ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 3
Kí La Rí Kọ́ Nínú Bí Jésù Ṣe Sunkún?
“Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í da omi lójú.”—JÒH. 11:35.
ORIN 17 “Mo Fẹ́ Bẹ́ẹ̀”
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1-3. Àwọn nǹkan wo ló lè mú káwọn ìránṣẹ́ Jèhófà sunkún lónìí?
ÌGBÀ wo lo sunkún kẹ́yìn? Àwọn ìgbà míì wà tá a máa ń sunkún torí pé inú wa ń dùn. Àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn nǹkan tó ń bà wá nínú jẹ́ ló máa ń pa wá lẹ́kún. Bí àpẹẹrẹ, a máa ń sunkún téèyàn wa kan bá kú. Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Lorilei ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Àwọn ìgbà kan wà tí ikú ọmọbìnrin mi dùn mí gan-an débi pé kò sí nǹkan táwọn èèyàn sọ tó tù mí nínú. Lásìkò yẹn, mi ò gbà pé màá lè fara dà á.”b
2 Àmọ́ àwọn nǹkan míì wà tó máa ń pa wá lẹ́kún. Arábìnrin aṣáájú-ọ̀nà kan tó ń jẹ́ Hiromi lórílẹ̀-èdè Japan sọ pé: “Nígbà míì inú mi kì í dùn torí pé àwọn tí mò ń wàásù fún kì í fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ Bíbélì rárá. Mo máa ń sunkún lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, mo sì máa ń bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kí n rí ẹni tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.”
3 Ṣé nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sáwọn arábìnrin yẹn ti ṣẹlẹ̀ sí ìwọ náà rí? Ó dájú pé ó ti ṣẹlẹ̀ sí ọ̀pọ̀ nínú wa rí. (1 Pét. 5:9) Ó wù wá ká máa “fi ayọ̀ sin Jèhófà,” àmọ́ àwọn nǹkan kan máa ń jẹ́ ká sunkún nígbà míì. Ó lè jẹ́ pé ẹnì kan tá a fẹ́ràn ló kú, a lè rẹ̀wẹ̀sì tàbí káwọn nǹkan kan ṣẹlẹ̀ tó jẹ́ kó ṣòro fún wa láti jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. (Sm. 6:6; 100:2) Kí lo lè ṣe tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ sí ẹ?
4. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
4 A lè kẹ́kọ̀ọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jésù. Àwọn ìgbà kan wà tí àwọn nǹkan kan ṣẹlẹ̀ tó dun Jésù gan-an tíyẹn sì mú kó “da omi lójú.” (Jòh. 11:35; Lúùkù 19:41; 22:44; Héb. 5:7) Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ yẹn yẹ̀ wò, kẹ́ ẹ sì fọkàn sáwọn ẹ̀kọ́ tẹ́ ẹ lè rí kọ́ níbẹ̀. A tún máa jíròrò àwọn nǹkan tá a lè ṣe tá a bá ń kojú àwọn nǹkan tó ń gba omijé lójú wa.
JÉSÙ SUNKÚN NÍTORÍ ÀWỌN Ọ̀RẸ́ Ẹ̀
5. Kí la rí kọ́ nínú ohun tí Jésù ṣe bó ṣe wà nínú Jòhánù 11:32-36?
5 Nígbà òtútù lọ́dún 32 S.K., Lásárù ọ̀rẹ́ Jésù tímọ́tímọ́ ṣàìsàn, ó sì kú. (Jòh. 11:3, 14) Lásárù láwọn arábìnrin méjì tórúkọ wọn ń jẹ́ Màríà àti Màtá, Jésù sì fẹ́ràn ìdílé wọn gan-an. Ikú Lásárù kó ẹ̀dùn ọkàn bá Màríà àti Màtá gan-an. Lẹ́yìn tí Lásárù kú, Jésù rìnrìn àjò lọ sí abúlé Bẹ́tánì níbi tí ìdílé náà ń gbé. Nígbà tí Màtá gbọ́ pé Jésù ti ń bọ̀, ó sáré lọ pàdé ẹ̀. Ẹ wo bẹ́nu Màtá á ṣe máa gbọ̀n bó ṣe ń sọ fún Jésù pé: “Olúwa, ká ní o wà níbí ni, arákùnrin mi ì bá má kú.” (Jòh. 11:21) Kò pẹ́ sígbà yẹn ni Jésù rí Màríà àtàwọn míì tí wọ́n ń sunkún, ni “Jésù [bá] bẹ̀rẹ̀ sí í da omi lójú.”—Ka Jòhánù 11:32-36.
