Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Kì Í Dáhùn Àwọn Àdúrà Kan?
Inú Jèhófà Baba wa ọ̀run máa ń dùn láti gbọ́ àdúrà tá a fi òótọ́ inú gbà. Àmọ́ àwọn nǹkan kan wà tó lè má jẹ́ kó gbọ́ àwọn àdúrà wa. Kí ni àwọn nǹkan náà? Kí ló sì yẹ ká fi sọ́kàn tá a bá ń gbàdúrà? Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Bíbélì sọ lórí ọ̀rọ̀ yìí.
“Tí o bá ń gbàdúrà, má sọ ohun kan náà ní àsọtúnsọ.”—Mátíù 6:7.
Jèhófà kò fẹ́ ká máa há àwọn àdúrà tá a fẹ́ gbà sórí tàbí ká máa kà wọ́n jáde nínú ìwé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fẹ́ ká máa gbàdúrà sí òun látọkàn wá. Wo bó ṣe máa rí lára ẹ tí ọ̀rẹ́ ẹ kan bá ń lo ọ̀rọ̀ kan náà lójoojúmọ́ láti fi bá ẹ sọ̀rọ̀, ṣé kò ní sú ẹ? Àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ látọkàn wá. Tá a bá fi ọ̀rọ̀ tó ti ọkàn wá gbàdúrà sí Ọlọ́run, ìyẹn á jẹ́ ká lè sọ ohun tó ń dùn wá lọ́kàn fún Bàbá wa ọ̀run.
“Nígbà tí ẹ sì béèrè, ẹ ò rí gbà torí ohun tí kò dáa lẹ fẹ́ fi ṣe.”—Jémíìsì 4:3.
Ó dájú pé a ò ní retí pé kí Ọlọ́run dáhùn àdúrà wa tó bá jẹ́ pé ohun tá a mọ̀ pé kò fẹ́ là ń béèrè pé kó ṣe fún wa. Bí àpẹẹrẹ, tí ẹni tó ń ta tẹ́tẹ́ bá gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kóun ṣoríire, kóun sì rówó jẹ́, ṣé Jèhófà á dáhùn àdúrà yẹn? Rárá, torí Ọlọ́run ti kìlọ̀ fún wa pe ojúkòkòrò àti ìgbàgbọ́ nínú “ọlọ́run oríire” kò dára. (Àìsáyà 65:11; Lúùkù 12:15) Ẹ ò rí i pé kò bọ́gbọ́n mu ká retí pé kí Jèhófà dáhùn irú àwọn àdúrà yẹn! Kí Ọlọ́run tó lè dáhùn àdúrà wa, a gbọ́dọ̀ rí i dájú pé ohun tá a béèrè bá ohun tó sọ nínu Bíbélì mu.
“Ẹni tí kì í fetí sí òfin, àdúrà rẹ̀ pàápàá jẹ́ ohun ìríra.”—Òwe 28:9.
Ní àkókò tí wọ́n kọ Bíbélì, Ọlọ́run kì í dáhùn àdúrà àwọn tí wọ́n bá ṣàìgbọràn sí òfin òdodo rẹ̀. (Àìsáyà 1:15, 16) Èrò Ọlọ́run kò tíì yí pa dà. (Málákì 3:6) Tá a bá fẹ́ kí Ọlọ́run dáhùn àdúrà wa, a gbọ́dọ̀ máa sa gbogbo ipá wa láti tẹ̀ lé àwọn òfin rẹ̀. Àmọ́ tá a bá ti ṣe ohun tó burú sẹ́yìn ńkọ́? Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé Jèhófà kò ní gbọ́ àdúrà wa ni? Rárá o! Ọlọ́run á fìfẹ́ dárí jì wá tá a bá ronú pìwà dà tá a sì ṣàtúnṣe tó yẹ láti ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́.—Ìṣe 3:19.