Máa Fi Ahọ́n Rẹ Sọ̀rọ̀ Tó Ń Gbéni Ró
“Kí àwọn àsọjáde ẹnu mi . . . dùn mọ́ ọ, ìwọ Jèhófà.”—SM. 19:14.
1, 2. Kí nìdí tá a fi lè fi agbára tó wà nínú ahọ́n wé iná?
NÍ ÌBẸ̀RẸ̀ oṣù October, ọdún 1871, iná ńlá kan jó igbó tó wà ní ìpínlẹ̀ Wisconsin ní apá àríwá ìlà òòrùn orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà run. Iná yìí ló ṣì pa àwọn èèyàn jù nínú ìtàn orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Bí iná yìí ṣe ń jó lala, ó run igi tó tó bílíọ̀nù méjì, èéfín àti ooru tó ń wá láti inú iná náà sì pa àwọn èèyàn tó ju ẹgbẹ̀rún kan ó lé igba [1,200] lọ. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó o, ó lè jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ́ná kékeré kan tó jábọ́ láti inú ọkọ̀ ojú irin ló dá iná náà sílẹ̀. Ẹ ò rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwé Jákọ́bù 3:5 tó ní: “Wò ó! Bí iná tí a fi ń dáná ran igbó igi tí ó tóbi gan-an ti kéré tó!” Kí nìdí tí òǹkọ̀wé Bíbélì yìí fi sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀?
2 Ohun tí ọmọ ẹ̀yìn náà Jákọ́bù sọ wá ṣe kedere ní ẹsẹ kẹfà. Ó ní: “Tóò, ahọ́n jẹ́ iná.” Ahọ́n ló ń jẹ́ ká lè sọ̀rọ̀. Bí iná ṣe lè jó nǹkan run kó sì ba nǹkan jẹ́, bẹ́ẹ̀ náà ni ahọ́n wa lè dá wàhálà ńlá sílẹ̀. Kódà, Bíbélì sọ pé “ikú àti ìyè ń bẹ ní agbára ahọ́n.” (Òwe 18:21) Lóòótọ́, a ò ṣáà ní torí pé a ò fẹ́ múnú bí àwọn ẹlòmíì, ká wá pa ẹnu mọ́, bó ṣe jẹ́ pé a ò lè sọ pé a ò ní lo iná mọ́ torí pé ó lè jó nǹkan run. Kókó ibẹ̀ ni pé ká ṣọ́ ohun tá a máa sọ. Bákan náà, a lè lo iná lọ́nà tó yẹ. Bí àpẹẹrẹ, a lè fi iná se oúnjẹ, a lè tanná sínú yàrá tó ṣókùnkùn, a sì lè yáná nígbà òtútù. Lọ́nà kan náà, tá a bá ń kó ahọ́n wa níjàánu, a lè fi yin Ọlọ́run lógo ká sì sọ̀rọ̀ tó máa ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́.—Sm. 19:14.
3. Àwọn nǹkan mẹ́ta wo la máa jíròrò nípa ọ̀rọ̀ ẹnu wa?
3 Yálà ẹnu la fi ń sọ̀rọ̀ tàbí ọwọ́ la fi ń sọ̀rọ̀, bá a ṣe lè sọ èrò wa àti bí nǹkan ṣe rí lára wa jẹ́ ẹ̀bùn àgbàyanu láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Báwo la ṣe lè fi ẹ̀bùn yìí gbé àwọn ẹlòmíì ró ká má sì kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wọn? (Ka Jákọ́bù 3:9, 10.) A máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun mẹ́ta kan nípa ọ̀rọ̀ ẹnu wa, ìyẹn ìgbà tó yẹ ká sọ̀rọ̀, ohun tó yẹ ká sọ àti bó ṣe yẹ ká sọ ọ́.
