Ìgbàgbọ́ Ń sún Wa Ṣiṣẹ́!
“Ẹ̀yin rí i pé ìgbàgbọ́ [Ábúráhámù] ṣiṣẹ́ pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ rẹ̀ àti nípa àwọn iṣẹ́ rẹ̀ a sọ ìgbàgbọ́ rẹ̀ di pípé.”—JÁKỌ́BÙ 2:22.
1, 2. Báwo ni a óò ṣe hùwà bí a bá ní ìgbàgbọ́?
Ọ̀PỌ̀ sọ pé àwọn ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run. Síbẹ̀, ìgbàgbọ́ ẹnu lásán ti kú bámúbámú. Jákọ́bù ọmọlẹ́yìn kọ̀wé pé: “Ìgbàgbọ́, bí kò bá ní àwọn iṣẹ́, jẹ́ òkú nínú ara rẹ̀.” Ó sọ pẹ̀lú pé Ábúráhámù olùbẹ̀rù Ọlọ́run ní ìgbàgbọ́ tí ó “ṣiṣẹ́ pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ rẹ̀.” (Jákọ́bù 2:17, 22) Kí ni ìjẹ́pàtàkì irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ fún wa?
2 Bí a bá ní ìgbàgbọ́ tòótọ́, a kò ní wulẹ̀ gba ohun tí a gbọ́ ní àwọn ìpàdé Kristẹni gbọ́ nìkan. A óò pèsè ẹ̀rí ìgbàgbọ́ nítorí pé a jẹ́ Ẹlẹ́rìí aláápọn fún Jèhófà. Bẹ́ẹ̀ ni, ìgbàgbọ́ yóò sún wa láti fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò nínú ìgbésí ayé, yóò sì sún wa ṣiṣẹ́.
Ìṣègbè Kò Bá Ìgbàgbọ́ Mu
3, 4. Báwo ni ó ṣe yẹ kí ìgbàgbọ́ nípa lórí bí a ṣe ń bá àwọn ẹlòmíràn lò?
3 Bí a bá ní ojúlówó ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run àti Kristi, a kì yóò ṣègbè. (Jákọ́bù 2:1-4) Díẹ̀ nínú àwọn tí Jákọ́bù kọ̀wé sí ni kò fi àìṣojúsàájú tí a ń béèrè lọ́wọ́ àwọn Kristẹni tòótọ́ hàn. (Róòmù 2:11) Nípa báyìí, Jákọ́bù béèrè pé: “Ẹ kò di ìgbàgbọ́ Olúwa wa Jésù Kristi, ògo wa, mú pẹ̀lú ìṣègbè, àbí ẹ ṣe bẹ́ẹ̀?” Bí ọlọ́rọ̀ kan tí ó jẹ́ aláìgbàgbọ́ tí ó to òrùka wúrà sọ́wọ́, tí ó sì rú sí aṣọ tí ó jojú ní gbèsè bá wá sí ìpàdé pẹ̀lú aláìgbàgbọ́ “òtòṣì kan nínú aṣọ [eléèérí],” àwọn méjèèjì ni ó yẹ kí a kí káàbọ̀ tayọ̀tayọ̀, ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́rọ̀ ni a kà sí. A ń fún wọn ní ìjókòó “ní ibi tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀,” nígbà tí a sì sọ fún àwọn òtòṣì aláìgbàgbọ́ pé kí wọ́n wà lórí ìdúró tàbí kí wọ́n jókòó sí ilẹ̀ pẹ̀pẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ ẹnì kan.
4 Jèhófà pèsè ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi fún àwọn ọlọ́rọ̀ àti òtòṣì láìyọ ẹnì kankan sílẹ̀. (Kọ́ríńtì Kejì 5:14) Nítorí náà, bí a bá ń ṣàyẹ́sí àwọn ọlọ́rọ̀ nìkan, a jẹ́ pé a ń yà kúrò nínú ìgbàgbọ́ Kristi, ẹni tí ‘ó di òtòṣì kí a lè di ọlọ́rọ̀ nípasẹ̀ ipò òṣì rẹ̀.’ (Kọ́ríńtì Kejì 8:9) Ẹ má ṣe jẹ́ kí a díwọ̀n àwọn ènìyàn lọ́nà bẹ́ẹ̀ láé—ní jíjẹ́ kí èrò òdì sún wa láti bọlá fún àwọn ènìyàn. Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n bí a bá ṣe ojúsàájú, a óò máa “ṣe àwọn ìpinnu burúkú.” (Jóòbù 34:19) Pẹ̀lú ìfẹ́ ọkàn láti mú inú Ọlọ́run dùn, dájúdájú a kì yóò jọ̀gọ̀nù fún ìdẹwò láti ṣègbè tàbí láti ‘kan sáárá sí àwọn ènìyàn jàǹkànjàǹkàn nítorí àǹfààní ti ara wa.’—Júúdà 4, 16.
