“Ẹ̀yin Ọmọ, Ẹ Jẹ́ Onígbọràn Sí Àwọn Òbí Yín”
“Ẹ̀yin ọmọ, ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn òbí yín ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Olúwa, nítorí èyí jẹ́ òdodo.”—ÉFÉSÙ 6:1.
1. Báwo ni ìgbọràn ṣe lè dáàbò bò ẹ́?
Ó LÈ jẹ́ pé ṣíṣe tá a ṣègbọràn ló jẹ́ ká ṣì wà láàyè lónìí, ṣùgbọ́n àwọn míì ti pàdánù ẹ̀mí wọn nítorí pé wọn ò ṣègbọràn. Ìgbọràn sí kí ni? Ó lè jẹ́ ìgbọ́ràn sí ìkìlọ̀ tí ara wa tí Ọlọ́run dá “tìyanu-tìyanu” ń fún wa. (Sáàmù 139:14) Nígbà tá a bá rí i tí ojú ọ̀run ṣú dùdù, tá a sì fetí gbọ́ ìró ààrá tó ń sán, tí mànàmáná sì ń kọ lójú ọ̀run, ẹ̀rù lè bẹ̀rẹ̀ sí í bà wá. Ìkìlọ̀ lèyí jẹ́ fáwọn tó ti gbọ́ nípa ewu tó lè wáyé lẹ́yìn irú nǹkan wọ̀nyí pé kí wọ́n lọ forí pa mọ́ síbi tó láàbò nítorí òjò oníjì àti yìnyín tó lè pani tó fẹ́ rọ̀.
2. Kí nìdí táwọn ọmọ fi nílò ìkìlọ̀, kí sì nìdí tó fi yẹ kí wọ́n máa ṣègbọràn sáwọn òbí wọn?
2 Ẹ̀yin ọmọ nílò ìkìlọ̀ nípa àwọn ohun tó lè wu yín léwu, ojúṣe àwọn òbí yín sì ni láti fún yín ní ìkìlọ̀ yìí. Òbí rẹ ti lè kìlọ̀ fún ẹ rí pé: “Má fọwọ́ kan ààrò yẹn o, ó gbóná o.” “Mà lọ wẹ̀ nínú odò yẹn o, ó lè gbé ẹ lọ.” “Rí i pé o wo títì dáadáa kó o tó sọdá o.” Ó bani nínú jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ọmọ ló ti ṣèṣe, ọ̀pọ̀ ló sì ti kú torí pé wọn ò gbọ́rọ̀ sí òbí wọn lẹ́nu. Bẹ́ẹ̀ kẹ̀, Bíbélì fi hàn pé ṣíṣe ìgbọràn sí òbí ẹni jẹ́ “òdodo,” tó túmọ̀ sí pé ó tọ̀nà ó sì yẹ. Ó sì tún bọ́gbọ́n mu láti ṣe bẹ́ẹ̀. (Òwe 8:33) Ẹsẹ Bíbélì mìíràn sọ pé ṣíṣe bẹ́ẹ̀ “dára gidigidi” lójú Jésù Kristi Olúwa. Àní, ńṣe ni Ọlọ́run pa á láṣẹ fún ẹ pé kó o máa ṣègbọràn sí àwọn òbí rẹ.—Kólósè 3:20; 1 Kọ́ríńtì 8:6.
