O Ha Ti Wọnú Ìsinmi Ọlọ́run Bí?
“Ẹni tí ó ti wọnú ìsinmi Ọlọ́run, òun pẹ̀lú ti sinmi kúrò nínú àwọn iṣẹ́ tirẹ̀.”—HÉBÉRÙ 4:10.
1. Èé ṣe tí ìsinmi fi jẹ́ ohun tí a ń fẹ́ tó bẹ́ẹ̀?
ÌSINMI. Ọ̀rọ̀ yìí mà dùn-ún gbọ́ létí o, ó sì tuni lára! Níwọ̀n bí a ti ń gbé nínú ayé bóò-lọ-o-yàá-mi àti oníhílàhílo ti òde òní, ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wa ni yóò gbà pé a nílò ìsinmi díẹ̀. Yálà a jẹ́ ọ̀dọ́ tàbí àgbàlagbà, yálà a ti ṣègbéyàwó tàbí a ṣì jẹ́ àpọ́n, ìgbésí ayé ojoojúmọ́ ti lè kó másùnmáwo bá wa, kí ó sì mú kí ó rẹ̀ wá. Fún àwọn tí ara wọn kò le tó tàbí tí wọ́n jẹ́ aláàbọ̀ ara, ojúmọ́ kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìpèníjà. Gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti sọ, “gbogbo ìṣẹ̀dá ń bá a nìṣó ní kíkérora pa pọ̀ àti ní wíwà nínú ìrora pa pọ̀ títí di ìsinsìnyí.” (Róòmù 8:22) Ẹnì kan tí ń sinmi lè máà jẹ́ ọ̀lẹ. Ìsinmi jẹ́ ohun tí ara wa ń fẹ́, ó sì pọndandan.
2. Láti ìgbà wo ni Jèhófà ti ń sinmi?
2 Ó ti pẹ́ tí Jèhófà Ọlọ́run alára ti ń sinmi. Nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì, a kà pé: “Bí ọ̀run àti ilẹ̀ ayé àti gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn ṣe wá sí àṣeparí nìyẹn. Àti ní ọjọ́ keje, Ọlọ́run dé àṣeparí iṣẹ́ rẹ̀ tí ó ti ṣe, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sinmi ní ọjọ́ keje kúrò nínú gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ tí ó ti ṣe.” “Ọjọ́ keje” jẹ́ ọjọ́ pàtàkì sí Jèhófà, nítorí àkọsílẹ̀ tí a mí sí ń bá a lọ láti sọ pé: “Ọlọ́run sì tẹ̀ síwájú láti bù kún ọjọ́ keje, ó sì ṣe é ní ọlọ́wọ̀.”—Jẹ́nẹ́sísì 2:1-3.
Ọlọ́run Sinmi Kúrò Nínú Iṣẹ́ Rẹ̀
3. Kí ni kò lè jẹ́ ìdí tí Ọlọ́run fi sinmi?
3 Èé ṣe tí Ọlọ́run fi sinmi ní “ọjọ́ keje”? Dájúdájú, kì í ṣe nítorí pé ó rẹ̀ ẹ́ ni ó fi sinmi. Jèhófà ní “ọ̀pọ̀ yanturu okun rẹ̀ alágbára gíga . . . àárẹ̀ kì í mú un, bẹ́ẹ̀ ni agara kì í dá a.” (Aísáyà 40:26, 28) Ọlọ́run kò sì sinmi nítorí pé ara rẹ̀ ń fẹ́ kí ó dáwọ́ dúró fún ìgbà díẹ̀ tàbí kí ó yí ìgbòkègbodò rẹ̀ padà, nítorí Jésù sọ fún wa pé: “Baba mi ti ń bá a nìṣó ní ṣíṣiṣẹ́ títí di ìsinsìnyí, èmi náà sì ń bá a nìṣó ní ṣíṣiṣẹ́.” (Jòhánù 5:17) Bí ó ti wù kí ó rí, “Ọlọ́run jẹ́ Ẹ̀mí,” kì í ṣe bí ará ṣe ń ṣiṣẹ́ àti àìní àwọn ẹ̀dá tí ó ṣeé fojú rí ni ó ń pinnu ohun tí yóò ṣe.—Jòhánù 4:24.
