Láìfi Àdánwò Pè, Rọ̀ Mọ́ Ìgbàgbọ́ Rẹ!
“Ẹ ka gbogbo rẹ̀ sí [ìdùnnú], ẹ̀yin ará mi, nígbà tí ẹ bá ń bá onírúurú àdánwò pàdé.”—JÁKỌ́BÙ 1:2.
1. Láìfi kí ni pè ni àwọn ènìyàn Jèhófà fi ń fi ìgbàgbọ́ àti “inú dídùn” sìn ín?
ÀWỌN ènìyàn Jèhófà ń fi ìgbàgbọ́ àti “inú dídùn” sìn gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí rẹ̀. (Diutarónómì 28:47; Aísáyà 43:10) Wọ́n ń ṣe èyí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń dojú kọ ọ̀pọ̀ àdánwò. Láìfi ìnira wọn pè, wọ́n ń rí ìtùnú nínú àwọn ọ̀rọ̀ náà pé: “Ẹ ka gbogbo rẹ̀ sí [ìdùnnú], ẹ̀yin ará mi, nígbà tí ẹ bá ń bá onírúurú àdánwò pàdé, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti mọ̀ ní tòótọ́ pé ìjójúlówó ìgbàgbọ́ yín yìí tí a ti dán wò ń ṣiṣẹ́ yọrí sí ìfaradà.”—Jákọ́bù 1:2, 3.
2. Kí ni a mọ̀ nípa òǹkọ̀wé lẹ́tà Jákọ́bù?
2 Jákọ́bù ọmọlẹ́yìn, ọmọ ìyá Jésù Kristi, ni ó kọ ọ̀rọ̀ yẹn ní nǹkan bí ọdún 62 Sànmánì Tiwa. (Máàkù 6:3) Alàgbà ni Jákọ́bù ní ìjọ Jerúsálẹ́mù. Àní, òun, Kéfà (Pétérù), àti Jòhánù “dà bí ọwọ̀n”—àwọn òpómúléró, tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ gbọn-ingbọn-in nínú ìjọ. (Gálátíà 2:9) Nígbà tí àríyànjiyàn lórí ìkọlà dé iwájú “àwọn àpọ́sítélì àti àwọn àgbà ọkùnrin” ní nǹkan bí ọdún 49 Sànmánì Tiwa, Jákọ́bù dábàá yíyèkooro tí a gbé ka Ìwé Mímọ́, èyí tí ẹgbẹ́ olùṣàkóso ti ọ̀rúndún kìíní yẹn tẹ́wọ́ gbà.—Ìṣe 15:6-29.
3. Kí ni díẹ̀ nínú àwọn ìṣòro tí ó dojú kọ àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní, báwo sì ni a ṣe lè jàǹfààní tí ó pọ̀ jù lọ láti inú lẹ́tà Jákọ́bù?
3 Gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn tẹ̀mí tí ń ṣàníyàn, Jákọ́bù ‘mọ ìrísí agbo ẹran’ rẹ̀. (Òwe 27:23) Ó mọ̀ pé àwọn Kristẹni ń dojú kọ àwọn àdánwò lílekoko ní àkókò náà. Ìrònú àwọn kan ń béèrè àtúnṣe, nítorí pé wọ́n ń fi ojú rere hàn sí àwọn ọlọ́rọ̀. Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀, ìjọsìn wulẹ̀ jẹ́ irú ọ̀nà ètò kan. Àwọn kan ń fi ewèlè ahọ́n wọn ṣe ìpalára. Ẹ̀mí ayé ti ń fa ìpalára, ọ̀pọ̀ kò ní sùúrù mọ́ bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì kún fún àdúrà. Ní tòótọ́, òkùnkùn tẹ̀mí ti ṣú bo àwọn Kristẹni kan. Lẹ́tà Jákọ́bù jíròrò irú àwọn ọ̀ràn bẹ́ẹ̀ lọ́nà tí ń gbéni ró, ìmọ̀ràn rẹ̀ sì gbéṣẹ́ gan-an lónìí gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa. Àwa yóò jàǹfààní lọ́pọ̀lọpọ̀ bí a bá gbé lẹ́tà yí yẹ̀ wò gẹ́gẹ́ bí èyí tí a kọ sí wa gan-an.a
