Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
Ó Fara Da Ìjákulẹ̀
SÁMÚẸ́LÌ mọ̀ pé ìbànújẹ́ kékeré kọ́ ló bá ìlú Ṣílò. Ọ̀pọ̀ èèyàn tó wà ní ìlú náà ni ìbànújẹ́ dorí wọn kodò. Ẹ ò rí i bí igbe àwọn obìnrin àtàwọn ọmọdé ti gbalẹ̀ kan tó, tí wọ́n ń ṣọ̀fọ̀ lórí ìròyìn tí wọ́n gbọ́ pé bàbá, ọkọ, ọmọkùnrin wọn àtàwọn arákùnrin wọn kò ní pa dà wá lé mọ́. Orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì pàdánù ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [30,000] ọmọ ogun nígbà táwọn Filísínì ṣẹ́gun wọn yán-ányán-án, ṣáájú ìgbà yẹn sì ni ẹgbẹ̀rún mẹ́rin [4,000] ọmọ ogun Ísírẹ́lì ti ṣègbé sọ́wọ́ wọn.—1 Sámúẹ́lì 4:1, 2, 10.
Ńṣe lèyí wulẹ̀ jẹ́ àpá kan lára ọ̀wọ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú tó wáyé. Élì Àlùfáà Àgbà ní ọmọkùnrin méjì, orúkọ wọn ni Hófínì àti Fíníhásì, ọmọkọ́mọ làwọn ọmọ yìí. Àwọn méjèèjì tẹ̀ lé àpótí májẹ̀mú mímọ́ jáde kúrò ní Ṣílò. Inú ibi mímọ́ jù lọ nínú àgọ́ ìjọsìn ni wọ́n máa ń gbé àpótí tó ṣeyebíye náà sí, àpótí náà sì ṣàpẹẹrẹ pé Ọlọ́run wà níbẹ̀. Nígbà tó yá, àwọn èèyàn yìí gbé Àpótí náà lọ sójú ogun, èrò òmùgọ̀ tí wọ́n ní ni pé, ó máa jẹ́ oògùn ààbò fún wọn, á sì mú kí àwọn borí. Àmọ́, àwọn Filísínì gba Àpótí náà, wọ́n sì pa Hófínì àti Fíníhásì dà nù.—1 Sámúẹ́lì 4:3-11.
Ó ti pẹ́ tí àgọ́ ìjọsìn tó wà ní Ṣílò ti jẹ́ ibi ọlọ́wọ̀ nítorí pé Àpótí yìí wà níbẹ̀. Ní báyìí, kò sí níbẹ̀ mọ́. Nígbà tí Élì, ẹni ọdún méjìdínlọ́gọ́rùn-ún [98] gbọ́ ìròyìn yìí, ńṣe ló ṣubú lulẹ̀ sọ́wọ́ ẹ̀yìn látorí àga rẹ̀, ó sì kú. Lọ́jọ́ yẹn ni ìyàwó ọmọ Élì di opó, obìnrin náà sì kú lọ́jọ́ kan náà yẹn nígbà tó ń bímọ. Àmọ́ kó tó kú, ó sọ pé: “Ògo ti fi Ísírẹ́lì sílẹ̀ lọ sí ìgbèkùn.” Kò sí àní-àní pé, Ṣílò kò ní rí bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́.—1 Sámúẹ́lì 4:12-22.
Báwo ni Sámúẹ́lì ṣe máa fara da ipò ìbànújẹ́ yìí? Ṣé ìgbàgbọ́ rẹ̀ á lágbára lákòókò yìí táá fi lè ṣèrànwọ́ fún àwọn èèyàn tó ti pàdánù ààbò àti ojú rere Jèhófà? Àwa náà lónìí lè dojú kọ ipò tó nira àti ìjákulẹ̀, èyí tó ń béèrè pé ká ní ìgbàgbọ́ tó lágbára, nítorí náà, ẹ jẹ́ ká wo ohun tá a lè rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ Sámúẹ́lì.