ÌGBÀ TÓ YẸ KÁ SỌ̀RỌ̀
4. Sọ àwọn àpẹẹrẹ ‘ìgbà tó yẹ ká dákẹ́ jẹ́ẹ́.’
4 Ojoojúmọ́ la máa ń sọ̀rọ̀, àmọ́ kò pọn dandan ká máa sọ̀rọ̀ ní gbogbo ìgbà. Kódà, Bíbélì sọ pé “ìgbà dídákẹ́ jẹ́ẹ́” wà. (Oníw. 3:7) Tá a bá dákẹ́ nígbà táwọn ẹlòmíì bá ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, ńṣe nìyẹn máa fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún wọn. (Jóòbù 6:24) Bákan náà, tá a bá ń pa ọ̀rọ̀ àṣírí tá a mọ̀ nípa rẹ̀ mọ́, ìyẹn á tún fi hàn pé a jẹ́ ọlọgbọ́n àti olóye. (Òwe 20:19) Tí ẹnì kan bá sì mú inú bí wa, ìwà ọgbọ́n ló máa jẹ́ tá a bá dákẹ́ jẹ́ẹ́ láì sọ ohunkóhun.—Sm. 4:4.
5. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọrírì ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ tí Ọlọ́run fún wa?
5 Bákan náà, Bíbélì tún sọ pé “ìgbà sísọ̀rọ̀” wà. (Oníw. 3:7) Ó dájú pé tí ọ̀rẹ́ rẹ bá fún ọ lẹ́bùn tó o fẹ́ràn gan-an, o ò kàn ní lọ wá ibì kan jù ú sí, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe lo máa lo ẹ̀bùn náà dáadáa kí ọ̀rẹ́ rẹ lè mọ̀ pé o mọrírì rẹ̀. Ó yẹ ká mọrírì ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ tí Jèhófà fún wa, ká máa lò ó lọ́nà tó dáa. Oríṣiríṣi ọ̀nà la sì lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀, bí àpẹẹrẹ, a lè yin Ọlọ́run lógo, a lè gbé àwọn ẹlòmíì ró, a lè sọ bí nǹkan ṣe rí lára wa ká sì sọ àwọn nǹkan tá a nílò fún àwọn ẹlòmíì. (Sm. 51:15) Àmọ́, báwo la ṣe lè mọ “ìgbà” tó dáa jù láti sọ̀rọ̀?
6. Kí ni Bíbélì sọ nípa bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká mọ ìgbà tó tọ́ láti sọ̀rọ̀?
6 Ìwé Òwe 25:11 sọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká mọ ìgbà tó tọ́ láti sọ̀rọ̀. Ó ní: “Bí àwọn èso ápù ti wúrà nínú àwọn ohun gbígbẹ́ tí a fi fàdákà ṣe ni ọ̀rọ̀ tí a sọ ní àkókò tí ó tọ́.” Ápù aláwọ̀ wúrà máa lẹ́wà gan-an lóòótọ́. Tá a bá tún wá gbé e sínú abọ́ fàdákà, ńṣe nìyẹn tún máa bu ẹwà kún un. Bákan náà, tá a bá fòye mọ ìgbà tó tọ́ láti sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ wa á tu àwọn èèyàn lára á sì wọ̀ wọ́n lọ́kàn. Àmọ́, báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?
7, 8. Báwo làwọn ará wa lórílẹ̀-èdè Japan ṣe tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù?
7 Ó lè jẹ́ pé ọ̀rọ̀ tá a sọ fẹ́nì kan ló máa ràn án lọ́wọ́, àmọ́ tá ò bá fòye mọ àkókò tó dáa jù láti sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ wa ò ní wọ̀ ọ́ lọ́kàn. (Ka Òwe 15:23.) Bí àpẹẹrẹ, lóṣù March ọdún 2011, ìsẹ̀lẹ̀ tó lágbára kan mú kí omi òkun ya wọ inú àwọn ìlú tó wà ní ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè Japan, ó sì run ọ̀pọ̀ ìlú tó wà níbẹ̀. Àwọn tó ju ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15,000] lọ ló pàdánù ẹ̀mí wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àjálù yìí ò yọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà níbẹ̀ sílẹ̀, wọ́n lo gbogbo àǹfààní tí wọ́n ní láti sọ̀rọ̀ ìtùnú tó wà nínú Bíbélì fún àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀. Ẹlẹ́sìn Búdà ni ọ̀pọ̀ àwọn tó wà níbẹ̀, wọn ò sì mọ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni. Àwọn ará wa fòye mọ̀ pé kò ní dáa kó jẹ́ pé ẹsẹ̀kẹsẹ̀ lẹ́yìn àjálù náà làwọn á máa wàásù ìrètí àjíǹde fáwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ náà. Ńṣe ni wọ́n lo ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ tí wọ́n ní láti tu àwọn èèyàn nínú, wọ́n sì lo Bíbélì láti fi ṣàlàyé ìdí tí irú àwọn nǹkan burúkú bẹ́ẹ̀ fi ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn aláìmọwọ́mẹsẹ̀.
