Ṣé Ojú Tí Jèhófà Fi Ń wo Ohun Mímọ́ Ni Ìwọ Náà Fi Ń wò ó?
“[Ẹ ṣọ́ra] gidigidi . . . kí ó má bàa sí àgbèrè kankan tàbí ẹnikẹ́ni tí kò mọrírì àwọn ohun ọlọ́wọ̀.”—HÉBÉRÙ 12:15, 16.
1. Irú èrò tó gbòde kan wo làwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kò ní?
BÍ ỌJỌ́ ti ń gorí ọjọ́ làwọn èèyàn ayé túbọ̀ ń ṣàìka ohun mímọ́ sí. Ọ̀gbẹ́ni Edgar Morin, ọmọ ilẹ̀ Faransé kan tó jẹ́ onímọ̀ nípa àjọgbé ẹ̀dá, sọ pé: “Gbogbo ìpìlẹ̀ tí ìwà rere sinmi lé kò ṣe pàtàkì lójú àwọn èèyàn mọ́, ìyẹn àwọn nǹkan bíi ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, ìṣẹ̀dá, ìlú ẹni, ìtàn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn, àtàwọn ohun mìíràn tó mọ́gbọ́n dání. . . . Ìwà tó wu kálukú ló ń hù.” Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn fi “ẹ̀mí ayé,” tàbí “ẹ̀mí tí ń ṣiṣẹ́ nísinsìnyí nínú àwọn ọmọ àìgbọ́ràn” hàn. (1 Kọ́ríńtì 2:12; Éfésù 2:2) Àwọn tí wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà tí wọ́n sì ń fi ìfẹ́ tẹrí bá fún un gẹ́gẹ́ bí Ọba Aláṣẹ kì í ní irú ẹ̀mí tí kò fi ọ̀wọ̀ hàn yìí. (Róòmù 12:1, 2) Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run mọ̀ pé ìjẹ́mímọ́ kó ipa pàtàkì nínú ìjọsìn wọn sí Jèhófà. Àwọn ohun wo ló yẹ ká kà sí mímọ́ nínú ìgbésí ayé wa? Nínú àpilẹ̀kọ́ yìí, a óò jíròrò ohun márùn-ún tó jẹ́ mímọ́ lójú gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run. Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí yóò sọ̀rọ̀ lórí jíjẹ́ tí àwọn ìpàdé Kristẹni jẹ́ mímọ́. Àmọ́ kí ni ọ̀rọ̀ náà “mímọ́” túmọ̀ sí gan-an?
2, 3. (a) Báwo ni Ìwé Mímọ́ ṣe fi hàn pé Jèhófà jẹ́ mímọ́? (b) Ọ̀nà wo là ń gbà fi hàn pé orúkọ Jèhófà jẹ́ mímọ́?
2 Ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n lò fún “mímọ́” nínú Bíbélì túmọ̀ sí ohun kan tá a yà sọ́tọ̀. Nínú ọ̀rọ̀ ìjọsìn, ọ̀rọ̀ náà “mímọ́” túmọ̀ sí ohun tá a yà sọ́tọ̀ gedegbe tàbí ohun tá a gbà pé ó jẹ́ mímọ́. Jèhófà jẹ́ mímọ́ ní gbogbo ọ̀nà. Bíbélì pè é ní “Ẹni Mímọ́ Jù Lọ.” (Òwe 9:10; 30:3) Ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, àlùfáà àgbà máa ń wé láwàní tó ní àwo wúrà tí wọ́n kọ “Ìjẹ́mímọ́ jẹ́ ti Jèhófà” sí lára. (Ẹ́kísódù 28:36, 37) Ìwé Mímọ́ fi hàn pé àwọn kérúbù àtàwọn séráfù tí wọ́n yí ìtẹ́ Jèhófà ká lọ́run ń polongo pé: “Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni Jèhófà.” (Aísáyà 6:2, 3; Ìṣípayá 4:6-8) Ọ̀rọ̀ táwọn áńgẹ́lì yìí sọ lásọtúnsọ túbọ̀ fi hàn pé Jèhófà jẹ́ mímọ́ lọ́nà tó ga jù lọ. Àní, ọ̀dọ̀ Jèhófà ni gbogbo ìjẹ́mímọ́ ti wá.
