Ẹ Maa Baa Lọ Ni Didagba Ninu Ìmọ̀
‘Ẹ fi ìmọ̀ kún igbagbọ yin.’—2 PETERU 1:5, NW.
1, 2. (a) Ki ni iwọ lè kẹkọọ rẹ̀ nipa wiwo oju ọ̀run? (Romu 1:20) (b) Ki ni ipẹkun ibisi ninu ìmọ̀ eniyan niti gidi?
KI NI o lè kẹkọọ rẹ̀ nipa bíbọ́ si ìtagbangba ni òru dúdú, mímọ́ kedere kan ti o sì ń wo oṣupa rokoṣo ati ailonka awọn irawọ? Iwọ lè kẹkọọ ohun kan nipa Ẹni naa ti o dá gbogbo nǹkan yii.—Orin Dafidi 19:1-6; 69:34.
2 Bi o bá fẹ́ lati mú ìmọ̀ yẹn pọ̀ sii, iwọ yoo ha gun ori òrùlé ile rẹ ki o sì maa woran lati ibẹ̀ bi? Boya kìí ṣe bẹẹ. Albert Einstein nigba kan ri lo iru àkàwé kan bẹẹ lati ṣalaye koko naa pe awọn onimọ-ijinlẹ kò tíì pọ̀ sii ninu ìmọ̀ nipa agbaye o sì daju pe iwọnba diẹ ni wọn mọ̀ nipa Ẹni naa ti ó dá a.a Dokita Lewis Thomas kọwe pe: “Aṣeyọri kanṣoṣo ti o ga julọ nipa imọ-ijinlẹ ninu awọn ọrundun ti o mesojade julọ niti imọ-ijinlẹ yii ni àwárí naa pe a jẹ́ alaimọkan gidigidi; ohun ti a mọ̀ nipa iṣẹda kere gan-an ni, ohun ti a sì lóye nipa rẹ̀ tun kere ju.”
3. Ni ero itumọ wo ni ibisi ninu ìmọ̀ ń gbà mú irora pọ sii?
3 Àní bi o bá tilẹ lo gbogbo eyi ti o kù ninu iye ọdun ti eniyan kan lè gbé ní ayé lati wá iru ìmọ̀ bẹẹ, iwọ lè tubọ mọ̀ sii nipa bi igbesi-aye ti kuru tó ki o sì rí i lọna ti o tubọ ṣe kedere pe ọ̀nà ti eniyan ń gbà lo ìmọ̀ ni aipe ati ‘ìwà-wíwọ́’ ayé yii ti pààlà si. Solomoni sọ kókó yẹn, ni kikọwe pe: “Ninu ọgbọ́n pupọ ni ibinujẹ pupọ wà, ẹni ti o sì ń sọ ìmọ̀ di pupọ, ó ń sọ ikaaanu di pupọ.” (Oniwasu 1:15, 18) Bẹẹni, jijere ìmọ̀ ati ọgbọ́n tí kò ní isopọ eyikeyii pẹlu awọn ète Ọlọrun sábà maa ń wémọ́ irora ati ibinujẹ.—Oniwasu 1:13, 14; 12:12; 1 Timoteu 6:20.
4. Ìmọ̀ wo ni awa nilati fẹ́ lati jere?
4 Bibeli ha ń damọran pe ki a máṣe nífẹ̀ẹ́-ọkàn ninu mímú ìmọ̀ wa pọ̀ sii ni bi? Aposteli Peteru kọwe pe: “Bẹẹkọ, ṣugbọn ẹ maa baa lọ ni didagba ninu inurere ailẹtọọsi ati ìmọ̀ Oluwa ati Olugbala wa Jesu Kristi. Tirẹ̀ ni ògo nisinsinyi ati titi de ọjọ ayeraye.” (2 Peteru 3:18, NW) A lè tẹwọgba iṣinileti yẹn gẹgẹ bi o ṣe kàn wá a sì nilati tẹwọgba a, niwọn bi o ti ń rọ̀ wá lati dagba ninu ìmọ̀. Ṣugbọn iru ìmọ̀ wo? Bawo ni a ṣe lè pọ̀ sii ninu rẹ̀? Awa ha sì ń ṣe bẹẹ niti gidi bi?
