Ṣọ́ra fún Àìnígbàgbọ́
“Ẹ kíyè sára, ẹ̀yin ará, kí ọkàn-àyà burúkú tí ó ṣaláìní ìgbàgbọ́ má bàa dìde nínú ẹnikẹ́ni nínú yín láé nípa lílọ kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run alààyè.”—HÉBÉRÙ 3:12.
1. Òtítọ́ tí ń dáyà foni wo ni àwọn ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù sí àwọn Kristẹni, tí wọ́n jẹ́ Hébérù, pè wá sí àfiyèsí wa?
ÈRÒ tí ń dáyà foni mà lèyí o—pé àwọn kan tí wọ́n ti gbádùn ipò ìbátan ti ara ẹni pẹ̀lú Jèhófà nígbà kan rí lè mú “ọkàn-àyà burúkú” dàgbà, kí wọ́n sì ‘lọ kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run alààyè’! Ìkìlọ̀ ńlá mà lèyí jẹ́ o! Àwọn tí wọ́n ti ya ìgbésí ayé wọn sí mímọ́ fún Jèhófà lórí ìpìlẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí, kì í ṣe àwọn aláìgbàgbọ́.
2. Àwọn ìbéèrè wo ni a ní láti gbé yẹ̀ wò?
2 Báwo ni ẹnì kan tí ó wà nínú irú ipò tẹ̀mí tí a bù kún bẹ́ẹ̀ ṣe lè mú “ọkàn-àyà burúkú tí ó ṣaláìní ìgbàgbọ́” dàgbà? Àní, báwo ni ẹnì kan tí ó ti tọ́ ìfẹ́ Ọlọ́run àti inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ wò ṣe lè dìídì lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀? Ó ha sì ṣeé ṣe kí èyí ṣẹlẹ̀ sí ẹnikẹ́ni nínú wa bí? Ọ̀rọ̀-ṣeni-wọ̀ọ̀ nìwọ̀nyí, ó sì pọndandan pé kí a mọ ìdí tí a fi fún wa ní ìkìlọ̀ yìí.—1 Kọ́ríńtì 10:11.
Èé Ṣe Tí A Fi Nílò Irú Ìmọ̀ràn Lílágbára Bẹ́ẹ̀?
3. Ṣàpèjúwe àyíká ipò tí ń nípa lórí àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní nínú àti ní àgbègbè Jerúsálẹ́mù?
3 Ó jọ pé àwọn Kristẹni, tí í ṣe Hébérù, tí ó wà ní Jùdíà ní ọdún 61 Sànmánì Tiwa, ni Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà rẹ̀ sí. Òpìtàn kan sọ pé èyí jẹ́ ní àkókò kan nígbà tí “kò sí àlàáfíà tàbí ìbàlẹ̀-ọkàn fún ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ ọmọlúwàbí, tí ó sì jẹ́ aláìlábòsí, tí ń gbé ní ìlú Jerúsálẹ́mù tàbí ní ibikíbi jákèjádò gbogbo ẹkùn ìpínlẹ̀ náà.” Ó jẹ́ àkókò tí ìwà àìlófin àti ìwà ipá gbilẹ̀, èyí tí àpapọ̀ àwọn ọmọ ogun Róòmù aninilára tí wọ́n wà káàkiri, àwọn Júù Onítara Ìsìn tí wọ́n ń halẹ̀ lásán, tí wọ́n jẹ́ alátakò ìjọba Róòmù, àti ìgbòkègbodò ìwà ọ̀daràn àwọn gbéwiri tí ń lo àǹfààní àkókò rúkèrúdò náà láti gbé nǹkan oníǹkan súnná sí. Gbogbo èyí mú kí nǹkan nira fún àwọn Kristẹni, tí wọ́n làkàkà kí àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ má ṣe ta bá wọn. (1 Tímótì 2:1, 2) Lóòótọ́, nítorí àìdásí tọ̀tún tòsì wọn, àwọn kan kà wọ́n sí kò-bẹ́gbẹ́-mu, wọ́n tilẹ̀ fojú adìtẹ̀mọ́jọba wò wọ́n. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n hùwà àìtọ́ sí àwọn Kristẹni, tí wọ́n fi wọ́n ṣẹlẹ́yà, tí wọ́n sì mú kí wọ́n pàdánù dúkìá wọn.—Hébérù 10:32-34.
