-
Ẹ Máa Fi Ìrẹ̀lẹ̀ Tẹrí Ba Fáwọn Olùṣọ́ Àgùntàn Onífẹ̀ẹ́Ilé Ìṣọ́—2007 | April 1
-
-
7. Ìmọ̀ràn wo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún wa nípa bó ṣe yẹ ká máa ṣe sáwọn Kristẹni tó jẹ́ alábòójútó?
7 Àwọn Olùṣọ́ Àgùntàn wa tó wà lọ́run, ìyẹn Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi, fẹ́ ká jẹ́ onígbọràn ká si máa tẹrí ba fáwọn olùṣọ́ àgùntàn tí wọ́n gbé iṣẹ́ lé lọ́wọ́ nínú ìjọ. (1 Pétérù 5:5) Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti kọ̀wé pé: “Ẹ máa rántí àwọn tí ń mú ipò iwájú láàárín yín, tí wọ́n ti sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún yín, bí ẹ sì ti ń fẹ̀sọ̀ ṣàgbéyẹ̀wò bí ìwà wọ́n ti rí, ẹ máa fara wé ìgbàgbọ́ wọn. Ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn tí ń mú ipò iwájú láàárín yín, kí ẹ sì jẹ́ ẹni tí ń tẹrí ba, nítorí wọ́n ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí ọkàn yín bí àwọn tí yóò ṣe ìjíhìn; kí wọ́n lè ṣe èyí pẹ̀lú ìdùnnú, kì í sì í ṣe pẹ̀lú ìmí ẹ̀dùn, nítorí èyí yóò ṣe ìpalára fún yín.”—Hébérù 13:7, 17.
8. Kí ni Pọ́ọ̀lù rọ̀ wá pé ká “fẹ̀sọ̀ ṣàgbéyẹ̀wò” rẹ̀, ọ̀nà wo ló sì yẹ ká gbà “jẹ́ onígbọràn”?
8 Kíyè sí i pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní ká “fẹ̀sọ̀ ṣàgbéyẹ̀wò,” tàbí ká fara balẹ̀ kíyè sí ìṣòtítọ́ àwọn alàgbà wọ̀nyí ká sì fara wé ìgbàgbọ́ irú àwọn alàgbà bẹ́ẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún ní ká ṣègbọràn ká sì máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà àwọn ọkùnrin tá a yàn sípò wọ̀nyí. Ọ̀gbẹ́ni R. T. France tó ń ṣèwádìí nípa Bíbélì ṣàlàyé pé nínú èdè Gíríìkì ìpilẹ̀ṣẹ̀, ọ̀rọ̀ tá a tú sí “jẹ́ onígbọràn” níbí yìí kọ́ ni “wọ́n sábà máa ń lò fún ìgbọràn, kàkà bẹ́ẹ̀ ohun tí ọ̀rọ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà túmọ̀ sí ní olówuuru ni ‘kéèyàn yí èrò rẹ̀ padà,’ kó jẹ́ pé tinútinú ló fi fara mọ́ ìtọ́sọ́nà.” Kì í ṣe nítorí pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní ká ṣègbọràn sáwọn alàgbà nìkan la ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀, àmọ́ ìdí tá a tún fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé wọ́n ti jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú Ìjọba Ọlọ́run àtàwọn ohun tó máa ṣe wá láǹfààní ló jẹ àwọn lọ́kàn. Dájúdájú, inú wa yóò dùn tó bá jẹ́ pé tinútinú la fi fara mọ́ bí wọ́n ṣe ń darí wa.
-
-
Ẹ Máa Fi Ìrẹ̀lẹ̀ Tẹrí Ba Fáwọn Olùṣọ́ Àgùntàn Onífẹ̀ẹ́Ilé Ìṣọ́—2007 | April 1
-
-
10, 11. Ọ̀nà wo làwọn alábòójútó gbà “sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” fún àwọn Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní àti lóde òní?
10 Nínú ìwé Hébérù 13:7, 17 tá a fa ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ yọ níṣàájú, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún wa ní ìdí mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó fi yẹ ká jẹ́ onígbọràn sáwọn alábòójútó ká sì máa tẹrí ba fún wọn. Ìdí àkọ́kọ́ ni pé wọ́n “ti sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” fún wa. Rántí pé ohun tí “àwọn ẹ̀bùn tó jẹ́ ènìyàn” tí Jésù fún ìjọ wà fún ni “ìtọ́sọ́nàpadà àwọn ẹni mímọ́.” (Éfésù 4:11, 12) Jésù tọ́ èrò àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní sọ́nà, ó sì mú kí wọ́n tún ìwà wọn ṣe nípasẹ̀ àwọn olùṣọ́ àgùntàn tó jẹ́ olóòótọ́, ìyẹn àwọn tí Ọlọ́run mí sí díẹ̀ lára wọn láti kọ lẹ́tà sáwọn ìjọ. Ó lo àwọn alábòójútó tá a fẹ̀mí yàn yìí láti tọ́ àwọn Kristẹni ìjímìjí sọ́nà àti láti gbé wọn ró.—1 Kọ́ríńtì 16:15-18; 2 Tímótì 2:2; Títù 1:5.
11 Lóde òní, Jésù ń darí wa nípasẹ̀ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye,” tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí àtàwọn alàgbà tá a yàn sípò ń ṣojú fún. (Mátíù 24:45) Nítorí ọ̀wọ̀ tá a ní fún “olórí olùṣọ́ àgùntàn” wa, Jésù Kristi, la ṣe ń fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù yẹn sílò pé: “Kí ẹ ní ẹ̀mí ìkanisí fún àwọn tí ń ṣiṣẹ́ kára láàárín yín, tí wọ́n ń ṣe àbójútó yín nínú Olúwa, tí wọ́n sì ń ṣí yín létí.”—1 Pétérù 5:4; 1 Tẹsalóníkà 5:12; 1 Tímótì 5:17.
-