‘Fi Ọwọ́ Títọ̀nà Mú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run’
“Sa gbogbo ipá rẹ láti fi ara rẹ hàn fún Ọlọ́run ní ẹni tí a tẹ́wọ́ gbà, aṣiṣẹ́ tí kò ní ohun kankan láti tì í lójú, tí ń fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́.”—2 TÍMÓTÌ 2:15.
1, 2. (a) Kí nìdí táwọn òṣìṣẹ́ fi nílò irin iṣẹ́? (b) Inú iṣẹ́ wo làwọn Kristẹni ti ń kópa, báwo ni wọ́n sì ṣe ń fi hàn pé àwọn ń wá Ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́?
ÀWỌN òṣìṣẹ́ nílò irin iṣẹ́ tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ wọn. Àmọ́, wíwulẹ̀ ní irin iṣẹ́ kan ṣá kò tó. Òṣìṣẹ́ nílò irin iṣẹ́ tí ó tọ́ láti lò, ó sì gbọ́dọ̀ mọ bá a ṣe ń lò ó lọ́nà tó yẹ. Bí àpẹẹrẹ, ká ní o fẹ́ kan igi méjì pọ̀ nígbà tó o ń kọ́ àtíbàbà kan, kì í ṣe kìkì òòlù àti ìṣó nìkan lo nílò lákòókò yẹn. O tún ní láti mọ bí a ṣe ń kan ìṣó mọ́ igi tí ìṣó náà ò sì ní tẹ̀. Gbígbìyànjú láti kan ìṣó mọ́ igi láìmọ bá a ṣe ń lo òòlù yóò mú kí iṣẹ́ náà ṣòro gan-an, kódà yóò tánni lókun. Àmọ́, àwọn irin iṣẹ́ tá a lò bó ti tọ́ àti bó ṣe yẹ yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àwọn iṣẹ́ tá a bá dáwọ́ lé láṣeyọrí.
2 Gẹ́gẹ́ bí Kristẹni, a ní iṣẹ́ kan láti ṣe. Ó jẹ́ iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ. Jésù Kristi rọ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n ‘máa wá ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́.’ (Mátíù 6:33) Báwo la ṣe lè ṣe ìyẹn? Ọ̀nà kan ni pé ká jẹ́ onítara nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà àti iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. Ọ̀nà mìíràn ni pé ká máa mú ohun tá a ń sọ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa jáde látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ọ̀nà kẹta ni pé kí ìwà wa dára. (Mátíù 24:14; 28:19, 20; Ìṣe 8:25; 1 Pétérù 2:12) Láti jẹ́ ọ̀jáfáfá ká sì láyọ̀ nínú iṣẹ́ tá a gbé lé wa lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, á nílò àwọn irin iṣẹ́ tó yẹ ká sì mọ bá a ó ṣe lò wọ́n lọ́nà tí ó tọ́. Látàrí èyí, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi àpẹẹrẹ títayọ kan lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Kristẹni òṣìṣẹ́, ó sì gba àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ níyànjú láti fara wé òun. (1 Kọ́ríńtì 11:1; 15:10) Nítorí náà, ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ lára Pọ́ọ̀lù, tó jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ wa?
Pọ́ọ̀lù Jẹ́ Olùfi Ìtara Pòkìkí Ìjọba Náà
3. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ òṣìṣẹ́ tó fi ìtara pòkìkí Ìjọba náà?
3 Irú òṣìṣẹ́ wo ni Pọ́ọ̀lù jẹ́? Ó dájú pé onítara ni. Pọ́ọ̀lù lo ara rẹ̀ tokuntokun, ó wàásù ìhìn rere náà ní gbogbo àgbègbè Mẹditaréníà. Nígbà tí àpọ́sítélì tí kì í rẹ̀ yìí ń sọ ìdí tí òun fi ń fi ìtara pòkìkí Ìjọba náà, ó ní: “Wàyí o, bí mo bá ń polongo ìhìn rere, kì í ṣe ìdí kankan fún mi láti ṣògo, nítorí àìgbọ́dọ̀máṣe wà lórí mi. Ní ti gidi, mo gbé bí èmi kò bá polongo ìhìn rere!” (1 Kọ́ríńtì 9:16) Ṣé kìkì gbígba ẹ̀mí ara rẹ̀ là ló ká Pọ́ọ̀lù lára? Rárá o. Kì í ṣe onímọtara-ẹni-nìkan. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fẹ́ kí àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú jàǹfààní látinú ìhìn rere náà. Ó kọ̀wé pé: “Mo ń ṣe ohun gbogbo nítorí ìhìn rere, kí n lè di alájọpín nínú rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn.”—1 Kọ́ríńtì 9:23.
