Ẹ Máa Bá a Lọ Ní Fífẹsẹ̀múlẹ̀ Ṣinṣin Bí Ẹni Tí Ń rí Ẹni Tí a Kò Lè rí!
“[Mósè] ń bá a lọ ní fífẹsẹ̀múlẹ̀ ṣinṣin bí ẹni tí ń rí Ẹni tí a kò lè rí.”—HÉBÉRÙ 11:27.
1. Kí ni gbólóhùn gbígbàfiyèsí tí Jésù sọ nípa Ọlọ́run nínú Ìwàásù rẹ̀ lórí Òkè?
ỌLỌ́RUN tí a kò lè rí ni Jèhófà. Nígbà tí Mósè sọ pé òun fẹ́ rí ògo Jèhófà, Ó dá a lóhùn pé: “Ìwọ kò lè rí ojú mi, nítorí pé kò sí ènìyàn tí ó lè rí mi kí ó sì wà láàyè síbẹ̀.” (Ẹ́kísódù 33:20) Àpọ́sítélì Jòhánù sì kọ̀wé pé: “Kò sí ènìyàn kankan tí ó ti rí Ọlọ́run nígbà kankan rí.” (Jòhánù 1:18) Nígbà tí Jésù Kristi jẹ́ ẹ̀dá ènìyàn lórí ilẹ̀ ayé, òun pàápàá kò lè rí Ọlọ́run. Àmọ́ nínú Ìwàásù Jésù lórí Òkè, ó sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn ẹni mímọ́ gaara ní ọkàn-àyà, níwọ̀n bí wọn yóò ti rí Ọlọ́run.” (Mátíù 5:8) Kí ni Jésù ní lọ́kàn?
2. Èé ṣe tí a kò lè fi ojúyòójú rí Ọlọ́run?
2 Ìwé Mímọ́ sọ pé Ẹ̀mí tí a kò lè rí ni Jèhófà. (Jòhánù 4:24; Kólósè 1:15; 1 Tímótì 1:17) Fún ìdí yìí, Jésù kò sọ pé àwa ẹ̀dá ènìyàn lè fi ojúyòójú rí Jèhófà. Òótọ́ ni pé àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró yóò rí Jèhófà Ọlọ́run ní ọ̀run lẹ́yìn táa bá jí wọn dìde gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí. Ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀dá ènìyàn tí wọ́n jẹ́ “ẹni mímọ́ gaara ní ọkàn-àyà,” tí wọ́n sì ní ìrètí wíwà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé lè “rí” Ọlọ́run pẹ̀lú. Báwo ni èyí ṣe lè ṣeé ṣe?
3. Báwo làwọn èèyàn ṣe lè mòye àwọn kan lára ànímọ́ Ọlọ́run?
3 A lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ nípa Jèhófà báa bá fara balẹ̀ kíyè sí àwọn ohun tó dá. Èyí lè jẹ́ kí agbára rẹ̀ wú wa lórí, ká sì wá gbà pé òun ni Ọlọ́run Ẹlẹ́dàá. (Hébérù 11:3; Ìṣípayá 4:11) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mẹ́nu ba kókó yìí nígbà tó kọ̀wé pé: “Àwọn ànímọ́ [Ọlọ́run] tí a kò lè rí ni a rí ní kedere láti ìgbà ìṣẹ̀dá ayé síwájú, nítorí a ń fi òye mọ̀ wọ́n nípasẹ̀ àwọn ohun tí ó dá, àní agbára ayérayé àti jíjẹ́ Ọlọ́run rẹ̀.” (Róòmù 1:20) Nítorí náà, ọ̀rọ̀ Jésù nípa rírí Ọlọ́run wé mọ́ mímòye àwọn kan lára àwọn ànímọ́ rẹ̀. Ìmọ̀ pípéye là ń gbé irú rírí bẹ́ẹ̀ kà, ‘ojú inú’ sì ni a fi ń mòye rẹ̀ nípa tẹ̀mí. (Éfésù 1:18) Ọ̀rọ̀ àti ìṣe Jésù tún jẹ́ ká mọ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa Ọlọ́run. Ìdí nìyẹn tí Jésù fi sọ pé: “Ẹni tí ó ti rí mi ti rí Baba pẹ̀lú.” (Jòhánù 14:9) Jésù gbé ànímọ́ Jèhófà yọ lọ́nà pípé. Fún ìdí yìí, ìmọ̀ nípa ìgbésí ayé àtàwọn ẹ̀kọ́ Jésù lè jẹ́ ká rí àwọn kan lára ànímọ́ Ọlọ́run tàbí ká mòye wọn.