Èrè Ayérayé Táwọn Ọmọ Máa Jẹ Tí Wọ́n Bá Ń Ṣègbọràn
3. Kí ni “ìyè tòótọ́,” ibo ni ọ̀pọ̀ jù lọ wa ti máa gbádùn rẹ̀, kí làwọn ọmọ sì gbọ́dọ̀ ṣe kọ́wọ́ wọn lè tẹ̀ ẹ́?
3 Tó o bá ń ṣègbọràn sáwọn òbí rẹ, ààbò ló máa jẹ́ fún ẹ̀mí rẹ, tó túmọ̀ sí pé wàá ní “ìyè ti ìsinsìnyí,” á sì tún jẹ́ kó o lè ní ìyè “tí ń bọ̀,” tí Bíbélì pè ní “ìyè tòótọ́.” (1 Tímótì 4:8; 6:19) Ìyè tòótọ́ yìí túmọ̀ sí ìwàláàyè títí láé, ọ̀pọ̀ jù lọ wa sì máa gbádùn rẹ̀ nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí fáwọn tí wọ́n ń pa òfin rẹ̀ mọ́. Ọ̀kan pàtàkì lára àwọn òfin náà sọ pé: “‘Bọlá fún baba rẹ àti ìyá rẹ’; èyí tí í ṣe àṣẹ kìíní pẹ̀lú ìlérí: ‘Kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún ọ, kí ìwọ sì lè wà fún àkókò gígùn lórí ilẹ̀ ayé.’” Èyí fi hàn pé tó o bá ń ṣègbọràn sáwọn òbí rẹ, wàá ní ayọ̀. Ọjọ́ ọ̀la rẹ á dára, á sì lè ṣeé ṣe fún ẹ láti ní ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé.—Éfésù 6:2, 3.
4. Báwo làwọn ọmọ ṣe lè bọlá fún Ọlọ́run, àǹfààní wo nìyẹn sì lè ṣe fún wọn?
4 Tó o bá ń bọlá fáwọn òbí rẹ nípa ṣíṣe ìgbọràn sí wọn, ò ń bọlá fún Ọlọ́run náà nìyẹn nítorí òun ló pa á láṣẹ pé kó o máa ṣe bẹ́ẹ̀. Bó o sì ṣe ń bọlá fún wọn, ńṣe lò ń ṣe ara rẹ láǹfààní. Bíbélì sọ pé: “Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ, Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní.” (Aísáyà 48:17; 1 Jòhánù 5:3) Báwo ni ṣíṣe ìgbọràn sáwọn òbí rẹ ṣe lè ṣe ẹ́ láǹfààní? Tó o bá ń ṣègbọràn, inú bàbá àti ìyá rẹ á dùn. Tínú wọn bá sì ń dùn, ó dájú pé wọ́n á fi ìdùnnú wọn hàn nípa ṣíṣe ohun tó máa múnú ìwọ alára dùn. (Òwe 23:22-25) Èrè tó ga jù lọ ni pé, ṣíṣe tó o bá ń ṣègbọràn sí wọn yóò múnú Bàbá rẹ ọ̀run dùn, yóò sì bùn kún ọ lọ́pọ̀ yanturu! Jésù sọ nípa ara rẹ̀ pé: “Nígbà gbogbo ni mo ń ṣe ohun tí ó wù ú.” Ẹ jẹ́ ká wo bí Jèhófà ṣe bùn kún Jésù, àti bó ṣe dàábò bò ó nítorí ìgbọràn rẹ̀.—Jòhánù 8:29.
Jésù Jẹ́ Ẹni Tó Máa Ń Tẹpá Mọ́ṣẹ́
5. Kí nìdí téèyàn fi lè gbà gbọ́ pé Jésù máa ń tẹpá mọ́ṣẹ́?
5 Jésù ni àkọ́bí Màríà ìyá rẹ̀. Káfíńtà ni Jósẹ́fù alágbàtọ́ rẹ̀ tó jẹ́ bíi bàbá fún un. Jésù alára di káfíńtà. Ẹ̀rí sì fi hàn pé ọwọ́ Jósẹ́fù ló ti kọ́ iṣẹ́ yìí. (Mátíù 13:55; Máàkù 6:3; Lúùkù 1:26-31) Irú káfíńtà wo lo rò pé Jésù jẹ́? Ṣó o rí i, nígbà tí Jésù, ẹni tí Bíbélì ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí ọgbọ́n, wà lọ́run, ìyẹn ṣáájú kí ìyá rẹ̀ tí í ṣe wúńdíá tó lóyún rẹ̀ lọ́nà ìyanu, ó sọ pé: “Nígbà náà ni mo wá wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ [Ọlọ́run] gẹ́gẹ́ bí àgbà òṣìṣẹ́, mo sì wá jẹ́ ẹni tí ó ní ìfẹ́ni sí lọ́nà àkànṣe lójoojúmọ́.” Nígbà tí Jésù wà lọ́run, Ọlọ́run fẹ́ràn rẹ̀ gan-an torí pé ó máa ń tẹpá mọ́ṣẹ́. Nígbà tó sì jẹ́ ọ̀dọ́ lórí ilẹ̀ ayé, ǹjẹ́ o ò rò pé ó máa gbìyànjú láti jẹ́ akíkanjú òṣìṣẹ́ àti káfíńtà tó mọ́ṣẹ́ dunjú?—Òwe 8:30; Kólósè 1:15, 16.
