Lo Igbagbọ Ti A Gbekari Otitọ
“Laisi igbagbọ ko ṣeeṣe lati wu u daradara, nitori ẹni ti o ba tọ Ọlọrun wa gbọdọ gbagbọ pe o nbẹ ati pe o di olusan ere fun awọn wọnni ti wọn nfi tọkantọkan wá a kiri.”—HEBERU 11:6, NW.
1, 2. Bawo ni a ṣe fi igbagbọ Adamu sinu idanwo, pẹlu abajade wo si ni?
IGBAGBỌ beere fun ohun pupọ ju gbigbagbọ pe Ọlọrun wà lọ. Ọkunrin akọkọ, Adamu, ko ni iyemeji nipa wiwa Jehofa Ọlọrun. Ọlọrun ti jumọsọrọpọ pẹlu Adamu, o ṣeeṣe julọ ki ó jẹ́ nipasẹ Ọmọkunrin Rẹ̀, Ọrọ naa. (Johanu 1:1-3; Kolose 1:15-17) Sibẹ, Adamu sọ ifojusọna iye ayeraye naa nù nitori pe o kuna lati ṣegbọran si Jehofa ki o si mu igbagbọ lo ninu rẹ̀.
2 Ayọ Adamu lẹhin ọla dabi eyi ti a ti fi sinu ewu nigba ti aya rẹ̀, Efa, ṣaigbọran si Jehofa. Eeṣe, ero naa gan an nipa pipadanu rẹ̀ fi igbagbọ ọkunrin akọkọ sinu idanwo! Ọlọrun ha le yanju iṣoro yii ni iru ọna kan ti o le mu ayọ ati ire alaafia Adamu wíwà titilọ daju bi? Nipa didarapọ mọ Efa ninu ẹṣẹ, Adamu fihan pe oun ni kedere ko ronu bẹẹ. O gbegbeesẹ lati yanju iṣoro naa ni ọna tirẹ, dipo fifi tọkantọkan wá itọsọna atọrunwa. Bi o ti kuna lati lo igbagbọ ninu Jehofa, Adamu mu iku wa sori araarẹ ati gbogbo awọn ọmọ rẹ̀.—Roomu 5:12.
Ki Ni Igbagbọ?
3. Bawo ni itumọ ti Bibeli fun igbagbọ ṣe yatọ si eyi ti iwe atumọ ede kan fun un?
3 Iwe atumọ ede kan tumọ igbagbọ gẹgẹ bi “igbagbọ gbọnyingbọnyin ninu ohun ti kò ní ẹ̀rí kankan.” Bi o ti wu ki o ri, dipo titi ero yẹn lẹhin, Bibeli tẹnumọ odikeji gan an. Igbagbọ ni a gbekari awọn ohun ti wọn ṣẹlẹ nitootọ, lori awọn ohun gidi, lori otitọ. Iwe mimọ wi pe: “Igbagbọ ni ifojusọna tí a mu daniloju nipa awọn ohun tí a nreti, aṣefihan tí ó hàn gbangba nipa awọn otitọ gidi bi a ko tilẹ ri wọn.” (Heberu 11:1, NW) Ẹnikan ti o ní igbagbọ ní ẹri idaniloju pe gbogbo ohun ti Ọlọrun ṣeleri ni ki a ṣaa sọ pe o ti ni imuṣẹ. Ẹri idaniloju otitọ gidi ti a ko ri naa lagbara debi pe igbagbọ ni a sọ pe o baramu pẹlu ẹri yẹn.
4. Bawo ni iwe kan ṣe ti itumọ tí Bibeli fun igbagbọ lẹhin?
4 Ninu New World Translation, ọrọ iṣe Heberu naa ʼa·manʹ ti a nlo lati ṣapejuwe okunfa ohun kan ni a ntumọ si “lo igbagbọ” nigbamiran. Gẹgẹ bi Theological Wordbook of the Old Testament ti wi, “ninu itumọ orisun ọrọ naa ni ero nipa idaniloju wà . . . ni iyatọ si awọn ero ode oni nipa igbagbọ gẹgẹ bi ohun kan ti o ṣeeṣe, ti a nireti pe o jẹ ootọ, ṣugbọn ti ko daniloju.” Itọkasi kan naa wi pe: “Ọrọ ti a fayọ naa ʼāmēn ti o tumọsi ‘lootọ’ ni a nlo niṣo ninu Majẹmu Titun gẹgẹ bi ọrọ naa amēn ti o jẹ ọrọ Yoruba [naa] ‘amin.’ Jesu lo ọrọ naa lemọlemọ (Mat. 5:18, 26, ati bẹẹ bẹẹ lọ) lati tẹnumọ idaniloju ọran kan.” Ọrọ naa ti a tumọ si “igbagbọ” ninu Iwe mimọ Kristẹni lede Giriiki tun tumọ si igbagbọ ninu ohun kan ti a fidii rẹ̀ mulẹ ṣinṣin sori ẹri tootọ tabi otitọ.