6. Kí nìdí tí Jésù fi sunkún nígbà tó dé ibi tí wọ́n tẹ́ Lásárù sí?
6 Kí nìdí tí Jésù fi sunkún nígbà tó dé ibi tí wọ́n tẹ́ Lásárù sí? Ìwé Insight on the Scriptures sọ pé: “Ikú Lásárù ọ̀rẹ́ ẹ̀ àti ìbànújẹ́ tó bá àwọn arábìnrin Lásárù ló jẹ́ kí Jésù ní ‘ẹ̀dùn ọkàn, tó sì mú kó da omi lójú.’”c Ó ṣeé ṣe kí Jésù máa ronú nípa ìrora tí Lásárù ní nígbà tó ń ṣàìsàn àti bó ṣe máa rí lára ẹ̀ nígbà tó mọ̀ pé òun ń kú lọ. Ó dájú pé nǹkan míì tó jẹ́ kí Jésù sunkún ni bó ṣe rí i tí Màríà àti Màtá ń sunkún torí ikú arákùnrin wọn. Tó bá jẹ́ pé ọ̀rẹ́ ẹ tàbí ẹnì kan nínú ìdílé ẹ ti kú, ó dájú pé bó ṣe máa rí lára ìwọ náà nìyẹn. Ẹ jẹ́ ká wo nǹkan mẹ́ta tá a lè kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí.
7. Kí la rí kọ́ nípa Jèhófà látinú bí Jésù ṣe sunkún nítorí àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀?
7 Jèhófà mọ bí ohun tó ṣẹlẹ̀ ṣe rí lára ẹ. Jésù “ni àwòrán irú ẹni [tí Bàbá rẹ̀] jẹ́ gẹ́lẹ́.” (Héb. 1:3) Bí Jésù ṣe sunkún jẹ́ ká mọ bó ṣe máa ń rí lára Jèhófà nígbà táwọn èèyàn wa bá kú. (Jòh. 14:9) Tí èèyàn ẹ kan bá kú, mọ̀ dájú pé Jèhófà rí ohun tó ṣẹlẹ̀, ó sì tún mọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára ẹ. Ó máa ṣàánú ẹ, ó sì máa wo ọgbẹ́ ọkàn ẹ sàn.—Sm. 34:18; 147:3.
8. Kí ló mú kó dá wa lójú pé Jésù máa jí àwọn èèyàn wa dìde?
8 Jésù máa jí àwọn èèyàn ẹ dìde. Kí Jésù tó bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún, ó sọ fún Màtá pé: “Arákùnrin rẹ máa dìde,” Màtá sì gba Jésù gbọ́. (Jòh. 11:23-27) Torí pé olùjọsìn Jèhófà ni Màtá, ó dájú pé ó mọ̀ nípa àwọn tí wòlíì Èlíjà àti Èlíṣà jí dìde lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn. (1 Ọba 17:17-24; 2 Ọba 4:32-37) Ó sì ṣeé ṣe kó ti gbọ́ nípa àwọn tí Jésù náà jí dìde. (Lúùkù 7:11-15; 8:41, 42, 49-56) Torí náà, ó dájú pé wàá pa dà rí àwọn èèyàn ẹ tó ti kú. Bí Jésù ṣe sunkún nígbà tó ń tu àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ nínú jẹ́ ẹ̀rí pé ó máa jí àwọn tó ti kú dìde!
9. Bíi ti Jésù, báwo lo ṣe lè tu àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ nínú? Sọ àpẹẹrẹ kan.
9 O lè tu àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ nínú. Kì í ṣe pé Jésù sunkún pẹ̀lú Màtá àti Màríà nìkan ni, ó tún tẹ́tí sí wọn, ó sì fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀. Àwa náà lè ṣe bẹ́ẹ̀ fáwọn tó ń ṣọ̀fọ̀. Alàgbà kan tó ń jẹ́ Dan nílẹ̀ Ọsirélíà sọ pé: “Nǹkan ò rọrùn fún mi rárá lẹ́yìn tí ìyàwó mi kú. Tọ̀sán-tòru làwọn tọkọtaya lóríṣiríṣi fi máa ń wà pẹ̀lú mi. Wọ́n máa ń tẹ́tí sí mi, wọ́n sì máa ń tù mí nínú. Wọ́n jẹ́ kí n sọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára mi, tí mo bá sì ń sunkún, wọ́n máa ń fìfẹ́ rẹ̀ mí lẹ́kún. Wọ́n tún máa ń bá mi fọ mọ́tò, wọ́n máa ń bá mi rajà, wọ́n sì máa ń bá mi dáná láwọn àsìkò tí mi ò lè ṣe bẹ́ẹ̀. Ìgbà gbogbo ni wọ́n máa ń gbàdúrà pẹ̀lú mi. Ṣe ni wọ́n dà bí ọ̀rẹ́ tòótọ́ àti ‘ọmọ ìyá tí a bí fún ìgbà wàhálà.’”—Òwe 17:17.