6. (a) Kí nìdí tó o fi lè sọ pé Jésù ṣe iṣẹ́ ilé nígbà tó wà lọ́mọdé? (b) Àwọn ọ̀nà wo làwọn ọmọdé lè gbà fara wé Jésù?
6 Nígbà tí Jésù wà lọ́mọdé, kò sí àní-àní pé ó máa ń ṣeré nígbà míì gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ pé àwọn ọmọdé máa ń ṣe láyé ìgbàanì. (Sekaráyà 8:5; Mátíù 11:16, 17) Síbẹ̀, nítorí pé Jésù ni àkọ́bí nínú ìdílé wọn ńlá tó jẹ́ ìdílé tálákà, ó dájú pé ó tún máa ń ṣe iṣẹ́ ilé yàtọ̀ sí iṣẹ́ káfíńtà tó ń kọ́ lọ́dọ̀ Jósẹ́fù. Nígbà tó ṣe, Jésù di oníwàásù, ó sì mú iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀ yìí lọ́kùn-ún-kúndùn débi pé ó yááfì àwọn ohun kan tó lè fún un ní ìgbádùn. (Lúùkù 9:58; Jòhánù 5:17) Ǹjẹ́ o rí àwọn apá ibi tó o ti lè fara wé Jésù báyìí? Ǹjẹ́ àwọn òbí rẹ máa ń sọ fún ẹ pé kó o tún yàrá ẹ ṣe tàbí kó o ṣe àwọn iṣẹ́ ilé míì? Ṣé wọ́n máa ń gbà ọ́ níyànjú pé kó o kópa nínú ìjọsìn Ọlọ́run nípa lílọ sípàdé ìjọ àti nípa sísọ àwọn ohun tó o gbà gbọ́ fáwọn èèyàn? Táwọn òbí Jésù bá sọ fún un pé kó ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyẹn nígbà tó wà lọ́mọdé, kí lo rò pé ó máa ṣe?
Ó Máa Ń Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Dáadáa Ó sì Máa Ń Kọ́ Àwọn Míì Lẹ́kọ̀ọ́
7. (a) Àwọn wo ló ṣeé ṣe kí Jésù àtàwọn jọ lọ síbi àjọyọ̀ Ìrékọjá? (b) Ibo ni Jésù wà nígbà táwọn yòókù ń padà bọ̀ wálé, kí ló sì ń ṣe níbẹ̀?
7 Ọlọ́run pa á láṣẹ pé kí gbogbo àwọn ọkùnrin tó wà nínú ìdílé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àtọmọdé àtàgbà, máa lọ sí tẹ́ńpìlì láti jọ́sìn Jèhófà nígbà àjọyọ̀ mẹ́ta táwọn Júù máa ń ṣe. (Diutarónómì 16:16) Nígbà tí Jésù wà lọ́mọ ọdún méjìlá, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé gbogbo ìdílé rẹ̀ ló lọ sí Jerúsálẹ́mù fún àjọyọ̀ Ìrékọjá. Ó sì ṣeé ṣe káwọn àbúrò rẹ̀ ọkùnrin àtobìnrin wà lára wọn. Yàtọ̀ sáwọn wọ̀nyẹn, Sàlómẹ̀ tó ṣeé ṣe kó jẹ́ arábìnrin Màríà lè wà lára àwọn míì tó bá wọn lọ àti Sébédè ọkọ rẹ̀ àtàwọn ọmọ wọn, ìyẹn Jákọ́bù àti Jòhánù tí wọ́n di àpọ́sítélì nígbà tó ṣe.a (Mátíù 4:20, 21; 13:54-56; 27:56; Máàkù 15:40; Jòhánù 19:25) Nígbà tí wọ́n ń padà bọ̀ wálé, Jósẹ́fù àti Màríà lè máa rò pé Jésù ń bá àwọn ìbátan wọn yòókù rìn bọ̀, ìyẹn ni ò jẹ́ kí wọ́n tètè fura pé wọ́n ti fi Jésù sẹ́yìn. Nígbà tí Màríà àti Jósẹ́fù máa wá rí Jésù lọ́jọ́ kẹta tí wọ́n ti ń wá a, inú tẹ́ńpìlì ló wà tó “jókòó sáàárín àwọn olùkọ́, ó sì ń fetí sí wọn, ó sì ń bi wọ́n ní ìbéèrè.”—Lúùkù 2:44-46.