5. Bawo ni a ṣe lo ọrọ Giriiki ti a tumọ si “ifojusọna ti a mu daniloju” ni Heberu 11:1 (NW) ninu awọn iwe iṣẹ-aje igbaani, ijẹpataki wo si ni eyi ni fun awọn Kristẹni?
5 Ọrọ Giriiki naa ti a tumọ si “ifojusọna ti a mu daniloju” ni Heberu 11:1 (NW) (hy·poʹsta·sis) ni a saba maa nlo ninu iwe aṣẹ iṣẹ-aje igbaani ti a fi papirọọsi ṣe lati gbe ero ohun kan ti o mu ìní ọjọ iwaju daniloju yọ. Awọn ọmọwe akẹkọọjinlẹ Moulton ati Milligan damọran itumọ naa pe: “Igbagbọ jẹ iwe ẹri oníǹǹkan fun awọn ohun ti a nreti.” (Vocabulary of the Greek Testament) Lọna ti o han gbangba, bi ẹnikan ba ni iwe ẹri oníǹǹkan fun ohun ìní, oun le ni “ifojusọna ti a mu daniloju” pe ni ọjọ kan ireti rẹ̀ lati gba a yoo ni imuṣẹ.
6. Ki ni ijẹpataki ọrọ Giriiki naa ti a tumọ si “aṣefihan ti o han gbangba” ni Heberu 11:1 (NW)?
6 Ni Heberu 11:1, ọrọ Giriiki naa ti a tumọ si “aṣefihan ti o han gbangba” (eʹleg·khos) funni ni ero gbigbe ẹri kalẹ lati ṣaṣefihan ohun kan, ni pataki ohun kan ti o yatọ si ohun ti o farahan pe o jẹ ọran naa. Ẹri ti o ṣe pato tabi ti o lẹsẹnilẹ mu ohun ti a ko loye tẹlẹ ṣe kedere, ti o tipa bayii tako ohun ti o wulẹ farahan lati jẹ ọran naa. Nitori naa ninu Iwe mimọ lede Heberu ati Giriiki, igbagbọ lọnakọna kii ṣe “igbagbọ gbọnyingbọnyin ninu ohun kan ti kò ní ẹ̀rí kankan.” Ni idakeji ẹwẹ, igbagbọ ni a gbekari otitọ.
A Gbe e Kari Awọn Otitọ Ṣiṣekoko
7. Bawo ni Pọọlu ati Dafidi ṣe ṣapejuwe awọn wọnni ti wọn sẹ́ wiwa Ọlọrun?
7 Apọsiteli Pọọlu sọ otitọ ṣiṣekoko kan nigba ti o kọwe pe “awọn animọ alaiṣeeri” ti Ẹlẹdaa “ni a ri ni kedere lati igba iṣẹda aye wá, nitori a nfi oye awọn ohun ti a dá mọ wọn, ani agbara ayeraye ati jijẹ Ọlọrun rẹ̀, tobẹẹ ti [awọn aṣodi si otitọ] fi jẹ alairiwi.” (Roomu 1:20, NW) Bẹẹni, “awọn ọrun nsọrọ ogo Ọlọrun,” “ayé” sì “kun fun ẹda rẹ̀.” (Saamu 19:1; 104:24) Ṣugbọn ki ni bi ẹnikan ko ba muratan lati yẹ ẹri naa wo? Dafidi onisaamu wi pe: “Eniyan buburu, nipa igberaga oju rẹ̀ [“onirera ti oun jẹ,” The New English Bible], ko fẹ ṣe àfẹ́rí Ọlọrun: Ọlọrun ko si ni gbogbo ironu rẹ̀.” (Saamu 10:4; 14:1) Ni apakan, igbagbọ ni a gbekari otitọ ṣiṣekoko naa pe Ọlọrun wà.
