“Ẹ Jẹ́ Kí Ìfaradà Ṣe Iṣẹ́ Rẹ̀ Pé Pérépéré”
“Ẹ jẹ́ kí ìfaradà ṣe iṣẹ́ rẹ̀ pé pérépéré, kí ẹ lè pé pérépéré, kí ẹ sì yè kooro ní gbogbo ọ̀nà, láìṣe aláìní ohunkóhun.”—JÁKỌ́BÙ 1:4.
1, 2. (a) Kí la lè rí kọ́ nínú ìfaradà Gídíónì àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.) (b) Níbàámu pẹ̀lú ohun tó wà nínú Lúùkù 21:19, kí nìdí tí ìfaradà fi ṣe pàtàkì?
FOJÚ inú wo bí Gídíónì Onídàájọ́ àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ ṣe ń fìjà pẹẹ́ta pẹ̀lú àwọn ọ̀tá wọn. Gbogbo òru mọ́jú ni Gídíónì àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ fi lé àwọn ará Mídíánì àtàwọn tó ń gbèjà wọn, nǹkan bíi kìlómítà méjìlélọ́gbọ̀n [32] ni wọ́n sì rìn bí wọ́n ti ń lé wọn. Bíbélì sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà, ó ní: “Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, Gídíónì wá sí Jọ́dánì, wọ́n sọdá rẹ̀, òun àti ọ̀ọ́dúnrún ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, ó ti rẹ̀ wọ́n.” Àmọ́ wọn ò tíì rẹ́yìn gbogbo àwọn ọ̀tá wọn, wọ́n ṣì ní láti bá ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15,000] ọmọ ogun jà. Ọjọ́ pẹ́ táwọn ọ̀tá yìí ti ń fojú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbolẹ̀, torí náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò dẹ̀yìn lẹ́yìn wọn. Ṣe ni Gídíónì àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ ṣáà ń lé àwọn ọ̀tá náà títí tí wọ́n fi ṣẹ́gun wọn.—Àwọn Onídàájọ́ 7:22; 8:4, 10, 28.
2 Àwa náà ń ja ìjà kan tó le gan-an, tó sì ń tánni lókun. Sátánì, ayé búburú yìí àti àìpé tiwa fúnra wa làwọn ọ̀tá tá à ń bá jà. Ọjọ́ pẹ́ táwọn ọ̀tá yìí ti ń bá ọ̀pọ̀ lára wa fà á. Lọ́pọ̀ ìgbà, Jèhófà ti mú ká borí wọn. Àmọ́, a ò tíì rẹ́yìn wọn. Ó lè rẹ̀ wá nígbà míì tàbí kí gbogbo nǹkan tiẹ̀ tojú sú wa torí pé ó ti pẹ́ tá a ti ń retí òpin ètò búburú yìí. Jésù ti sọ fún wa pé a máa dojú kọ àwọn àdánwò tó le koko, wọ́n sì máa ṣe inúnibíni tó lé kenkà sí wa láwọn ọjọ́ ìkẹyìn. Àmọ́, ó tún sọ pé àá borí tá a bá fara dà á. (Ka Lúùkù 21:19.) Kí ni ìfaradà? Kí ló máa jẹ́ ká ní ìfaradà? Kí la lè rí kọ́ lára àwọn tó ti fara da ọ̀pọ̀ ìṣòro? Báwo la sì ṣe lè “jẹ́ kí ìfaradà ṣe iṣẹ́ rẹ̀ pé pérépéré”?—Jákọ́bù 1:4.
KÍ NI ÌFARADÀ?
