Jèhófà Kì Yóò Fi Ọ́ Sílẹ̀ Lọ́nàkọnà
ÀWỌN Kristẹni tó wà ní Jùdíà ń fojú winá àtakò tó lékenkà, àárín àwọn tó nífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì bí nǹkan míì ni wọ́n tún ń gbé. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fa ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì lákòókò tí wọ́n fẹ́ wọ Ilẹ̀ Ìlérí yọ láti fi gbà wọ́n níyànjú. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Dájúdájú, èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà.” (Hébérù 13:5; Diutarónómì 31:6) Ó dájú pé ìlérí yẹn fún àwọn Hébérù tó jẹ́ Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní lókun nípa tẹ̀mí.
Ó yẹ kí ìlérí kan náà yìí fún wa lókun tó máa jẹ́ ká lè fara da ìṣòro tó ń jẹ yọ nítorí gbígbé tá à ń gbé ní “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” yìí. (2 Tímótì 3:1) Tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà tá a sì ń ṣe ohun tó fi hàn pé lóòótọ́ la gbẹ́kẹ̀ lé e, Jèhófà ò ní fi wá sílẹ̀ àní nígbà ìṣòro tó le koko pàápàá. Ká lè mọ bí Jèhófà ṣe ń mú ìlérí rẹ̀ yìí ṣẹ, ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ ìgbà tí iṣẹ́ bá bọ́ lọ́wọ́ ẹni yẹ̀ wò.
Ìgbà Tí Ohun Tá Ò Rò Tẹ́lẹ̀ Bá Ṣẹlẹ̀
Ńṣe ni iye àwọn tí kò níṣẹ́ lọ́wọ́ túbọ̀ ń pọ̀ sí i jákèjádò ayé. Ìwé ìròyìn kan lórílẹ̀-èdè Poland sọ pé àìníṣẹ́lọ́wọ́ “jẹ́ ọ̀kan lára ìṣòro tó ga jù lọ láwùjọ.” Kódà, àwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà pàápàá níṣòro yẹn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó fi máa di ọdún 2004, iye àwọn tí kò níṣẹ́ lọ́wọ́ láwọn orílẹ̀-èdè tí ń bẹ nínú Àjọ Tó Wà fún Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àti Ìdàgbàsókè Ètò Ọrọ̀ Ajé “ti fò sókè sí mílíọ̀nù méjìlélọ́gbọ̀n. Iye yìí sì ju iye àwọn tí kò níṣẹ́ lọ́wọ́ láwọn ọdún 1930 nígbà tí ọrọ̀ ajé dẹnu kọlẹ̀ lágbàáyé.” Iléeṣẹ́ Tí Ń Ṣe Ìṣirò Àwọn Nǹkan lórílẹ̀-èdè Poland sọ pé títí di oṣù December ọdún 2003, mílíọ̀nù mẹ́ta èèyàn ni kò níṣẹ́ lọ́wọ́ lórílẹ̀-èdè náà, tó túmọ̀ sí pé “ká ní iye àwọn tó ti dàgbà tẹ́ni tó lè máa ṣiṣẹ́ jẹ́ ọgọ́rùn-ún, méjìdínlógún lára wọn ni kò níṣẹ́ lọ́wọ́.” Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìròyìn kan sọ, ní ọdún 2002 ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ìdajì àwọn ọmọ adúláwọ̀ tó ń gbé ní orílẹ̀-èdè Gúúsù Áfíríkà ni kò níṣẹ́ lọ́wọ́!
Ọ̀pọ̀ èèyàn, títí kan àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà, ló wà nínú ìpọ́njú látàrí bí wọ́n ṣe ṣàdédé dẹni tí kò níṣẹ́ lọ́wọ́ tàbí nítorí dídá tí wọ́n ṣàdédé dá wọn dúró lẹ́nu iṣẹ́. Kò sẹ́ni tí “ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀” kì í ṣẹlẹ̀ sí. (Oníwàásù 9:11) A lè bẹ̀rẹ̀ sí sọ irú ọ̀rọ̀ tí Dáfídì tó jẹ́ onísáàmù sọ pé: “Wàhálà ọkàn-àyà mi ti di púpọ̀.” (Sáàmù 25:17) Ǹjẹ́ wàá lè fàyà rán ipò tí kò rọgbọ yìí? Irú ipò báyìí lè mú kí ìbànújẹ́ dorí ẹni kodò, ó lè ṣàkóbá fún ìjọsìn rẹ sí Ọlọ́run, ó sì lè mú kí àtigbọ́ bùkátà dìṣòro fún ọ. Tó o bá jẹ́ ẹnì kan tí iṣẹ́ ti bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀, ǹjẹ́ o lè wá nǹkan ṣe kí nǹkan bàa lè padà bọ̀ sípò fún ọ?
