A Óò Dán Ìgbàgbọ́ Kristẹni Wò
“Ìgbàgbọ́ kì í ṣe ohun ìní gbogbo ènìyàn.”—2 TẸSALÓNÍKÀ 3:2.
1. Báwo ni ìtàn ṣe fi hàn pé kì i ṣe gbogbo ènìyàn ni ó ní ìgbàgbọ́ tòótọ́?
JÁLẸ̀ ìtàn, a ti rí àwọn ọkùnrin, obìnrin, àti àwọn ọmọdé tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ tòótọ́. Ọ̀rọ̀ ajúwe náà, “tòótọ́,” bá a mu wẹ́kú nítorí pé àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn mìíràn ti fi ìgbàgbọ́ oréfèé hàn, wọ́n múra tán láti gba nǹkan gbọ́ láìsí ẹ̀rí tí ó múná dóko. Lọ́pọ̀ ìgbà, irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ ti wé mọ́ àwọn ọlọ́run èké tàbí ọ̀nà ìjọsìn tí kò bá Ọ̀rọ̀ tí Olódùmarè, Jèhófà, ṣí payá, mu. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tipa báyìí kọ̀wé pé: “Ìgbàgbọ́ kì í ṣe ohun ìní gbogbo ènìyàn.”—2 Tẹsalóníkà 3:2.
2. Èé ṣe tí ó fi ṣe pàtàkì pé kí a yẹ ìgbàgbọ́ wa wò?
2 Ṣùgbọ́n ohun tí gbólóhùn Pọ́ọ̀lù túmọ̀ sí ni pé, nígbà náà lọ́hùn-ún, àwọn kan ní ìgbàgbọ́ tòótọ́, bákan náà lónìí, àwọn kan ní in. Ọ̀pọ̀ àwọn tí ń ka ìwé ìròyìn yìí fẹ́ láti ní irú ìgbàgbọ́ tòótọ́ bẹ́ẹ̀, wọ́n sì fẹ́ kí ó pọ̀ sí i—ìgbàgbọ́ tí ó wà ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ pípéye ti òtítọ́ àtọ̀runwá. (Jòhánù 18:37; Hébérù 11:6) Ṣé bí ọ̀ràn tìrẹ náà ti rí nìyẹn? Nígbà náà, ó ṣe pàtàkì kí o mọ òtítọ́ náà pé a óò dán ìgbàgbọ́ rẹ wò, kí o sì múra sílẹ̀ fún un. Èé ṣe tí a fi lè sọ bẹ́ẹ̀?
3, 4. Èé ṣe tí a fi ní láti wo Jésù ní ti ọ̀ràn ìdánwò ìgbàgbọ́?
3 A gbọ́dọ̀ gbà pé Jésù Kristi ṣe pàtàkì sí ìgbàgbọ́ wa. Ní tòótọ́, Bíbélì sọ̀rọ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Aláṣepé ìgbàgbọ́ wa. Ìyẹn jẹ́ nítorí ohun tí Jésù sọ, tí ó sì ṣe, ní pàtàkì bí ó ṣe mú àsọtẹ́lẹ̀ ṣẹ. Ó fún ìpìlẹ̀ tí àwọn ẹ̀dá ènìyàn lè gbé ìgbàgbọ́ tòótọ́ kà lókun. (Hébérù 12:2; Ìṣípayá 1:1, 2) Síbẹ̀, a kà pé a “dán” Jésù “wò ní gbogbo ọ̀nà bí àwa fúnra wa, ṣùgbọ́n kò ní ẹ̀ṣẹ̀.” (Hébérù 4:15) Bẹ́ẹ̀ ni, a dán ìgbàgbọ́ Jésù wò. Dípò tí ìyẹn yóò fi kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa tàbí tí yóò fi da jìnnìjìnnì bò wá, ṣe ni ó yẹ kí ó tù wá nínú.