8. Kí ni Jésù ń ṣe nínú tẹ́ńpìlì, kí sì nìdí táwọn èèyàn fi ń ṣe kàyéfì?
8 Nígbà tí Bíbélì sọ pé Jésù “ń bi [àwọn olùkọ́] ní ìbéèrè,” irú ìbéèrè wo ni? Ó lè má jẹ́ pé ńṣe ni Jésù wulẹ̀ ń bi wọ́n ní ìbéèrè nípa nǹkan tí ò mọ̀ tàbí pé ńṣe ló kàn fẹ́ mọ̀ sí i nípa nǹkan kan. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí ibí yìí lò lè tọ́ka sí ọ̀nà tí wọ́n gbà ń béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ èèyàn nílé ẹjọ́, tó sì lè gba pé kí wọ́n da ìbéèrè bo èèyàn lórí ohun tó ti sọ tẹ́lẹ̀. Àbó ò rí i, àtigbà tí Jésù ti wà lọ́mọdé ló ti ní ìmọ̀ Bíbélì dáadáa débi pé ìmọ̀ tó ní ya àwọn olùkọ́ ìsìn lẹ́nu! Bíbélì sọ pé: “Gbogbo àwọn tí ń fetí sí i ni wọ́n ń ṣe kàyéfì léraléra nítorí òye rẹ̀ àti àwọn ìdáhùn rẹ̀.”—Lúùkù 2:47.
9. Báwo lo ṣe lè ṣe bíi ti Jésù tó bá dọ̀rọ̀ kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
9 Kí lo rò pé ó mú kí Jésù ní ìmọ̀ Bíbélì nígbà tó wà lọ́mọdé débi táwọn olùkọ́ ìsìn fi ń ṣe kàyéfì? Àwọn òbí rẹ̀ tó bẹ̀rù Ọlọ́run tí wọ́n fi ẹ̀kọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ ọ láti kékeré ló jẹ́ kó lè nírú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀. (Ẹ́kísódù 12:24-27; Diutarónómì 6:6-9; Mátíù 1:18-20) Ó dá wa lójú pé Jósẹ́fù máa ń mú Jésù dání lọ sí sínágọ́gù nígbà tí Jésù wà lọ́mọdé kó lè gbọ́ ọ̀rọ̀ inú Ìwé Mímọ́ tí wọ́n ń kà tí wọ́n sì ń ṣàlàyé níbẹ̀. Ǹjẹ́ ìwọ náà ní àwọn òbí tó ń fi ẹ̀kọ́ Bíbélì kọ́ ẹ tí wọ́n sì ń mú ẹ lọ sípàdé ìjọ? Ǹjẹ́ o mọrírì ohun táwọn òbí rẹ ń ṣe fún ẹ yìí, gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe mọrírì ohun táwọn òbí rẹ̀ ṣe fún un? Ǹjẹ́ o máa ń sọ àwọn nǹkan tó ò ń kọ́ fáwọn ẹlòmíràn gẹ́gẹ́ bí Jésù ti ṣe?
Jésù Lẹ́mìí Ìtẹríba
10. (a) Kí nìdí tó fi yẹ káwọn òbí Jésù mọ ibi tó yẹ kí Jésù wà? (b) Àpẹẹrẹ rere wo ni Jésù fi lélẹ̀ fáwọn ọmọ?
