‘Baba Yín Jẹ́ Aláàánú’
“Ẹ máa bá a lọ ní dídi aláàánú, gan-an gẹ́gẹ́ bí Baba yín ti jẹ́ aláàánú.”—LÚÙKÙ 6:36.
1, 2. Báwo ni ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fáwọn akọ̀wé àti Farisí àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ṣe fi hàn pé ó dára láti jẹ́ aláàánú?
NǸKAN bí ẹgbẹ̀ta [600] òfin àti ìlànà ló wà nínú Òfin tí Ọlọ́run tipasẹ̀ Mósè fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́dọ̀ pa Òfin Mósè yẹn mọ́, ó ṣe pàtàkì gan-an pé kí wọ́n jẹ́ olójú àánú. Ìwọ wo ohun tí Jésù sọ fáwọn Farisí tí kò lójú àánú. Ẹ̀ẹ̀mejì ni Jésù bá wọn wí gan-an, tó fi yé wọn pé ohun tí Ọlọ́run sọ ni pé: “Àánú ni èmi fẹ́, kì í sì í ṣe ẹbọ.” (Mátíù 9:10-13; 12:1-7; Hóséà 6:6) Nígbà tí iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù lórí ilẹ̀ ayé ń parí lọ, ó sọ pé: “Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin akọ̀wé òfin àti ẹ̀yin Farisí, alágàbàgebè! nítorí pé ẹ ń fúnni ní ìdá mẹ́wàá efinrin àti ewéko dílì àti ewéko kúmínì, ṣùgbọ́n ẹ ṣàìka àwọn ọ̀ràn wíwúwo jù lọ nínú Òfin sí, èyíinì ni, ìdájọ́ òdodo àti àánú àti ìṣòtítọ́.”—Mátíù 23:23.
2 Láìsí àní-àní, Jésù ka àánú sí ànímọ́ tó ṣe pàtàkì gan-an. Ó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ máa bá a lọ ní dídi aláàánú, gan-an gẹ́gẹ́ bí Baba yín ti jẹ́ aláàánú.” (Lúùkù 6:36) Ká tó lè “di aláfarawé Ọlọ́run,” ká jẹ́ aláàánú bíi tiẹ̀, a ní láti mọ ohun tí àánú jẹ́ gan-an. (Éfésù 5:1) Yàtọ̀ síyẹn, tá a bá mọ àǹfààní ńlá tó wà nínú jíjẹ́ aláàánú, àá túbọ̀ máa ṣàánú.
Ẹ Máa Ṣàánú Àwọn Tó Wà Nínú Ìṣòro
3. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé Jèhófà ló lè jẹ́ ká mọ ohun tí àánú jẹ́ gan-an?
3 Onísáàmù kọ ọ́ lórin pé: “Jèhófà jẹ́ olóore ọ̀fẹ́ àti aláàánú, ó ń lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́. Jèhófà ń ṣe rere fún gbogbo gbòò, àánú rẹ̀ sì ń bẹ lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ̀.” (Sáàmù 145:8, 9) Jèhófà ni “Baba àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo.” (2 Kọ́ríńtì 1:3) Téèyàn bá ń fìyọ́nú báni lò, ìyẹn fi hàn pé ó jẹ́ olójú àánú. Ọ̀kan pàtàkì sì ni àánú jẹ́ lára ànímọ́ Ọlọ́run. Àpẹẹrẹ rẹ̀ àti ìtọ́ni tó fún wa lè jẹ́ ká mọ ohun tí àánú jẹ́ gan-an.
4. Ẹ̀kọ́ wo ni Aísáyà 49:15 kọ́ wa nípa àánú?
4 Nínú Aísáyà 49:15, Jèhófà sọ pé: “Aya ha lè gbàgbé ọmọ ẹnu ọmú rẹ̀ tí kì yóò fi ṣe ojú àánú sí ọmọ ikùn rẹ̀?” Irú ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n lò nínú ẹsẹ Bíbélì yìí, tá a tú sí “ojú àánú” náà ni wọ́n pè ní àánú nínú Sáàmù 145:8, 9, tó wà ní ìpínrọ̀ kẹta. Ìwé Aísáyà yìí fi ohun tó máa ń mú kí Jèhófà fàánú hàn wé ohun tó máa ń mú kí abiyamọ ṣàánú ọmọ rẹ̀. Tí ebi bá ń pa ọmọ tàbí ó ń fẹ́ nǹkan kan, ìyọ́nú tàbí ẹ̀mí ìbánikẹ́dùn máa ń mú kí ìyá rẹ̀ wá nǹkan ṣe sí i. Bẹ́ẹ̀ náà ni ìyọ́nú ṣe máa ń mú kí Jèhófà ṣàánú àwọn èèyàn.
