Bawo Ni Ìgbàgbọ́ Rẹ Ṣe Lágbára Tó?
“Nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ yín ni ẹ dúró.”—2 KỌ́RÍŃTÌ 1:24.
1, 2. Kí nìdí tó fi yẹ ká ní ìgbàgbọ́, báwo ló sì ṣe lè túbọ̀ lágbára sí i?
ÀWỌN ìránṣẹ́ Jèhófà mọ̀ pé àwọn gbọ́dọ̀ nígbàgbọ́. Ká sòótọ́, ‘láìsí ìgbàgbọ́ kò ṣeé ṣe láti wu Ọlọ́run dáadáa.’ (Hébérù 11:6) Nítorí náà, ó bọ́gbọ́n mu pé ká gbàdúrà kí Ọlọ́run fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ àti ìgbàgbọ́, tó jẹ́ ara èso rẹ̀ fífanimọ́ra. (Lúùkù 11:13; Gálátíà 5:22, 23) Fífara wé ìgbàgbọ́ àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ tún lè fún ànímọ́ yìí lókun nínú wa.—2 Tímótì 1:5; Hébérù 13:7.
2 Ìgbàgbọ́ wa yóò túbọ̀ lágbára sí i tá a bá tẹra mọ́ títẹ̀lé ipa ọ̀nà tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run là sílẹ̀ fún gbogbo Kristẹni. Ìgbàgbọ́ wa sì lè pọ̀ sí i tá a bá ń ka Bíbélì lójoojúmọ́, tá a sì ń fi taápọntaápọn kẹ́kọ̀ọ́ nínú Ìwé Mímọ́ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ìtẹ̀jáde tí “olóòótọ́ ìríjú náà” ń pèsè. (Lúùkù 12:42-44; Jóṣúà 1:7, 8) Ìgbàgbọ́ ẹnì kìíní kejì wa tún ń fún wa níṣìírí nípasẹ̀ àwọn ìpàdé Kristẹni àtàwọn àpéjọ. (Róòmù 1:11, 12; Hébérù 10:24, 25) A tún ń fún ìgbàgbọ́ wa lókun nígbà tá a bá ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lóde ẹ̀rí.—Sáàmù 145:10-13; Róòmù 10:11-15.
3. Lórí ọ̀ràn ìgbàgbọ́, ìrànlọ́wọ́ wo la máa ń rí gbà látọ̀dọ̀ àwọn Kristẹni alàgbà tó jẹ́ onífẹ̀ẹ́?
3 Àwọn Kristẹni alàgbà ń ràn wá lọ́wọ́ láti gbé ìgbàgbọ́ wa ró nípa fífún wa ní ìmọ̀ràn àti ìṣírí látinú Ìwé Mímọ́. Ẹ̀mí tí wọ́n ní dà bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, tó sọ fún àwọn ará Kọ́ríńtì pé: “A jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ fún ìdùnnú yín, nítorí nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ yín ni ẹ dúró.” (2 Kọ́ríńtì 1:23, 24) Ìtumọ̀ Bíbélì mìíràn kà pé: “À ń bá yín ṣiṣẹ́ pọ̀ kí inú yín lè dùn, nítorí pé ìgbàgbọ́ yín lágbára.” (Contemporary English Version) Ìgbàgbọ́ ló máa mú kí olódodo wà láàyè. Ó dájú pé kò sí ẹnikẹ́ni tó lè bá wa ní ìgbàgbọ́ tó yẹ ká ní tàbí tó lè sọ wá di adúróṣinṣin tó ń pa ìwà títọ́ mọ́. Nínú èyí, ‘olúkúlùkù gbọ́dọ̀ ru ẹrù ara rẹ̀.’—Gálátíà 3:11; 6:5.
4. Báwo ni ìtàn àwọn onígbàgbọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó wà nínú Ìwé Mímọ́ ṣe lè ṣèrànwọ́ láti fún ìgbàgbọ́ wa lókun?