3. Kí ni ìfaradà?
3 Ọ̀nà tí Bíbélì gbà lo ìfaradà jẹ́ ká mọ̀ pé ó kọjá kéèyàn kàn máa forí ti nǹkan tàbí kéèyàn máa fàyà rán ìṣòro. Ó tún kan èrò wa nípa àwọn àdánwò tá à ń kojú àti ojú tá a fi ń wo àwọn àdánwò náà. Ìfaradà máa ń jẹ́ kéèyàn ní ìgboyà, ó máa ń jẹ́ kéèyàn ní sùúrù, kì í sì í jẹ́ kéèyàn bọ́hùn nígbà ìṣòro. Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé ìfaradà máa ń mú ká ní ìgbàgbọ́ tó lágbára, kì í sì í jẹ́ ká bọ́hùn nígbà ìṣòro. Ó máa ń jẹ́ ká ṣọkàn akin kódà nígbà tá a bá dojú kọ àwọn àdánwò tí ń pinni lẹ́mìí. Ó máa jẹ́ ká borí àwọn àdánwò náà, àá sì lè pọkàn pọ̀ sórí ohun tá à ń lé dípò ká máa ronú ṣáá nípa ohun tá à ń fàyà rán.
4. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ìfẹ́ ló ń mú ká ní ìfaradà?
4 Ìfẹ́ ló ń mú ká máa fara dà á. (Ka 1 Kọ́ríńtì 13:4, 7.) Lọ́nà wo? Ìfẹ́ tá a ní sí Jèhófà ló mú ká máa fara da ohunkóhun tó bá fàyè gbà. (Lúùkù 22:41, 42) Ìfẹ́ tá a ní sáwọn ará wa ló ń mú ká máa fara da àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ wọn. (1 Pétérù 4:8) Ìfẹ́ tá a ní sí ọkọ tàbí aya wa ló ń mú ká máa fara da “ìpọ́njú” irú èyí tí àwọn tọkọtaya tí ilé wọn tòrò pàápàá máa ń ní, á sì mú kí àjọṣe wa túbọ̀ dán mọ́rán.—1 Kọ́ríńtì 7:28.
KÍ LÓ MÁA MÚ KÓ O NÍ ÌFARADÀ?
5. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé Jèhófà ló wà nípò tó dára jù lọ láti ràn wá lọ́wọ́ ká lè ní ìfaradà?
5 Bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ lókun. Jèhófà ni “Ọlọ́run tí ń pèsè ìfaradà àti ìtùnú.” (Róòmù 15:5) Òun nìkan lọ̀rọ̀ wa yé, òun nìkan ló mọ ohun tá à ń bá yí, ó sì mọ bí nǹkan ṣe máa ń rí lára wa. Torí náà, ó mọ ohun tá a nílò gan-an ká lè máa fara dà á. Bíbélì sọ pé: “Ìfẹ́-ọkàn àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ni òun yóò mú ṣẹ, igbe wọn fún ìrànlọ́wọ́ ni òun yóò sì gbọ́, yóò sì gbà wọ́n là.” (Sáàmù 145:19) Àmọ́ lẹ́yìn tá a bá ti gbàdúrà sí Ọlọ́run, báwo ló ṣe máa fún wa lókun ká lè máa fara dà á?
Jèhófà lọ̀rọ̀ wa yé, ó sì mọ ohun tá a nílò gan-an ká lè máa fara dà á
6. Bí Bíbélì ṣe sọ, báwo ni Jèhófà ṣe máa ń “ṣe ọ̀nà àbájáde” tá a bá wà nínú ìṣòro?
6 Jèhófà ṣèlérí pé tá a bá ké pe òun pé kóun ràn wá lọ́wọ́ ká lè fara dà á, òun á “ṣe ọ̀nà àbájáde” fún wa. (Ka 1 Kọ́ríńtì 10:13.) Báwo ló ṣe máa ń ṣe é? Nígbà míì, ó lè mú ìṣòro náà kúrò. Àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, ṣe ló máa ń fún wa lókun ká ‘lè fara dà á ní kíkún, ká sì máa ní ìpamọ́ra pẹ̀lú ìdùnnú.’ (Kólósè 1:11) Torí pé Jèhófà mọ ibi tí agbára wa mọ, ó mọ bí nǹkan ṣe máa ń rí lára wa, ó sì mọ ibi tá a lè mú nǹkan mọ́ra dé, kò ní jẹ́ kí ìṣòro ọ̀hún mu wá lómi débi tá ò fi ní lè jẹ́ olóòótọ́ sí i mọ́.