5, 6. Bawo ni Peteru ṣe tẹnumọ ọn pe o yẹ ki a jèrè ìmọ̀?
5 Pipọ sii ninu ìmọ̀ pipeye nipa Ẹlẹdaa agbaye ati nipa Jesu ni èrò ti o ṣe pataki julọ ninu lẹta Peteru keji. Ni ibẹrẹ rẹ̀ ó kọwe pe: “Ki inurere ailẹtọọsi ati alaafia bí sii fun yin nipa ìmọ̀ pipeye ti Ọlọrun ati ti Jesu Oluwa wa, niwọn bi agbara atọrunwa rẹ̀ ti fun wa ni ohun gbogbo ti o kan ọ̀ràn ìyè ati ifọkansin oniwa-bi-Ọlọrun lọfẹẹ, nipa ìmọ̀ pipeye ti ẹni naa ti o pè wá nipasẹ ògo ati iwafunfun.” (2 Peteru 1:2, 3, NW) Nitori naa ó so níní inurere ailẹtọọsi ati alaafia pọ̀ mọ́ jíjèrè ti a ń jèrè ìmọ̀ nipa Ọlọrun ati Ọmọkunrin rẹ̀. Iyẹn bọ́gbọ́nmu, niwọn bi o ti jẹ pe Jehofa, Ẹlẹdaa, ni ìmọ̀ tootọ dá lé lori. Ó ṣeeṣe fun ẹnikan ti o bẹru Ọlọrun lati fi oju ti o tọ́ wo awọn ọ̀ràn ki ó sì dé ipari-ero ti o fẹsẹmulẹ.—Owe 1:7.
6 Lẹhin naa Peteru rọni pe: “Ẹ fi iwafunfun kún igbagbọ yin, ìmọ̀ kún iwafunfun yin, ikora-ẹni-nijaanu kún ìmọ̀ yin, ifarada kún ikora-ẹni-nijaanu yin, ifọkansin oniwa-bi-Ọlọrun kún ifarada yin, ifẹni ará kún ifọkansin oniwa-bi-Ọlọrun yin, ifẹ kún ifẹni ará yin. Nitori bi ohun wọnyi bá wà ninu yin ti wọn sì kún àkúnwọ́sílẹ̀, wọn kì yoo jẹ́ ki ẹ di alaiṣiṣẹ tabi alaileso niti ìmọ̀ pipeye Jesu Kristi Oluwa wa.” (2 Peteru 1:5-8, NW)b Ninu akori ti o tẹle e, a kà pe gbigba ìmọ̀ ń ran awọn eniyan lọwọ lati bọ́ lọwọ awọn isọdẹgbin ayé. (2 Peteru 2:20) Peteru tipa bayii mú un ṣe kedere pe awọn wọnni ti wọn ń di Kristian nilo ìmọ̀, gẹgẹ bi awọn wọnni ti wọn ti ń ṣiṣẹsin Jehofa ṣaaju akoko yii ti ṣe. Iwọ ha wà ninu ọ̀kan ninu awọn ìsọ̀rí wọnyẹn bi?
Kẹkọọ, Ṣàtúnsọ, Lò
7. Ni ọ̀nà wo ni ọpọ ti gbà jèrè ìmọ̀ pipeye nipa awọn otitọ ipilẹ Bibeli?
7 Iwọ lè maa ṣe ikẹkọọ Bibeli pẹlu awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nitori pe o moye otitọ naa ti o wà ninu ihin-iṣẹ wọn. Lẹẹkan lọsẹ, fun wakati kan tabi eyi ti o sunmọ ọn, ẹ ń ṣagbeyẹwo akori Bibeli kan ni lilo aranṣe kan bi Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. Iyẹn tayọlọla! Ọpọlọpọ ti o ti ṣe iru ikẹkọọ kan bẹẹ pẹlu awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti jèrè ìmọ̀ pipeye. Bi o ti wu ki o ri, ki ni iwọ lè ṣe lati mú iwọn ti iwọ bi ẹnikan ń kẹkọọ rẹ̀ pọ̀ sii? Awọn idamọran diẹ niyi.c
