“Ẹ Máa Tẹ̀ Lé Ìlà Ipa Ọ̀nà Aájò Àlejò”
“Ẹ máa ṣe àjọpín pẹ̀lú àwọn ẹni mímọ́ ní ìbámu pẹ̀lú àwọn àìní wọn. Ẹ máa tẹ̀ lé ìlà ipa ọ̀nà aájò àlejò.”—RÓÒMÙ 12:13.
1. Kí ni àìní pàtàkì kan tí ẹ̀dá ènìyàn ní, báwo ni ó sì ṣe fara hàn ní kedere?
LÓNÌÍ, láti rìn gba òpópónà tí ó dá páro kọjá lálẹ́, ní àdúgbò kan tí ó ṣàjèjì, lè jẹ́ ìrírí tí ń dáni níjì. Ṣùgbọ́n ó lè tojú súni lọ́nà kan náà, bí ènìyàn bá wà láàárín èrò, tí kò mọ ẹnikẹ́ni tàbí tí ẹnikẹ́ni kò mọ̀ ọ́n. Ní tòótọ́, àìní náà láti jẹ́ ẹní tí a bìkítà fún, tí a fẹ́, tí a sì nífẹ̀ẹ́, jẹ́ apá pàtàkì kan lára ànímọ́ ẹ̀dá ènìyàn. Kò sí ẹni tí ń fẹ́ kí a bá òun lò gẹ́gẹ́ bí àlejò tàbí àtọ̀húnrìnwá.
2. Báwo ni Jèhófà ṣe pèsè fún àìní wa fún níní olùbákẹ́gbẹ́pọ̀?
2 Jèhófà Ọlọ́run, Olùṣe àti Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo, mọ àìní ẹ̀dá ènìyàn fún ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ dunjú. Gẹ́gẹ́ bí Olùpète ẹ̀dá ènìyàn tí í ṣe ìṣẹ̀dá rẹ̀, Ọlọ́run mọ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ pé “kò dára kí ọkùnrin náà kí ó nìkan máa gbé,” ó sì ṣe ohun kan nípa rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 2:18, 21, 22) Àkọsílẹ̀ Bíbélì kún fún àwọn àpẹẹrẹ ìṣe inú rere tí Jèhófà àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ fi hàn sí ẹ̀dá ènìyàn. Èyí mú kí ó ṣeé ṣe fún wa láti kọ́ bí a ṣe lè “máa tẹ̀ lé ìlà ipa ọ̀nà àlejò ṣíṣe,” láti lè mú ayọ̀ àti inú dídùn bá àwọn ẹlòmíràn, kí àwa fúnra wa sì ní ìtẹ́lọ́rùn.—Róòmù 12:13.
Nínífẹ̀ẹ́ Àwọn Àlejò
3. Ṣàlàyé ìtumọ̀ pàtàkì tí aájò àlejò ní.
3 Ọ̀rọ̀ náà, “aájò àlejò” gẹ́gẹ́ bí a ti lò ó nínú Bíbélì ni a túmọ̀ láti inú ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, phi·lo·xe·niʹa, tí ó ní ọ̀rọ̀ ìpìlẹ̀ méjì tí ó túmọ̀ sí “ìfẹ́” àti “àlejò.” Nípa báyìí, aájò àlejò ní pàtàkì túmọ̀ sí “ìfẹ́ àlejò.” Ṣùgbọ́n, èyí kì í wulẹ̀ẹ́ ṣe títẹ̀ lé ìlànà kan tàbí ọ̀ràn àyẹ́sí lásán. Ó ní ìmọ̀lára àti ìfẹ́ni ara ẹni nínú. Gẹ́gẹ́ bí ìwé atọ́ka náà, Exhaustive Concordance of the Bible, ti James Strong ti sọ, ọ̀rọ̀ ìṣe náà, phi·leʹo, túmọ̀ sí “láti jẹ́ ọ̀rẹ́ (nífẹ̀ẹ́ [ẹnì kan tàbí ohun kan]), ìyẹn ni pé, ní ìfẹ́ni fún (ní títọ́ka sí níní ìsopọ̀ tímọ́tímọ́ ti ara ẹni, tí ó jẹ́ ọ̀ràn èrò ìmọ̀lára tàbí ìmọ̀lára).” Nítorí náà, aájò àlejò ré kọjá ìfẹ́ tí a gbé karí ìlànà, bóyá tí a ń fi hàn nítorí pé ó jẹ́ ọ̀ranyàn tàbí àìgbọdọ̀máṣe. Ó sábà máa ń jẹ́ ìfihàn ojúlówó ìfẹ́, ìfẹ́ni, àti ìbádọ́rẹ̀ẹ́.
