Ṣé Ẹnì Kankan Tiẹ̀ Bìkítà Nípa Mi?
Ṣó ti ṣe ẹ́ rí bíi pé o dá nìkan wà, tó ò lólùrànlọ́wọ́, tó wá dà bí ẹni pé kò sẹ́nì kankan tó lóye ìṣòro tó ń bá ẹ fínra? Táwọn kan bá tiẹ̀ lóye ohun tó ń ṣe ẹ́, ó ṣe ẹ́ bíi pé wọn ò rí tìẹ rò.
NÍGBÀ tíṣòro bá dé, ìgbésí ayé wa lè dà bí ìjì tí kò ní dáwọ́ dúró. Nígbà míì, a lè parí èrò sí pé à ń jìyà láìnídìí àti pé àwọn ìṣòro wa ti mu wá lómi gan-an débi pé a ò ní lè fara dà á mọ́. Bó ṣe sábà máa ń rí nìyẹn nígbà tọ́kàn wa bá bà jẹ́, tá a sorí kọ́, tí jàǹbá tó ń sọni di aláìlágbára bá ṣẹlẹ̀ sí wa, tá à ń ṣàìsàn tí kì í lọ bọ̀rọ̀ tàbí tá a ní àwọn ìṣòro míì. Ó lè dà bíi pé a ò lólùrànlọ́wọ́, a ò sì nírètí, ká wá máa ronú pé ibo la ti lè rí ìtùnú. Ṣẹ́nì kankan tiẹ̀ bìkítà nípa wa?
“Ọlọ́run Ìtùnú Gbogbo” Bìkítà
Bíbélì sọ pé Ọlọ́run jẹ́ “Baba àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo.” (2 Kọ́ríńtì 1:3) Ọlọ́run tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà mọ̀ pé a nílò ìtùnú. Ó lé ní ọgọ́rùn-ún [100] ìgbà tí Bíbélì mẹ́nu ba “ìtùnú” lónírúurú ọ̀nà, ìyẹn sì ń fi dá wa lójú pé Ọlọ́run lóye ohun tó ń ṣe wá, ó sì ń wù ú láti tù wá nínú. Ohun tá a mọ̀ nípa Ọlọ́run yìí jẹ́ kó dá wa lójú pé bó tiẹ̀ dà bíi pé àwọn èèyàn ò lóye àwọn ìṣòro wa, tí wọn ò sì rí tiwa rò, a mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run bìkítà nípa wa.
A rí i kedere nínú Ìwé Mímọ́ pé Jèhófà bìkítà nípa wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Bíbélì sọ pé: “Ojú Jèhófà ń bẹ ní ibi gbogbo, ó ń ṣọ́ àwọn ẹni búburú àti àwọn ẹni rere.” (Òwe 15:3) Yàtọ̀ síyẹn, ìwé Jóòbù 34:21 sọ pé: “Ojú rẹ̀ ń bẹ ní àwọn ọ̀nà ènìyàn, ó sì ń rí ìṣísẹ̀ rẹ̀ gbogbo.” Jèhófà ń rí gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ wa, yálà rere tàbí búburú, ó mọ ohun tó mú ká ṣe ohun tá a ṣe, ìyẹn ló sì máa jẹ́ kó gbégbèésẹ̀ lọ́nà tó rí i pé ó tọ́. A rí èyí nínú àwọn ọ̀rọ̀ tí Hánáánì tó jẹ́ aríran tàbí wòlíì sọ fún Ásà Ọba Júdà, ó ní: “Ní ti Jèhófà, ojú rẹ̀ ń lọ káàkiri ní gbogbo ilẹ̀ ayé láti fi okun rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí ọkàn-àyà wọn pé pérépéré síhà ọ̀dọ̀ rẹ̀.”—2 Kíróníkà 16:7, 9.