Mímọyì Nǹkan Tẹ̀mí Ṣe Pàtàkì
4. Báwo ló ṣe hàn gbangba pé ọ̀pọ̀ èèyàn kò náání nǹkan tẹ̀mí lónìí?
4 Lónìí, ìgbàgbọ́ àti ojúlówó ìfẹ́ fún nǹkan tẹ̀mí ṣọ̀wọ́n. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ìgbàgbọ́ kì í ṣe ohun ìní gbogbo ènìyàn.” (2 Tẹsalóníkà 3:2) Ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́ pé tara wọn nìkan ni wọ́n ń dù lójú méjèèjì, wọn ò sì gba Ọlọ́run gbọ́ rárá. Ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọn àti àìnáání nǹkan tẹ̀mí kò lè jẹ́ kí wọ́n fi ojú inú wọn rí i, nítorí àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Ẹni tí ó bá ń ṣe búburú kò tíì rí Ọlọ́run.” (3 Jòhánù 11) Nítorí pé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kò lè fi ojúyòójú rí Ọlọ́run, wọ́n ń hùwà bíi pé kò rí ohun tí wọ́n ń ṣe. (Ìsíkíẹ́lì 9:9) Wọ́n ń fojú tín-ínrín àwọn nǹkan tẹ̀mí, ìyẹn ni wọn kò fi lè ní “ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an.” (Òwe 2:5) Abájọ tí Pọ́ọ̀lù fi kọ̀wé pé: “Ènìyàn ti ara kì í gba àwọn nǹkan ti ẹ̀mí Ọlọ́run, nítorí ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ ni wọ́n jẹ́ lójú rẹ̀; kò sì lè mọ̀ wọ́n, nítorí nípa ti ẹ̀mí ni a ń wádìí wọn wò.”—1 Kọ́ríńtì 2:14.
5. Kókó wo ni àwọn tí nǹkan tẹ̀mí jẹ lógún máa ń rántí?
5 Àmọ́, bí nǹkan tẹ̀mí bá jẹ wá lógún, ìgbà gbogbo la óò máa rántí pé bí Jèhófà kì í tilẹ̀ẹ́ ṣe Ọlọ́run tí ń wá ẹ̀sùn síni lẹ́sẹ̀, ó mọ ìgbà tí èrò búburú àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ bá sún wa ṣe nǹkan. Àní “àwọn ọ̀nà ènìyàn ń bẹ ní iwájú Jèhófà, ó sì ń ṣàgbéyẹ̀wò gbogbo òpó ọ̀nà rẹ̀.” (Òwe 5:21) Bí ẹ̀ṣẹ̀ bá ṣèèṣì lé wa bá, a ó tètè ronú pìwà dà, a ó sì tọrọ àforíjì lọ́wọ́ Jèhófà nítorí pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, a ò sì fẹ́ ṣe nǹkan tó máa dùn ún.—Sáàmù 78:41; 130:3.
Kí Làwọn Nǹkan Tó Ń Jẹ́ Ká Fẹsẹ̀ Múlẹ̀ Ṣinṣin?
6. Kí ló túmọ̀ sí láti fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin?
6 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò lè fojú rí Jèhófà, ẹ jẹ́ ká máa rántí nígbà gbogbo pé ó ń rí wa. Mímọ̀ pé ó wà àti ìdánilójú pé ó ń bẹ nítòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é yóò jẹ́ ká fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin—àní a óò dúró sán-ún láìyẹsẹ̀ nínú ìṣòtítọ́ wa sí i. (Sáàmù 145:18) A lè dà bíi Mósè, tí Pọ́ọ̀lù kọ̀wé nípa rẹ̀ pé: “Nípa ìgbàgbọ́ ni ó fi Íjíbítì sílẹ̀, ṣùgbọ́n tí kò bẹ̀rù ìbínú ọba, nítorí tí ó ń bá a lọ ní fífẹsẹ̀múlẹ̀ ṣinṣin bí ẹni tí ń rí Ẹni tí a kò lè rí.”—Hébérù 11:27.
7, 8. Kí nìdí tí Mósè fi ní ìgboyà níwájú Fáráò?