8. Imudaniloju ati oye jijinlẹ wo ni o ti ṣeeṣe fun awọn wọnni ti wọn nlo igbagbọ lati ni?
8 Jehofa ko wulẹ walaaye nikan; oun tun ṣee gbẹkẹle, a si le gbarale awọn ileri rẹ̀. Oun ti wi pe: “Loootọ gẹgẹ bi mo ti gbèrò, bẹẹ ni yoo ri, ati gẹgẹ bi mo ti pinnu, bẹẹ ni yoo si duro.” (Aisaya 14:24; 46:9, 10) Iwọnyi kii ṣe awọn ọrọ ti ko nitumọ. Ẹri kedere wa pe ọgọrọọrun awọn asọtẹlẹ ti a kọ silẹ ninu Ọrọ Ọlọrun ti ni imuṣẹ. Pẹlu ilaloye yii, awọn wọnni ti wọn lo igbagbọ tun le moye imuṣẹ ọpọlọpọ awọn asọtẹlẹ Bibeli miiran ti nlọ lọwọ. (Efesu 1:18) Fun apẹẹrẹ, wọn nri imuṣẹ “ami” wiwanihin in Jesu, papọ pẹlu iwaasu ti ntẹsiwaju nipa Ijọba naa tí a ti fidii rẹ̀ mulẹ, ati pẹlu imugbooro ijọsin tootọ ti a sọtẹlẹ. (Matiu 24:3-14; Aisaya 2:2-4; 60:8, 22) Wọn mọ pe laipẹ awọn orilẹ-ede yoo kigbe “Alaafia ati ailewu!” ati pe ni kete lẹhin naa Ọlọrun yoo “run awọn ti npa aye run.” (1 Tẹsalonika 5:3; Iṣipaya 11:18) Iru ibukun wo ni o jẹ lati ni igbagbọ ti a gbekari awọn otitọ alasọtẹlẹ!
Eso Ti Ẹmi Mimọ
9. Ki ni ipo ibatan ti o wa laaarin igbagbọ ati ẹmi mimọ?
9 Otitọ naa lori eyi ti a gbe igbagbọ le ni a ri ninu Bibeli, eso ẹmi mimọ Ọlọrun. (2 Samuẹli 23:2; Sekaraya 7:12; Maaku 12:36) Lọna ti o ba ọgbọn mu, nigba naa, igbagbọ ko le wà laisi iṣiṣẹ ẹmi mimọ. Idi niyẹn ti Pọọlu fi le kọwe pe: “Eso ti ẹmi [ni ninu] . . . igbagbọ.” (Galatia 5:22) Ṣugbọn ọpọlọpọ ṣá otitọ atọrunwa tì, ni sisọ igbesi-aye wọn di ẹlẹgbin pẹlu ifẹ ọkan ati oju iwoye ẹran ara eyi ti nkobanujẹ ba ẹmi Ọlọrun. Nipa bayii, “igbagbọ kii ṣe ìní gbogbo eniyan,” nitori wọn ko ni ipilẹ lori eyi ti wọn yoo ti mu un dagba.—2 Tẹsalonika 3:2, NW; Galatia 5:16-21; Efesu 4:30.
10. Bawo ni diẹ lara awọn iranṣẹ Jehofa ni ijimiji ṣe fihan pe awọn nlo igbagbọ?
10 Bi o ti wu ki o ri, laaarin atirandiran atẹle Adamu, awọn kan ti lo igbagbọ. Heberu ori 11 mẹnukan Ebẹli, Enọku, Noa, Aburahamu, Sara, Isaaki, Jakọbu, Josẹfu, Mose, Rahabu, Gidioni, Baraki, Samusini, Jẹfita, Dafidi, ati Samuẹli, papọ pẹlu ọpọlọpọ awọn iranṣẹ Jehofa ti a ko darukọ ti wọn “ni ẹri ti a jẹ́ si wọn nipa igbagbọ wọn.” Ṣakiyesi ohun ti a ṣe “nipa igbagbọ.” Nipa igbagbọ ni Ebẹli “rú ẹbọ . . . si Ọlọrun” Noa si “kan ọkọ aaki.” Nipa igbagbọ Aburahamu “ṣegbọran ni jijade lọ si ibi kan ti a yan fun un lati gba bi ogun.” Ati nipa igbagbọ, Mose “kuro ni Ijibiti.”—Heberu 11:4, 7, 8, 27, 29, 39, NW.