5. Báwo ni Jèhófà ṣe bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lò lọ́nà tó fi hàn pé ó “jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú àánú”?
5 Ọ̀tọ̀ ni pé ká káàánú ẹni, ọ̀tọ̀ sì ni pé ká jẹ́ kí àánú yẹn mú wa ṣe nǹkan kan láti fi ran ẹni náà lọ́wọ́. Wo ohun tí Jèhófà ṣe nígbà táwọn olùjọsìn rẹ̀ wà lóko ẹrú ní Íjíbítì ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ààbọ̀ [3,500] ọdún sẹ́yìn. Ó sọ fún Mósè pé: “Láìsí tàbí-ṣùgbọ́n, mo ti rí ṣíṣẹ́ tí a ń ṣẹ́ àwọn ènìyàn mi tí ń bẹ ní Íjíbítì níṣẹ̀ẹ́, mo sì ti gbọ́ igbe ẹkún wọn nítorí àwọn tí ń kó wọn ṣiṣẹ́; nítorí tí mo mọ ìrora tí wọ́n ń jẹ ní àmọ̀dunjú. Èmi ń sọ̀ kalẹ̀ lọ láti dá wọn nídè kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì, kí n sì mú wọn gòkè wá láti ilẹ̀ yẹn sí ilẹ̀ kan tí ó dára tí ó sì ní àyè gbígbòòrò, sí ilẹ̀ kan tí ń ṣàn fún wàrà àti oyin.” (Ẹ́kísódù 3:7, 8) Ní nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] ọdún lẹ́yìn tí Jèhófà dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè kúrò ní Íjíbítì, ó rán wọn létí pé: “Èmi ni ó mú Ísírẹ́lì gòkè wá láti Íjíbítì, tí ó sì dá yín nídè kúrò lọ́wọ́ Íjíbítì àti kúrò lọ́wọ́ gbogbo ìjọba tí ó ń ni yín lára.” (1 Sámúẹ́lì 10:18) Àmọ́, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ ìlànà Ọlọ́run lójú, ìyẹn sì ń kó wọn sí hílàhílo lemọ́lemọ́. Síbẹ̀ àánú wọn tó ń ṣe Jèhófà mú kó gbà wọ́n láìmọye ìgbà. (Àwọn Onídàájọ́ 2:11-16; 2 Kíróníkà 36:15) Èyí jẹ́ ká rí bí Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ ṣe máa ń gbọ́ tàwọn aláìní, àwọn tó wà nínú ewu tàbí àwọn tó wà nínú ìṣòro. Dájúdájú Jèhófà “jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú àánú.”—Éfésù 2:4.
6. Báwo ni Jésù Kristi ṣe ṣàánú àwọn èèyàn bíi ti Baba rẹ̀?
6 Nígbà tí Jésù Kristi wà lórí ilẹ̀ ayé, bíi ti Baba rẹ̀ gẹ́lẹ́ ló ṣe ń ṣàánú àwọn èèyàn. Wo ohun tó ṣe nígbà táwọn ọkùnrin afọ́jú méjì ń bẹ̀ ẹ́ pé, “Olúwa, ṣàánú fún wa, Ọmọkùnrin Dáfídì.” Ohun tí wọ́n ń bẹ̀ ẹ́ pé kó ṣe ni pé kó fi iṣẹ́ ìyanu la ojú àwọn. Jésù là wọ́n lójú, àmọ́ kò ṣe é ní ìṣe gbà-jẹ́-n-sinmi. Bíbélì sọ pé: “Bí àánú ti ṣe é, Jésù fọwọ́ kan ojú wọn, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ wọ́n sì ríran.” (Mátíù 20:30-34) Àánú tó ń ṣe Jésù ló mú kó ṣe iṣẹ́ ìyanu láti fi la ojú afọ́jú, láti tú àwọn tí ẹ̀mí èṣù gbé dè sílẹ̀, láti mú àwọn adẹ́tẹ̀ lára dá, àti láti mú àwọn ọmọ kan lára dá kí ọkàn àwọn òbí wọn lè balẹ̀.—Mátíù 9:27; 15:22; 17:15; Máàkù 5:18, 19; Lúùkù 17:12, 13.