Nígbà Tí Àdánwò Bá Dé Bá Wa
4. Ojú wo ni ó yẹ kí a fi wo àwọn àdánwò?
4 Jákọ́bù fi ojú tí ó yẹ kí a fi wo àdánwò hàn wá. (Jákọ́bù 1:1-4) Láìmẹ́nu kan okùn àjọbí rẹ̀ pẹ̀lú Ọmọ Ọlọ́run, ó fi ìrẹ̀lẹ̀ pe ara rẹ̀ ní “ẹrú Ọlọ́run àti ti Jésù Kristi Olúwa.” Jákọ́bù kọ́kọ́ kọ̀wé sí “àwọn ẹ̀yà méjìlá” Ísírẹ́lì tẹ̀mí “tí ó túká káàkiri,” nítorí inúnibíni. (Ìṣe 8:1; 11:19; Gálátíà 6:16; Pétérù Kíní 1:1) Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, a ń ṣenúnibíni sí wa pẹ̀lú, a sì “ń bá onírúurú àdánwò pàdé.” Ṣùgbọ́n bí a bá rántí pé àwọn àdánwò tí a bá fara dà máa ń fún ìgbàgbọ́ wa lókun, a óò “ka gbogbo rẹ̀ sí [ìdùnnú]” nígbà tí wọ́n bá dé bá wa. Bí a bá pa ìwà títọ́ wa mọ́ sí Ọlọ́run nígbà àdánwò, èyí yóò mú ayọ̀ tí ó wà pẹ́ títí wá fún wa.
5. Kí ni àwọn àdánwò wa lè ní nínú, kí ni ó sì ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí a bá kẹ́sẹ járí ní fífaradà?
5 Àwọn àdánwò wa ní àwọn ìpọ́njú tí ó wọ́pọ̀ láàárín aráyé nínú. Fún àpẹẹrẹ, àìlera lè pọ́n wa lójú. Ọlọ́run kì í woni sàn lọ́nà iṣẹ́ ìyanu nísinsìnyí, ṣùgbọ́n ó máa ń dáhùn àwọn àdúrà wa fún ọgbọ́n àti ẹ̀mí ìfàyàrán tí a nílò láti kojú àìsàn. (Orin Dáfídì 41:1-3) A tún ń jìyà nítorí òdodo gẹ́gẹ́ bí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí a ń ṣe inúnibíni sí. (Tímótì Kejì 3:12; Pétérù Kíní 3:14) Nígbà tí a bá kẹ́sẹ járí nínú fífarada irú àwọn àdánwò bẹ́ẹ̀, a ń fi hàn pé a ní ìgbàgbọ́, ní dídi èyí tí a ti ‘dán ìjójúlówó rẹ̀ wò.’ Nígbà tí ìgbàgbọ́ wa bá sì ṣẹ́gun, èyí “ń ṣiṣẹ́ yọrí sí ìfaradà.” Ìgbàgbọ́ tí àwọn àdánwò túbọ̀ fún lókun yóò ràn wá lọ́wọ́ láti fara da àwọn ìdánwò ọjọ́ iwájú.
6. Báwo ni ‘ìfaradà ṣe ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀ pé pérépéré,’ kí sì ni àwọn ìgbésẹ̀ gbígbéṣẹ́ tí a lè gbé nígbà tí a bá wà lábẹ́ àdánwò?
6 Jákọ́bù sọ pé: “Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí ìfaradà ṣe iṣẹ́ rẹ̀ pé pérépéré.” Bí a bá jẹ́ kí àdánwò máa bá a nìṣó láìgbìyànjú láti tètè fòpin sí i lọ́nà tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu, ìfaradà yóò ṣe “iṣẹ́” mímú kí a pé pérépéré gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, tí kò ṣàìní ìgbàgbọ́. Dájúdájú, bí àdánwò bá fi àwọn àìlera tí a ní hàn, ó yẹ kí a wá ìrànwọ́ Jèhófà láti borí rẹ̀. Bí àdánwò náà bá jẹ́ ìdẹwò láti lọ́wọ́ nínú ìwà pálapàla ńkọ́? Ẹ jẹ́ kí a gbàdúrà nípa ìṣòro yẹn, lẹ́yìn náà, kí a sì hùwà níbàámu pẹ̀lú àdúrà wa. Ó lè di dandan pé kí a wá ibòmíràn tí a óò ti máa ṣiṣẹ́, tàbí kí a gbé àwọn ìgbésẹ̀ míràn láti pa ìwà títọ́ mọ́ sí Ọlọ́run.—Jẹ́nẹ́sísì 39:7-9; Kọ́ríńtì Kíní 10:13.