7 Nígbà tí Mósè ń ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run rán an láti kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní ìgbèkùn Íjíbítì, ọ̀pọ̀ ìgbà ló fara hàn níwájú Fáráò òṣìkà nínú ààfin títóbi lọ́lá tó kún fáwọn èèyàn jàǹkànjàǹkàn nínú ọ̀ràn ẹ̀sìn àti ọ̀ràn ológun. Ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n to àwọn òòṣà sára ògiri ààfin ọ̀hún. Ṣùgbọ́n bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà kò ṣeé fojú rí, ó jẹ́ ẹni gidi lójú Mósè, ó yàtọ̀ pátápátá sí gbogbo òòṣà tí ń ṣojú fún àwọn ọlọ́run aláìlẹ́mìí ilẹ̀ Íjíbítì. Abájọ tí ẹ̀rù Fáráò ò fi ba Mósè!
8 Kí ló fún Mósè ní ìgboyà láti fara hàn léraléra níwájú Fáráò? Ìwé Mímọ́ sọ fún wa pé “ọkùnrin náà Mósè sì fi gbọ̀ọ̀rọ̀-gbọọrọ jẹ́ ọlọ́kàn tútù jù lọ nínú gbogbo ènìyàn tí ó wà ní orí ilẹ̀.” (Númérì 12:3) Dájúdájú, ìdúró dáadáa Mósè nípa tẹ̀mí àti ìdánilójú náà pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀ fún un lókun tó nílò láti ṣojú “Ẹni tí a kò lè rí” níwájú ọba Íjíbítì tó jẹ́ òǹrorò. Kí ni díẹ̀ lára ọ̀nà táwọn tó ń “rí” Ọlọ́run tí a kò lè rí gbà ń fi hàn pé àwọn gbà á gbọ́ lónìí?
9. Kí ni ọ̀kan lára ọ̀nà táa fi lè máa bá a lọ ní fífẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin?
9 Ọ̀nà kan táa lè gbà fi hàn pé a ní ìgbàgbọ́, kí a sì máa bá a lọ ní fífẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin bí ẹni tí ń rí Ẹni tí a kò lè rí ni fífi tìgboyà-tìgboyà wàásù láìfi inúnibíni pè. Jésù kìlọ̀ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ ó sì jẹ́ ẹni ìkórìíra lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí orúkọ mi.” (Lúùkù 21:17) Ó tún sọ fún wọn pé: “Ẹrú kò tóbi ju ọ̀gá rẹ̀ lọ. Bí wọ́n bá ti ṣe inúnibíni sí mi, wọn yóò ṣe inúnibíni sí yín pẹ̀lú.” (Jòhánù 15:20) Bí Jésù ti sọ ọ́ gẹ́lẹ́ lọ̀ràn náà rí, nítorí pé kété lẹ́yìn ikú rẹ̀ ni inúnibíni dé sáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí halẹ̀ mọ́ wọn, wọ́n ń mú wọn, wọ́n sì ń lù wọ́n. (Ìṣe 4:1-3, 18-21; 5:17, 18, 40) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inúnibíni wà lọ́tùn-ún lósì, àwọn àpọ́sítélì Jésù àtàwọn ọmọlẹ́yìn yòókù ń wàásù ìhìn rere náà nìṣó láìṣojo.—Ìṣe 4:29-31.
10. Báwo ni ìgbọ́kànlé táa ní pé ààbò Jèhófà ń bẹ́ lórí wa ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà?
10 Bíi ti Mósè, ọ̀pọ̀ ọ̀tá tó yí àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ìjímìjí ká kò dẹ́rù bà wọ́n. Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, àti fún ìdí yìí, wọ́n lè fara da inúnibíni mímúná tí wọ́n dojú kọ. Àní sẹ́, wọ́n ń bá a lọ ní fífẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin bí ẹni tí ń rí Ẹni tí a kò lè rí. Lónìí, rírí tí à ń rí i nígbà gbogbo pé ààbò Jèhófà wà lórí wa ń fún wa ní ìgboyà, ìyẹn lẹ̀rù ò fi bà wá, tá ò sì ṣojo rárá, báa ṣe ń wàásù Ìjọba náà. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé “wíwárìrì nítorí ènìyàn ni ohun tí ń dẹ ìdẹkùn, ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ni a óò dáàbò bò.” (Òwe 29:25) Fún ìdí yìí, a kì í fà sẹ́yìn nítorí ìbẹ̀rù inúnibíni; bẹ́ẹ̀ ni ojú kì í tì wá nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Ìgbàgbọ́ wa ń sún wa láti fìgboyà jẹ́rìí fáwọn aládùúgbò wa, àwọn táa jọ ń ṣiṣẹ́, àwọn ọmọ iléèwé wa, àtàwọn ẹlòmíì.—Róòmù 1:14-16.