Ìdí mìíràn tún wà tí Jèhófà fi ń bójú tó wa. Jésù ṣàlàyé pé: “Kò sí ènìyàn kankan tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi láìjẹ́ pé Baba, tí ó rán mi, fà á.” (Jòhánù 6:44) Jèhófà bìkítà fún wa débi pé ó máa ń wo ọkàn àyà ẹnì kọ̀ọ̀kan wa kó lè rí i bóyá ó ń wù wá láti túbọ̀ sún mọ́ òun. Tí Ọlọ́run bá rí i pé ẹnì kan fẹ́ túbọ̀ mọ òun dáadáa, ó ṣe tán láti ran irú ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ lọ́nà ìyanu. Bí àpẹẹrẹ, obìnrin kan lórílẹ̀-èdè Dominican Republic ní àrùn jẹjẹrẹ, ó sì wà nílé ìwòsàn, ó ń retí iṣẹ́ abẹ tí wọ́n fẹ́ ṣe fún un. Ó gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó jẹ́ kóun rí ìsìn tòótọ́. Kò pẹ́ sígbà náà ni ọkọ ẹ̀ mú ìwé pẹlẹbẹ kan wá fún un, àkọlé ìwé náà ni Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?a Ọkọ ẹ̀ gba ìwé náà láàárọ̀ ọjọ́ yẹn lọ́wọ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó wá wàásù fún un nílé. Obìnrin náà ka ìwé pẹlẹbẹ náà, ó sì wá mọ̀ pé ńṣe ni Ọlọ́run fi ìwé náà dáhùn àdúrà òun. Ó gbà káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa wá kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́, kò sì tó oṣù mẹ́fà lẹ́yìn ìgbà náà tó fi yara ẹ̀ sí mímọ́ sí Ọlọ́run tó sì ṣèrìbọmi.
Nínú ìwé Sáàmù tó wà nínú Bíbélì, a rí ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ tó tuni lára táwọn onísáàmù ayé ìgbàanì kan tí wọ́n jẹ́ Hébérù kọ, ọ̀kan lára wọn ni Dáfídì Ọba, ó sọ bí Jèhófà ṣe máa ń fìfẹ́ bójú tó àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Nínú ìwé Sáàmù 56:8, Dáfídì Ọba bẹ Ọlọ́run, ó ní: “Fi omijé mi sínú ìgò awọ rẹ. Wọn kò ha sí nínú ìwé rẹ?” Bí Dáfídì ṣe fi omijé wé nǹkan iyebíye tó máa ń wà nínú ìgò awọ, fi hàn pé Dáfídì lóye pé Jèhófà mọ ìyà tó ń jẹ òun, ó sì mọ ẹ̀dùn ọkàn òun. Jèhófà mọ ìrora tó dé bá Dáfídì, ó sì rántí bí ìdààmú ọkàn ṣe mú kí Dáfídì máa da omijé lójú. Lóòótọ́, Ẹlẹ́dàá wa ń bójú tó gbogbo àwọn tí wọ́n ń sapá láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀, ìyẹn àwọn tí “ọkàn-àyà wọn pé pérépéré síhà ọ̀dọ̀ rẹ̀.”
Ẹsẹ Bíbélì míì tó sọ nípa bí Ọlọ́run ṣe ń fìfẹ́ bójú tó àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ni Sáàmù kẹtàlélógún [23], ọ̀pọ̀ èèyàn ló mọ ọ̀rọ̀ inú Sáàmù yìí. Àwọn ọ̀rọ̀ tó bẹ̀rẹ̀ Sáàmù yẹn jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run dà bí olùṣọ́ àgùntàn tó ń fìfẹ́ bójú tó àwọn àgùntàn rẹ̀, ó ní: “Jèhófà ni Olùṣọ́ Àgùntàn mi. Èmi kì yóò ṣaláìní nǹkan kan.” Àwọn olùṣọ́ àgùntàn ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ayé sábà máa ń bójú tó àwọn àgùntàn wọn níkọ̀ọ̀kan, kódà wọ́n máa ń sọ wọ́n lórúkọ. Lójoojúmọ́, wọ́n máa ń pe ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn àgùntàn náà sọ́dọ̀ ara wọn, wọ́n á sì máa fọwọ́ pa wọ́n lára kí wọ́n lè mọ̀ bóyá ọgbẹ́ wà lára wọn. Tí wọ́n bá rí ọgbẹ́ èyíkéyìí lára àwọn àgùntàn náà, wọ́n á fi òróró sójú ẹ̀ kó lè tètè jinná. Tí àgùntàn kan bá ń ṣàìsàn, ó lè gba pé kí olùṣọ́ àgùntàn náà fi tipátipá foògùn sẹ́nu ẹ̀, kó sì fọwọ́ dì í mú kó má bàa dùbúlẹ̀, kó sì gbabẹ̀ kú. Àfiwé yìí bá bí Jèhófà ṣe máa ń bójú tó àwọn tó bá gbẹ́kẹ̀ lé e mu.