4. Pákáǹleke wo tí ó jẹ́ ti ìsìn ni a mú dé bá àwọn Kristẹni, tí wọ́n jẹ́ Hébérù?
4 Àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ Hébérù tún wà lábẹ́ pákáǹleke gbígbóná janjan tí ó jẹ́ ti ọ̀ràn ẹ̀sìn. Ìtara àwọn olóòótọ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù tí ó wá yọrí sí ìjọ Kristẹni tí ń gbilẹ̀ sí i lọ́nà tí ó yá kánkán, ru owú àti ìbínú àwọn Júù sókè—ní pàtàkì àwọn aṣáájú ìsìn wọn. Kò sí ohun tí wọn kò ṣe tán láti dún kùkùlajà mọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi, kí wọ́n sì ṣenúnibíni sí wọn.a (Ìṣe 6:8-14; 21:27-30; 23:12, 13; 24:1-9) Àní bí a kò tilẹ̀ ṣenúnibíni sí àwọn Kristẹni kan ní tààràtà, síbẹ̀síbẹ̀, àwọn Júù kẹ́gàn wọ́n, wọ́n sì fi wọ́n ṣẹ̀sín. Wọ́n tẹ́ńbẹ́lú ẹ̀sìn Kristẹni gẹ́gẹ́ bí ẹ̀sìn tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé, tí ògo rẹ̀ kò tó ti ẹ̀sìn àwọn Júù, ẹ̀sìn tí kò ní tẹ́ńpìlì, tí kò lálùfàá, tí kì í ṣàjọ̀dún, tí kì í ṣèrúbọ aláàtò ìsìn, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Kódà, bí ọ̀daràn tí a ti dá lẹ́bi, ni a ṣe pa Jésù, ọ̀gá wọn, pàápàá. Láti ṣe ìsìn wọn, àwọn Kristẹni ní láti ní ìgbàgbọ́, ìgboyà, àti ìfaradà.
5. Èé ṣe tí ó fi ṣe pàtàkì fún àwọn Kristẹni ní Jùdíà láti wà lójúfò nípa tẹ̀mí?
5 Ju gbogbo rẹ̀ lọ, àkókò lílekoko nínú ìtàn orílẹ̀-èdè yẹn, ni àwọn Kristẹni, tí wọ́n jẹ́ Hébérù, tí ó wà ní Jùdíà ń gbé. Ọ̀pọ̀ nǹkan tí Olúwa wọn, Jésù Kristi, sọ pé yóò sàmì sí òpin ètò àwọn Júù ti ṣẹlẹ̀. Òpin náà kò ní pẹ́ dé mọ́. Láti lè là á já, àwọn Kristẹni ní láti wà lójúfò nípa tẹ̀mí, kí wọ́n sì wà ní sẹpẹ́ láti “sá lọ sí àwọn òkè ńlá.” (Mátíù 24:6, 15, 16) Wọn yóò ha ní ìgbàgbọ́ àti okun tẹ̀mí tí wọ́n nílò láti gbé ìgbésẹ̀ kíá-mọ́sá, gẹ́gẹ́ bí Jésù ti pàṣẹ bí? Ó dà bí pé ominú ń kọ àwọn kan.
6. Kí ni àwọn Kristẹni tí ń bẹ ní Jùdíà nílò ní kánjúkánjú?
6 Ní ẹ̀wádún tí ó kẹ́yìn, kí ó tó di pé gbogbo ètò àwọn nǹkan ti àwọn Júù dojú dé, ó ṣe kedere pé pákáǹleke ńláǹlà nínú àti lóde ìjọ dé bá àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ Hébérù. Wọ́n nílò ìṣírí. Ṣùgbọ́n wọ́n tún nílò ìmọ̀ràn àti ìtọ́sọ́nà tí yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ̀ pé ọ̀nà tí ó tọ́ ni àwọn yàn àti pé ìyà àti ìfaradà wọn kì í ṣe lórí asán. Ó dùn mọ́ni pé, Pọ́ọ̀lù wá nǹkan ṣe sí ọ̀ràn náà, ó sì ràn wọ́n lọ́wọ́.