Ẹni Náà Tí A Kò Lè Rí Ló Ń Darí Àwọn Èèyàn Rẹ̀
11. Gẹ́gẹ́ bí Pétérù àti Júúdà ti wí, báwo làwọn kan tí ń bẹ nínú ìjọ Kristẹni ṣe fi hàn pé nǹkan tẹ̀mí ò jọ àwọn lójú?
11 Ìgbàgbọ́ ń jẹ́ kí a rí i pé Jèhófà lẹni tí ń darí ètò àjọ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé. Ìyẹn á sì jẹ́ ká yẹra fún ṣíṣe àríwísí àwọn tí ẹrù iṣẹ́ já lé léjìká nínú ìjọ. Àpọ́sítélì Pétérù àti Júúdà iyèkan Jésù ṣe kìlọ̀kìlọ̀ nípa àwọn kan tí nǹkan tẹ̀mí kò jọ lójú rárá débi pé wọ́n ń sọ ìsọkúsọ sáwọn tí ń mú ipò iwájú láàárín àwọn Kristẹni. (2 Pétérù 2:9-12; Júúdà 8) Ṣé irú àwọn alárìíwísí bẹ́ẹ̀ á jẹ́ sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ níwájú Jèhófà, ká ní wọ́n rí i ní ojúkorojú? Wọn ò tó bẹ́ẹ̀! Àmọ́ nítorí pé a kò lè rí Ọlọ́run, àwọn ẹni ti ara wọ̀nyí ti gbàgbé pé àwọn ṣì máa jíhìn fún un.
12. Ojú wo ló yẹ ká máa fi wo àwọn tí ń mú ipò iwájú nínú ìjọ?
12 A ò kúkú jiyàn pé kì í ṣe àwọn ẹ̀dá aláìpé ló kún inú ìjọ Kristẹni. Àwọn tí ń sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà ń ṣe àwọn àṣìṣe tó lè kan àwa alára nígbà míì. Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ni Jèhófà ń lò gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn agbo rẹ̀. (1 Pétérù 5:1, 2) Àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí nǹkan tẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn mọ̀ pé ọ̀kan lára ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń darí àwọn èèyàn rẹ̀ nìyí. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé, gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, a máa ń yẹra fún ẹ̀mí àríwísí àti ẹ̀mí ìráhùn, a sì ń bọ̀wọ̀ fún ìṣètò tí Ọlọ́run ṣe fún dídarí àwọn èèyàn rẹ̀. Nípa ṣíṣègbọràn sáwọn tí ń mú ipò iwájú láàárín wa, a ń fi hàn pé a ń rí Ẹni tí a kò lè rí.—Hébérù 13:17.
Rírí Ọlọ́run Gẹ́gẹ́ bí Olùkọ́ni Wa Atóbilọ́lá
13, 14. Kí ni rírí Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Olùkọ́ni Atóbilọ́lá túmọ̀ sí fún ọ?
13 Ìhà mìíràn wà tó tún ń béèrè fún fífi ojú tẹ̀mí wo nǹkan. Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ojú rẹ yóò sì di ojú tí ń rí Olùkọ́ni rẹ Atóbilọ́lá.” (Aísáyà 30:20) Ó gba ìgbàgbọ́ láti lè tẹ́wọ́ gba òtítọ́ náà pé Jèhófà lẹni tó ń tipasẹ̀ ètò àjọ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́. (Mátíù 24:45-47) Rírí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Olùkọ́ni wa Atóbilọ́lá kò mọ sórí níní ètò ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó jíire àti lílọ sáwọn ìpàdé Kristẹni déédéé. Ó túmọ̀ sí lílo gbogbo ètò tẹ̀mí tí Ọlọ́run ti ṣe fún àǹfààní wa. Fún àpẹẹrẹ, ó pọndandan ká pe àfiyèsí àrà ọ̀tọ̀ sí ìtọ́sọ́nà tí Jèhófà ń fún wa nípasẹ̀ Jésù ká má bàa sú lọ.—Hébérù 2:1.
