Ẹ Máa Lépa Àlàáfíà
“Ẹ jẹ́ kí a máa lépa àwọn ohun tí ń yọrí sí àlàáfíà.”—RÓÒMÙ 14:19.
1, 2. Kí ló mú káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa wà ní àlàáfíà láàárín ara wọn?
OJÚLÓWÓ àlàáfíà ṣọ̀wọ́n nínú ayé lónìí. Kódà, àwọn èèyàn tó wá láti orílẹ̀-èdè kan náà tí wọ́n sì ń sọ èdè kan náà, kì í fohùn ṣọ̀kan lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn, ìṣèlú àti àwọn ohun tó ń lọ láwùjọ. Èyí yàtọ̀ pátápátá sí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn èèyàn Jèhófà. Wọ́n wà ní ìṣọ̀kan, bó tilẹ̀ jẹ́ pé látinú “gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n” ni wọ́n ti wá.—Ìṣí. 7:9.
2 Àlàáfíà tá a sábà máa ń gbádùn láàárín ara wa yìí kò ṣàdédé rí bẹ́ẹ̀. Ohun pàtàkì tó mú kó rí bẹ́ẹ̀ ni pé à ń “gbádùn àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run” nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ tá a ní nínú Ọmọ rẹ̀, ẹni tí ẹ̀jẹ̀ tó fi rúbọ bo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa mọ́lẹ̀. (Róòmù 5:1; Éfé. 1:7) Bákan náà, Ọlọ́run tòótọ́ máa ń fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ adúróṣinṣin ní ẹ̀mí mímọ́, àlàáfíà sì jẹ́ apá kan èso ẹ̀mí yẹn. (Gál. 5:22) Ìdí míì tí àlàáfíà fi gbilẹ̀ láàárín wa ni pé a “kì í ṣe apá kan ayé.” (Jòh. 15:19) Dípò ká máa pọ̀n sápá kan nínú ọ̀ràn ìṣèlú, a kì í dá sí tọ̀tún tòsì. A kì í lọ́wọ́ sí ogun abẹ́lé tàbí ogun láàárín àwọn orílẹ̀-èdè torí pé a ti ‘fi idà wa rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀.’—Aísá. 2:4.
3. Kí ni àlàáfíà tá à ń gbádùn mú kó ṣeé ṣe, kí la sì máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
3 Kì í wulẹ̀ ṣe torí pé a kì í ṣe ohunkóhun tó lè pa àwọn ará wa lára la fi lè sọ pé àlàáfíà jọba láàárín wa. Òótọ́ tó wà níbẹ̀ ni pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé ibi tí olúkúlùkù àwa tá a wà nínú ìjọ Kristẹni ti wá àti àṣà ìbílẹ̀ wa yàtọ̀ síra, a ‘nífẹ̀ẹ́ ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.’ (Jòh. 15:17) Bá a ṣe ń bára wa gbé lálàáfíà yìí ń mú kó ṣeé ṣe fún wa láti máa “ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn, ṣùgbọ́n ní pàtàkì sí àwọn tí ó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́.” (Gál. 6:10) Ó yẹ ká mọyì Párádísè tẹ̀mí wa tí àlàáfíà ti ń jọba yìí ká sì máa pa kún àlàáfíà tó wà níbẹ̀. Torí náà, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè máa wá àlàáfíà nínú ìjọ.
Tá A Bá Kọsẹ̀
4. Kí la lè ṣe láti wá àlàáfíà tá a bá ṣẹ ẹnì kan?
4 Ọmọ ẹ̀yìn náà, Jákọ́bù kọ̀wé pé: “Gbogbo wa ni a máa ń kọsẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà. Bí ẹnì kan kò bá kọsẹ̀ nínú ọ̀rọ̀, ẹni yìí jẹ́ ènìyàn pípé.” (Ják. 3:2) Èyí fi hàn pé èdèkòyédè àti àìgbọ́ra-ẹni-yé ò lè ṣe kó máà wáyé láàárín àwa àtàwọn ará wa. (Fílí. 4:2, 3) Bó bá sì rí bẹ́ẹ̀, ó yẹ káwọn tí ọ̀ràn kàn lè yanjú ìṣòro náà láì pa àlàáfíà ìjọ lára. Bí àpẹẹrẹ, ronú lórí ohun tí Ìwé Mímọ́ gbà wá nímọ̀ràn pé ká ṣe bá a bá rò pé a ti ṣẹ ẹnì kan.—Ka Mátíù 5:23, 24.