5. Àwọn wo ni Ọlọ́run ti yàn láti jẹ́ “ọlọ́rọ̀ nínú ìgbàgbọ́,” báwo sì ni àwọn ọlọ́rọ̀ nípa ti ara ṣe máa ń hùwà lọ́pọ̀ ìgbà?
5 Jákọ́bù jẹ́ kí a mọ àwọn tí ó jẹ́ ọlọ́rọ̀ ní tòótọ́, ó sì rọni pé kí a fi ìfẹ́ hàn sí gbogbo ènìyàn láìṣègbè. (Jákọ́bù 2:5-9) ‘Ọlọ́run ti yan àwọn òtòṣì láti jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú ìgbàgbọ́ àti ajogún ìjọba náà.’ Èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé, lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn òtòṣì ni wọ́n tètè máa ń dáhùn pa dà sí ìhìn rere. (Kọ́ríńtì Kíní 1:26-29) Lápapọ̀, àwọn ọlọ́rọ̀ nípa ti ara máa ń fi gbèsè, owó ọ̀yà, àti àwọn ìgbésẹ̀ ọ̀ràn òfin ni àwọn ẹlòmíràn lára. Wọ́n ń sọ̀rọ̀ ibi nípa Kristi, wọ́n sì ń ṣe inúnibíni sí wa nítorí pé a ń jẹ́ orúkọ rẹ̀. Ṣùgbọ́n, ẹ jẹ́ kí ó jẹ́ ìpinnu wa láti ṣègbọràn sí “ọba òfin,” èyí tí ó ń béèrè ìfẹ́ aládùúgbò—kí a nífẹ̀ẹ́ ọlọ́rọ̀ àti òtòṣì lọ́gbọọgba. (Léfítíkù 19:18; Mátíù 22:37-40) Níwọ̀n bí Ọlọ́run ti ń béèrè èyí, ìṣègbè jẹ́ ‘ṣíṣiṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.’
‘Àánú Ń Yọ Ayọ̀ Ńláǹlà Lórí Ìdájọ́’
6. Báwo ni a ṣe lè di arúfin bí a kò bá fi àánú bá àwọn ẹlòmíràn lò?
6 Bí a bá ń ṣègbè lọ́nà àìláàánú, arúfin ni wá. (Jákọ́bù 2:10-13) Bí a bá ṣi ẹsẹ̀ gbé lọ́nà yí, a di olùrú gbogbo òfin Ọlọ́run. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí kò ṣe panṣágà ṣùgbọ́n tí wọ́n jẹ́ olè di olùré Òfin Mósè kọjá. Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, a ń ṣèdájọ́ wa nípasẹ̀ “òfin àwọn ẹni òmìnira”—Ísírẹ́lì tẹ̀mí tí ó wà nínú májẹ̀mú tuntun, tí a kọ òfin rẹ̀ sínú ọkàn àyà wọn.—Jeremáyà 31:31-33.
7. Èé ṣe tí àwọn tí ń bá a lọ ní ṣíṣègbè kò fi lè retí àánú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run?
7 Bí a bá sọ pé a ní ìgbàgbọ́ ṣùgbọ́n tí a ń bá a lọ ní ṣíṣègbè, a wà nínú ewu. Àwọn tí wọ́n jẹ́ aláìnífẹ̀ẹ́ àti aláìláàánú yóò gba ìdájọ́ wọn láìsí àánú. (Mátíù 7:1, 2) Jákọ́bù sọ pé: “Àánú a máa yọ ayọ̀ [ńláǹlà] lọ́nà ìṣẹ́gun lórí ìdájọ́.” Bí a bá fara mọ́ ìtọ́sọ́nà ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà nípa fífi àánú hàn nínú gbogbo ìbálò wa, a kì yóò dá wa lẹ́bi nígbà tí a bá dájọ́ wa. Dípò bẹ́ẹ̀, a óò rí àánú gbà, a óò sì tipa báyìí ṣẹ́gun ìdájọ́ lílekoko tàbí ìdájọ́ aláìbáradé.