3 Orúkọ Jèhófà jẹ́ mímọ́. Ọ̀kan lára àwọn tó kọ sáàmù sọ pé: “Kí wọ́n gbé orúkọ rẹ lárugẹ. Títóbi àti amúnikún-fún-ẹ̀rù ni, mímọ́ ni.” (Sáàmù 99:3) Jésù kọ́ wa láti máa gbàdúrà pé: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́.” (Mátíù 6:9) Màríà tó jẹ́ ìyá Jésù sọ pé: “Ọkàn mi gbé Jèhófà ga lọ́lá . . . Ẹni alágbára ti ṣe àwọn ìṣe ńláǹlà fún mi, mímọ́ sì ni orúkọ rẹ̀.” (Lúùkù 1:46, 49) Lójú àwa ìránṣẹ́ Jèhófà, orúkọ rẹ̀ jẹ́ mímọ́, a kò sì gbọ́dọ̀ ṣe ohunkóhun tó lè mú ẹ̀gàn bá orúkọ mímọ́ náà. Síwájú sí i, ojú tí Jèhófà fi ń wo ohun mímọ́ làwa náà fi ń wò ó, ìyẹn ni pé, ohun tó bá kà sí mímọ́ làwa náà kà sí mímọ́.—Ámósì 5:14, 15.
Ìdí Tá A Fi Ń Fún Jésù Ní Ọ̀wọ̀ Tó Jinlẹ̀
4. Kí nìdí tí Bíbélì fi pe Jésù ní “Ẹni Mímọ́”?
4 Ọlọ́run dá Jésù ní mímọ́, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé òun ni “ọmọ bíbí kan ṣoṣo” ti Ọlọ́run mímọ́ náà, Jèhófà. (Jòhánù 1:14; Kólósè 1:15; Hébérù 1:1-3) Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi pè é ní “Ẹni Mímọ́ Ọlọ́run.” (Jòhánù 6:69) Nígbà tí Ọlọ́run mú kí Jésù tó ti wà lọ́run tẹ́lẹ̀ dẹni tí Màríà bí gẹ́gẹ́ bí èèyàn lórí ilẹ̀ ayé, Jésù ṣì jẹ́ ẹni mímọ́ síbẹ̀, nítorí pé nípasẹ̀ agbára ẹ̀mí mímọ́ ni Màríà fi bí i. Áńgẹ́lì kan sọ fún un pé: “Ẹ̀mí mímọ́ yóò bà lé ọ . . . ohun tí a bí ni a ó pè ní mímọ́, Ọmọ Ọlọ́run.” (Lúùkù 1:35) Nínú àdúrà táwọn Kristẹni tó wà ní Jerúsálẹ́mù gbà sí Jèhófà, ẹ̀ẹ̀mejì ni wọ́n pe Ọmọ Ọlọ́run ní “Jésù ìránṣẹ́ rẹ̀ mímọ́.”—Ìṣe 4:27, 30.
5. Iṣẹ́ mímọ́ wo ni Jésù ṣe lórí ilẹ̀ ayé, kí sì nìdí tí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ fi ṣeyebíye?
5 Jésù ní iṣẹ́ mímọ́ kan láti ṣe nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé. Nígbà tí Jésù ṣèrìbọmi ní ọdún 29 Sànmánì Kristẹni, Ọlọ́run fi ẹ̀mí yan Jésù láti jẹ́ Àlùfáà Àgbà ní tẹ́ńpìlì ńlá tẹ̀mí tó jẹ́ ti Jèhófà. (Lúùkù 3:21, 22; Hébérù 7:26; 8:1, 2) Láfikún sí i, ó ní láti kú kó lè fi ara rẹ̀ rúbọ. Ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tó máa ta sílẹ̀ á pèsè ìràpadà táwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ nílò láti lè rí ìgbàlà. (Mátíù 20:28; Hébérù 9:14) Ìdí nìyí tá a fi ka ẹ̀jẹ̀ Jésù sí ohun mímọ́, ohun ‘tó ṣeyebíye.’—1 Pétérù 1:19.
