Ta Ní Ń Bẹ Lẹ́yìn Gbogbo Rẹ̀?
HENRI Mouhot, olùṣàwárí, ọmọ ilẹ̀ Faransé kan tí ó gbé ayé ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún, dé ibi yàrà ńlá kan tí ó yí tẹ́ńpìlì kan ká, bí ó ti ń ṣán ọ̀nà gba inú ẹgàn kiri ní Cambodia. Ní nǹkan bí kìlómítà kan sí ibi tí ó dúró sí, ó ń wo ilé gogoro márùn-ún ti tẹ́ńpìlì náà tí ó ga ju 60 mítà lọ lókè. Angkor Wat ni, ohun ìrántí ti ìsìn tí ó tóbi jù lọ lórí ilẹ̀ ayé. Ó ti wà fún ọ̀rúndún méje kí Mouhot tó ṣàwárí rẹ̀.
Mouhot lè sọ lójú ẹsẹ̀ pé ilé tí èpò eléwé wẹẹrẹ ti bò yìí jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ ènìyàn. Ó kọ̀wé pé: “Àwọn ẹ̀dá tí ó ní òye iṣẹ́ ìkọ́lé bí ti Michelangelo ni ó kọ́ ọ, ó sì tóbi ju ohunkóhun mìíràn tí àwọn ará Gíríìsì tàbí Róòmù fi sílẹ̀ fún wa lọ.” Láìka pé a ti pa á tì fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sí, kò ṣiyèméjì pé oníṣẹ́ ọnà kan ni ó ṣe ilé àwòyanu yìí.
Ó dùn mọ́ni pé, ìwé ọgbọ́n kan tí a kọ ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn lo irú èrò bẹ́ẹ̀ láti ṣàlàyé ìdí tí ayé tí ó yí wa ká fi gbọ́dọ̀ jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ Oníṣẹ́ Ọnà kan. Ó gbọ́dọ̀ jẹ́ pé kíkọ́ ni a kọ́ ọ. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Dájúdájú, olúkúlùkù ilé ni a kọ́ láti ọwọ́ ẹnì kan, ṣùgbọ́n ẹni tí ó kọ́ ohun gbogbo ni Ọlọ́run.” (Hébérù 3:4) Àwọn kan lè má fara mọ́ àlàyé yìí, wọ́n lè sọ pé: ‘Ọ̀nà ìgbàṣiṣẹ́ ohun ìṣẹ̀dá yàtọ̀ sí ohun tí ènìyàn ṣe.’ Ṣùgbọ́n, kì í ṣe gbogbo àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ni ó fara mọ́ èrò tí ó yàtọ̀ yìí. Michael Behe, ọ̀jọ̀gbọ́n amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ nínú ìmọ̀ ìṣesí èròjà oníkẹ́míkà inú ohun alààyè ní Yunifásítì Lehigh, lẹ́yìn tí ó ti gbà pé “èròjà oníkẹ́míkà inú ohun alààyè jẹ́ ẹ̀dá abẹ̀mí,” ó béèrè pé: “Ó ha ṣeé ṣe láti fi òye ṣẹ̀dá àwọn èròjà oníkẹ́míkà inú ohun alààyè bí?” Ó ń bá a nìṣó láti fi hàn pé àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti bẹ̀rẹ̀ sí wéwèé àtiṣe àwọn ìyípadà pàtàkì sí àwọn ohun alààyè nípa lílo irú àwọn ọ̀nà bí ìlànà ìyípadà èròjà apilẹ̀ àbùdá. Ó ṣe kedere pé, gbogbo ohun abẹ̀mí àti ohun aláìlẹ́mìí ni a lè dá, kí a sì yí padà! Ní ṣíṣàyẹ̀wò ayé àwọn ohun alààyè tín-tìn-tín ti àwọn sẹ́ẹ̀lì abẹ̀mí, Behe jíròrò àwọn ètò àgbàyanu dídíjú, tí ó ní onírúurú apá tí ọ̀kan gbára lé èkejì rẹ̀ láti lè ṣiṣẹ́. Kí ni ìparí èrò rẹ̀? “Àbájáde àwọn ìsapá tí a tò jọ pelemọ láti ṣèwádìí nípa sẹ́ẹ̀lì—láti wádìí ìwàláàyè ní ìpele ti molecule—jẹ́ ẹ̀rí kedere, tí ń wọni lára pé ó jẹ́ ‘ìgbékalẹ̀ àmọ̀ọ́mọ̀ṣe!”