Ìgbàgbọ́ Ń Mú Àwọn Iṣẹ́ Àtàtà Jáde
8. Kí ni ipò tí ẹnì kan tí ó sọ pé òun ní ìgbàgbọ́ ṣùgbọ́n tí kò ní iṣẹ́ wà?
8 Yàtọ̀ sí mímú kí a jẹ́ onífẹ̀ẹ́ àti aláàánú, ìgbàgbọ́ ń mú àwọn iṣẹ́ àtàtà míràn jáde. (Jákọ́bù 2:14-26) Àmọ́ ṣáá o, ìgbàgbọ́ ẹnu lásán tí kò ní iṣẹ́ kì yóò gbà wá là. Lóòótọ́, a kò lè ní ìdúró òdodo pẹ̀lú Ọlọ́run nípa àwọn iṣẹ́ Òfin. (Róòmù 4:2-5) Jákọ́bù ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn iṣẹ́ tí ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ ń sún wa ṣe, kì í ṣe èyí tí àkójọ òfin ń sún wa ṣe. Bí irú àwọn ànímọ́ bẹ́ẹ̀ bá sún wa ṣiṣẹ́, a kì yóò wulẹ̀ fi ẹnu lásán fi ìdàníyàn onínúrere hàn sí ẹlẹgbẹ́ wa olùjọsìn tí ó nílò ìrànwọ́. A óò pèsè ìrànwọ́ nípa ti ara fún àwọn arákùnrin tàbí arábìnrin tí kò láṣọ tàbí tí ebi ń pa. Jákọ́bù béèrè pé: ‘Bí o ba sọ fún ará kan tí ó nílò ìrànwọ́ pé: “Máa lọ ní àlàáfíà, kí ara rẹ yá gágá kí o sì jẹun yó dáadáa” ṣùgbọ́n tí o kò fún un ní àwọn ohun tí ó nílò gan-an, àǹfààní wo ni ìyẹn jẹ́?’ Kò ṣàǹfààní kankan. (Jóòbù 31:16-22) Irú “ìgbàgbọ́” bẹ́ẹ̀ jẹ́ òkú!
9. Kí ni ó ń fi hàn pé a ní ìgbàgbọ́?
9 A lè máa dara pọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn Ọlọ́run dé àyè kan, ṣùgbọ́n àwọn iṣẹ́ tí a ṣe tọkàntọkàn nìkan ni ó lè fi hàn ní tòótọ́ pé a ní ìgbàgbọ́. Ẹ wo bí ó ti dára tó bí a bá ti kọ ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan sílẹ̀ tí a sì gbà gbọ́ pé Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo ni ó wà. Síbẹ̀, kí a wulẹ̀ gbà gbọ́ lásán kì í ṣe ìgbàgbọ́. “Àwọn ẹ̀mí èṣù . . . gbà gbọ́” wọ́n sì “gbọ̀n jìnnìjìnnì” fún ìbẹ̀rù nítorí ìparun ń dúró dè wọ́n. Bí a bá ní ìgbàgbọ́ ní tòótọ́, yóò sún wa láti mú irú àwọn iṣẹ́ bíi wíwàásù ìhìn rere àti pípèsè oúnjẹ àti aṣọ fún onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa tí ó nílò ìrànwọ́ jáde. Jákọ́bù béèrè pé: “Ìwọ ha bìkítà láti mọ̀, Óò òfìfo ènìyàn [tí kò kún fún ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run], pé ìgbàgbọ́ láìsí àwọn iṣẹ́ jẹ́ aláìṣiṣẹ́?” Bẹ́ẹ̀ ni, ìgbàgbọ́ ń béèrè iṣẹ́.
10. Èé ṣe tí a fi pe Ábúráhámù ní “bàbá gbogbo àwọn wọnnì tí wọ́n ní ìgbàgbọ́”?