5. Báwo la ṣe lè wá àlàáfíà bí ẹnì kan bá ṣẹ̀ wá?
5 Kí ló yẹ ká ṣe bí ẹnì kan bá ṣẹ̀ wá? Ṣó yẹ ká retí pé kí onítọ̀hún wá tọrọ àforíjì lọ́wọ́ wa? Ìwé 1 Kọ́ríńtì 13:5 sọ pé: “[Ìfẹ́] kì í kọ àkọsílẹ̀ ìṣeniléṣe.” Bí ẹnì kan bá ṣẹ̀ wá, bá a ṣe lè wá àlàáfíà ni pé ká dárí ji onítọ̀hún ká sì gbàgbé nípa ẹ̀ṣẹ̀ náà, ìyẹn ni pé ‘ká má ṣe kọ àkọsílẹ̀ ìṣeniléṣe.’ (Ka Kólósè 3:13.) Ìlànà Ìwé Mímọ́ yìí ló yẹ ká tẹ̀ lé bí ẹnì kan bá ṣẹ̀ wá lẹ́ṣẹ̀ tí kò tó nǹkan. Lọ́nà yìí, a kò ní fàyè gba irú ẹ̀ṣẹ̀ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ tó máa ń wáyé lójoojúmọ́ bẹ́ẹ̀ láti ba àlàáfíà tá à ń gbádùn láàárín ara wa jẹ́, ó sì máa jẹ́ ká ní ìbàlẹ̀ ọkàn. Òwe ọlọgbọ́n kan sọ pé: ‘Ẹwà ni ó jẹ́ láti gbójú fo ìrélànàkọjá.’—Òwe 19:11.
6. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe bí kò bá rọrùn rárá láti gbójú fo ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹnì kan ṣẹ̀ wá?
6 Kí ló yẹ ká ṣe bí kò bá rọrùn rárá láti gbójú fo ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹnì kan ṣẹ̀ wá? Kì í ṣe ohun tó bọ́gbọ́n mu pé ká máa sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ náà káàkiri. Irú òfófó bẹ́ẹ̀ máa ń ba àlàáfíà ìjọ jẹ́ ni. Kí la lè ṣe láti yanjú ọ̀rọ̀ náà? Ìwé Mátíù 18:15 sọ pé: “Bí arákùnrin rẹ bá dá ẹ̀ṣẹ̀ kan, lọ fi àléébù rẹ̀ hàn án láàárín ìwọ àti òun nìkan. Bí ó bá fetí sí ọ, ìwọ ti jèrè arákùnrin rẹ.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì ni Mátíù 18:15-17 ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, a lè lo ìlànà tó wà nínú ẹsẹ 15, tó sọ pé ó dára ká tọ ẹni tó ṣẹ̀ wá lọ kí àwa àti òun nìkan sì jọ gbìyànjú láti yanjú ọ̀rọ̀ náà kí àárín wa lè pa dà gún.a
7. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa tètè yanjú aáwọ̀?