4. Lọ́nà wo ni “ọjọ́ keje” fi yàtọ̀ sí “ọjọ́” mẹ́fà tí ó ṣáájú?
4 Báwo ni a ṣe lè ní ìjìnlẹ̀ òye nípa ìdí tí Ọlọ́run fi sinmi ní “ọjọ́ keje”? Nípa ṣíṣàkíyèsí pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé inú Ọlọ́run dùn gan-an sí ohun tí ó ti ṣe parí ní àkókò gígùn ti “ọjọ́” mẹ́fà ti ìṣẹ̀dá tí ó ṣáájú, ní pàtó ó bù kún “ọjọ́ keje,” ó sì kéde rẹ̀ pé ó jẹ́ “ọlọ́wọ̀.” Ìwé atúmọ̀ èdè náà, Concise Oxford Dictionary, túmọ̀ “ọlọ́wọ̀” gẹ́gẹ́ bí “ohun tí a yà sí mímọ́ pátápátá tàbí tí a yà sọ́tọ̀ (fún ọlọ́run kan tàbí fún ète ìjọsìn kan).” Nípa báyìí, bíbùkún tí Jèhófà bù kún “ọjọ́ keje,” tí ó sì kéde rẹ̀ ní ọlọ́wọ̀ fi hàn pé ọjọ́ náà àti “ìsinmi” rẹ̀ gbọ́dọ̀ ní í ṣe pẹ̀lú ìfẹ́ àti ète rẹ̀ ọlọ́wọ̀ dípò kí ó ní í ṣe pẹ̀lú ohunkóhun tí ó jẹ́ àìní rẹ̀. Kí ni wọn ní í ṣe pẹ̀lú ara wọn?
5. Kí ni Ọlọ́run gbé kalẹ̀ láàárín “ọjọ́” mẹ́fà àkọ́kọ́ ti ìṣẹ̀dá?
5 Ní “ọjọ́” mẹ́fà ti ìṣẹ̀dá tí ó ṣáájú, Ọlọ́run ti parí gbogbo àwọn ìlànà ìyípoyípo àti òfin tí ń ṣàkóso ọ̀nà ìṣiṣẹ́ ilẹ̀ ayé àti ohun gbogbo tí ó wà láyìíká rẹ̀, wọ́n sì ti ń báṣẹ́ lọ. Nísinsìnyí, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ń kọ́ bí àwọn iṣẹ́ ọnà wọ̀nyí ti jẹ́ àgbàyanu tó. Nígbà tí “ọjọ́ kẹfà” ń parí lọ, Ọlọ́run dá tọkọtaya àkọ́kọ́, ó sì fi wọ́n sí “ọgbà kan ní Édẹ́nì, síhà ìlà-oòrùn.” Paríparí rẹ̀, Ọlọ́run kéde ète rẹ̀ nípa ìdílé ènìyàn àti ilẹ̀ ayé nínú àwọn ọ̀rọ̀ alásọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí: “Ẹ máa so èso, kí ẹ sì di púpọ̀, kí ẹ sì kún ilẹ̀ ayé, kí ẹ sì ṣèkáwọ́ rẹ̀, kí ẹ sì máa jọba lórí ẹja òkun àti àwọn ẹ̀dá tí ń fò ní ojú ọ̀run àti olúkúlùkù ẹ̀dá alààyè tí ń rìn lórí ilẹ̀ ayé.”—Jẹ́nẹ́sísì 1:28, 31; 2:8.
6. (a) Ní òpin “ọjọ́ kẹfà,” báwo ni Ọlọ́run ti rí gbogbo ohun tí ó ti dá sí? (b) Lọ́nà wo ni “ọjọ́ keje” fi jẹ́ ọlọ́wọ̀?
