Ẹ Má Ṣe Di Olùgbọ́ Tí Ń gbàgbé
“Ẹ di olùṣe ọ̀rọ̀ náà, kì í sì í ṣe olùgbọ́ nìkan, ní fífi èrò èké tan ara yín jẹ.”—JÁKỌ́BÙ 1:22.
1. Àwọn iṣẹ́ ìyanu wo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì láǹfààní láti fojú ara wọn rí?
“MÁNIGBÀGBÉ” lọ̀rọ̀ tó yẹ láti fi ṣàpèjúwe àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jèhófà ṣe ní Íjíbítì ìgbàanì. Kò sí àní-àní pé amúni-kún-fún-ẹ̀rù-jẹ̀jẹ̀ ni ọ̀kọ̀ọ̀kan Ìyọnu Mẹ́wàá náà. Ohun tó tẹ̀ lé ìyọnu wọ̀nyẹn ni ìdáǹdè àgbàyanu ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó gba inú omi Òkun Pupa tó pínyà kọjá. (Diutarónómì 34:10-12) Ká ní ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyẹn ṣojú rẹ ni, kò jọ pé wàá gbàgbé Ẹni tó ṣe wọ́n láé. Ṣùgbọ́n, onísáàmù náà kọ ọ́ lórin pé: “Wọ́n [ìyẹn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì] gbàgbé Ọlọ́run Olùgbàlà wọn, Olùṣe àwọn ohun ńlá ní Íjíbítì, àwọn iṣẹ́ àgbàyanu ní ilẹ̀ Hámù, àwọn ohun amúnikún-fún-ẹ̀rù ní Òkun Pupa.”—Sáàmù 106:21, 22.
2. Kí ló fi hàn pé kò pẹ́ rárá tí Ísírẹ́lì pàdánù ìmọrírì tí wọ́n ní fún àwọn iṣẹ́ àrà Ọlọ́run?
2 Lẹ́yìn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì la Òkun Pupa já, wọ́n “bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀rù Jèhófà, wọ́n sì ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà.” (Ẹ́kísódù 14:31) Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa ohùn wọn pọ̀ mọ́ ti Mósè nínú kíkọ orin ìṣẹ́gun sí Jèhófà, Míríámù àtàwọn obìnrin yòókù bẹ̀rẹ̀ sí lu ìlù tanboríìnì sórin ọ̀hún, wọ́n sì fijó bẹ́ ẹ. (Ẹ́kísódù 15:1, 20) Àní sẹ́, àwọn iṣẹ́ àrà Jèhófà jọ àwọn èèyàn Ọlọ́run lójú. Àmọ́ kò pẹ́ tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí hùwà abaraá-móore-jẹ sí Ẹni tó ṣe iṣẹ́ àrà wọ̀nyẹn. Kété lẹ́yìn ìyẹn ni ọ̀pọ̀ lára wọn bẹ̀rẹ̀ sí ṣe bí ẹni tí iyè wọn ti ra. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ráhùn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí Jèhófà. Àwọn kan tiẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí bọ̀rìṣà, tí wọ́n sì ń ṣèṣekúṣe.—Númérì 14:27; 25:1-9.
Kí Ló Lè Mú Wa Gbàgbé?
3. Nítorí ẹ̀dá aláìpé táa jẹ́, kí ló ṣeé ṣe ká gbàgbé?
3 Ìwà àìní ìmọrírì Ísírẹ́lì mà kúkú ga o. Ṣùgbọ́n, ohun kan náà lè ṣẹlẹ̀ sí wa. Òótọ́ ni pé Ọlọ́run ò tíì ṣe irú àwọn iṣẹ́ ìyanu bẹ́ẹ̀ níṣojú wa. Àmọ́, ó dájú pé nǹkan mánigbàgbé ti ṣẹlẹ̀ nínú àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run. Àwọn kan lára wa lè rántí ìgbà táa tẹ́wọ́ gba òtítọ́ látinú Bíbélì. Àwọn àkókò aláyọ̀ míì lè jẹ́ ìgbà táa gbàdúrà ìyàsímímọ́ sí Jèhófà àtìgbà táa ṣe ìrìbọmi gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni tòótọ́. Ọ̀pọ̀ lára wa ti rí ọwọ́ Jèhófà lára wa ní àwọn àkókò mìíràn nínú ìgbésí ayé wa. (Sáàmù 118:15) Lékè gbogbo rẹ̀, a ti ní ìrètí ìgbàlà nípasẹ̀ ikú ìrúbọ tí Jésù Kristi, Ọmọ Ọlọ́run kú. (Jòhánù 3:16) Ṣùgbọ́n nítorí ẹ̀dá aláìpé táa jẹ́, nígbà tí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti àníyàn ìgbésí ayé bá dà bò wá, a lè tètè gbàgbé àwọn ohun rere tí Jèhófà ti ṣe fún wa.