Ó “Ṣiṣẹ́ Òdodo Yọrí”
Bíbélì dánu dúró lórí ọ̀rọ̀ Sámúẹ́lì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ nípa Àpótí mímọ́ náà, ó jẹ́ ká mọ bí àwọn Filísínì ṣe jìyà nítorí pé wọ́n gbé àpótí náà àti bó ṣe di dandan fún wọn láti dá a pa dà. Ogún ọdún sì ti kọjá kí Bíbélì tó pa dà sọ̀rọ̀ nípa Sámúẹ́lì. (1 Sámúẹ́lì 7:2) Kí ló ń ṣe láwọn ọdún wọ̀nyẹn? Kò sí ìdí láti méfò.
Kí ogún ọdún náà tó bẹ̀rẹ̀, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé, “Ọ̀rọ̀ Sámúẹ́lì sì ń bá a lọ ní títọ gbogbo Ísírẹ́lì wá.” (1 Sámúẹ́lì 4:1) Àkọsílẹ̀ náà jẹ́ ká mọ̀ pé, lẹ́yìn tí ogún ọdún náà ti pé, ó jẹ́ àṣà Sámúẹ́lì láti máa ṣèbẹ̀wò sí ìlú mẹ́ta kan ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì tó sì ń yíká wọn lẹ́ẹ̀kan lọ́dún, tí á máa yanjú ìṣòro, tí á sì máa dáhùn àwọn ìbéèrè. Tó bá ti ṣe tán, á pa dà sí ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀ ní Rámà. (1 Sámúẹ́lì 7:15-17) Kò sí iyè méjì pé, ọwọ́ Sámúẹ́lì máa ń dí nígbà gbogbo, ó sì dájú pé, ọ̀pọ̀ nǹkan ló ń ṣe láàárín ogún ọdún náà.
Ìwà pálapàla àti ìwà jẹgúdújẹrá tí àwọn ọmọ Élì ń hù ti ba ìgbàgbọ́ àwọn èèyàn jẹ́. Ó jọ pé èyí ló mú kí ọ̀pọ̀ nínú wọn bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn òrìṣà. Àmọ́, lẹ́yìn iṣẹ́ àṣekára tí Sámúẹ́lì ṣe fún ogún ọdún, ó sọ ọ̀rọ̀ yìí fún àwọn èèyàn náà pé: “Bí ó bá jẹ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà yín ni ẹ fi ń padà sọ́dọ̀ Jèhófà, ẹ mú àwọn ọlọ́run ilẹ̀ òkèèrè kúrò ní àárín yín àti àwọn ère Áṣítórétì pẹ̀lú, kí ẹ sì darí ọkàn-àyà yín sọ́dọ̀ Jèhófà láìyà bàrá, kí ẹ sì máa sin òun nìkan ṣoṣo, yóò sì dá yín nídè kúrò ní ọwọ́ àwọn Filísínì.”—1 Sámúẹ́lì 7:3
“Ọwọ́ àwọn Filísínì” le ju ti àwọn èèyàn náà lọ. Àwọn Filísínì ṣẹ́gun àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì yán-ányán-án, èyí sì mú kí wọ́n ṣe àwọn èèyàn Ọlọ́run bí ọṣẹ ṣe ń ṣe ojú, tí nǹkan kan kò sí tẹ̀yìn rẹ̀ yọ. Àmọ́, Sámúẹ́lì fi dá àwọn èèyàn náà lójú pé, nǹkan máa yí pa dà tí wọ́n bá pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà. Ṣé wọ́n fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀? Inú Sámúẹ́lì dùn gan-an nígbà tí wọ́n kó àwọn ère wọn dà nù, tí “wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sin Jèhófà nìkan ṣoṣo.” Sámúẹ́lì ṣètò láti ṣe àpéjọ kan ní Mísípà, ìyẹn ìlú kan tó ní àwọn òkè, èyí tó wà ní àríwá Jerúsálẹ́mù. Àwọn èèyàn náà péjọ, wọ́n gbààwẹ̀, wọ́n sì ronú pìwà dà ẹ̀ṣẹ̀ ìbọ̀rìṣà tí wọ́n ti dá.—1 Sámúẹ́lì 7:4-6.