14 Nígbà míì, ó máa ń gba àkànṣe ìsapá láti jẹ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àǹfààní látinú oúnjẹ tẹ̀mí. Fún àpẹẹrẹ, ó lè jẹ́ pé ńṣe la kàn ń sáré ka àwọn àkọsílẹ̀ Bíbélì tó nira fún wa láti lóye. Nígbà táa bá ń ka ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí!, a tilẹ̀ lè fo àwọn àpilẹ̀kọ kan nítorí pé a ò nífẹ̀ẹ́ sí kókó tí wọ́n ń jíròrò. Tàbí kẹ̀, a lè jẹ́ kí ọkàn wa máa rìn gbéregbère nígbà tí ìpàdé Kristẹni bá ń lọ lọ́wọ́. Bó ti wù kó rí, a lè wà lójúfò báa bá fara balẹ̀ ronú lórí àwọn kókó ìjíròrò náà. Ìmọrírì jíjinlẹ̀ táa ní fún ìtọ́ni tẹ̀mí táa ń rí gbà fi hàn pé a gbà pé Jèhófà ni Olùkọ́ni wa Atóbilọ́lá.
A Ò Ní Ṣàì Jíhìn
15. Báwo làwọn kan ṣe ń ṣe bíi pé Jèhófà ò rí àwọn?
15 Níní ìgbàgbọ́ nínú Ẹni tí a kò lè rí ṣe pàtàkì gan-an, pàápàá jù lọ nítorí pé ìwà ibi ti gbòde kan ní “àkókò òpin” yìí. (Dáníẹ́lì 12:4) Ìwà àìṣòótọ́ àti ìṣekúṣe peléke. Dájúdájú, ó bọ́gbọ́n mu láti rántí pé Jèhófà ń rí gbogbo ohun táa ń ṣe, kódà nígbà téèyàn kò lè rí wa. Àwọn kan kì í fi kókó yìí sọ́kàn. Nígbà táwọn èèyàn ò bá rí wọn, wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ohun tó lòdì sí Ìwé Mímọ́. Fún àpẹẹrẹ, àwọn kan ti kó sínú ìdẹwò wíwo àwọn eré tí kò bójú mu àtàwọn ohun tí ń ru ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sókè lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, tẹlifíṣọ̀n, àtàwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé mìíràn. Níwọ̀n bí wíwo irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ti sábà máa ń ṣẹlẹ̀ níbi tójú àwọn ẹlòmíì ò ti ní tó wọn, àwọn kan ń ṣe bíi pé Jèhófà ò rí ohun tí àwọ́n ń ṣe.
16. Kí ló yẹ kó ràn wá lọ́wọ́ láti rọ̀ mọ́ àwọn ìlànà gíga Jèhófà?
16 Ó dáa láti máa fi ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ́kàn, pé: “Olúkúlùkù wa ni yóò ṣe ìjíhìn ara rẹ̀ fún Ọlọ́run.” (Róòmù 14:12) Ó yẹ ká mọ̀ pé gbogbo ìgbà táa bá ṣẹ̀, Jèhófà là ń ṣẹ̀ sí. Ó yẹ kí mímọ èyí ràn wá lọ́wọ́ láti rọ̀ mọ́ àwọn ìlànà gíga rẹ̀, ká sì yàgò fún ìwà àìmọ́. Bíbélì rán wa létí pé: “Kò sì sí ìṣẹ̀dá tí kò hàn kedere sí ojú rẹ̀, ṣùgbọ́n ohun gbogbo wà ní ìhòòhò àti ní ṣíṣísílẹ̀ gbayawu fún ojú ẹni tí a óò jíhìn fún.” (Hébérù 4:13) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò ní ṣàì jíhìn fún Ọlọ́run, síbẹ̀ ó dájú pé ìfẹ́ jíjinlẹ̀ táa ní fún Jèhófà ni olórí ìdí táa fi ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀, táa sì ń ṣègbọràn sí àwọn ìlànà òdodo rẹ̀. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká kíyè sára ní ti irú eré ìnàjú táa yàn àti ìṣesí wa pẹ̀lú ẹ̀yà kejì.