4, 5. (a) Báwo ni Jákọ́bù ṣe kìlọ̀ nípa ewu dídi olùgbọ́ tí ń gbàgbé? (b) Báwo la ṣe lè fi àkàwé Jákọ́bù nípa ọkùnrin náà àti jígí sílò?
4 Nínú lẹ́tà tí Jákọ́bù, iyèkan Jésù, kọ sáwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, ó kìlọ̀ nípa dídi olùgbọ́ tí ń gbàgbé. Ó kọ̀wé pé: “Ẹ di olùṣe ọ̀rọ̀ náà, kì í sì í ṣe olùgbọ́ nìkan, ní fífi èrò èké tan ara yín jẹ. Nítorí bí ẹnikẹ́ni bá jẹ́ olùgbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí kò sì jẹ́ olùṣe, ẹni yìí dà bí ènìyàn tí ń wo ojú àdánidá rẹ̀ nínú dígí. Nítorí ó wo ara rẹ̀, ó sì lọ, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó gbàgbé irú ènìyàn tí òun jẹ́.” (Jákọ́bù 1:22-24) Kí ni Jákọ́bù ní lọ́kàn tó fi sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn?
5 Nígbà táa bá jí láàárọ̀, a sábà máa ń lọ wo dígí láti lè mọ bó ṣe yẹ ká tún ojú wa ṣe. Nígbà táa bá bẹ̀rẹ̀ ìgbòkègbodò, tí ọkàn wa sì wà lórí àwọn nǹkan míì, a kì í rántí ohun táa rí nínú dígí mọ́. Èyí lè ṣẹlẹ̀ nípa tẹ̀mí pẹ̀lú. Báa ti ń wo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, a lè fi ohun tí a jẹ́ wé ohun tí Jèhófà fẹ́ kí a jẹ́. Nítorí náà, a óò wá rí àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ wa ní kedere. Àwọn ohun táa rí yìí gbọ́dọ̀ sún wa láti tún ìwà wa ṣe. Ṣùgbọ́n báa ṣe ń lọ́wọ́ nínú ìgbòkègbodò wa ojoojúmọ́, táa sì ń bá àwọn ìṣòro wa yí, ó rọrùn láti mọ́kàn kúrò lórí àwọn nǹkan tẹ̀mí. (Mátíù 5:3; Lúùkù 21:34) Kò yàtọ̀ sí gbígbàgbé àwọn ohun tí Ọlọ́run fi tìfẹ́tìfẹ́ ṣe fún wa. Bí èyí bá ṣẹlẹ̀, ọkàn wa lè bẹ̀rẹ̀ sí tẹ̀ sí ẹ̀ṣẹ̀ dídá.
6. Kí la fẹ́ gbé yẹ̀ wò nínú Ìwé Mímọ́ tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti má ṣe gbàgbé ọ̀rọ̀ Jèhófà?
6 Nínú lẹ́tà onímìísí tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ́kọ́ kọ sáwọn ará Kọ́ríńtì, ó tọ́ka sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó di onígbàgbé ní aginjù. Gẹ́gẹ́ bí àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ṣe jàǹfààní nínú ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù, ṣíṣàtúnyẹ̀wò ohun tó kọ lè ran àwa náà lọ́wọ́ láti má ṣe gbàgbé ọ̀rọ̀ Jèhófà. Fún ìdí yìí, ẹ jẹ́ ká gbé 1 Kọ́ríńtì 10:1-12 yẹ̀ wò.
Yàgò fún Ìfẹ́ Ayé
7. Ẹ̀rí tó dájú ṣáká wo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí tó fi hàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wọn?