10 Ìgbàgbọ́ Ábúráhámù baba ńlá tí ó jẹ́ olùṣèfẹ́ Ọlọ́run sún un ṣiṣẹ́. Gẹ́gẹ́ bíi “bàbá gbogbo àwọn wọnnì tí wọ́n ní ìgbàgbọ́” òun ni a “polongo . . . ní olódodo nípa àwọn iṣẹ́ lẹ́yìn tí ó ti fi Aísíìkì ọmọkùnrin rẹ̀ rúbọ lórí pẹpẹ.” (Róòmù 4:11, 12; Jẹ́nẹ́sísì 22:1-14) Ká ní Ábúráhámù ti ṣàìní ìgbàgbọ́ pé Ọlọ́run lè jí Aísíìkì díde kí ó sì mú ìlérí Rẹ̀ nípa irú-ọmọ nípasẹ̀ rẹ̀ ṣẹ ńkọ́? Nígbà náà, Ábúráhámù kì bá tí gbìyànjú láé láti fi ọmọkùnrin rẹ̀ rúbọ. (Hébérù 11:19) Àwọn iṣẹ́ onígbọràn Ábúráhámù ni a fi “sọ ìgbàgbọ́ rẹ̀ di pípé,” tàbí fi mú un pé pérépéré. Nípa báyìí, “a . . . mú ìwé mímọ́ náà [Jẹ́nẹ́sísì 15:6] ṣẹ tí ó wí pé: ‘Ábúráhámù lo ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà, a sì kà á sí òdodo fún un.’” Àwọn iṣẹ́ Ábúráhámù ní gbígbìyànjú láti fi Aísíìkì rúbọ fìdí ohun tí Ọlọ́run ti sọ ṣáájú múlẹ̀ pé Ábúráhámù jẹ́ olódodo. Nípa àwọn iṣẹ́ ìgbàgbọ́, ó fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn fún Ọlọ́run, a sì wá ń pè é ní “ọ̀rẹ́ Jèhófà.”
11. Ẹ̀rí ìgbàgbọ́ wo ni a rí nínú ọ̀ràn Ráhábù?
11 Ábúráhámù fi hàn pé “a óò polongo ènìyàn kan ní olódodo nípa àwọn iṣẹ́, kì í sì í ṣe nípa ìgbàgbọ́ nìkan.” Ìyẹn rí bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ní ti Ráhábù, aṣẹ́wó kan ní Jẹ́ríkò. Òun ni a “polongo . . . ní olódodo nípa àwọn iṣẹ́, lẹ́yìn tí ó ti gba àwọn ońṣẹ́ [ọmọ Ísírẹ́lì] pẹ̀lú ẹ̀mí aájò àlejò tí ó sì rán wọn jáde gba ọ̀nà míràn” tí wọ́n fi yè bọ́ lọ́wọ́ àwọn ọmọ Kénáánì ọ̀tá wọn. Kí ó tó bá àwọn amí ọmọ Ísírẹ́lì pàdé, òun ti mọ Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run tòótọ́, àwọn ọ̀rọ̀ tí ó sì sọ lẹ́yìn náà àti fífi tí ó fi iṣẹ́ kárùwà sílẹ̀ fi ẹ̀rí ìgbàgbọ́ rẹ̀ hàn. (Jóṣúà 2:9-11; Hébérù 11:31) Lẹ́yìn àpẹẹrẹ kejì yí ti ìgbàgbọ́ tí a fi hàn nípasẹ̀ iṣẹ́, Jákọ́bù sọ pé: “Ní tòótọ́, gẹ́gẹ́ bí ara láìsí ẹ̀mí ti jẹ́ òkú, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni ìgbàgbọ́ láìsí àwọn iṣẹ́ jẹ́ òkú.” Nígbà tí ẹnì kan bá ti kú, kò sí ipá asúnniṣiṣẹ́, tàbí “ẹ̀mí,” nínú rẹ̀, kò sì lè ṣe ohunkóhun. Ìgbàgbọ́ ẹnu lásán ti kú bámúbámú, ó sì jẹ́ aláìwúlò bí òkú. Ṣùgbọ́n, bí a bá ní ojúlówó ìgbàgbọ́ yóò sún wa sí ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.
Ṣàkóso Ahọ́n Yẹn!
