Máa Tẹ̀ Lé Àṣẹ Jèhófà
“Èyí ni ohun tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí, pé kí a pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́; síbẹ̀ àwọn àṣẹ rẹ̀ kì í ṣe ẹrù ìnira.”—1 JÒH. 5:3.
1, 2. (a) Kí nìdí tí inú ọ̀pọ̀ èèyàn fi máa ń ru tí wọ́n bá gbọ́ pé ó yẹ kéèyàn máa tẹrí ba fáwọn aláṣẹ? (b) Ṣé lóòótọ́ làwọn tí wọ́n láwọn ò gba ẹnì kankan lọ́gàá wà lómìnira ara wọn? Ṣàlàyé.
LÓDE òní, ọ̀pọ̀ èèyàn kì í fẹ́ kí ẹnikẹ́ni máa darí àwọn. Ṣe ni inú ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń ru tí wọ́n bá gbọ́ pé ó yẹ kéèyàn máa tẹ̀ lé àṣẹ àwọn ẹlòmíì. Àwọn kan wà tí wọn ò fẹ́ máa tẹrí ba fáwọn aláṣẹ, ìwà tí wọ́n ń hù jọ bí ẹní ń sọ pé: “Ẹnikẹ́ni ò lè kọ́ mi lóhun tó yẹ kí n ṣe.” Àmọ́, ṣé lóòótọ́ làwọn èèyàn yìí wà lómìnira ara wọn? Irọ́ gbuu! Ṣe ni ọ̀pọ̀ wọn kàn ń tẹ̀ lé àìmọye èèyàn tó ń ṣe “àfarawé ètò àwọn nǹkan yìí” lẹ́yìn gọ̀ọ́gọ̀ọ́. (Róòmù 12:2) Kàkà kí wọ́n wà lómìnira, “ẹrú ìdíbàjẹ́” ni àpọ́sítélì Pétérù pè wọ́n. (2 Pét. 2:19) Wọ́n ń rìn “ní ìbámu pẹ̀lú ètò àwọn nǹkan ti ayé yìí, ní ìbámu pẹ̀lú olùṣàkóso ọlá àṣẹ afẹ́fẹ́,” ìyẹn Sátánì Èṣù.—Éfé. 2:2.
2 Òǹṣèwé kan fọ́nnu pé: “Mi ò fara mọ́ ọn kó jẹ́ pé àwọn òbí mi, tàbí àlùfáà kan tàbí oníwàásù èyíkéyìí . . . tàbí Bíbélì lá máa sọ ohun tí màá kà sí òtítọ́ tàbí irọ́ fún mi.” Lóòótọ́, àwọn kan lè ṣi agbára wọn lò débi pé wọn ò yẹ lẹ́ni tá a lè máa gbọ́ràn sí lẹ́nu. Àmọ́ ṣé ká wá sọ pé a ò nílò ìtọ́ni ẹnikẹ́ni rárá ni? Tá a bá wo àwọn àkọlé tó wà nínú ìwé ìròyìn gààràgà, a óò rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí. Ó bani nínú jẹ́ pé àkókò yìí gan-an tọ́mọ aráyé nílò ìtọ́sọ́nà ni ọ̀pọ̀ jù lọ wọn ò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni máa tọ́ wọn sọ́nà.
Ojú Tá A Fi Ń Wo Títẹríba Fáwọn Aláṣẹ
3. Báwo làwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ṣe fi hàn pé àwọn kì í kàn-án ṣe gbogbo ohun táwọn èèyàn bá pa láṣẹ?
3 Èrò àwa Kristẹni yàtọ̀ sí tayé. Àwa kì í kàn-án ṣe gbogbo ohun táwọn èèyàn bá ní ká ṣe láìwò ó bóyá ó tọ́ tàbí kò tọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn ìgbà kan wà tá a ní láti kọ ohun táwọn kan bá pa láṣẹ fún wa, kódà káwọn onítọ̀hún jẹ́ aláṣẹ. Bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ àwọn Kristẹni tó wà ní ọ̀rúndún kìíní rí. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí àlùfáà àgbà àtàwọn èèyàn jàǹkàn-jàǹkàn yòókù tó wà nínú ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn pàṣẹ fáwọn àpọ́sítélì pé kí wọ́n ṣíwọ́ wíwàásù, àwọn àpọ́sítélì ò jẹ́ kí ẹ̀rù bà wọ́n débi tí wọ́n á fi tẹ̀ lé àṣẹ yẹn. Wọn ò tìtorí pé wọ́n fẹ́ láti tẹrí ba fáwọn aláṣẹ ayé kí wọ́n wá pa ìwà títọ́ wọn tì.—Ka Ìṣe 5:27-29.
