe juwọ́ sílẹ̀ nínú fífi ìmọrírì jíjinlẹ̀ hàn fún gbogbo ohun tí Ọlọ́run àti Kristi ti ṣe—àti èyí tí wọ́n ṣì ń ṣe—fún wa. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ̀ wá pé: “Ẹ máa yọ̀ nígbà gbogbo nínú Olúwa. . . . Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín nípasẹ̀ Kristi Jésù.”—Fílípì 4:4, 6, 7.
Ọ̀nà pàtàkì kan wà tí o lè gbà fi ìmoore hàn sí Jésù Kristi, Olùrànlọ́wọ́ wa ní ọ̀run. Tí oòrùn bá wọ̀ ní ọjọ́ Wednesday, April 19, 2000, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jákèjádò ayé yóò kóra jọ láti ṣe Ìṣe Ìrántí ikú Kristi. (Lúùkù 22:19) Èyí yóò jẹ́ àǹfààní fún ọ láti mú kí ìmọrírì rẹ fún ẹbọ ìràpadà Kristi jinlẹ̀ sí i. A fi tọ̀yàyàtọ̀yàyà ké sí ọ láti wá gbọ́ bí ètò àgbàyanu tí Ọlọ́run ṣe fún ìgbàlà nípasẹ̀ Kristi ṣe lè ṣe ọ́ láǹfààní títí ayérayé. Jọ̀wọ́, béèrè lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ, kí wọ́n sọ àkókò àti ibi tí wọn ó ti ṣe ìpàdé pàtàkì yí fún ọ.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Jésù mọ bó ṣe ń rí tí a bá gbàdúrà sí Ọlọ́run kíkankíkan
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Kristi yóò ràn wá lọ́wọ́ láti lè fara da àwọn ìṣòro tó kọjá agbára wa
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Kristi ń lo àwọn alàgbà onífẹ̀ẹ́ láti ràn wá lọ́wọ́