6 Bí “ọjọ́ kẹfà” ti ìṣẹ̀dá ti ń wá sí òpin, àkọsílẹ̀ náà sọ fún wa pé: “Ọlọ́run rí ohun gbogbo tí ó ti ṣe, sì wò ó! ó dára gan-an ni.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:31) Ohun gbogbo tí Ọlọ́run ti ṣe sì tẹ́ ẹ lọ́rùn. Nípa báyìí, ó sinmi, tàbí kí a sọ pé ó ṣíwọ́ ṣíṣiṣẹ́ ìṣẹ̀dá mìíràn lórí ilẹ̀ ayé. Ṣùgbọ́n, bí ọgbà párádísè náà ti pinminrin, tí ó sì lẹ́wà tó, àgbègbè kéréje ni ó kárí, ènìyàn méjì péré sì ni ó wà lórí ilẹ̀ ayé. Yóò gba àkókò kí ilẹ̀ ayé àti ìdílé ènìyàn tó dé ipò tí Ọlọ́run ṣèlérí. Nítorí ìdí yìí, ó yan “ọjọ́ keje,” ọjọ́ tí yóò mú kí ó ṣeé ṣe fún gbogbo ohun tí òun ti fi “ọjọ́” mẹ́fà ìṣáájú dá láti dàgbà ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ ọlọ́wọ̀ rẹ̀. (Fi wé Éfésù 1:11.) Bí “ọjọ́ keje” náà ti ń parí lọ, ilẹ̀ ayé ì bá ti di párádísè àgbáyé ti àwọn ìdílé ènìyàn pípé. (Aísáyà 45:18) A ya “ọjọ́ keje” sọ́tọ̀, tàbí a yà á sí mímọ́ fún, ṣíṣe àṣeparí ìfẹ́ Ọlọ́run nípa ilẹ̀ ayé àti aráyé àti mímú ìfẹ́ náà ṣẹ. Lọ́nà yẹn ó jẹ́ “ọlọ́wọ̀.”
7. (a) Lọ́nà wo ni Ọlọ́run fi sinmi ní “ọjọ́ keje”? (b) Báwo ni ohun gbogbo yóò ṣe wá rí nígbà tí “ọjọ́ keje” yóò bá fi dópin?
7 Nítorí náà, Ọlọ́run sinmi kúrò nínú iṣẹ́ ìṣẹ̀dá rẹ̀ ní “ọjọ́ keje.” Ṣe ni ó dà bíi pé ó ṣíwọ́, tí ó sì yọ̀ǹda fún ohun tí ó ti gbé kalẹ̀ láti máa báṣẹ́ lọ. Ó dá a lójú ṣáká pé nígbà tí ó bá fi máa di òpin “ọjọ́ keje,” ohun gbogbo a ti ṣẹlẹ̀ bí ó ti pète rẹ̀. Àní bí ìṣòro tilẹ̀ wà, wọn ì bá ti borí rẹ̀. Gbogbo aráyé onígbọràn ni yóò jàǹfààní nígbà tí ìfẹ́ Ọlọ́run bá ṣẹ ní kíkún. Kò sí ohun tí yóò dí èyí lọ́wọ́, nítorí pé, ìbùkún Ọlọ́run wà lórí “ọjọ́ keje,” ó sì ṣe é ní “ọlọ́wọ̀.” Ẹ wo irú ìfojúsọ́nà ológo tí èyí jẹ́ fún aráyé onígbọràn!
Ísírẹ́lì Kùnà Láti Wọnú Ìsinmi Ọlọ́run
8. Ọjọ́ wo ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń pa Sábáàtì mọ́, báwo sì ni wọ́n ṣe ń ṣe é?