7. Kí ni àpẹẹrẹ Jèhófà Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀ kọ́ wa nípa àánú ṣíṣe?
7 Àpẹẹrẹ Jèhófà Ọlọ́run àti ti Jésù Kristi fi hàn pé ohun méjì ló so pọ̀ mọ́ jíjẹ́ olójú àánú. Àkọ́kọ́ ni pé kí àánú ẹni tó níṣòro ṣèèyàn kéèyàn sì bá a kẹ́dùn. Ìkejì ni pé kéèyàn ṣe nǹkan tó máa mú ìtura bá onítọ̀hún. Ká tó lè jẹ́ aláàánú, a ní láti ṣe nǹkan méjèèjì. Ní ọ̀pọ̀ jù lọ ibi tí Bíbélì ti sọ̀rọ̀ nípa àánú, ohun tó sábà máa ń tọ́ka sí ni pé kí ojú àánú múni ṣoore fẹ́ni tó wà nínú ìṣòro. Àmọ́ báwo ni ká ṣe lo àánú yìí tó bá kan ọ̀rọ̀ ìdájọ́? Ǹjẹ́ ohun tí àánú yìí túmọ̀ sí ni pé ká má fìyà jẹ ẹlẹ́ṣẹ̀ rárá?
Ṣíṣe Ojú Àánú sí Ẹlẹ́ṣẹ̀
8, 9. Kí ló jẹ́ kí Jèhófà ṣàánú Dáfídì lẹ́yìn tó bá Bátí-ṣébà ṣe panṣágà?
8 Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Nátánì wòlíì fi panṣágà tí Dáfídì ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì bá Bátí-ṣébà ṣe ko Dáfídì lójú. Dáfídì kábàámọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ó sì gbàdúrà pé: “Fi ojú rere hàn sí mi, Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́. Nu àwọn ìrélànàkọjá mi kúrò gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ yanturu àánú rẹ. Wẹ̀ mí mọ́ tónítóní kúrò nínú ìṣìnà mi, kí o sì wẹ̀ mí mọ́ àní kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi. Nítorí èmi fúnra mi mọ àwọn ìrélànàkọjá mi, ẹ̀ṣẹ̀ mi sì ń bẹ ní iwájú mi nígbà gbogbo. Ìwọ, ìwọ nìkan ṣoṣo, ni mo dẹ́ṣẹ̀ sí, mo sì ti ṣe ohun tí ó burú ní ojú rẹ.”—Sáàmù 51:1-4.
9 Dáfídì kábàámọ̀ gidigidi. Nítorí náà, Jèhófà dárí jì í, ó sì dín ìyà ẹ̀ṣẹ̀ òun àti ti Bátí-ṣébà kù. Pẹ̀lú ohun tí Òfin Mósè sọ, pípa ló yẹ kí wọ́n pa Dáfídì àti Bátí-ṣébà. (Diutarónómì 22:22) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò bọ́ lọ́wọ́ gbogbo nǹkan ìbànújẹ́ tí ẹ̀ṣẹ̀ wọn fà, Ọlọ́run dá ẹ̀mí wọn sí. (2 Sámúẹ́lì 12:13) Jíjẹ́ tí Ọlọ́run jẹ́ aláàánú máa ń mú kó dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini, síbẹ̀ kì í jẹ́ kí ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ láìjìyà tó tọ́ sí i.
10. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà máa ń lo ojú àánú tó bá ń ṣèdájọ́, kí nìdí tá ò fi gbọ́dọ̀ rò pé Ọlọ́run á kàn máa fàánú hàn sí wa ṣáá láìka ohun yòówù ká ṣe sí?
10 Níwọ̀n bí “ẹ̀ṣẹ̀ ti tipasẹ̀ ènìyàn kan [ìyẹn Ádámù] wọ ayé,” tó sì jẹ́ pé “owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san ni ikú,” gbogbo èèyàn pátá ni ikú tọ́ sí. (Róòmù 5:12; 6:23) A mà dúpẹ́ o pé Jèhófà ń ṣàánú wa tó bá ń ṣèdájọ́ wa! Ṣùgbọ́n ká ṣọ́ra ṣá o, ká má lọ rò pé Ọlọ́run á kàn máa fàánú hàn sí wa ṣáá láìka ohun yòówù ká ṣe sí. Ohun tí Diutarónómì 32:4 sọ ni pé: “Gbogbo ọ̀nà [Jèhófà] jẹ́ ìdájọ́ òdodo.” Ọlọ́run kì í tẹ ìlànà ìdájọ́ òdodo rẹ̀ pípé lójú tó bá ń lo ojú àánú.