7 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ fi ìrunú hàn, síbẹ̀ kí ẹ má ṣẹ̀; ẹ má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá yín nínú ipò ìbínú, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe fi àyè sílẹ̀ fún Èṣù.” (Éfé. 4:26, 27) Jésù sọ pé: “Bẹ̀rẹ̀ sí yanjú àwọn ọ̀ràn ní kíákíá pẹ̀lú ẹni tí ń fi ọ́ sùn lábẹ́ òfin.” (Mát. 5:25) Èyí fi hàn pé tá a bá fẹ́ wá àlàáfíà àfi ká máa tètè yanjú aáwọ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé tí a kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, irú aáwọ̀ bẹ́ẹ̀ á máa fẹjú sí i bí egbò tí kòkòrò àrùn ti kó wọ̀ torí pé kò rí ìtọ́jú. Ká má ṣe jẹ́ kí ìgbéraga, owú tàbí kíka ohun ìní tara sí ju bó ṣe yẹ lọ, dí wa lọ́wọ́ láti yanjú aáwọ̀ gbàrà tó bá ti wáyé.—Ják. 4:1-6.
Bí Èdèkòyédè Bá Wáyé Láàárín Ẹni Púpọ̀
8, 9. (a) Èdèkòyédè wo ló wáyé ní ọ̀rúndún kìíní torí pé àwọn tó wà nínú ìjọ Róòmù fi ojú tó yàtọ̀ wo ọ̀ràn kan? (b) Ìmọ̀ràn wo ni Pọ́ọ̀lù fún àwọn Kristẹni tó wà ní Róòmù nípa bó ṣe yẹ kí wọ́n yanjú awuyewuye tó wà láàárín wọn?
8 Nígbà míì èdèkòyédè tó máa ń wáyé nínú ìjọ kì í mọ sáàárín ẹni méjì, àwọn tí ọ̀ràn kàn lè pọ̀ ju bẹ́ẹ̀ lọ. Irú ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn Kristẹni tó wà nínú ìjọ Róòmù nìyẹn tó mú kí Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti kọ lẹ́tà sí wọn. Awuyewuye wáyé láàárín àwọn Júù àtàwọn Kèfèrí tó di Kristẹni. Àwọn kan wà nínú ìjọ tí wọ́n ní ẹ̀rí ọkàn tó lágbára, èyí tó fàyè gbà wọ́n láti ṣe àwọn nǹkan kan. Ṣùgbọ́n wọ́n ń tẹ́ńbẹ́lú àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn kò lágbára tàbí tí kò fàyè gbà wọ́n láti ṣe irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀. Àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn lágbára wá ń ṣèdájọ́ àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn kò lágbára lórí àwọn ọ̀ràn tó ti yẹ kí kálukú pinnu ohun tó máa ṣe. Irú ìdájọ́ bẹ́ẹ̀ kò tọ́. Ìmọ̀ràn wo ni Pọ́ọ̀lù fún àwọn ará nínú ìjọ?—Róòmù 14:1-6.
9 Pọ́ọ̀lù bá àwọn tó ń bára wọn ṣe awuyewuye náà wí. Àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn lágbára mọ̀ pé àwọn Kristẹni kò sí lábẹ́ Òfin Mósè mọ́, torí náà, Pọ́ọ̀lù sọ fún wọn pé kí wọ́n má ṣe tẹ́ńbẹ́lú àwọn arákùnrin wọn. (Róòmù 14:2, 10) Irú ìwà bẹ́ẹ̀ lè fa ìkọ̀sẹ̀ fún àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́, àmọ́ tí wọ́n ṣì kórìíra láti máa jẹ ohun tí Òfin sọ pé wọn kò gbọ́dọ̀ jẹ. Pọ́ọ̀lù wá gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n “dẹ́kun yíya iṣẹ́ Ọlọ́run lulẹ̀ kìkì nítorí oúnjẹ. . . . Ó dára láti má ṣe jẹ ẹran tàbí [mu] wáìnì tàbí ṣe ohunkóhun tí yóò mú arákùnrin rẹ kọsẹ̀.” (Róòmù 14:14, 15, 20, 21) Lẹ́yìn náà, Pọ́ọ̀lù bá àwọn Kristẹni tí ẹ̀rí ọkàn wọn kò lágbára wí, ó ní kò yẹ kí wọ́n máa dá àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn lágbára lẹ́jọ́ pé wọn kò ṣe ohun tó bá Òfin mu. (Róòmù 14:13) Ó sọ fún ‘gbogbo ẹni tí ń bẹ láàárín wọn níbẹ̀ láti má ṣe ro ara wọn ju bí ó ti yẹ ní rírò lọ.’ (Róòmù 12:3) Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù ti bá àwọn tó ń bára wọn ṣe awuyewuye yìí wí tán, ó kọ̀wé pé: “Nítorí bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ kí a máa lépa àwọn ohun tí ń yọrí sí àlàáfíà àti àwọn ohun tí ń gbéni ró fún ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.”—Róòmù 14:19.