8. Nigba ti ó bá ń mura ikẹkọọ kan silẹ, ki ni akẹkọọ kan lè ṣe lati kọ́ ohun pupọ sii?
8 Ṣaaju, bi o ti ń murasilẹ fun ikẹkọọ rẹ, wo akojọpọ-ọrọ ti o fẹ́ lati kárí naa lọ gààràgà. Iyẹn tumọsi wíwo ẹṣin-ọrọ akori naa, awọn isọri-ori-ọrọ, ati awọn aworan eyikeyii ti a lò lati ṣapejuwe akojọpọ-ọrọ naa latokedelẹ. Nigba naa, bi o ti ń ka ipinrọ tabi ẹ̀ka ìpín kan ninu itẹjade naa, maa wá awọn èrò pataki ati awọn iwe mimọ ti o ti awọn èrò pataki naa lẹhin, ni fífàlà sidii iwọnyi tabi pipafiyesi si wọn. Lati rí i bi o bá kẹkọọ awọn otitọ ti a kari naa, gbiyanju lati dahun awọn ibeere ti a beere lori oniruuru awọn ipinrọ. Ni ṣiṣe eyi, gbidanwo lati sọ awọn idahun naa ni ọ̀rọ̀ tirẹ. Lakootan, ṣatunyẹwo ẹkọ naa, ni gbigbiyanju lati ranti awọn koko pataki ati awọn alaye ọ̀rọ̀ tí ó tì í lẹhin.
9. Bawo ni fifi awọn amọran nipa ikẹkọọ silo ṣe lè ran ẹnikan lọwọ lati kẹkọọ?
9 Iwọ lè reti lati pọ̀ sii ninu ìmọ̀ bi o bá fi awọn imọran wọnyi silo. Eeṣe ti o fi jẹ bẹẹ? Idi kan ni pe iwọ yoo maa koju akojọpọ-ọrọ naa pẹlu ìfẹ́-ọkàn mimuna lati kẹkọọ, ni ṣíṣán ọ̀nà silẹ, ki a sọ bẹẹ. Nipa níní òye ṣoki ati wíwá awọn lajori koko ati ọ̀nà ti a gbà gbé ironu kalẹ lẹhin naa, iwọ yoo ri bi awọn kulẹkulẹ ṣe tanmọ ẹṣin-ọrọ tabi ipari-ọrọ naa. Atunyẹwo ikẹhin yoo ràn ọ́ lọwọ lati ranti ohun ti o ti kẹkọọ. Ki ni yoo ràn ọ́ lọwọ lẹhin naa, nigba ikẹkọọ Bibeli rẹ?
10. (a) Eeṣe ti wiwulẹ sọ àsọtúnsọ awọn otitọ tabi isọfunni titun fi ni iniyelori ti o mọniwọn? (b) Ki ni “ipepadasọkan latigbadegba” ni ninu? (c) Bawo ni ọmọkunrin ará Israeli kan ti ṣe lè janfaani lati inu àsọtúnsọ?