7. Èé ṣe tí ó fi yẹ kí a nífẹ̀ẹ́ sí ohun tí Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ Hébérù?
7 Ohun tí Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn Kristẹni, tí wọ́n jẹ́ Hébérù, yẹ kí ó fà wá mọ́ra gidigidi. Èé ṣe? Nítorí pé a ń gbé ní àkókò kan tí ó fara jọ tiwọn. Ojoojúmọ́ ni pákáǹleke ń dé bá wa láti ọ̀dọ̀ ayé tí Sátánì ń darí. (1 Jòhánù 5:19) Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Jésù àti ti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ nípa àwọn ọjọ́ ìkẹyìn àti “ti ìparí ètò àwọn nǹkan” ń nímùúṣẹ lójú wa kòrókòró. (Mátíù 24:3-14; 2 Tímótì 3:1-5; 2 Pétérù 3:3, 4; Ìṣípayá 6:1-8) Ju gbogbo rẹ̀ lọ, a gbọ́dọ̀ wà lójúfò nípa tẹ̀mí kí a bàa lè “kẹ́sẹ járí ní yíyèbọ́ nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí a ti yàn tẹ́lẹ̀ láti ṣẹlẹ̀.”—Lúùkù 21:36.
Ẹnì Kan Tí Ó Tóbi Ju Mósè
8. Nípa sísọ ohun tí a kọ sílẹ̀ nínú Hébérù 3:1, kí ni Pọ́ọ̀lù ń rọ àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ láti ṣe?
8 Ní mímẹ́nukan kókó pàtàkì kan, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ ronú nípa àpọ́sítélì àti àlùfáà àgbà tí àwa jẹ́wọ́—Jésù.” (Hébérù 3:1) Láti ‘ronú nípa nǹkan’ túmọ̀ sí “láti kíyè sí nǹkan fínnífínní . . . , láti lóye nǹkan délẹ̀délẹ̀, láti ronú nípa nǹkan dáradára.” (Vine’s Expository Dictionary of Old and New Testament Words) Nítorí náà, Pọ́ọ̀lù ń rọ àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ láti sapá gidigidi láti ní ìmọ̀ tòótọ́ nípa ipa tí Jésù kó nínú ìgbàgbọ́ àti ìgbàlà wọn. Ṣíṣe èyí yóò fún ìpinnu wọn láti dúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́ lókun. Kí wá ni ipa tí Jésù kó, èé sì ti ṣe tí ó fi yẹ kí a “ronú nípa” rẹ̀?
9. Èé ṣe tí Pọ́ọ̀lù fi pe Jésù ní “àpọ́sítélì” àti “àlùfáà àgbà”?
9 Pọ́ọ̀lù lo ọ̀rọ̀ náà “àpọ́sítélì” àti “àlùfáà àgbà” fún Jésù. “Àpọ́sítélì” ni ẹnì kan tí a rán jáde, níhìn-ín ó ń tọ́ka sì ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà bá aráyé sọ̀rọ̀. “Àlùfáà àgbà” ni ẹni tí àwọn ènìyàn lè tipasẹ̀ rẹ̀ bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀. Àwọn ìpèsè méjèèjì wọ̀nyí kò ṣeé fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn nínú ìjọsìn tòótọ́, Jésù sì ni ó ń ṣe méjèèjì papọ̀. Òun ni ẹni tí a rán láti ọ̀run láti kọ́ aráyé ní òtítọ́ nípa Ọlọ́run. (Jòhánù 1:18; 3:16; 14:6) Jésù tún ni ẹni náà tí a yàn gẹ́gẹ́ bí Àlùfáà Àgbà amápẹẹrẹṣẹ nínú ìṣètò fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ nínú tẹ́ńpìlì Jèhófà nípa tẹ̀mí. (Hébérù 4:14, 15; 1 Jòhánù 2:1, 2) Bí a bá mọrírì àwọn ìbùkún tí a lè rí gbà nípasẹ̀ Jésù ní tòótọ́, a óò ní ìgboyà láti dúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́, a óò sì pinnu láti ṣe bẹ́ẹ̀.