6. Irú ojú wo la fi ń wo Kristi Jésù, kí sì nìdí tá a fi ń ṣe bẹ́ẹ̀?
6 Láti fi hàn pé à ń fọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ hàn fún Ọba àti Àlùfáà wa Àgbà, Jésù Kristi, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ọlọ́run [gbé Ọmọ rẹ̀] sí ipò gíga, tí ó sì fi inú rere fún un ní orúkọ tí ó lékè gbogbo orúkọ mìíràn, kí ó lè jẹ́ pé ní orúkọ Jésù ni kí gbogbo eékún máa tẹ̀ ba ti àwọn tí ń bẹ ní ọ̀run àti àwọn tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé àti àwọn tí ń bẹ lábẹ́ ilẹ̀, kí gbogbo ahọ́n sì máa jẹ́wọ́ ní gbangba pé Jésù Kristi ni Olúwa fún ògo Ọlọ́run Baba.” (Fílípì 2:9-11) Tá a bá ń fayọ̀ tẹrí ba fún Aṣáájú àti Ọba wa tí ń jọba, ìyẹn Jésù Kristi, Orí ìjọ Kristẹni, ńṣe la ń fi hàn pé ojú tí Jèhófà fi ń wo ohun mímọ́ làwa náà fi ń wò ó.—Mátíù 23:10; Kólósè 1:18.
7. Báwo la ṣe lè fi hàn pé à ń tẹrí ba fún Kristi?
7 Lára ohun tá a gbọ́dọ̀ ṣe láti fi hàn pé à ń tẹrí ba fún Kristi ni pé ká máa fi ọ̀wọ̀ tó yẹ hàn fún àwọn tó ń ṣojú rẹ̀ nínú iṣẹ́ tó ń darí lọ́wọ́lọ́wọ́. A gbọ́dọ̀ ka ipa táwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n jẹ́ Ìgbìmọ̀ Olùdarí ń kó, sí iṣẹ́ mímọ́. Ó sì tún yẹ ká gbà pé iṣẹ́ mímọ́ ni iṣẹ́ àwọn alábòójútó tí wọ́n yàn sáwọn ẹ̀ka ilé iṣẹ́ wa, àti iṣẹ́ àwọn alábòójútó àgbègbè, àti tàwọn alábòójútó àyíká, àti tàwọn alábòójútó nínú ìjọ. Nítorí náà, ó yẹ ká fi ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ hàn fún àwọn ètò wọ̀nyí ká sì fara mọ́ wọn.—Hébérù 13:7, 17.
Àwọn Èèyàn Tó Jẹ́ Mímọ́
8, 9. (a) Ọ̀nà wo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbà jẹ́ èèyàn mímọ́? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ̀ pé ìjẹ́mímọ́ ṣe pàtàkì?
8 Jèhófà bá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú. Àjọṣe yẹn mú kí orílẹ̀-èdè tuntun yẹn wà ní ipò tó jẹ́ àkànṣe. Ọlọ́run yà wọ́n sí mímọ́ tàbí yà wọ́n sọ́tọ̀. Jèhófà fúnra rẹ̀ sọ fún wọn pé: “Kí ẹ sì jẹ́ mímọ́ lójú mi, nítorí pé èmi Jèhófà jẹ́ mímọ́; mó sì bẹ̀rẹ̀ sí yà yín sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ènìyàn láti di tèmi.”—Léfítíkù 19:2; 20:26.
9 Nígbà tí Jèhófà fìdí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì múlẹ̀, ó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ìjẹ́mímọ́ ṣe pàtàkì. Wọn kò gbọ́dọ̀ fọwọ́ kan òkè ibi tí Ọlọ́run ti fún wọn ní Òfin Mẹ́wàá, nítorí pé kíkú ni ẹni tó bá ṣe bẹ́ẹ̀ yóò kú. Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, ohun mímọ́ ni Òkè Sínáì jẹ́. (Ẹ́kísódù 19:12, 23) Iṣẹ́ àlùfáà, àgọ́ ìjọsìn, àtàwọn ohun tó wà nínú rẹ̀ tún jẹ́ mímọ́. (Ẹ́kísódù 30:26-30) Báwo ni ọ̀ràn ìjẹ́mímọ́ ṣe rí nínú ìjọ Kristẹni?