11. Báwo ni Jèhófà ṣe rí i pé òun ṣe ohun tó bá ìdájọ́ òdodo mu lórí ẹ̀ṣẹ̀ Dáfídì pẹ̀lú Bátí-ṣébà?
11 Kí ìjìyà míì tó lè rọ́pò ìdájọ́ ikú tó wà lórí Dáfídì àti Bátí-ṣébà, àfi kí wọ́n rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà. Àmọ́ Jèhófà ò gbé ojúṣe yẹn lé àwọn onídàájọ́ Ísírẹ́lì lọ́wọ́. Ká ní Jèhófà jẹ́ kí wọ́n dá ẹjọ́ yẹn ni, ó di dandan kí wọ́n dájọ́ ikú fún wọn. Ohun tí Òfin Mósè ní kí wọ́n ṣe fẹ́ni tó bá dá irú ẹ̀ṣẹ̀ yẹn nìyẹn. Ṣùgbọ́n nítorí májẹ̀mú tí Jèhófà ti bá Dáfídì dá, ó fẹ́ wò ó bóyá ìdí kankan tiẹ̀ lè wà tí Dáfídì á fi rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà. (2 Sámúẹ́lì 7:12-16) Ìdí nìyẹn tí Jèhófà Ọlọ́run, “Onídàájọ́ gbogbo ilẹ̀ ayé” tó jẹ́ “olùṣàyẹ̀wò ọkàn-àyà” fi fúnra rẹ̀ dá ẹjọ́ yẹn. (Jẹ́nẹ́sísì 18:25; 1 Kíróníkà 29:17) Ọlọ́run arínúróde lè wo ohun tó wà lọ́kàn Dáfídì látòkèdélẹ̀, kó rí bí ìrònúpìwàdà rẹ̀ ṣe jinlẹ̀ tó, kó sì dárí jì í.
12 Báwo ni èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ ṣe lè jàǹfààní àánú Ọlọ́run?
12 Bí Jèhófà ṣe ṣàánú wa, tó mú kí á lè bọ́ lọ́wọ́ ikú tí ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún mú wá sórí wa bá ìdájọ́ òdodo rẹ̀ mu. Kí Jèhófà lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì wá láìjẹ́ pé ó tẹ ìlànà ìdájọ́ òdodo rẹ̀ lójú, ó fi Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀ ṣe ẹbọ ìràpadà fún wa, èyí tí í ṣe ọ̀nà tó ga jù lọ tẹ́nikẹ́ni tíì gbà ṣàánú rí. (Mátíù 20:28; Róòmù 6:22, 23) Ká tó lè jàǹfààní àánú Ọlọ́run yìí, èyí tó lè kó wa yọ lọ́wọ́ ìyà ẹ̀ṣẹ̀ àjogúnbá, a gbọ́dọ̀ “lo ìgbàgbọ́ nínú Ọmọ” Ọlọ́run.—Jòhánù 3:16, 36.
Ọlọ́run Àánú àti Ìdájọ́ Òdodo
13, 14. Ǹjẹ́ àánú Ọlọ́run máa ń pẹ̀rọ̀ sí ìdájọ́ òdodo rẹ̀? Ṣàlàyé.
13 A ti rí i pé tí Jèhófà bá ń ṣàánú ẹni, kì í tẹ ìlànà ìdájọ́ òdodo rẹ̀ lójú. Àmọ́ ṣé àánú rẹ̀ máa ń yí ìdájọ́ òdodo rẹ̀ padà lọ́nà kan ṣáá? Ṣé àánú rẹ̀ máa ń rọ ìdájọ́ òdodo rẹ̀ lójú bí ẹni pé ìdájọ́ rẹ̀ ti le koko jù? Rárá o.