4 Ìtàn àwọn tó nígbàgbọ́ kún inú Ìwé Mímọ́ fọ́fọ́. A lè mọ ọ̀pọ̀ lára ohun títayọ tí wọ́n ṣe, àmọ́ ìgbàgbọ́ tí wọ́n ń fi hàn lójoojúmọ́ ńkọ́, bóyá fún àkókò gígùn pàápàá? Ríronú nísinsìnyí lórí bí wọ́n ṣe fi ànímọ́ yìí hàn nínú àwọn ipò tó bá tiwa mu lè ṣèrànwọ́ láti fún ìgbàgbọ́ wa lókun.
Ìgbàgbọ́ Ń Fún Wa Nígboyà
5. Ẹ̀rí Ìwé Mímọ́ wo ló fi hàn pé ìgbàgbọ́ ń fún wa lókun láti fi tìgboyàtìgboyà kéde ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
5 Ìgbàgbọ́ ń fún wa lókun láti fi ìgboyà kéde Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Énọ́kù fi tìgboyàtìgboyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìmúṣẹ ìdájọ́ Ọlọ́run. Ó sọ pé: “Wò ó! Jèhófà wá pẹ̀lú ẹgbẹẹgbàárùn-ún rẹ̀ mímọ́, láti mú ìdájọ́ ṣẹ ní kíkún sí gbogbo ènìyàn, àti láti dá gbogbo aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run lẹ́bi nípa gbogbo ìṣe àìṣèfẹ́ Ọlọ́run wọn, èyí tí wọ́n ṣe lọ́nà àìṣèfẹ́ Ọlọ́run, àti nípa gbogbo ohun amúnigbọ̀nrìrì tí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run ti sọ lòdì sí i.” (Júúdà 14, 15) Ó dájú pé pípa làwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá Énọ́kù fẹ́ pa á nígbà tí wọ́n gbọ́ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀, ó fi tìgboyàtìgboyà sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìgbàgbọ́, Ọlọ́run sì “mú un lọ” nípa jíjẹ́ kó sùn nínú ikú, ìyẹn ni pé kò jẹ́ kó joró ikú rárá. (Jẹ́nẹ́sísì 5:24; Hébérù 11:5) Àwọn iṣẹ́ ìyanu báwọ̀nyí kì í ṣẹlẹ̀ sí wa, àmọ́ Jèhófà ń dáhùn àwọn àdúrà wa ká lè máa fi ìgbàgbọ́ àti ìgboyà kéde ọ̀rọ̀ rẹ̀.—Ìṣe 4:24-31.
6. Báwo ni ìgbàgbọ́ àti ìgboyà tí Ọlọ́run ń fúnni ṣe ran Nóà lọ́wọ́?
6 Nípa ìgbàgbọ́ ni Nóà “kan ọkọ̀ áàkì fún ìgbàlà agbo ilé rẹ̀.” (Hébérù 11:7; Jẹ́nẹ́sísì 6:13-22) Nóà tún jẹ́ “oníwàásù òdodo” tó fi tìgboyàtìgboyà kéde ìkìlọ̀ Ọlọ́run fáwọn èèyàn ìgbà ayé rẹ̀. (2 Pétérù 2:5) Wọ́n ti ní láti fi ìwàásù rẹ̀ nípa Àkúnya Omi tó ń bọ̀ ṣẹ̀sín, báwọn kan ṣe máa ń ṣẹlẹ́yà nígbà tá a bá fún wọn ní ẹ̀rí látinú Ìwé Mímọ́ pé ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí yóò pa run láìpẹ́. (2 Pétérù 3:3-12) Àmọ́, bíi ti Énọ́kù àti Nóà, àwa náà lè jẹ́ irú iṣẹ́ yẹn nítorí ìgbàgbọ́ àti ìgboyà tí Ọlọ́run fún wa.
