-
Ẹ Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Ẹnu Yín “Dára fún Gbígbéniró”‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’
-
-
7, 8. Dé ìwọ̀n àyè wo la fi máa jíhìn bá a ṣe ń lo ahọ́n wa fún Jèhófà?
7 Ìdí kẹta tá a fi gbọ́dọ̀ máa ṣọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu wa ni pé a máa jíhìn bá a bá ṣe ń lo ahọ́n wa fún Jèhófà. Bá a ṣe ń lo ahọ́n wa kan àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì, ó sì tún ń nípa lórí àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà. Ìwé Jákọ́bù 1:26 sọ pé: “Bí ọkùnrin èyíkéyìí lójú ara rẹ̀ bá dà bí olùjọsìn ní irú ọ̀nà kan, síbẹ̀ tí kò kó ahọ́n rẹ̀ níjàánu, ṣùgbọ́n tí ó ń bá a lọ ní títan ọkàn-àyà ara rẹ̀ jẹ, ọ̀nà ìjọsìn ọkùnrin yìí jẹ́ ìmúlẹ̀mófo.”b Bá a ṣe kà á nínú orí tó ṣáájú, ìjọsìn wa àti ọ̀rọ̀ ẹnu wa jọ ń rìn pọ̀ ni. Bí a kì í bá kó ahọ́n wa níjàánu, tó wá di pé a bẹ̀rẹ̀ sí fọ̀rọ̀ ẹnu wa ba àwọn èèyàn lọ́kàn jẹ́, tá a sì fi ń kó bá wọn, ńṣe ni Ọlọ́run máa gbàgbé gbogbo iṣẹ́ rere wa. Àbẹ́ ò rí i pé ọ̀rọ̀ yìí gbèrò?—Jákọ́bù 3:8-10.
-
-
Ẹ Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Ẹnu Yín “Dára fún Gbígbéniró”‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’
-
-
b Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “ìmúlẹ̀mófo” tún lè túmọ̀ sí “aláìwúlò” àti “aláìléso.”—1 Kọ́ríńtì 15:17; 1 Pétérù 1:18.
-