4. Àwọn àpẹẹrẹ wo ló wà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tó jẹ́ ká rí i pé ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn Ọlọ́run ló ṣohun tó yàtọ̀ sí tayé?
4 Ọ̀pọ̀ ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó wà ṣáájú ìgbà ayé Jésù ló ṣerú ìpinnu kan náà. Bí àpẹẹrẹ, Mósè “kọ̀ kí a máa pe òun ní ọmọkùnrin ti ọmọbìnrin Fáráò, ó yàn pé kí a ṣẹ́ òun níṣẹ̀ẹ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn Ọlọ́run,” bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyẹn mú kó rí “ìbínú ọba.” (Héb. 11:24, 25, 27) Jósẹ́fù kọ̀ láti bá ìyàwó Pọ́tífárì ṣe ìṣekúṣe, bó tilẹ̀ jẹ́ pé obìnrin yẹn lágbára láti mú kí Jósẹ́fù jìyà rẹ̀. (Jẹ́n. 39:7-9) Dáníẹ́lì “pinnu ní ọkàn-àyà rẹ̀ pé òun kì yóò sọ ara òun di eléèérí nípasẹ̀ àwọn oúnjẹ adùnyùngbà ọba,” bó tilẹ̀ jẹ́ olórí àwọn òṣìṣẹ́ ààfin ọba Bábílónì kò fẹ́ fara mọ́ ìpinnu tó ṣe yẹn. (Dán. 1:8-14) Irú àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyí jẹ́ ká rí i pé látìgbà láéláé ni àwọn èèyàn Ọlọ́run ti máa ń dúró lórí òtítọ́ láìbẹ̀rù ohun tó lè tìdí ẹ̀ yọ. Wọn ò tìtorí àtirí ojú rere ẹ̀dá kí wọ́n wá máa tẹ̀ lé àṣẹ wọn. Ó yẹ káwa náà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn.
5. Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín àwa àti aráyé lórí ọ̀ràn títẹ̀lé àṣẹ?
5 Dídúró tá a dúró bí onígboyà kì í ṣọ̀rọ̀ oríkunkun, kì í sì í ṣe pé a dà bí àwọn kan tó ń fẹ̀hónú hàn lórí ohun tí kò tẹ́ wọn lọ́rùn nínú ètò òṣèlú. Kàkà bẹ́ẹ̀, tiwa ni pé ká ti máa tẹ̀ lé àṣẹ Jèhófà dípò tènìyàn. Tó bá ṣẹlẹ̀ pé òfin èèyàn ta ko òfin Ọlọ́run, ìpinnu wa kì í ṣe ọ̀rọ̀ lọ-ká-bọ̀. Ohun táwọn àpọ́sítélì ṣe ní ọ̀rúndún kìíní làwa náà á ṣe, ìyẹn ni pé a gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.
6. Kí nìdí tó fi dáa ká máa ṣe gbogbo ohun tí Jèhófà bá pa láṣẹ?
6 Kí ló ti ràn wá lọ́wọ́ láti máa tẹ̀ lé àṣẹ Ọlọ́run? Ohun tó ràn wá lọ́wọ́ ni pé a fara mọ́ ohun tó wà nínú Òwe 3:5, 6 tó sọ pé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.” A gbà pé ohunkóhun tí Ọlọ́run bá ní ká ṣe yóò ṣe wá láǹfààní. (Ka Diutarónómì 10:12, 13.) Kódà nígbà tí Jèhófà ṣàlàyé bóun ṣe jẹ́ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó sọ pé òun ni “Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní, Ẹni tí ń mú kí o tọ ọ̀nà tí ó yẹ kí o máa rìn.” Ó wá fi kún un pé: “Ì bá ṣe pé ìwọ yóò fetí sí àwọn àṣẹ mi ní tòótọ́! Nígbà náà, àlàáfíà rẹ ì bá dà bí odò, òdodo rẹ ì bá sì dà bí ìgbì òkun.” (Aísá. 48:17, 18) A gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yẹn. Ó dá wa lójú pé fún àǹfààní ara wa ni tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tí Ọlọ́run pa láṣẹ.