7. Ṣàlàyé ìdí tá a fi nílò oúnjẹ tẹ̀mí ká tó lè ní ìfaradà.
7 Máa jẹ oúnjẹ tẹ̀mí kí ìgbàgbọ́ rẹ lè lágbára. Kí nìdí tí oúnjẹ tẹ̀mí fi ṣe pàtàkì? Wo àpèjúwe yìí ná: Bí ẹnì kan bá fẹ́ gun òkè ńlá kan tí wọ́n pè ní Òkè Everest, ìyẹn òkè tó ga jù lọ lágbàáyé, àfi kó máa parí oúnjẹ ọjọ́ mẹ́ta sí mẹ́rin lóòjọ́ kó lè lókun nínú dáadáa. Ìyẹn pọ̀ ju oúnjẹ tó yẹ kéèyàn jẹ lóòjọ́. Àmọ́ kí ẹni tó ń pọ́nkè náà má bàa kú sọ́nà, ó pọn dandan pé kó jẹ oúnjẹ púpọ̀ tó máa fún un lókun. Lọ́nà kan náà, àfi ká jẹ ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ tẹ̀mí ká lè fara dà á títí dé òpin. A gbọ́dọ̀ máa wáyè dá kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé, ká sì máa lọ sípàdé déédéé. Èyí á mú kí ìgbàgbọ́ wa máa lágbára sí i.—Jòhánù 6:27.
8, 9. (a) Bí Jóòbù 2:4, 5 ṣe sọ, kí ló yẹ ká máa rántí tá a bá dojú kọ àdánwò? (b) Kí lo lè máa fojú inú yàwòrán ẹ̀ tó o bá dojú kọ àdánwò?
8 Máa rántí pé ó yẹ kó o jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run. Òótọ́ ni pé ojú wa máa ń rí tó nígbà àdánwò, àmọ́ èyí tó tún wá burú jù ni pé Sátánì ń dán wa wò bóyá a máa jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run àbí a ò ní jẹ́ adúróṣinṣin sí I. Ohun tá a bá ṣe nígbà tá a dojú kọ àdánwò máa fi hàn bóyá òótọ́ la gbà pé Jèhófà ni Alákòóso ayé àtọ̀run. Kí nìdí tọ́rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé Sátánì tó jẹ́ ọ̀tá Ọlọ́run tó sì tún ta ko ìṣàkóso rẹ̀ ti sọ fún Jèhófà pé torí ohun táwa èèyàn ń rí gbà lọ́wọ́ Ọlọ́run la ṣe ń sìn ín. Sátánì sọ pé: “Ohun gbogbo tí ènìyàn bá sì ní ni yóò fi fúnni nítorí ọkàn rẹ̀.” Sátánì wá sọ nípa Jóòbù pé: “Fún ìyípadà, jọ̀wọ́, na ọwọ́ rẹ, kí o sì fi kan egungun rẹ̀ àti ẹran ara rẹ̀, kí o sì rí i bóyá kì yóò bú ọ ní ojú rẹ gan-an.” (Jóòbù 2:4, 5) Ṣé Sátánì ti wá yí èrò tó ní nípa wa pa dà? Rárá o! Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, nígbà tí wọ́n lé Sátánì kúrò lọ́run, ó ṣì ń fẹ̀sùn kan àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run lójoojúmọ́. (Ìṣípayá 12:10) Sátánì ṣì ń sọ pé torí ohun tá à ń rí gbà lọ́wọ́ Ọlọ́run la ṣe ń sìn ín. Bá a ṣe máa ta ko ìṣàkóso Ọlọ́run tá ò sì ní sin Jèhófà mọ́ ló ń wá.