14 Jèhófà gbẹnu wòlíì Hóséà sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Èmi yóò . . . fẹ́ ọ fún ara mi fún àkókò tí ó lọ kánrin, èmi yóò sì fẹ́ ọ fún ara mi ní òdodo àti ní ìdájọ́ òdodo àti ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti ní àánú.” (Hóséà 2:19) Ọ̀rọ̀ yìí fi hàn pé Jèhófà máa ń lo àánú rẹ̀ lọ́nà tó bá àwọn ànímọ́ rẹ̀ yòókù mu rẹ́gí, títí kan ìdájọ́ òdodo rẹ̀. “Ọlọ́run aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́” ni Jèhófà. “Ó ń dárí ìṣìnà àti ìrélànàkọjá àti ẹ̀ṣẹ̀ jì, ṣùgbọ́n lọ́nàkọnà, kì í dáni sí láìjẹni-níyà.” (Ẹ́kísódù 34:6, 7) Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run àánú àti ìdájọ́ òdodo. Bíbélì sọ nípa rẹ̀ pé: “Àpáta náà, pípé ni ìgbòkègbodò rẹ̀, nítorí gbogbo ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ìdájọ́ òdodo.” (Diutarónómì 32:4) Bí àánú Ọlọ́run ṣe jẹ́ pípé náà ni ìdájọ́ òdodo rẹ̀ ṣe pé. Ọ̀kan kò ta yọ ìkejì, bẹ́ẹ̀ ni kò sídìí tí ọ̀kan fi máa pẹ̀rọ̀ sí èkejì. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni ànímọ́ méjèèjì jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀ lọ́nà tó bára mu rẹ́gí.
15, 16. (a) Kí ló fi hàn pé ìdájọ́ Ọlọ́run ò le koko? (b) Kí ló dá àwọn olùjọsìn Jèhófà lójú pé yóò ṣẹlẹ̀ nígbà tí ìdájọ́ Jèhófà bá dé sórí ètò àwọn nǹkan búburú yìí?
15 Ìdájọ́ òdodo Jèhófà kì í le koko o. Ńṣe ni ìdájọ́ òdodo sábà máa ń gba pé ká tẹ̀ lé ohun tí òfin ti là sílẹ̀, tí wọ́n bá sì ti dá ẹnì kan lẹ́jọ́, ohun tó sábà máa ń gbà ni pé kí wọ́n fi jófin. Ṣùgbọ́n ní ti ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run, ó lè yọrí sí ìgbàlà fáwọn tí ìgbàlà tọ́ sí. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ìparun dé bá àwọn ẹni ibi tó wà ní ìlú Sódómù àti Gòmórà, Lọ́ọ̀tì àtàwọn ọmọbìnrin rẹ̀ rí ìgbàlà.—Jẹ́nẹ́sísì 19:12-26.
16 Ó dá àwa náà lójú pé nígbà tí ìdájọ́ Jèhófà bá máa dé sórí ètò àwọn nǹkan búburú yìí, Jèhófà yóò dáàbò bo àwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá” olùjọsìn tòótọ́, tí wọ́n “ti fọ aṣọ wọn, [tí] wọ́n sì ti sọ wọ́n di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.” Wọn yóò tipa bẹ́ẹ̀ “jáde wá láti inú ìpọ́njú ńlá náà.”—Ìṣípayá 7:9-14.
Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Jẹ́ Aláàánú?
17. Kí ni ìdí pàtàkì tó fi yẹ ká jẹ́ aláàánú?
17 Ẹ̀kọ́ ńlá ni àpẹẹrẹ Jèhófà àti Jésù Kristi kọ́ wa nípa béèyàn ṣe lè fi hàn pé òun jẹ́ olójú àánú lóòótọ́. Òwe 19:17 sọ ìdí pàtàkì tó fi yẹ ká jẹ́ aláàánú, ó ní: “Ẹni tí ń fi ojú rere hàn sí ẹni rírẹlẹ̀, Jèhófà ni ó ń wín, Òun yóò sì san ìlòsíni rẹ̀ padà fún un.” Inú Jèhófà máa ń dùn gan-an tí àpẹẹrẹ òun àti Ọmọ rẹ̀ bá mú kí àwa náà máa ṣàánú ọmọnìkejì wa. (1 Kọ́ríńtì 11:1) Ìyẹn sì lè mú káwọn tá a ṣàánú dẹni tó ń ṣàánú àwa náà, torí pé ńṣe ni ẹ̀mí àánú máa ń ranni.—Lúùkù 6:38.