Wíwá Ọgbọ́n Kiri
7. Báwo ni a ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti kojú àwọn àdánwò?
7 Jákọ́bù fi ohun tí a óò ṣe hàn wá bí a kò bá mọ bí a ṣe lè kojú àdánwò kan. (Jákọ́bù 1:5-8) Jèhófà kì yóò pẹ̀gàn wa fún ṣíṣàìní ọgbọ́n, tí a sì ń fi ìgbàgbọ́ gbàdúrà fún un. Òun yóò ràn wá lọ́wọ́ láti fi ojú tí ó yẹ wo àdánwò, kí a sì fara dà á. Àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa lè mú Ìwé Mímọ́ wá sí àfiyèsí wa, tàbí kí a pe àfiyèsí wa sí i nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí agbára Ọlọ́run darí lè mú kí a rí ohun tí ó yẹ kí a ṣe. Ẹ̀mí Ọlọ́run lè tọ́ wa sọ́nà. (Lúùkù 11:13) Láti gbádùn irú àwọn àǹfààní bẹ́ẹ̀, bí ó ti yẹ kí ó rí, a gbọ́dọ̀ rọ̀ mọ́ Ọlọ́run àti àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.—Òwe 18:1.
8. Èé ṣe ti oníyèméjì kì yóò fi rí ohunkóhun gbà lọ́dọ̀ Jèhófà?
8 Jèhófà ń fún wa ní ọgbọ́n láti kojú àwọn àdánwò bí a bá ń “bá a nìṣó ní bíbéèrè nínú ìgbàgbọ́, láìṣiyèméjì rárá.” Oníyèméjì “dà bí ìgbì òkun tí ẹ̀fúùfù ń bì tí a sì ń fẹ́ káàkiri” láìmọ ibi tí ó forí lé. Bí a bá jẹ́ aláìdúrósójúkan bẹ́ẹ̀ nípa tẹ̀mí, ‘kí a má ṣe rò pé a óò rí ohunkóhun gbà láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.’ Ẹ má ṣe jẹ́ kí a jẹ́ “aláìnípinnu” àti “aláìdúrósójúkan” nínú àdúrà tàbí ní àwọn ọ̀nà míràn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ kí a ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà, Orísun ọgbọ́n.—Òwe 3:5, 6.
Ọlọ́rọ̀ àti Òtòṣì Lè Yọ Ayọ̀ Ńláǹlà
9. Èé ṣe tí a fi ní ìdí fún ayọ̀ ńláǹlà gẹ́gẹ́ bí olùjọsìn Jèhófà?
9 Àní bí ipò òṣì bá jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn àdánwò wa pàápàá, ẹ jẹ́ kí a fi sọ́kàn pé àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ ọlọ́rọ̀ tàbí òtòṣì lè yọ ayọ̀ ńláǹlà. (Jákọ́bù 1:9-11) Kí wọ́n tó di ọmọlẹ́yìn Jésù, ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ẹni àmì òróró ni kò fi bẹ́ẹ̀ ní ohun ìní ti ara, ayé sì fojú tẹ́ńbẹ́lú wọn. (Kọ́ríńtì Kíní 1:26) Ṣùgbọ́n wọ́n lè yọ ayọ̀ ńláǹlà lórí “ìgbéga” wọn sí ipò àwọn ajogún Ìjọba. (Róòmù 8:16, 17) Ní òdì kejì ẹ̀wẹ̀, àwọn ọlọ́rọ̀ tí a ti ń bọlá fún nígbà kan rí nírìírí “ìtẹ́lógo” gẹ́gẹ́ bí ọmọlẹ́yìn Kristi nítorí tí ayé tẹ́ńbẹ́lú wọn. (Jòhánù 7:47-52; 12:42, 43) Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jèhófà gbogbo wa lè yọ ayọ̀ ńláǹlà nítorí pé ọrọ̀ àti ipò gíga ti ayé kò já mọ́ nǹkan kan bí a bá fi wé ọrọ̀ tẹ̀mí tí a ń gbádùn. Ẹ sì wo bí a ṣe kún fún ìmoore tó pé kò sí àyè fún fífi ipò ẹni láwùjọ yangàn láàárín wa!—Òwe 10:22; Ìṣe 10:34, 35.