4. Àwọn wo ní ó yẹ kí a fi aájò àlejò hàn sí?
4 Ẹni tí a ń fi ìfẹ́ àti ìfẹ́ni yìí hàn sí ní “àlejò” (Gíríìkì, xeʹnos). Ta ni ẹni yìí lè jẹ́? Lẹ́ẹ̀kan sí i, ìwé Concordance ti Strong túmọ̀ ọ̀rọ̀ náà, xeʹnos, gẹ́gẹ́ bí ‘àjòjì (ní òwuuru, àtìpó, tàbí ní èdè ìṣàpẹẹrẹ ṣẹ̀ṣẹ̀dé); tí ó dọ́gbọ́n túmọ̀ sí àlejò tàbí àjèjì.’ Nítorí náà, aájò àlejò, gẹ́gẹ́ bí a ti fi hàn nínú Bíbélì, lè ṣàgbéyọ inú rere tí a fi hàn sí ẹnì kan tí a nífẹ̀ẹ́, tàbí a lè fi hàn sí àlejò pátápátá pàápàá. Jésù ṣàlàyé pé: “Nítorí bí ẹ̀yin bá nífẹ̀ẹ́ àwọn wọnnì tí wọ́n ń nífẹ̀ẹ́ yín, èrè ẹ̀san wo ni ẹ̀yin ní? Àwọn agbowó-orí kò ha ń ṣe ohun kan náà bí? Bí ẹ̀yin bá sì kí àwọn arákùnrin yín nìkan, ohun àrà ọ̀tọ̀ wo ni ẹ̀yin ń ṣe? Àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú kò ha ń ṣe ohun kan náà bí?” (Mátíù 5:46, 47) Ojúlówó aájò àlejò ré kọjá ìpínyà àti àìbánilò lọ́gbọọgba tí ẹ̀tanú àti ìbẹ̀rù ń fà.
Jèhófà, Olùgbàlejò Pípé
5, 6. (a) Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tí ó wí pé, “Bàbá yín ọ̀run . . . jẹ́ pípé”? (b) Báwo ni a ṣe fòye mọ ìwà ọ̀làwọ́ Jèhófà?
5 Lẹ́yìn títọ́ka sí àìkúnjú ìwọ̀n tí ń bẹ nínú ìfẹ́ tí ẹ̀dá ènìyàn ń fi hàn sí ara wọn lẹ́nì kíní kejì gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ lókè, Jésù fi ọ̀rọ̀ yìí kún un pé: “Ẹ̀yin gbọ́dọ̀ jẹ́ pípé bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, bí Bàbá yín ọ̀run ti jẹ́ pípé.” (Mátíù 5:48) Dájúdájú, Jèhófà jẹ́ pípé ní gbogbo ọ̀nà. (Diutarónómì 32:4) Bí ó ti wù kí ó rí, Jésù ń tẹnu mọ́ apá pàtàkì kan ti ìjẹ́pípé Jèhófà, gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ ṣáájú pé: “[Ọlọ́run] ń mú kí oòrùn rẹ̀ là sórí àwọn ènìyàn burúkú àti rere tí ó sì ń mú kí òjò rọ̀ sórí àwọn olódodo àti aláìṣòdodo.” (Mátíù 5:45) Nígbà tí ó bá kan fífi inú rere hàn, Jèhófà kì í ṣe ojúsàájú.