Àmọ́ àwọn Filísínì gbọ́ nípa àpéjọ ńlá yìí, wọ́n sì rò pé, àǹfààní rèé láti gbéjà ko àwọn ọ̀tá. Ni wọ́n bá rán àwọn ọmọ ogun wọn lọ sí Mísípà láti pa àwọn èèyàn tó ń jọ́sìn Jèhófà run. Tóò, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́ nípa ewu tó ń bọ̀ náà. Ẹ̀rù bà wọ́n gan-an, wọ́n sì ní kí Sámúẹ́lì gbàdúrà fún àwọn. Sámúẹ́lì ṣe bẹ́ẹ̀, ó tún rúbọ. Ní àkókò àpéjọ ọlọ́wọ̀ yìí, ni àwọn ọmọ ogun Filísínì gbéjà wá sí Mísípà. Nítorí náà, Jèhófà dáhùn àdúrà Sámúẹ́lì. Ó sì fìbínú sán ààrá. Ó “mú kí ààrá sán . . . pẹ̀lú ariwo dídún ròkè lu àwọn Filísínì ní ọjọ́ yẹn.”—1 Sámúẹ́lì 7:7-10.
Ṣé a wá lè sọ pé àwọn Filísínì jẹ́ ọmọdé tí ìbẹ̀rù máa ń mú kí wọ́n sá sẹ́yìn ìyá wọn nígbà tí wọ́n bá gbọ́ ìró ààrá? Rárá, ògbójú jagunjagun ni wọ́n. Àmọ́, ààrá yìí ti ní láti yàtọ̀ pátápátá sí gbogbo ààrá tí wọ́n ti gbọ́ rí. Ṣé bí ìró rẹ̀ ṣe dún lọ sókè lálá ni? Ṣé láti ọ̀run ló ti wá ni, àbí láti àárín àwọn òkè kéékèèké ló ti dún lọ́nà tó ń kó ìpayà báni? Èyí ó wù tí ì báà jẹ́, ṣìbáṣìbo bá àwọn Filísínì gan-an. Ṣìbáṣìbo yìí wá mú kí àwọn tó ń léni di ẹni tá à ń lé. Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì jáde láti Mísípà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ́gun wọn, wọ́n sì lépa wọn fún ọ̀pọ̀ kìlómítà, gba gúúsù ìwọ̀ oòrùn Jerúsálẹ́mù.—1 Sámúẹ́lì 7:11.
Àyípadà ńlá ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí jẹ́ fún àwọn èèyàn Ọlọ́run. Àwọn Filísínì kò sì yọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lẹ́nu mọ́ ní gbogbo àkókò tó kù tí Sámúẹ́lì fi jẹ́ onídàájọ́ wọn. Àwọn èèyàn Ọlọ́run sì gba gbogbo ìlú wọn pa dà ní ọ̀kọ̀ọ̀kan.—1 Sámúẹ́lì 7:13, 14.
Ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi orúkọ Sámúẹ́lì sáàárín àwọn onídàájọ́ àti wòlíì olóòótọ́ tí “wọ́n ṣiṣẹ́ òdodo yọrí.” (Hébérù 11:32, 33) Kò sí àní-àní pé, Sámúẹ́lì ṣèrànwọ́ láti mú káwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ohun tó dára àti èyí tó tọ́ lójú Ọlọ́run. Nítorí pé ó fi sùúrù dúró de Jèhófà, kò jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì bá òun, ó sì ń fi ìṣòtítọ́ ṣe iṣẹ́ rẹ̀ nìṣó láìka ìjákulẹ̀ sí. Ó tún fi ìmọrírì hàn. Lẹ́yìn ìṣẹ́gun tó wáyé ní Mísípà, Sámúẹ́lì ṣe ọwọ̀n kan láti fi ṣèrántí ọ̀nà tí Jèhófà gbà ran àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́.—1 Sámúẹ́lì 7:12.