4 Jésù “kọ́ ìgbọràn,” nípa líla àwọn àdánwò ńlá kọjá títí dójú ikú lórí òpó igi. (Hébérù 5:8) Ó fẹ̀rí hàn pé àwọn ènìyàn lè fi ìgbàgbọ́ tòótọ́ gbé ìgbésí ayé láìka ìdánwò èyíkéyìí tí ó lè dé bá wọn sí. Èyí jẹ́ ọ̀ràn pàtàkì bí a bá ronú nípa ohun tí Jésù sọ nípa àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ fi ọ̀rọ̀ tí mo sọ fún yín sọ́kàn, pé, Ẹrú kò tóbi ju ọ̀gá rẹ̀ lọ.” (Jòhánù 15:20) Ní tòótọ́, nípa àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní àkókò wa, Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ẹ ó sì jẹ́ ẹni ìkórìíra lọ́dọ̀ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ní tìtorí orúkọ mi.”—Mátíù 24:9.
5. Báwo ni Ìwé Mímọ́ ṣe fi hàn pé a óò dojú kọ ìdánwò?
5 Ní kùtùkùtù ọ̀rúndún yìí, ìdájọ́ bẹ̀rẹ̀ ní ilé Ọlọ́run. Ìwé Mímọ́ sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Àkókò tí a yàn kalẹ̀ ti tó fún ìdájọ́ láti bẹ̀rẹ̀ ní ilé Ọlọ́run. Wàyí o, bí ó bá kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ní ọ̀dọ̀ wa, kí ni yóò jẹ́ òpin àwọn tí kò ṣègbọràn sí ìhìn rere Ọlọ́run? ‘Bí ó bá sì jẹ́ pé agbára káká ni a fi ń gba olódodo là, níbo ni aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run àti ẹlẹ́ṣẹ̀ yóò gbé yọjú?’”—1 Pétérù 4:17, 18.
A Dán Ìgbàgbọ́ Wò—Èé Ṣe?
6. Èé ṣe tí ìgbàgbọ́ tí a dán wò fi níye lórí?
6 Lọ́nà kan, ìgbàgbọ́ tí a kò dán wò kò lè fi ìníyelórí rẹ̀ hàn, a kò sì lè mọ bí ó ti jẹ́ ojúlówó tó. O lè fi wé ìwé sọ̀wédowó kan tí a kò tí ì mú lọ sí báǹkì. O ti lè gba ìwé sọ̀wédowó kan fún iṣẹ́ kan tí o ti ṣe, fún ọjà kan tí o tà, tàbí kí a fi ta ọ́ lọ́rẹ. Ìwé sọ̀wédowó náà lè dà bí ojúlówó, ṣùgbọ́n, ṣé ojúlówó ni? Ó ha tó iye owó tí a kọ sínú rẹ̀ bí? Bákan náà, ìgbàgbọ́ wa kò gbọ́dọ̀ jẹ́ oréfèé tàbí ti orí ahọ́n lásán. A gbọ́dọ̀ dán an wò bí a óò bá fi hàn pé kì í ṣe ìgbàgbọ́ yẹ̀bùyẹ́bù, ṣùgbọ́n pé ó jẹ́ ojúlówó. Nígbà tí a bá dán ìgbàgbọ́ wa wò, a óò lè ri pé ó lágbára, ó sì níye lórí. Ìdánwò kan sì lè ṣí àwọn apá èyíkéyìí tí ìgbàgbọ́ wa ti nílò ìyọ́mọ́ tàbí ìfúnlókun payá.
7, 8. Ibo ni ìdánwò ìgbàgbọ́ wa ti ń wá?
7 Ọlọ́run ń yọ̀ǹda kí inúnibíni àti àwọn ìdánwò ìgbàgbọ́ mìíràn dé bá wa. A kà pé: “Nígbà tí ẹnikẹ́ni bá wà lábẹ́ àdánwò, kí ó má ṣe sọ pé: ‘Ọlọ́run ni ó ń dán mi wò.’ Nítorí a kò lè fi àwọn ohun tí ó jẹ́ ibi dán Ọlọ́run wò, bẹ́ẹ̀ ni òun fúnra rẹ̀ kì í dán ẹnikẹ́ni wò.” (Jákọ́bù 1:13) Ta ni tàbí kí ni ó ń ṣokùnfà irú àdánwò bẹ́ẹ̀? Sátánì, ayé, àti ẹran ara àìpé tiwa fúnra wa ni.