12. Kí ni ó yẹ kí àwọn alàgbà nínú ìjọ ṣe?
12 Sísọ̀rọ̀ àti kíkọ́ni lè pèsè ẹ̀rí níní ìgbàgbọ́ pẹ̀lú, ṣùgbọ́n ó yẹ kí a ṣàkóso ara wa. (Jákọ́bù 3:1-4) Gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ nínú ìjọ, àwọn alàgbà ní ẹrù iṣẹ́ wíwúwo àti ìjíhìn ńláǹlà fún Ọlọ́run. Nítorí náà, wọ́n gbọ́dọ̀ yẹ ìsúnniṣe àti ìtóótun wọn wò tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀. Yàtọ̀ sí ìmọ̀ àti ìpegedé, àwọn ọkùnrin wọ̀nyí gbọ́dọ̀ ní ìfẹ́ jíjinlẹ̀ fún Ọlọ́run àti fún àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn. (Róòmù 12:3, 16; Kọ́ríńtì Kíní 13:3, 4) Àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ gbé ìmọ̀ràn wọn ka Ìwé Mímọ́. Bí alàgbà kan bá ṣàṣìṣe nínú ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, tí èyí sì yọrí sí ìṣòro fún àwọn ẹlòmíràn, Ọlọ́run yóò dá a lẹ́jọ́ lọ́nà tí kò báradé nípasẹ̀ Kristi. Nítorí náà, àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti aláápọn nínú ìkẹ́kọ̀ọ́, ní fífi òtítọ́ rọ̀ mọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
13. Èé ṣe tí a fi máa ń kọsẹ̀ nínú ọ̀rọ̀?
13 Kódà àwọn olùkọ́ dídáńgájíá pàápàá—àní, gbogbo wa—“ń kọsẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ìgbà” nítorí àìpé. Kíkọsẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìkù-díẹ̀-káàtó tí ó wọ́pọ̀ jù lọ, tí ó sì lè di èyí tí ń pani lára. Jákọ́bù sọ pé: “Bí ẹnì kan kò bá kọsẹ̀ nínú ọ̀rọ̀, ẹni yìí jẹ́ ènìyàn pípé, tí ó lè kó gbogbo ara rẹ̀ pẹ̀lú níjàánu.” Láìdàbí Jésù Kristi, a kò lè ṣàkóso ahọ́n wa lọ́nà pípé. Bí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a óò lè ṣàkóso àwọn ẹ̀yà ara wa yòó kù. Ó ṣe tán, ìjánu àti irin rẹ̀ ń mú kí ẹṣin lọ sí ibi tí a bá darí rẹ̀ sí, àní ọkọ̀ ojú omi ńlá tí ìjì ń gbé kiri pàápàá ni atukọ̀ lè fi ìtọ́kọ̀ kékeré kan darí bí ó bá ṣe fẹ́.
14. Báwo ni Jákọ́bù ṣe tẹnu mọ́ ìdí tí ó fi yẹ kí a sapá kí a baà lè ṣàkóso ahọ́n wa?
14 Gbogbo wa gbọ́dọ̀ fi àìlábòsí gbà pé ṣíṣàkóso ahọ́n wa ń béèrè ìsapá gidi. (Jákọ́bù 3:5-12) Bí a bá fi wé ẹṣin, ìjánu kéré; ìtọ́kọ̀ sì kéré bákan náà bí a bá fi wé ọkọ̀ ojú omi. Bí a bá sì fi wé ara ènìyàn, ahọ́n kéré “síbẹ̀ a sì máa ṣe ìfọ́nnu ńlá.” Níwọ̀n bí Ìwé Mímọ́ ti mú kí ó ṣe kedere pé ìṣògo kì í mú inú Ọlọ́run dùn, ẹ jẹ́ kí a wá ìrànwọ́ Rẹ̀ láti jáwọ́ nínú rẹ̀. (Orin Dáfídì 12:3, 4; Kọ́ríńtì Kíní 4:7) Ǹjẹ́ kí a ṣàkóso ahọ́n wa pẹ̀lú nígbà tí a bá mú wa bínú, kí a rántí pé kìkì ìtapàrà iná lè dáná ran igbó. Gẹ́gẹ́ bí Jákọ́bù ti fi hàn, “ahọ́n jẹ́ iná” tí ó lágbára láti fa ìpalára ńláǹlà. (Òwe 18:21) Họ́wù, ewèlè ahọ́n “jẹ́ ayé àìṣòdodo”! Gbogbo ànímọ́ búburú ayé aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run yìí ní a so pọ̀ mọ́ ahọ́n tí a kò ṣàkóso. Òun ni ó fa irú àwọn nǹkan apanilára bíbanijẹ́ àti ẹ̀kọ́ èké. (Léfítíkù 19:16; Pétérù Kejì 2:1) Àbí kí ni èrò rẹ? Kò ha yẹ kí ìgbàgbọ́ wa sún wa láti ṣiṣẹ́ kára ní ṣíṣàkóso ahọ́n wa bí?