7 Ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ nípa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ ìkìlọ̀ fáwọn Kristẹni. Ara ohun tí Pọ́ọ̀lù kọ ni pé: “Èmi kò fẹ́ kí ẹ ṣe aláìmọ̀, ẹ̀yin ará, pé gbogbo àwọn baba ńlá wa wà lábẹ́ àwọsánmà, gbogbo wọn sì gba inú òkun kọjá, a sì batisí gbogbo wọn sínú Mósè nípasẹ̀ àwọsánmà àti òkun.” (1 Kọ́ríńtì 10:1-4) Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà ayé Mósè rí àwọn ohun àgbàyanu tí Ọlọ́run fi agbára rẹ̀ ṣe, títí kan iṣẹ́ ìyanu ti ọwọ̀n àwọsánmà tó ṣamọ̀nà wọn lọ́sàn-án, tó sì jẹ́ kí wọ́n gba inú Òkun Pupa kọjá láìṣègbé. (Ẹ́kísódù 13:21; 14:21, 22) Dájúdájú, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ̀nyẹn rí ẹ̀rí tó dájú ṣáká pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wọn.
8. Kí ni ìyọrísí dídì tí Ísírẹ́lì di onígbàgbé nípa tẹ̀mí?
8 Pọ́ọ̀lù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run kò tẹ́wọ́ gbà púpọ̀ jù lọ nínú wọn, nítorí a ṣá wọn balẹ̀ nínú aginjù.” (1 Kọ́ríńtì 10:5) Ó mà bani nínú jẹ́ o! Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jáde kúrò ní Íjíbítì ṣe ohun tí wọn ò fi tóótun láti wọ Ilẹ̀ Ìlérí náà. Wọ́n pàdánù ojú rere Ọlọ́run nítorí àìnígbàgbọ́, wọ́n sì tipa báyìí kú sí aginjù. (Hébérù 3:16-19) Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú èyí? Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Nǹkan wọ̀nyí di àpẹẹrẹ fún wa, kí àwa má bàa jẹ́ ẹni tí ń ní ìfẹ́-ọkàn sí àwọn ohun tí ń ṣeni léṣe, àní gẹ́gẹ́ bí àwọn ṣe ní ìfẹ́-ọkàn sí wọn.”—1 Kọ́ríńtì 10:6.
9. Báwo ni Jèhófà ṣe pèsè fáwọn èèyàn rẹ̀, báwo sì ni Ísírẹ́lì ṣe hùwà?
9 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ohun púpọ̀ tó lè jẹ́ kí wọ́n wà lójúfò nípa tẹ̀mí bí wọ́n ti wà ní aginjù. Wọ́n ti wọnú májẹ̀mú pẹ̀lú Jèhófà, wọ́n sì tipa báyìí di orílẹ̀-èdè táa yà sí mímọ́ fún un. Síwájú sí i, a ti fún wọn ní iṣẹ́ àlùfáà, àgọ́ ìjọsìn tí í ṣe ibùdó ìjọsìn, wọ́n sì ní ètò fún ẹbọ rírú sí Jèhófà. Ṣùgbọ́n, kàkà tí wọn ì bá fi máa yọ̀ nítorí àwọn ẹ̀bùn tẹ̀mí wọ̀nyí, wọ́n jẹ́ kí àwọn nǹkan tara tí Ọlọ́run pèsè fún wọn sọ wọ́n di aláìnítẹ̀ẹ́lọ́rùn.—Númérì 11:4-6.
10. Èé ṣe tó fi yẹ ká máa fi Ọlọ́run sọ́kàn nígbà gbogbo?
10 Láìdàbí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó rìn ní aginjù, àwọn èèyàn Jèhófà òde òní ń gbádùn ojú rere Ọlọ́run. Àmọ́ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, ó ṣe pàtàkì ká máa fi Ọlọ́run sọ́kàn nígbà gbogbo. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò ràn wá lọ́wọ́ láti máa yẹra fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan tó lè máà jẹ́ ká ríran kedere nípa tẹ̀mí. A gbọ́dọ̀ pinnu “láti kọ àìṣèfẹ́ Ọlọ́run sílẹ̀ àti àwọn ìfẹ́-ọkàn ti ayé àti láti gbé pẹ̀lú ìyèkooro èrò inú àti òdodo àti fífọkànsin Ọlọ́run nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí.” (Títù 2:12) Àwa táa ti ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ Kristẹni láti ìgbà kékeré kò gbọ́dọ̀ ronú láé pé a ń fi àwọn ìgbádùn kan dù wá. Bí irú èrò bẹ́ẹ̀ bá tilẹ̀ ṣèèṣì wá sí wa lọ́kàn, á dáa ká rántí Jèhófà àtàwọn ìbùkún àgbàyanu tó ní nípamọ́ fún wa.—Hébérù 12:2, 3.