8 Jésù mọ ìgbà tó yẹ kí òun sọ̀rọ̀ àtìgbà tí kò yẹ. (Jòh. 18:33-37; 19:8-11) Nígbà kan, ó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Mo ṣì ní ohun púpọ̀ láti sọ fún yín, ṣùgbọ́n ẹ kò lè gbà wọ́n mọ́ra nísinsìnyí.” (Jòh. 16:12) Àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà lórílẹ̀-èdè Japan tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. Lẹ́yìn ọdún méjì àtàbọ̀ tí àjálù náà ṣẹlẹ̀, wọ́n kópa nínú pípín Ìròyìn Ìjọba Ọlọ́run No. 38 táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà pín kárí ayé, àkòrí ìwé àṣàrò kúkúrú náà ni “Ǹjẹ́ Àwọn Òkú Lè Jíǹde?” Ara àwọn èèyàn ti wá silé láti gbọ́ ọ̀rọ̀ ìtùnú nípa àjíǹde báyìí, ọ̀pọ̀ lára wọn ló sì gba ẹ̀dà ìwé àṣàrò kúkúrú náà. Lóòótọ́, àṣà ìbílẹ̀ àti ẹ̀sìn àwọn èèyàn yàtọ̀ síra, torí náà a gbọ́dọ̀ fòye mọ ìgbà tó tọ́ láti sọ̀rọ̀.
9. Àwọn ìgbà míì wo ló tún yẹ ká sọ̀rọ̀ lásìkò tó tọ́?
9 Ó dájú pé àwọn ìgbà kan wà tó yẹ ká fòye mọ àkókò tó tọ́ láti sọ̀rọ̀. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀rọ̀ tẹ́nì kan sọ lè dùn wá bó tilẹ̀ jẹ́ pé ire wa ló ní lọ́kàn. Ó máa dáa tá a bá lè fara balẹ̀ ronú lórí ọ̀rọ̀ náà bóyá ó tiẹ̀ tó nǹkan tá a máa fèsì sí. Tó bá wá pọn dandan pé ká sọ̀rọ̀, kò ní bọ́gbọ́n mu kó jẹ́ ìgbà tí inú ń bí wa la máa dá ẹni náà lóhùn torí a lè fìbínú sọ̀rọ̀ sí i. (Ka Òwe 15:28.) Bákan náà, ó yẹ ká máa lo òye tá a bá ń bá àwọn ẹbí wa tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí sọ̀rọ̀ nípa òtítọ́ inú Bíbélì. Òótọ́ ni pé a fẹ́ kí wọ́n wá mọ Jèhófà, àmọ́ àfi ká mú sùúrù ká sì fọgbọ́n ṣe é. Tá a bá ń sọ̀rọ̀ tó yẹ lásìkò tó tọ́, ìyẹn lè jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa wọ̀ wọ́n lọ́kàn.
OHUN TÓ YẸ KÁ SỌ
10. (a) Kí nìdí tó fi yẹ ká máa fara balẹ̀ ro ọ̀rọ̀ tá a fẹ́ sọ wò ká tó sọ ọ́? (b) Sọ àpẹẹrẹ àwọn ọ̀rọ̀ tí kò yẹ ká máa sọ.