15. Ìpalára wo ni ahọ́n tí a kò kó níjàánu lè ṣe?
15 Ahọ́n tí a kò kó níjàánu ‘lè bẹ̀tẹ́ lù wá’ pátápátá. Fún àpẹẹrẹ, bí a bá gbá wa mú tí a ń purọ́ léraléra, a lè wá mọ̀ wá sí òpùrọ́. Ṣùgbọ́n, báwo ni ewèlè ahọ́n kan ṣe “ń mú àgbá kẹ̀kẹ́ ìgbésí ayé ẹ̀dá gbiná”? Nípa mímú kí ìgbésí ayé kún fún ìṣòro. Ahọ́n kan ṣoṣo tí a kò ṣàkóso lè dá rúgúdù sílẹ̀ láàárín odindi ìjọ. Jákọ́bù mẹ́nu kan “Gẹ̀hẹ́nà,” Àfonífojì Hínómù. A ti lò ó rí fún fífi ọmọ rúbọ, ó di ààtàn fún fífi iná jó pàǹtírí Jerúsálẹ́mù. (Jeremáyà 7:31) Nítorí náà, Gẹ̀hẹ́nà ń ṣàpẹẹrẹ ìparun yán-ányán-án. Ní ìtumọ̀ kan, Gẹ̀hẹ́nà ti fún ewèlè ahọ́n ní agbára ìpanirun rẹ̀. Bí a kò bá kó ahọ́n wa níjàánu, àwa fúnra wa lè wá jìyà iná tí a dá. (Mátíù 5:22) A tilẹ̀ lè yọ wá lẹ́gbẹ́ pàápàá kúrò nínú ìjọ fún kíkẹ́gàn ẹnì kan.—Kọ́ríńtì Kíní 5:11-13.
16. Lójú ìwòye ìpalára tí ewèlè ahọ́n lè ṣe, kí ni ó yẹ kí a ṣe?
16 Gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti lè mọ̀ láti inú kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, Jèhófà pàṣẹ pé kí ènìyàn jọba lórí àwọn ẹ̀dá ẹranko. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Gbogbo onírúurú àwọn ẹ̀dá ẹranko ni a sì ti rọ̀ lójú. Fún àpẹẹrẹ, àwọn àṣáǹwéwé tí a kọ́ ni a ti lò fún ọdẹ ṣíṣe. ‘Àwọn ohun tí ń rákò’ tí Jákọ́bù mẹ́nu kàn lè ní àwọn ejò tí àwọn atujú ejò ń darí nínú. (Orin Dáfídì 58:4, 5) Ènìyàn tilẹ̀ lè darí àwọn ẹja àbùùbùtán pàápàá, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ a kò lè rọ ahọ́n lójú pátápátá. Síbẹ̀síbẹ̀, a gbọ́dọ̀ yẹra fún sísọ ọ̀rọ̀ èébú, tí ń gúnni lára, tàbí tí ń bani lórúkọ jẹ́. Ewèlè ahọ́n lè jẹ́ ohun eléwu kan tí ó kún fún májèlé panipani. (Róòmù 3:13) Lọ́nà tí ó bani nínú jẹ́, ahọ́n àwọn olùkọ́ èké yí àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ mélòó kan pa dà kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Nítorí náà, kí a má ṣe jẹ́ kí àwọn ọ̀rọ̀ olóró láti ọ̀dọ̀ apẹ̀yìndà ṣẹ́pá wa láé, yálà èyí ti wọ́n sọ ni o tàbí èyí tí wọ́n kọ sílẹ̀.—Tímótì Kíní 1:18-20; Pétérù Kejì 2:1-3.
17, 18. Ìtakora ahọ́n wo ni a tọ́ka sí nínú Jákọ́bù 3:9-12, kí sì ni ohun tí ó yẹ kí a ṣe nípa èyí?