4. Irin iṣẹ́ wo làwọn Kristẹni òṣìṣẹ́ kà sí pàtàkì jù lọ?
4 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ òṣìṣẹ́ tó mọ̀wọ̀n ara rẹ̀, tó mọ̀ pé òun ò lè gbara lé kìkì òye ti ara òun. Gẹ́gẹ́ bí káfíńtà kan ṣe nílò òòlù, bẹ́ẹ̀ náà ni Pọ́ọ̀lù nílò àwọn irin iṣẹ́ tó yẹ láti mú kí òtítọ́ Ọlọ́run wọ àwọn olùgbọ́ rẹ̀ lọ́kàn ṣinṣin. Irin iṣẹ́ wo ni Pọ́ọ̀lù wá lò ní ti gidi? Ìwé Mímọ́, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni. Bákan náà, Bíbélì ni olórí irin iṣẹ́ tá a máa ń lò, tó ń ràn wá lọ́wọ́ láti sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn.
5. Tá a bá fẹ́ jẹ́ òjíṣẹ́ tó jáfáfá, kí la ní láti ṣe láfikún sí fífa ọ̀rọ̀ yọ látinú Ìwé Mímọ́?
5 Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé fífi ọwọ́ tí ó tọ̀nà mú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ju kéèyàn kàn máa fa ọ̀rọ̀ yọ látinú rẹ̀. Ó lo “ìyíniléròpadà.” (Ìṣe 28:23) Lọ́nà wo ló gbà lò ó? Pọ́ọ̀lù kẹ́sẹ̀ járí nínú lílo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó wà lákọsílẹ̀ láti yí ọ̀pọ̀ èèyàn lérò padà kí wọ́n lè tẹ́wọ́ gba òtítọ́ Ìjọba náà. Ó bá wọn fèrò wérò. Odindi oṣù mẹ́ta gbáko ni Pọ́ọ̀lù fi wà nínú sínágọ́gù kan ní Éfésù tó ‘ń sọ àsọyé, tó sì ń lo ìyíniléròpadà nípa ìjọba Ọlọ́run.’ Bó tilẹ̀ jẹ́ pé “àwọn kan ń sọ ara wọn di aláyà líle, tí wọn kò sì gbà gbọ́,” síbẹ̀ àwọn mìíràn fetí sílẹ̀. Nítorí iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí Pọ́ọ̀lù ṣe ní Éfésù yìí, “ọ̀rọ̀ Jèhófà ń bá a nìṣó ní gbígbilẹ̀ àti ní bíborí.”—Ìṣe 19:8, 9, 20.
6, 7. Ọ̀nà wo ni Pọ́ọ̀lù gbà ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lógo, báwo làwa náà ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?
6 Gẹ́gẹ́ bí olùfi ìtara pòkìkí Ìjọba náà, Pọ́ọ̀lù ‘ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lógo.’ (Róòmù 11:13) Lọ́nà wo? Kò nífẹ̀ẹ́ sí gbígbé ara rẹ̀ ga rárá; bẹ́ẹ̀ ni kò sì tì í lójú láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ òun gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run. Dípò ìyẹn, ó ka iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ sí ọlá tó ga jù lọ. Pọ́ọ̀lù lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ́nà tó jáfáfá tó sì gbéṣẹ́. Ìgbòkègbodò rẹ̀ tó méso jáde jẹ́ ìṣírí fún àwọn ẹlòmíràn, tíyẹn sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti túbọ̀ ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn láṣepé. Ó tún ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lógo lọ́nà yìí pẹ̀lú.