9 Tó o bá ń jìyà nígbà àdánwò, fojú inú wò ó pé Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ wà lápá kan, wọ́n fẹ́ mọ ohun tó o máa ṣe, wọ́n sì ń lérí pé wàá tó bọ́hùn. Jèhófà, Jésù Kristi Ọba wa, àwọn ẹni àmì òróró tó ti jíǹde àti ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn áńgẹ́lì náà sì wà lápá kejì, wọ́n rí gbogbo bó o ṣe ń tiraka, wọ́n sì ń fún ẹ níṣìírí pé kó o mọ́kàn, wàá borí. Inú wọn ń dùn bí wọ́n ṣe ń rí ẹ tó ò ń fara dà á, tó o sì jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. Lẹ́yìn náà, lo wá gbọ́ ohùn Jèhófà tó ń sọ fún ẹ pé: “Ọmọ mi, jẹ́ ọlọ́gbọ́n, kí o sì mú ọkàn-àyà mi yọ̀, kí n lè fún ẹni tí ń ṣáátá mi lésì.”—Òwe 27:11.
Jésù pọkàn pọ̀ sórí ibi tí ìfaradà rẹ̀ máa já sí
10. Bíi ti Jésù, báwo lo ṣe lè pọkàn pọ̀ sórí ibi tí ìfaradà rẹ máa já sí?
10 Pọkàn pọ̀ sórí ibi tí ìfaradà rẹ máa já sí. Ńṣe lọ̀rọ̀ ìgbésí ayé dà bí ìgbà téèyàn ń rìnrìn-àjò. Tó sì ṣẹlẹ̀ pé ó máa gba ibì kan tó ṣókùnkùn kọjá. Àmọ́, ó mọ̀ dájú pé bó ti wù kó rí, òun máa tó pa dà já síbi tí ìmọ́lẹ̀ wà. Ìgbésí ayé lè dà bí irú ìrìn àjò bẹ́ẹ̀. Ìgbà míì wà tá a máa dojú kọ ìṣòro tó nira gan-an, táá sì wá dà bíi pé ìṣòro ọ̀hún ò ní tán. Bóyá ó ti ṣe Jésù náà bẹ́ẹ̀ rí nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé. Kó tó di pó kú sorí òpó igi oró tí wọ́n kàn án mọ́, àwọn èèyàn fi í ṣẹ̀sín, ó sì fara da ọ̀pọ̀ ìrora. Ó dájú pé àkókò yìí ló nira fún un jù lọ nígbèésí ayé rẹ̀! Àmọ́, kí ló ran Jésù lọ́wọ́ tó fi lè fara dà á? Bíbélì sọ pé ó wo “ìdùnnú tí a gbé ka iwájú rẹ̀.” (Hébérù 12:2, 3) Jésù pọkàn pọ̀ sórí ibi tí ìfaradà rẹ̀ máa já sí, ní pàtàkì jù lọ, ó máa yọrí sí yíya orúkọ Ọlọ́run sí mímọ́, ó sì máa tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé òun gbà pé Jèhófà ní ẹ̀tọ́ láti máa ṣàkóso. Ó mọ̀ pé àdánwò náà ò ní máa lọ títí ayé, àmọ́ èrè tóun á gbà lọ́run máa wà títí láé. Ó lè dà bíi pé àwọn àdánwò tíwọ náà ń kojú lónìí ò ní tán mọ́, ó sì lè máa fa ẹ̀dùn ọkàn fún ẹ, àmọ́ gbogbo ẹ̀ máa tó dópin.
“ÀWỌN TÍ WỌ́N LO ÌFARADÀ”
11. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ronú lórí àpẹẹrẹ “àwọn tí wọ́n lo ìfaradà”?