17 Ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run àti fífẹ́ láti mú inú rẹ̀ dùn lè dáàbò bò wá kúrò lọ́wọ́ ìpẹ̀yìndà, ó sì lè fà wá sẹ́yìn kúrò nínú lílo ahọ́n wa lọ́nà tí ó ta kora. Ní títọ́ka sí ìtakora ahọ́n àwọn kan, Jákọ́bù sọ pé ‘ahọ́n ni a fi ń fi ìbùkún fún Bàbá wa, Jèhófà, a sì ń fi gégùn-ún fún àwọn ènìyàn tí wọ́n di wíwà ní jíjọ Ọlọ́run.’ (Jẹ́nẹ́sísì 1:26) Jèhófà ni Bàbá wa ní ti pé òun “ni ó fún gbogbo ènìyàn ní ìyè àti èémí àti ohun gbogbo.” (Ìṣe 17:24, 25) Òun tún ni Bàbá àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ní ìtumọ̀ tẹ̀mí. Gbogbo wa ni a wà “ní jíjọ Ọlọ́run” ní ti àwọn ànímọ́ èrò orí àti ti ìwà rere, títí kan ìfẹ́, ìdájọ́ òdodo, àti ọgbọ́n tí ó mú wa yàtọ̀ sí àwọn ẹranko. Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀ nígbà náà, báwo ni ó ṣe yẹ kí a hùwà bí a bá ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà?
18 Bí a bá gégùn-ún fún ènìyàn, ìyẹn yóò túmọ̀ sí pé a óò ṣépè, tàbí pe ibi sọ̀ kalẹ̀, lé wọn lórí. Níwọ̀n bí àwa kì í ti í ṣe wòlíì tí a mí sí látọ̀runwá, àwọn tí a fún ní ọlá àṣẹ láti pe ibi sọ̀ kalẹ̀ sórí ẹnikẹ́ni, irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ yóò jẹ́ ẹ̀rí ìkórìíra tí yóò mú ìyìn tí a ń fún Ọlọ́run já sí asán. Kò tọ́ pé kí “ìbùkún àti ègún” máa jáde wá láti ẹnu kan náà. (Lúùkù 6:27, 28; Róòmù 12:14, 17-21; Júúdà 9) Ẹ wo bí yóò ti jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tó láti kọrin ìyìn sí Ọlọ́run ní ìpàdé, lẹ́yìn náà kí a sì sọ̀rọ̀ ibi nípa àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa! Omi dídùn àti kíkorò kò lè sun jáde láti inú orísun kan náà. Bí “igi ọ̀pọ̀tọ́ kò [ti] lè mú àwọn èso ólífì jáde tàbí kí àjàrà mú àwọn èso ọ̀pọ̀tọ́ jáde,” bẹ́ẹ̀ ni omi iyọ̀ kò lè mú omi tí ó ṣeé mu jáde. Ohun kan ti ṣẹlẹ̀ sí wa nípa tẹ̀mí bí àwa, tí ó yẹ kí ó máa sọ ohun tí ó dára, bá ń sọ ọ̀rọ̀ kíkorò jáde nígbà gbogbo. Bí irú ìwà yẹn bá ti wọ̀ wá lẹ́wù, ẹ jẹ́ kí a gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́ Jèhófà kí a lè ṣíwọ́ sísọ̀rọ̀ lọ́nà bẹ́ẹ̀.—Orin Dáfídì 39:1.