10 Awọn ìjìmì ninu pápá ẹkọ-iwe mọ iniyelori àsọtúnsọ ti o bọ si kòńgẹ́ ti o sì níláárí. Eyi kìí ṣe ṣíṣàwítúnwí awọn ọ̀rọ̀ lasan, eyi ti o ti lè gbiyanju ni ile-ẹkọ nigba ti o ń kọ́ awọn orukọ, otitọ, tabi èrò kan lákọ̀ọ́sórí. Bi o ti wu ki o ri, iwọ ha rí i pe kò pẹ́ ti o fi gbagbe ohun ti o ti kà ni àkàsórí naa, pe ó ti yára pòórá kuro ninu agbara iranti? Eeṣe? Wiwulẹ ṣàwítúnwí ọ̀rọ̀ titun tabi otitọ kan lè jẹ́ ohun tí ń súni, awọn iyọrisi rẹ̀ kìí sìí pẹ́. Ki ni o lè yi iyẹn pada? Fifẹ ti o ń fi tootọ tootọ fẹ́ lati kẹkọọ yoo ṣeranwọ. Koko pataki miiran ni àsọtúnsọ ti o níláárí. Ni awọn iṣẹju diẹ lẹhin ti o bá ti kẹkọọ koko kan, ṣaaju ki o tó lọ kuro ninu iranti, gbiyanju lati pe ohun ti o ti kẹkọọ rẹ̀ pada sọkan araarẹ. Eyi ni a ń pè ni “ipepadasọkan latigbadegba.” Nipa mimu agbara iranti rẹ sọji ṣaaju ki ó tó jo isọfunni danu, iwọ ń mú gigun àìgbàgbé gbooro si. Ni Israeli, awọn baba ni wọn nilati fi ìtẹnumọ́ gbin awọn ofin Ọlọrun sinu awọn ọmọkunrin wọn. (Deuteronomi 6:6, 7) “Fi ìtẹnumọ́ gbìn sínú” tumọ si lati kọni nipa àsọtúnsọ. Boya, ọpọlọpọ ninu awọn baba wọnni a kọkọ maa gbé awọn ofin naa kalẹ fun awọn ọmọkunrin wọn; lẹhin naa wọn a tún isọfunni naa sọ; ati lẹhin naa wọn beere ibeere lọwọ awọn ọmọkunrin wọn nipa ohun ti wọn ti kọ́.
11. Ki ni a lè ṣe nigba ikẹkọọ Bibeli kan lati pọ sii ni ẹkọ?
11 Bi Ẹlẹ́rìí kan bá ń dari ikẹkọọ Bibeli pẹlu rẹ, oun lọkunrin tabi lobinrin lè ràn ọ́ lọwọ lati kẹkọọ nipa ṣiṣe àkópọ̀ ti ń tẹsiwaju lóòrèkóòrè laaarin akoko ikẹkọọ naa. Eyi kìí ṣe ọ̀ràn fifini pe ọmọde. Ọ̀nà ìgbàṣe nǹkan ti ń mú ki kikẹkọọ sunwọn sii ni, nitori naa fi tayọtayọ ṣajọpin ninu awọn atunyẹwọ atigbadegba naa. Lẹhin naa, ní opin ikẹkọọ naa, kópa ninu atunyẹwo ikẹhin ninu eyi ti iwọ óò ti dahun lórí. Ni awọn ọ̀rọ̀ tìrẹ funraarẹ, iwọ lè ṣalaye awọn koko naa gẹgẹ bi iwọ yoo ti ṣe ninu kíkọ́ ẹlomiran. (1 Peteru 3:15) Eyi yoo ṣeranwọ lati mu ki ohun ti o kọ́ di apakan agbara iranti rẹ̀ titilọ.—Fiwe Orin Dafidi 119:1, 2, 125; 2 Peteru 3:1.
12. Akẹkọọ kan funraarẹ lè ṣe ki ni lati mú agbara iranti rẹ̀ sunwọn sii?
12 Igbesẹ miiran ti o tun lè ràn ọ́ lọwọ ni pe, ki o sọ ohun ti o kọ́ fun ẹlomiran kan, laaarin ọjọ kan si meji, boya ọmọ ile-ẹkọ ẹlẹgbẹ rẹ, oṣiṣẹ ẹlẹgbẹ rẹ, tabi aladuugbo rẹ kan. Iwọ lè mẹnukan ẹṣin-ọrọ naa ki o sì wá sọ lẹhin naa pe iwọ wulẹ fẹ́ lati rí i bi ó bá lè ranti awọn lajori ọ̀nà ti a gbà gbé ironu kalẹ tabi awọn ẹsẹ iwe mimọ ti o tì í lẹhin lati inu Bibeli. Iyẹn lè tanná ran ọkàn-ìfẹ́ ẹnikeji. Àní bi kò bá tilẹ ṣe bẹẹ, ọ̀nà ti o gba ṣe àsọtúnsọ isọfunni titun naa laaarin alafo ọjọ kan si meji yoo fi idi rẹ̀ mulẹ ninu agbara iranti rẹ. Nigba naa iwọ yoo ti kẹkọọ rẹ̀ niti tootọ, ni ṣiṣe ohun ti 2 Peteru 3:18 rọni lati ṣe.