10. Bíi tàwọn ará Róòmù ọ̀rúndún kìíní, kí ló pọn dandan pé ká ṣe lónìí ká bàa lè yanjú aáwọ̀?
10 Ó dá wa lójú pé ìjọ tó wà ní Róòmù ṣiṣẹ́ lórí ìbáwí tí Pọ́ọ̀lù fún wọn, wọ́n sì ṣe àtúnṣe tó yẹ. Bí aáwọ̀ bá wáyé láàárín àwa àtàwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni lónìí, ǹjẹ́ kò yẹ kí àwa náà máa tètè yanjú irú àwọn aáwọ̀ bẹ́ẹ̀ nípa fífi ìrẹ̀lẹ̀ wá ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ lórí ọ̀ràn náà ká sì ṣiṣẹ́ lé e lórí? Bíi ti àwọn ará Róòmù, ó lè pọn dandan kí àwọn tí wọ́n bá ní aáwọ̀ láàárín ara wọn ṣe àtúnṣe tó bá yẹ kí wọ́n lè ‘pa àlàáfíà mọ́ láàárín ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì.’—Máàkù 9:50.
Báwo La Ṣe Lè Ran Àwọn Tó Níṣòro Lọ́wọ́?
11. Kí nìdí tí alàgbà kan fi ní láti ṣọ́ra bí Kristẹni kan bá fẹ́ bá a sọ̀rọ̀ nípa awuyewuye kan tó ní pẹ̀lú Kristẹni mìíràn?
11 Bí Kristẹni kan bá fẹ́ láti bá alàgbà kan sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro tó ní pẹ̀lú ìbátan tàbí Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ńkọ́? Ìwé Òwe 21:13 sọ pé: “Ní ti ẹnikẹ́ni tí ó bá di etí rẹ̀ sí igbe ìráhùn ẹni rírẹlẹ̀, òun alára yóò pè, a kì yóò sì dá a lóhùn.” Ó dájú pé alàgbà kan kò jẹ́ “di etí rẹ̀.” Àmọ́, òwe mìíràn kìlọ̀ fún wa pé: “Ẹnì kìíní nínú ẹjọ́ rẹ̀ jẹ́ olódodo; ọmọnìkejì rẹ̀ wọlé wá, dájúdájú, ó sì yẹ̀ ẹ́ wò látòkè délẹ̀.” (Òwe 18:17) Ó yẹ kí alàgbà tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa, àmọ́ ó gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kó má bàa gbè sẹ́yìn ẹni tó wá rojọ́ fún un. Lẹ́yìn tó bá ti gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀, ó ṣeé ṣe kó béèrè bóyá ẹni tó wá fẹjọ́ sùn ún ti sọ̀rọ̀ náà létí ẹni tó sọ pé ó ṣẹ òun. Alàgbà náà tún lè jíròrò àwọn ìgbésẹ̀ tó bá Ìwé Mímọ̀ mu tí ẹni tó mú ẹ̀sùn wá náà lè gbé kó bàa lè wá àlàáfíà.