6 Gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́dàá, Jèhófà ni ó ni ohun gbogbo. Jèhófà wí pé: “Gbogbo ẹran igbó ni ti èmi, àti ẹrankẹ́ran lórí ẹgbẹ̀rún òkè. Èmi mọ gbogbo ẹyẹ àwọn òkè ńlá: àti ẹranko ìgbẹ́ ni ti èmi.” (Orin Dáfídì 50:10, 11) Síbẹ̀, òun kò fi ìmọtara ẹni nìkan fawọ́ ohunkóhun sẹ́yìn. Láti inú ìwà ọ̀làwọ́ rẹ̀, ó ń pèsè fún gbogbo ẹ̀dá rẹ̀. Onísáàmù sọ nípa Jèhófà pé: “Ìwọ ṣí ọwọ́ rẹ, ìwọ sì tẹ́ ìfẹ́ gbogbo ohun alààyè lọ́rùn.”—Orin Dáfídì 145:16.
7. Kí ni a lè kọ́ láti inú ọ̀nà tí Jèhófà gbà bá àwọn àlejò àti àwọn tí wọ́n ṣaláìní lò?
7 Jèhófà ń fún àwọn ènìyàn ní ohun tí wọ́n ṣaláìní—àní àwọn ènìyàn tí kò mọ̀ ọ́n, tí wọ́n jẹ́ àjèjì sí i pàápàá. Pọ́ọ̀lù àti Bánábà rán àwọn olùjọsìn òrìṣà ní ìlú Lísírà létí pé, Jèhófà “kò fi ara rẹ̀ sílẹ̀ láìsí ẹ̀rí ní ti pé ó ṣe rere, ó ń fún yín ní òjò láti ọ̀run àti àwọn àsìkò eléso, ó ń fi oúnjẹ àti ìmóríyágágá kún ọkàn-àyà yín dé ẹ̀kún rẹ́rẹ́.” (Ìṣe 14:17) Jèhófà jẹ́ onínúure àti ọ̀làwọ́, ní pàtàkì sí àwọn tí ó ṣe aláìní. (Diutarónómì 10:17, 18) Ọ̀pọ̀ nǹkan ni a lè rí kọ́ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà ní fífi inú rere àti ìwà ọ̀làwọ́ hàn—ní fífi aájò àlejò hàn—sí àwọn ẹlòmíràn.
8. Báwo ni Jèhófà ṣe fi ìwà ọ̀làwọ́ rẹ̀ hàn ní bíbójú tó àwọn àìní wa nípa tẹ̀mí?
8 Ní àfikún sí pípèsè lọ́pọ̀ yanturu fún àwọn àìní tí ara àwọn ẹ̀dá rẹ̀, Jèhófà ń bójú tó àìní wọn nípa tẹ̀mí. Jèhófà gbégbèésẹ̀ lọ́nà gíga lọ́lá jù lọ nítorí ire wa nípa tẹ̀mí, àní kí ẹnikẹ́ni nínú wa tò mọ́ pé a wà ní ipò àìnírètí nípa tẹ̀mí. A kà nínú Róòmù 5:8, 10 pé: “Ọlọ́run dámọ̀ràn ìfẹ́ tirẹ̀ fún ìtẹ́wọ́gbà wa ní ti pé, nígbà tí àwa ṣì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa. . . . Nígbà tí àwa jẹ́ ọ̀tá, a mú wa padà bá Ọlọ́run rẹ́ nípasẹ̀ ikú Ọmọkùnrin rẹ̀.” Ìpèsè yẹn mú kí ó ṣeé ṣe fún ẹ̀dá ènìyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ láti wá sínú ipò ìbátan ìdílé aláyọ̀ pẹ̀lú Bàbá wa ọ̀run. (Róòmù 8:20, 21) Jèhófà tún rí i dájú pé a pèsè ìtọ́sọ́nà àti ìdarí tí ó tọ́ fún wa, kí a baà lè ṣe àṣeyọrí nínú ìgbésí ayé láìka ipò ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé wa sí.—Orin Dáfídì 119:105; Tímótì Kejì 3:16.