Ìgbọràn Àtọkànwá sí Jèhófà
11, 12. Báwo lẹnì kan ṣe lè jẹ̀bi ìbọ̀rìṣà láìjẹ́ pé ó forí balẹ̀ fún ère kankan?
11 Pọ́ọ̀lù fún wa ní ìkìlọ̀ míì nígbà tó kọ̀wé pé: “Kí ẹ má di abọ̀rìṣà, bí àwọn kan nínú wọn ti ṣe; gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Àwọn ènìyàn náà jókòó láti jẹ àti láti mu, wọ́n sì dìde láti gbádùn ara wọn.’” (1 Kọ́ríńtì 10:7) Ìṣẹ̀lẹ̀ tí Pọ́ọ̀lù ń tọ́ka sí ni ìgbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi túláàsì mú Áárónì pé kó ṣe ère ọmọ màlúù oníwúrà fáwọn. (Ẹ́kísódù 32:1-4) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè máà lọ jìnnà dórí bíbọ̀rìṣà, a lè di abọ̀rìṣà nípa jíjẹ́ kí ìfẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan pín ọkàn wa níyà tí a ò fi ní lè máa fi tọkàntọkàn sin Jèhófà mọ́.—Kólósè 3:5.
12 Nínú ọ̀ràn mìíràn, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé nípa àwọn kan tó jẹ́ pé nǹkan tara nìkan ló wà ní góńgó ẹ̀mí wọn, dípò nǹkan tẹ̀mí. Ó kọ̀wé nípa àwọn “tí ń rìn gẹ́gẹ́ bí ọ̀tá òpó igi oró Kristi” pé: “Ìparun . . . ni òpin wọn, ikùn wọn sì ni ọlọ́run wọn.” (Fílípì 3:18, 19) Òrìṣà tí wọ́n ń bọ kì í ṣe ère fífín. Ìfẹ́ ọkàn wọn fún nǹkan tara ni wọ́n ń bọ. Ẹ má ṣì wá gbọ́ o, a ò sọ pé gbogbo ìfẹ́ ọkàn ló burú o. Jèhófà tó dá wa mọ̀ pé àwọn nǹkan kan wa táa nílò, ó sì ṣí ọ̀nà fàájì sílẹ̀ fún wa lóríṣiríṣi. Ṣùgbọ́n àwọn tó bá fi ọ̀ràn fàájì ṣáájú àjọṣe àárín àwọn àti Ọlọ́run ti di abọ̀rìṣà paraku.—2 Tímótì 3:1-5.
13. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú ìtàn ère ọmọ màlúù oníwúrà?
13 Lẹ́yìn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní Íjíbítì, wọ́n ṣe ère ọmọ màlúù oníwúrà fún ìjọsìn. Yàtọ̀ sí pé èyí jẹ́ ìkìlọ̀ fún wa láti má ṣe yà sídìí ìbọ̀rìṣà, ẹ̀kọ́ pàtàkì míì tún wà nínú ìtàn yìí. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣàìgbọràn sí ìtọ́ni tó ṣe kedere látọ̀dọ̀ Jèhófà. (Ẹ́kísódù 20:4-6) Wọn ò kúkú sọ pé àwọn fẹ́ dìídì kẹ̀yìn sí Jèhófà Ọlọ́run wọn. Wọ́n rú ẹbọ sí ọmọ màlúù dídà, wọ́n sì wá pe àṣeyẹ náà ní “àjọyọ̀ fún Jèhófà.” Lọ́nà kan ṣá, wọ́n ń tan ara wọn jẹ nípa ríronú pé Ọlọ́run máa gbójú fo àìgbọràn wọn dá. Ìwọ̀sí gbáà lèyí jẹ́ sí Jèhófà, ó sì bí i nínú gidigidi.—Ẹ́kísódù 32:5, 7-10; Sáàmù 106:19, 20.
14, 15. (a) Èé ṣe táwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò fi ní àwíjàre kankan fún dídi olùgbọ́ tí ń gbàgbé? (b) Bí a bá ti pinnu láti má ṣe di olùgbọ́ tí ń gbàgbé, ojú wo ni a óò máa fi wo àwọn àṣẹ Jèhófà?