10. Ojú wo ni ó yẹ kí Kristẹni kan fi wo ọrọ̀ ti ara?
10 Jákọ́bù ràn wá lọ́wọ́ láti rí i pé ìwàláàyè wa kò sinmi lórí ọrọ̀ àti àṣeyọrí nínú ayé. Bí ẹwà òdòdó kò ti lè dènà gbígbẹ rẹ̀ nínú “ooru ajóni,” bẹ́ẹ̀ ni ọlà ọlọ́rọ̀ kan kò lè mú kí ìwàláàyè rẹ̀ gùn sí i. (Orin Dáfídì 49:6-9; Mátíù 6:27) Ó lè kú sẹ́nu ibi tí ó ti ń lépa “àwọn ọ̀nà ìgbésí ayé” rẹ̀, bóyá sẹ́nu òwò rẹ̀. Nítorí náà, ohun tí ó ṣe pàtàkì ni láti ní “ọrọ̀ síhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run,” kí a sì ṣe gbogbo ohun tí a bá lè ṣe láti máa gbé ire Ìjọba lárugẹ.—Lúùkù 12:13-21; Mátíù 6:33; Tímótì Kíní 6:17-19.
Aláyọ̀ Ni Àwọn Tí Ń Fara Da Àdánwò
11. Kí ni ohun tí àwọn tí ó rọ̀ mọ́ ìgbàgbọ́ wọn lójú àwọn àdánwò lè fojú sọ́nà fún?
11 Yálà a jẹ́ ọlọ́rọ̀ tàbí òtòṣì, a lè láyọ̀ kìkì bí a bá fara da àwọn àdánwò wa. (Jákọ́bù 1:12-15) Bí a bá fara da irú àwọn àdánwò bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ìgbàgbọ́ wa tí kò mì, a lè pè wá ní aláyọ̀, nítorí pé ìdùnnú ń bẹ nínú ṣíṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Ọlọ́run. Nípa rírọ̀mọ́ ìgbàgbọ́ wọn títí dójú ikú, àwọn Kristẹni tí a fi ẹ̀mí bí ń gba “adé ìyè,” àìleèkú ní ọ̀run. (Ìṣípayá 2:10; Kọ́ríńtì Kíní 15:50) Bí a bá ní ìrètí ti ilẹ̀ ayé, tí a sì pa ìgbàgbọ́ wa mọ́ nínú Ọlọ́run, a lè fojú sọ́nà fún ìyè ayérayé nínú párádísè orí ilẹ̀ ayé. (Lúùkù 23:43; Róòmù 6:23) Ẹ wo bí Jèhófà ṣe jẹ́ ẹni rere tó sí gbogbo àwọn tí ó bá lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀!
12. Nígbà tí ìpọ́njú bá dé bá wa, èé ṣe tí a kò fi gbọ́dọ̀ sọ pé: “Ọlọ́run ni ó ń dán mi wò”?
12 Ó ha ṣeé ṣe pé kí Jèhófà fúnra rẹ̀ fi ìpọ́njú dán wa wò bí? Rárá, a kò gbọ́dọ̀ sọ pé: “Ọlọ́run ni ó ń dán mi wò.” Jèhófà kì í gbìyànjú láti sún wa dẹ́ṣẹ̀, ṣùgbọ́n ó dájú pé òun yóò ràn wá lọ́wọ́, yóò sì fún wa ní okun tí a nílò láti fara da àwọn àdánwò bí a bá fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin nínú ìgbàgbọ́. (Fílípì 4:13) Ọlọ́run jẹ́ mímọ́, nítorí náà òun kì í fi wa sínú àwọn àyíká ipò tí yóò dín agbára wa láti dènà ìwà àìtọ́ kù. Bí a bá rí ara wa nínú ipò àìmọ́ kan, tí a sì dẹ́ṣẹ̀, a kò gbọ́dọ̀ dẹ́bi fún un, “nítorí a kò lè fi àwọn ohun tí ó jẹ́ ibi dán Ọlọ́run wò bẹ́ẹ̀ ni òun fúnra rẹ̀ kì í dán ẹnikẹ́ni wò.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà lè yọ̀ǹda kí àdánwò kan bá wa wí fún ire wa, òun kì í dán wa wò pẹ̀lú ète ibi lọ́kàn. (Hébérù 12:7-11) Sátánì lè dẹ wa wò láti ṣe ohun tí kò tọ́, ṣùgbọ́n Ọlọ́run lè dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ ẹni burúkú yẹn.—Mátíù 6:13.