11. Ki ni Iṣe 5:32 fihan niti awọn eniyan ti wọn nṣegbọran si Ọlọrun?
11 Ni kedere, gbogbo awọn iranṣẹ Jehofa wọnni ṣe ju wiwulẹ ni igbagbọ ninu wíwà Ọlọrun lọ. Ni lilo igbagbọ, wọn nigbọkanle ninu rẹ̀ gẹgẹ bi Ẹni naa ti o jẹ “olusan ere fun awọn wọnni ti nfi tọkantọkan wa a kiri.” (Heberu 11:6, NW) Wọn nṣe ohun ti ẹmi Ọlọrun ndari wọn lati ṣe, ni gbigbegbeesẹ lori imọ pipeye ti otitọ ti o wà larọọwọto nigba naa, bi o tilẹ jẹ pe o mọniwọn. Wo bí wọn ti yatọ si Adamu tó! Oun ko gbegbeesẹ pẹlu igbagbọ ti a gbekari otitọ tabi ni ibamu pẹlu itọsọna ẹmi mimọ. Ọlọrun nfi ẹmi rẹ̀ fun kiki awọn wọnni ti wọn bá ṣegbọran si i.—Iṣe 5:32.
12. (a) Ninu ki ni Ebẹli ni igbagbọ, bawo ni o si ṣe fi eyi han? (b) Laika igbagbọ wọn sí, ki ni awọn ẹlẹrii Jehofa ṣaaju akoko Kristẹni ko gba?
12 Laidabi baba rẹ̀, Adamu, Ebẹli olubẹru Ọlọrun ni igbagbọ. Lọna hihan gbangba o mọ nipa asọtẹlẹ akọkọ ti a tii sọ ri, lati ọdọ awọn obi rẹ̀ pe: “Emi [Jehofa Ọlọrun] yoo si fi ọta saaarin iwọ ati obinrin naa, ati saaarin iru-ọmọ rẹ ati iru-ọmọ rẹ̀: oun o fọ́ ọ ni ori, iwọ o si pa a ni gigiisẹ.” (Jẹnẹsisi 3:15) Ọlọrun tipa bayii ṣeleri lati pa iwa buburu run ati lati mu iwa ododo pada bọsipo. Bi ileri yii yoo ti ni imuṣẹ, Ebẹli ko mọ. Ṣugbọn igbagbọ rẹ̀ pe Ọlọrun ni Olusan ere fun awọn wọnni ti nfarabalẹ wa A lagbara tó lati sun un lati rú ẹbọ kan. O ṣeeṣe ki o ti ronu gidigidi si asọtẹlẹ naa ki o si gbagbọ pe titajẹ silẹ yoo pọndandan lati mu ileri naa ṣẹ ati lati gbe araye ga si ijẹpipe. Fun idi yii, ẹbọ ẹran Ebẹli tọna. Bi o ti wu ki o ri, laika igbagbọ wọn sí, Ebẹli ati awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa miiran ṣaaju akoko Kristẹni “ko ri imuṣẹ ileri naa gbà.”—Heberu 11:39, NW.
Ṣiṣe Aṣepe Igbagbọ
13. (a) Ki ni Aburahamu ati Dafidi mọ nipa imuṣẹ ileri naa? (b) Eeṣe ti a fi le sọ pe “otitọ tipasẹ Jesu Kristi wá”?