Ǹjẹ́ ìwọ náà fẹ́ ‘ṣiṣẹ́ òdodo yọrí’? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, á dára kó o kẹ́kọ̀ọ́ látinú sùúrù Sámúẹ́lì àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ òun ìmọrírì tó fi hàn. Ta ni lára wa tí kò fẹ́ àwọn ànímọ́ yẹn? Ó dára pé Sámúẹ́lì ti ní irú àwọn ànímọ́ yẹn nígbà tó wà lọ́mọdé, nítorí ó rí àwọn ìjákulẹ̀ tó lágbára nígbà tó dàgbà.
“Àwọn Ọmọkùnrin Rẹ̀ Kò sì Rìn ní Àwọn Ọ̀nà Rẹ̀”
Ní báyìí Sámúẹ́lì ti “darúgbó.” Ó ní ọmọkùnrin méjì tí wọ́n ti dàgbà, ìyẹn Jóẹ́lì àti Ábíjà, ó sì gbé iṣẹ́ lé wọn lọ́wọ́ láti máa ran òun lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìdájọ́. Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn ọmọ rẹ̀ kò bójú tó ohun tó fi síkàáwọ́ wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Sámúẹ́lì jẹ́ olóòótọ́ àti olódodo, àmọ́, ńṣe làwọn ọmọ rẹ̀ ń lo ipò wọn fún ìmọtara ẹni nìkan, wọ́n ń ṣe èrú nínú ìdájọ́, wọ́n sì ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀.—1 Sámúẹ́lì 8:1-3.
Lọ́jọ́ kan, àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì lọ mú ẹ̀sùn bá wòlíì tó ti dàgbà yìí. Wọ́n sọ pé: “Àwọn ọmọkùnrin tìrẹ kò rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ.” (1 Sámúẹ́lì 8:4, 5) Ǹjẹ́ Sámúẹ́lì mọ nípa ìwà táwọn ọmọ rẹ̀ ń hù yìí? Ìtàn náà kò sọ fún wa. Àmọ́ Ọlọ́run kò bá Sámúẹ́lì wí nítorí kò dà bí Élì. Jèhófà bá Élì wí kíkankíkan ó sì fìyà jẹ ẹ́, nítorí kò tọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ sọ́nà nígbà tí wọ́n ń hùwà burúkú, ó sì bọlá fún àwọn ọmọ náà ju Ọlọ́run lọ. (1 Sámúẹ́lì 2:27-29) Jèhófà kó rí irú ìwà burúkú yìí lọ́wọ́ Sámúẹ́lì.
Àkọsílẹ̀ ìtàn náà kò sọ bí ìtìjú, ẹ̀dùn ọkàn tàbí ìjákulẹ̀ tó bá Sámúẹ́lì ti pọ̀ tó nígbà tó gbọ́ nípa ìwàkiwà àwọn ọmọ rẹ̀. Àmọ́, ọ̀pọ̀ òbí máa mọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ̀. Ní àkókò burúkú tá a wà yìí, ṣíṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ àwọn òbí àti ìwà àìgbẹ̀kọ́ ti wọ́pọ̀ gan-an. (2 Tímótì 3:1-5) Àwọn òbí tí irú nǹkan yìí ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá, lè rí ìtùnú àti ìtọ́sọ́nà látinú àpẹẹrẹ Sámúẹ́lì. Kò jẹ́ kí ìwà àìnígbàgbọ́ tí àwọn ọmọ rẹ̀ ń hù mú kó jáwọ́ nínú ìfẹ́ Ọlọ́run. Má gbà gbé pé, bí ọ̀rọ̀ àti ìbáwí òbí kò bá lè yí ọkàn ọmọ tó ti yigbì pa dà, àpẹẹrẹ tó lágbára tí àwọn òbí bá fi lélẹ̀ lè wọ irú ọmọ bẹ́ẹ̀ lọ́kàn. Ìgbà gbogbo làwọn òbí làǹfààní láti mú inú Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Bàbá wọn ọ̀run dùn bí Sámúẹ́lì ti ṣe.