Ìgbàgbọ́ Ń Jẹ́ Ká Ní Sùúrù
7. Báwo ni Ábúráhámù àtàwọn yòókù ṣe fi ìgbàgbọ́ àti sùúrù hàn?
7 A nílò ìgbàgbọ́ àti sùúrù, àgàgà lákòókò yìí tá à ń dúró de òpin ètò nǹkan ìsinsìnyí. Ábúráhámù, baba ńlá nì tó jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run wà lára àwọn ‘tí yóò tipasẹ̀ ìgbàgbọ́ àti sùúrù jogún àwọn ìlérí náà.’ (Hébérù 6:11, 12) Ìgbàgbọ́ ló mú kó lè fi ìlú ńlá Úrì sílẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ìgbésí ayé gbẹdẹmukẹ ibẹ̀, tó wá di àtìpó nílẹ̀ àjèjì tí Ọlọ́run ṣèlérí fún un. Ísákì àti Jékọ́bù jẹ́ ajogún ìlérí kan náà. Àmọ́, “gbogbo àwọn wọ̀nyí kú nínú ìgbàgbọ́, bí wọn kò tilẹ̀ rí ìmúṣẹ àwọn ìlérí náà gbà.” Nípa ìgbàgbọ́ ni wọ́n ‘nàgà sí ibi tí ó sàn ju, èyíinì ni, ọ̀kan tí ó jẹ́ ti ọ̀run.’ Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Ọlọ́run “ti pèsè ìlú ńlá kan sílẹ̀ fún wọn.” (Hébérù 11:8-16) Bẹ́ẹ̀ ni o, Ábúráhámù, Ísákì, àti Jékọ́bù—àti àwọn aya wọn tó jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run—fi sùúrù dúró de Ìjọba ọ̀run ti Ọlọ́run lábẹ́ èyí tí a óò jí wọn dìde sí láti gbé lórí ilẹ̀ ayé.
8. Ábúráhámù, Ísákì, àti Jékọ́bù fi sùúrù àti ìgbàgbọ́ hàn láìfi kí ni pé?
8 Ábúráhámù, Ísákì, àti Jékọ́bù kò sọ ìgbàgbọ́ wọn nù. Wọn ò rí Ilẹ̀ Ìlérí náà, wọn ò sì rí i kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé bù kún ara wọn nípasẹ̀ irú ọmọ Ábúráhámù. (Jẹ́nẹ́sísì 15:5-7; 22:15-18) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ní láti kọjá kí wọ́n tó rí ‘ìlú tí Ọlọ́run kọ́,’ síbẹ̀ àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ní ìgbàgbọ́ àti sùúrù jálẹ̀ gbogbo ìgbésí ayé wọn. Dájúdájú, àwa náà ní láti ṣe bákan náà nísinsìnyí tí Ìjọba Mèsáyà ti fìdí kalẹ̀ sókè ọ̀run.—Sáàmù 42:5, 11; 43:5.
Ìgbàgbọ́ Ń Jẹ́ Ká Ní Góńgó Tó Dára Jù Lọ Tá À Ń Lépa
9. Ipa wo ni ìgbàgbọ́ ń ní lórí àwọn góńgó tá à ń lépa?
9 Àwọn baba ńlá olóòótọ́ ìgbàanì kò bá wọn lọ́wọ́ nínú ìgbésí ayé oníwàkiwà táwọn ará Kénáánì ń gbé, nítorí pé wọ́n ní àwọn góńgó tó ga gan-an tí wọ́n ń lépa. Bákan náà ni ìgbàgbọ́ tún ń jẹ́ ká ní àwọn ohun tẹ̀mí tá à ń lépa tó máa ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún dídi apá kan ayé tó wà lábẹ́ agbára ẹni búburú nì, Sátánì Èṣù.—1 Jòhánù 2:15-17; 5:19.
10. Báwo la ṣe mọ̀ pé Jósẹ́fù lépa góńgó kan tó dára gan-an ju òkìkí ayé lọ?
10 Nípasẹ̀ ìdarí àtọ̀runwá, Jósẹ́fù ọmọ Jékọ́bù di alákòóso oúnjẹ ní ilẹ̀ Íjíbítì, àmọ́ kì í ṣe pé ó lépa àtidi ẹni ńlá nínú ayé yìí. Pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú ìmúṣẹ àwọn ìlérí tí Jèhófà ṣe, Jósẹ́fù tó jẹ́ ẹni àádọ́fà ọdún sọ fún àwọn èèyàn rẹ̀ pé: “Èmi ń kú lọ; ṣùgbọ́n, láìkùnà, Ọlọ́run yóò yí àfiyèsí rẹ̀ sí yín, dájúdájú, òun yóò mú yín gòkè kúrò ní ilẹ̀ yìí, lọ sí ilẹ̀ tí ó búra nípa rẹ̀ fún Ábúráhámù, fún Ísákì àti fún Jékọ́bù.” Jósẹ́fù ní kí wọ́n sin òkú òun sí ilẹ̀ ìlérí. Nígbà tó kú, wọ́n kun òkú rẹ̀ lọ́ṣẹ, wọ́n sì gbé e sínú pósí kan ní Íjíbítì. Àmọ́ nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì gba òmìnira kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì, wòlíì Mósè ní kí wọ́n kó àwọn egungun Jósẹ́fù dání kí wọ́n lè sin ín sí Ilẹ̀ Ìlérí. (Jẹ́nẹ́sísì 50:22-26; Ẹ́kísódù 13:19) Ó yẹ kí ìgbàgbọ́ bíi ti Jósẹ́fù sún wa láti lépa àwọn góńgó tó dára gan-an ju òkìkí ayé lọ.—1 Kọ́ríńtì 7:29-31.