Àdúrà àti Àjíǹde Jẹ́ Ká Mọ̀ Pé Ọlọ́run Bìkítà
Àwọn ẹsẹ tá a ti gbé yẹ̀ wò nínú sáàmù àtàwọn míì kì í ṣe àkàgbádùn lásán. Wọ́n jẹ́ ká mọ báwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run láyé àtijọ́ ṣe sọ ẹ̀dùn ọkàn wọn fún Jèhófà pé àwọn nílò ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ àwọ́n sì fi ìmoore hàn fún ìtọ́sọ́nà àti ìbùkún Ọlọ́run. Àwọn ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ ká mọ̀ dáadáa pé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run látijọ́ nígbàgbọ́ tó lágbára pé Ọlọ́run bìkítà nípa wọn. Bó ṣe máa rí fáwa náà nìyẹn tá a bá ń ka àwọn ọ̀rọ̀ wọn tá a sì ń ṣàṣàrò lórí ohun tá a bá kà. Àǹfààní tí Jèhófà fún wa láti máa gbàdúrà sí i jẹ́ ẹ̀rí tó lágbára pé Ọlọ́run bìkítà nípa wa.
Àmọ́, nígbà míì ìṣòro kan lè mu wá lómi débi pé a ò tiẹ̀ ní mọ bá a ṣe máa gbàdúrà nípa rẹ̀. Ṣéyẹn wá túmọ̀ sí pé Jèhófà ò lè mọ ìṣòro wa ni? Ìwé Róòmù 8:26 dáhùn ìbéèrè yìí, ó ní: “Ẹ̀mí pẹ̀lú dara pọ̀ mọ́ ìrànlọ́wọ́ fún àìlera wa; nítorí ìṣòro ohun tí àwa ì bá máa gbàdúrà fún bí ó ti yẹ kí a ṣe ni àwa kò mọ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀mí tìkára rẹ̀ ń jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún wa pẹ̀lú àwọn ìkérora tí a kò sọ jáde.” Ẹsẹ Bíbélì yìí jẹ́ ká mọ̀ pé àdúrà àtọkànwá táwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan gbà látijọ́ lè bá ohun tó ń ṣe wá mu, Jèhófà, “Olùgbọ́ àdúrà” sì lè gbọ́ àdúrà yìí bíi pé àwa gan-an la gbà á.—Sáàmù 65:2.
Ìrètí tá a ní pé àwọn òkú máa jíǹde tún jẹ́ ẹ̀rí míì tó dájú tó jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa. Jésù Kristi sọ pé: “Wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn [Jésù], wọn yóò sì jáde wá.” (Jòhánù 5:28, 29) Ó bá a mu gan-an bí wọ́n ṣe tú ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n lò níhìn-ín sí “ibojì ìrántí” tí kì í kàn án ṣe “sàréè.” Ó jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run ṣì rántí ohun gbogbo nípa ìgbésí ayé ẹnì kan tó ti kú.
Rò ó wò ná, láti jí ẹnì kan dìde, Ọlọ́run ní láti mọ gbogbo nǹkan nípa onítọ̀hún, títí kan bónítọ̀hún ṣe rí, àwọn ìwà tó ní àtàwọn èyí tó jogún, Ọlọ́run sì mọ gbogbo ohun tó wà lọ́pọlọ ẹ̀! (Máàkù 10:27) Kódà lẹ́yìn ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún, Ọlọ́run ò ní gbàgbé gbogbo nǹkan nípa onítọ̀hún. (Jóòbù 14:13-15; Lúùkù 20:38) Torí náà, ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn tó ti kú ni Jèhófà Ọlọ́run rántí ohun gbogbo nípa wọn, ìyẹn sì jẹ́ ẹ̀rí tó dájú pé Ọlọ́run bìkítà nípa ẹnì kọ̀ọ̀kan wa!
Olùsẹ̀san Ni Jèhófà
Kí la gbọ́dọ̀ ṣe kí Ọlọ́run lè fìfẹ́ bójú tó wa, kó sì bìkítà fún wa? Ohun àkọ́kọ́ ni pé, a gbọ́dọ̀ fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé e, ká máa ṣègbọràn sí i, ká sì nígbàgbọ́ nínú rẹ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ ká mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì kéèyàn nígbàgbọ́ kí Ọlọ́run tó lè bójú tó o. Ó kọ̀wé pé: “Láìsí ìgbàgbọ́ kò ṣeé ṣe láti wù ú dáadáa, nítorí ẹni tí ó bá ń tọ Ọlọ́run wá gbọ́dọ̀ gbà gbọ́ pé ó ń bẹ àti pé òun ni olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a.”—Hébérù 11:6.