8 Orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì jàǹfààní nínú ìṣètò Jèhófà fún iṣẹ́ àti ìsinmi. Àní kí Ọlọ́run tó fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Òfin ní Òkè Sínáì pàápàá, ó tipasẹ̀ Mósè sọ fún wọn pé: “Kíyè sí òtítọ́ náà pé Jèhófà ti fún yín ní Sábáàtì. Ìdí nìyẹn tí ó fi ń fún yín ní oúnjẹ ọjọ́ méjì ní ọjọ́ kẹfà. Kí ẹ wà ní ìjókòó olúkúlùkù ní àyè rẹ̀. Kí ẹnikẹ́ni má ṣe jáde kúrò ní àdúgbò rẹ̀ ní ọjọ́ keje.” Ìyọrísí rẹ̀ ni pé “àwọn ènìyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí pa Sábáàtì mọ́ ní ọjọ́ keje.”—Ẹ́kísódù 16:22-30.
9. Èé ṣe tí kò fi sí iyèméjì pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi tayọ̀tayọ̀ tẹ́wọ́ gba ìyípadà tí òfin Sábáàtì mú wá?
9 Ìṣètò tuntun ni èyí jẹ́ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ ní oko ẹrú ní Íjíbítì. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ márùn-ún sí ọjọ́ mẹ́wàá ni àwọn ará Íjíbítì àti àwọn orílẹ̀-èdè yòókù fi ń ṣírò àkókò tiwọn, bóyá ni wọ́n fi fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ó wà ní oko ẹrú ní ọjọ́ kan láti sinmi. (Fi wé Ẹ́kísódù 5:1-9.) Nítorí náà, ó bọ́gbọ́n mu láti parí èrò sí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi tayọ̀tayọ̀ tẹ́wọ́ gba ìyípadà yìí. Dípò kíka ìṣètò Sábáàtì sí ìnira tàbí ìkálọ́wọ́kò, inú wọn gbọ́dọ̀ dùn láti tẹ̀ lé e. Àní, Ọlọ́run sọ fún wọn lẹ́yìn náà pé Sábáàtì jẹ́ láti rán wọn létí ìsìnrú wọn ní Íjíbítì àti bí òun ṣe dá wọn nídè.—Diutarónómì 5:15.
10, 11. (a) Nípa jíjẹ́ onígbọràn, kí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ì bá ti fojú sọ́nà fún láti gbádùn? (b) Èé ṣe tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi kùnà láti wọnú ìsinmi Ọlọ́run?
10 Bí ó bá jẹ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n bá Mósè jáde kúrò ní Íjíbítì jẹ́ onígbọràn ni, wọn ì bá ti ní àǹfààní wíwọ “ilẹ̀” tí a ṣèlérí náà, “tí ń ṣàn fún wàrà àti oyin.” (Ẹ́kísódù 3:8) Níbẹ̀, wọn ì bá ti gbádùn ìsinmi tòótọ́, kì í ṣe ní ọjọ́ Sábáàtì nìkan ṣùgbọ́n jálẹ̀ ìgbésí ayé wọn. (Diutarónómì 12:9, 10) Ṣùgbọ́n, ọ̀ràn kò rí bẹ́ẹ̀. Nípa wọn, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Àwọn wo ni wọ́n gbọ́, síbẹ̀síbẹ̀ tí wọ́n ṣokùnfà ìbínú kíkorò? Ní tòótọ́, kì í ha ṣe gbogbo àwọn tí wọ́n jáde kúrò ní Íjíbítì lábẹ́ Mósè ni wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀? Jù bẹ́ẹ̀ lọ, àwọn wo ni ọ̀ràn wọ́n sú Ọlọ́run fún ogójì ọdún? Kì í ha ṣe àwọn tí wọ́n dẹ́ṣẹ̀, tí òkú wọ́n ṣubú ní aginjù? Ṣùgbọ́n àwọn wo ni ó búra fún pé wọn kò ní wọnú ìsinmi òun bí kò ṣe àwọn tí wọ́n ṣe àìgbọràn? Nítorí náà, a rí i pé wọn kò lè wọnú rẹ̀ nítorí àìnígbàgbọ́.”—Hébérù 3:16-19.