13 Ni saa kọọkan la ọpọ ọgọrun un ọdun já, Ọlọrun ṣipaya awọn afikun otitọ nipa bi ileri ‘iru-ọmọ obinrin naa’ yoo ti ni imuṣẹ. A sọ fun Aburahamu pe: “Ati ninu iru-ọmọ rẹ ni a o bukun fun gbogbo orilẹ-ede aye.” (Jẹnẹsisi 22:18) Lẹhin naa, Ọba Dafidi ni a sọ fun pe Iru ọmọ ti a ṣeleri naa yoo wá nipasẹ ìlà ọlọba rẹ̀. Ni 29 C.E., Jesu Kristi ẹni tii ṣe iru ọmọ yẹn farahan. (Saamu 89:3, 4; Matiu 1:1; 3:16, 17) Ni iyatọ si Adamu alainigbagbọ, “Adamu ikẹhin,” Jesu Kristi, jẹ awofiṣapẹẹrẹ ninu fifi igbagbọ han. (1 Kọrinti 15:45) O gbe igbesi-aye iṣẹ-isin afitọkantọkan ṣe si Jehofa o si mu ọpọlọpọ awọn asọtẹlẹ ti nsọ tẹlẹ nipa Mesaya ṣẹ. Jesu tipa bayii mu otitọ nipa Iru ọmọ ti a ṣeleri naa ṣe kedere sii o si mu awọn ohun ti Ofin Mose jẹ ojiji fun wa sinu ilẹ akoso otitọ. (Kolose 2:16, 17) A le sọ nigba naa pe “otitọ tipasẹ Jesu Kristi wá.”—Johanu 1:17.
14. Bawo ni Pọọlu ṣe fihan awọn ara Galatia pe igbagbọ ti mu iha titun mọra?
14 Nisinsinyi ti otitọ ti wá nipasẹ Jesu Kristi, ipilẹ ti a mu tobi sii wà lori eyi ti a o gbe igbagbọ ninu “ileri naa” kà. Igbagbọ ni a ti fẹsẹ rẹ̀ mulẹ sii, o ti mu iha titun mọra, gẹgẹ bi a ti le sọ pe o jẹ. Ni ọna yii Pọọlu sọ fun awọn Kristẹni ẹni ami ororo ẹlẹgbẹ rẹ̀ pe: “Iwe mimọ fi ohun gbogbo lapapọ le itọju ẹṣẹ lọwọ, ki a ba le fi ileri ti o jẹyọ lati inu igbagbọ sọdọ Jesu Kristi fun awọn wọnni ti nlo igbagbọ. Bi o ti wu ki o ri, ki igbagbọ to dé, a nṣetọju wa labẹ ofin, ni fifi wa lapapọ sinu itọju, a nwo igbagbọ ti a kádàrá pe a o ṣipaya. Nitori naa ofin ti di olùtọ́ wa ti nsinni lọ sọdọ Kristi, ki a baa le kà wa si olododo nitori igbagbọ. Ṣugbọn nisinsinyi ti igbagbọ naa ti de, awa ko sí labẹ olùtọ́ mọ. Niti tootọ, ọmọkunrin Ọlọrun ni gbogbo yin nipasẹ igbagbọ yin ninu Kristi Jesu.”—Galatia 3:22-26, NW.
15. Kiki lọna wo ni a le gbà ṣaṣepe igbagbọ?
15 Awọn ọmọ Isirẹli ti lo igbagbọ ninu awọn ibalo Ọlọrun pẹlu wọn nipasẹ majẹmu Ofin naa. Ṣugbọn nisinsinyi igbagbọ yii ni a nilati mu pọ sii. Bawo? Nipa lilo igbagbọ ninu ẹni ti a fi ami ororo yan naa Jesu nititori ẹni ti a pete Ofin naa lati ṣamọna wọn. Kiki ni ọna yẹn ni a le ṣaṣepe igbagbọ ṣaaju akoko Kristẹni. Bawo ni o ti ṣe pataki tó fun awọn Kristẹni ijimiji wọnni lati ‘tẹjumọ Jesu, Olori Aṣoju ati Alaṣepe igbagbọ wọn’! (Heberu 12:2, NW) Nitootọ, gbogbo awọn Kristẹni nilati ṣe bẹẹ.
16. Bawo ni ẹmi mimọ ṣe de ní ọna pupọ sii, eesitiṣe?
16 Loju iwoye imọ otitọ atọrunwa ti o pọ sii ati aṣepe igbagbọ ti ó yọrisi, o ha tó akoko ki ẹmi mimọ pẹlu wá lọna ti o tubọ pọ sii bi? Bẹẹni. Ni Pẹntikọsi 33 C.E., ẹmi Ọlọrun, oluranlọwọ ti a ṣeleri tí Jesu ti sọrọ nipa rẹ̀, ni a tú jade sori awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀. (Johanu 14:26; Iṣe 2:1-4) Ẹmi mimọ nṣiṣẹ nigba naa lori wọn ni ọna titun patapata kan gẹgẹ bi awọn arakunrin ẹni ami ororo Kristi. Igbagbọ wọn, eso ti ẹmi mimọ, ni a fun lokun. Eyi mura wọn silẹ fun iṣẹ takuntakun ti sisọni di ọmọ ẹhin ti o wà niwaju.—Matiu 28:19, 20.