13. Kí ni ó lè ṣẹlẹ̀ bí a kò bá kọ ìfẹ́ ọkàn tí kò tọ́ sílẹ̀?
13 Ó yẹ kí a kún fún àdúrà nítorí pé ipò kan lè yọrí sí ìrònú tí kò tọ́ tí ó lè sún wa dẹ́ṣẹ̀. Jákọ́bù sọ pé: “Olúkúlùkù ni a ń dán wò nípa fífà á jáde àti ríré e lọ láti ọwọ́ ìfẹ́ ọkàn òun fúnra rẹ̀.” A kò lè dá Ọlọ́run lẹ́bi fún ẹ̀ṣẹ̀ wa bí a bá ti jẹ́ kí ọkàn àyà wa máa fìgbà gbogbo wà lórí ìfẹ́ ọkàn tí ó kún fún ẹ̀ṣẹ̀. Bí a kò bá mú ìfẹ́ ọkàn tí kò tọ́ kúrò, ‘á lóyún,’ á dàgbà nínú ọkàn àyà, á sì “bí ẹ̀ṣẹ̀.” Nígbà tí a bá dẹ́ṣẹ̀ tán, á “mú ikú wá.” Lọ́nà tí ó hàn gbangba, ó yẹ kí a dáàbò bo ọkàn àyà wa, kí a sì dènà àwọn ìrònú tí ó kún fún ẹ̀ṣẹ̀. (Òwe 4:23) A kìlọ̀ fún Kéènì pé ẹ̀ṣẹ̀ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ borí rẹ̀, ṣùgbọ́n kò dènà rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 4:4-8) Nítorí náà, bí a bá bẹ̀rẹ̀ sí í lépa ọ̀nà kan tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu ńkọ́? Dájúdájú, ó yẹ kí a kún fún ìmoore bí àwọn Kristẹni alàgbà bá gbìyànjú láti tọ́ wa sọ́nà kí a má baà dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run.—Gálátíà 6:1.
Ọlọ́run—Orísun Àwọn Ohun Rere
14. Lọ́nà wo ni a lè gbà sọ pé àwọn ẹ̀bùn Ọlọ́run jẹ́ “pípé”?
14 A gbọ́dọ̀ rántí pé Jèhófà ni Orísun ohun rere, òun kì í ṣe Orísun àwọn àdánwò. (Jákọ́bù 1:16-18) Jákọ́bù pe àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ní “olùfẹ́ ọ̀wọ́n,” ó sì fi hàn pé Ọlọ́run ni Olùfúnni ní ‘gbogbo ẹ̀bùn rere àti ọrẹ pípé.’ Àwọn ẹ̀bùn nípa tẹ̀mí àti ti ara láti ọ̀dọ̀ Jèhófà jẹ́ “pípé,” tàbí pé pérépéré, kò kù síbì kan. Wọ́n wá “láti òkè,” láti ibi tí Ọlọ́run ń gbé ní ọ̀run. (Àwọn Ọba Kìíní 8:39) Jèhófà ni “Bàbá àwọn ìmọ́lẹ̀ àtọ̀runwá”—oòrùn, òṣùpá, àti àwọn ìràwọ̀. Ó tún ń fún wa ní ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí àti òtítọ́. (Orin Dáfídì 43:3; Jeremáyà 31:35; Kọ́ríńtì Kejì 4:6) Láìdàbí oòrùn tí ń mú kí òjìji yí pa dà bí ó ti ń lọ, tí ó sì máa ń dé òtéńté rẹ̀ ní ọ̀sán ganrínganrín nìkan, ìgbà gbogbo ni Ọlọ́run máa ń wà ní òtéńté tirẹ̀ láti pèsè ohun rere. Ó dájú pé òun yóò mú wa gbára dì láti kojú àwọn àdánwò bí a bá lo àǹfààní àwọn ìpèsè tẹ̀mí tí a ń pèsè nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti nípasẹ̀ “olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n inú ẹrú” lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́.—Mátíù 24:45.