9, 10. (a) Èé ṣe tí a fi lè sọ pé Jèhófà ni olùgbàlejò pípé? (b) Báwo ni ó ṣe yẹ kí àwọn olùjọsìn tòótọ́ fara wé Jèhófà nínú èyí?
9 Pẹ̀lú ohun tí a ti jíròrò yìí, a lè sọ pé Jèhófà, ní tòótọ́, jẹ́ olùgbàlejò pípé lọ́pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà. Kì í gbójú fo àwọn aláìní, àwọn mẹ̀kúnnù, àti àwọn ẹni rírẹlẹ̀ dá. Ó ń fi ọkàn-ìfẹ́, àti ìdàníyàn tí ó jẹ́ ojúlówó hàn fún àwọn àlejò, àní sí àwọn ọ̀tá rẹ̀ pàápàá, kì í sì í wọ̀nà fún èrè kankan. Nínú gbogbo èyí, kì í ha í ṣe òun ni àpẹẹrẹ gíga lọ́lá jù lọ ti olùgbàlejò pípé kan?
10 Gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run tí ó ní irú ìfẹ́ inú rere àti ìwà ọ̀làwọ́ bẹ́ẹ̀, Jèhófà fẹ́ kí àwọn olùjọsìn rẹ̀ fara wé e. Jálẹ̀ Bíbélì, a rí àwọn àpẹẹrẹ títa yọ nípa ànímọ́ inú rere yìí. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, Encyclopaedia Judaica, sọ pé, “ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, aájò àlejò kì í ṣe ọ̀ràn ìwà rere lásán, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ìgbékalẹ̀ ọ̀nà ìwà híhù . . . Àṣà tí ó bá Bíbélì mu ti kíkí arìnrìn àjò tí ó ti rẹ̀ tẹnutẹnu káàbọ̀, àti ti gbígba àlejò mọ́ra ni orísun tí aájò àlejò àti gbogbo apá tí ó jẹ mọ́ ọn ti jẹyọ, tí ó sì di ìwà yíyẹ tí a gbé gẹ̀gẹ̀ gidigidi nínú òfin àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn Júù.” Dípò kí ó jẹ́ ànímọ́ ìdánimọ̀ fún orílẹ̀-èdè tàbí àwùjọ ẹ̀yà ìbílẹ̀ èyíkéyìí, aájò àlejò yẹ kí ó jẹ́ ohun tí a fi ń dá gbogbo olùjọsìn tòótọ́ fún Jèhófà mọ̀ yàtọ̀.
Olùgbàlejò Àwọn Áńgẹ́lì
11. Àpẹẹrẹ títa yọ wo ni ó fi hàn pé aájò àlejò mú àwọn ìbùkún tí a kò fojú sọ́nà fún wa? (Tún wo Jẹ́nẹ́sísì 19:1-3; Àwọn Onídàájọ́ 13:11-16.)
11 Ọ̀kan nínú àkọsílẹ̀ Bíbélì nípa fífi aájò àlejò hàn tí a mọ̀ jù lọ ni ti Ábúráhámù àti Sárà nígbà tí wọ́n ń pàgọ́ láàárín àwọn igi ńlá Mámúrè, lẹ́bàá Hébúrónì. (Jẹ́nẹ́sísì 18:1-10; 23:19) Ó dájú pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní ìṣẹ̀lẹ̀ yìí lọ́kàn nígbà tí ó ń pèsè ìṣílétí yìí: “Ẹ má ṣe gbàgbé aájò àlejò, nítorí nípasẹ̀ rẹ̀ àwọn kan ṣe àwọn áńgẹ́lì lálejò, láìjẹ́ pé àwọn fúnra wọn mọ̀.” (Hébérù 13:2) Kíkẹ́kọ̀ọ́ àkọsílẹ̀ yìí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti rí i pé aájò àlejò kì í wulẹ̀ ṣe ọ̀ràn àṣà lásán tàbí bí a ṣe tọ́ni dàgbà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ ànímọ́ oníwà-bí-Ọlọ́run tí ń mú ìbùkún àgbàyanu wá.