Fi Ọgbọ́n Àtòkèwá Hùwà
19. Bí ọgbọ́n àtọ̀runwá bá tọ́ wa sọ́nà, báwo ni a ṣe lè nípa lórí àwọn ẹlòmíràn?
19 Gbogbo wa ni a nílò ọgbọ́n láti sọ̀rọ̀ kí a sì ṣe àwọn nǹkan tí ó yẹ àwọn tí ó ní ìgbàgbọ́. (Jákọ́bù 3:13-18) Bí a bá ní ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ fún Ọlọ́run, òun yóò fún wa ní ọgbọ́n àtọ̀runwá, agbára láti lo ìmọ̀ bí ó ti tọ́. (Òwe 9:10; Hébérù 5:14) Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ń kọ́ wa bí a ṣe lè fi “ìwà tútù tí ó jẹ́ ti ọgbọ́n” hàn. Àti nítorí pé a jẹ́ oníwà tútù, a ń gbé àlàáfíà ìjọ lárugẹ. (Kọ́ríńtì Kíní 8:1, 2) Ẹnikẹ́ni nínú àwọn tí wọ́n bá ń ṣògo pé àwọn jẹ́ olùkọ́ títayọ láàárín àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn ‘ń purọ́ lòdì sí òtítọ́ Kristẹni,’ èyí tí ó dẹ́bi fún ìgbéra-ẹni-lárugẹ wọn. (Gálátíà 5:26) “Ọgbọ́n” wọn jẹ́ ti “ilẹ̀ ayé”—èyí tí ó jẹ́ ànímọ́ àwọn ènìyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ ti a sọ di àjèjì sí Ọlọ́run. Ó jẹ́ ti ‘ẹranko,’ ní jíjẹ́ àbájáde ìrònú ti ẹran ara. Họ́wù, ó jẹ́ ti “ẹ̀mí èṣù” pàápàá, nítorí pé àwọn ẹ̀mí búburú jẹ́ agbéraga! (Tímótì Kíní 3:6) Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a fi ọgbọ́n àti ìrẹ̀lẹ̀ hùwà kí a má baà ṣe ohunkóhun tí yóò fa ipò tí irú ‘àwọn nǹkan tí ó burú jáì’ bíi fífi ọ̀rọ̀ èké bani jẹ́ àti ṣíṣègbè ti lè gbèrú.
20. Báwo ni ìwọ yóò ṣe ṣàpèjúwe ọgbọ́n àtọ̀runwá?
20 “Ọgbọ́n tí ó wá láti òkè á kọ́kọ́ mọ́ níwà,” ní mímú kí a mọ́ ní ti ìwà híhù àti nípa tẹ̀mí. (Kọ́ríńtì Kejì 7:11) Ó “lẹ́mìí àlàáfíà,” ní sísún wa láti lépa àlàáfíà. (Hébérù 12:14) Ọgbọ́n àtọ̀runwá ń mú kí a “fòye báni lò,” kì í mú kí a jẹ́ olójú ìwòye tí kò ṣe é yí pa dà, tí ó sì ṣòro láti bá lò. (Fílípì 4:5) Ọgbọ́n àtòkèwá “múra tán láti ṣègbọràn,” ó ń gbé ṣíṣe ìgbọràn sí ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ètò àjọ Jèhófà lárugẹ. (Róòmù 6:17) Ọgbọ́n àtòkèwá tún ń mú kí a kún fún àánú àti ìyọ́nú. (Júúdà 22, 23) Nítorí tí ó ti kún fún “àwọn èso rere,” ó máa ń súnni sí ṣíṣe àníyàn nípa àwọn ẹlòmíràn àti nípa àwọn iṣẹ́ tí ó wà ní ìbámu pẹ̀lú ohun rere, òdodo, àti òtítọ́. (Éfésù 5:9) Àti bí olùwá àlàáfíà, a ń gbádùn “èso òdodo” tí ń gbèrú lábẹ́ àwọn ipò alálàáfíà.
21. Ní ìbámu pẹ̀lú Jákọ́bù 2:1–3:18, kí ni àwọn iṣẹ́ tí ó yẹ kí ìgbàgbọ́ wa nínú Ọlọ́run sún wa ṣe?
21 Nítorí náà, ó ṣe kedere pé ìgbàgbọ́ ń sún wa ṣiṣẹ́. Ó ń mú kí a jẹ́ ẹni tí kì í ṣe ojúsàájú, tí ó jẹ́ aláàánú, àti aláápọn nínú àwọn iṣẹ́ àtàtà. Ìgbàgbọ́ ń ràn wá lọ́wọ́ láti ṣàkóso ahọ́n wa, kí a sì fi ọgbọ́n àtọ̀runwá hùwà. Ṣùgbọ́n, kì í ṣe gbogbo ohun tí a lè rí kọ́ nínú lẹ́tà yí nìyí. Jákọ́bù ní ìmọ̀ràn púpọ̀ sí i tí ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti hùwà lọ́nà tí ó yẹ àwọn tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà.
Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?
◻ Kí ni ohun tí ó burú nínú ṣíṣègbè?
◻ Báwo ni ìgbàgbọ́ àti àwọn iṣẹ́ ṣe bára tan?
◻ Èé ṣe tí ó fi ṣe pàtàkì láti ṣàkóso ahọ́n wa?
◻ Kí ni ohun tí ọgbọ́n àtọ̀runwá jẹ́?