12. Fúnni ní àwọn àpẹẹrẹ ewu tó wà nínú kéèyàn máa fi wàdùwàdù gbégbèésẹ̀ lẹ́yìn tó bá ti gbọ́ nípa ìṣòro tó wáyé.
12 Àwọn àpẹẹrẹ mẹ́ta kan wà nínú Bíbélì tó jẹ́ ká mọ ewu tó wà nínú kéèyàn máa fi wàdùwàdù gbégbèésẹ̀ lẹ́yìn tó bá ti gbọ́ ẹjọ́ apá kan. Pọ́tífárì gba ìyàwó rẹ̀ gbọ́ nígbà tó sọ fún un pé Jósẹ́fù fẹ́ fipá bá òun lò pọ̀. Lẹ́yìn náà, Pọ́tífárì fìbínú ju Jósẹ́fù sẹ́wọ̀n láìwádìí. (Jẹ́n. 39:19, 20) Dáfídì Ọba gba Síbà gbọ́ nígbà tó sọ fún un pé ọ̀gá òun, Mefibóṣẹ́tì, ti lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀tá Dáfídì. Dáfídì fi ìwàǹwára sọ fún un pé: “Wò ó! Ohun gbogbo tí í ṣe ti Mefibóṣẹ́tì jẹ́ tìrẹ.” (2 Sám. 16:4; 19:25-27) Wọ́n sọ fún Atasásítà Ọba pé àwọn Júù ti ń tún odi Jerúsálẹ́mù kọ́, wọ́n sì máa tó dìtẹ̀ sí Ilẹ̀ Ọba Páṣíà. Ọba gba irọ́ yìí gbọ́ ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n dá gbogbo ohun tí wọ́n ń tún kọ́ ní Jerúsálẹ́mù dúró. Látàrí èyí, àwọn Júù dáwọ́ iṣẹ́ àtúnkọ́ tẹ́ńpìlì Ọlọ́run dúró. (Ẹ́sírà 4:11-13, 23, 24) Ó bọ́gbọ́n mu nígbà náà pé káwọn alàgbà ìjọ máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fún Tímótì pé kí wọ́n má ṣe máa ṣèdájọ́ láìwádìí.—Ka 1 Tímótì 5:21.
13, 14. (a) Bí awuyewuye bá wáyé láàárín àwọn mìíràn, kí ló yẹ ká rántí? (b) Kí ló lè ran àwọn alàgbà lọ́wọ́ láti máa ṣèdájọ́ àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ lọ́nà tó tọ́?
13 Kódà, lẹ́yìn tá a bá ti gbọ́rọ̀ lẹ́nu àwọn méjèèjì tí awuyewuye ṣẹlẹ̀ láàárín wọn, ó ṣe pàtàkì ká rántí pé “bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun ti ní ìmọ̀ ohun kan, síbẹ̀ kò tíì mọ̀ ọ́n gan-an bí ó ti yẹ kí ó mọ̀ ọ́n.” (1 Kọ́r. 8:2) Ǹjẹ́ a mọ gbogbo ohun tó fà á tí awuyewuye náà fi wáyé? Ṣé a mọ àwọn tọ́ràn kàn náà dunjú? Bí àwọn alàgbà bá fẹ́ ṣèdájọ́, ó ṣe pàtàkì pé kí wọ́n má ṣe jẹ́ kí wọn fi irọ́, ọgbọ́n àyínìke tàbí àhesọ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ tan àwọn jẹ! Jésù Kristi, Onídàájọ́ tí Ọlọ́run yàn sípò, máa fi òdodo ṣèdájọ́. Kì í “ṣe ìdájọ́ nípasẹ̀ ohun èyíkéyìí tí ó hàn lásán sí ojú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fi ìbáwí tọ́ni sọ́nà ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí etí rẹ̀ wulẹ̀ gbọ́.” (Aísá. 11:3, 4) Ẹ̀mí Jèhófà ló ń darí Jésù. Bákan náà, àwọn alàgbà ìjọ ní àǹfààní láti jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run máa darí wọn.