12. Báwo ni Ábúráhámù ṣe fi ìfẹ́ rẹ̀ fún àwọn àlejò hàn?
12 Jẹ́nẹ́sísì 18:1, 2 fi hàn pé Ábúráhámù kò mọ àwọn àlejò náà, kò sì retí wọn, àfi bí ẹni pé àjèjì mẹ́ta wulẹ̀ ń kọja lọ ni. Gẹ́gẹ́ bí àwọn sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ kan ti sọ, àṣà tí ó wà láàárín àwọn ará Gábásì ni pé arìnrìn àjò kan, ní ilẹ̀ àjèjì, ní ẹ̀tọ́ láti retí aájò àlejò, àní bí kò bá tilẹ̀ mọ ẹnikẹ́ni níbẹ̀. Ṣùgbọ́n Ábúráhámù kò dúró di ìgbà tí àwọn àlejò náà yóò béèrè fún ẹ̀tọ́ wọn; ó lo ìdánúṣe. Ó “sáré” láti pàdé àwọn àlejò wọ̀nyí, tí wọ́n jìnnà sí i díẹ̀—gbogbo èyí jẹ́ nínú “ìmóoru ọjọ́,” Ábúráhámù sì jẹ́ ẹni ọdún 99! Èyí kò ha fi ìdí tí Pọ́ọ̀lù fi tọ́ka sí Ábúráhámù gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ fún wa láti tẹ̀ lé hàn bí? Ohun tí aájò àlejò jẹ́ nìyẹn, nínífẹ̀ẹ́ tàbí níní ìfẹ́ni fún àlejò, dídàníyàn nípa àìní wọn. Ó jẹ́ ànímọ́ rere.
13. Èé ṣe tí Ábúráhámù fi “tẹrí ba” fún àwọn àlejò náà?
13 Àkọsílẹ̀ náà tún sọ fún wa pé lẹ́yìn tí ó ti pàdé àwọn àjèjì náà, Ábúráhámù “tẹrí ba sílẹ̀.” Ṣe ó ń tẹrí ba fún àwọn àjèjì tí wọ́n jẹ́ ẹni pípé ni? Tóò, ìtẹríba, gẹ́gẹ́ bí Ábúráhámù ti ṣe, jẹ́ ọ̀kan nínú ọ̀nà tí a ń gbà kí àjèjì tí a bọlá fún, tàbí ẹnì kan tí ó wà ní ipò gíga, a kò ní láti rò pé ó jẹ́ ìṣe ìjọsìn, tí ó wà fún Ọlọ́run nìkan ṣoṣo. (Fi wé Ìṣe 10:25, 26; Ìṣípayá 19:10.) Nípa títẹrí ba, kì í wulẹ̀ í ṣe títẹ orí lásán, ṣùgbọ́n títẹrí ba “sílẹ̀,” Ábúráhámù fún àwọn àjèjì wọ̀nyí ní ọlá pé wọ́n ṣe pàtàkì. Òun jẹ́ olórí ìdílé ńlá ti baba-ńlá aláásìkí kan, síbẹ̀ ó ka àwọn àjèjì wọ̀nyí sí ẹni tí ó yẹ fún ọlá tí ó ju tirẹ̀ lọ. Ẹ wo bí èyí ṣe yàtọ̀ sí àṣà fífura sí àwọn àjèjì, ìṣarasíhùwà jẹ́-á-wo-rú-ẹni-yóò-jẹ́! Ábúráhámù ní ti tòótọ́ ṣàfihàn ìtúmọ̀ gbólóhùn náà pé: “Nínú bíbu ọlá fún ara yín lẹ́nì kíní kejì ẹ mú ipò iwájú.”—Róòmù 12:10.
14. Ìsapá àti ìrúbọ wo ni Ábúráhámù ṣe láti fi aájò àlejò hàn sí àwọn àlejò náà?