10 Báwo lo ṣe rò pé ó máa rí lára Màríà àti Jósẹ́fù nígbà tí wọ́n rí Jésù nínú tẹ́ńpìlì lọ́jọ́ kẹta tí wọ́n ti ń wá a? Ńṣe lọkàn wọn balẹ̀. Àmọ́, ó ya Jésù lẹ́nu pé àwọn òbí òun ò mọ ibi tóun lè wà. Ó ṣe tán, àwọn méjèèjì mọ̀ nípa ìbí Jésù tó wáyé lọ́nà ìyanu. Yàtọ̀ síyẹn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lè má mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tí Jésù máa ṣe lọ́jọ́ iwájú gẹ́gẹ́ bí Olùgbàlà àti Ọba Ìjọba Ọlọ́run, síbẹ̀ wọ́n á ṣì mọ díẹ̀ nípa rẹ̀. (Mátíù 1:21; Lúùkù 1:32-35; 2:11) Ìdí rèé tí Jésù fi bi wọ́n pé: “Èé ṣe tí ẹ fi ní láti máa wá mi? Ṣé ẹ kò mọ̀ pé èmi gbọ́dọ̀ wà nínú ilé Baba mi ni?” Àmọ́ nítorí pé Jésù jẹ́ elétí ọmọ, ó tẹ̀ lé àwọn òbí rẹ̀ padà sílé wọn ní Násárétì. Bíbélì sọ pé: “Ó sì ń bá a lọ ní fífi ara rẹ̀ sábẹ́ wọn.” Pẹ̀lúpẹ̀lù, “ìyá rẹ̀ rọra pa gbogbo àsọjáde wọ̀nyí mọ́ nínú ọkàn-àyà rẹ̀.”—Lúùkù 2:48-51.
11. Ẹ̀kọ́ wo lo lè rí kọ́ lára Jésù tó bá dọ̀rọ̀ ṣíṣe ìgbọràn?
11 Ǹjẹ́ ó rọrùn fún ẹ láti máa ṣègbọràn sáwọn òbí rẹ nígbà gbogbo bíi ti Jésù? Àbí ò ń ronú pé àwọn òbí rẹ ò lajú, pé o mọ nǹkan jù wọ́n lọ? Lóòótọ́, ó ṣeé ṣe kó o mọ̀ nípa àwọn nǹkan kan jù wọ́n lọ. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣeé ṣe kó o mọ béèyàn ṣe ń lo tẹlifóònù alágbèéká, kọ̀ǹpútà, tàbí àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé míì jù wọ́n lọ. Àmọ́, ronú nípa Jésù, ẹni tó jẹ́ pé “òye rẹ̀ àti àwọn ìdáhùn rẹ̀” mú kí ẹnu ya àwọn àgbà olùkọ́ ìsìn. Tí wọ́n bá fi òye tó o ní wé ti Jésù, wàá gbà pé òye rẹ kò tó nǹkan kan. Pẹ̀lú gbogbo ìmọ̀ tí Jésù sì ní yẹn náà, ó ṣì máa ń tẹrí ba fáwọn òbí rẹ̀. Àmọ́ o, ó lè má jẹ́ pé gbogbo nǹkan táwọn òbí rẹ̀ bá ti sọ náà ló máa ń fara mọ́. Síbẹ̀, “ó . . . ń bá a lọ ní fífi ara rẹ̀ sábẹ́ wọn” ní gbogbo ìgbà tó fi wá lọ́mọdé. Ẹ̀kọ́ wo ló lè rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Jésù?—Diutarónómì 5:16, 29.