8 A lè gbà pé Sátánì ń lo agbára ńlá lórí ayé, lórí ìrònú àti ọ̀nà rẹ̀. (1 Jòhánù 5:19) Ó sì ṣeé ṣe kí a mọ̀ pé ó ń ru àwọn ènìyàn sókè láti ṣe inúnibíni sí àwọn Kristẹni. (Ìṣípayá 12:17) Ṣùgbọ́n, ó ha dá wa lójú bákan náà pé Sátánì ń gbìyànjú láti ṣì wá lọ́nà nípa lílo ẹran ara wa aláìpé, nípa fífi àwọn ohun fífanimọ́ra ti ayé yàn wá lójú, ní ríretí pé a óò fẹ́ hán an, tí a óò sì ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, tí a óò wá di ẹni tí Jèhófà kò tẹ́wọ́ gbà? Àmọ́ ṣáá o, kò yẹ kí àwọn ọgbọ́n Sátánì yà wá lẹ́nu, nítorí ó lo irú ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ kan náà nígbà tí ó ń dán Jésù wò.—Mátíù 4:1-11.
9. Báwo ni a ṣe lè jàǹfààní láti inú àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́?
9 Nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ìjọ Kristẹni, Jèhófà fún wa ní àwọn àpẹẹrẹ rere ti ìgbàgbọ́ tí a lè fara wé. Pọ́ọ̀lù ṣí wa létí pé: “Ẹ di aláfarawé mi ní ìsopọ̀ṣọ̀kan, ẹ̀yin ará, kí ẹ sì tẹ ojú yín mọ́ àwọn tí ń rìn ní ọ̀nà tí ó bá àpẹẹrẹ tí ẹ rí nínú wa mu.” (Fílípì 3:17) Gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn ẹni àmì òróró ìránṣẹ́ Ọlọ́run ní ọ̀rúndún kìíní, Pọ́ọ̀lù mú ipò iwájú nínú ṣíṣe iṣẹ́ ìgbàgbọ́ láìka àwọn àdánwò ńlá tí ó nírìírí rẹ̀ sí. Títí di òpin ọ̀rúndún ogún, a kò kẹ̀rẹ̀ ní fífi àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ lélẹ̀. Àwọn ọ̀rọ̀ Hébérù 13:7 kàn wá gbọ̀ngbọ̀n nísinsìnyí gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti kanni gbọ̀ngbọ̀n nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ̀wé ọ̀rọ̀ wọnnì, pé: “Ẹ máa rántí àwọn tí ń mú ipò iwájú láàárín yín, tí wọ́n ti sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún yín, bí ẹ sì ti ń fẹ̀sọ̀ ṣàgbéyẹ̀wò bí ìwà wọ́n ti rí, ẹ máa fara wé ìgbàgbọ́ wọn.”
10. Ní pàtó, àwọn àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ wo ni a ní láìpẹ́ yìí?
10 Ọ̀rọ̀ ìṣílétí yẹn kàn wá ní pàtàkì bí a bá ṣàgbéyẹ̀wò bí ìwà àṣẹ́kù ẹni àmì òróró ti wá rí. A lè ronú nípa àpẹẹrẹ wọn, kí a sì fara wé ìgbàgbọ́ wọn. Tiwọn jẹ́ ìgbàgbọ́ tòótọ́ tí àdánwò ti yọ́ mọ́. Pẹ̀lú ìbẹ̀rẹ̀ kékeré ní àwọn ọdún 1870, ẹgbẹ́ ará Kristẹni kan tí ó kárí ayé bẹ̀rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí èso ìgbàgbọ́ àti ìfaradà àwọn ẹni àmì òróró láti ìgbà náà wá, ní báyìí, ó ti lé ní mílíọ̀nù márùn-ún àbọ̀ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n ń wàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń kọ́ni nípa rẹ̀. Ìjọ àwọn onítara olùjọsìn tòótọ́ tí ó wà kárí ayé nísinsìnyí jẹ́ ẹ̀rí ìgbàgbọ́ kan tí a ti dán wò.—Títù 2:14.