11. Ọ̀nà wo ni Mósè gbà fi ẹ̀rí hàn pé òun ní àwọn góńgó tẹ̀mí tóun ń lépa?
11 Mósè ‘yàn pé kí a ṣẹ́ òun níṣẹ̀ẹ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn Ọlọ́run dípò tí ì bá fi jẹ ìgbádùn ẹ̀ṣẹ̀ fúngbà díẹ̀’ gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn tó kàwé dáadáa nínú ìdílé ọba Íjíbítì. (Hébérù 11:23-26; Ìṣe 7:20-22) Èyí jẹ́ kó pàdánù ipò ìyí tí ì bá wà nínú ayé àti pósí olówó gọbọi tí wọn ì bá fi sin ín síbi tí wọ́n máa ń sin àwọn ọlọ́lá sí nílẹ̀ Íjíbítì. Àmọ́ àǹfààní wo nìyẹn ì bá jẹ́ fún un ní ìfiwéra pẹ̀lú jíjẹ́ “ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́,” alárinà májẹ̀mú Òfin, wòlíì Jèhófà, àti òǹkọ̀wé Bíbélì? (Ẹ́sírà 3:2) Ṣé ìgbéga lẹ́nu iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ ló jẹ ọ́ lógún ni, àbí ìgbàgbọ́ ti mú kó o máa lépa àwọn góńgó tẹ̀mí tó dára gan-an jùyẹn lọ?
Ìgbàgbọ́ Ń Jẹ́ Ká Ní Ìgbésí Ayé Aláyọ̀
12. Ipa wo ni ìgbàgbọ́ ní lórí ìgbésí ayé Ráhábù?
12 Kì í ṣe pé ìgbàgbọ́ ń jẹ́ kéèyàn lépa àwọn góńgó tó dára jù lọ nìkan àmọ́ ó tún ń jẹ́ kéèyàn gbé ìgbésí ayé aláyọ̀ pẹ̀lú. Ráhábù ará Jẹ́ríkò ti ní láti rí i pé ìgbésí ayé òun gẹ́gẹ́ bí aṣẹ́wó kò nítumọ̀ rárá. Síbẹ̀, ẹ wo bí gbogbo ìyẹn ṣe yí padà nígbà tó lo ìgbàgbọ́! A “polongo [rẹ̀] ní olódodo nípa àwọn iṣẹ́ [ìgbàgbọ́], lẹ́yìn tí ó ti gba àwọn ońṣẹ́ pẹ̀lú ẹ̀mí aájò àlejò, tí ó sì rán wọn jáde gba ọ̀nà mìíràn,” tó fi jẹ́ pé àwọn ará Kénáánì tó jẹ́ ọ̀tá wọn kò rí wọn gbé ṣe. (Jákọ́bù 2:24-26) Nítorí pé Ráhábù gba Jèhófà ní Ọlọ́run tòótọ́, ó fi ìgbàgbọ́ hàn nípa pípa iṣẹ́ aṣẹ́wó tó ń ṣe tì. (Jóṣúà 2:9-11; Hébérù 11:30, 31) Ó fẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà, kò fẹ́ aláìgbàgbọ́ Ọmọ Kénáánì. (Diutarónómì 7:3, 4; 1 Kọ́ríńtì 7:39) Ráhábù ní àǹfààní ńlá ti dídi ìyá ńlá fún Mèsáyà náà. (1 Kíróníkà 2:3-15; Rúùtù 4:20-22; Mátíù 1:5, 6) Bíi tàwọn yòókù, táwọn kan lára wọn ti pa ìgbésí ayé oníwà pálapàla tí wọ́n ń gbé tì, obìnrin yìí yóò tún rí èrè mìíràn gbà—ìyẹn ni àjíǹde sínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé.