7 Bíi ti Pọ́ọ̀lù, àwa náà tá a jẹ́ òjíṣẹ́ lè ṣe iṣẹ́ wa lógo nípa lílo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ́nà tó gbéṣẹ́ ní gbogbo ìgbà. Ní gbogbo ọ̀nà tá a gba ń wàásù, ohun tá a gbọ́dọ̀ máa lépa jù lọ ni bá a ó ṣe ka ohun kan látinú Ìwé Mímọ́ fún gbogbo èèyàn tó bá ṣeé ṣe fún wa láti bá sọ̀rọ̀. Báwo la ṣe lè ka Ìwé Mímọ́ láti yíni lérò padà? Gbé àwọn ọ̀nà pàtàkì mẹ́ta yẹ̀ wò: (1) Darí àfiyèsí àwọn èèyàn sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ́nà tó máa fi ọ̀wọ̀ fún un. (2) Fọgbọ́n ṣàlàyé ohun tí Bíbélì wí, kó o sì sọ bó ṣe ti ohun tó o fẹ́ fi kọ́ni lẹ́yìn. (3) Báwọn fèrò-wérò látinú Ìwé Mímọ́ lọ́nà tó fi hàn pé ohun tó ò ń sọ dá ọ lójú.
8. Àwọn irin iṣẹ́ wo ló wà fún iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà lónìí, báwo lo sì ṣe ń lò wọ́n?
8 Àwọn olùpòkìkí Ìjọba náà lóde òní ní àwọn ìrìn iṣẹ́ kan tí Pọ́ọ̀lù ò ní lákòókò tó ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Lára wọn ni àwọn ìwé, ìwé ìròyìn, ìwé pẹlẹbẹ, ìwé ìléwọ́, ìwé àṣàrò kúkúrú, ohùn tá a gbà sílẹ̀ sórí kásẹ́ẹ̀tì àti fídíò. Ohun mìíràn tá a tún lò ní ọ̀rúndún tó kọjá ni, káàdì ìjẹ́rìí, ẹ̀rọ giramafóònù, ọkọ̀ tó ní gbohùngbohùn, àti ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ lórí rédíò. Àmọ́ ṣá o, irin iṣẹ́ wa tó ṣe pàtàkì jù lọ ni Bíbélì, a sì ní láti lo irin iṣẹ́ tí kò lẹ́gbẹ́ yìí lọ́nà tó yẹ.
A Gbọ́dọ̀ Fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa Lẹ́yìn
9, 10. Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ látinú ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fún Tímótì nípa bó ṣe yẹ ká máa lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
9 Báwo la ṣe lè lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí irin iṣẹ́ tó gbéṣẹ́? A lè lò ó nípa títẹ̀lé àwọn ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ ní tààràtà fún Tímótì tó jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ rẹ̀ pé: “Sa gbogbo ipá rẹ láti fi ara rẹ hàn fún Ọlọ́run ní ẹni tí a tẹ́wọ́ gbà, aṣiṣẹ́ tí kò ní ohun kankan láti tì í lójú, tí ń fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́.” (2 Tímótì 2:15) Kí ni ‘fífi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́’ ní nínú?