7. Kí ló yẹ ká ṣe tá ò bá mọ ìdí tí Ọlọ́run fi pa ohun kan láṣẹ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀?
7 A ní láti máa tẹ̀ lé àṣẹ Jèhófà, ká sì ṣe gbogbo ohun tó bá ní ká ṣe, kódà tá ò bá tiẹ̀ mọ ìdí tó fi pa ohun kan láṣẹ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Kì í ṣe pé a ya gọ̀ǹgọ̀ṣú o; ìgbẹ́kẹ̀lé tá a ní nínú rẹ̀ ló fà á. Ńṣe ló fi hàn pé ọkàn wa balẹ̀ digbí pé Jèhófà mọ ohun tó yẹ wá. Ìgbọ́ràn wa sì tún fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, torí ohun tí àpọ́sítélì Jòhánù sọ ni pé: “Èyí ni ohun tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí, pé kí a pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.” (1 Jòh. 5:3) Àmọ́ ohun kan wà lórí ọ̀ràn ìgbọràn yìí tí kò yẹ ká gbójú fò.
Bá A Ṣe Lè Kọ́ Agbára Ìwòye Wa
8. Báwo ni ọ̀ràn títẹ̀lé àṣẹ Jèhófà ṣe kan ọ̀ràn kíkọ́ “agbára ìwòye” wa?
8 Bíbélì sọ fún wa pé ká “kọ́ agbára ìwòye” wa “láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.” (Héb. 5:14) Torí náà, kì í ṣe pé a ó kàn máa pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́ láìronú nípa wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká lè lo ìlànà Jèhófà láti “fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.” Ó yẹ káwa fúnra wa rí bí àwọn ọ̀nà Jèhófà ṣe bọ́gbọ́n mu ká lè sọ bí onísáàmù kan ṣe sọ, pé: “Òfin rẹ sì ń bẹ ní ìhà inú mi.”—Sm. 40:8.
9. Báwo la ṣe lè mú kí ẹ̀rí ọkàn wa máa ṣiṣẹ́ níbàámu pẹ̀lú ìlànà Jèhófà, kí sì nìdí tí èyí fi ṣe pàtàkì?
9 Ká tó lè ní irú ìmọrírì yẹn fún òfin Ọlọ́run, a ní láti máa ṣàṣàrò lórí ohun tá a bá kà nínú Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun kan tí Jèhófà fẹ́ ká máa ṣe, a lè béèrè pé: ‘Ọgbọ́n wo ló wà nínú àṣẹ tàbí ìlànà yìí? Kí nìdí tó fi jẹ́ pé títẹ̀lé àṣẹ náà ló máa ṣe mí láǹfààní jù lọ? Wàhálà wo làwọn tí kò tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Ọlọ́run lórí ọ̀ràn yìí ti kó sí?’ Tí ẹ̀rí ọkàn wa bá ti tipa báyìí bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ níbàámu pẹ̀lú ìlànà Jèhófà, a óò túbọ̀ lè máa ṣèpinnu tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu. Á ṣeé ṣe fún wa láti máa “bá a lọ ní ríróye ohun tí ìfẹ́ Jèhófà jẹ́,” a ó sì lè máa bá a lọ́ gẹ́gẹ́ bí onígbọràn. (Éfé. 5:17) Èyí kì í fìgbà gbogbo rọrùn ṣá o.
Sátánì Fẹ́ Máa Jin Àṣẹ Ọlọ́run Lẹ́sẹ̀
10. Kí ni ọ̀kan lára ọ̀nà tí Sátánì máa ń gbà jin àṣẹ Ọlọ́run lẹ́sẹ̀?
10 Ó ti pẹ́ tí Sátánì ti ń gbìyànjú láti máa jin àṣẹ Ọlọ́run lẹ́sẹ̀. À ń rí èyí nínú oríṣiríṣi ọ̀nà tó ń gbà mú kí àwọn èèyàn máa ní ẹ̀mí tinú-mi-ni-màá-ṣe. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ èèyàn ò fọwọ́ pàtàkì mú ètò ìgbéyàwó tí Ọlọ́run dá sílẹ̀. Àwọn ọkùnrin àti obìnrin kan yàn láti máa gbé pọ̀ láìṣègbéyàwó, àwọn míì sì ń wá ọgbọ́n tí wọ́n á fi kọ aya tàbí ọkọ wọn sílẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ gbà pẹ̀lú ìlúmọ̀ọ́ká eléré orí ìtàgé kan tó sọ pé: “Aláya-máà-lálè kan ò sí, bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí alọ́kọ-máà-lálè.” Ó fi kún un pé: “Mi ò tíì rẹnì ọ̀hún tó lè sọ pé òun ò lójú síta tàbí kó sọ pé òun kò ní lójú síta.” Nígbà tí gbajúmọ̀ òṣèré míì ń sọ̀rọ̀ nípa bí àárín òun àtìyàwó ẹ̀ ṣe dà rú, ó ní: “Mi ò rò pé ó wà nínú ẹ̀jẹ̀ wa pé kéèyàn má pààrọ̀ ọkọ tàbí ìyàwò rẹ̀ títí ayé ẹ̀.” Ó yẹ kí olúkúlùkù wa bi ara rẹ̀ pé, ‘Ṣé mo fara mọ́ àṣẹ Jèhófà lórí ọ̀ràn ìgbéyàwó, àbí ọwọ́ yọ̀bọ́kẹ́ táráyé fi mú un lèmi náà gbà pé ó tọ̀nà?’