10. (a) Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe ran àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ Hébérù lọ́wọ́ láti lóye pé ẹ̀sìn Kristẹni lọ́lá ju ẹ̀sìn àwọn Júù lọ? (b) Òtítọ́ wo tí a tẹ́wọ́ gba níbi gbogbo, ni Pọ́ọ̀lù tọ́ka sí láti fìdí kókó ọ̀rọ̀ rẹ̀ múlẹ̀?
10 Láti tẹnu mọ́ ìníyelórí ìgbàgbọ́ Kristẹni, Pọ́ọ̀lù fi Jésù wé Mósè, tí àwọn Júù wò gẹ́gẹ́ bí wòlíì títóbi jù lọ láàárín àwọn baba ńlá wọn. Bí àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ Hébérù bá lè fi tọkàntọkàn lóye òtítọ́ náà pé ipò Jésù ga ju ti Mósè, kò ní sí ìdí kankan fún wọn láti kọminú nípa pé ẹ̀sìn Kristẹni lọ́la ju ẹ̀sìn àwọn Júù lọ. Pọ́ọ̀lù tọ́ka sí i pé bí a tilẹ̀ ka Mósè sí ẹni tí ó yẹ láti fa “ilé” Ọlọ́run—orílẹ̀-èdè, tàbí ìjọ, Ísírẹ́lì—lé lọ́wọ́, ẹmẹ̀wà tàbí ìránṣẹ́ olóòótọ́ lásán ni ó jẹ́. (Númérì 12:7) Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, Jésù jẹ́ Ọmọ, ọ̀gá ilé náà. (1 Kọ́ríńtì 11:3; Hébérù 3:2, 3, 5) Láti ti kókó yìí lẹ́yìn, Pọ́ọ̀lù gbé ohun tí ó jẹ́ òtítọ́ níbi gbogbo yìí kalẹ̀ pé: “Dájúdájú, olúkúlùkù ilé ni a kọ́ láti ọwọ́ ẹnì kan, ṣùgbọ́n ẹni tí ó kọ́ ohun gbogbo ni Ọlọ́run.” (Hébérù 3:4) A kì í jiyàn-an bóyá irú Ọlọ́run wà àbí kò sí, nítorí pé òun ní Olùmọ, tàbí Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo. Nígbà náà, ó bọ́gbọ́n mu pé, níwọ̀n bí Jésù ti jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run, òun gbọ́dọ̀ tóbi ju gbogbo ẹ̀dá yòókù lọ, títí kan Mósè.—Òwe 8:30; Kólósè 1:15-17.
11, 12. Kí ni Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni, tí wọ́n jẹ́ Hébérù láti dì mú “[ṣinṣin] títí dé òpin,” báwo sì ni a ṣe lè fi ìmọ̀ràn yìí sílò?
11 Lóòótọ́, àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ Hébérù, wà ní ipò tí a ṣe ojú rere ńláǹlà sí. Pọ́ọ̀lù rán wọn létí pé wọ́n jẹ́ “alábàápín ìpè ti ọ̀run,” àǹfààní kan tí wọ́n ní láti ṣìkẹ́ ju ohunkóhun mìíràn tí ètò àwọn Júù lè fi fúnni lọ. (Hébérù 3:1) Àwọn ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù ti gbọ́dọ̀ mú kí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró wọnnì kún fún ọpẹ́ pé àwọn jẹ́ ẹni tí ó lè rí ogún tuntun gbà dípò tí wọn yóò fi banú jẹ́ pé àwọn ti fi ohun tí ó jẹ mọ́ ogún ti àwọn Júù sílẹ̀. (Fílípì 3:8) Nígbà tí ó ń rọ̀ wọ́n láti di àǹfààní wọn mú, kí wọ́n má sì fọwọ́ yọ̀bọ́kẹ́ mú un, Pọ́ọ̀lù wí pé: “Kristi jẹ́ olùṣòtítọ́ gẹ́gẹ́ bí Ọmọ lórí ilé [Ọlọ́run]. Àwa jẹ́ ilé Ẹni yẹn, bí a bá di òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ wa mú ṣinṣin àti ìṣògo wa lórí ìrètí náà ní fífìdímúlẹ̀ gbọn-in títí dé òpin.”—Hébérù 3:6.