JÉSÙ SUNKÚN NÍTORÍ ÀWỌN TÓ WÀÁSÙ FÚN
10. Sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú Lúùkù 19:36-40.
10 Jésù dé sí Jerúsálẹ́mù ní Nísàn 9, 33 S.K. Bó ṣe ń lọ, àwọn èèyàn péjọ, wọ́n sì ń tẹ́ aṣọ wọn sójú ọ̀nà fún un torí wọ́n gbà pé òun ni Ọba wọn. Dájúdájú, ọjọ́ ayọ̀ lọjọ́ yẹn. (Ka Lúùkù 19:36-40.) Torí náà, àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ ò retí ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn. Bíbélì sọ pé: “Nígbà [tí Jésù] dé tòsí, ó wo ìlú náà, ó sì sunkún lé e lórí.” Pẹ̀lú omijé lójú, Jésù sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sáwọn ará ìlú Jerúsálẹ́mù láìpẹ́.—Lúùkù 19:41-44.
11. Kí nìdí tí Jésù fi sunkún nítorí àwọn èèyàn Jerúsálẹ́mù?
11 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan tẹ́wọ́ gba Jésù tọwọ́tẹsẹ̀, inú Jésù ò dùn torí ó mọ̀ pé èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn èèyàn Jerúsálẹ́mù ni ò ní gba ìhìn rere Ìjọba náà. Torí náà, wọ́n máa pa Jerúsálẹ́mù run, àwọn tó bá sì yè bọ́ máa lọ sígbèkùn. (Lúùkù 21:20-24) Ohun tí Jésù sọ gan-an ló ṣẹlẹ̀, ọ̀pọ̀ lára wọn ni ò gbà á gbọ́. Ṣé àwọn èèyàn máa ń gbọ́ ìwàásù lágbègbè ibi tó ò ń gbé? Tó bá jẹ́ pé ìwọ̀nba èèyàn ló ń gbọ́, kí lo lè kọ́ látinú bí Jésù ṣe sunkún torí àwọn tó wàásù fún? Ẹ jẹ́ ká wo nǹkan mẹ́ta míì tá a lè kọ́.
12. Kí la rí kọ́ lára Jèhófà látinú bí Jésù ṣe sunkún nítorí àwọn ará ìlú ẹ̀?
12 Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn. Bí Jésù ṣe sunkún tún jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn gan-an. Bíbélì sọ pé: “Kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo èèyàn ronú pìwà dà.” (2 Pét. 3:9) Lónìí, àwa náà lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn tá à ń wàásù fún tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe kí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run lè wọ̀ wọ́n lọ́kàn.—Mát. 22:39.d
13-14. Báwo ni Jésù ṣe fàánú hàn sáwọn èèyàn, báwo làwa náà ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?
13 Jésù ṣiṣẹ́ kára lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Gbogbo àyè tó bá ṣí sílẹ̀ ni Jésù fi ń kọ́ àwọn èèyàn, ìyẹn sì fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wọn. (Lúùkù 19:47, 48) Kí ló mú kó ṣe bẹ́ẹ̀? Àánú tí Jésù ní sí wọn ló mú kó ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn ìgbà míì wà tí Jésù kọ́ àwọn èèyàn débi pé òun àtàwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ “ò ráyè jẹun pàápàá.” (Máàkù 3:20) Nígbà tí ọkùnrin kan wá sọ́dọ̀ Jésù lálẹ́ kó lè gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀, Jésù rí i pé òun kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ lásìkò yẹn. (Jòh. 3:1, 2) Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn tó kọ́kọ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jésù ò di ọmọlẹ́yìn ẹ̀. Àmọ́ gbogbo àwọn tó tẹ́tí sí i ni Jésù jẹ́rìí fún kúnnákúnná. Lónìí, gbogbo èèyàn ló yẹ káwa náà wàásù fún. (Ìṣe 10:42) Ká tó lè ṣe bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ yí àwọn ìgbà tá à ń wàásù pa dà.