15. Kí ni ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀bùn Jèhófà tí ó dára jù lọ?
15 Kí ni ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀bùn Ọlọ́run tí ó dára jù lọ? Mímú àwọn ọmọ tẹ̀mí jáde nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́, tí ń ṣiṣẹ́ ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú ìhìn rere, tàbí “ọ̀rọ̀ òtítọ́.” Àwọn tí ó nírìírí ìbí tẹ̀mí jẹ́ “àkọ́so kan,” tí a yàn láti inú aráyé láti jẹ́ “ìjọba kan àti àlùfáà” ti ọ̀run. (Ìṣípayá 5:10; Éfésù 1:13, 14) Jákọ́bù ti lè máa ronú nípa àkọ́so ọkà bálì tí a fi rúbọ ní Nísàn 16, tí ó jẹ́ ọjọ́ tí Jésù jíǹde, àti fífi ìṣù àkàrà àlìkámà méjì rúbọ ní ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì, nígbà tí a tú ẹ̀mí mímọ́ jáde. (Léfítíkù 23:4-11, 15-17) Nípa bẹ́ẹ̀, Jésù ni ó jẹ́ àkọ́so náà, tí àwọn àjùmọ̀jogún pẹ̀lú rẹ̀ sì jẹ́ “àkọ́so kan.” Bí a bá ní ìrètí ti ilẹ̀ ayé ńkọ́? Tóò, fífi í sọ́kàn yóò ràn wá lọ́wọ́ láti rọ̀ mọ́ ìgbàgbọ́ wa nínú Olùfúnni ní “gbogbo ẹ̀bùn rere,” ẹni tí ó ti mú ìyè ayérayé ṣeé ṣe lábẹ́ àkóso Ìjọba.
Ẹ Jẹ́ “Olùṣe Ọ̀rọ̀ Náà”
16. Èé ṣe tí ó fi yẹ kí a ‘yára nípa gbígbọ́, ṣùgbọ́n kí a lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ àti ìrunú’?
16 Yálà àwọn àdánwò ìgbàgbọ́ wa ti dé bá wa nísinsìnyí tàbí kò tí ì dé, a gbọ́dọ̀ jẹ́ “olùṣe ọ̀rọ̀ náà.” (Jákọ́bù 1:19-25) Ó yẹ kí a ‘yára nípa gbígbọ́’ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kí a jẹ́ ẹni tí ń ṣe ìgbọràn sí i. (Jòhánù 8:47) Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ẹ jẹ́ kí a “lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ,” ní fífi ìṣọ́ra yẹ àwọn ọ̀rọ̀ wa wò. (Òwe 15:28; 16:23) Jákọ́bù ti lè máa rọ̀ wá kí a má ṣe tètè sọ pé Ọlọ́run ni ó fa àwọn àdánwò wa. A fún wa nímọ̀ràn pẹ̀lú láti “lọ́ra nípa ìrunú, nítorí ìrunú ènìyàn kì í ṣiṣẹ́ yọrí sí òdodo Ọlọ́run.” Bí ohun tí ẹnì kan sọ bá bí wa nínú, ẹ jẹ́ kí a ‘fara balẹ̀’ kí a baà lè yẹra fún fífèsì láti gbẹ̀san. (Éfésù 4:26, 27) Ẹ̀mí ìrunú tí ó lè fa ìṣòro fún wa tí yóò sì di àdánwò fún àwọn ẹlòmíràn kò lè mú ohun tí ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run òdodo wa ń béèrè lọ́wọ́ wa jáde. Yàtọ̀ sí ìyẹn, bí a bá “ní ìmọ̀ púpọ̀,” a óò “lọ́ra àtibínú,” àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa yóò sì fà sún mọ́ wa.—Òwe 14:29.