11, 12. (a) Kí nìdí tó fi lè ṣòro fáwọn ọ̀dọ́ láti máa tẹ̀ lé àṣẹ Jèhófà? (b) Sọ ìrírí ẹnì kan tó jẹ́ ká rí i pé ìwà òmùgọ̀ ni láti máa ṣàìgbọràn sí òfin àti ìlànà Jèhófà.
11 Tó o bá jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀dọ́ tó wà nínú ètò Jèhófà, ó ṣeé ṣe kí Sátánì máa wá gbogbo ọ̀nà táá fi mú kó o rò pé títẹ̀lé àṣẹ Jèhófà kò pé ọ. “Àwọn ìfẹ́-ọkàn tí ó máa ń bá ìgbà èwe rìn” àti báwọn ẹgbẹ́ rẹ á ṣe fẹ́ kó o máa ṣohun tí wọ́n ń ṣe lè mú kó o rò pé àwọn òfin Ọlọ́run ti nira jù. (2 Tím. 2:22) Má ṣe jẹ́ kíyẹn ṣẹlẹ̀ sí ẹ o. Gbìyànjú láti rí ìdí táwọn ìlànà Ọlọ́run fi bọ́gbọ́n mu. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé kó o “máa sá fún àgbèrè.” (1 Kọ́r. 6:18) O tún lè bi ara rẹ pé: ‘Ọgbọ́n wo ló wà nínú àṣẹ yẹn? Àǹfààní wo ni màá rí nínú rẹ̀ tí mo bá ṣègbọràn sí i?’ Ó ṣeé ṣe kó o mọ àwọn kan tó tàpá sí ìmọ̀ràn Ọlọ́run tí ojú wọn sì rí màbo nídìí ohun tí wọ́n ṣe. Ǹjẹ́ àwọn èèyàn yìí ń láyọ̀ nísinsìnyí? Ṣé ìgbésí ayé wọn dára ju bó ṣe rí lọ nígbà tí wọ́n wà nínú ètò Jèhófà? Ṣé lóòótọ́ ni wọ́n ti rí àṣírí ayọ̀ kan táwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó kù kò tíì rí?—Ka Aísáyà 65:14.
12 Ronú nípa ohun tí arábìnrin kan tó ń jẹ́ Sharon sọ, ó ní: “Nítorí pé mo tàpá sófin Jèhófà, mo kó àrùn éèdì. Mo máa ń kábàámọ̀ àṣìṣe mi yìí tí mo bá rántí ọ̀pọ̀ ọdún tí mo ti fi gbádùn iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.” Ó rí i pé ìwà òmùgọ̀ ló jẹ́ láti rú òfin Jèhófà àti pé ó yẹ kóun ti máa fọ́wọ́ pàtàkì mú àwọn òfin náà. Ààbò làwọn òfin Jèhófà jẹ́ fún wa. Ọ̀sẹ̀ méje péré lẹ́yìn tí Sharon kọ ọ̀rọ̀ yìí sílẹ̀ ló kú. Gẹ́gẹ́ bá a ṣe rí i látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i yìí, Sátánì ò ní àǹfààní kankan tó lè ṣe fáwọn tó bá dara pọ̀ mọ́ ètò nǹkan búburú yìí. “Baba irọ́” ni, ó máa ń ṣe ọ̀pọ̀ ìlérí, àmọ́ kì í mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Àwa náà ṣáà rí i pé ìlérí tó ṣe fún Éfà kò ṣẹ. (Jòh. 8:44) Torí náà, ohun tó dáa jù ni pé ká máa tẹ̀ lé àṣẹ Jèhófà.