10, 11. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró jẹ́ mímọ́, ipa wo lèyí sì ní lórí “àwọn àgùntàn mìíràn”?
10 Lójú Jèhófà, àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n para pọ̀ jẹ́ ìjọ Kristẹni jẹ́ mímọ́. (1 Kọ́ríńtì 1:2) Àní, Bíbélì fi gbogbo àwọn ẹni àmì òróró tó wà lórí ilẹ̀ ayé nígbàkigbà wé tẹ́ńpìlì mímọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kì í ṣe tẹ́ńpìlì ńlá tẹ̀mí ti Jèhófà. Jèhófà ń gbé àárín wọn nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú [Kristi Jésù], gbogbo ilé náà, níwọ̀n bí a ti so ó pọ̀ ní ìṣọ̀kan, ń dàgbà di tẹ́ńpìlì mímọ́ fún Jèhófà. Ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ẹ̀yin pẹ̀lú, ni a ń kọ́ pa pọ̀ di ibì kan fún Ọlọ́run láti gbé nípasẹ̀ ẹ̀mí.”—Éfésù 2:21, 22; 1 Pétérù 2:5, 9.
11 Pọ́ọ̀lù tún kọ̀wé sáwọn Kristẹni ẹni àmì òróró pé: “Ṣé ẹ kò mọ̀ pé tẹ́ńpìlì Ọlọ́run ni yín, àti pé ẹ̀mí Ọlọ́run ń gbé inú yín? . . . Tẹ́ńpìlì Ọlọ́run jẹ́ mímọ́, tẹ́ńpìlì tí ẹ̀yin jẹ́.” (1 Kọ́ríńtì 3:16, 17) Jèhófà ‘ń gbé’ láàárín àwọn ẹni àmì òróró ó sì ‘ń rìn láàárín wọn’ nípasẹ̀ ẹ̀mí rẹ̀. (2 Kọ́ríńtì 6:16) Ó ń tọ́ “ẹrú” rẹ̀ tó jẹ́ olóòótọ́ sọ́nà nígbà gbogbo. (Mátíù 24:45-47) “Àwọn àgùntàn mìíràn” sì mọyì àǹfààní tí wọ́n ní láti máa dara pọ̀ mọ́ àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n jẹ́ “tẹ́ńpìlì” náà.—Jòhánù 10:16; Mátíù 25:37-40.
Àwọn Ohun Tó Jẹ́ Mímọ́ Nínú Ìgbésí Ayé Àwa Kristẹni
12. Àwọn ohun wo ló jẹ́ mímọ́ nínú ìgbésí ayé wa, kí sì nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀?
12 Kò yani lẹ́nu rárá pé ọ̀pọ̀ nǹkan tó ní í ṣe pẹ̀lú ìgbésí ayé àwọn ẹni àmì òróró àti tàwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn ló jẹ́ mímọ́. Ohun mímọ́ ni àjọṣe àárín àwa àti Jèhófà jẹ́. (1 Kíróníkà 28:9; Sáàmù 36:7) Àjọṣe náà ṣeyebíye gan-an débi pé a ò jẹ́ gbà kí ohunkóhun ba àárín àwa àti Jèhófà Ọlọ́run jẹ́. (2 Kíróníkà 15:2; Jákọ́bù 4:7, 8) Àdúrà ń kó ipa pàtàkì nínú mímú kí àjọṣe àárín àwa àti Jèhófà dán mọ́rán. Àdúrà jẹ́ ohun mímọ́ gan-an lójú wòlíì Dáníẹ́lì débi pé, kò jáwọ́ nínú gbígbàdúrà sí Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀, kódà nígbà tí èyí fi ẹ̀mí rẹ̀ sínú ewu. (Dáníẹ́lì 6:7-11) Bíbélì fi “àdúrà àwọn ẹni mímọ́” tàbí ti àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró wé tùràrí táwọn àlùfáà máa ń lò nínú ìjọsìn inú tẹ́ńpìlì. (Ìṣípayá 5:8; 8:3, 4; Léfítíkù 16:12, 13) Tùràrí tá a fi ṣàpẹẹrẹ yìí túbọ̀ jẹ́ ká mọ bí àdúrà ti jẹ́ ohun mímọ́ tó. Àǹfààní ńláǹlà mà ni o, pé èèyàn lè bá Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run sọ̀rọ̀! Abájọ tá a fi ka àdúrà sí ohun mímọ́ ní ìgbésí ayé wa!