Ohun Tá A Lè Ṣe Tí Ìbànújẹ́ Ò Fi Ní Dorí Wa Kodò
Afìṣemọ̀rònú-ẹ̀dá kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Janusz Wietrzyński sọ pé: “Tó bá dọ̀rọ̀ kí iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ èèyàn, àwọn ọkùnrin ló máa ń ká lára jù lọ” nítorí pé àwọn làwọn èèyàn gbà pé ó yẹ kó máa gbọ́ bùkátà ìdílé. Ó sọ pé ó lè mú kí ọkùnrin kan “máa hùwà lódì-lódì,” bíi kó máa bínú tàbí kó tiẹ̀ ro ara rẹ̀ pin. Tí wọ́n bá dá ọkùnrin kan dúró lẹ́nu iṣẹ́, ó lè máa ronú pé òun ò níyì mọ́, kó wá bẹ̀rẹ̀ sí “kanra mọ́ ìyàwó àtàwọn ọmọ rẹ̀.”
Ọkùnrin Kristẹni kan tó ń jẹ́ Adam, tó ní ọmọ méjì sọ bí ọ̀ràn ṣe rí lára rẹ̀ nígbà tí iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀, ó ní: “Ńṣe lara mi máa ń gbẹ̀kan, gbogbo nǹkan ló sì máa ń bí mi nínú. Àní lóru pàápàá, iṣẹ́ ni mo fi máa ń lálàá ṣáá àti bí màá ṣe pèsè fáwọn ọmọ mi àti ìyàwó mi tó jẹ́ pé lójijì ni wọ́n dá òun náà dúró lẹ́nu iṣẹ́.” Lákòókò tí iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ Ryszard àti Mariola, tọkọtaya kan tí wọ́n ní ọmọ kan, gbèsè ńlá kan ṣì wà lọ́rùn wọn tí wọn ò tíì san tán ní báńkì. Èyí aya sọ pé: “Gbogbo ìgbà lọkàn mi máa ń gbọgbẹ́, ẹ̀rí ọkàn mi sì máa ń dá mi lẹ́bi nítorí owó tá a lọ yá náà. Ìgbà gbogbo ni mo máa ń rò ó pé èmi ni mo fà á.” Tá a bá bára wa nírú ipò yẹn, inú lè tètè máa bí wa, kí ọkàn wa má balẹ̀ tàbí ká má tiẹ̀ mọ ohun tó yẹ ká ṣe mọ́. Tó bá wá rí bẹ́ẹ̀, kí la lè ṣe tí ìbànújẹ́ ò fi ní dorí wa kodò?
Bíbélì fún wa láwọn ìmọ̀ràn tó wúlò lórí ohun tá a lè ṣe. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbani nímọ̀ràn pé: “Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín nípasẹ̀ Kristi Jésù.” (Fílípì 4:6, 7) Tá a bá gbàdúrà sí Jèhófà, a óò ní “àlàáfíà Ọlọ́run,” ìyẹn ni pé a óò ní ìbàlẹ̀ ọkàn nítorí ìgbàgbọ́ tá a ní nínú Ọlọ́run. Irena, ìyàwó Adam sọ pé: “Nígbà témi àti ọkọ mi bá ń gbàdúrà sí Jèhófà, a máa ń jẹ́ kó mọ ipò tá a wà, a sì máa ń jẹ́ kó mọ ohun tá a fẹ́ ṣe láti mú àwọn ohun tí kò pọn dandan kúrò nígbèésí ayé wa. Baálé mi tó jẹ́ pé kò lè ṣe kó má ṣàníyàn tẹ́lẹ̀ wá bẹ̀rẹ̀ sí rí i pé ìṣòro wa máa níyanjú.”