11 Ẹ̀kọ́ ńlá mà ni èyí jẹ́ fún wa o! Nítorí àìnígbàgbọ́ wọn nínú Jèhófà, ìran yẹn kò rí ìsinmi tí ó ti ṣèlérí gbà. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n run nínú aginjù. Wọ́n kùnà láti fòye mọ̀ pé gẹ́gẹ́ bí àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù, wọ́n ní ohun kan ṣe pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run ní pípèsè ìbùkún fún àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé. (Jẹ́nẹ́sísì 17:7, 8; 22:18) Kàkà tí wọn yóò fi hùwà ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run, ìfẹ́-ọkàn ti ayé àti ti onímọtara-ẹni-nìkan wọn pín ọkàn wọn níyà pátápátá. Kí a má ṣe jìn sínú irú ọ̀fìn bẹ́ẹ̀ láé!—1 Kọ́ríńtì 10:6, 10.
Ìsinmi Kan Ń Bẹ
12. Ìfojúsọ́nà wo ni ó ṣì wà fún àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní, báwo sì ni ọwọ́ wọn ṣe lè tẹ̀ ẹ́?
12 Lẹ́yìn títọ́ka sí ìkùnà Ísírẹ́lì láti wọnú ìsinmi Ọlọ́run nítorí àìnígbàgbọ́, Pọ́ọ̀lù darí àfiyèsí rẹ̀ sí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàkíyèsí rẹ̀ nínú Hébérù 4:1-5, ó mú un dá wọn lójú pé “ó . . . ku ìlérí kan nílẹ̀ fún wíwọnú ìsinmi [Ọlọ́run].” Pọ́ọ̀lù rọ̀ wọ́n láti lo ìgbàgbọ́ nínú “ìhìn rere,” nítorí pé, “àwa tí a ti lo ìgbàgbọ́ wọnú ìsinmi náà ní tòótọ́.” Níwọ̀n bí ẹbọ ìràpadà Jésù ti mú Òfin náà kúrò lọ́nà fún wa, kì í ṣe ìsinmi nípa ti ara tí Sábáàtì pèsè ni Pọ́ọ̀lù ń tọ́ka sí níhìn-ín. (Kólósè 2:13, 14) Nípa ṣíṣàyọlò Jẹ́nẹ́sísì 2:2 àti Sáàmù 95:11, Pọ́ọ̀lù ń rọ àwọn Kristẹni, tí wọ́n jẹ́ Hébérù, láti wọnú ìsinmi Ọlọ́run.
13. Ní ṣíṣàyọlò Sáàmù 95, èé ṣe tí Pọ́ọ̀lù fi darí àfiyèsí sí ọ̀rọ̀ náà, “lónìí”?
13 Ṣíṣeéṣe náà láti wọnú ìsinmi Ọlọ́run ì bá ti jẹ́ “ìhìn rere” fún àwọn Kristẹni, tí wọ́n jẹ́ Hébérù, gan-an gẹ́gẹ́ bí ìsinmi Sábáàtì ì bá ti jẹ́ “ìhìn rere” fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ó wà ṣáájú wọn. Nítorí náà, Pọ́ọ̀lù rọ àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ láti má ṣe ṣàṣìṣe tí Ísírẹ́lì ṣe nínú aginjù. Ní ṣíṣàyọlò ohun tí a ń pè ní Sáàmù 95:7, 8 nísinsìnyí, ó pe àfiyèsí sí ọ̀rọ̀ náà, “lónìí,” bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti pẹ́ gan-an tí Ọlọ́run ti sinmi ṣíṣẹ̀dá. (Hébérù 4:6, 7) Kí ni lájorí ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù? Òun ni pé, “ọjọ́ keje” tí Ọlọ́run ti yà sọ́tọ̀ láti mú kí ète rẹ̀ nípa ilẹ̀ ayé àti aráyé ṣẹ ní kíkún, ṣì ń bá a lọ. Nítorí náà, ó jẹ́ ọ̀ràn kánjúkánjú fún àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ láti hùwà ní ìbámu pẹ̀lú ète náà dípò tí wọn yóò fi jẹ́ kí àwọn ìlépa onímọtara-ẹni-nìkan gbà wọ́n lọ́kàn. Lẹ́ẹ̀kan sí i, ó kìlọ̀ pé: “Ẹ má ṣe sé ọkàn-àyà yín le.”
14. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe fi hàn pé “ìsinmi” Ọlọ́run ṣì ń bá a lọ?
14 Ní àfikún sí i, Pọ́ọ̀lù fi hàn pé “ìsinmi” tí a ṣèlérí kì í wulẹ̀ ṣe ọ̀ràn títẹ̀dó sí Ilẹ̀ Ìlérí lábẹ́ ìdarí Jóṣúà. (Jóṣúà 21:44) Pọ́ọ̀lù jiyàn pé: “Bí Jóṣúà bá ti mú wọn lọ sí ibi ìsinmi kan, Ọlọ́run lẹ́yìn náà kì bá ti sọ̀rọ̀ ọjọ́ mìíràn.” Pẹ̀lú ìyẹn lọ́kàn, Pọ́ọ̀lù fi kún un pé: “Ìsinmi ti sábáàtì kan ṣì kù fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run.” (Hébérù 4:8, 9) Kí ni “ìsinmi ti sábáàtì”?
Wọnú Ìsinmi Ọlọ́run
15, 16. (a) Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà, “ìsinmi ti sábáàtì”? (b) Kí ni ó túmọ̀ sí ‘láti sinmi kúrò nínú iṣẹ́ ẹni’?
15 A túmọ̀ gbólóhùn náà, “ìsinmi ti sábáàtì,” láti inú ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà tí ó túmọ̀ sí “ṣíṣe sábáàtì.” (Kingdom Interlinear) Ọ̀jọ̀gbọ́n William Lane sọ pé: “Ọ̀rọ̀ náà rí ìtumọ̀ rẹ̀ pàtó gbà nínú ìtọ́ni lórí Sábáàtì tí ó pilẹ̀ nínú ẹ̀sìn àwọn Júù, tí a gbé ka Ẹ́kísódù 20:8-10, níbi tí a tẹnu mọ́ ọn pé ìsinmi àti ìyìn jẹ́ ohun kan náà . . . [Ó] tẹnu mọ́ apá pàtàkì ti àjọyọ̀ ṣíṣe àti ìdùnnú, tí a ń fi hàn nípa bíbu ọlá fún Ọlọ́run àti fífi ìyìn fún un.” Nítorí náà, ìsinmi tí a ṣèlérí kì í wulẹ̀ ṣe dídáwọ́ iṣẹ́ dúró. Ó jẹ́ pípa òpò atánnilókun tí kò ní ète nínú tì, kí a sí bẹ̀rẹ̀ sí lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn aláyọ̀ tí ń bọlá fún Ọlọ́run.
16 Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ tẹ̀ lé e ti èyí lẹ́yìn: “Nítorí ẹni tí ó ti wọnú ìsinmi Ọlọ́run, òun pẹ̀lú ti sinmi kúrò nínú àwọn iṣẹ́ tirẹ̀, gan-an gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti ṣe kúrò nínú tirẹ̀.” (Hébérù 4:10) Kì í ṣe tìtorí pé ó ti rẹ Ọlọ́run ni ó fi sinmi ní ọjọ́ keje ti ìṣẹ̀dá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ṣíwọ́ gbogbo iṣẹ́ ìṣẹ̀dá orí ilẹ̀ ayé kí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ lè dàgbà, kí ó wá sínú ògo kíkún, sí ìyìn àti ọlá rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí apá kan ìṣẹ̀dá Ọlọ́run, ó yẹ kí àwa pẹ̀lú bá ìṣètò rẹ̀ mu. Ó yẹ kí a ‘sinmi kúrò nínú àwọn iṣẹ́ wa,’ ìyẹn ni pé, kí a gbìyànjú láti dẹ́kun dídá ara wa láre níwájú Ọlọ́run nítorí kí a lè rí ìgbàlà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí a ní ìgbàgbọ́ nínú ohun tí Ọlọ́run ti ṣèlérí. Ó yẹ kí a nígbàgbọ́ pé ìgbàlà wa sinmi lórí ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi, ipasẹ̀ èyí tí a óò tún mú ohun gbogbo padà bá ète Ọlọ́run ṣọ̀kan.—Éfésù 1:8-14; Kólósè 1:19, 20.