13. Báwo ni Dáfídì ṣe dẹ́ṣẹ̀ nínú ọ̀ràn Bátí-ṣébà, àmọ́ ìṣarasíhùwà wo ni Dáfídì fi hàn?
13 Lẹ́yìn tí Ráhábù pa ọ̀nà ìgbésí ayé ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tì, ó dájú pé ó tẹ̀ lé ipa ọ̀nà títọ́. Àmọ́ ṣá o, àwọn kan wà tí wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run láti ọjọ́ tó ti pẹ́ tí wọ́n dá ẹ̀ṣẹ̀ tó wúwo gan-an. Dáfídì Ọba bá Bátí-ṣébà ṣe panṣágà, ó ní kí wọ́n pa ọkọ rẹ̀ lójú ogun, ó sì fi obìnrin náà ṣaya. (2 Sámúẹ́lì 11:1-27) Dáfídì ronú pìwà dà jinlẹ̀jinlẹ̀, ó sì bẹ Jèhófà pé: “Ẹ̀mí mímọ́ rẹ ni kí o má sì gbà kúrò lára mi.” Dáfídì ò pàdánù ẹ̀mí Ọlọ́run. Ó nígbàgbọ́ pé Jèhófà, aláàánú, kò ní tẹ́ńbẹ́lú “Ọkàn-àyà tí ó ní ìròbìnújẹ́ tí ó sì wó palẹ̀” nítorí ẹ̀ṣẹ̀. (Sáàmù 51:11, 17; 103:10-14) Nítorí ìgbàgbọ́ tí Dáfídì àti Bátí-ṣébà ní, wọ́n láǹfààní láti wà lára àwọn tó jẹ́ baba ńlá àti ìyá ńlá fún Mèsáyà.—1 Kíróníkà 3:5; Mátíù 1:6, 16; Lúùkù 3:23, 31.
Ìgbàgbọ́ Tí Ìdánilójú Fún Lókun
14. Ìdánilójú wo ni Gídíónì rí gbà, báwo sì ni ìtàn yìí ṣe lè nípa lórí ìgbàgbọ́ wa?
14 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé à ń rìn nínú ìgbàgbọ́, síbẹ̀ àwọn ìgbà mìíràn wà tá a máa ń fẹ́ rí ẹ̀rí ìdánilójú pé Ọlọ́run yóò ràn wá lọ́wọ́. Bí ọ̀ràn Gídíónì Onídàájọ́ ṣe rí nìyẹn, ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó jẹ́ pé “nípasẹ̀ ìgbàgbọ́, wọ́n ṣẹ́gun àwọn ìjọba nínú ìforígbárí.” (Hébérù 11:32, 33) Nígbà táwọn ará Mídíánì àtàwọn olùgbèjà wọn gbógun ti Ísírẹ́lì, ẹ̀mí Ọlọ́run bà lé Gídíónì. Kó lè ní ìdánilójú pé Jèhófà wà pẹ̀lú òun, ó ṣe ìdánwò méjì tó ní í ṣe pẹ̀lú ìṣùpọ̀ irun àgùntàn tó tẹ́ sílẹ̀ ní ilé ìpakà ní òru mọ́jú. Nínú ìdánwò àkọ́kọ́, ìrì sẹ̀ sórí kìkì irun àgùntàn náà nìkan, nígbà tí orí gbogbo ilẹ̀ gbẹ táútáú. Àmọ́ nínú ìdánwò kejì ìrì sẹ̀ sórí ilẹ̀, irun àgùntàn sì gbẹ táútáú. Pẹ̀lú okun tí ìdánilójú wọ̀nyí fún un, Gídíónì tó wà lójúfò fi ìgbàgbọ́ gbégbèésẹ̀ ó sì ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá Ísírẹ́lì. (Àwọn Onídàájọ́ 6:33-40; 7:19-25) Tá a bá béèrè ẹ̀rí ìdánilójú nígbà tá a bá fẹ́ ṣe ìpinnu, kò túmọ̀ sí pé a ò nígbàgbọ́. Ńṣe la dìídì ń fi ìgbàgbọ́ hàn nípa yíyẹ Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde Kristẹni wò àti nípa gbígbàdúrà fún ìtọ́sọ́nà ẹ̀mí mímọ́ nígbà tá a bá ń ṣe àwọn ìpinnu.—Róòmù 8:26, 27.