Kikẹkọọ Loju Mejeeji
13, 14. Eeṣe ti awa fi nilati fẹ́ lati lọ rekọja jijere ati riranti isọfunni lasan?
13 Kikẹkọọ rekọja wiwulẹ gba awọn otitọ kan sinu tabi lílè pe awọn isọfunni kan pada sọkan. Awọn onisin ni ọjọ Jesu ṣe iyẹn pẹlu awọn adura wọn alásọtúnsọ. (Matteu 6:5-7) Ṣugbọn bawo ni isọfunni naa ṣe nipa lori wọn? Wọn ha ń mú eso òdodo jade bi? Ki a má rí i. (Matteu 7:15-17; Luku 3:7, 8) Apakan iṣoro naa ni pe ìmọ̀ naa kò kọja lọ sinu ọkan-aya wọn, lati nipa lori wọn si rere.
14 Gẹgẹ bi Peteru ti wi, kò gbọdọ rí bẹẹ pẹlu awọn Kristian, nigba naa lẹhin lọhun-un ati nisinsinyi. Ó rọ̀ wá lati fi ìmọ̀ ti yoo ràn wá lọwọ lati yẹra fun jijẹ alaiṣiṣẹ tabi alaileso kún igbagbọ wa. (2 Peteru 1:5, 8) Fun eyi lati jasi otitọ ninu ọ̀ràn tiwa, a gbọdọ fẹ́ lati dagba soke ninu ìmọ̀ yẹn ki a sì fẹ́ lati jẹ ki o nipa lori wa jinlẹ jinlẹ, ní gbígbún ibi ti o jinlẹ ninu ọkàn wa ni kẹ́ṣẹ́. Iyẹn lè ṣalai maa figba gbogbo ṣẹlẹ.
15. Iṣoro wo ni o dide lọdọ awọn Heberu diẹ ti wọn jẹ́ Kristian?
15 Ni ọjọ Paulu awọn Heberu ti wọn jẹ́ Kristian ní iṣoro kan lori koko yii. Bi wọn ti jẹ́ Ju, wọn ni ìmọ̀ diẹ nipa Iwe Mimọ. Wọn mọ nipa Jehofa ati diẹ ninu awọn ohun ti o beere fun. Lẹhin naa wọn fi ìmọ̀ nipa Messia kun un, wọn lò igbagbọ, a sì baptisi wọn gẹgẹ bi Kristian. (Iṣe 2:22, 37-41; 8:26-36) La ọpọ oṣu ati ọdun ja, wọn ti nilati lọ si awọn ipade Kristian, nibi ti wọn ti lè ṣajọpin ninu kíka iwe mimọ ati ni sisọrọ ilohunsi. Sibẹ, awọn kan kò dagba ninu ìmọ̀. Paulu kọwe pe: “Nitori nigba ti akoko tó ti o yẹ ki ẹ jẹ olukọ, ẹ tun wà ni ẹni ti ẹnikan yoo maa kọ́ ni ibẹrẹ ipilẹ awọn ọ̀rọ̀ Ọlọrun; ẹ sì di iru awọn ti kò lè ṣe aini wàrà, ti wọn kò sì fẹ́ ounjẹ lile.” (Heberu 5:12) Bawo ni iyẹn ṣe lè rí bẹẹ? Ó ha lè ṣẹlẹ si awa naa pẹlu bi?