14 Kí àwọn alàgbà tó ṣèdájọ́ àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́, wọ́n gbọ́dọ̀ gbàdúrà pé kí ẹ̀mí Jèhófà ran àwọn lọ́wọ́, wọ́n sì gbọ́dọ̀ fi hàn pé àwọn gbára lé ìtọ́sọ́nà rẹ̀ nípa ṣíṣàyẹ̀wò ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àtàwọn ìtẹ̀jáde ẹrú olóòótọ́ àti olóye sọ nípa ọ̀rọ̀ náà.—Mát. 24:45.
Ṣó Tọ́ Ká Wá Àlàáfíà Lọ́nàkọnà?
15. Bá a bá mọ̀ nípa ẹ̀ṣẹ̀ kan tó burú jáì, ìgbà wo ló yẹ ká sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?
15 A rọ àwa Kristẹni pé ká máa lépa àlàáfíà. Àmọ́, Bíbélì tún sọ pé: “Ọgbọ́n tí ó wá láti òkè a kọ́kọ́ mọ́ níwà, lẹ́yìn náà, ó lẹ́mìí àlàáfíà.” (Ják. 3:17) Jíjẹ́ ẹni tó mọ́ níwà, ìyẹn híhùwà mímọ́, tó ṣètẹ́wọ́gbà lójú Ọlọ́run àti gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà òdodo rẹ̀ ló ṣe pàtàkì ju wíwá àlàáfíà lọ. Bí Kristẹni kan bá mọ̀ pé arákùnrin tàbí arábìnrin kan ti hùwà tó burú jáì, ó gbọ́dọ̀ rọ onítọ̀hún pé kó lọ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ fáwọn alàgbà. (1 Kọ́r. 6:9, 10; Ják. 5:14-16) Bí oníwà àìtọ́ náà kò bá lọ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, Kristẹni tó mọ̀ nípa ẹ̀ṣẹ̀ náà gbọ́dọ̀ lọ sọ ohun tó rí fáwọn alàgbà. Bó bá kùnà láti lọ sọ fáwọn alàgbà nítorí àtipa àlàáfíà mọ́ pẹ̀lú ẹlẹ́ṣẹ̀ náà, a jẹ́ pé òun náà bá a nípìn-ín nínú ìwà àìtọ́ rẹ̀ nìyẹn.—Léf. 5:1; ka Òwe 29:24.
16. Kí la rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín Jéhù àti Jèhórámù Ọba?
16 Ìtàn tí Bíbélì sọ nípa Jéhù fi hàn pé òdodo Ọlọ́run ṣe pàtàkì ju wíwá àlàáfíà lọ. Ọlọ́run rán Jéhù láti lọ mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ sórí ilé Áhábù Ọba. Jèhórámù Ọba búburú, ọmọ Áhábù àti Jésíbẹ́lì, gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ láti lọ pàdé Jéhù. Ó sì sọ pé: “Ṣé àlàáfíà ni, Jéhù?” Èsì wo ni Jéhù fún un? Ó dá a lóhùn pé: “Àlàáfíà báwo, níwọ̀n ìgbà tí ìwà àgbèrè Jésíbẹ́lì ìyá rẹ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àjẹ́ rẹ̀ bá ń bẹ?” (2 Ọba 9:22) Bí Jéhù ṣe ta ọfà ọwọ́ rẹ̀ lu Jèhórámù nìyẹn, ọfà náà sì gún ọkàn-àyà rẹ̀ ní àgúnyọ. Bí Jéhù ò ṣe fàyè gba ohun tí kò tọ́, bẹ́ẹ̀ náà ní àwọn alàgbà kò ṣe gbọ́dọ̀ gbà kí ẹni tó mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́ṣẹ̀, àmọ́ tí kò ronú pìwà dà máa wà nìṣó nínú ìjọ nítorí àtipa àlàáfíà mọ́. Ńṣe ni wọ́n máa ń yọ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò bá ronú pìwà dà lẹ́gbẹ́ kí ìjọ lè máa bá a lọ láti wà lálàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run.—1 Kọ́r. 5:1, 2, 11-13.