14 Èyí tí ó kù nínú àkọsílẹ̀ náà fi hàn pé ìmọ̀lára Ábúráhámù jẹ́ ojúlówó. Àrà ọ̀tọ̀ ni oúnjẹ náà alára. Àní nínú agboolé ńlá tí wọ́n ti ní ohun ọ̀sìn púpọ̀ pàápàá, wọn kì í ṣàdédé jẹ “ẹgbọọrọ akọ màlúù kan tí ó rọ̀ tí ó dára.” Nípa àwọn àṣà tí ó wọ́pọ̀ ní agbègbè náà, ìwé náà, Daily Bible Illustrations, ti John Kitto sọ pé: “Wọn kì í ṣàdédé gbáfẹ́ àfi nígbà àwọn àjọyọ̀ kan, tàbí nígbà tí àlejò kan bá dé; ìgbà yẹn nìkan sì ni wọ́n máa ń jẹ ẹran, títí kan àwọn tí ó ní ọ̀pọ̀ agbo ẹran àti ọ̀wọ́ ẹran pàápàá.” Ojú ọjọ́ tí ń móoru kì í jẹ́ kí wọ́n tọ́jú oúnjẹ èyíkéyìí tí ó lè bàjẹ́, nítorí náà láti gbọ́ irú oúnjẹ bẹ́ẹ̀, ojú ẹsẹ̀ ni a óò ṣe gbogbo rẹ̀. Kò yani lẹ́nu pé nínú àkọsílẹ̀ kúkúrú yìí, ọ̀rọ̀ náà “yára” tàbí “sì yára” fara hàn nígbà mẹ́ta, Ábúráhámù ní ti gidi sì “sáré” láti mú kí oúnjẹ náà wà ní sẹpẹ́!—Jẹ́nẹ́sísì 18:6-8.
15. Kí ni ojú ìwòye tí ó tọ́ nípa àwọn ìpèsè ohun ìní ti ara nígbà tí a bá ń fi aájò àlejò hàn, gẹ́gẹ́ bí Ábúráhámù ti fi àpẹẹrẹ rẹ̀ hàn?
15 Ṣùgbọ́n, kì í ṣe nítorí ètè àtiṣe oúnjẹ rẹpẹtẹ láti ṣí ẹnì kan lórí ni ó fi ṣe é. Àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ábúráhámù àti Sárà ṣe gbogbo ìsapá yẹn láti gbọ́ oúnjẹ náà, tí wọ́n sì gbé e kalẹ̀, kíyè sí bí Ábúráhámù ṣe tọ́ka sí i ní ìṣáájú pé: “Jẹ́ kí a mú omi díẹ̀ wá nísinsìnyí, kí ẹ̀yin kí ó sì wẹ ẹsẹ̀ yín, kí ẹ̀yin kí ó sì sinmi lábẹ́ igi. Èmi óò sì mú oúnjẹ díẹ̀ wá, kí ẹ̀yin sì fi ọkàn yín balẹ̀; lẹ́yìn èyíinì kí ẹ̀yin máa kọjá lọ: ǹjẹ́ nítorí náà ni ẹ̀yin ṣe tọ ọmọ ọ̀dọ̀ yín wá.” (Jẹ́nẹ́sísì 18:4, 5) “Oúnjẹ díẹ̀” yẹn wá di àsè ọmọ màlúù sísanra pẹ̀lú àkàrà róbótó tí a fi ìyẹ̀fun dáradára, bọ́tà, àti wàrà ṣe—oúnjẹ ọba. Kí ni ẹ̀kọ́ tí ó wà níbẹ̀? Nígbà tí a bá ń fi aájò àlejò hàn, ohun tí ó ṣe pàtàkì, tàbí ohun tí a ní láti tẹnu mọ́, kì í ṣe bí oúnjẹ àti ohun mímu náà yóò ti kúnlé kúnnà tó, tàbí eré ìnàjú gígọntíọ tí a óò pèsè, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Aájò àlejò kò sinmi lórí bóyá agbára ẹnì kan lè ká àwọn nǹkan olówó gọbọi. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sinmi lórí àníyàn ojúlówó fún ire àwọn ẹlòmíràn àti èyí tí ó sinmi lórí ìfẹ́ ọkàn láti ṣe rere fún àwọn ẹlòmíràn débi tí ẹnì kan bá lè ṣe é dé. Òwe Bíbélì kan sọ pé: “Oúnjẹ ewébẹ̀ níbi tí ìfẹ́ wà, ó sàn ju àbọ́pa màlúù lọ àti ìríra pẹ̀lú rẹ̀,” ìyẹn sì ni kọ́kọ́rọ́ náà sí ojúlówó aájò àlejò.—Òwe 15:17.