10 Ohun tí ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a pè ní “fi ọwọ́ títọ̀nà mú” túmọ̀ sí ní ṣáńgílítí ni “gígé nǹkan ní ọ̀gbọnrangandan” tàbí “láti la ọ̀nà kan tọ́.” Kìkì ibi tí Pọ́ọ̀lù ti ń gba Tímótì níyànjú nìkan ni ọ̀rọ̀ yẹn ti wáyé nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì. A tún lè lo ọ̀rọ̀ kan náà yìí láti ṣàpèjúwe kíkọ pooro ebè tó tọ́ sínú oko kan. Pooro ebè tó rí wọ́gọwọ̀gọ yóò kó ìtìjú bá àgbẹ̀ kan tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́. Kí Tímótì lè jẹ́ “aṣiṣẹ́ tí kò ní ohun kankan láti tì í lójú,” a rán an létí pé a kò ní gbà á láyè rárá láti yà kúrò nínú àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Tímótì kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí èrò ti ara rẹ̀ nípa lórí àwọn ohun tó fi ń kọ́ni. Ó gbọ́dọ̀ gbé ìwàásù rẹ̀ àti ẹ̀kọ́ tó fi ń kọ́ni karí Ìwé Mímọ́ nìkan. (2 Tímótì 4:2-4) Nípa ṣíṣe èyí, èrò àwọn ọlọ́kàntútù èèyàn yóò máa bá èrò Jèhófà mú lórí àwọn nǹkan, wọn ò ní fara mọ́ ìmọ̀ ọgbọ́n orí ti ayé. (Kólósè 2:4, 8) Bákan náà lọ̀rọ̀ rí lónìí.
Ìwà Wa Gbọ́dọ̀ Dára
11, 12. Ipa wo ni ìwà wa ní lórí bá a ṣe ń fi ọwọ́ títọ̀nà mú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
11 Kì í ṣe nípa kíkéde òtítọ́ nìkan la ò fi sọ pé a ń fi ọwọ́ títọ̀nà mú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ìwà wa gbọ́dọ̀ bá ohun tá a ń sọ mu pẹ̀lú. “Alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run” ni wá, ìdí nìyẹn tí a ò fi gbọ́dọ̀ jẹ́ òṣìṣẹ́ tó ń ṣe àgàbàgebè. (1 Kọ́ríńtì 3:9) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Bí ó ti wù kí ó rí, ǹjẹ́ ìwọ, ẹni tí ń kọ́ ẹlòmíràn, kò kọ́ ara rẹ? Ìwọ, ẹni tí ń wàásù pé ‘Má jalè,’ ìwọ ha ń jalè bí? Ìwọ, ẹni tí ń sọ pé ‘Má ṣe panṣágà,’ ìwọ ha ń ṣe panṣágà bí? Ìwọ, ẹni tí ń fi ìkórìíra tẹ̀gàntẹ̀gàn hàn sí àwọn òrìṣà, ìwọ ha ń ja àwọn tẹ́ńpìlì lólè bí?” (Róòmù 2:21, 22) Nítorí náà, ọ̀nà kan tí àwa tó jẹ́ òṣìṣẹ́ Ọlọ́run lóde òní lè gbà fi ọwọ́ títọ̀nà mú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni pé ká tẹ̀lé ìmọ̀ràn tó sọ pé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.”—Òwe 3:5, 6.
12 Kí làwọn àbájáde tá a lè retí látinú fífi ọwọ́ títọ̀nà mú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? Ṣàgbéyẹ̀wò agbára tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó wà lákọsílẹ̀ lè ní lórí ìgbésí ayé àwọn ọlọ́kàntútù èèyàn.
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní Agbára Láti Yíni Padà
13. Kí ni fífi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò lè ṣe fún ẹnì kan?
13 Nígbà táwọn èèyàn bá gbà pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣeé gbára lé, àwọn ìhìn inú rẹ̀ máa ń ni ipa tó lágbára tó lè ran wọ́n lọ́wọ́ láti yí ìgbésí ayé wọn padà lọ́nà tó yani lẹ́nu. Pọ́ọ̀lù ti rí iṣẹ́ tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe, ó sì ti rí ipa rere tó ní lórí àwọn tó di Kristẹni ní ìlú Tẹsalóníkà ìgbàanì. Ìdí nìyẹn tó fi sọ fún wọn pé: “Àwa pẹ̀lú . . ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run láìdabọ̀, nítorí nígbà tí ẹ gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí tí ẹ gbọ́ láti ọ̀dọ̀ wa, ẹ tẹ́wọ́ gbà á, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ènìyàn, ṣùgbọ́n, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ lótìítọ́, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí tí ó wà lẹ́nu iṣẹ́ pẹ̀lú nínú ẹ̀yin onígbàgbọ́.” (1 Tẹsalóníkà 2:13) Lójú àwọn Kristẹni wọ̀nyẹn, àní, lójú gbogbo àwọn tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn tòótọ́ fún Kristi, ọgbọ́n orí èèyàn kò já mọ́ nǹkan kan rárá tá a bá fi wéra pẹ̀lú ọgbọ́n gíga jù lọ tí Ọlọ́run ní. (Aísáyà 55:9) Àwọn ará Tẹsalóníkà “tẹ́wọ́ gba ọ̀rọ̀ náà lábẹ́ ìpọ́njú púpọ̀ pẹ̀lú ìdùnnú ẹ̀mí mímọ́,” wọ́n sì di àpẹẹrẹ fún àwọn mìíràn tó jẹ́ onígbàgbọ́.—1 Tẹsalóníkà 1:5-7.