Má Ṣe Fàyè Gba Ẹ̀mí Tinú-Mi-Ni-Màá-Ṣe
13. Kí ló yẹ ká ṣọ́ra fún ká má bàa fàyè gba ẹ̀mí tinú-mi-ni-màá-ṣe?
13 Tá a bá fẹ́ máa tẹ̀ lé àṣẹ Jèhófà, a ò ní fàyè gba ẹ̀mí tinú-mi-ni-màá-ṣe. Ẹ̀mí ìgbéraga lè mú ká máa rò pé a kò nílò ìtọ́sọ́nà látọ̀dọ̀ ẹnì kankan. Bí àpẹẹrẹ, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í kọ etí ikún sí ìmọ̀ràn àwọn tó ń múpò iwájú láàárín àwa èèyàn Ọlọ́run. Ọlọ́run ti ṣètò pé kí ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye máa fún wa lóunjẹ tẹ̀mí ní àkókò tó bẹ́tọ̀ọ́ mu. (Mát. 24:45-47) Ó yẹ kí ìrẹ́lẹ̀ mú ká gbà pé ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń bójú tó àwọn èèyàn rẹ̀ lónìí nìyẹn. Ẹ jẹ́ ká fìwà jọ àwọn àpọ́sítélì adúróṣinṣin. Nígbà táwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù kan kọsẹ̀ tí wọ́n sì padà lẹ́yìn rẹ̀, Jésù béèrè lọ́wọ́ àwọn àpọ́sítélì pé: “Ẹ̀yin kò fẹ́ lọ pẹ̀lú, àbí?” Pétérù fèsì pé: “Olúwa, ọ̀dọ̀ ta ni àwa yóò lọ? Ìwọ ni ó ní àwọn àsọjáde ìyè àìnípẹ̀kun.”—Jòh. 6:66-68.
14, 15. Kí nìdí tó fi yẹn ká máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀?
14 Títẹ̀lé àṣẹ Jèhófà túmọ̀ sí pé ká máa tẹ̀ lé àwọn ìmọ̀ràn tó bá wá látinú Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye ti ń ṣèkìlọ̀ pé “kí a wà lójúfò, kí a sì pa agbára ìmòye wa mọ́.” (1 Tẹs. 5:6) Ìmọ̀ràn yẹn wúlò gan-an láwọn ọjọ́ ìkẹyìn tá a wà yìí, nínú èyí tí ọ̀pọ̀ èèyàn ti di “olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó.” (2 Tím. 3:1, 2) Ǹjẹ́ irú ẹ̀mí tó gbòde kan yìí lè ran àwa náà? Ó lè ràn wá o. Tá a bá ń lépa àwọn ohun tí kì í ṣe tẹ̀mí, ó lè mú ká sùn nípa tẹ̀mí, tàbí kó mú ká dẹni tó ń fẹ́ kó dúkìá jọ. (Lúùkù 12:16-21) Ẹ ò rí i báyìí pé ó bọ́gbọ́n mu láti máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì, ká sì yẹra fún ẹ̀mí ìmọ̀tara-ẹni-nìkan tó gbòde kan nínú ayé Sátánì yìí!—1 Jòh. 2:16.
15 À ń rí oúnjẹ tẹ̀mí tí ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye ń pèsè gbà nípasẹ̀ àwọn alàgbà tá a yàn sípò nínú ìjọ. Bíbélì gbà wá níyànjú pé: “Ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn tí ń mú ipò iwájú láàárín yín, kí ẹ sì jẹ́ ẹni tí ń tẹrí ba, nítorí wọ́n ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí ọkàn yín bí àwọn tí yóò ṣe ìjíhìn; kí wọ́n lè ṣe èyí pẹ̀lú ìdùnnú, kì í sì í ṣe pẹ̀lú ìmí ẹ̀dùn, nítorí èyí yóò ṣe ìpalára fún yín.” (Héb. 13:17) Ṣéyẹn wá túmọ̀ sí pé àwọn alàgbà ò lè ṣàṣìṣe ni? Rárá o! Ọlọ́run rí àwọn àṣìṣe wọn kedere ju béèyàn èyíkéyìí ṣe lè rí i lọ. Síbẹ̀, ó fẹ́ ká jẹ́ onítẹríba. Tá a bá ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn alàgbà, láìwo kùdìẹ̀-kudiẹ wọn, ńṣe là ń fi hàn pé a ń tẹ̀ lé àṣẹ Jèhófà.
Bí Ìrẹ̀lẹ̀ Ti Ṣe Pàtàkì Tó
16. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún Jésù tó jẹ́ Orí ìjọ?