15. Báwo ni ríronú lórí ìgbàgbọ́ Bárákì ṣe lè ràn wá lọ́wọ́?
15 A fún ìgbàgbọ́ Bárákì Onídàájọ́ lókun nípa fífún un ní ẹ̀rí ìdánilójú tó dà bí ìṣírí. Dèbórà tó jẹ́ wòlíì obìnrin fún un níṣìírí láti lo ìdánúṣe ní gbígba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò lọ́wọ́ ìnilára Jábínì Ọba àwọn ará Kénáánì. Nínú ìgbàgbọ́ àti pẹ̀lú ìdánilójú ìtìlẹ́yìn Ọlọ́run, Bárákì kó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá àwọn ọmọ ogun tí wọn ò fi bẹ́ẹ̀ mọ ogun jà lọ sójú ogun, ó sì ṣẹ́gun agbo ọmọ ogun Jábínì tí wọ́n pọ̀ gan-an lábẹ́ ìdarí Sísérà. Orin amúniláyọ̀ tí Dèbórà àti Bárákì kọ ni wọ́n fi ṣayẹyẹ ìṣẹ́gun yẹn. (Àwọn Onídàájọ́ 4:1–5:31) Dèbórà fún Bárákì níṣìírí láti ṣe gẹ́gẹ́ bí aṣáájú tí Ọlọ́run yàn fún Ísírẹ́lì, ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tí ó jẹ́ pé nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ “wọ́n lé ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ilẹ̀ òkèèrè sá kìjokìjo.” (Hébérù 11:34) Ríronú lórí bí Ọlọ́run ṣe bù kún Bárákì nítorí pé ó lo ìgbàgbọ́ lè sún àwa náà láti gbégbèésẹ̀ tá a bá ń lọ́ tìkọ̀ láti ṣe àwọn iṣẹ́ kan tó dà bíi pé ó ṣòro nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.
Ìgbàgbọ́ Ń Fi Kún Àlàáfíà
16. Àpẹẹrẹ àtàtà wo ni Ábúráhámù fi lélẹ̀ nínú wíwá àlàáfíà pẹ̀lú Lọ́ọ̀tì?
16 Gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ ti ń ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àwọn iṣẹ́ líle tí a yàn fún wa nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ náà ló tún ń fi kún àlàáfíà àti ìfọ̀kànbalẹ̀ wa. Ábúráhámù tó jẹ́ àgbàlagbà jẹ́ kí Lọ́ọ̀tì àbúrò rẹ̀ yan ilẹ̀ tó lọ́ràá jù lọ nígbà táwọn darandaran wọn bẹ̀rẹ̀ sí jà tó sì di dandan fún wọn láti pínyà. (Jẹ́nẹ́sísì 13:7-12) Ábúráhámù ti ní láti fi ìgbàgbọ́ gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ran òun lọ́wọ́ láti yanjú ìṣòro yìí. Dípò tí ì bá fi ire ti ara rẹ̀ ṣáájú, ó fi ẹ̀mí àlàáfíà yanjú ọ̀ràn náà. Tá a bá rí i pé a ní awuyewuye pẹ̀lú Kristẹni arákùnrin wa, ẹ jẹ́ ká fi ìgbàgbọ́ gbàdúrà ká sì máa “wá àlàáfíà,” ká máa fi ẹ̀mí ìgbatẹnirò onífẹ̀ẹ́ tí Ábúráhámù ní sọ́kàn.—1 Pétérù 3:10-12.
17. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé awuyewuye tó wáyé láàárín Pọ́ọ̀lù, Bánábà, àti Máàkù yanjú lọ́nà pẹ̀lẹ́tù?