13. Ohun wo ló jẹ́ mímọ́, báwo la sì ṣe lè jẹ́ kó ṣiṣẹ́ nínú ìgbésí ayé wa?
13 Ohun kan wà táwọn Kristẹni ẹni àmì òróró àtàwọn ẹlẹgbẹ́ wọn tún kà sí mímọ́. Ẹ̀mí mímọ́ ni ohun náà. Ẹ̀mí yẹn jẹ́ agbára tí Jèhófà ń lò, níwọ̀n bó sì ti ń ṣiṣẹ́ níbàámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run mímọ́, ó tọ̀nà láti pè é ní “ẹ̀mí mímọ́,” tàbí “ẹ̀mí ìjẹ́mímọ́.” (Jòhánù 14:26; Róòmù 1:4) Nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́, Jèhófà ń fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lágbára láti wàásù ìhìn rere. (Ìṣe 1:8; 4:31) Jèhófà ń fi ẹ̀mí rẹ̀ fún “àwọn tí ń ṣègbọràn sí i gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso,” ìyẹn àwọn tó ‘ń rìn nípa ẹ̀mí,’ kì í fi fún àwọn tó ń rìn nípa ìfẹ́ tara. (Ìṣe 5:32; Gálátíà 5:16, 25; Róòmù 8:5-8) Agbára tó ń ṣiṣẹ́ ribiribi yìí ló ń mú káwọn Kristẹni ní “èso ti ẹ̀mí,” ìyẹn àwọn ànímọ́ rere àti “ìṣe ìwà mímọ́ àti àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run.” (Gálátíà 5:22, 23; 2 Pétérù 3:11) Bí ẹ̀mí mímọ́ bá jẹ́ ohun mímọ́ lójú wa, a ò ní ṣe ohunkóhun tó lè kó ẹ̀dùn-ọkàn bá ẹ̀mí yẹn tàbí ohun tó lè dènà rẹ̀ nínú ìgbésí ayé wa.—Éfésù 4:30.
14. Àǹfààní wo làwọn ẹni àmì òróró kà sí ohun mímọ́, báwo sì ni àwọn àgùntàn mìíràn ṣe ń nípìn-ín nínú àǹfààní náà?
14 Àǹfààní tá a ní láti máa jẹ́ orúkọ mọ́ Ọlọ́run mímọ́, Jèhófà, àti jíjẹ́ tá a jẹ́ Ẹlẹ́rìí rẹ̀ jẹ́ ohun mìíràn tá a kà sí mímọ́. (Aísáyà 43:10-12, 15) Jèhófà ló ń sọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró di ẹni tó kunjú ìwọ̀n láti “jẹ́ òjíṣẹ́ májẹ̀mú tuntun.” (2 Kọ́ríńtì 3:5, 6) Nítorí náà, Jésù pàṣẹ fún wọn láti wàásù “ìhìn rere ìjọba yìí” kí wọ́n sì “máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.” (Mátíù 24:14; 28:19, 20) Àwọn ẹni àmì òróró ń pa àṣẹ náà mọ́, àìmọye èèyàn tí wọ́n jẹ́ ẹni bí àgùntàn sì ń dara pọ̀ mọ́ wọn, wọ́n ń sọ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ fáwọn ẹni àmì òróró pé: “Àwa yóò bá yín lọ, nítorí a ti gbọ́ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú yín.” (Sekaráyà 8:23) Tayọ̀tayọ̀ làwọn wọ̀nyí ń sìn gẹ́gẹ́ bí “àgbẹ̀” àti “olùrẹ́wọ́ àjàrà” nípa tẹ̀mí fún àwọn “òjíṣẹ́ Ọlọ́run wa” tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró. Lọ́nà yìí, àwọn àgùntàn mìíràn ń ran àwọn ẹni àmì òróró lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà kárí ayé.—Aísáyà 61:5, 6.