“Yan Ọba Sípò fún Wa”
Àwọn ọmọ Sámúẹ́lì kò ronú lórí àkóbá tí ìwà wọ̀bìà àti ìmọtara-ẹni-nìkan wọn máa ṣe fún àwọn èèyàn. Àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì ń bá ọ̀rọ̀ wọn lọ, wọ́n sọ fún Sámúẹ́lì pé: “Wàyí o, yan ọba sípò fún wa láti máa ṣe ìdájọ́ wa bí ti gbogbo orílẹ̀ èdè.” Ǹjẹ́ Sámúẹ́lì wo ohun tí wọ́n béèrè yìí bíi pé wọ́n ti kọ òun sílẹ̀? Ó ṣe tán, ó ti lo ọ̀pọ̀ ọdún láti ṣojú fún Jèhófà nínú ṣíṣèdájọ́ àwọn èèyàn náà. Àmọ́ ní báyìí, ọba ni wọ́n ń fẹ́ kó máa ṣèdájọ́ àwọn, wọn kò fẹ́ Sámúẹ́lì mọ́ nítorí pé wòlíì ni. Àwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká ní ọba, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì náà sì fẹ́ kí ọba máa ṣàkóso wọn! Kí ni Sámúẹ́lì ṣe? A kà pé, “ohun náà burú” lójú rẹ̀.—1 Sámúẹ́lì 8:5, 6.
Wo ohun tí Jèhófà ṣe nígbà tí Sámúẹ́lì gbàdúrà sí i lórí ọ̀ràn náà, ó ní: “Fetí sí ohùn àwọn ènìyàn náà ní ti gbogbo ohun tí wọ́n sọ fún ọ; nítorí kì í ṣe ìwọ ni wọ́n kọ̀, ṣùgbọ́n èmi ni wọ́n kọ̀ ní ọba lórí wọn.” Ó dájú pé ọ̀rọ̀ yìí máa tu Sámúẹ́lì nínú gan-an, àmọ́, ìwà àrífín gbáà làwọn èèyàn náà hù sí Ọlọ́run Olódùmarè! Jèhófà ní kí wòlíì rẹ̀ sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa àwọn nǹkan burúkú tó máa tẹ̀yìn rẹ̀ yọ tí wọ́n bá ní ọba. Nígbà tí Sámúẹ́lì sọ ọ̀rọ̀ náà fún wọn, ńṣe ni wọ́n yarí pé: “Bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n ọba ni yóò wá wà lórí wa.” Ìgbà gbogbo ni Sámúẹ́lì máa ń ṣègbọràn sí Ọlọ́run rẹ̀, nítorí náà, ó lọ ta òróró sórí ọba tí Jèhófà yàn.—1 Sámúẹ́lì 8:7-19.
Àmọ́, báwo ni Sámúẹ́lì ṣe ṣègbọràn? Ṣé ó ní ìkùnsínú, tí kò sì ṣe ìgbọràn látọkànwá? Ǹjẹ́ ó jẹ́ kí ìjákulẹ̀ ba òun lọ́kàn jẹ́, tó sì wá fàyè gba ìbínú? Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ṣe bẹ́ẹ̀, àmọ́ Sámúẹ́lì kò ṣe bẹ́ẹ̀. Ó fòróró yan Sọ́ọ̀lù, ó sì gbà pé ọkùnrin yìí ni Jèhófà yàn. Ó fẹnu ko Sọ́ọ̀lù lẹnu, èyí tó jẹ́ àmì pé ó tẹ́wọ́ gbà á gẹ́gẹ́ bí ọba tuntun, ó sì ṣe tán láti máa tẹrí ba fún un. Ó sì sọ fún àwọn èèyàn náà pé: “Ṣé ẹ rí ẹni tí Jèhófà yàn, pé kò sí ẹnì kankan tí ó dà bí rẹ̀ láàárín gbogbo ènìyàn?”—1 Sámúẹ́lì 10:1, 24.