12 Bẹ́ẹ̀ ni, bí àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ Hébérù yóò bá la òpin ètò nǹkan ti àwọn Júù tí ó rọ̀ dẹ̀dẹ̀ já, wọ́n ní láti di ìrètí tí Ọlọ́run fi fún wọn mú “[ṣinṣin] títí dé òpin.” Àwa pẹ̀lú gbọ́dọ̀ ṣe ohun kan náà lónìí bí a bá fẹ́ la òpin ètò àwọn nǹkan yìí já. (Mátíù 24:13) A kò gbọ́dọ̀ fàyè gba àníyàn ìgbésí ayé, ìdágunlá àwọn ènìyàn, tàbí ìtẹ̀sí àìpé tiwa fúnra wa láti mú kí a yẹsẹ̀ nínú ìgbàgbọ́ tí a ní nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run. (Lúùkù 21:16-19) Láti rí bí a ṣe lè fún ara wa lókun, ẹ jẹ́ kí a fiyè sí àwọn ọrọ̀ mìíràn tí Pọ́ọ̀lù sọ.
“Ẹ Má Ṣe Sé Ọkàn-Àyà Yín Le
13. Ìkìlọ̀ wo ni Pọ́ọ̀lù fúnni, báwo sì ni ó ṣe lo Sáàmù 95?
13 Lẹ́yìn ríronú nípa ipò ojú rere tí àwọn Kristẹni tí í ṣe Hébérù wà, Pọ́ọ̀lù fúnni ní ìkìlọ̀ yìí: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ̀mí mímọ́ ti wí pé: ‘Lónìí, bí ẹ bá fetí sí ohùn rẹ̀, ẹ má ṣe sé ọkàn-àyà yín le bí ti àkókò fífa ìbínú kíkorò, bí ti ọjọ́ dídánniwò ní aginjù.’” (Hébérù 3:7, 8) Pọ́ọ̀lù ń fa ọ̀rọ̀ yọ láti inú Sáàmù 95, nítorí náà, ó lè sọ pé “ẹ̀mí mímọ́ . . . wí pé.”b (Sáàmù 95:7, 8; Ẹ́kísódù 17:1-7) Ọlọ́run mí sí Ìwé Mímọ́ nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀.—2 Tímótì 3:16.
14. Báwo ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe hùwà padà sí ohun tí Jèhófà ṣe fún wọn, èé sì ti ṣe?
14 Lẹ́yìn tí a ti dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ ní oko ẹrú Íjíbítì, a fún wọn ní ọlá ńlá láti wọnú ipò ìbátan onímájẹ̀mú pẹ̀lú Jèhófà. (Ẹ́kísódù 19:4, 5; 24:7, 8) Àmọ́, kàkà tí wọn yóò fi fìmoore hàn fún ohun tí Ọlọ́run ṣe fún wọn, kò pẹ́ kò jìnnà tí wọ́n fi hùwà ọ̀tẹ̀. (Númérì 13:25–14:10) Báwo ni ìyẹn ṣe lè ṣẹlẹ̀? Pọ́ọ̀lù sọ ohun tí ó fà á: sísé ọkàn-àyà wọn le. Ṣùgbọ́n báwo ni ọkàn-àyà tí ó ń gbọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ lé e lórí, ṣe wá di èyí tí a sé le? Kí sì ni a gbọ́dọ̀ ṣe láti dènà èyí?
15. (a) Báwo ni a ṣe gbọ́ ‘ohùn Ọlọ́run fúnra rẹ̀,’ nígbà àtijọ́ àti nísinsìnyí? (b) Àwọn ìbéèrè wo ni a ní láti bi ara wa nípa “ohùn Ọlọ́run”?