A Dán Ìgbàgbọ́ Wò Nípa Ọdún 1914
11. Báwo ni ọdún 1914 ti ṣe pàtàkì tó fún C. T. Russell àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀?
11 Ní àwọn ọdún díẹ̀ ṣáájú kí Ogun Àgbáyé Kìíní tó bẹ́ sílẹ̀, àṣẹ́kù ẹni àmì òróró ti ń pòkìkí pé ọdún 1914 yóò jẹ́ ọdún mánigbàgbé kan nínú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì. Ṣùgbọ́n, díẹ̀ lára àwọn ìfojúsọ́nà wọn kò tí ì tákòókò, ojú ìwòye wọn nípa ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ kò sì péye délẹ̀délẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, C. T. Russell, ààrẹ àkọ́kọ́ Watch Tower Society àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ rí i pé iṣẹ́ ìwàásù lọ́nà gbígbòòrò pọndandan. Wọ́n kà á pé: “A óò sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ayé láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” (Mátíù 24:14, King James Version) Ṣùgbọ́n, báwo ni ẹgbẹ́ kéréje kan ṣe lè ṣe ìyẹn?
12. Báwo ni ọ̀kan nínú àwọn alábàákẹ́gbẹ́ Russell ṣe dáhùn padà sí òtítọ́ Bíbélì?
12 Ṣàgbéyẹ̀wò bí èyí ṣe nípa lórí A. H. Macmillan, tí ó jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ Russell. A bí Macmillan sí Kánádà, kò sì tí ì pé ọmọ 20 ọdún nígbà tí ó gba ìwé náà, The Plan of the Ages (1886), tí Russell kọ. (Ìwé yìí kan náà tí a ń pè ní The Divine Plan of the Ages, di Ìdìpọ̀ Kìíní nínú ìwé Studies in the Scriptures tí a pín kiri lọ́nà gbígbòòrò. Ìdìpọ̀ Kejì The Time Is at Hand [1889], tọ́ka sí ọdún 1914 gẹ́gẹ́ bí òpin “àkókò àwọn Kèfèrí.” [Lúùkù 21:24, KJ]) Ní alẹ́ ọjọ́ náà gan-an tí Macmillan bẹ̀rẹ̀ sí kà á, ó ronú pé: “Tóò, ìyẹn dà bí òtítọ́!” Ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 1900, ó pàdé Russell ní àpéjọpọ̀ Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, gẹ́gẹ́ bí a ti ń pe Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà náà. Kò pẹ́ rárá, Macmillan ṣe batisí, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí bá Arákùnrin Russell ṣiṣẹ́ ní orílé iṣẹ́ Society ní New York.
13. Ìṣòro wo ni Macmillan àti àwọn mìíràn rí ní ti ìmúṣẹ Mátíù 24:14?
13 Ní gbígbé e ka ohun tí wọ́n kà nínú Bíbélì, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró wọ̀nyẹn tọ́ka sí ọdún 1914 gẹ́gẹ́ bí àkókò ìyípadà ńlá nínú ète Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n kò yé Macmillan àti àwọn yòókù bí a óò ṣe lè ṣàṣeparí wíwàásù fún àwọn orílẹ̀-èdè tí a sọ tẹ́lẹ̀ nínú Mátíù 24:14 láàárín àkókò kúkúrú tí ó ṣẹ́ kù. Lẹ́yìn náà, ó wí pé: “Mo rántí jíjíròrò ọ̀ràn yẹn pẹ̀lú Arákùnrin Russell lemọ́lemọ́, òun sì máa ń sọ pé, ‘Tóò, arákùnrin, àwọn Júù tí ń bẹ ní New York níhìn-ín gan-an ju àwọn tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù lọ. Àwọn ará Ireland tí ó wà níhìn-ín ju àwọn tí ó wà ní Dublin lọ. Àwọn ará Ítálì tí ó sì wà níhìn-ín kì í ṣẹgbẹ́ ti àwọn tí ó wà ní Róòmù. Wàyí o, bí a bá wàásù fún wọn níhìn-ín, ìyẹn túmọ̀ sí mímú ìhìn iṣẹ́ náà dé gbogbo ayé.’ Àmọ́ ìyẹn kò tẹ́ wa lọ́rùn. Nítorí náà, a ronú nípa sinimá ‘Photo-Drama.’”
14. Ṣáájú ọdún 1914, iṣẹ́ títayọlọ́lá wo ni a dáwọ́ lé?