Ìgbọràn Kì Í Rọrùn Nígbà Míì
12. Báwo ni ìgbọràn ṣe lè gba ẹ̀mí rẹ là?
12 Nígbà míì, kì í rọrùn láti ṣègbọràn sí òbí ẹni gẹ́gẹ́ bí ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ọdún mélòó kan sẹ́yìn ṣe fi hàn. Àwọn ọmọdébìnrin méjì kan fẹ́ sọdá títì ńlá kan tó gba mọ́tò mẹ́fà lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo dípò kí wọ́n lọ gba orí afárá tí wọ́n ṣe fáwọn tó ń fẹsẹ̀ rìn. Nígbà táwọn ọmọ méjì náà rí i pé ọmọdékùnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ John táwọn àtiẹ̀ jọ ń lọ fẹ́ lọ gba orí afárá yẹn, wọ́n sọ fún un pé: “John, jẹ́ ká sọdá jàre, àbí o ò bá wa lọ mọ́ ni?” Nígbà tí John lóun ò ní bá wọn gba àárín títì ńlá yẹn, ọkàn lára wọn fi í ṣe yẹ̀yẹ́, ó ní, “Ojo ni ẹ́!” Àmọ́ kì í ṣe pé ẹ̀rù ló ń ba John. Ó sọ fún wọn pé, “Màmá mi ti ní kí n má gbabẹ̀.” Bí John ṣe gun orí afárá náà, ó gbọ́ ìró táyà mọ́tò tó dún nísàlẹ̀. Bó ṣe bojú wo ìsàlẹ̀ ló rí i tí mọ́tò kan kọ lu àwọn ọmọbìnrin méjì náà. Ọ̀kan nínú wọn kú, ìkejì sì fara pa gan-an débi pé wọ́n gé ẹsẹ̀ rẹ̀ kan dà nù. Lẹ́yìn tí jàǹbá yìí ṣẹlẹ̀, ìyá àwọn ọmọdébìnrin méjì náà tóun alára ti kìlọ̀ fáwọn ọmọ rẹ̀ yìí pé kí wọ́n má gba àárín títì sọdá, sọ fún ìyá John pé: “Ká láwọn ọmọ mi gbọ́rọ̀ sí mi lẹ́nu bíi tọmọ rẹ ni, jàǹbá yìí kì bá má ṣẹlẹ̀.”—Éfésù 6:1.
13. (a) Kí nìdí tó o fi gbọ́dọ̀ máa ṣègbọràn sáwọn òbí rẹ? (b) Ìgbà wo ni kò ní yẹ kí ọmọ kan ṣe ohun tí òbí rẹ̀ ní kó ṣe?
13 Kí nìdí tí Ọlọ́run fi sọ pé: “Ẹ̀yin ọmọ, ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn òbí yín”? Ìdí ni pé tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run lò ń ṣègbọràn sí. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn òbí rẹ nírìírí jù ẹ́ lọ. Bí àpẹẹrẹ, ní ọdún márùn-ún péré ṣáájú kí jàǹbá tá a sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan tó wáyé, mọ́tò pa ọmọ ọ̀rẹ́ ìyá John kan lójú títì yẹn kan náà nígbà tọ́mọ náà fẹ́ sọdá! Lóòótọ́, ó lè má rọrùn nígbà míì láti ṣègbọràn sáwọn òbí rẹ, àmọ́ àṣẹ Ọlọ́run ni pé kó o máa ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n o, táwọn òbí rẹ tàbí ẹlòmíràn bá sọ fún ẹ pé kó o purọ́, kó o jalè tàbí kó o ṣe ohunkóhun mìíràn tínú Ọlọ́run ò dùn sí, o “gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.” Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé lẹ́yìn tí Bíbélì sọ pé kí ẹ̀yin ọmọ “jẹ́ onígbọràn sí àwọn òbí yín,” ó wá sọ pé “ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Olúwa.” Èyí túmọ̀ sí pé o gbọ́dọ̀ máa ṣègbọràn sáwọn òbí rẹ nínú ohun gbogbo tó bá wà níbàámu pẹ̀lú òfin Ọlọ́run.—Ìṣe 5:29.