16. Ki ni ilẹ̀-oníyìnyín, bawo ni o sì ṣe ń nipa lori awọn eweko?
16 Gẹgẹ bi àkàwé kan, gbé ilẹ̀-oníyìnyín kan yẹwo, ilẹ dídì gbagidi laiyipada ni Ariwa Ilẹ̀-Ayé ati ni awọn ẹkùn miiran nibi ti ipindọgba ìwọ̀n ìgbóná-ìtutù ti wà nisalẹ òdo. Ilẹ, apata, ati omi-abẹ́lẹ̀ ń dì gbagidi, o sì lè fi 900 mita (3,000 ẹsẹ bata) jin sisalẹ nigba miiran. Ni ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn, yíyọ́ yìnyín naa lè wáyé lori iyẹpẹ ti o wà loke ilẹ (ti a ń pè ni iyẹpẹ òkè yìnyín). Bi o ti wu ki o ri, ìpele fẹlẹfẹlẹ ti ilẹ ti ó yọ́ yii sábà maa ń jẹ́ ẹrọ̀fọ̀ nitori pe ọrinrin kò lè ṣàn wọnu ilẹ̀-oníyìnyín nisalẹ. Awọn eweko ti ń dagba lori ìpele fẹlẹfẹlẹ ti o wà lókè sábà maa ń kere tabi jẹ́ rírán; gbongbo wọn kò lè wọnu ilẹ̀-oníyìnyín naa lọ. ‘Ki ni ilẹ̀-oníyìnyín níí ṣe pẹlu boya emi ń dagba ninu ìmọ̀ otitọ Bibeli?’ ni iwọ lè ṣe kayeefi.
17, 18. Bawo ni a ṣe lè lo ilẹ̀-oníyìnyín ati iyẹpẹ ti o wà loke rẹ̀ lati ṣàkàwé ohun ti o ṣẹlẹ si awọn Heberu kan ti wọn di Kristian?
17 Ilẹ̀-oníyìnyín ṣàkàwé ipo ẹni tí agbara èrò-orí rẹ̀ kò fi ìgbékánkán kopa ninu gbígbà sinu, riranti, ati lilo ìmọ̀ pipeye. (Fiwe Matteu 13:5, 20, 21.) Ó ṣeeṣe ki ẹni naa ní agbara èrò-orí lati kẹkọọ oniruuru koko-ẹkọ, titikan awọn otitọ Bibeli. Oun kẹkọọ “ibẹrẹ ipilẹ awọn ọ̀rọ̀ Ọlọrun” ó sì ti lè tootun lati di ẹni ti a baptisi, gẹgẹ bi awọn Heberu ti wọn jẹ́ Kristian wọnni ti ṣe. Bi o ti wu ki o ri, oun lè má maa “lọ si pipe,” si awọn ohun ti o rekọja “ipilẹṣẹ ẹkọ Kristi.”—Heberu 5:12; 6:1.
18 Foju inu wo awọn Kristian wọnyẹn ni ipade nigba naa lọhun-un. Wọn wà nibẹ wọn sì jí kalẹ, ṣugbọn ero-inu wọn ha kopa ninu kikẹkọọ bi? Wọn ha ń fi ìgbékánkán ati ifọkansi dagba ninu ìmọ̀ bi? Boya o lè má jẹ́ bẹẹ. Fun awọn ti kò gbóṣáṣá, ikopa eyikeyii ninu awọn ipade ń ṣẹlẹ lori iyẹpẹ òkè yìnyín, ki a sọ ọ́ bẹẹ, nigba ti o jẹ́ pe isalẹ jẹ́ dídì gbagidi. Gbongbo awọn otitọ ti o tubọ le tabi ṣoro kò lè wọnu ẹkùn ilẹ̀-oníyìnyín niti èrò-orí yii.—Fiwe Isaiah 40:24.
19. Ni ọ̀nà wo ni Kristian oniriiri kan lonii lè gbà dabi awọn Heberu ti wọn di Kristian?
19 Ó lè rí bakan naa pẹlu Kristian kan lonii. Nigba ti oun lè wà ni ipade oun lè má lo awọn akoko iṣẹlẹ wọnyẹn lati dagba ninu ìmọ̀. Ki ni nipa fifi ìgbékánkán ṣajọpin ninu wọn? Fun ẹni titun tabi ọ̀dọ́ kan lati yọnda lati ka ẹsẹ iwe mimọ tabi sọ ọ̀rọ̀ ilohunsi kan ni awọn ọ̀rọ̀ ti o wà ninu ipinrọ lè gba isapa ńláǹlà, ti ń ṣagbeyọ lilo agbara rẹ̀ lọna rere ti o sì yẹ fun igboriyin. Ṣugbọn Paulu fihàn pe fun awọn yooku, ni oju-iwoye akoko ti wọn ti fi jẹ́ Kristian, wọn nilati tẹsiwaju rekọja ipo kikopa akọkọbẹrẹ bi wọn bá fẹ́ lati maa baa lọ ni didagba ninu ìmọ̀.—Heberu 5:14.