14 Àrà mérìíyìírí mà ni sinimá “Photo-Drama of Creation” jẹ́ o! Ó jẹ́ àpapọ̀ àwòrán tí ń rìn àti àwòrán gbagidi aláwọ̀ mèremère, àsọyé Bíbélì àti orin tí a ti gbà sínú ohun èlò agbóhùnjáde sì ń bá àwọn àwòrán tí ó ń jáde mu. Ní ọdún 1913, Ilé Ìṣọ́ (Gẹ̀ẹ́sì) sọ nípa àpéjọpọ̀ kan ní Arkansas, U.S.A., pé: “A dorí ìpinnu ní ìfìmọ̀ṣọ̀kan pé àkókò ti tó láti máa lo sinimá nínú kíkọ́ni ní òtítọ́ Bíbélì. . . . [Russell] ṣàlàyé pé ó ti tó ọdún mẹ́ta tí òun ti wà lórí ìwéwèé yìí àti pé òun ti ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwòrán ẹlẹ́wà lọ́wọ́ nísinsìnyí, tí kò sí iyèméjì pé yóò fa ogunlọ́gọ̀ ènìyàn mọ́ra, tí yóò pòkìkí Ìhìn Rere náà, tí yóò sì ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti padà ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run.”
15. Irú ìyọrísí wo ni sinimá “Photo-Drama” ní?
15 Ohun tí sinimá “Photo-Drama” ṣe gan-an nìyẹn lẹ́yìn tí a kọ́kọ́ fi hàn ní January 1914. Àwọn ìròyìn tí ó jáde nínú Ilé Ìṣọ́ 1914 (Gẹ̀ẹ́sì) nìyí:
April 1: “Òjíṣẹ́ kan, lẹ́yìn tí ó ti wo apá méjèèjì, wí pé, ‘Apá kan àti ààbọ̀ péré ni mo tí ì wò nínú sinimá PHOTO-DRAMA OF CREATION, ṣùgbọ́n ohun tí ó ti kọ́ mi nípa Bíbélì ju ohun tí mo fi odindi ọdún mẹ́ta kọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ṣẹ́ àlùfáà lọ.’ Lẹ́yìn tí Júù kan ti wò ó, ó wí pé, ‘N óò fibí sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Júù tí ó sunwọ̀n sí i ju ìgbà tí mo wọlé lọ.’ Ọ̀pọ̀ àlùfáà Kátólíìkì àti àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ànìkàngbé ti wo sinimá DRAMA náà, wọ́n sì ti fi ìmọrírì ńláǹlà hàn. . . . Apá méjìlá péré nínú sinimá DRAMA náà ni ó wà nílẹ̀ . . . Síbẹ̀síbẹ̀, a ti dé ìlú mọkànlélọ́gbọ̀n, a sì ti fi sinimá náà hàn wọ́n . . . Ó lé ní ẹgbẹ̀rún márùndínlógójì ènìyàn tí ó ń wò ó, tí ó ń gbọ́ ọ, tí ó ń yà lẹ́nu, tí ó ń ronú nípa rẹ̀, tí ó sì ń rí ìbùkún gbà lójoojúmọ́.”
June 15: “Àwọn àwòrán náà ti jẹ́ kí n túbọ̀ di onítara láti tan Òtítọ́ kálẹ̀, ó sì ti mú kí ìfẹ́ mi fún Bàbá Ọ̀run àti Ẹ̀gbọ́n wa Àgbà ọ̀wọ́n Jésù dàgbà sí. Lójoojúmọ́ ni mo ń gbàdúrà fún ìbùkún yabuga lórí sinimá PHOTO-DRAMA OF CREATION àti gbogbo àwọn tí ó lọ́wọ́ nínú ìgbékalẹ̀ rẹ̀ . . . Ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ yín nínú Rẹ̀, F. W. KNOCHE.—Iowa.”
July 15: “Inú wa dún láti jẹ́ kí ẹ mọ̀ nípa èrò rere tí àwòrán náà ti gbìn sọ́kàn àwọn ará ìlú yìí, a sì ní ìdánilójú pé ẹ̀rí yìí tí a ń jẹ́ fún ayé ni a tún fi ń kó ọ̀pọ̀ tí wọ́n fi ẹ̀rí hàn pé àwọn jẹ́ ohun iyebíye tí Olúwa yàn jọ. A mọ ọ̀pọ̀ lára àwọn onítara akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n ti dara pọ̀ mọ́ Ìjọ náà níhìn-ín nísinsìnyí gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí wíwo sinimá Photo-Drama. . . . Arábìnrin yín nínú Olúwa, EMMA L. BRICKER.”