15. Iṣẹ́ wo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kà sí iṣẹ́ mímọ́, kí sì nìdí tí àwa náà fi kà á sí iṣẹ́ mímọ́?
15 Àpẹẹrẹ kan ni ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó ka iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ sí ohun mímọ́. Ó sọ pé òun jẹ́ “ìránṣẹ́ gbogbo ènìyàn fún Kristi Jésù sí àwọn orílẹ̀-èdè, tí ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ mímọ́ ti ìhìn rere Ọlọ́run.” (Róòmù 15:16) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé sáwọn Kristẹni ní Kọ́ríńtì, ó pe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ní “ìṣúra.” (2 Kọ́ríńtì 4:1, 7) Nípasẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tá à ń ṣe fún gbogbo èèyàn, à ń sọ “àwọn ọ̀rọ̀ ìkéde ọlọ́wọ̀ Ọlọ́run” fún àwọn èèyàn. (1 Pétérù 4:11) Nítorí náà, yálà a jẹ́ ara àwọn ẹni àmì òróró tàbí àgùntàn mìíràn, a ka kíkópa tá à ń kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù sí àǹfààní mímọ́.
“Kí A Máa Sọ Ìjẹ́mímọ́ Di Pípé Nínú Ìbẹ̀rù Ọlọ́run”
16. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti má ṣe dẹni tí “kò mọrírì àwọn ohun ọlọ́wọ̀”?
16 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ fún àwọn Kristẹni bíi tirẹ̀ pé kí wọn má ṣe dẹni tí “kò mọrírì àwọn ohun ọlọ́wọ̀.” Kàkà bẹ́ẹ̀, ó gbà wọ́n nímọ̀ràn láti máa ‘lépa ìsọdimímọ́,’ kí wọ́n máa ‘ṣọ́ra gidigidi kí gbòǹgbò onímájèlé kankan má bàa rú yọ, kí ó sì dá ìjàngbọ̀n sílẹ̀ àti kí a má bàa sọ ọ̀pọ̀ di ẹlẹ́gbin nípasẹ̀ rẹ̀.’ (Hébérù 12:14-16) Gbólóhùn náà “gbòǹgbò onímájèlé” ń sọ nípa àwọn kan nínú ìjọ Kristẹni tí wọ́n lè máa ṣàríwísí àwọn ọ̀nà tá à ń gbà ṣe nǹkan. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè má fara mọ́ ojú tí Jèhófà fi ń wo jíjẹ́ tí ìgbéyàwó jẹ́ mímọ́ tàbí jíjẹ́ tá a gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́ nínú ìwà wa. (1 Tẹsalóníkà 4:3-7; Hébérù 13:4) Ohun mìíràn ni pé wọ́n lè máa tan èrò àwọn apẹ̀yìndà kálẹ̀, ìyẹn ‘àwọn òfìfo ọ̀rọ̀ tí ó máa ń fi àìmọ́ ba ohun mímọ́ jẹ́’ tí àwọn tí wọ́n “ti yapa kúrò nínú òtítọ́” máa ń sọ.—2 Tímótì 2:16-18.