Tó bá jẹ́ pé iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ rẹ lójijì, á jẹ́ pé o wà nípò tó dára láti fi ìmọ̀ràn tí Jésù Kristi sọ nínú ìwàásù rẹ̀ lórí òkè sílò, ìmọ̀ràn náà ni pé: “Ẹ dẹ́kun ṣíṣàníyàn nípa ọkàn yín, ní ti ohun tí ẹ ó jẹ tàbí ohun tí ẹ ó mu, tàbí nípa ara yín, ní ti ohun tí ẹ ó wọ̀. . . . Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà àti òdodo Rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín.” (Mátíù 6:25, 33) Ìmọ̀ràn yìí ni Ryszard àti Mariola tẹ̀ lé tí ìbànújẹ́ ò fi dorí wọn kodò. Mariola rántí ohun tó ṣẹlẹ̀, ó ní: “Gbogbo ìgbà ni ọkọ mi máa ń tù mí nínú, tó sì máa ń mú un dá mi lójú pé Jèhófà ò ní fi wá sílẹ̀.” Ọkọ rẹ̀ sọ pé: “Àdúrà tí èmi àtìyàwó mi jọ ń gbà déédéé ti mú ká túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run, ó sì ti mú ká túbọ̀ sún mọ́ ara wa, èyí sì ti tù wá nínú gan-an.”
Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run yóò ràn wá lọ́wọ́ pẹ̀lú. Ìkóra-ẹni-níjàánu tí ẹ̀mí yìí ń mú ká ní kò ní jẹ́ ká bara jẹ́, kò sì ní jẹ́ kí àníyàn bò wá mọ́lẹ̀. (Gálátíà 5:22, 23) Ó lè má rọrùn o, àmọ́ ìyẹn ò túmọ̀ sí pé kò ṣeé ṣe nítorí Jésù ṣèlérí pé “Baba tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.”—Lúùkù 11:13; 1 Jòhánù 5:14, 15.
Má Ṣe Pa Àwọn Nǹkan Tẹ̀mí Tì
Bí iṣẹ́ bá bọ́ lọ́wọ́ ẹni láìròtẹ́lẹ̀, ì báà tiẹ̀ jẹ́ Kristẹni tó dàgbà dénú nípa tẹ̀mí pàápàá, ó lè kọ́kọ́ mú kó máa ṣàníyàn. Ṣùgbọ́n kò yẹ ká jẹ́ kí ìyẹn mú wa pa àwọn nǹkan tẹ̀mí tì. Gbé àpẹẹrẹ Mósè tó jẹ́ ọmọ ogójì ọdún yẹ̀ wò. Ìgbésí ayé rẹ̀ yí padà látòkèdélẹ̀ nígbà tí kì í ṣe ara agboolé ọba mọ́, tó wá dẹni tó lọ ń ṣe olùṣọ́ àgùntàn, iṣẹ́ yìí sì jẹ́ iṣẹ́ kan táwọn ará Íjíbítì tẹ́ńbẹ́lú. (Jẹ́nẹ́sísì 46:34) Mósè ní láti jẹ́ kí ipò tó bá ara rẹ̀ yìí bá a lára mu. Ní ogójì ọdún tó tẹ̀ lé e, Mósè jẹ́ kí Jèhófà kọ́ òun kó sì múra òun sílẹ̀ fún iṣẹ́ tó fẹ́ fún òun. (Ẹ́kísódù 2:11-22; Ìṣe 7:29, 30; Hébérù 11:24-26) Láìka àwọn ìṣòro tí Mósè ní sí, ó dúró sán-ún nípa tẹ̀mí, ó sì ṣe tán láti jẹ́ kí Jèhófà kọ́ òun. Ẹ má ṣe jẹ́ ká tìtorí pé nǹkan ò rọgbọ fún wa ká wá pa àwọn nǹkan tẹ̀mí tì!
Lóòótọ́ tí iṣẹ́ bá bọ́ lọ́wọ́ ẹni lójijì, ó lè kó ìdààmú báni, àmọ́ àkókò tó dára nìyẹn láti túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà Ọlọ́run àtàwọn èèyàn rẹ̀. Adam tá a mẹ́nu kàn níṣàájú gbà pé bí ọ̀rọ̀ ṣe rí gan-an nìyẹn. Ó ní: “Lákòókò tí iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ èmi àti ìyàwó mi, a ò fìgbà kankan ronú pé a ò ní lọ sáwọn ìpàdé ìjọ mọ́ tàbí pé a ò ní fọwọ́ dan-indan-in mú iṣẹ́ ìwàásù. Èyí ni ò jẹ́ ká máa ṣàníyàn jù nípa ọ̀la.” Ohun tí Ryszard náà sọ fara jọ ìyẹn, ó ní: “Tí kì í bá ṣe ìpàdé àti iṣẹ́ ìwàásù, ìṣòro náà ì bá ga wá lára, àníyàn ṣíṣe ì bá ti bò wá mọ́lẹ̀ bámúbámú. Ìṣírí ni ọ̀rọ̀ lórí nǹkan tẹ̀mí tí àwa àtàwọn míì jọ máa ń sọ jẹ́ fún wa, nítorí ó máa ń jẹ́ ká mọ́kàn kúrò lórí ìṣòro tiwa ká máa ronú nípa tiwọn.”—Fílípì 2:4.