17. (a) Bawo ni otitọ ṣe de bawo ni a si ti ṣàṣepé igbagbọ lati 1914? (b) Ẹri wo ni a ni nipa wiwa lẹnu iṣẹ ẹmi mimọ lati 1919?
17 Igbagbọ de nigba ti Jesu fi araarẹ han gẹgẹ bi Ọba Lọla ni ohun ti o ju 1,900 ọdun sẹhin. Ṣugbọn nisinsinyi ti oun ti jẹ Ọba ọrun ti njọba, ipilẹ fun igbagbọ wa—otitọ ti a ṣipaya—ti pọ sii lọna pipabambari, ni titipa bayii ṣaṣepe igbagbọ wa. Bakan naa, iṣiṣẹ ẹmi mimọ ni a ti mu pọ sii. Ẹri kedere wa fun eyi ni 1919, nigba ti ẹmi mimọ tún okun fifun awọn iranṣẹ Ọlọrun oluṣeyasimimọ kuro ninu ipo ti o sunmọ aileṣiṣẹmọ. (Esikiẹli 37:1-14; Iṣipaya 11:7-12) Ipilẹ naa ni a fi lelẹ fun paradise tẹmi nigba naa, eyi ti o di mímọ̀ sii ni awọn ẹwadun ti o tẹle e ti o si nlogo sii lati ọdun de ọdun. Ẹri titobi eyikeyii ha tun le wa fun iwalẹnu iṣẹ ẹmi mimọ Ọlọrun bi?
Eeṣe Ti A Fi Nilati Ṣayẹwo Igbagbọ Wa?
18. Bawo ni awọn amí Isirẹli ṣe yatọ si araawọn niti igbagbọ?
18 Ni kete lẹhin ti a dá awọn ọmọ Isirẹli nide kuro ninu oko ẹru ni Ijibiti, awọn ọkunrin 12 ni a ran lọ lati ṣe amí ilẹ Kenani. Bi o ti wu ki o ri, mẹwaa ninu wọn ṣe alaini igbagbọ, ni ṣiṣiyemeji agbara Jehofa lati mu ileri rẹ̀ ṣẹ lati fi ilẹ naa fun Isirẹli. A sun wọn nipa ohun ti wọn foju rí, nipa awọn ohun ti ara. Ninu awọn mejila naa, Joṣua ati Kelẹbu nikan ni wọn fihan pe wọn nrin nipa igbagbọ, kii ṣe nipa ohun ti wọn foju rí. (Fiwe 2 Kọrinti 5:7.) Fun lilo igbagbọ, awọn nikan lara awọn ọkunrin wọnni ni wọn yebọ lati wọnu Ilẹ Ileri naa.—Numeri 13:1-33; 14:35-38.
19. Bawo ni ipilẹ lori eyi ti a kọ́ igbagbọ lé ṣe jinlẹ sii lonii ju ti igbakigba ri lọ, ati sibẹ ki ni a nilati ṣe?
19 Lonii, a duro lẹnu ibode aye titun ododo ti Ọlọrun. Bi awa ba nilati wọ ọ, igbagbọ ṣe pataki. Lọna ti o funni layọ, ipilẹ otitọ naa lori eyi ti a gbe igbagbọ yẹn kà ko jinlẹ nigbakigba rí ju ti isinsinyi lọ. A ni gbogbo Ọrọ Ọlọrun, apẹẹrẹ Jesu Kristi ati ti awọn ọmọlẹhin rẹ̀ ẹni ami ororo, itilẹhin araadọta ọkẹ awọn arakunrin ati arabinrin tẹmi, ati itilẹhin ẹmi mimọ Ọlọrun ni iwọn ti ko lẹ́gbẹ́. Sibẹ o dara ki a ṣayẹwo igbagbọ wa ki a si gbe awọn igbesẹ lati mu un lokun nigba ti a ṣì le ṣe bẹẹ.