November 15: “Ó dá wa lójú pé inú yín yóò dùn láti gbọ́ nípa ẹ̀rí tí ó jíire tí a ti jẹ́ nípasẹ̀ sinimá PHOTO-DRAMA OF CREATION ní The London Opera House, Kingsway. A ti rí ọwọ́ Olúwa tí ń tọ́ni sọ́nà lọ́nà àgbàyanu nínú gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ àfihàn yìí débi pé àwọn ará wulẹ̀ ń kún fún ayọ̀ ṣáá ni . . . Àwọn tí ó para pọ̀ jẹ́ àwùjọ wa wá láti onírúurú ẹgbẹ́ àti ọ̀gbà; a ṣàkíyèsí pé ọ̀pọ̀ àlùfáà wá. Àlùfáà kan . . . béèrè fún tíkẹ́ẹ̀tì kí òun àti aya rẹ̀ bàa lè wá wò ó lẹ́ẹ̀kan sí i. Àlùfáà Ṣọ́ọ̀ṣì Ilẹ̀ England kan ti wá wo sinimá DRAMA náà lọ́pọ̀ ìgbà, ó sì ti . . mú ọ̀pọ̀ ọ̀rẹ́ rẹ̀ wa wò ó. Bíṣọ́ọ̀bù méjì pẹ̀lú ti wá àti ọ̀pọ̀ ènìyàn jàǹkàn-jàǹkàn.”
December 1: “Èmi àti aya mi dúpẹ́ gidigidi lọ́wọ́ Baba wa Ọ̀run fún ìbùkún yabuga-yabuga tí kò ṣeé díyelé tí ó wá sórí wa nípasẹ̀ yín. Sinimá PHOTO-DRAMA yín rírẹwà tí ó ru ìmọ̀lára sókè gan-an ni ó jẹ́ kí a rí Òtítọ́, tí a sì tẹ́wọ́ gbà á . . . A ní ìdìpọ̀ mẹ́fà ti ìwé STUDIES IN THE SCRIPTURES yin. Ìrànwọ́ ńláǹlà ni wọ́n jẹ́.”
Ìhùwàpadà sí Ìdánwò Nígbà Náà Lọ́hùn-ún
16. Èé ṣe tí ọdún 1914 fi mú ìdánwò ìgbàgbọ́ wá?
16 Ṣùgbọ́n, kí ní ṣẹlẹ̀ nígbà tí irú àwọn Kristẹni olóòótọ́-ọkàn àti olùfọkànsìn bẹ́ẹ̀ rí pé ìfojúsọ́nà wọn ní ti dídarapọ̀ mọ́ Olúwa ní ọdún 1914 kò wáyé? Àwọn ẹni àmì òróró wọ̀nyẹn nírìírí àkókò àdánwò tí ó yàtọ̀ pátápátá. Ilé Ìṣọ́ November 1, 1914, (Gẹ̀ẹ́sì), polongo pé: “Ẹ jẹ́ kí a rántí pé a wà ní àkókò ìdánwò.” Nípa èyí, ìwé Jehovah’s Witnesses—Proclaimers of God’s Kingdom (1993) sọ pé: “Ní tòótọ́, ọdún 1914 sí 1918 jẹ́ ‘àkókò ìdánwò’ fún Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.” Wọn yóò ha gbà kí a yọ́ ìgbàgbọ́ wọn mọ́, kí a sì tún wọn ṣe, kí wọ́n bàa lè ṣe iṣẹ́ bàǹtàbanta tí ń bẹ níwájú wọn bí?