Bákan náà, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa àgbáálá ayé àti onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ohun àdánidá ti wo ayé àti àgbáálá ayé láwòfín, wọ́n sì ti mú àwọn kókó tí ń múni ṣe háà jáde. Fún àpẹẹrẹ, wọ́n ti wá mọ̀ nísinsìnyí pé bí ìyàtọ̀ ṣíún pàápàá bá wà nínú èyíkéyìí lára iye àwọn nọ́ńbà tí kì í yí padà ní àgbáálá ayé, kò ní ku ohun abẹ̀mí kankan mọ́ ní àgbáálá ayé.a Onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa àgbáálá ayé, Brandon Carter, pe àwọn kókó bẹ́ẹ̀ ní àwọn ìṣekòńgẹ́ yíyanilẹ́nu. Ṣùgbọ́n bí o bá ṣalábàápàdé ọ̀wọ́ àwọn ìṣekòńgẹ́, tí ó jẹ́ àdììtú tí ó wọnú ara wọn, ìwọ kò ha ní fura pé ẹnì kan ń bẹ lẹ́yìn wọn bí?
Ní tòótọ́, Olùṣàgbékalẹ̀ kan ni ó ṣe àwọn ìgbékalẹ̀ dídíjú àti “àwọn ìṣekòńgẹ́” wọ̀nyí tí a mú wà ní àyè yíyẹ wẹ́kú. Ta ni ẹni náà? Ọ̀jọ̀gbọ́n Behe sọ pé: “Lílo ọgbọ́n tí ó bá ìlànà sáyẹ́ǹsì mu láti dá olùṣàgbékalẹ̀ náà mọ̀ lè ṣòro gan-an,” ó sì fi ìbéèrè náà sílẹ̀ fún “àbá èrò orí àti ẹ̀kọ́ ìsìn” láti gbìyànjú láti dáhùn rẹ̀. Ìwọ fúnra rẹ lè rò pé ìbéèrè náà kò já mọ́ nǹkan kan fún ọ. Ṣùgbọ́n, bí o bá rí ẹ̀bùn tí a fi nǹkan pọ́n dáradára, tí ó sì ní ohun tí o nílò gan-an nínú, o kò ha ní fẹ́ mọ ẹni tí ó fi ṣọwọ́ sí ọ bí?
Lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, a ti rí irú ẹ̀bùn bẹ́ẹ̀ gbà—ẹ̀bùn kan tí ó kún fún àwọn nǹkan àgbàyanu tí ó mú kí a lè wà láàyè, kí a sì gbádùn ìgbésí ayé. Ẹ̀bùn náà ni ilẹ̀ ayé, pẹ̀lú gbogbo ìgbékalẹ̀ pípabanbarì tí ó ní fún mímú kí ìwàláàyè máa bá a nìṣó. Kò ha yẹ kí a fẹ́ mọ ẹni tí ó fún wa ní àwọn ẹ̀bùn wọ̀nyí bí?
Ó dùn mọ́ni pé, Ẹni tí ó fi ẹ̀bùn náà ránṣẹ́ lẹ ìwé kan mọ́ ọn. “Ìwé” náà ni ìwé àtayébáyé kan tí ó kún fún ọgbọ́n, tí a ti ṣàyọlò ṣáájú—Bíbélì. Nínú àwọn ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bíbélì dáhùn ìbéèrè nípa ẹni tí ó fún wa ní ẹ̀bùn náà lọ́nà tí ó rọrùn gidigidi, tí ó sì ṣe kedere pé: “Ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀, Ọlọ́run dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.”—Jẹ́nẹ́sísì 1:1.
Nínú “ìwé” rẹ̀, Ẹlẹ́dàá náà dárúkọ ara rẹ̀: “Èyí ni ohun tí Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́, wí, Ẹlẹ́dàá ọ̀run . . . , Ẹni tí ó tẹ́ ilẹ̀ ayé àti èso rẹ̀, Ẹni tí ó fi èémí fún àwọn ènìyàn tí ń bẹ lórí rẹ̀.” (Aísáyà 42:5) Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run tí ó gbé àgbáálá ayé kalẹ̀, tí ó sì ṣe ọkùnrin àti obìnrin tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé. Ṣùgbọ́n, ta ni Jèhófà? Irú Ọlọ́run wo ni ó jẹ́? Èé sì ti ṣe tí ó fi yẹ kí àwọn ènìyàn orí ilẹ̀ ayé fetí sí i?
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a “Àwọn nọ́ńbà tí kì í yí padà” ni àwọn iye tí ó máa ń dàbí pé kì í yí padà jákèjádò àgbáálá ayé. Àpẹẹrẹ méjì ni ìkọmànà ìmọ́lẹ̀ àti ìbátan tí ó wà láàárín òòfàmọ́lẹ̀ àti ìṣùjọ.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]
Àwọn ènìyàn ni ó kọ́ Angkor Wat
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Nígbà tí o bá rí ẹ̀bùn kan gbà, o kò ha ní fẹ́ mọ ẹni tí ó fi ṣọwọ́ sí ọ bí?