15 Pọ́ọ̀lù bẹ̀rẹ̀ ìkìlọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú gbólóhùn àfi náà, “bí ẹ bá fetí sí ohùn rẹ̀.” Ọlọ́run bá àwọn ènìyàn rẹ̀ sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Mósè àti àwọn wòlíì mìíràn. Lẹ́yìn náà, Jèhófà bá wọn sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi. (Hébérù 1:1, 2) Lónìí, a ní odindi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí a mí sí, Bíbélì Mímọ́. A tún ní “ẹrú olóòótọ́ àti olóye,” tí Jésù yàn láti máa pèsè “oúnjẹ” tẹ̀mí “ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.” (Mátíù 24:45-47) Nípa báyìí, Ọlọ́run ṣì ń sọ̀rọ̀. Ṣùgbọ́n a ha ń fetí sí i bí? Fún àpẹẹrẹ, báwo ni a ṣe ń hùwà padà sí ìmọ̀ràn nípa ìmúra àti ìwọṣọ tàbí eré ìnàjú àti orin tí a yàn? A ha ń “fetí sí” ohun tí a ń gbọ́, ìyẹn ni pé a ha ń fiyè sí i, tí a sì ń ṣègbọràn sí i bí? Bí a bá ní àṣà ṣíṣàwáwí tàbí kíkọ etí ikún sí ìmọ̀ràn, a ń fara wa wewu sísé ọkàn-àyà wa le.
16. Ọ̀nà wo ni ọkàn-àyà wa fi lè di èyí tí a sé le?
16 A tún lè sé ọkàn-àyà wa le bí a bá ń yẹ ohun tí a lè ṣe tàbí tí ó yẹ kí a ṣe sílẹ̀. (Jákọ́bù 4:17) Pẹ̀lú gbogbo ohun tí Jèhófà ṣe fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n kọ̀ láti lo ìgbàgbọ́, wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí Mósè, wọ́n yàn láti gba ìròyìn búburú nípa Kénáánì gbọ́, wọ́n sì kọ̀ láti wọ Ilẹ̀ Ìlérí. (Númérì 14:1-4) Nítorí èyí, Jèhófà pàṣẹ pé 40 ọdún gbáko ni wọn yóò lò nínú aginjù—àkókò tí yóò gùn tó fún àwọn aláìnígbàgbọ́ tí ń bẹ láàárín wọn láti kú dànù. Nígbà tí ọ̀ràn wọn sú Ọlọ́run, ó wí pé: “‘Nígbà gbogbo ni wọ́n ń ṣáko lọ nínú ọkàn-àyà wọn, àwọn fúnra wọn kò sì mọ àwọn ọ̀nà mi.’ Nítorí náà, mo búra nínú ìbínú mi pé, ‘Dájúdájú, wọn kì yóò wọnú ìsinmi mi.’” (Hébérù 3:9-11) A ha rí ẹ̀kọ́ kankan kọ́ nínú èyí bí?
Ẹ̀kọ́ Àríkọ́gbọ́n
17. Bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí àwọn iṣẹ́ àrà tí Jèhófà ṣe, tí wọ́n sì gbọ́ àwọn ìkéde rẹ̀, èé ṣe tí wọn kò fi nígbàgbọ́?
17 Ìran àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ó jáde kúrò ní Íjíbítì fojú ara wọn rí àwọn iṣẹ́ àrà tí Jèhófà ṣe, wọ́n sì fetí ara wọn gbọ́ àwọn ìkéde rẹ̀. Síbẹ̀, wọn kò ní ìgbàgbọ́ kankan pé Ọlọ́run yóò mú wọn wọ Ilẹ̀ Ìlérí náà láìséwu. Èé ṣe? Jèhófà wí pé: “Àwọn fúnra wọn kò . . . mọ àwọn ọ̀nà mi.” Wọ́n mọ ohun tí Jèhófà wí, wọ́n sì mọ ohun tí ó ti ṣe, ṣùgbọ́n wọn kò tí ì mú níní ìgbọ́kànlé nínú rẹ̀ àti gbígbẹ́kẹ̀lé agbára rẹ̀ láti bójú tó wọn dàgbà. Àwọn àìní ti ara wọn àti ohun tí wọ́n fẹ́, gbà wọ́n lọ́kàn tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí wọn kò fi ronú rárá nípa àwọn ọ̀nà àti ète Ọlọ́run. Àní, wọ́n kò nígbàgbọ́ nínú ìlérí rẹ̀.
18. Gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ti sọ, ìgbésẹ̀ wo ni yóò yọrí sí “ọkàn-àyà burúkú tí ó ṣaláìní ìgbàgbọ́”?