17. Irú ojú wo ni Jèhófà fi ń ṣọ́ wa?
17 Jèhófà kì í fọ̀rọ̀ wa ṣeré rárá, ṣùgbọ́n ìyẹn ò wá túmọ̀ sí pé ó ń dúró dè wá láti ṣàṣìṣe kó lè fìyà jẹ wá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló ń ṣàkíyèsí wa tìfẹ́tìfẹ́, bíi bàbá tó fẹ́ san èrè fún àwọn ọmọ rẹ̀ onígbọràn. Ẹ wo bó ti ń tuni nínú tó láti mọ̀ pé inú Baba wa ọ̀run dùn sí ìgbàgbọ́ wa, àti pé “òun ni olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a”! (Hébérù 11:6) Ǹjẹ́ kí a fi tọkàntọkàn lo ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà, ká sì máa ‘fi ọkàn-àyà pípé pérépéré sìn ín.’—1 Kíróníkà 28:9.
18. Nítorí pé Jèhófà ń wò wá, tó sì ń kíyè sí ìṣòtítọ́ wa, ìdánilójú wo la rí nínú Ìwé Mímọ́?
18 Ìwé Òwe 15:3 sọ pé: “Ojú Jèhófà ń bẹ ní ibi gbogbo, ó ń ṣọ́ àwọn ẹni búburú àti àwọn ẹni rere.” Bẹ́ẹ̀ ni, Ọlọ́run ń ṣọ́ àwọn ẹni búburú, ó sì ń san èrè iṣẹ́ ọwọ́ wọn fún wọn. Àmọ́, táa bá wà lára “àwọn ẹni rere,” a lè ní ìdánilójú pé Jèhófà ń kíyè sí ìwà ìṣòtítọ́ wa. Ẹ wo bó ti ń fúnni lókun tó láti mọ̀ pé ‘òpò wa kì í ṣe asán ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Olúwa’ àti pé ẹni tí a kò lè rí náà kì yóò ‘gbàgbé iṣẹ́ wa àti ìfẹ́ tí a fi hàn fún orúkọ rẹ̀’!—1 Kọ́ríńtì 15:58; Hébérù 6:10.
Kíké sí Jèhófà Láti Wá Yẹ̀ Wá Wò
19. Kí ni díẹ̀ lára àǹfààní níní ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú Jèhófà?
19 Gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ olóòótọ́ fún Jèhófà, a ṣeyebíye lójú rẹ̀. (Mátíù 10:29-31) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò lè rí i, ó lè jẹ́ ẹni gidi sí wa, a sì lè máa fojú ribiribi wo àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀. Fífi irú ojú yẹn wo Baba wa ọ̀run ń mú ọ̀pọ̀ ìbùkún wá fún wa. Ìgbàgbọ́ lílágbára táa ní ń ràn wá lọ́wọ́ láti ní ọkàn mímọ́ àti ẹ̀rí ọkàn rere níwájú Jèhófà. Ìgbàgbọ́ láìsí àgàbàgebè tún ń jẹ́ ká yàgò fún gbígbé ìgbésí ayé méjì. (1 Tímótì 1:5, 18, 19) Ìgbàgbọ́ tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ táa ní nínú Ọlọ́run jẹ́ àpẹẹrẹ rere, ó sì lè jẹ́ ìṣírí fáwọn tó yí wa ká. (1 Tímótì 4:12) Jù bẹ́ẹ̀ lọ, irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ ń gbé ìwà bí Ọlọ́run lárugẹ, ó ń mú inú Jèhófà dùn.—Òwe 27:11.
20, 21. (a) Èé ṣe tó fi dára kí Jèhófà máa fi ìṣọ́ rẹ̀ ṣọ́ wa? (b) Báwo ni àwa fúnra wa ṣe lè fi Sáàmù 139:23, 24 sílò?