17 Ṣàgbéyẹ̀wò bí fífi àwọn ìlànà Kristẹni sílò pẹ̀lú ìgbàgbọ́ ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ kí àlàáfíà máa pọ̀ sí i. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù fẹ́ rìnrìn àjò míṣọ́nnárì ẹlẹ́ẹ̀kejì, Bánábà fara mọ́ ohun tó sọ pé kí wọ́n lọ padà bẹ àwọn ìjọ tó wà ní Kípírọ́sì àti Éṣíà Kékeré wò. Àmọ́, Bánábà fẹ́ mú Máàkù tó jẹ́ ìbátan rẹ̀ lọ́wọ́. Pọ́ọ̀lù kọ̀ nítorí pé Máàkù ti fìgbà kan já wọn sílẹ̀ ní Panfílíà. “Ìbújáde ìbínú mímúná” wáyé, awuyewuye yìí sì jẹ́ kí wọ́n pínyà. Bánábà mú Máàkù, wọ́n forí lé Kípírọ́sì, Pọ́ọ̀lù náà mú Sílà gẹ́gẹ́ bí alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀, ó sì “la Síríà àti Sìlíṣíà já, ó ń fún àwọn ìjọ lókun.” (Ìṣe 15:36-41) Kò pẹ́ rárá tí wọ́n fi yanjú awuyewuye náà nítorí pé Máàkù wà lọ́dọ̀ Pọ́ọ̀lù ní Róòmù, àpọ́sítélì náà sì ròyìn rẹ̀ dáadáa. (Kólósè 4:10; Fílémónì 23, 24) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń ṣẹ̀wọ̀n ní Róòmù lọ́dún 65 Sànmánì Tiwa, ó sọ fún Tímótì pé: “Mú Máàkù, kí o sì mú un wá pẹ̀lú rẹ, nítorí ó wúlò fún mi fún iṣẹ́ ìránṣẹ́.” (2 Tímótì 4:11) Ó dájú pé Pọ́ọ̀lù ti ní láti fi àjọṣe àárín òun pẹ̀lú Bánábà àti Máàkù sínú àdúrà tí ó fi ìgbàgbọ́ gbà, tí èyí sì ti yọrí sí ìbàlẹ̀ ọkàn tó so pọ̀ mọ́ “àlàáfíà Ọlọ́run.”—Fílípì 4:6, 7.
18. Kí ló ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀ nínú ọ̀ràn Yúódíà àti Síńtíkè?
18 A mọ̀ pé jíjẹ́ tá a jẹ́ aláìpé máa ń mú ká “kọsẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà.” (Jákọ́bù 3:2) Ìjà wà láàárín àwọn obìnrin Kristẹni méjì kan, àwọn tí Pọ́ọ̀lù kọ̀wé nípa wọn pé: “Yúódíà ni mo gbà níyànjú, Síńtíkè ni mo sì gbà níyànjú láti ní èrò inú kan náà nínú Olúwa. . . . Máa bá a nìṣó ní ṣíṣèrànwọ́ fún àwọn obìnrin wọ̀nyí tí wọ́n ti làkàkà ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú mi nínú ìhìn rere.” (Fílípì 4:1-3) Àwọn obìnrin tó jẹ́ èèyàn Ọlọ́run yìí ti ní láti yanjú ìṣòro wọn lọ́nà pẹ̀lẹ́tù nípa títẹ̀lé ìmọ̀ràn bí irú èyí tó wà nínú Mátíù 5:23, 24. Fífi àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ sílò pẹ̀lú ìgbàgbọ́ yóò ṣe púpọ̀ láti fi kún àlàáfíà lóde òní.