10 Ọ̀rọ̀ wa lè gbéni ró tàbí kó fa ìrẹ̀wẹ̀sì. (Ka Òwe 12:18.) Àwọn èèyàn máa ń fi ọ̀rọ̀ gún ara wọn lára nínú ayé Sátánì yìí. Àwọn olórin àtàwọn òṣèré ń kọ́ àwọn èèyàn láti máa “pọ́n ahọ́n wọn bí idà” kí wọ́n sì máa “sọ̀kò ọ̀rọ̀ burúkú bí ẹni ta ọfà.” (Sm. 64:3, Bibeli Ìròyìn Ayọ̀) Kò yẹ kí àwa Kristẹni máa bá wọn dá irú àṣà burúkú yìí. Àpẹẹrẹ irú àwọn “ọ̀rọ̀ burúkú” bẹ́ẹ̀ ni kéèyàn máa dọ́gbọ́n fọ̀rọ̀ kanni lábùkù tàbí kéèyàn máa fèèyàn ṣe yẹ̀yẹ́. Ńṣe làwọn èèyàn máa ń fi irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ pa àwọn èèyàn lẹ́rìn-ín, àmọ́ irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ máa ń yọrí sí àbùkù tàbí àrífín. Irú àwọn ẹ̀fẹ̀ yìí wà lára àwọn ọ̀rọ̀ èébú tó yẹ káwa Kristẹni ‘mú kúrò lọ́dọ̀’ wa. Lóòótọ́, àwàdà máa ń mú kọ́rọ̀ wa dùn, àmọ́ kò yẹ ká máa sọ̀rọ̀ tó máa bí àwọn ẹlòmíì nínú tàbí ọ̀rọ̀ tó máa dójú tì wọ́n. Bíbélì kìlọ̀ fún wa pé: “Kí àsọjáde jíjẹrà má ti ẹnu yín jáde, bí kò ṣe àsọjáde yòówù tí ó dára fún gbígbéniró bí àìní bá ṣe wà, kí ó lè fi ohun tí ó ṣeni lóore fún àwọn olùgbọ́”—Éfé. 4:29, 31.
11. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ronú jinlẹ̀ ká tó sọ̀rọ̀?
11 Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé “lára ọ̀pọ̀ yanturu tí ń bẹ nínú ọkàn-àyà ni ẹnu ń sọ.” (Mát. 12:34) Torí náà, ó yẹ kéèyàn ronú jinlẹ̀ dáadáa kó tó sọ̀rọ̀. Ọ̀rọ̀ tá a bá sọ ló máa fi irú ojú tá a fi ń wo àwọn ẹlòmíì hàn. Tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn látọkànwá, tá a sì ń gba tiwọn rò, ọ̀rọ̀ tó dáa làá máa sọ sí wọn, ọ̀rọ̀ wa á sì máa gbé wọn ró.
12. Kí ló tún lè ràn wá lọ́wọ́ láti mọ ọ̀rọ̀ tó yẹ ká sọ?
12 Ó yẹ ká máa ronú jinlẹ̀ ká tó sọ̀rọ̀. Kódà, Sólómọ́nì ọlọgbọ́n Ọba pàápàá “fẹ̀sọ̀ ronú, ó sì ṣe àyẹ̀wò fínnífínní,” kí ó lè rí àwọn ọ̀rọ̀ tó ń tuni lára tàbí “àwọn ọ̀rọ̀ dídùn àti àkọsílẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ títọ̀nà tí ó jẹ́ òtítọ́.” (Oníw. 12:9, 10) Ṣé ó máa ń ṣòro fún ẹ láti rí àwọn ọ̀rọ̀ tó ń tuni lára tó o máa sọ? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé o ṣì ní láti kọ́ bí wọ́n ṣe ń lo ọ̀rọ̀ lédè rẹ. Ọ̀kan lára ọ̀nà tó o lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kó o máa kọ́ bí wọ́n ṣe lo ọ̀rọ̀ nínú Bíbélì àti nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa. Tó o bá rí ọ̀rọ̀ kan tó ò mọ̀ tẹ́ lẹ̀, gbìyànjú láti mọ ìtumọ̀ rẹ̀. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, kọ́ bó o ṣe lè máa sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó máa ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́. Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa àjọṣe tó wà láàárín Jèhófà àti àkọ́bí Ọmọ rẹ̀, ó sọ pé: ‘Jèhófà ti fún mi [Jésù] ní ahọ́n àwọn tí a kọ́, kí n lè mọ bí a ti ń fi ọ̀rọ̀ dá ẹni tí ó ti rẹ̀ lóhùn.’ (Aísá. 50:4) Tá a bá ń fẹ̀sọ̀ ronú lórí ohun tá a fẹ́ sọ, àá lè máa sọ ọ̀rọ̀ tó tọ́, tó sì yẹ. (Ják. 1:19) A lè bi ara wa pé, ‘Ṣé ọ̀rọ̀ tí mo fẹ́ sọ yìí máa yé ẹni tí mo fẹ́ sọ ọ́ fún? Báwo ni ọ̀rọ̀ tí mo fẹ́ sọ yìí ṣe máa rí lára ẹ̀?’
13. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká sọ̀rọ̀ lọ́nà táwọn èèyàn á fi lóye ohun tá à ń sọ?
13 Ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì, wọ́n máa ń fun kàkàkí láti pe àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jọ tàbí tú wọn ká. Wọ́n sì tún máa ń fun ún kí àwọn ọmọ ogun lè gbára dì fún ogun. Ó bá a mu wẹ́kú nígbà náà pé Bíbélì fi kàkàkí ṣàpèjúwe ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kéèyàn sọ̀rọ̀ lọ́nà tó máa tètè yéni. Bí ìrò kàkàkí kan ò bá dún ketekete, ó lè ṣi àwọn ọmọ ogun lọ́nà. Lọ́nà kan náà, tí ọ̀rọ̀ wa ò bá ṣe kedere tàbí tó bá lọ́jú pọ̀, àwọn èèyàn ò ní lóye ohun tá à ń sọ, a sì lè ṣì wọ́n lọ́nà. Àmọ́, kò yẹ ká torí pé a fẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa ṣe kedere ká wá máa sọ̀rọ̀ tó máa bí wọn nínú tàbí tó máa rín wọn fín.—Ka 1 Kọ́ríńtì 14:8, 9.
14. Sọ àpẹẹrẹ kan nípa bí Jésù ṣe máa ń sọ̀rọ̀ lọ́nà tó máa tètè yéni.
14 Jésù fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ tó bá dọ̀ràn ká sọ̀rọ̀ tó tọ́. Ronú nípa àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ nínú ìwé Mátíù orí karùn-ún sí ìkeje. Jésù ò lo àwọn ọ̀rọ̀ kàǹkà-kàǹkà tàbí àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣòroó lóye. Kò fọ̀rọ̀ gún àwọn èèyàn lára, kò sì sọ̀rọ̀ tó máa tàbùkù sí wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sọ̀rọ̀ tó ṣe kedere tó sì máa tètè yé àwọn olùgbọ́ rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó ń sọ ìdí tí kò fi yẹ kí wọ́n máa ṣàníyàn nípa àtijẹ àtimu, ó ṣàlàyé bí Jèhófà ṣe ń bọ́ àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run. Ó wá bi wọ́n pé: “Ẹ kò ha níye lórí jù wọ́n lọ bí?” (Mát. 6:26) Ó dájú pé àwọn ọ̀rọ̀ tó rọrùn lóye tí Jésù lò yìí máa mú kí ẹ̀kọ́ pàtàkì tí Jésù kọ́ wọn tètè yé wọn, á sì wọ̀ wọ́n lọ́kàn. Ẹ jẹ́ ká jíròrò ohun kẹta tó ṣe pàtàkì nípa ọ̀rọ̀ ẹnu wa, ìyẹn bó ṣe yẹ ká sọ̀rọ̀.
BÓ ṢE YẸ KÁ SỌ̀RỌ̀
15. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa fi ohùn pẹ̀lẹ́ sọ̀rọ̀?
15 Ohun tá a sọ àti bá a ṣe sọ ọ́ ṣe pàtàkì. Nígbà tí Jésù sọ̀rọ̀ nínú sínágọ́gù nípa ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀, ìyẹn Násárétì, ẹnu yà àwọn èèyàn náà “nítorí àwọn ọ̀rọ̀ alárinrin tí ń jáde láti ẹnu rẹ̀.” (Lúùkù 4:22) Tá a bá ń fi ohùn pẹ̀lẹ́ bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀, wọ́n á tẹ́tí sí wa, ọ̀rọ̀ wa á sì wọ̀ wọ́n lọ́kàn. (Òwe 25:15) Tá a bá ń bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn, tá a sì ń gba tiwọn rò, á rọrùn fún wa láti bá wọn sọ̀rọ̀ lọ́nà pẹ̀lẹ́. Ohun tí Jésù ṣe nìyẹn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó rí làálàá táwọn ogunlọ́gọ̀ kan ṣe torí kí wọ́n lè gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, àánú wọn ṣe é, ó sì “bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn ní ohun púpọ̀.” (Máàkù 6:34) Kódà, nígbà táwọn kan bú Jésù, kò bú wọn pa dà.—1 Pét. 2:23.