Ìwà dáadáa ọkùnrin tí Jèhófà yàn yìí ni Sámúẹ́lì ń wò, kì í ṣe àṣìṣe rẹ̀. Nípa Sámúẹ́lì fúnra rẹ̀, ìwà títọ́ rẹ̀ sí Ọlọ́run ló ń múnú rẹ̀ dùn kì í ṣe bí àwọn èèyàn tí kò láyọ̀lé náà ṣe ń gbóríyìn fún un. (1 Sámúẹ́lì 12:1-4) Ó tún ń fi ìṣòtítọ́ ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé fún un, ó ń gba àwọn èèyàn Ọlọ́run níyànjú láti yẹra fún àwọn ohun tó lè bá àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́, ó sì ń fún wọn níṣìírí pé kí wọ́n máa jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà nìṣó. Ìmọ̀ràn tí Sámúẹ́lì gbà wọ́n yìí wọ̀ wọ́n lọ́kàn, wọ́n sì bẹ̀ ẹ́ pé kò gbàdúrà nítorí àwọn. Ó fún wọn ní èsì tó dára yìí pé: “Kò ṣeé ronú kàn, níhà ọ̀dọ̀ mi, láti ṣẹ̀ sí Jèhófà nípa ṣíṣíwọ́ láti gbàdúrà nítorí yín; èmi yóò sì fún yín ní ìtọ́ni ní ọ̀nà rere àti títọ́.”—1 Sámúẹ́lì 12:21-24.
Ǹjẹ́ ó ti dùn ẹ́ rí pé wọ́n fún ẹnì kan ní àǹfààní kan tó o rò pé ìwọ ló yẹ kí wọ́n fún? Àpẹẹrẹ Sámúẹ́lì jẹ́ ìránnilétí pàtàkì pé, a kò gbọ́dọ̀ fàyè gba owú tàbí ìbínú nínú ọkàn wa. Ọlọ́run ní ọ̀pọ̀ iṣẹ́ aláyọ̀ tó ń mérè wá tó lè fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́.
“Yóò Ti Pẹ́ Tó Tí Ìwọ Yóò Fi Máa Ṣọ̀fọ̀ Sọ́ọ̀lù?”
Sámúẹ́lì kò ṣì sọ nígbà tó sọ pé òun rí ohun rere lára Sọ́ọ̀lù, nítorí pé Sọ́ọ̀lù jẹ́ ọkùnrin kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Ọkùnrin yìí ga, ó síngbọnlẹ̀, ó nígboyà, ó mọ bó ṣe lè yanjú ìṣòro, síbẹ̀, níbẹ̀rẹ̀ ó mọ̀wọ̀n ara rẹ̀, kò sì lépa òkìkí. (1 Sámúẹ́lì 10:22, 23, 27) Yàtọ̀ sí àwọn ẹ̀bùn yẹn, ó tún ní ẹ̀bùn kan tó ṣeyebíye gan-an, ìyẹn ni òmìnira láti yan ohun tó wù ú kó sì dá ṣe ìpinnu fúnra rẹ̀. (Diutarónómì 30:19) Ṣé ó lo ẹ̀bùn náà lọ́nà rere?