14 Yóò ṣàjèjì gan-an láti rí i kí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan lọ dara pọ̀ mọ́ ẹ̀sìn èké. Àmọ́, àwọn kan lè wà nínú ìjọ, síbẹ̀ kí wọ́n kọ ìtọ́ni Jèhófà sílẹ̀ láwọn ọ̀nà míì. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò ní àwíjàre kankan fún dídi olùgbọ́ tí ń gbàgbé. Wọ́n fi etí wọn gbọ́ Òfin Mẹ́wàá náà, wọ́n sì wà níbẹ̀ nígbà tí Mósè sọ àṣẹ Ọlọ́run fún wọn pé: “Ẹ kò gbọ́dọ̀ ṣe àwọn ọlọ́run fàdákà pẹ̀lú mi, ẹ kò sì gbọ́dọ̀ ṣe àwọn ọlọ́run wúrà fún ara yín.” (Ẹ́kísódù 20:18, 19, 22, 23) Síbẹ̀, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún lọ ń bọ ère ọmọ màlúù oníwúrà.
15 Àwa náà kò lè ní àwíjàre kankan tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, bí a bá di olùgbọ́ tí ń gbàgbé. Ìtọ́ni látọ̀dọ̀ Ọlọ́run wà nínú Ìwé Mímọ́ fún wa nípa onírúurú apá ìgbésí ayé. Fún àpẹẹrẹ, Ọ̀rọ̀ Jèhófà dìídì dẹ́bi fún àṣà yíyá nǹkan láìsan án padà. (Sáàmù 37:21) A pa á láṣẹ pé kí àwọn ọmọ máa gbọ́ràn sáwọn òbí wọn lẹ́nu, ojúṣe àwọn bàbá sì ni pé kí wọ́n máa tọ́ àwọn ọmọ wọn nínú “ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfésù 6:1-4) A fún àwọn Kristẹni àpọ́n nítọ̀ọ́ni pé kí wọ́n ṣègbéyàwó “kìkì nínú Olúwa,” a sì sọ fáwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó ti ṣègbéyàwó pé: “Kí ìgbéyàwó ní ọlá láàárín gbogbo ènìyàn, kí ibùsùn ìgbéyàwó sì wà láìní ẹ̀gbin, nítorí Ọlọ́run yóò dá àwọn àgbèrè àti àwọn panṣágà lẹ́jọ́.” (1 Kọ́ríńtì 7:39; Hébérù 13:4) Bí a bá ti pinnu pé a ò ní di olùgbọ́ tí ń gbàgbé, a óò máa fojú pàtàkì wo ìtọ́ni wọ̀nyí àtàwọn ìtọ́ni mìíràn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, a ó sì máa tẹ̀ lé wọn.
16. Kí ni ìyọrísí bíbọ ère ọmọ màlúù oníwúrà náà?
16 Jèhófà kò gbà kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa sin òun bó ṣe wù wọ́n. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ló ṣègbé, bóyá nítorí pé àwọn ló kó àwọn yòókù sòdí nínú ìwà ọ̀tẹ̀ ti bíbọ ère ọmọ màlúù oníwúrà. Jèhófà mú ìyọnu àjálù bá àwọn oníwà àìtọ́ yòókù. (Ẹ́kísódù 32:28, 35) Ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n gbáà lèyí jẹ́ fún ẹnikẹ́ni tó bá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n tó ya aṣèyówùú!
“Ẹ Máa Sá fún Àgbèrè”
17. Ìṣẹ̀lẹ̀ wo ni 1 Kọ́ríńtì 10:8 ń tọ́ka sí?
17 Pọ́ọ̀lù pe àfiyèsí wa sí àgbègbè míì tí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ tara ti lè jẹ́ kéèyàn di onígbàgbé nípa tẹ̀mí, ó sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni kí a má ṣe fi àgbèrè ṣe ìwà hù, bí àwọn kan nínú wọn ti ṣe àgbèrè, kìkì láti ṣubú, ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlélógún nínú wọn ní ọjọ́ kan ṣoṣo.” (1 Kọ́ríńtì 10:8) Ohun tó ṣẹlẹ̀ ní Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù lópin ìrìn àjò ogójì ọdún tí Ísírẹ́lì rìn la aginjù já ni Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ bá níhìn-ín. Ṣebí Jèhófà ṣẹ̀ṣẹ̀ ran àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́wọ́ láti ṣẹ́gun àwọn ilẹ̀ tó wà ní ìlà oòrùn Jọ́dánì ni, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ nínú wọ́n di onígbàgbé àti abaraá-móore-jẹ. Nígbà tí wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ wọ Ilẹ̀ Ìlérí tán, a tún ré wọn lọ sínú ìṣekúṣe àti ìjọsìn àìmọ́ Báálì ti Péórù. Nǹkan bí ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbàajì [24,000] ló ṣègbé, ẹgbẹ̀rún lára wọ́n jẹ́ àwọn ògúnnágbòǹgbò.—Númérì 25:9.