18 Àwọn ọ̀rọ̀ tí ó tẹ̀ lé e yìí tí a bá àwọn Hébérù sọ, kàn wá lọ́nà kan náà: “Ẹ kíyè sára, ẹ̀yin ará, kí ọkàn-àyà burúkú tí ó ṣaláìní ìgbàgbọ́ má bàa dìde nínú ẹnikẹ́ni nínú yín láé nípa lílọ kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run alààyè.” (Hébérù 3:12) Pọ́ọ̀lù tú iṣu ọ̀ràn náà dé ìsàlẹ̀ ìkòkò nípa títọ́ka sí i pé “ọkàn-àyà burúkú tí ó ṣaláìní ìgbàgbọ́” jẹ́ àbájáde “lílọ kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run alààyè.” Ṣáájú nínú lẹ́tà yìí, ó ti sọ nípa ‘sísú lọ’ nítorí àìláfiyèsí. (Hébérù 2:1) Ṣùgbọ́n, ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà tí a tú sí “sú lọ” túmọ̀ sí “láti takété,” ó sì tan mọ́ ọ̀rọ̀ náà “ìpẹ̀yìndà.” Ó túmọ̀ sí mímọ̀ọ́mọ̀ ṣàtakò, mímọ̀ọ́mọ̀ fà sẹ́yìn, àti mímọ̀ọ́mọ̀ yapa, tí ó ní ìtẹ́ńbẹ́lú nínú.
19. Báwo ni kíkọ̀ láti fetí sí ìmọ̀ràn ṣe lè yọrí sí àbájáde bíburú jáì? Ṣàkàwé.
19 Nítorí náà, ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n náà ni pé, bí àṣà kíkọ̀ láti “fetí sí ohùn rẹ̀” bá ti wọ̀ wá lẹ́wù, tí a kò ka ìmọ̀ràn láti ọ̀dọ̀ Jèhófà nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ẹrú olóòótọ́ àti olóye sí mọ́, kò ní pẹ́ tí ọkàn-àyà wa yóò fi sébọ́, tí yóò sì le koránkorán. Fún àpẹẹrẹ, wọléwọ̀de àwọn ẹni méjì tí kò tí ì ṣègbéyàwó lè pọ̀ jù. Bí wọn kò bá ka ọ̀ràn náà sí ńkọ́? Ìyẹn yóò ha dáàbò bò wọ́n kúrò lọ́wọ́ pípadà ṣàṣìṣe náà, àbí yóò wulẹ̀ mú kí ó túbọ̀ rọrùn fún wọn láti padà ṣe bẹ́ẹ̀? Bákan náà, nígbà tí ẹgbẹ́ ẹrú náà bá pèsè ìmọ̀ràn lórí ìjẹ́pàtàkì ṣíṣe àṣàyàn orin tí a ń gbọ́ àti eré ìnàjú tí a ń ṣe, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, a ha ń fi ìmoore tẹ́wọ́ gbà á bí, tí a sì ń ṣàtúnṣe níbi tí ó bá yẹ? Pọ́ọ̀lù rọ̀ wá ‘láti má ṣe kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀.’ (Hébérù 10:24, 25) Láìfi ìmọ̀ràn yìí pé, àwọn ìpàdé Kristẹni kò jọ àwọn kan lójú rárá. Wọ́n lè rò pé pípa àwọn ìpàdé kan jẹ tàbí kí wọ́n tilẹ̀ dìídì pa àwọn ìpàdé kan tì kì í ṣe nǹkan bàbàrà.
20. Èé ṣe tí ó fi ṣe pàtàkì pé kí a dáhùn padà lọ́nà rere sí ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́?