14, 15. Báwo ni ìhìn inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe lágbára tó, kí sì nídìí?
14 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lágbára gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà tó jẹ́ Orísun rẹ̀ ṣe lágbára. Ó wá látọ̀dọ̀ “Ọlọ́run alààyè,” ẹni tó jẹ́ pé nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ “ni a ṣe ọ̀run,” ọ̀rọ̀ yẹn sì máa ń ‘ní àṣeyọrí sí rere tí ó dájú nínú èyí tó tìtorí rẹ̀ rán an.’ (Hébérù 3:12; Sáàmù 33:6; Aísáyà 55:11) Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ kan sọ pé: “Ọlọ́run kò ya ara rẹ̀ kúrò lára Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Kò sọ pé ohun àjèjì ló jẹ́ sí òun. . . . Nítorí náà, kì í ṣe òkú ọ̀rọ̀, òun kì í dágunlá sí ohun táwọn èèyàn bá ṣe sí ọ̀rọ̀ náà; nítorí pé ó jẹ́ ìdè ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run alààyè.”
15 Báwo ni ìhìn tó tinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wá ṣe lágbára tó? Ó ní agbára tó ga. Abájọ tí Pọ́ọ̀lù fi kọ̀wé pé: “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára, ó mú ju idà olójú méjì èyíkéyìí lọ, ó sì ń gúnni àní títí dé pípín ọkàn àti ẹ̀mí níyà, àti àwọn oríkèé àti mùdùnmúdùn wọn, ó sì lè fi òye mọ ìrònú àti àwọn ìpètepèrò ọkàn-àyà.”—Hébérù 4:12.
16. Báwo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe lè yí ẹnì kan padà tó?
16 Ìhìn tó wà nínú àkọsílẹ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run “mú ju idà olójú méjì èyíkéyìí lọ.” Nípa bẹ́ẹ̀, ó ní agbára tí ń wọni lọ́kàn gan-an, èyí tó ju ohun èlò tàbí irin iṣẹ́ èyíkéyìí téèyàn lè ní lọ. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa ń gúnni wọnú ọkàn lọ́hùn-ún, ó sì lè yí onítọ̀hún padà láti inú wá, kí ó nípa lórí bó ṣe ń ronú àti àwọn ohun tó nífẹ̀ẹ́ sí, kó sì sọ ọ́ di òṣìṣẹ́ tó jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run. Ẹ ò rí i pé irin iṣẹ́ tó lágbára gan-an ló jẹ́!
17. Ṣàlàyé agbára tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní láti yíni padà.