Bẹ́ẹ̀ ni o, dípò tí wàá fi máa ṣàníyàn nípa iṣẹ́, gbìyànjú láti lo àkókò tí o kò fi ṣiṣẹ́ láti kópa nínú ìgbòkègbodò tẹ̀mí, kó o máa dá kẹ́kọ̀ọ́, kó o máa kópa nínú ìgbòkègbodò ìjọ, kó o sì tẹ̀ síwájú nínú iṣẹ́ ìwàásù. Èyí á jẹ́ kó o ní ‘púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe nínú iṣẹ́ Olúwa’ dípò tí wàá kàn jókòó tẹtẹrẹ torí pé iṣẹ́ ti bọ́ lọ́wọ́ rẹ, yóò sì fún ìwọ àtàwọn olóòótọ́ ọkàn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run tó ò ń wàásù láyọ̀.—1 Kọ́ríńtì 15:58.
Pèsè fún Ìdílé Rẹ Nípa Tara
Àmọ́, oúnjẹ tẹ̀mí nìkan ò lè yó ẹni tí ebi bá ń pa o. Ìlànà kan tó yẹ ká fi sọ́kàn ni pé: “Dájúdájú, bí ẹnì kan kò bá pèsè fún àwọn tí í ṣe tirẹ̀, àti ní pàtàkì fún àwọn tí í ṣe mẹ́ńbà agbo ilé rẹ̀, ó ti sẹ́ ìgbàgbọ́, ó sì burú ju ẹni tí kò ní ìgbàgbọ́.” (1 Tímótì 5:8) Adam sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará tó wà nínú ìjọ máa ń dìde ìrànlọ́wọ́, síbẹ̀ àwa Kristẹni ṣì gbọ́dọ̀ wáṣẹ́ tí a óò máa ṣe.” Òótọ́ ni pé Jèhófà àtàwọn èèyàn rẹ̀ yóò ràn wá lọ́wọ́, àmọ́ kò yẹ ká gbàgbé pé a ṣì ní láti wá nǹkan ṣe.
Àwọn nǹkan wo la lè ṣe? Adam sọ pé: “Má kàn káwọ́ lẹ́rán kó o máa dúró dìgbà tí Ọlọ́run máa ṣèyanu. Nígbà tó o bá ń wáṣẹ́, jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ọ́. Àwọn èèyàn máa ń fẹ́ gba àwọn Ẹlẹ́rìí síṣẹ́.” Ìmọ̀ràn Ryszard ni pé: “Gbogbo àwọn tó o bá mọ̀ pé ó lè bá ọ ríṣẹ́ ni kó o sọ fún, máa lọ sí ọ́fíìsì àwọn tó ń báni wáṣẹ́ déédéé, kó o sì máa wo bébà tàbí ara pátákó táwọn tó ń wá òṣìṣẹ́ máa ń kọ ọ̀rọ̀ sí, irú bíi: ‘À ń wá obìnrin tó lè máa bá wa tọ́jú ọmọ’ tàbí, ‘À ń wá ẹni tí yóò máa bá wa tajà.’ Má ṣe jẹ́ kó sú ẹ! Má sì ṣakọ pé o ò lè ṣe irú iṣẹ́ kan, kódà bó tiẹ̀ jẹ́ iṣẹ́ táwọn èèyàn fojú tẹ́ńbẹ́lú tàbí iṣẹ́ tí kò wù ọ́ pàápàá.”