20. Ayẹwo kínníkínní ara-ẹni wo ni ẹnikọọkan wa nilati ṣe?
20 Bi Kristian oniriiri kan kò bá tẹsiwaju rekọja wiwulẹ ka ẹsẹ Bibeli kan tabi sisọ ipilẹ ọ̀rọ̀ ilohunsi kan lati inu ipinrọ, o ṣeeṣe ki ikopa rẹ̀ wá lati inu “iyẹpẹ òkè yìnyín” niti ero-inu rẹ̀. Ipade lẹhin ipade lè kọjalọ nigba ti ijinlẹ agbara èrò-orí rẹ̀ ṣì wà ni ipo dídì gbagidi, lati maa bá àkàwé wa nipa ilẹ̀-oníyìnyín lọ. A nilati beere lọwọ araawa pe: ‘Bi ọ̀ràn ha ti rí pẹlu mi niyẹn bi? Mo ha ti jẹ́ ki iru ilẹ̀-oníyìnyín kan niti èrò-orí gbarajọ bi? Bawo ni mo ṣe jẹ́ ẹni ti o wà lojufo niti èrò-orí ti o sì nifẹẹ-ọkan ninu kikẹkọọ tó?’ Àní bi ara kò bá tilẹ tù wá pẹlu awọn idahun alailabosi wa, awa lè bẹrẹ nisinsinyi lati gbé awọn igbesẹ lati dagba ninu ìmọ̀.
21. Awọn igbesẹ ti a jiroro ṣaaju wo ni iwọ lè fisilo ninu mimurasilẹ fun tabi lilọ si awọn ipade?
21 Lẹnikọọkan a lè fi awọn amọran ti o wà ni ipinrọ 8 silo. Laika bi o ti pẹ́ tó ti a ti ń darapọ pẹlu ijọ, a lè pinnu lati maa tẹsiwaju si idagba di gende ati pipọ sii ni ìmọ̀. Pẹlu awọn kan iyẹn yoo tumọsi mimurasilẹ fun awọn ipade lọna alakikanju sii, boya ní mimu awọn àṣà ti wọn tẹ̀lé ní ọpọ ọdun sẹhin ṣugbọn ti o ti rọra fi kẹrẹkẹrẹ bọ́rẹ́lẹ̀ sọjí. Bi o ti ń murasilẹ, gbiyanju lati pinnu ohun ti awọn kókó pataki jẹ́ ati lati loye awọn iwe mimọ ti o kò mọ̀ daradara ti a lò lati gbé ironu kalẹ. Ṣawari oju-iwoye tabi apa-iha titun eyikeyii ninu akojọpọ-ọrọ ikẹkọọ naa. Bakan naa, lakooko ipade, gbiyanju lati fi awọn amọran ti a mẹnukan ninu ipinrọ 10 ati 11 silo fun ara tirẹ alára. Lakaka lati wà lojufo niti èrò-orí, gẹgẹ bi ẹni pe o ń pa ìwọ̀n ìgbóná-ìtutù mọ́ si ìwọ̀n gbigbona ninu ero-inu rẹ. Iyẹn yoo gbejako itẹsi eyikeyii fun “ilẹ̀-oníyìnyín” lati gbarajọ; isapa onifọkansi yii yoo tun yọ́ ipo “dídì gbagidi” eyikeyii ti o ti lè gbèrú ni iṣaaju.—Owe 8:12, 32-34.
Ìmọ̀, Aranṣe kan Siha Imesojade
22. Bawo ni a ṣe lè janfaani bi a bá ṣiṣẹ lori mimu ìmọ̀ wa pọ sii?
22 Bawo ni awa yoo ṣe janfaani lẹnikọọkan bi a bá ṣiṣẹ lori ọ̀ràn didagba ninu inurere ailẹtọọsi ati ìmọ̀ Oluwa ati Olugbala wa Jesu Kristi? Nipa isapa wa tọkàntara lati pa agbara èrò-orí wa mọ ni rekete, ti a sì wà ni imuratan lati gba ìmọ̀ sinu, irugbin awọn otitọ Bibeli titun ti o tubọ daju sii yoo fidii gbongbo mulẹ ṣinṣin, òye wa yoo sì pọ̀ sii yoo sì wà titilọ. Awa yoo lè fiwera pẹlu ohun ti Jesu sọ ninu àkàwé yiyatọ kan nipa ọkan-aya. (Luku 8:5-12) Awọn irugbin ti wọn bọ́ sori ilẹ rere lè mú gbongbo lilagbara jade lati ṣetilẹhin fun awọn eweko ti ń múrú jade ti o sì ń so eso.—Matteu 13:8, 23.