17 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa ń ṣí ohun tí ẹnì kan jẹ́ gan-an nínú lọ́hùn-ún payá tí á wá fi hàn pé ẹni náà yàtọ̀ sóhun tó rò pé òun jẹ́ tàbí ohun tó jẹ́ káwọn ẹlòmíràn gbà pé òun jẹ́. (1 Sámúẹ́lì 16:7) Kódà ẹni tó jẹ́ olubi lè fi ohun tó jẹ́ pa mọ́ nígbà mìíràn kó máa ṣe bí olójú àánú tàbí olùfọkànsìn. Àwọn ẹni ibi máa ń díbọ́n kí wọ́n lè rọ́nà ṣe iṣẹ́ ibi wọn. Àwọn agbéraga máa ń gbé agọ̀ ìrẹ̀lẹ̀ wọ̀ nígbà tí wọ́n bá fẹ́ káwọn èèyàn máa yìn wọ́n. Àmọ́, nípa fífi ohun tó wà lọ́kàn ẹni hàn, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè mú kí ẹnì kan tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà rẹ̀ sílẹ̀ kí ó sì “gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, èyí tí a dá ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run nínú òdodo tòótọ́ àti ìdúróṣinṣin.” (Éfésù 4:22-24) Àwọn ẹ̀kọ́ inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tún lè sọ àwọn onítìjú èèyàn di akíkanjú Ẹlẹ́rìí fún Jèhófà àti olùfìtara pòkìkí Ìjọba Ọlọ́run.—Jeremáyà 1:6-9.
18, 19. Sọ bí òtítọ́ inú Ìwé Mímọ́ ṣe lè yí èrò ẹnì kan padà, bá a ṣe fi hàn nínú ìpínrọ̀ yìí tàbí látinú ìrírí tó o ní lóde ẹ̀rí.
18 Agbára tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní láti yíni padà ti ní ipa tó dára lórí àwọn èèyàn níbí gbogbo. Bí àpẹẹrẹ, àwọn olùpòkìkí Ìjọba Ọlọ́run láti Phnom Penh, Cambodia, máa ń wàásù ní ẹkùn-ìpínlẹ̀ Kompong Cham lẹ́ẹ̀mejì lóṣù. Lẹ́yìn tí àwùjọ àlùfáà ibẹ̀ sọ ohun tí kò dára nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni obìnrin kan tó jẹ́ pásítọ̀ lágbègbè náà wá ṣètò pé òun á bá àwọn Ẹlẹ́rìí fọ̀rọ̀ wérọ̀ nígbà tí wọ́n bá tún padà wá sí àgbègbè náà. Obìnrin yìí da ọ̀pọ̀ ìbéèrè bò wọ́n lórí ṣíṣayẹyẹ àwọn ọdún, ó sì tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa bí wọ́n ṣe ń bá a fèrò-wérò látinú Ìwé Mímọ́. Ó wá sọ lẹ́yìn náà pé: “Mo ti wá mọ̀ báyìí pé ohun táwọn pásítọ̀ ẹlẹgbẹ́ mi ń sọ nípa yín kì í ṣe òótọ́ rárá! Wọ́n sọ pé ẹ kì í lo Bíbélì, àmọ́ òun nìkan lẹ lò láàárọ̀ yìí!”
19 Obìnrin yìí ń bá ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tó ń ní pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí lọ, kò sì jẹ́ kí ìbẹ̀rù pé wọ́n lè yọ òun kúrò nípò pásítọ̀ dá a dúró. Ó sọ fún ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan nípa ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tó ń ní pẹ̀lú àwọn èèyàn náà látinú Ìwé Mímọ́, ọ̀rẹ́ rẹ̀ yìí sì bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí. Ohun tí ọ̀rẹ́ yìí ń kọ́ wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan-an débi pé nígbà kan tí ìsìn ń lọ lọ́wọ́ ní ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀, kò mọ̀gbà tó sọ pé, “Ẹ wá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà!” Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn ni kò lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì náà mọ́. Obìnrin tó jẹ́ pásítọ̀ tẹ́lẹ̀ yìí, ọ̀rẹ́ rẹ̀, àtàwọn mìíràn bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