Bẹ́ẹ̀ ni o, “Jèhófà ni olùrànlọ́wọ́ [rẹ].” Òun kì “yóò fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà.” (Hébérù 13:5, 6) Nítorí náà, kò yẹ kó o máa ṣàníyàn ju bó ṣe yẹ lọ. Dáfídì onísáàmù kọ̀wé pé: “Yí ọ̀nà rẹ lọ sọ́dọ̀ Jèhófà, kí o sì gbójú lé e, òun yóò sì gbé ìgbésẹ̀.” (Sáàmù 37:5) Tá a bá sọ pé a ‘yí ọ̀nà wa lọ sọ́dọ̀ Jèhófà,’ ó túmọ̀ sí pé a gbẹ́kẹ̀ lé e, àti pé bó ṣe fẹ́ ká máa ṣe nǹkan là ń ṣé e, àní nígbà tí nǹkan ò bá rọgbọ pàápàá.
Iṣẹ́ wíńdò fífọ̀ àti iṣẹ́ nínu ògiri ibi àtẹ̀gùn ni Adam àti Irena lọ ń ṣe láti fi gbọ́ bùkátà ara wọn, wọ́n sì máa ń ṣọ́ owó ná tí wọ́n bá fẹ́ rajà. Wọn ò sì yéé lọ sí ọ́fíìsì àwọn tó ń báni wáṣẹ́. Irena sọ pé: “Gbogbo ìgbà tá a bá ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́ la máa ń rí i.” Ọkọ rẹ̀ sọ pé: “Àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí wa fi hàn pé àwọn ohun tá a máa ń gbàdúrà fún nígbà míì kì í ṣe ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́ fún wa. Èyí ti kọ́ wa láti gbára lé ọgbọ́n Ọlọ́run, ká má ṣe gbára lé ọgbọ́n ti ara wa. Ohun tó ti dára jù ni pé ká ní sùúrù de ìgbà tí Ọlọ́run máa yanjú ìṣòro náà.”—Jákọ́bù 1:4.
Kò sí iṣẹ́ tí Ryszard àti Mariola kò fẹ́rẹ̀ẹ́ ṣe tán, bí wọ́n sì ṣe ń ṣe ìyẹn náà ni wọ́n tún lọ ń wàásù láwọn ìpínlẹ̀ tí kò ti fi bẹ́ẹ̀ sí Ẹlẹ́rìí. Ryszard sọ pé: “A máa ń ríṣẹ́ tá a lè fi gbọ́ bùkátà ara wa lákòókò tí kò bá sí nǹkan kan lọ́wọ́ wa mọ́. A rí àwọn iṣẹ́ tó ń mówó gidi wọlé àmọ́ a ò ṣe é nítorí pé ó máa forí gbárí pẹ̀lú ìgbòkègbodò tẹ̀mí. Ó tẹ́ wa lọ́rùn láti dúró de àkókò Jèhófà.” Tọkọtaya yìí gbà gbọ́ pé Jèhófà ló ṣe é tí wọ́n fi lè rí ilé fúláàtì kan gbà lówó kékeré, tí èyí ọkọ sì fi ríṣẹ́ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.
Ó máa ń dunni gan-an tí iṣẹ́ bá bọ́ lọ́wọ́ ẹni, àmọ́ o ò ṣe wò ó gẹ́gẹ́ bí àǹfààní kan tó máa jẹ́ kó o rí i fúnra rẹ pé Jèhófà ò ní fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà? Jèhófà bìkítà fún ọ. (1 Pétérù 5:6, 7) Ó tipasẹ̀ wòlíì Aísáyà ṣèlérí pé: “Má wò yí ká, nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ. Dájúdájú, èmi yóò fi okun fún ọ. Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ ní ti tòótọ́.” (Aísáyà 41:10) Má ṣe jẹ́ kí ìṣẹ̀lẹ̀ àìròtẹ́lẹ̀ dà ọ́ láàmú ju bó ṣe yẹ lọ, kódà bó bá tiẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ ló bọ́ lọ́wọ́ rẹ. Ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe, kó o sì fi èyí tó kù lé Jèhófà lọ́wọ́. Dúró de Jèhófà, “àní ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́.” (Ìdárò 3:26) Jèhófà yóò bù kún ọ lọ́pọ̀ yanturu.—Jeremáyà 17:7.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Lo àkókò tí o kò fi níṣẹ́ lọ́wọ́ fún ìgbòkègbodò tẹ̀mí
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Máa ṣọ́ owó ná, nígbà tó o bá sì ń wáṣẹ́ má ṣakọ pé o ò lè ṣe irú iṣẹ́ kan