14 Máa ṣe àwọn àyípadà tó yẹ. Tó bá jẹ́ pé àkókò kan náà là ń wàásù ṣáá, a lè má rí àwọn tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Aṣáájú-ọ̀nà kan tó ń jẹ́ Matilda sọ pé: “Àsìkò táwọn èèyàn máa gbọ́ ìwàásù la máa ń lọ sọ́dọ̀ wọn. Ibi táwọn èèyàn ti ń tajà la máa ń lọ láàárọ̀. Tó bá di ọ̀sán táwọn èèyàn ń rìn lọ rìn bọ̀, a máa ń lo àtẹ ìwé. Tó bá wá di ọwọ́ ìrọ̀lẹ́, ọ̀pọ̀ èèyàn á ti wà nílé, torí náà, ilé wọn la máa ń lọ láti bá wọn sọ̀rọ̀.” Dípò ká ní àkókò kan pàtó tó rọ̀ wá lọ́rùn tá a fi ń wàásù fáwọn èèyàn, ṣe ló yẹ ká yí àkókò tá a fi ń wàásù pa dà ká lè túbọ̀ ráwọn èèyàn bá sọ̀rọ̀. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé inú Jèhófà máa dùn sí wa.
JÉSÙ SUNKÚN NÍTORÍ ORÚKỌ BÀBÁ RẸ̀
15. Bó ṣe wà nínú Lúùkù 22:39-44, kí ló ṣẹlẹ̀ ní alẹ́ ọjọ́ tó ṣáájú ikú Jésù?
15 Ní alẹ́ Nísàn 14, 33 S.K., Jésù lọ sínú ọgbà Gẹ́tísémánì. Nígbà tó débẹ̀, ó sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn ẹ̀ fún Jèhófà. (Ka Lúùkù 22:39-44.) Àsìkò tí nǹkan nira fún Jésù yẹn ló “rawọ́ ẹ̀bẹ̀ [pẹ̀lú] ẹkún tó rinlẹ̀ àti omijé.” (Héb. 5:7) Kí ni Jésù sọ pé kí Jèhófà ṣe fún òun ní alẹ́ ọjọ́ tó ṣáájú ikú rẹ̀? Ó gbàdúrà pé kí Jèhófà fún òun lókun kí òun lè ṣe ìfẹ́ Rẹ̀, kóun sì jẹ́ olóòótọ́ dópin. Jèhófà gbọ́ àdúrà àtọkànwá tí Ọmọ rẹ̀ gbà, ó sì rán áńgẹ́lì kan láti fún un lókun.
16. Kí nìdí tí ìdààmú fi bá Jésù nígbà tó ń gbàdúrà nínú ọgbà Gẹ́tísémánì?
16 Ìdí tí Jésù fi sunkún nígbà tó ń gbàdúrà nínú ọgbà Gẹ́tísémánì ni pé àwọn èèyàn máa fojú ẹni tí kò bọ̀wọ̀ fún orúkọ Ọlọ́run wò ó, ìyẹn sì kó ìdààmú bá a. Yàtọ̀ síyẹn, Jésù mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì gan-an kí òun jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, kí òun sì ya orúkọ rẹ̀ sí mímọ́. Tó o bá ń kojú ìṣòro kan tó jẹ́ kó ṣòro fún ẹ láti jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, kí lo lè kọ́ látinú bí Jésù ṣe sunkún? Ẹ jẹ́ ká wo nǹkan mẹ́ta míì tá a lè kọ́.
17. Kí la rí kọ́ nípa Jèhófà nínú bó ṣe dáhùn àdúrà àtọkànwá tí Jésù gbà?
17 Jèhófà máa ń fetí sí ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ. Jèhófà fetí sí àdúrà àtọkànwá tí Jésù gbà. Kí nìdí? Ìdí ni pé ohun tó ṣe pàtàkì jù sí Jésù ni bó ṣe máa jẹ́ olóòótọ́ sí Bàbá rẹ̀ àti bó ṣe máa dá orúkọ Bàbá rẹ̀ láre. Tó bá jẹ́ ohun tó jẹ àwa náà lógún ni bá a ṣe máa jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà àti bá a ṣe máa dá orúkọ rẹ̀ láre, ó máa dáhùn àdúrà wa.—Sm. 145:18, 19.