16. Báwo ni Ábúráhámù ṣe fi ìmọrírì hàn fún àwọn nǹkan tẹ̀mí nínú ohun tí ó ṣe fún àwọn àlejò náà?
16 Ṣùgbọ́n, a gbọ́dọ̀ kíyè sí i pé, ìjẹ́pàtàkì tẹ̀mí tún wà nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà látòkè délẹ̀. Bákan ṣáá, Ábúráhámù fòye mọ̀ pé àwọn àlejò wọ̀nyí jẹ́ ońṣẹ́ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà. Èyí fara hàn nínú ọ̀nà tí ó gbà bá wọn sọ̀rọ̀ pé: “Olúwa mi, ǹjẹ́ bí mo bá rí ore ọ̀fẹ́ ní ojú rẹ, èmi bẹ̀ ọ́, má ṣe kọjá lọ kúrò lọ́dọ̀ ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀.”a (Jẹ́nẹ́sísì 18:3; fi wé Ẹ́kísódù 33:20.) Ábúráhámù kò mọ̀ tẹ́lẹ̀ bóyá wọ́n ni ìhìn iṣẹ́ fún un tàbí bóyá wọ́n wulẹ̀ ń kọjá lọ ni. Láìka ìyẹn sí, ó mọrírì rẹ̀ pé, àṣeparí ète Jèhófà ń lọ lọ́wọ́. Àwọn ẹni wọ̀nyí wà lẹ́nu iṣẹ́ àṣẹ kan ṣá láti ọ̀dọ̀ Jèhófà. Bí òun bá lè ṣe ohun kan láti lọ́wọ́ sí ìyẹn, yóò jẹ́ ìdùnnú rẹ̀. Ó mọ̀ pé àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lẹ́tọ̀ọ́ sí ohun tí ó dára jù lọ, òun yóò sì pèsè ohun tí ó dára jù lọ lábẹ́ àyíká ipò náà. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ìbùkún tẹ̀mí yóò wà, yálà fún òun alára tàbí fún ẹlòmíràn kan. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, a bù kún Ábúráhámù àti Sárà gidigidi fún aájò àlejò tí wọ́n ṣe tọkàntọkàn.—Jẹ́nẹ́sísì 18:9-15; 21:1, 2.
Àwọn Ènìyàn Ẹlẹ́mìí Aájò Àlejò
17. Kí ni Jèhófà ń béèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa àwọn àlejò àti aláìní tí ń bẹ láàárín wọn?
17 Orílẹ̀-èdè tí ó ti ọ̀dọ̀ Ábúráhámù jáde kì yóò gbàgbé àpẹẹrẹ títa yọ rẹ̀. Òfin tí Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi àyè sílẹ̀ fún fífi aájò àlejò hàn sí àwọn àlejò tí ń bẹ láàárín wọn. “Kí àlejò tí ń báa yín gbé kí ó já sí fún yín bí ìbílẹ̀, kí ìwọ kí ó sì fẹ́ ẹ bí ara rẹ; nítorí pé ẹ̀yin ti ṣe àlejò ní ilẹ̀ Íjíbítì: Èmi ni OLÚWA Ọlọ́run yín.” (Léfítíkù 19:34) Àwọn ènìyàn náà gbọ́dọ̀ gba ti àwọn tí wọ́n nílò ìrànwọ́ ohun ìní ti ara rò ní pàtàkì, wọ́n kò sì gbọdọ̀ ta wọ́n nù. Nígbà tí Jèhófà bá fi ìkórè yanturu bù kún wọn, nígbà tí wọ́n bá ń yọ̀ nínú àjọyọ̀ wọn, nígbà tí wọ́n bá sinmi kúrò nínú iṣẹ́ wọn ní àwọn ọdún Sábáàtì, àti nígbà àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ míràn, àwọn ènìyàn náà gbọ́dọ̀ rántí àwọn tí nǹkan kò ṣẹnuure fún—àwọn opó, àwọn ọmọ aláìníbàbá, àti àwọn àtìpó olùgbé.—Diutarónómì 16:9-14; 24:19-21; 26:12, 13.