17. Báwo ni àwọn olóòótọ́ ẹni àmì òróró ṣe hùwà padà sí àwọn tí ó ṣẹ́ kù sórí ilẹ̀ ayé lẹ́yìn ọdún 1914?
17 Ilé Ìṣọ́ September 1, 1916, (Gẹ̀ẹ́sì) wí pé: “A ronú pé iṣẹ́ Ìkórè ti kíkó Ṣọ́ọ̀ṣì náà [àwọn ẹni àmì òróró] jọ yóò parí ṣáájú òpin Àkókò Àwọn Kèfèrí; ṣùgbọ́n kò sí ibi tí Bíbélì ti sọ bẹ́ẹ̀. . . . A ha kábàámọ̀ pé iṣẹ́ Ìkórè náà ṣì ń bá a nìṣó bí? . . . Ẹ̀yin ará, ìṣarasíhùwà wa ìsinsìnyí, yẹ kí ó fọpẹ́ fún Ọlọ́run, kí ó fi ìmọrírì tí ó pọ̀ sí i hàn fún Òtítọ́ gbígbámúṣé tí Òun ti fún wa láǹfààní láti rí, tí a sì mọ̀ wá mọ̀, àti ìtara tí ń pọ̀ sí i nínú ṣíṣèrànwọ́ láti mú Òtítọ́ yẹn wá fún àwọn ẹlòmíràn.” A ti dán ìgbàgbọ́ wọn wò, síbẹ̀, wọ́n dojú kọ ìdánwò náà, wọ́n sì ṣàṣeyọrí. Ṣùgbọ́n ó yẹ kí àwa Kristẹni mọ̀ pé ìdánwò ìgbàgbọ́ lè pọ̀, ó sì lè yàtọ̀ síra.
18, 19. Àwọn ìdánwò ìgbàgbọ́ mìíràn wo ni àwọn ènìyàn Ọlọ́run rí kété lẹ́yìn tí Arákùnrin Russell dolóògbé?
18 Fún àpẹẹrẹ, ìdánwò mìíràn dé bá àṣẹ́kù náà kété lẹ́yìn tí Arákùnrin Charles T. Russell dolóògbé. Ìyẹn jẹ́ ìdánwò ìdúróṣinṣin àti ìgbàgbọ́ wọn. Ta ni “ẹrú olóòótọ́” tí Mátíù 24:45 sọ? Àwọn kan rò pé Arákùnrin Russell fúnra rẹ̀ ni, wọ́n sì kọ̀ jálẹ̀ láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ìṣètò tuntun. Bí ó bá jẹ́ òun ni ẹrú náà, kí ni àwọn arákùnrin yóò wá ṣe nísinsìnyí tí ó ti kú? Ṣé kí wọ́n tẹ̀ lé ẹlòmíràn tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn sípò ni, àbí àkókò náà ti tó nísinsìnyí láti mọ̀ pé kì í ṣe ẹnì kan ṣoṣo ni Jèhófà ń lò gẹ́gẹ́ bí irinṣẹ́, bí kò ṣe àpapọ̀ ẹgbẹ́ àwọn Kristẹni, tàbí ẹgbẹ́ ẹrú?
19 Ìdánwò mìíràn tún dé bá àwọn Kristẹni tòótọ́ ní ọdún 1918 nígbà tí àwọn aláṣẹ ayé, tí àwọn àlùfáà Kirisẹ́ńdọ̀mù ru sókè, “fi òfin dìmọ̀” lòdì sí ètò àjọ Jèhófà. (Sáàmù 94:20, KJ) Ọ̀pọ̀ inúnibíni gbígbóná janjan dìde sí Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Àríwá Amẹ́ríkà àti ní Yúróòpù. Àtakò tí àwọn àlùfáà dáná rẹ̀ dé òtéńté ní May 7, 1918, nígbà tí a fàṣẹ ìjọba àpapọ̀ United States mú J. F. Rutherford àti ọ̀pọ̀ àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́, títí kan A. H. Macmillan. A fẹ̀sùn èké kàn wọ́n pé wọ́n dìtẹ̀ mọ́ ìjọba, àwọn aláṣẹ kò sì fetí sí ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn pé àwọn kò jẹ̀bi ẹ̀sùn náà.
20, 21. Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ tẹ́lẹ̀ nínú Málákì 3:1-3, iṣẹ́ wo ni a ṣe láàárín àwọn ẹni àmì òróró?
20 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò mọ̀ bẹ́ẹ̀ nígbà náà lọ́hùn-ún, iṣẹ́ ìsọdimímọ́ kan ń lọ lọ́wọ́, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàpèjúwe rẹ̀ ní Málákì 3:1-3 pé: “Ta ni ó lè fara da ọjọ́ dídé rẹ̀, ta sì ni ẹni tí yóò dúró nígbà tí ó bá fara hàn? Nítorí [ońṣẹ́ májẹ̀mú náà] yóò dà bí iná ẹni tí ń yọ́ nǹkan mọ́ àti gẹ́gẹ́ bí ọṣẹ ìfọṣọ alágbàfọ̀. Òun yóò sì jókòó gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ń yọ́ fàdákà, tí ó sì ń fọ̀ ọ́ mọ́, yóò sì fọ àwọn ọmọ Léfì mọ́; yóò sì mú wọn mọ́ kedere bí wúrà àti bí fàdákà, dájúdájú, wọn yóò di àwọn ènìyàn tí ń mú ọrẹ ẹbọ ẹ̀bùn wá fún Jèhófà nínú òdodo.”