Ó bani nínú jẹ́ pé ìrẹ̀lẹ̀ ni èèyàn sábà máa ń kọ́kọ́ pàdánù tó bá dé ipò agbára. Kò pẹ́ tí Sọ́ọ̀lù fi bẹ̀rẹ̀ sí í gbéra ga. Ó yàn láti ṣàìgbọràn sí ọ̀rọ̀ Jèhófà tí Sámúẹ́lì sọ fún un. Lákòókò kan, Sọ́ọ̀lù kò ní sùúrù, ó sì rú ẹbọ tó jẹ́ pé Sámúẹ́lì nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti rú u. Sámúẹ́lì ní láti bá Sọ́ọ̀lù wí lọ́nà tó múná, ó sì sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn ìdílé Sọ́ọ̀lù kò ní lẹ́tọ̀ọ́ sí ìṣàkóso mọ́. Kàkà kí Sọ́ọ̀lù ronú lórí ìbáwí náà, ńṣe ló tún hùwà àìgbọràn tó burú jáì.—1 Sámúẹ́lì 13:8, 9, 13, 14.
Jèhófà rán Sámúẹ́lì pé kó sọ fún Sọ́ọ̀lù láti lọ gbé ogun ja àwọn ará Ámálékì. Ara ìtọ́ni tí Jèhófà fún un ni pé kó pa Ágágì ọba wọn tó jẹ́ èèyàn burúkú. Àmọ́, Sọ́ọ̀lù dá Ágágì sí àtàwọn ẹrù tó dára jù, èyí tí wọ́n rí níbẹ̀, tó yẹ kí wọ́n pa run. Nígbà tí Sámúẹ́lì wá bá Sọ́ọ̀lù wí lórí ọ̀ràn yìí, Sọ́ọ̀lù fi hàn pé, òun kò tíì yí pa dà. Kàkà kó fìrẹ̀lẹ̀ tẹ́wọ́ gba ìbáwí yìí, ńṣe ló ń wá àwáwí, ó ń dá ara rẹ̀ láre, ó pa ọ̀rọ̀ náà tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, ó sì gbìyànjú láti ti ẹ̀bi ọ̀rọ̀ náà sórí àwọn èèyàn náà. Nígbà tí Sọ́ọ̀lù sọ pé òun ní in lọ́kàn láti fi díẹ̀ lára ohun tóun kó ti ogun bọ̀ rúbọ sí Jèhófà, tí kò fẹ́ gba ìbáwí, Sámúẹ́lì wá sọ ọ̀rọ̀ táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa náà, ó ní: “Wò ó! Ṣíṣègbọràn sàn ju ẹbọ.” Sámúẹ́lì wá fi ìgboyà ba Sọ́ọ̀lù wí, ó sì jẹ́ kó mọ ìpinnu Jèhófà pé: Ọlọ́run máa gba ìṣàkóso kúrò lọ́wọ́ Sọ́ọ̀lù, ó sì máa fún ọkùnrin míì tó sàn jù ú lọ.—1 Sámúẹ́lì 15:1-33.
Àìgbọràn Sọ́ọ̀lù yìí mú inú bí Sámúẹ́lì gan-an. Ńṣe ni Sámúẹ́lì fi gbogbo òru ké pe Jèhófà lórí ọ̀ràn náà. Ó tiẹ̀ ṣọ̀fọ̀ nítorí ọkùnrin yìí pàápàá. Sámúẹ́lì ti fojú inú wo bí àwọn ohun rere tí Sọ́ọ̀lù lè ṣe ti pọ̀ tó, àmọ́ gbogbo ìrètí rẹ̀ ti wọmi báyìí. Ọkùnrin tó mọ̀ tẹ́lẹ̀ yìí ti yí pa dà, ó ti pàdánù àwọn ànímọ́ tó dára jù lọ tó ní, ó sì ti kẹ̀yìn sí Jèhófà. Sámúẹ́lì kò fẹ́ rí Sọ́ọ̀lù mọ́. Àmọ́ nígbà tó yá, Jèhófà fún Sámúẹ́lì ní ìbáwí díẹ̀, ó ní: “Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò fi máa ṣọ̀fọ̀ Sọ́ọ̀lù, nígbà tí ó jẹ́ pé èmi, ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ti kọ̀ ọ́ láti máa ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lórí Ísírẹ́lì? Fi òróró kún ìwo rẹ, kí o sì lọ. Èmi yóò rán ọ lọ sọ́dọ̀ Jésè ará Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, nítorí pé mo ti pèsè ọba fún ara mi lára àwọn ọmọkùnrin rẹ̀.”—1 Sámúẹ́lì 15:34, 35; 16:1.