11 Kì í ṣe àwa nìkan là ń sáré ìje náà. Àpọ́sítélì Pétérù gba àwọn Kristẹni níyànjú pé kí wọ́n fara da onírúurú àdánwò tí Sátánì lè gbé wá, ó ní: “Ṣùgbọ́n ẹ mú ìdúró yín lòdì sí i, ní dídúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́, ní mímọ̀ pé àwọn ohun kan náà ní ti ìyà jíjẹ ní ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará yín nínú ayé.” (1 Pétérù 5:9) Àpẹẹrẹ “àwọn tí wọ́n lo ìfaradà” máa kọ́ wa bá a ṣe lè máa sin Jèhófà láìyẹsẹ̀, ó máa fọkàn wa balẹ̀ pé a lè borí, ó sì máa rán wa létí pé Jèhófà máa san wá lẹ́san rere tá a bá jẹ́ adúróṣinṣin. (Jákọ́bù 5:11) Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ díẹ̀.[1]—Wo àfikún àlàyé.
12. Kí la rí kọ́ lára àwọn kérúbù tí Jèhófà ní kó máa ṣọ́ ọgbà Édẹ́nì?
12 Áńgẹ́lì onípò-ńlá làwọn kérúbù. Lẹ́yìn tí Ádámù àti Éfà dẹ́ṣẹ̀, Jèhófà rán àwọn kan lára àwọn kérúbù náà wá sórí ilẹ̀ ayé. Iṣẹ́ tó ní kí wọ́n wá ṣe yàtọ̀ pátápátá sí èyí tí wọ́n ń ṣe lọ́run. Àpẹẹrẹ wọn kọ́ wa pé a lè fara dà á tí ètò Ọlọ́run bá gbé iṣẹ́ kan tó dà bíi pé ó le fún wa. Bíbélì sọ pé Jèhófà “yan àwọn kérúbù sí ìlà-oòrùn ọgbà Édẹ́nì àti abẹ idà tí ń jó lala, tí ń yí ara rẹ̀ láìdáwọ́ dúró láti máa ṣọ́ ọ̀nà tí ó lọ síbi igi ìyè náà.”[2] (Wo àfikún àlàyé.) (Jẹ́nẹ́sísì 3:24) Bíbélì ò sọ pé àwọn kérúbù náà ráhùn tàbí kí wọ́n rò pé àwọn ti ga ju ẹni tó ń ṣe irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ lọ. Wọn ò jẹ́ kó sú wọn, wọn ò sì yarí pé àwọn ò lè ṣe iṣẹ́ náà mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n dúró síbi tí Jèhófà ní kí wọ́n wà títí tí wọ́n fi parí iṣẹ́ náà, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé nígbà Ìkún-omi tó wáyé ní ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà [1,600] ọdún lẹ́yìn náà ni wọ́n tó pa dà sọ́run!
13. Báwo ni Jóòbù ṣe borí àwọn àdánwò tó kojú?
13 Jóòbù, ọkùnrin olóòótọ́. Nígbà míì, ọ̀rẹ́ rẹ tàbí mẹ́ńbà ìdílé rẹ kan lè sọ ohun kan tó dùn ẹ́ gan-an. O sì lè máa ṣàìsàn tó le koko tàbí kí èèyàn rẹ kan kú. Àmọ́, ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀ sí wa, àpẹẹrẹ Jóòbù lè tù wá nínú. (Jóòbù 1:18, 19; 2:7, 9; 19:1-3) Jóòbù ò mọ ìdí tí onírúurú àjálù fi ń dé bá òun, àmọ́ kò bọ́hùn. Kí ló mú kó lè fara dà á? Ohun kan ni pé ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kò sì fẹ́ ṣe ohun tínú Jèhófà ò dùn sí. (Jóòbù 1:1) Ohun míì ni pé Jóòbù ti pinnu pé ohun tí Jèhófà fẹ́ lòun á máa ṣe nígbà tó rọgbọ àti nígbà tí kò rọgbọ. Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà tún jẹ́ kí Jóòbù rí bí agbára òun ṣe pọ̀ tó nígbà tó sọ fún un nípa àwọn ohun àgbàyanu tó dá. Èyí mú kó dá Jóòbù lójú pé tó bá tó àkókò lójú Jèhófà, á fòpin sí àjálù tó dé bá òun. (Jóòbù 42:1, 2) Ohun tó sì ṣẹlẹ̀ gẹ́lẹ́ nìyẹn. “Jèhófà tìkára rẹ̀ sì yí ipò òǹdè Jóòbù padà . . . Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí fún Jóòbù ní àfikún ohun gbogbo tí ó jẹ́ tirẹ̀ rí.” Jóòbù “darúgbó, ó sì kún tẹ́rùn-tẹ́rùn fún ọjọ́.”—Jóòbù 42:10, 17.