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ń Sa Agbára
17. Ọ̀nà wo tí Ísírẹ́lì nípa ti ara tọ̀ ni a gbọ́dọ̀ yẹra fún?
17 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kùnà láti wọnú ìsinmi tí Ọlọ́run ti ṣèlérí nítorí àìgbọràn àti àìnígbàgbọ́ wọn. Nítorí náà, Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni, tí wọ́n jẹ́ Hébérù pé: “Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a sa gbogbo ipá wa láti wọnú ìsinmi yẹn, kí ẹnikẹ́ni má bàa ṣubú sínú àpẹẹrẹ ọ̀nà àìgbọràn kan náà.” (Hébérù 4:11) Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn Júù ti ọ̀rúndún kìíní kò lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù, ọ̀pọ̀ nínú wọn sì jìyà, wọn tún jewé iyá mọ́ ọn nígbà tí ètò àwọn nǹkan ti àwọn Júù dópin ní ọdún 70 Sànmánì Tiwa. Ẹ wo bí ó ti ṣe pàtàkì tó pé kí a nígbàgbọ́ nínú ọ̀rọ̀ ìlérí Ọlọ́run lónìí!
18. (a) Àwọn ìdí wo ni Pọ́ọ̀lù fúnni fún lílo ìgbàgbọ́ nínú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? (b) Báwo ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe “mú ju idà olójú méjì èyíkéyìí lọ”?
18 A ní ìdí yíyèkooro láti lo ìgbàgbọ́ nínú ọ̀rọ̀ Jèhófà. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára, ó mú ju idà olójú méjì èyíkéyìí lọ, ó sì ń gúnni àní títí dé pípín ọkàn àti ẹ̀mí níyà, àti àwọn oríkèé àti mùdùnmúdùn wọn, ó sì lè fi òye mọ ìrònú àti àwọn ìpètepèrò ọkàn-àyà.” (Hébérù 4:12) Bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tàbí ìhìn iṣẹ́ rẹ̀, “mú ju idà olójú méjì èyíkéyìí lọ.” Ó yẹ kí àwọn Kristẹni, tí wọ́n jẹ́ Hébérù rántí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn baba ńlá wọn. Nítorí àìka ìdájọ́ Jèhófà pé wọn yóò pa run nínú aginjù sí, wọ́n gbìyànjú láti wọ Ilẹ̀ Ìlérí náà. Ṣùgbọ́n Mósè kìlọ̀ fún wọn pé: “Àwọn ọmọ Ámálékì àti àwọn ọmọ Kénáánì wà níbẹ̀ níwájú yín; ẹ̀yin yóò sì tipa idà ṣubú dájúdájú.” Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fàáké kọ́rí, tí wọ́n sì ń bá ìrìn àjò wọn lọ, “àwọn ọmọ Ámálékì àti àwọn ọmọ Kénáánì tí ń gbé ní òkè ńlá yẹn sọ̀ kalẹ̀ wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kọlù wọ́n, tí wọ́n sì ń tú wọn ká títí dé Hóómà.” (Númérì 14:39-45) Lóòótọ́, ọ̀rọ̀ Jèhófà mú ju idà olójú méjì èyíkéyìí lọ, ó sì dájú ṣáká pé ẹnikẹ́ni tí ó bá mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìnáání rẹ̀ yóò jẹyán rẹ̀ níṣu.—Gálátíà 6:7-9.
19. Báwo ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe ń “gúnni” wọra tó, èé sì ti ṣe tí ó fi yẹ kí a gbà pé a óò jíhìn fún Ọlọ́run?