Bí ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn ṣe máa kẹ́sẹ járí kò sinmi lórí ẹ̀dá èèyàn aláìpé tí kì í fìgbà gbogbo jẹ́ adúróṣinṣin. Bí ẹnì kan bá di aláìṣòótọ́, Jèhófà á wá ẹlòmíì láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ. Nítorí náà, Sámúẹ́lì tó ti darúgbó kò jẹ́ kí ìbànújẹ́ bá òun mọ́ lórí Sọ́ọ̀lù. Jèhófà rán Sámúẹ́lì lọ sí ilé Jésè ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, nígbà tó débẹ̀, ó rí àwọn ọmọkùnrin tí wọ́n síngbọnlẹ̀. Àmọ́ Jèhófà rán Sámúẹ́lì létí nígbà tí ọmọkùnrin àkọ́kọ́ wá síwájú rẹ̀, ó ní: “Má wo ìrísí rẹ̀ àti gíga rẹ̀ ní ìdúró, . . . Nítorí kì í ṣe ọ̀nà tí ènìyàn gbà ń wo nǹkan ni Ọlọ́run gbà ń wo nǹkan, nítorí pé ènìyàn lásán-làsàn ń wo ohun tí ó fara hàn sí ojú; ṣùgbọ́n ní ti Jèhófà, ó ń wo ohun tí ọkàn-àyà jẹ́.” (1 Sámúẹ́lì 16:7) Níkẹyìn, Dáfídì tó jẹ́ ọmọkùnrin tó kéré jù lọ wá síwájú Sámúẹ́lì, òun sì ni Jèhófà yàn!
Láwọn ọdún tí Sámúẹ́lì lò kẹ́yìn ìgbésí ayé rẹ̀, ó túbọ̀ wá rí i pé ìpinnu tí Jèhófà ṣe láti fi Dáfídì rọ́pò Sọ́ọ̀lù ló tọ́. Sọ́ọ̀lù wá di òjòwú tó ń lépa láti pa Dáfídì, ó sì di apẹ̀yìndà. Àmọ́ Dáfídì ní tirẹ̀ fi àwọn ànímọ́ rere hàn, irú bí, ìgboyà, ìwà títọ́, ìgbàgbọ́ àti ìdúróṣinṣin. Bí Sámúẹ́lì ṣe túbọ̀ ń sún mọ́ òpin ìgbésí ayé rẹ̀, ni ìgbàgbọ́ rẹ̀ ń lágbára sí i. Ó yé e pé kò sí ìbànújẹ́ tàbí ìjákulẹ̀ kankan tí Jèhófà kò lè mú kúrò tàbí sọ di ìbùkún. Níkẹyìn, Sámúẹ́lì kú, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kó tó kú, ìgbésí ayé rere ló sì gbé. Abájọ tí gbogbo Ísírẹ́lì fi ṣọ̀fọ̀ ọkùnrin olóòótọ́ yìí! Nítorí náà, ó yẹ kí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà títí dòní máa bi ara wọn pé, ‘Ṣé màá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Sámúẹ́lì?’
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Báwo ni Sámúẹ́lì ṣe ran àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ láti fara da ìjákulẹ̀ àti àdánù?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Nígbà tí àwọn ọmọ Sámúẹ́lì ya ìyàkuyà, báwo ni Sámúẹ́lì ṣe fara da ìjákulẹ̀ náà?