17. Kí ni a ń ṣàṣeparí rẹ̀ nípa mímú ohun búburú kúrò nínú ọkàn àyà àti èrò inú?
17 Dájúdájú, a gbọ́dọ̀ bọ́ lọ́wọ́ “gbogbo èérí ẹ̀gbin”—gbogbo ohun tí ó jẹ́ ìríra sí Ọlọ́run, tí ó sì ń gbé ìrunú lárugẹ. Ní àfikún sí i, a gbọ́dọ̀ ‘mú ohun àṣerégèé yẹn, ìwà búburú, kúrò.’ Gbogbo wa gbọ́dọ̀ mú ohun àìmọ́ èyíkéyìí nípa ti ara tàbí ti ẹ̀mí kúrò nínú ìgbésí ayé wa. (Kọ́ríńtì Kejì 7:1; Pétérù Kíní 1:14-16; Jòhánù Kíní 1:9) Mímú ohun búburú kúrò nínú ọkàn àyà àti èrò inú wa ń ràn wá lọ́wọ́ láti “fi ìwà tútù tẹ́wọ́ gba gbígbin ọ̀rọ̀” òtítọ́ “sínú.” (Ìṣe 17:11, 12) Bí ó ti wù kí ó pẹ́ tó ti a ti jẹ́ Kristẹni, a gbọ́dọ̀ máa bá a lọ ní jíjẹ́ kí a gbin òtítọ́ Ìwé Mímọ́ púpọ̀ sí i sínú wa. Èé ṣe? Nítorí pé nípasẹ̀ ẹ̀mí Ọlọ́run, ọ̀rọ̀ tí a gbìn sínú náà ń mú “àkópọ̀ ìwà tuntun” jáde tí ń mú ọwọ́ ẹni tẹ ìgbàlà.—Éfésù 4:20-24.
18. Báwo ni ẹnì kan tí ó jẹ́ olùgbọ́ ọ̀rọ̀ náà nìkan ṣe yàtọ̀ sí ẹni tí ó jẹ́ olùṣe é pẹ̀lú?
18 Báwo ni a ṣe ń fi hàn pé ọ̀rọ̀ náà jẹ́ atọ́nà wa? Nípa fífi tinútinú jẹ́ “olùṣe ọ̀rọ̀ náà, kì í sì í ṣe olùgbọ́ nìkan.” (Lúùkù 11:28) ‘Àwọn olùṣe’ ní ìgbàgbọ́ tí ń mú iṣẹ́ bí ìgbòkègbodò onítara nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni àti ìkópa déédéé nínú àwọn ìpàdé àwọn ènìyàn Ọlọ́run jáde. (Róòmù 10:14, 15; Hébérù 10:24, 25) Olùgbọ́ ọ̀rọ̀ náà lásán “dà bí ènìyàn kan tí ń wo ojú àdánidá rẹ̀ nínú jígí.” Ó wo ara rẹ̀, lẹ́yìn náà ó lọ, ó sì gbàgbé ohun tí ó yẹ kí ó ṣe láti tún ìrísí ara rẹ̀ ṣe. Gẹ́gẹ́ bí “olùṣe ọ̀rọ̀ náà,” a ń fara balẹ̀ kọ́ “òfin pípé” Ọlọ́run, a sì ń ṣègbọràn sí i, èyí tí ó kan gbogbo ohun tí ó béèrè lọ́wọ́ wa. Òmìnira tí a ń tipa báyìí gbádùn jẹ́ òdì kejì gan-an sí ìsọdẹrú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú, nítorí ó ń ṣamọ̀nà sí ìyè. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a ‘tẹpẹlẹ mọ òfin pípé náà,’ kí a máa yẹ̀ ẹ́ wò fínnífínní nígbà gbogbo, kí a sì ṣègbọ́ràn sí i. Sì tún rò ó wò ná! Gẹ́gẹ́ bí ‘olùṣe iṣẹ́ náà, tí kì í sì í ṣe olùgbọ́ nìkan,’ a ní ìdùnnú tí ń jẹyọ láti inú ojú rere Ọlọ́run.—Orin Dáfídì 19:7-11.
Ó Ju Wíwulẹ̀ Jẹ́ Olùjọsìn ní Irú Ọ̀nà Ètò Kan
19, 20. (a) Gẹ́gẹ́ bí Jákọ́bù 1:26, 27 ṣe sọ, kí ni ohun tí ìjọsìn tí ó mọ́ ń béèrè lọ́wọ́ wa? (b) Fúnni ní àwọn àpẹẹrẹ mélòó kan ní ti ìjọsìn tí kò ní èérí?