14. Kí ló mú kí ṣíṣe ìgbọràn rọrùn fẹ́ni pípé, síbẹ̀ kí nìdí tí ẹni pípé fi ní láti kọ́ ẹ̀kọ́ nípa ìgbọràn?
14 Tó bá jẹ́ pé ẹni pípé ni ẹ́, tó túmọ̀ sí pé o jẹ́ “aláìlẹ́gbin, tí a yà sọ́tọ̀ kúrò láàárín àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,” gẹ́gẹ́ bíi ti Jésù, ǹjẹ́ o rò pé ìgbà gbogbo ló máa rọrùn fún ẹ láti máa ṣègbọràn sáwọn òbí rẹ? (Hébérù 7:26) Tó o bá jẹ́ ẹni pípé, èrò àtiṣe nǹkan tí ò dáa kò ní máa wá sọ́kàn rẹ bó ṣe rí nísinsìnyí. (Jẹ́nẹ́sísì 8:21; Sáàmù 51:5) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni pípé ni Jésù, síbẹ̀ ó kọ́ onírúurú ẹ̀kọ́ nípa ìgbọràn. Bíbélì sọ pé: “Bí [Jésù] tilẹ̀ jẹ́ Ọmọ, ó kọ́ ìgbọràn láti inú àwọn ohun tí ó jìyà rẹ̀.” (Hébérù 5:8) Báwo ni ìyà ṣe mú kí Jésù kọ́ ìgbọràn, èyí tí Jésù ò kọ́ nígbà tó wà lọ́run?
15, 16. Báwo ni Jésù ṣe kọ́ ìgbọràn?
15 Nígbà tí Jésù wà lọ́mọdé, Jèhófà sọ fún Jósẹ́fù àti Màríà nípa bí wọ́n ṣe máa dáàbò bo Jésù kí ewu má bàa wu ú. (Matthew 2:7-23) Àmọ́ nígbà tó ṣe, Ọlọ́run ò dáàbò bo Jésù lọ́nà ìyanu. Ìrora àti ìyà tí Jésù jẹ pọ̀ débi pé Bíbélì sọ pé Jésù “ṣe ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ àti ìtọrọ . . . pẹ̀lú igbe ẹkún kíkankíkan àti omijé.” (Hébérù 5:7) Ìgbà wo nìyẹn ṣẹlẹ̀?
16 Àkókò tí ìyẹn ṣẹlẹ̀ gan-an ni ìgbà tó kù díẹ̀ ṣíún kí Jésù parí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, tí Sátánì sa gbogbo ipá rẹ̀ láti mú kó ṣe ohun tó lòdì sí ìfẹ́ Ọlọ́run. Ó hàn gbangba pé bí wọ́n ṣe fẹ́ pa Jésù bí arúfin, tó sì mọ̀ pé èyí lè kó ẹ̀gàn bá Bàbá òun, bà á lọ́kàn jẹ́ gan-an débi pé “ó ń bá a lọ ní títúbọ̀ fi taratara gbàdúrà [nínú ọgbà Gẹtisémánì]; òógùn rẹ̀ sì wá dà bí ẹ̀kán ẹ̀jẹ̀ tí ń jábọ́ sí ilẹ̀.” Ní wákàtí díẹ̀ lẹ́yìn ìgbà yẹn, ọ̀nà tí Jésù gbà kú lórí òpó igi mú kó jẹ̀rora débi pé ó ké “igbe ẹkún kíkankíkan [pẹ̀lú] omijé.” (Lúùkù 22:42-44; Máàkù 15:34) Báyìí ni Jésù ṣe dẹni tó “kọ́ ìgbọràn láti inú àwọn ohun tí ó jìyà rẹ̀,” ó sì tipa báyìí múnú Bàbá rẹ̀ dùn. Nísinsìnyí tí Jésù ti wà lọ́run, ó ń bá wa kẹ́dùn bó ṣe ń rí i tá à ń tiraka láti máa ṣègbọràn.—Òwe 27:11; Hébérù 2:18; 4:15.
Bá A Ṣe Lè Kọ́ Ẹ̀kọ́ Nípa Ìgbọràn
17. Ojú wo ló yẹ ká fi wo gbígba ìbáwí?
17 Nígbà tí bàbá rẹ àti ìyá rẹ bá bá ẹ wí, ìyẹn fi hàn pé wọ́n fẹ́ràn ẹ wọ́n sì fẹ́ kó dáa fún ẹ. Bíbélì béèrè pé: “Ọmọ wo ni baba kì í bá wí?” Báwo ló ṣe máa rí táwọn òbí rẹ ò bá fẹ́ràn rẹ débi tí wọ́n á fi máa tọ́ ẹ sọ́nà? Ìyẹn á mà burú o! Bákan náà, ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí ẹ ló mú kó máa tọ́ ẹ sọ́nà. “Lóòótọ́, kò sí ìbáwí tí ó dà bí ohun ìdùnnú nísinsìnyí, bí kò ṣe akó-ẹ̀dùn-ọkàn-báni; síbẹ̀ nígbà tí ó bá yá, fún àwọn tí a ti kọ́ nípasẹ̀ rẹ̀, a máa so èso ẹlẹ́mìí àlàáfíà, èyíinì ni, òdodo.”—Hébérù 12:7-11.