19 Ẹ wo bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti lágbára tó, “tí ó ń gúnni àní títí dé pípín ọkàn àti ẹ̀mí níyà, àti àwọn oríkèé àti mùdùnmúdùn”! Ó ń wọnú ìrònú àti ète ènìyàn, lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, ó ń gúnni wọnú mùdùnmúdùn inú egungun lọ́hùn-ún lọ́hùn-ún! Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí a ti gbà kúrò ní oko ẹrú Íjíbítì gbà láti pa Òfin Jèhófà mọ́, ó mọ̀ pé nínú ọkàn-àyà wọn lọ́hùn-ún, wọn kò mọrírì àwọn ohun tí òun pèsè fún wọn àti ohun tí òun béèrè lọ́wọ́ wọn. (Sáàmù 95:7-11) Kàkà tí wọn yóò fi ṣe ìfẹ́ rẹ̀, títẹ́ ìfẹ́ ọkàn ti ẹran ara wọn lọ́rùn nìkan ni ó jẹ wọ́n lógún. Nítorí náà, wọn kò wọnú ìsinmi tí Ọlọ́run ti ṣèlérí, ṣùgbọ́n wọ́n run nínú aginjù. Ó yẹ kí a fi èyíinì sọ́kàn, nítorí tí “kò . . . sí ìṣẹ̀dá tí kò hàn kedere sí ojú rẹ̀, ṣùgbọ́n ohun gbogbo wà ní ìhòòhò àti ní ṣíṣísílẹ̀ gbayawu fún ojú ẹni tí a óò jíhìn fún.” (Hébérù 4:13) Ǹjẹ́ kí a lè mú ìyàsímímọ́ wa sí Jèhófà ṣẹ, kí a má sì ṣe “fà sẹ́yìn sí ìparun.”—Hébérù 10:39.
20. Kí ní ń bẹ níwájú wa, kí sì ni a gbọ́dọ̀ ṣe nísinsìnyí láti wọnú ìsinmi Ọlọ́run?
20 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé “ọjọ́ keje”—ọjọ́ ìsinmi Ọlọ́run—kò tí ì dópin, ó wà lójúfò sí ṣíṣe àṣeparí ète rẹ̀ nípa ilẹ̀ ayé àti aráyé. Láìpẹ́ láìjìnnà, Mèsáyà Ọba, Jésù Kristi, yóò gbé ìgbésẹ̀ láti gba ilẹ̀ ayé lọ́wọ́ gbogbo àwọn tí ń tako ìfẹ́ Ọlọ́run, títí kan Sátánì Èṣù pàápàá. Nígbà Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìjọba Kristi, Jésù àti àwọn 144,000, alájùmọ̀ṣàkóso rẹ̀, yóò mú ilẹ̀ ayé àti aráyé wá sí ipò tí Ọlọ́run ti pète. (Ìṣípayá 14:1; 20:1-6) Àkókò nìyí fún wa láti fi hàn pé ìfẹ́ Jèhófà Ọlọ́run ni ó jẹ wá lógún. Kàkà tí a óò fi máa dá ara wa láre níwájú Ọlọ́run tí a óò sì máa wá ire ti ara wa, àkókò nìyí fún wa láti ‘sinmi kúrò nínú iṣẹ́ ti ara wa,’ kí a sì fi tọkàntọkàn sìn fún ire Ìjọba náà. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀ àti dídúró gẹ́gẹ́ bí olóòótọ́ sí Baba wa ọ̀run, Jèhófà, a óò láǹfààní láti gbádùn àwọn àjẹmọ́nú ti ìsinmi Ọlọ́run nísinsìnyí àti títí láéláé.
Ìwọ Ha Lè Ṣàlàyé Bí?
◻ Ète wo ni Ọlọ́run fi sinmi “ní ọjọ́ keje”?
◻ Ìsinmi wo ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ì bá ti gbádùn, ṣùgbọ́n èé ṣe tí wọ́n fi kùnà láti wọnú rẹ̀?
◻ Kí ni a gbọ́dọ̀ ṣe láti wọnú ìsinmi Ọlọ́run?
◻ Báwo ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe yè, tí ó lágbára, tí ó sì mú ju idà olójú méjì èyíkéyìí lọ?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa Sábáàtì mọ́, ṣùgbọ́n wọn kò wọnú ìsinmi Ọlọ́run. O ha mọ ohun tí ó fà á bí?