20 Bí a bá gbọ́n lóòótọ́, inú wa yóò dùn pé Jèhófà ń fi ìṣọ́ rẹ̀ ṣọ́ wa. Kì í ṣe kìkì pé a fẹ́ kó rí wa nìkan ni, ṣùgbọ́n a tún ń fẹ́ kó yẹ èrò àti ìṣesí wa wò fínnífínní. Nígbà táa bá ń gbàdúrà, á dáa ká ké sí i láti wá yẹ̀ wá wò látòkè délẹ̀, kí ó sì rí i bóyá èròkérò wà lọ́kàn wa. Ó dájú pé ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìṣòro wa, ká sì ṣe àtúnṣe èyíkéyìí tó bá bójú mu. Ó bá a mu wẹ́kú pé Dáfídì onísáàmù náà kọ ọ́ lórin pé: “Yẹ̀ mí wò látòkè délẹ̀, Ọlọ́run, kí o sì mọ ọkàn-àyà mi. Wádìí mi wò, kí o sì mọ àwọn ìrònú tí ń gbé mi lọ́kàn sókè, kí o sì rí i bóyá ọ̀nà èyíkéyìí tí ń roni lára wà nínú mi, kí o sì ṣamọ̀nà mi ní ọ̀nà àkókò tí ó lọ kánrin.”—Sáàmù 139:23, 24.
21 Dáfídì bẹ Jèhófà pé kí ó yẹ òun wò látòkè délẹ̀ láti rí i bóyá “ọ̀nà èyíkéyìí tí ń roni lára” wà nínú òun. Bíi ti onísáàmù náà, ǹjẹ́ àwa náà kì í yán hànhàn pé kí Olọ́run yẹ ọkàn wa wò, kí ó sì rí i bóyá ètekéte wà níbẹ̀? Nígbà náà, ẹ jẹ́ ká fi ìgbàgbọ́ bẹ Jèhófà pé kí ó yẹ̀ wá wò. Àmọ́ bí ọkàn wa ò bá lélẹ̀ nítorí àṣìṣe kan, tàbí bí ète burúkú kan bá wà lọ́kàn wa ńkọ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká máa fi taratara gbàdúrà sí Jèhófà, Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́, kí a sì máa fi tìrẹ̀lẹ̀-tìrẹ̀lẹ̀ tẹ̀ lé ìdarí ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ àti ìmọ̀ràn látinú Ọ̀rọ̀ rẹ̀. A lè ní ìdánilójú pé yóò tì wá lẹ́yìn, yóò sì ràn wá lọ́wọ́ láti tọ ipa ọ̀nà tí yóò ṣamọ̀nà sí ìyè àìnípẹ̀kun.—Sáàmù 40:11-13.
22. Kí ló yẹ kó jẹ́ ìpinnu wa nípa Ẹni tí a kò lè rí náà?
22 Dájúdájú, Jèhófà yóò fi ìyè ayérayé jíǹkí wa báa bá dójú ìlà àwọn ohun tó ń béèrè. Àmọ́ ṣá o, a gbọ́dọ̀ gbà pé ọwọ́ rẹ̀ ni agbára àti ọlá àṣẹ wà, àní gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti gbà nígbà tó kọ̀wé pé: “Ọba ayérayé, tí kò lè díbàjẹ́, tí a kò lè rí, Ọlọ́run kan ṣoṣo náà, ni kí ọlá àti ògo jẹ́ tirẹ̀ títí láé àti láéláé. Àmín.” (1 Tímótì 1:17) Ǹjẹ́ kí a máa ní irú ọ̀wọ̀ àtọkànwá bẹ́ẹ̀ fún Jèhófà nígbà gbogbo. Ní ipòkípò táa bá wà, kí ìpinnu wa má yẹ̀ láé láti máa bá a lọ ní fífẹsẹ̀múlẹ̀ ṣinṣin gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ń rí Ẹni tí a kò lè rí.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Báwo ló ṣe ṣeé ṣe fún ẹ̀dá ènìyàn láti rí Ọlọ́run?
• Bí Jèhófà bá jẹ́ ẹni gidi lójú wa, kí la ó ṣe nígbà tí wọ́n bá ń ṣe inúnibíni sí wa?
• Kí ló túmọ̀ sí láti máa wo Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Olùkọ́ni wa Atóbilọ́lá?
• Èé ṣe tó fi yẹ ká fẹ́ kí Jèhófà yẹ̀ wá wò?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ẹ̀rù Fáráò kò ba Mósè, ṣùgbọ́n ó gbégbèésẹ̀ bí ẹni tó lè rí Jèhófà, Ọlọ́run tí a kò lè rí
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Ẹ má ṣe jẹ́ ká gbégbèésẹ̀ láé bíi pé Jèhófà kò lè rí ohun tí à ń ṣe
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
A ń fi taratara wá ìmọ̀ Ọlọ́run nítorí pé a rí i gẹ́gẹ́ bí Olùkọ́ni wa Atóbilọ́lá