19 Bí a óò bá gbádùn ojú rere àtọ̀runwá, ó yẹ kí a rántí pé ìjọsìn tòótọ́ kì í wulẹ̀ í ṣe ti irú ọ̀nà ètò kan lásán. (Jákọ́bù 1:26, 27) A lè ronú pé a jẹ́ ‘olùjọsìn’ Jèhófà ‘ní irú ọ̀nà ètò kan’ tí a tẹ́wọ́ gbà, ṣùgbọ́n ohun tí òun rò nípa ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ni ó ṣe pàtàkì. (Kọ́ríńtì Kíní 4:4) Àbùkù tí ó burú jáì kan lè jẹ́ ìkùnà láti ‘kó ahọ́n níjàánu.’ Ṣe ni a ń tan ara wa jẹ́ bí a bá rò pé inú Ọlọ́run dùn sí ìjọsìn wa bí a bá ń ba ẹlòmíràn jẹ́, tí a ń purọ́, tàbí tí a ń ṣi ahọ́n wa lò lọ́nà míràn. (Léfítíkù 19:16; Éfésù 4:25) Dájúdájú, a kò fẹ́ kí “irú ọ̀nà ètò ìjọsìn” wa jẹ́ “òtúbáńtẹ́,” tí Ọlọ́run kì yóò sì tẹ́wọ́ gbà nítorí ìdí èyíkéyìí.
20 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jákọ́bù kò mẹ́nu kan gbogbo apá ìjọsìn tí ó mọ́, òun sọ pé ó wé mọ́ ‘bíbójútó àwọn ọmọ òrukàn àti àwọn opó nínú ìpọ́njú wọn.’ (Gálátíà 2:10; 6:10; Jòhánù Kíní 3:18) Ìjọ Kristẹni ń fi ọkàn ìfẹ́ àrà ọ̀tọ̀ hàn nínú pípèsè fún àwọn opó. (Ìṣe 6:1-6; Tímótì Kíní 5:8-10) Níwọ̀n bí Ọlọ́run ti jẹ́ Olùdáàbòbo àwọn opó àti aláìníbaba, ẹ jẹ́ kí a fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú Rẹ̀ nípa ṣíṣe ohun tí a bá lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí àti nípa ti ara. (Diutarónómì 10:17, 18) Ìjọsìn tí ó mọ́ tún túmọ̀ sí “láti pa ara ẹni mọ́ láìní èérí kúrò nínú ayé,” àwùjọ ènìyàn aláìṣòdodo tí ó wà lábẹ́ agbára Sátánì. (Jòhánù 17:16; Jòhánù Kíní 5:19) Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a máa bá a lọ ní ṣíṣàìlọ́wọ́ nínú ìwà àìfi-Ọlọ́run-pè ti ayé, kí a baà lè máa yin Jèhófà lógo, kí a sì jẹ́ ẹni tí ó wúlò nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀.—Tímótì Kejì 2:20-22.
21. Ní ìsopọ̀ pẹ̀lú lẹ́tà Jákọ́bù, àwọn ìbéèrè míràn wo ni ó yẹ kí a gbé yẹ̀ wò?
21 Ìmọ̀ràn Jákọ́bù tí a ti gbé yẹ̀ wò báyìí yẹ kí ó ràn wá lọ́wọ́ láti fara da àwọn àdánwò, kí a sì rọ̀ mọ́ ìgbàgbọ́ wa. Ó yẹ kí ó mú ìmọrírì wa pọ̀ sí i fún Olùfúnni ní àwọn ẹ̀bùn rere. Àwọn ọ̀rọ̀ Jákọ́bù sì ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe ìjọsìn tí ó mọ́. Kí ni ohun mìíràn tí ó mú wá sí àfiyèsí wa? Kí ni àwọn ìgbésẹ̀ tí a lè gbé síwájú sí i láti fi hàn pé a ní ìgbàgbọ́ tòótọ́ nínú Jèhófà?
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Nígbà tí o bá ń ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́ tàbí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé nínú àpilẹ̀kọ yìí àti méjì tí ó tẹ̀ lé e, ìwọ yóò rí i pé ó ṣàǹfààní gan-an láti ka apá tí a tọ́ka sí nínú lẹ́tà Jákọ́bù tí ń fún ìgbàgbọ́ lókun.
Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?
◻ Kí ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti fara da àdánwò?
◻ Láìfi àdánwò pè, èé ṣe tí àwọn Kristẹni fi lè yọ ayọ̀ ńláǹlà?
◻ Báwo ni a ṣe lè jẹ́ olùṣe ọ̀rọ̀ náà?
◻ Kí ni ohun tí ìjọsìn tí ó mọ́ ní nínú?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Nígbà tí o bá wà lábẹ́ àdánwò, lo ìgbàgbọ́ nínú agbára Jèhófà láti dáhùn àdúrà
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Àwọn “olùṣe ọ̀rọ̀ náà” ń pòkìkí Ìjọba Ọlọ́run kárí ayé