21 Bí Ogun Àgbáyé Kìíní ti ń parí lọ, àwọn kan lára Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì dojú kọ ìdánwò ìgbàgbọ́ mìíràn—bóyá wọn yóò di àìdásí tọ̀túntòsì wọn mú ní ti ọ̀ràn ológun ti ayé. (Jòhánù 17:16; 18:36) Àwọn kan kò ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, ní ọdún 1918, Jèhófà rán “ońṣẹ́ májẹ̀mú” náà, Kristi Jésù, sínú ìṣètò tẹ́ńpìlì Rẹ̀ nípa tẹ̀mí láti fọ ẹgbẹ́ kékeré ti àwọn olùjọsìn Rẹ̀ mọ́ kúrò nínú àbààwọ́n ayé. Àwọn tí wọn ti fara jin fífi ìgbàgbọ́ tòótọ́ hàn kẹ́kọ̀ọ́ láti inú ìrírí, wọ́n tẹ̀ síwájú, wọ́n sì ń fi ìtara bá iṣẹ́ ìwàásù náà lọ.
22. Ní ti ìdánwò ìgbàgbọ́, kí ni ó kù tí a óò gbé yẹ̀ wò?
22 Ohun tí a ti gbé yẹ̀ wò yìí kì í wulẹ̀ ṣe ọ̀ràn ìtàn àtijọ́ lásán. Ó ní í ṣe ní tààràtà pẹ̀lú ipò tẹ̀mí ìjọ Jèhófà kárí ayé ní lọ́ọ́lọ́ọ́. Ṣùgbọ́n, nínú àpilẹ̀kọ tí yóò tẹ̀ lé e, ẹ jẹ́ kí a gbé díẹ̀ nínú àwọn ìdánwò ìgbàgbọ́ tí àwọn ènìyàn Ọlọ́run ń dojú kọ lónìí yẹ̀ wò, kí a sì rí bí a ṣe lè ṣàṣeyọrí nínú bíborí wọn.
Ìwọ Ha Rántí Bí?
◻ Èé ṣe tí ó fi yẹ kí àwọn ènìyàn Jèhófà retí pé a óò dán ìgbàgbọ́ wọn wò?
◻ Irú ìsapá wo láti tan ìhìn iṣẹ́ Ọlọ́run kálẹ̀ ni ó wà lẹ́nu iṣẹ́ ṣáájú ọdún 1914?
◻ Kí ni sinimá “Photo-Drama,” kí sì ni ó yọrí sí?
◻ Báwo ni àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ní ọdún 1914 sí 1918 ṣe dán àwọn ẹni àmì òróró wò?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Nígbà tí a óò fi wọ ọ̀rúndún tuntun, pẹ̀lú ìrànwọ́ ọ̀wọ́ ìwé náà, “Millennial Dawn,” tí a wá pè ní “Studies in the Scriptures,” lẹ́yìn náà, àwọn ènìyàn ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀ ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Lẹ́tà kan tí C. T. Russell kọ, tí ó ní ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ fún ìgbohùnsílẹ̀ kan nínú, èyí tí ó ti wí pé: “IBSA [Ẹgbẹ́ Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Káàkiri Àgbáyé] ni ó ṣe sinimá ‘Photo-Drama of Creation.’ Ète rẹ̀ jẹ́ láti pèsè ìtọ́ni fún àwọn ènìyàn nípa ìbátan tí ó wà láàárín ìsìn àti ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì, àti láti gbèjà Bíbélì”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Demetrius Papageorge rìnrìn àjò kiri láti fi sinimá “Photo-Drama of Creation” hàn. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, wọ́n fi í sẹ́wọ̀n nítorí pé gẹ́gẹ́ bí Kristẹni kò dá sí tọ̀túntòsì