20 Bí a kò bá hùwà padà lọ́nà yíyẹ sí “ohùn” Jèhófà tí ó ń dún ketekete nínú Ìwé Mímọ́ àti àwọn ìtẹ̀jáde tí a gbé ka Bíbélì, láìpẹ́, a óò rí i pé a ń ‘lọ kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run alààyè.’ Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ṣíṣàìka ìmọ̀ràn sí lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan lè wá di mímọ̀ọ́mọ̀ fojú kéré ìmọ̀ràn, ṣíṣe lámèyítọ́, àti títakò ó. Bí a kò bá sì káwọ́ rẹ̀, yóò yọrí sí “ọkàn-àyà burúkú tí ó ṣaláìní ìgbàgbọ́,” kíkọ́fẹ padà láti inú irú ipò bẹ́ẹ̀ sì máa ń ṣòro gidigidi. (Fi wé Éfésù 4:19.) Jeremáyà kọ̀wé lọ́nà tí ó bá a mu wẹ́kú pé: ““Ọkàn-àyà ṣe àdàkàdekè ju ohunkóhun mìíràn lọ, ó sì ń gbékútà. Ta ni ó lè mọ̀ ọ́n?” (Jeremáyà 17:9) Nítorí ìdí yìí, Pọ́ọ̀lù rọ àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ Hébérù pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní gbígba ara yín níyànjú lẹ́nì kìíní-kejì lójoojúmọ́, níwọ̀n ìgbà tí a bá ti lè pè é ní ‘Òní,’ kí agbára ìtannijẹ ẹ̀ṣẹ̀ má bàa sọ ẹnikẹ́ni nínú yín di aláyà líle.”—Hébérù 3:13.
21. Kí ni a gba gbogbo wa níyànjú láti ṣe, ìrètí wo sì ni a ní?
21 Ẹ wo bí inú wa ti dùn tó pé Jèhófà ṣì ń bá wa sọ̀rọ̀ lónìí, nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ètò àjọ rẹ̀! A dúpẹ́ pé “ẹrú olóòótọ́ àti olóye náà” ń bá a nìṣó láti máa ràn wá lọ́wọ́ láti “di ìgbọ́kànlé tí a ní ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ mú ṣinṣin ní fífìdímúlẹ̀ gbọn-in títí dé òpin.” (Hébérù 3:14) Àkókò nìyí fún wa láti dáhùn padà sí ìfẹ́ àti ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run. Bí a ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀, a lè gbádùn àwọn ìlérí Jèhófà mìíràn tí ó jẹ́ àgbàyanu—ìyẹn ni ti ‘wíwọnú’ ìsinmi rẹ̀. (Hébérù 4:3, 10) Kókó ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù jíròrò tẹ̀ lé e pẹ̀lú àwọn Kristẹni, tí wọ́n jẹ́ Hébérù nìyẹn, òun sì ni a óò gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Josephus ròyìn pé kété lẹ́yìn ikú Fẹ́sítọ́ọ̀sì, Ananus (Ananíà) ti ẹ̀ya ìsìn àwọn Sadusí ni ó di àlùfáà àgbà. Ó mú Jákọ́bù, iyèkan Jésù, àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn mìíràn wá síwájú Sànhẹ́dírìn, ó jẹ́ kí a dájọ́ ikú fún wọn, a sì sọ wọn lókùúta.
b Ó ṣe kedere pé, Pọ́ọ̀lù fa ọ̀rọ̀ yọ láti inú Septuagint ti èdè Gíríìkì, tí ó túmọ̀ ọ̀rọ̀ Hébérù náà fún “Mẹ́ríbà” àti “Másà” gẹ́gẹ́ bí “ṣíṣaáwọ̀“ àti “dídánniwò.” Wo ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, Insight on the Scriptures, ojú ewé 350 àti 379, Ìdìpọ̀ 2 tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.
Ìwọ Ha Lè Ṣàlàyé Bí?
◻ Èé ṣe tí Pọ́ọ̀lù fi kọ irú ìmọ̀ràn lílágbára bẹ́ẹ̀ sí àwọn Kristẹni, tí wọ́n jẹ́ Hébérù?
◻ Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe ran àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ Hébérù lọ́wọ́ láti lóye pé wọ́n ní ohun kan tí ó dára ju ìgbésí ayé lábẹ́ ẹ̀sìn àwọn Júù lọ?
◻ Báwo ni ọkàn-àyà ẹnì kan ṣe ń di èyí tí a sé le?
◻ Kí ni a gbọ́dọ̀ ṣe láti yẹra fún mímú “ọkàn-àyà burúkú tí ó ṣaláìní ìgbàgbọ́” dàgbà?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ìwọ ha ń lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù, Mósè Títóbi Jù bí?