14. Bí 2 Kọ́ríńtì 1:6 ṣe sọ, báwo ni ìfaradà Pọ́ọ̀lù ṣe ran àwọn míì lọ́wọ́?
14 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Ṣé àwọn kan ń ṣe àtakò tàbí inúnibíni sí ẹ? Ṣé alàgbà ni ẹ́ àbí alábòójútó àyíká, tó o sì ń ronú pé iṣẹ́ tó ò ń ṣe ń wọ̀ ẹ́ lọ́rùn? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù lè ràn ẹ́ lọ́wọ́. Àwọn èèyàn ṣe inúnibíni tó rorò sí Pọ́ọ̀lù, síbẹ̀ ọ̀dọ̀ àwọn ará lọkàn Pọ́ọ̀lù máa ń wà ní gbogbo ìgbà. (2 Kọ́ríńtì 11:23-29) Kò jẹ́ kó sú òun, àpẹẹrẹ rẹ̀ sì máa ń gbé àwọn míì ró. (Ka 2 Kọ́ríńtì 1:6.) Bí ìwọ náà bá ń fara da ìṣòro, wàá jẹ́ àwòkọ́ṣe fáwọn míì.
ṢÉ WÀÁ JẸ́ KÍ ÌFARADÀ “ṢE IṢẸ́ RẸ̀ PÉ PÉRÉPÉRÉ” NÍNÚ RẸ?
15, 16. (a) “Iṣẹ́” wo ni ìfaradà gbọ́dọ̀ ṣe pé pérépéré? (b) Sọ àpẹẹrẹ bá a ṣe lè “jẹ́ kí ìfaradà ṣe iṣẹ́ rẹ̀ pé pérépéré.”
15 Ọlọ́run mí sí ọmọ ẹ̀yìn náà Jákọ́bù láti kọ ohun tó wà nínú Jákọ́bù 1:4 pé: “Ẹ jẹ́ kí ìfaradà ṣe iṣẹ́ rẹ̀ pé pérépéré, kí ẹ lè pé pérépéré, kí ẹ sì yè kooro ní gbogbo ọ̀nà, láìṣe aláìní ohunkóhun.” (Jákọ́bù 1:4) Báwo ni ìfaradà ṣe máa ṣe “iṣẹ́” rẹ̀ pé pérépéré nínú wa? Tá a bá ń kojú àdánwò, ó ṣeé ṣe ká kíyè sí i pé ó yẹ ká túbọ̀ máa mú sùúrù, ká túbọ̀ máa ronú jinlẹ̀ ká lè mọ ọpẹ́ dá tàbí ká túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn. Bá a ṣe ń fara da àdánwò, bẹ́ẹ̀ la ó máa túbọ̀ mú sùúrù, àá mọpẹ́ dá, àá túbọ̀ máa fìfẹ́ hàn, ìyẹn á sì mú ká túbọ̀ máa hùwà tó yẹ Kristẹni.