16 Ó yẹ ká máa rántí ní gbogbo ìgbà pé Jésù gan-an ni Orí ìjọ. (Kól. 1:18) Ìdí nìyẹn tó fi yẹ ká nírẹ̀lẹ̀ ká sì máa tẹrí ba fún àwọn alàgbà tó yàn sípò, ká máa “fún wọn ní ìkàsí tí ó ju àrà ọ̀tọ̀ lọ.” (1 Tẹs. 5:12, 13) Àmọ́ ṣá, àwọn alàgbà náà ní láti fi hàn pé àwọn nítẹríba nípa ṣíṣọ́ra, kí wọ́n rí i dájú pé ọ̀rọ̀ tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni wọ́n ń sọ fún ìjọ, kì í ṣe èrò tara wọn. Wọn ò gbọdọ̀ “ré kọjá àwọn ohun tí a ti kọ̀wé rẹ̀,” nítorí àtigbé èrò tara wọn lárugẹ.—1 Kọ́r. 4:6.
17. Kí nìdí tí wíwá ipò ọlá fi léwu?
17 Gbogbo àwa tá a wà nínú ìjọ la gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún wíwá ògo ara wa. (Òwe 25:27) Ẹ̀rí fi hàn pé ohun tó fa ìṣòro ọmọ ẹ̀yìn kan tí àpọ́sítélì Jòhánù pàdé nìyẹn. Jòhánù kọ̀wé pé: “Dìótíréfè, ẹni tí ń fẹ́ láti gba ipò àkọ́kọ́ láàárín wọn, kò fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ gba ohunkóhun láti ọ̀dọ̀ wa. Ìdí nìyẹn, bí mo bá dé, tí èmi yóò fi rántí àwọn iṣẹ́ rẹ̀ tí ó ń bá a lọ ní ṣíṣe, tí ó ń fi àwọn ọ̀rọ̀ burúkú wírèégbè nípa wa.” (3 Jòh. 9, 10) Àwa pẹ̀lú ní ẹ̀kọ́ kan tá a lè rí kọ́ nínú ìyẹn lónìí. Ó yẹ ká fa gbogbo ohun tá a bá rí tó jẹ mọ́ wíwá ipò ọlá tu kúrò lọ́kàn wa. Bíbélì sọ fún wa pé: “Ìgbéraga ní í ṣáájú ìfọ́yángá, ẹ̀mí ìrera sì ní í ṣáájú ìkọsẹ̀.” Àwọn tó bá ń tẹ̀ lé àṣẹ Ọlọ́run ní láti ṣọ́ra fún ẹ̀mí ìkùgbù, torí pé ìkùgbù máa ń fa ẹ̀tẹ́.—Òwe 11:2; 16:18.
18. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti máa tẹ̀ lé àṣẹ Jèhófà?
18 Látàrí èyí, fi ṣe àfojúsùn rẹ láti má ṣe fàyè gba ẹ̀mí tinú-mi-ni-màá-ṣe, àṣẹ Jèhófà ni kó o sì máa tẹ̀ lé. Látìgbàdégbà, máa ṣàṣàrò lórí àǹfààní ńlá tó o ní láti máa sin Jèhófà, kó o sì mọrírì àǹfààní náà. Pé o tiẹ̀ wà lára àwọn èèyàn Ọlọ́run jẹ́ ẹ̀rí pé Ọlọ́run ti fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ fà ọ́. (Jòh. 6:44) Má ṣe fojú kékeré wo àjọṣe àárín ìwọ àti Ọlọ́run. Máa sa gbogbo ipá rẹ ní gbogbo ọ̀nà láti rí i pé o kọ ẹ̀mí tinú-mi-ni-màá-ṣe sílẹ̀, kó o sì máa tẹ̀ lé àṣẹ Jèhófà.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Kí ló túmọ̀ sí láti máa tẹ̀ lé àṣẹ Jèhófà?
• Báwo ni ọ̀ràn títẹ̀lé àṣẹ Jèhófà ṣe kan ọ̀ràn kíkọ́ agbára ìwòye wa?
• Àwọn apá ibo ni Sátánì ti ń gbìyànjú láti jin àṣẹ Ọlọ́run lẹ́sẹ̀?
• Kí nìdí tí ìrẹ̀lẹ̀ fi ṣe pàtàkì nínú títẹ̀lé àṣẹ Jèhófà?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
“Àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Ohun tó bọ́gbọn mu ni pé ká máa tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run