20. Awọn ibeere wo ni yoo ba a mu lati beere lọwọ araawa?
20 Iwọ le wi pe, ‘Óò, mo gbagbọ pe eyi ni otitọ.’ Ṣugbọn bawo ni igbagbọ rẹ ti lagbara tó? Beere lọwọ araarẹ: ‘Ijọba ọrun ti Jehofa ha jẹ gidi si mi gẹgẹ bi ijọba eniyan ti jẹ bi? Mo ha jẹwọ eto-ajọ Jehofa ti a le fojuri ati Ẹgbẹ Oluṣakoso rẹ̀ ti mo si nti i lẹhin bi? Pẹlu oju igbagbọ, mo ha le ri i pe awọn orilẹ-ede ni a ndari sinu ipo ikẹhin fun Amagẹdọni bi? Igbagbọ mi ha lafiwe rere pẹlu “awọsanmọ nla ti awọn ẹlẹrii” tí a mẹnukan ni Heberu ori 11 bi?’—Heberu 12:1; Iṣipaya 16:14-16.
21. Bawo ni igbagbọ ṣe sun awọn wọnni ti wọn ni in ṣiṣẹ, bawo ni a si ti ṣe bukun wọn? (Fi alaye ọrọ lati inu apoti ti o wa ni oju-iwe 13 kun un.)
21 Awọn wọnni ti wọn ni igbagbọ ti a gbekari otitọ ni a nsun sẹnu iṣẹ. Bi ẹbọ ti o ṣetẹwọgba ti Ebẹli rú, awọn ẹbọ iyin wọn ntẹ Ọlọrun lọrun. (Heberu 13:15, 16) Bi Noa, oniwaasu ododo ẹni ti o ṣegbọran si Ọlọrun, wọn lepa ọna ododo gẹgẹ bi oniwaasu Ijọba. (Heberu 11:7; 2 Peteru 2:5) Bii Aburahamu, awọn wọnni ti wọn ni igbagbọ ti a gbekari otitọ nṣegbọran si Jehofa laika airọgbọ sí ati labẹ awọn ipo ti ndanniwo julọ paapaa. (Heberu 11:17-19) Gẹgẹ bi awọn olootọ iranṣẹ Jehofa ti akoko igbaani, awọn wọnni ti wọn ni igbagbọ lonii ni a bukun fun jingbinni ti a si nbojuto lati ọdọ Baba wọn onifẹẹ ti ọrun.—Matiu 6:25-34; 1 Timoti 6:6-10.
22. Bawo ni a ṣe le fun igbagbọ lokun?
22 Bi iwọ ba jẹ iranṣẹ Jehofa ti o si ri i pe igbagbọ rẹ ko lagbara ni ọna kan, ki ni iwọ le ṣe? Mu igbagbọ rẹ lokun nipa kikẹkọọ Ọrọ Ọlọrun taapọntaapọn ki o si jẹ ki ẹnu rẹ maa tu omi otitọ ti o kun ọkan-aya rẹ jade. (Owe 18:4) Bi iwọ ko ba mu igbagbọ rẹ lokun deedee, o le di alaileramọ, alaiṣiṣẹ, tabi oku paapaa. (1 Timoti 1:19; Jakọbu 2:20, 26) Pinnu pe eyi ki yoo ṣẹlẹ si igbagbọ rẹ. Bẹ Jehofa fun iranlọwọ, ni gbigbadura pe: “Ran mi lọwọ nibi ti mo ti nilo igbagbọ!”—Maaku 9:24, NW.
Ki Ni Idahun Rẹ?
◻ Ki ni igbagbọ?
◻ Eeṣe ti igbagbọ ko fi le dá wà laisi otitọ ati ẹmi mimọ?
◻ Bawo ni Jesu Kristi ṣe di Alaṣepe igbagbọ wa?
◻ Eeṣe ti a fi nilati ṣayẹwo bi igbagbọ wa ti lagbara tó?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 13]
AWỌN WỌNNI TI WỌN NI IGBAGBỌ. . .
◻ Nsọrọ nipa Jehofa.—2 Kọrinti 4:13.
◻ Nse awọn iṣẹ bi iru wọnni ti Jesu ṣe.—Johanu 14:12.
◻ Jẹ orisun iṣiri fun awọn ẹlomiran.—Roomu 1:8, 11, 12.
◻ Ṣẹgun aye.—1 Johanu 5:5.
◻ Ko ni idi lati bẹru.—Aisaya 28:16.
◻ Wa ni oju ila fun iye ainipẹkun.—Johanu 3:16.