20. Báwo ni ìrírí obìnrin kan ní Gánà ṣe ṣàpèjúwe agbára tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní?
20 A tún ṣàpèjúwe agbára tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Paulina, ìyẹn obìnrin kan ní Gánà. Ẹnì kan tó jẹ́ olùpòkìkí Ìjọba náà tó sì jẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ń bá a ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì látinú ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun.a Oníyàwó púpọ̀ ni ọkọ tí Paulina fẹ́, ó sì wá rí i pé òun ní láti ṣe àwọn ìyípadà kan, àmọ́ ọkọ rẹ̀ àtàwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ fàáké kọ́rí, wọ́n làwọn ò gbà. Bàbá ìyá rẹ̀ tó jẹ́ adájọ́ ní ilé ẹjọ́ gíga, tó sì tún jẹ́ alàgbà ní ṣọ́ọ̀ṣì, gbìyànjú láti yí i lérò padà nípa títúmọ̀ ohun tó wà nínú Mátíù 19:4-6 sọ́nà òdì fún un. Ohun tí adájọ́ náà sọ dà bí òótọ́ ọ̀rọ̀, àmọ́ kíá ni Paulina rí i pé èyí ò yàtọ̀ sí bí Sátánì ṣe ṣi Ìwé Mímọ́ túmọ̀ nígbà tó ń dán Jésù Kristi wò. (Mátíù 4:5-7) Ó rántí ọ̀rọ̀ yíyè kooro tí Jésù sọ nípa ìgbéyàwó, tó sọ ní kedere pé Ọlọ́run dá wọn ní akọ kan àti abo kan, kì í ṣe ní akọ kan àti àwọn abo, àti pé àwọn méjì lo sọ pé yóò di ara kan, kì í ṣe àwọn mẹ́ta. Kò yí ìpinnu tó ṣe yìí padà, níkẹyìn kóòtù ìbílẹ̀ fọwọ́ sí i pé kó kọ ọkọ rẹ̀ tó jẹ́ akóbìnrinjọ yìí sílẹ̀. Láìpẹ́, ó ṣe ìrìbọmi gẹ́gẹ́ bí olùpòkìkí Ìjọba Ọlọ́run, inú rẹ̀ sì ń dùn.
Ẹ Máa Bá A Lọ ní Fífi Ọwọ́ Títọ̀nà Mú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
21, 22. (a) Kí la fẹ́ kó jẹ́ ìpinnu wa gẹ́gẹ́ bí olùpòkìkí Ìjọba Ọlọ́run? (b) Kí la ó jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
21 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó wà lákọsílẹ̀ jẹ́ irin iṣẹ́ tó lágbára gan-an tó yẹ ká máa lò láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ kí wọ́n lè yí ìgbésí ayé wọn padà kí ó bàa ṣeé ṣe fún wọn láti sún mọ́ Jèhófà. (Jákọ́bù 4:8) Gẹ́gẹ́ bí àwọn òṣìṣẹ́ tó mọṣẹ́ dunjú ṣe máa ń lo àwọn irin iṣẹ́ wọn láti ṣe iṣẹ́ wọn láṣeyọrí, kí ó jẹ́ ìpinnu tíwa náà láti sa gbogbo ipá wa láti máa lo Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ́nà tó jáfáfá nínú iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé wa lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí olùpòkìkí Ìjọba rẹ̀.
22 Báwo la ṣe lè túbọ̀ máa fi ọwọ́ títọ̀nà mú Ìwé Mímọ́ nínú iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn tá à ń ṣe? Ọ̀nà kan ni pé ká túbọ̀ mọ bó ṣe yẹ ká jẹ́ olùkọ́ tó lè yíni lérò padà. Jọ̀wọ́ ka àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e, nítorí pé ó mẹ́nu kan àwọn ọ̀nà tá a lè gbà kọ́ni ká sì ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti tẹ́wọ́ gba ìhìn Ìjọba náà.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Àwọn irin iṣẹ́ wo ló wà lárọ̀ọ́wọ́tó àwọn olùpòkìkí Ìjọba Ọlọ́run?
• Àwọn ọ̀nà wo ni Pọ́ọ̀lù gbà fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ Ìjọba náà?
• Kí ni fífi ọwọ́ títọ̀nà mú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wé mọ́?
• Báwo ni Ọ̀rọ̀ Jèhófà tó wà lákọsílẹ̀ ṣe jẹ́ irin iṣẹ́ alágbára?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Díẹ̀ lára àwọn irin iṣẹ́ táwọn Kristẹni ń lò nínú iṣẹ́ pípolongo Ìjọba náà