Ìgbàgbọ́ Ń Mú Ká Ní Ìfaradà
19. Ipò líle koko wo ni kò ba ìgbàgbọ́ Ísákì àti Rèbékà jẹ́?
19 Ìgbàgbọ́ tún lè mú ká fara da ìpọ́njú. Bóyá ọkàn wa gbọgbẹ́ nítorí pé ẹnì kan nínú ìdílé wa ti ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run nípa fífẹ́ aya tàbí ọkọ tó jẹ́ aláìgbàgbọ́. (1 Kọ́ríńtì 7:39) Wàhálà bá Ísákì àti Rèbékà nítorí pé Ísọ̀ ọmọ wọn fi àwọn obìnrin tí kò bẹ̀rù Ọlọ́run ṣaya. Àwọn ọmọ Hétì tó fi ṣaya jẹ́ “orísun ìkorò ẹ̀mí” fún wọn—tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí Rèbékà fi sọ pé: “Mo ti wá fi tẹ̀gàntẹ̀gàn kórìíra ìgbésí ayé tèmi yìí nítorí àwọn ọmọbìnrin Hétì. Bí Jékọ́bù bá lọ mú aya nínú àwọn ọmọbìnrin Hétì bí ìwọ̀nyí nínú àwọn ọmọbìnrin ilẹ̀ yìí, ire wo ni ìgbésí ayé jẹ́ fún mi?” (Jẹ́nẹ́sísì 26:34, 35; 27:46) Síbẹ̀, ipò líle koko yìí kò ba ìgbàgbọ́ Ísákì àti Rèbékà jẹ́. Ǹjẹ́ kí àwa náà ní ìgbàgbọ́ tó lágbára bí ipò líle koko bá di èyí tó ṣòro fún wa láti kojú rẹ̀.
20. Àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ wo la rí nínú Náómì àti Rúùtù?
20 Ará Jùdíà ni Náómì arúgbó tó jẹ́ opó, ó sì mọ̀ pé àwọn obìnrin kan ní Júdà lè bí àwọn ọmọkùnrin tó máa di baba ńlá fún Mèsáyà. Nígbà tó jẹ́ pé àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ti kú láìbímọ, tí òun alára sì ti dàgbà kọjá ẹni tó lè bímọ, kò sí ẹ̀rí kankan tó fi hàn pé ìdílé rẹ̀ tún lè kópa kankan nínú wíwà lára ìlà ìdílé Mèsáyà náà. Síbẹ̀, Rúùtù aya ọmọ rẹ̀ tí òun náà jẹ́ opó di aya Bóásì arúgbó, ó bí ọmọkùnrin kan fún un, ó sì di ìyá ńlá fún Jésù, Mèsáyà náà! (Jẹ́nẹ́sísì 49:10, 33; Rúùtù 1:3-5; 4:13-22; Mátíù 1:1, 5) Ìgbàgbọ́ Náómì àti ti Rúùtù fara da ìpọ́njú ó sì mú ayọ̀ wá fún wọn. Ayọ̀ ńlá yóò jẹ́ ti àwa náà tá a bá nígbàgbọ́ nígbà ìpọ́njú.
21. Kí ni ìgbàgbọ́ ń ṣe fún wa, kí ló sì yẹ kó jẹ́ ìpinnu wa?
21 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò lè sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wa lọ́la, síbẹ̀ nípa ìgbàgbọ́ a lè kojú ìṣòro èyíkéyìí. Ìgbàgbọ́ ń sọ wa di onígboyà àti onísùúrù. Ó ń jẹ́ ká ní góńgó tó dára jù lọ àti ìgbésí ayé aláyọ̀. Ìgbàgbọ́ ń ní ipa tó dára lórí àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn ó sì ń fara da ìpọ́njú. Ǹjẹ́ kí àwa náà wà lára “irú àwọn tí ó ní ìgbàgbọ́ fún pípa ọkàn mọ́ láàyè.” (Hébérù 10:39) Nínú okun tí Jèhófà Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́ ń fúnni àti fún ògo rẹ̀, ẹ jẹ́ ká máa bá a lọ ní lílo ìgbàgbọ́ tó lágbára.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Ẹ̀rí Ìwé Mímọ́ wo ló fi hàn pé ìgbàgbọ́ lè sọ wá di onígboyà?
• Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ìgbàgbọ́ ń jẹ́ ká ní ìgbésí ayé aláyọ̀?
• Báwo ni ìgbàgbọ́ ṣe ń fi kún àlàáfíà?
• Ẹ̀rí wo ló fi hàn pé ìgbàgbọ́ ń mú kó ṣeé ṣe fún wa láti fara da ìpọ́njú?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Ìgbàgbọ́ fún Nóà àti Énọ́kù nígboyà láti kéde ìhìn Jèhófà
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Ìgbàgbọ́ bíi ti Mósè ń jẹ́ ká lépa àwọn góńgó tẹ̀mí
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ìdánilójú ìrànlọ́wọ́ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run fún ìgbàgbọ́ Bárákì, Dèbórà, àti ti Gídíónì lókun