Kíyè sí pé ìgbàgbọ́ tínú Ọlọ́run dùn sí pín sápá méjì. Àkọ́kọ́, a gbọ́dọ̀ “gbà gbọ́ pé ó ń bẹ,” ìyẹn ni pé, ká gbà gbọ́ pé Ọlọ́run wà àti pé òun ni Alákòóso Gíga Jù Lọ tó yẹ ká máa gbọ́ tiẹ̀ ká sì máa sìn. Èkejì, a gbọ́dọ̀ gbà gbọ́ pé òun ni “olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a.” Ọ̀kan lára ohun tí ìgbàgbọ́ tòótọ́ ní nínú ni pé kéèyàn gbà pé ọ̀rọ̀ gbogbo àwọn tí wọ́n ń sapá gidigidi láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ń jẹ ẹ́ lógún, ó sì máa ń san wọ́n lẹ́san. Tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tó o sì ń kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn tí wọ́n ń ṣègbọràn sí i, ìwọ náà á lè nírú ìgbàgbọ́ tó máa jẹ́ kí Ọlọ́run san ẹ́ lẹ́san, kó sì fìfẹ́ bójú tó ẹ.
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà lónìí pé ọ̀rọ̀ wa ò jẹ Ọlọ́run lógún. Àmọ́, a ti wá rí i bí Bíbélì ṣe jẹ́ kó ṣe kedere pé Ọlọ́run bìkítà gidigidi nípa àwọn tí wọ́n fi hàn pé àwọ́n nígbàgbọ́ tòótọ́ nínú rẹ̀. Bí ìgbésí ayé nísinsìnyí tiẹ̀ kún fún ìṣòro, ìdààmú, ìjákulẹ̀ àtàwọn ohun tó ń kó ẹ̀dùn ọkàn báni, kò sídìí fún wa láti máa bẹ̀rù, torí pé Jèhófà Ọlọ́run bìkítà nípa wa. Kódà, tìfẹ́tìfẹ́ ló fi ké sí wa pé ká wá ìrànlọ́wọ́ wá sọ́dọ̀ òun. Ọ̀kan lára àwọn tó kọ Sáàmù sọ pé: “Ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀, òun fúnra rẹ̀ yóò sì gbé ọ ró. Kì yóò jẹ́ kí olódodo ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n láé.”—Sáàmù 55:22.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Àwọn Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Tó Máa Jẹ́ Kó O Nígbàgbọ́ Tó Lágbára Pé Ọlọ́run Bìkítà fún Ẹ
“Ní ti Jèhófà, ojú rẹ̀ ń lọ káàkiri ní gbogbo ilẹ̀ ayé láti fi okun rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí ọkàn-àyà wọn pé pérépéré síhà ọ̀dọ̀ rẹ̀.”—2 KÍRÓNÍKÀ 16:9
“Fi omijé mi sínú ìgò awọ rẹ. Wọn kò ha sí nínú ìwé rẹ?”—SÁÀMÙ 56:8
“Jèhófà ni Olùṣọ́ Àgùntàn mi. Èmi kì yóò ṣaláìní nǹkan kan.”—SÁÀMÙ 23:1
“Ìwọ Olùgbọ́ àdúrà, àní ọ̀dọ̀ rẹ ni àwọn ènìyàn ẹlẹ́ran ara gbogbo yóò wá.”—SÁÀMÙ 65:2
“Ìwọ yóò pè, èmi fúnra mi yóò sì dá ọ lóhùn. Ìwọ yóò ṣe àfẹ́rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.”—JÓÒBÙ 14:15
“Ẹni tí ó bá ń tọ Ọlọ́run wá gbọ́dọ̀ gbà gbọ́ pé ó ń bẹ àti pé òun ni olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a.”—HÉBÉRÙ 11:6
“Ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀, òun fúnra rẹ̀ yóò sì gbé ọ ró. Kì yóò jẹ́ kí olódodo ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n láé.”—SÁÀMÙ 55:22