18. Báwo ní aájò àlejò ti ṣe pàtàkì tó ní ìsopọ̀ pẹ̀lú rírí ojú rere Jèhófà àti ìbùkún rẹ̀ gbà?
18 A lé rí ìjẹ́pàtàkì fífi inú rere, ìwà ọ̀làwọ́, àti aájò àlejò hàn sí àwọn ẹlòmíràn, ní pàtàkì sí àwọn tí ń bẹ nínú àìní, nínú ọ̀nà tí Jèhófà gbà bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lò nígbà tí wọ́n kọ̀ láti lo àwọn ànímọ́ wọ̀nyí. Jèhófà mú un ṣe kedere pé fífi inú rere àti ìwà ọ̀làwọ́ hàn sí àwọn àlejò àti aláìní wà lára ohun àbéèrèfún lọ́wọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ láti lè máa gba ìbùkún rẹ̀ tí kò dáwọ́ dúró. (Orin Dáfídì 82:2, 3; Aísáyà 1:17; Jeremáyà 7:5-7; Ìsíkẹ́ẹ̀lì 22:7; Sekaráyà 7:9-11) Nígbà tí orílẹ̀-èdè náà ń fi taápọntaápọn ṣe ìwọ̀nyí àti àwọn ohun àbéèrèfún mìíràn, wọ́n láásìkí, wọ́n sì gbádùn ọ̀pọ̀ yanturu ohun tí ara àti ti ẹ̀mí. Nígbà tí wọ́n ri ara wọn bọnú àwọn ìlépa onímọtara-ẹni-nìkan wọn, tí wọ́n sì kọ̀ láti fi àwọn ànímọ́ inú rere wọ̀nyí hàn sí àwọn tí wọ́n ṣaláìní, wọ́n gba ìdálẹ́bi Jèhófà, a sì fún wọn ní ìdájọ́ tí kò bára dé lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.—Diutarónómì 27:19; 28:15, 45.
19. Kí ni a gbọ́dọ̀ gbé yẹ̀ wò síwájú sí i?
19 Nígbà náà, ẹ wo bí ó ti ṣe pàtàkì tó fún wa láti wádìí ara wa, kí a sì mọ̀ bóyá àwa ń kúnjú àwọn ohun tí Jèhófà ń fojú sọ́nà fún lórí èyí! Èyí rí bẹ́ẹ̀ ní pàtàkì lónìí lójú ìwòye ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan àti ẹ̀mí ìpinyà tí ń bẹ nínú ayé. Báwo ni a ṣe lè fi aájò àlejò ti Kristẹni hàn nínú ayé tí ó pínyà? Kókó ẹ̀kọ́ yẹn ni a jíròrò nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀ lé e.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún ìjíròrò lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ lórí kókó yìí, wo ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà, “Ẹnikẹni Ha Ti Rí Ọlọrun Bí?” nínú Ilé-Ìṣọ́nà, May 15, 1988, ojú ìwé 21 sí 23.
Ìwọ Ha Rántí Bí?
◻ Kí ni ìtúmọ̀ ọ̀rọ̀ Bíbélì náà tí a túmọ̀ sí “aájò àlejò”?
◻ Lọ́nà wo ni Jèhófà gbà jẹ́ àpẹẹrẹ pípé nínú fífi aájò àlejò hàn?
◻ Báwo ni Ábúráhámù ti lọ jìnnà tó láti jẹ́ ẹlẹ́mìí aájò àlejò?
◻ Èé ṣe tí gbogbo àwọn olùjọsìn tòótọ́ fi gbọ́dọ̀ “máa tẹ̀ lé ìlà ipa ọ̀nà aájò àlejò”?