16, 17. (a) Tá a bá ń bá àwọn tó wà nínú ìdílé wa tàbí àwọn ọ̀rẹ́ wa tímọ́tímọ́ tó wà nínú ìjọ sọ̀rọ̀, báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.) (b) Àǹfààní wo ló wà nínú kéèyàn máa fi ohùn pẹ̀lẹ́ sọ̀rọ̀?
16 Ó lè ṣòro fún wa láti lo òye ká sì fi ohùn pẹ̀lẹ́ sọ̀rọ̀ pàápàá tó bá jẹ́ pé ẹni tó sún mọ́ wa dáadáa là ń bá sọ̀rọ̀. A lè máa rò ó pé a lè bá àwọn mẹ́ńbà ìdílé wa tàbí ọ̀rẹ́ wa nínú ìjọ sọ̀rọ̀ bó ṣe wù wá. Àmọ́, ṣé Jésù sọ̀rọ̀ sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bó ṣe wù ú torí wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́? Rárá o! Nígbà táwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ń jiyàn nípa ẹni tó lọ́lá jù láàárín wọn, Jésù fi ohùn pẹ̀lẹ́ bá wọn sọ̀rọ̀, ó sì fi ọmọ kékeré kan ṣàpèjúwe fún wọn. (Máàkù 9:33-37) Àwọn alàgbà náà lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, kí wọ́n máa gbani nímọ̀ràn pẹ̀lú “ẹ̀mí ìwà tútù.”—Gál. 6:1.
17 Tá a bá fi ohùn pẹ̀lẹ́ sọ̀rọ̀ kódà tí ẹnì kan bá sọ ohun tó múnú bí wa, àlááfíà á wà láàárín wa. (Òwe 15:1) Bí àpẹẹrẹ, ọmọ arábìnrin anìkàntọ́mọ kan ń kẹ́gbẹ́kẹ́gbẹ́. Arábìnrin kan sọ fún ìyá ọmọ náà pé: “Ẹ ò kọ́ ọmọ yín yìí rárá.” Ìyá ọmọ náà ronú fún bí ìṣẹ́jú mélòó kan, ó wá sọ pé: “Òótọ́ ni pé nǹkan ò lọ bó ṣe yẹ nísinsìnyí, àmọ́ ó ṣì máa yí pa dà. Lẹ́yìn ogun Amágẹ́dọ́nì, a máa mọ̀ bóyá mọ kọ àbí mi ò kọ́ ọ.” Bí ìyá ọmọ yìí ṣe fohùn pẹ̀lẹ́ bá arábìnrin yìí sọ̀rọ̀ pa àlááfíà tó wà láàárín wọn mọ́. Ìjíròrò yìí ta sọ́mọ yẹn létí, ó sì wú u lórí láti mọ̀ pé ìyá òun ò tíì sọ̀rètí nù lórí òun. Ohun tó gbọ́ yìí ló mú kó yé kẹ́gbẹ́ burúkú mọ́. Nígbà tó yá, ó ṣèrìbọmi ó sì lọ sìn ní Bẹ́tẹ́lì. Yálà a wà láàárín àwọn ará, ẹbí tàbí àwọn àjèjì, ó yẹ kí ọ̀rọ̀ ẹnu wa máa fìgbà gbogbo jẹ́ “pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́, tí a fi iyọ̀ dùn.”—Kól. 4:6.
18. Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù nínú bá a ṣe ń sọ̀rọ̀?
18 Ẹ̀bùn àgbàyanu la ní bá a ṣe lè sọ èrò àti bí nǹkan ṣe rí lára wa. Ẹ jẹ́ ká máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, ká máa sọ̀rọ̀ nígbà tó tọ́, ká sọ ohun tó yẹ, ká sì sapá láti máa sọ̀rọ̀ tó ń tuni lára. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ ẹnu wa á máa gbé àwọn èèyàn ró, á sì máa múnú Jèhófà dùn, Ẹni tó fún wa lẹ́bùn ọ̀rọ̀ sísọ.