17. Kí nìdí táwọn ẹni àmì òróró fi gbọ́dọ̀ máa sapá nígbà gbogbo láti ní èrò tí Jèhófà ní nípa ìjẹ́mímọ́?
17 Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sáwọn ẹni àmì òróró bíi tirẹ̀ pé: “Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹ jẹ́ kí a wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ẹran ara àti ti ẹ̀mí, kí a máa sọ ìjẹ́mímọ́ di pípé nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run.” (2 Kọ́ríńtì 7:1) Gbólóhùn yìí fi hàn pé àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, ìyẹn àwọn “alábàápín ìpè ti ọ̀run,” gbọ́dọ̀ máa sapá nígbà gbogbo láti fi hàn pé àwọn ní èrò tí Jèhófà ní nípa ìjẹ́mímọ́ nínú gbogbo ohun tí wọ́n bá ń ṣe nígbèésí ayé wọn. (Hébérù 3:1) Bákan náà, àpọ́sítélì Pétérù gba àwọn tí Ọlọ́run fẹ̀mí bí, níyànjú pé: “Gẹ́gẹ́ bí onígbọràn ọmọ, ẹ jáwọ́ nínú dídáṣà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìfẹ́-ọkàn tí ẹ ti ní tẹ́lẹ̀ rí nínú àìmọ̀kan yín, ṣùgbọ́n, ní ìbámu pẹ̀lú Ẹni Mímọ́ tí ó pè yín, kí ẹ̀yin fúnra yín pẹ̀lú di mímọ́ nínú gbogbo ìwà yín.”—1 Pétérù 1:14, 15.
18, 19. (a) Báwo làwọn tó jẹ́ ara “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ṣe ń fi hàn pé ojú tí Jèhófà fi ń wo ohun mímọ́ làwọn náà fi ń wò ó? (b) Ohun mìíràn wo tó jẹ́ mímọ́ nínú ìgbésí ayé àwa Kristẹni la óò gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí?
18 Ǹjẹ́ àwọn tó jẹ́ “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tí yóò la “ìpọ́njú ńlá” já ní láti sapá? Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn náà gbọ́dọ̀ fi hàn pé àwọn ní èrò tí Jèhófà ní nípa àwọn ohun mímọ́. Ìwé Ìṣípayá sọ pé, wọ́n ń ṣe “iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀” sí Jèhófà nínú àgbàlá tẹ́ńpìlì rẹ̀ tẹ̀mí ti orí ilẹ̀ ayé. Wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Kristi. Lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ ‘wọ́n ń fọ aṣọ wọn, wọ́n sì ń sọ wọ́n di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.’ (Ìṣípayá 7:9, 14, 15) Èyí mú kí wọ́n jẹ́ ẹni tó mọ́ lójú Jèhófà, èyí sì mú kó pọn dandan fún wọn láti máa ‘wẹ ara wọn mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ẹran ara àti ti ẹ̀mí, kí wọ́n sì máa sọ ìjẹ́mímọ́ di pípé nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run.’
19 Pípàdé déédéé láti jọ́sìn Jèhófà àti láti kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́ ohun tó ṣe pàtàkì nínú ìgbésí ayé àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn. Ohun mímọ́ ni Jèhófà sì ka ìkórajọ àwọn èèyàn rẹ̀ sí. Ọ̀nà tá a lè gbà máa fi ojú tí Jèhófà fi ń wo ohun mímọ́ wo ìkórajọ tó ṣe pàtàkì yìí, àti ìdí tó fi yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀, la óò gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.
Àtúnyẹ̀wò
• Irú èrò táwọn èèyàn ayé ní wo làwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kò ní?
• Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ọ̀dọ̀ Jèhófà ni gbogbo ohun mímọ́ ti wá?
• Báwo la ṣe ń fi hàn pé à ń fọ̀wọ̀ hàn fún jíjẹ́ tí Kristi jẹ́ mímọ́?
• Àwọn ohun wo ló yẹ ká kà sí mímọ́ ní ìgbésí ayé wa?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, Ọlọ́run sọ pé kí wọ́n ka iṣẹ́ àlùfáà, àgọ́ ìjọsìn, àtàwọn ohun tó wà nínú rẹ̀ sí mímọ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó wà lórí ilẹ̀ ayé ni tẹ́ńpìlì mímọ́
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Àdúrà àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa jẹ́ àǹfààní mímọ́