23. Awọn abajade wo ni ó lè jẹyọ nigba ti a bá fi 2 Peteru 3:18 (NW) sọkan? (Kolosse 1:9-12)
23 Àkàwé Jesu yatọ lọna kan ṣá, sibẹ iyọrisi rere naa jọra pẹlu ohun ti Peteru ṣeleri: “Nitori idi yii gan-an, nipa fifi gbogbo isapa onifọkansi yin ṣeranlọwọ afikun ni idahunpada, ẹ fi iwafunfun kún igbagbọ yin, ìmọ̀ kún iwafunfun yin, . . . Nitori bi ohun wọnyi bá wà ninu yin ti wọn sì kún àkúnwọ́sílẹ̀, wọn kì yoo jẹ ki ẹ di alaiṣiṣẹ tabi alaileso niti ìmọ̀ pipeye Jesu Kristi Oluwa wa.” (2 Peteru 1:5-8, NW) Bẹẹni, didagba soke wa ninu ìmọ̀ yoo ràn wá lọwọ lati jẹ́ amesojade. Awa yoo rí i pe gbígba ìmọ̀ pupọ sii sinu paapaa yoo tubọ maa gbadun mọ́ wa. (Owe 2:2-5) Ohun ti o kẹkọọ rẹ̀ ni iwọ yoo ranti yoo sì wulo bi o ti ń kọ́ awọn miiran lati di ọmọ-ẹhin. Nitori naa ni ọ̀nà yii pẹlu, iwọ yoo tubọ jẹ́ amesojade iwọ yoo sì mú ògo wá fun Ọlọrun ati Ọmọkunrin rẹ̀. Peteru pari lẹta rẹ̀ keji pe: “Ẹ maa baa lọ ni didagba ninu inurere ailẹtọọsi ati ìmọ̀ Oluwa ati Olugbala wa Jesu Kristi. Tirẹ̀ ni ògo ati nisinsinyi ati titi de ọjọ ayeraye.”—2 Peteru 3:18, NW.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a “[Ibisi ninu ìmọ̀ wa] ni a lè fiwera pẹlu eyi ti ọkunrin kan, ti o nifẹẹ ọkàn lati mọ pupọ sii nipa oṣupa, ní nigba ti o gun orí òrùlé ile rẹ̀ lati tubọ wo orisun-imọlẹ yẹn.”
b Igbagbọ ati iwafunfun, awọn animọ meji akọkọ ninu àyọkà yii, ni a jiroro ninu itẹjade wa ti July 15, 1993.
c Awọn idamọran wọnyi tun lè ran awọn Kristian ọlọ́jọ́ pipẹ lọwọ lati jèrè pupọ sii lati inu idakẹkọọ ati imurasilẹ wọn fun awọn ipade.
Iwọ Ha Ranti Bi?
◻ Eeṣe ti o fi nilati nifẹẹ-ọkan ninu mimu ìmọ̀ rẹ pọ sii?
◻ Bawo ni akẹkọọ Bibeli titun kan ṣe lè janfaani pupọ sii lati inu ikẹkọọ rẹ̀?
◻ Ewu wo ni iwọ fẹ́ lati yẹra fun, gẹgẹ bi a ṣe ṣàkàwé rẹ̀ nipasẹ ilẹ̀-oníyìnyín?
◻ Eeṣe ti o fi nilati pinnu lati mú agbara rẹ̀ lati pọ̀ sii ni ìmọ̀ gbé pẹẹli?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Mo ha ní iṣoro pẹlu ilẹ̀-oníyìnyín niti èrò-orí bi?