16 Torí a mọ̀ pé ṣe ni ìfaradà máa ń mú kí àjọṣe àwa àti Jèhófà túbọ̀ lágbára, a ò ní fẹ́ rú òfin Jèhófà tàbí ká gbọ̀nà ẹ̀bùrú wá ojútùú sí àdánwò tó bá dé bá wa. Bí àpẹẹrẹ, tí èrò tí kò tọ́ bá ń wá sí ẹ lọ́kàn ṣáá, má ṣe jẹ́ kíyẹn mú ẹ ṣe ohun tí kò tọ́! Bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè gbé èrò búburú náà kúrò lọ́kàn kíá. Ṣé mọ̀lẹ́bí rẹ kan ló ń ṣe inúnibíni sí ẹ? Má ṣe rẹ̀wẹ̀sì! Pinnu pé wàá máa sin Jèhófà nìṣó. Ìyẹn á mú kó o túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Má gbà gbé pé, ká tó lè rí ojú rere Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ ní ìfaradà.—Róòmù 5:3-5; Jákọ́bù 1:12.
17, 18. (a) Sọ àpèjúwe kan tó fi hàn pé ó ṣe pàtàkì ká fara dà á títí dé òpin. (b) Bí òpin ti ń sún mọ́lé, kí ló dá wa lójú?
17 A gbọ́dọ̀ fara dà á, kì í wulẹ̀ ṣe fúngbà díẹ̀, àmọ́ títí dé òpin. Ká sọ pé ọkọ̀ òkun kan ń rì. Táwọn èrò inú ọkọ̀ náà ò bá fẹ́ bómi lọ, wọ́n gbọ́dọ̀ lúwẹ̀ẹ́ lọ sí etíkun. Ṣe lẹni tó bá lóun ò wẹ̀ mọ́ láì tiẹ̀ tíì lúwẹ̀ẹ́ débì kan á bómi lọ. Bẹ́ẹ̀ náà lẹni tó ti ń wẹ̀ bọ̀ tó wá kù díẹ̀ kó dé etíkun, tó wá ní òun ò wẹ̀ mọ́, àfàìmọ̀ kóun náà má bómi lọ. Tá a bá fẹ́ gbé nínú ayé tuntun, àfi ká fara dà á títí dé òpin. Ẹ jẹ́ kí gbogbo wa fìwà jọ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó sọ pé: “Àwa kò juwọ́ sílẹ̀.”—2 Kọ́ríńtì 4:1, 16.
18 Bíi ti Pọ́ọ̀lù, ó dá wa lójú hán-ún hán-ún pé Jèhófà máa mú ká lè fara dà á dé òpin. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Àwa ń di ajagunmólú pátápátá nípasẹ̀ ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ wa. Nítorí mo gbà gbọ́ dájú pé kì í ṣe ikú tàbí ìyè tàbí àwọn áńgẹ́lì tàbí àwọn ìjọba tàbí àwọn ohun tí ó wà níhìn-ín nísinsìnyí tàbí àwọn ohun tí ń bọ̀ tàbí àwọn agbára tàbí ibi gíga tàbí ibi jíjìn tàbí ìṣẹ̀dá èyíkéyìí mìíràn ni yóò lè yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó wà nínú Kristi Jésù Olúwa wa.” (Róòmù 8:37-39) Òótọ́ ni pé ó lè rẹ̀ wá nígbà míì. Àmọ́, ẹ jẹ́ ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Gídíónì àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀. Ó rẹ̀ wọ́n lóòótọ́, àmọ́ wọn ò dáwọ́ ogun dúró. “Wọ́n ń bá ìlépa náà nìṣó”!—Àwọn Onídàájọ́ 8:4.
^ [1] (ìpínrọ̀ 11) Wàá tún rí bí àwọn èèyàn Ọlọ́run ṣe fara dà á láwọn ọjọ́ wa yìí. Bí àpẹẹrẹ, Ìwé Ọdọọdún wa ti ọdún 1992, 1999 àti 2008 ní àwọn ìrírí tó ń gbéni ró nípa àwọn ará wa lórílẹ̀-èdè Etiópíà, Màláwì àti Rọ́ṣíà.
^ [2] (ìpínrọ̀ 12) Bíbélì ò sọ iye àwọn kérúbù tí Jèhófà gbé iṣẹ́ yìí fún.