18. Kí nìdí tó fi yẹ ká gbìyànjú láti jẹ́ olójú àánú?
18 Àmọ́ kẹ́nì kan tó lè jẹ́ aláàánú, ó gbọ́dọ̀ ní àwọn ànímọ́ rere míì. Yóò jẹ́ olóore ọ̀fẹ́ àti onínúure, yóò sì ní ìfẹ́. Ẹ̀mí ìyọ́nú àti ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò ló ń múni ṣàánú ọmọnìkejì ẹni. Lóòótọ́, ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ń ṣàánú kì í tẹ ìlànà ìdájọ́ òdodo rẹ̀ lójú, síbẹ̀ ó máa ń lọ́ra láti bínú, ó sì ń mú sùúrù kí ẹlẹ́ṣẹ̀ lè ronú pìwà dà. (2 Pétérù 3:9, 10) Èyí fi hàn pé èèyàn ní láti ní sùúrù àti ìpamọ́ra kó tó lè jẹ́ aláàánú. Níwọ̀n bó sì ti jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ànímọ́ rere, títí kan àwọn tó para pọ̀ di èso ti ẹ̀mí, ló máa ń mú kéèyàn ṣàánú, ẹni tó bá ń ṣàánú á dẹni tó ní àwọn ànímọ́ rere wọ̀nyí. (Gálátíà 5:22, 23) Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì gan-an pé kéèyàn gbìyànjú láti jẹ́ olójú àánú!
“Aláyọ̀ Ni Àwọn Aláàánú”
19, 20. Ọ̀nà wo ni àánú gbà ń yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun lórí ìdájọ́?
19 Jákọ́bù ọmọ ẹ̀yìn Jésù sọ ìdí tó fi yẹ ká jẹ́ aláàánú. Ó ní: “Àánú a máa yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun lórí ìdájọ́.” (Jákọ́bù 2:13b) Àánú tí olùjọsìn Jèhófà máa ń ṣe fún ọmọnìkejì rẹ̀ ni Jákọ́bù ń sọ níbí o. Àánú yìí máa ń yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun lórí ìdájọ́ ní ti pé tó bá dìgbà téèyàn bá máa “ṣe ìjíhìn ara rẹ̀ fún Ọlọ́run,” Jèhófà yóò wo àánú tónítọ̀hún ti ń ṣe mọ́ ọn lára, yóò sì dárí jì í lọ́lá ẹbọ ìràpadà Jésù Ọmọ rẹ̀. (Róòmù 14:12) Ó dájú pé ara ìdí tí Ọlọ́run fi ṣàánú Dáfídì nígbà tó dẹ́ṣẹ̀ pẹ̀lú Bátí-ṣébà ni jíjẹ́ tóun alára jẹ́ aláàánú èèyàn. (1 Sámúẹ́lì 24:4-7) Àmọ́ ní tàwọn aláìláàánú, Bíbélì ní: “Ẹni tí kò bá sọ àánú ṣíṣe dàṣà yóò gba ìdájọ́ rẹ̀ láìsí àánú.” (Jákọ́bù 2:13a) Abájọ tí Bíbélì fi ka àwọn “aláìláàánú” mọ́ àwọn tí Ọlọ́run kà sí ẹni tó “yẹ fún ikú!”—Róòmù 1:31, 32.
20 Nínú Ìwàásù Lórí Òkè tí Jésù ṣe, ó ní: “Aláyọ̀ ni àwọn aláàánú, níwọ̀n bí a ó ti fi àánú hàn sí wọn.” (Mátíù 5:7) Èyí fi hàn kedere pé béèyàn bá ń fẹ́ kí Ọlọ́run ṣàánú òun, ńṣe ni kóun náà rí i dájú pé òun jẹ́ olójú àánú! Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí yóò sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè jẹ́ ẹni tó ń ṣàánú ọmọnìkejì wa.
Ẹ̀kọ́ Wo Lo Kọ́?
• Kí ni àánú?
• Àwọn ọ̀nà wo lèèyàn lè gbà máa ṣàánú ẹni?
• Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà jẹ́ Ọlọ́run àánú àti ìdájọ́ òdodo?
• Kí nìdí tó fi yẹ ká jẹ́ olójú àánú?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Ńṣe ni Jèhófà máa ń yọ́nú sáwọn tó wà nínú ìṣòro bí abiyamọ ṣe ń yọ́nú sí ọmọ rẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ẹ̀kọ́ wo làwọn iṣẹ́ ìyanu Jésù kọ́ wa nípa àánú ṣíṣe?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Ǹjẹ́ Jèhófà tẹ ìlànà ìdájọ́ òdodo rẹ̀ lójú bó ṣe ṣàánú Dáfídì?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ń ṣàánú àwa èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ bá ìdájọ́ òdodo rẹ̀ mu rẹ́gí