18. Irú àwọn ìwà wo ló lè yọrí sí ìṣekúṣe?
18 Wọ́n mọ àwọn èèyàn Jèhófà lónìí bí ẹní mowó nítorí ìlànà ìwà rere gíga tí wọ́n ń tẹ̀ lé. Àmọ́ nígbà tí àwọn Kristẹni kan dojú kọ ìdánwò láti ṣèṣekúṣe, ṣe ni wọ́n ṣíwọ́ ríronú nípa Ọlọ́run àtàwọn ìlànà rẹ̀. Wọ́n di olùgbọ́ tí ń gbàgbé. Ó lè máà jẹ́ orí àgbèrè ṣíṣe ni ìdánwò náà ti ń bẹ̀rẹ̀. Ó lè jẹ́ ìtẹ̀sí láti lọ máa ṣe ojúmìító nínú wíwo àwọn ohun tí ń ru ìfẹ́ ìṣekúṣe sókè, tàbí kíkúndùn láti máa sọ ọ̀rọ̀ àlùfààṣá tàbí láti máa bá ẹlòmíì tage, tàbí láti máa ṣe wọlé-wọ̀de pẹ̀lú àwọn tí ọwọ́ wọn ò mọ́. Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ló ti sún àwọn Kristẹni dẹ́ṣẹ̀.—1 Kọ́ríńtì 15:33; Jákọ́bù 4:4.
19. Ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ wo ló ń ràn wá lọ́wọ́ láti “máa sá fún àgbèrè”?
19 Bí a bá dojú kọ àdánwò láti ṣèṣekúṣe, a ò gbọ́dọ̀ ṣíwọ́ ríronú nípa Jèhófà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ ká máa tẹ̀ lé àwọn ìránnilétí tó wà nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀. (Sáàmù 119:1, 2) Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, èyí tó pọ̀ jù lọ lára wa ló ń sa gbogbo ipá wa láti jẹ́ oníwà mímọ́, ṣùgbọ́n ṣíṣe ohun tí ó tọ́ lójú Ọlọ́run ń béèrè fún sísapá láìjuwọ́ sílẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 9:27) Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sáwọn Kristẹni ní Róòmù pé: “Ìgbọràn yín ti wá sí àfiyèsí gbogbo ènìyàn. Nítorí náà, mo yọ̀ nítorí yín. Ṣùgbọ́n mo fẹ́ kí ẹ jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ti ohun rere, ṣùgbọ́n ọlọ́wọ́-mímọ́ ní ti ohun tí ó jẹ́ ibi.” (Róòmù 16:19) Bí Jèhófà ṣe fikú pa ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélógún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn yẹn gan-an ni yóò ṣe mú ìdájọ́ ṣẹ sórí àwọn àgbèrè àtàwọn oníwà àìtọ́ yòókù láìpẹ́. (Éfésù 5:3-6) Nítorí náà, dípò dídi olùgbọ́ tí ń gbàgbé, a gbọ́dọ̀ máa bá a lọ láti “sá fún àgbèrè.”—1 Kọ́ríńtì 6:18.