18. Kí ló fi hàn pé onínúure àti ẹni tó ń gba tẹni rò ni Jésù?
18 Jésù máa ń bá wa kẹ́dùn. Inú wa dùn pé a ní ẹni tó lè bá wa kẹ́dùn tá a bá wà nínú ìṣòro torí pé òun náà ti kojú irú ìṣòro tá a ní. Ṣẹ́ ẹ mọ ẹni náà? Jésù ni. Ó mọ bó ṣe máa ń rí téèyàn ò bá lókun mọ́ tó sì nílò ìrànlọ́wọ́. Ó mọ bí nǹkan ṣe ń rí lára wa, ó sì máa ń rí i dájú pé a rí ìrànlọ́wọ́ tá a nílò “ní àkókò tó tọ́.” (Héb. 4:15, 16) Jésù gbà kí áńgẹ́lì tí Jèhófà rán sí i nínú ọgbà Gẹ́tísémánì ran òun lọ́wọ́. Torí náà, ó yẹ káwa náà gba ìrànlọ́wọ́ tí Jèhófà ń fún wa nípasẹ̀ àwọn ìwé wa, fídíò, àsọyé àti ọ̀rọ̀ ìṣírí tí alàgbà tàbí ọ̀rẹ́ wa kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ sọ fún wa.
19. Kí ló máa fún ẹ lókun tọ́kàn ẹ ò bá balẹ̀? Sọ àpẹẹrẹ kan.
19 Jèhófà máa fún ẹ ní “àlàáfíà” rẹ̀. Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń fún wa lókun? Tá a bá gbàdúrà, á máa ní “àlàáfíà Ọlọ́run tó kọjá gbogbo òye.” (Fílí. 4:6, 7) Àlàáfíà tí Jèhófà ń fún wa máa ń jẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀, ká sì ronú lọ́nà tó tọ́. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Arábìnrin Luz fi hàn pé bọ́rọ̀ ṣe rí gan-an nìyẹn. Ó sọ pé: “Ó máa ń ṣe mí bíi pé mo dá wà. Nígbà míì, ó máa ń jẹ́ kí n ronú pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ mi. Àmọ́ tó bá ti ń ṣe mí bẹ́ẹ̀, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni mo máa ń sọ bí nǹkan ṣe rí lára mi fún Jèhófà. Tí mo bá ti gbàdúrà, ara máa ń tù mí gan-an.” Bá a ṣe rí i nínú ìrírí arábìnrin yìí, àdúrà lè mú kí ọkàn tiwa náà balẹ̀.
20. Kí la rí kọ́ nínú bí Jésù ṣe sunkún?
20 Bí Jésù ṣe sunkún tù wá nínú, a sì rí àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì kọ́ nínú ẹ̀! Ó kọ́ wa pé ká máa tu àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ nínú, ká sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà àti Jésù pé wọ́n máa tu àwa náà nínú tí èèyàn wa kan bá kú. Torí pé Jèhófà àti Jésù máa ń fàánú hàn sí wa, àwa náà máa ń fàánú hàn sáwọn tá à ń wàásù fún, tá a sì ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́. Yàtọ̀ síyẹn, ó ń tù wá nínú bá a ṣe mọ̀ pé Jèhófà àti Jésù mọ bí nǹkan ṣe rí lára wa, wọ́n ń bá wa kẹ́dùn torí àwọn àìléra wa, wọ́n sì ń fẹ́ láti ràn wá lọ́wọ́ ká lè fara da àwọn ìṣòro tá a bá kojú. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa lo àwọn nǹkan tá a ti kọ́ títí dìgbà tí Jèhófà máa mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ pé màá “nu gbogbo omijé kúrò ní ojú” yín!—Ìfi. 21:4.
ORIN 120 Jẹ́ Oníwà Tútù Bíi Kristi
a Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn nǹkan kan ṣẹlẹ̀ tó dun Jésù gan-an, tíyẹn sì mú kó sunkún. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí Jésù sunkún àtàwọn ẹ̀kọ́ tá a lè rí kọ́.
b A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.
c Wo ìwé Insight on the Scriptures, ìdìpọ̀ kejì lójú ìwé 69.
d Kì í ṣe àwọn tó ń gbé ládùúgbò wa nìkan ni ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “ọmọnìkejì” nínú Mátíù 22:39 ń tọ́ka sí. Ó kan gbogbo àwọn tá a bá bá pàdé.
e ÀWÒRÁN: Àánú mú kí Jésù tu Màríà àti Màtá nínú. Àwa náà lè ṣe bẹ́ẹ̀ fáwọn tí èèyàn wọn kú.
f ÀWÒRÁN: Jésù rí i pé òun kọ́ Nikodémù lẹ́kọ̀ọ́ nígbà tó wá sọ́dọ̀ ẹ̀ lálẹ́. Ìgbà tó bá rọrùn fáwọn èèyàn ló yẹ káwa náà máa kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
g ÀWÒRÁN: Jésù gbàdúrà pé kí Jèhófà jẹ́ kóun jẹ́ adúróṣinṣin sí i. Ohun tó yẹ káwa náà ṣe nìyẹn tá a bá ń kojú àdánwò.