18. (a) Ẹ̀rí kí ni ìbáwí onífẹ̀ẹ́ jẹ́? (b) Àwọn àpẹẹrẹ wo lo ti rí tó fi hàn pé irú ìbáwí bẹ́ẹ̀ máa ń tún ìgbésí ayé àwọn èèyàn ṣe?
18 Sólómọ́nì ọba tó jẹ nílẹ̀ Ísírẹ́lì ìgbàanì, tí Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé ó ní ọgbọ́n tó ga, fi hàn pé ó yẹ káwọn òbí máa fi ìfẹ́ tọ́ ọmọ wọn sọ́nà. Sólómọ́nì kọ̀wé pé: “Ẹni tí ó fa ọ̀pá rẹ̀ sẹ́yìn kórìíra ọmọ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ ni ẹni tí ó wà lójúfò láti fún un ní ìbáwí.” Sólómọ́nì tiẹ̀ sọ pé tẹ́nì kan bá gba ìbáwí onífẹ̀ẹ́ tí wọ́n fún un, èyí lè dá ọkàn rẹ̀ gan-an nídè kúrò lọ́wọ́ ikú. (Òwe 13:24; 23:13, 14; Mátíù 12:42) Arábìnrin kan sọ pé nígbà tóun ṣì kéré, tóun bá ta félefèle nípàdé, bàbá òun á sọ fóun pé táwọn bá délé òun máa jìyà nǹkan tóun ṣe. Ní báyìí tó ti dàgbà, ńṣe ni inú rẹ̀ máa ń dùn sí bàbá rẹ̀ tó bá rántí ìbáwí onífẹ̀ẹ́ tí bàbá rẹ̀ máa ń fún un, èyí tó mú kó máa gbé ìgbé ayé rere.
19. Kí ni ìdí tó ṣe pàtàkì jù lọ tó fi yẹ kó o máa ṣègbọràn sáwọn òbí rẹ?
19 Tó o bá ní òbí tó fẹ́ràn rẹ débi pé wọ́n ń gbìyànjú láti fi ìfẹ́ bá ọ wí, ńṣe ni kó o máa dúpẹ́. Máa ṣègbọràn sí wọn, gẹ́gẹ́ bí Jésù Kristi Olúwa ṣe ṣègbọràn sí Jósẹ́fù àti Màríà tí wọ́n jẹ́ òbí rẹ̀. Ìdí tó ṣe pàtàkì jù lọ tó fi yẹ kó o máa ṣègbọràn sáwọn òbí rẹ ni pé Jèhófà Ọlọ́run tí í ṣe Bàbá rẹ ọ̀run sọ pé kó o máa ṣe bẹ́ẹ̀. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, yóò ṣe ọ́ láǹfààní, ‘nǹkan á lè máa lọ dáadáa fún ọ, wàá sì lè wà fún àkókò gígùn lórí ilẹ̀ ayé.’—Éfésù 6:2, 3.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà Insight on the Scriptures, Apá Kejì, ojú ìwé 841. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Àwọn èrè wo làwọn ọmọ lè rí jẹ tí wọ́n bá ń ṣègbọràn sáwọn òbí wọn?
• Nígbà tí Jésù wà lọ́mọdé, àpẹẹrẹ wo ló fi lélẹ̀ nípa bó ṣe ń ṣègbọràn sáwọn òbí rẹ̀?
• Báwo ni Jésù ṣe kọ́ ìgbọràn?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Nígbà tí Jésù wà lọ́mọ ọdún méjìlá, ó mọ Ìwé Mímọ́ dunjú
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Báwo ni ìyà tí wọ́n fi jẹ Jésù ṣe mú kó kọ́ ìgbọràn?