Máa Mọrírì Àwọn Ìpèsè Jèhófà Nígbà Gbogbo
20. Báwo ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe dán Jèhófà wò, kí sì ni àbájáde rẹ̀?
20 Èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn Kristẹni kì í ṣubú sínú ìdẹkùn ìṣekúṣe. Síbẹ̀, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kí a má bàa bẹ̀rẹ̀ sí tọ ipa ọ̀nà tí yóò sọ wá di oníkùnsínú, tó sì lè yọrí sí pípàdánù ojú rere Ọlọ́run. Pọ́ọ̀lù ṣí wa létí pé: “Bẹ́ẹ̀ ni kí a má ṣe dán Jèhófà wò, bí àwọn kan nínú [àwọn ọmọ Ísírẹ́lì] ti dán an wò, kìkì láti ṣègbé nípasẹ̀ àwọn ejò. Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe jẹ́ oníkùnsínú, gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn kan nínú wọn ti kùn, kìkì láti ṣègbé láti ọwọ́ apanirun.” (1 Kọ́ríńtì 10:9, 10) Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí Mósè àti Áárónì—bẹ́ẹ̀ ni, àní wọ́n tún kùn sí Ọlọ́run pàápàá—wọ́n ń ráhùn nípa mánà táa pèsè lọ́nà iṣẹ́ ìyanu. (Númérì 16:41; 21:5) Ǹjẹ́ àgbèrè tí wọ́n ṣe bí Jèhófà nínú ju kíkùn tí wọ́n ń kùn lọ? Àkọsílẹ̀ Bíbélì fi hàn pé ejò pa ọ̀pọ̀ lára àwọn oníkùnsínú náà. (Númérì 21:6) Nínú ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó wáyé ṣáájú ìgbà yẹn, iye tó ju ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlá ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin [14,700] àwọn ọlọ̀tẹ̀ tó kùn ló ṣègbé. (Númérì 16:49) Fún ìdí yìí, ẹ má ṣe jẹ́ ká tán Jèhófà ní sùúrù nípa títẹ́ńbẹ́lú àwọn ìpèsè rẹ̀.
21. (a) Ọ̀rọ̀ ìyànjú wo ni a mí sí Pọ́ọ̀lù láti kọ? (b) Gẹ́gẹ́ bí Jákọ́bù 1:25 ti wí, kí ló lè fún wa láyọ̀ tòótọ́?
21 Ọ̀rọ̀ ìyànjú tó tẹ̀ lé e yìí ni Pọ́ọ̀lù fi kádìí ìwé tó kọ sáwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, ó ní: “Wàyí o, nǹkan wọ̀nyí ń bá a lọ ní ṣíṣẹlẹ̀ sí wọn gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ, a sì kọ̀wé wọn kí ó lè jẹ́ ìkìlọ̀ fún àwa tí òpin àwọn ètò àwọn nǹkan dé bá. Nítorí náà, kí ẹni tí ó bá rò pé òun dúró kíyè sára kí ó má bàa ṣubú.” (1 Kọ́ríńtì 10:11, 12) Bíi ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwa náà ti rí ọ̀pọ̀ ìbùkún gbà látọ̀dọ̀ Jèhófà. Àmọ́ láìdàbí wọn, ǹjẹ́ kí ìgbàgbé má ṣe wá, ká má sì di abaraá-móore-jẹ, tí kò mọrírì àwọn ohun rere tí Ọlọ́run ń ṣe fún wa. Nígbà tí àníyàn ìgbésí ayé bá fẹ́ wọ̀ wá lọ́rùn, ẹ jẹ́ ká máa ronú nípa àwọn ìlérí àgbàyanu tó wà nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ǹjẹ́ ká máa rántí pé àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà ṣeyebíye, ká sì máa ṣe iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà tó gbé lé wa lọ́wọ́ nìṣó. (Mátíù 24:14; 28:19, 20) Ó dájú pé títọ irú ọ̀nà yẹn ni yóò fún wa ní ayọ̀ tòótọ́, nítorí Ìwé Mímọ́ ṣèlérí pé: “Ẹni tí ó bá ń wo inú òfin pípé tí í ṣe ti òmìnira ní àwòfín, tí ó sì tẹpẹlẹ mọ́ ọn, ẹni yìí, nítorí tí kò di olùgbọ́ tí ń gbàgbé, bí kò ṣe olùṣe iṣẹ́ náà, yóò láyọ̀ nínú ṣíṣe é.”—Jákọ́bù 1:25.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Kí ló lè sọ wá di olùgbọ́ tí ń gbàgbé?
• Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì láti máa ṣègbọràn sí Ọlọ́run láìkù síbì kankan?
• Báwo la ṣe lè “máa sá fún àgbèrè”?
• Ojú wo ló yẹ ká máa fi wo àwọn ìpèsè Jèhófà?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbàgbé àwọn iṣẹ́ àrà tí Jèhófà ṣe fún wọn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Àwọn èèyàn Jèhófà ti pinnu láti rọ̀ mọ́ ìlànà ìwà rere gíga