17. Ọ̀nà wo ni gbogbo Kristẹni gbà ń pa kún lílépa àlàáfíà?
17 Èyí tó pọ̀ jù lọ nínú awuyewuye tó máa ń wáyé láàárín àwọn ará kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì, tó yẹ kí ìgbìmọ̀ onídàájọ́ bójú tó. Torí náà, ẹ wo bó ti dára tó ká jẹ́ kí ìfẹ́ máa mú ká bo àṣìṣe àwọn ẹlòmíì mọ́lẹ̀. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Ẹni tí ń bo ìrélànàkọjá mọ́lẹ̀ ń wá ìfẹ́, ẹni tí ó sì ń sọ̀rọ̀ ṣáá nípa ọ̀ràn, ń ya àwọn tí ó mọ ara wọn dunjú nípa.” (Òwe 17:9) Bí gbogbo wa bá ń ṣe ohun tí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ, ó máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè pa àlàáfíà tó wà nínú ìjọ mọ́ ká sì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà.—Mát. 6:14, 15.
A Máa Rí Ìbùkún Gbà Tá A Bá Ń Lépa Àlàáfíà
18, 19. Ìbùkún wo ló máa ń tìdí lílépa àlàáfíà wá?
18 Lílépa “àwọn ohun tí ń yọrí sí àlàáfíà” máa ń mú ọ̀pọ̀ ìbùkún wá. A máa ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà bá a ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀, a ó sì máa pa kún àlàáfíà tó ń mú ká wà ní ìṣọ̀kan nínú Párádísè tẹ̀mí wa. Bí àwa tá a wà nínú ìjọ bá ń lépa àlàáfíà, ìyẹn á ràn wá lọ́wọ́ láti mọ àwọn ọ̀nà tá a lè máa gbà wá àlàáfíà pẹ̀lú àwọn tá à ń wàásù “ìhìn rere àlàáfíà” fún. (Éfé. 6:15) Ó tún ń mú ká túbọ̀ gbára dì láti ‘jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ sí gbogbo ènìyàn, ká sì máa kó ara wa ní ìjánu lábẹ́ ibi.’—2 Tím. 2:24.
19 Rántí, pẹ̀lú, pé “àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo” yóò wà. (Ìṣe 24:15) Jèhófà máa jí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn tí ìṣesí wọn, ànímọ́ wọn àti ibi tí wọ́n ti wá yàtọ̀ síra dìde, títí kan àwọn tó gbé láyé “láti ìgbà pípilẹ̀ ayé”! (Lúùkù 11:50, 51) Dájúdájú, àǹfààní ńlá ló máa jẹ́ láti kọ́ àwọn tó jíǹde bí wọ́n á ṣe máa gbé lálàáfíà. Ẹ sì wo bí ìdálẹ́kọ̀ọ́ tá à ń rí gbà nísinsìnyí, ka lè jẹ́ ẹni tó ń wá àlàáfíà, ṣe máa ṣèrànwọ́ fún wa tó nígbà yẹn!
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún ìtọ́sọ́nà Ìwé Mímọ́ nípa bá a ṣe lè bójú tó àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì bí ìbanilórúkọjẹ́ àti jìbìtì, wo Ilé Ìṣọ́, October 15, 1999, ojú ìwé 17 sí 22.
Ẹ̀kọ́ Wo Lo Kọ́?
• Bá a bá ṣẹ ẹnì kan, báwo la ṣe lè wá àlàáfíà?
• Kí la gbọ́dọ̀ ṣe láti wá àlàáfíà bí ẹnì kan bá ṣẹ̀ wá?
• Bí awuyewuye bá wáyé láàárín ẹni méjì, kí nìdí tí kò fi bọ́gbọ́n mu pé ká gbè sẹ́yìn ẹnì kan nínú wọn?
• Ṣàlàyé ìdí tí a kò fi gbọ́dọ̀ wá àlàáfíà lọ́nàkọnà.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn tó bá ń dárí ji àwọn ẹlòmíràn ní fàlàlà