“Olúkúlùkù Ni Yóò Ru Ẹrù Ti Ara Rẹ̀”
“Olúkúlùkù wa ni yóò ṣe ìjíhìn ara rẹ̀ fún Ọlọ́run.”—Róòmù 14:12.
1. Ojúṣe wo làwọn ọ̀dọ́ Hébérù mẹ́ta kan ṣe?
ÀWỌN ọ̀dọ́ Hébérù mẹ́ta kan, Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò, tó ń gbé ní Bábílónì ní ìpinnu kan láti ṣe, èyí tó jẹ́ pé ó la ikú lọ. Ìpinnu náà ni pé, ṣé kí wọ́n tẹrí ba fún ère gìrìwò kan, bí òfin orílẹ̀-èdè yẹn ṣe pa á láṣẹ ni, àbí kí wọ́n kọ̀ láti júbà ère náà kí wọ́n sì jù wọ́n sínú iná ìléru? Ìpinnu ojú ẹsẹ̀ ni, láìsí pé wọ́n ń fọ̀rọ̀ lọ ẹnikẹ́ni. Kì í tiẹ̀ ṣe ohun tó yẹ kí wọ́n fọ̀rọ̀ lọ ẹnikẹ́ni lé lórí pàápàá. Ojú ẹsẹ̀ ni wọ́n sọ pé: “Kí ó di mímọ̀ fún ọ, ọba, pé àwọn ọlọ́run rẹ kì í ṣe èyí tí àwa ń sìn, àwa kì yóò sì jọ́sìn ère wúrà tí o gbé kalẹ̀.” (Dáníẹ́lì 3:1-18) Àwọn Hébérù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí ru ẹrù ara wọn, ìyẹn ni pé wọ́n ṣe ojúṣe wọn nípa fífúnra wọn ṣèpinnu.
2. Ta ló gba ìpinnu ṣe fún Pílátù lórí ọ̀rọ̀ Jésù Kristi, ǹjẹ́ ìyẹn sì fi hàn pé ọwọ́ Pílátù mọ́ nínú ọ̀ràn náà?
2 Ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún mẹ́fà lẹ́yìn ìgbà yẹn, àwọn kan mú ẹjọ́ Jésù wá síwájú Pọ́ńtù Pílátù, ará Róòmù tó jẹ́ gómìnà. Nígbà tó wo ẹjọ́ ọ̀hún látòkèdélẹ̀, ó dá a lójú pé Jésù ò ṣẹ̀ rárá. Ṣùgbọ́n àwọn èrò tó wà níbẹ̀ ní kó ṣáà pa á. Gómìnà yìí ò kọ́kọ́ gbà sí wọn lẹ́nu, àmọ́ nígbà tó yá ó fi ojúṣe rẹ̀ sílẹ̀, ó ṣe ohun tí wọ́n wí. Ó wẹ ọwọ́ rẹ̀, ó ní: “Ọwọ́ mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀jẹ̀ ọkùnrin yìí.” Ó wá fi Jésù lé wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lọ kàn án mọ́gi. Dípò kí Pílátù ṣe ojúṣe rẹ̀, kí ó fúnra rẹ̀ ṣèpinnu lórí ọ̀rọ̀ Jésù Kristi, ńṣe ló jẹ́ káwọn èèyàn gba ìpinnu ṣe fóun. Bó tiẹ̀ wẹ ọwọ́ rẹ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ, ọwọ́ rẹ̀ ò lè mọ́ nínú pípa tó ní kí wọ́n lọ pa Jésù aláìṣẹ̀.—Mátíù 27:11-26; Lúùkù 23:13-25.
3. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa jẹ́ káwọn èèyàn gba ìpinnu ṣe fún wa?
3 Ìwọ ńkọ́? Bí ọ̀ràn bá kan ìpinnu ṣíṣe, ṣé bíi tàwọn Hébérù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yẹn lo máa ń ṣe ni, àbí o máa ń jẹ́ káwọn èèyàn gba ìpinnu ṣe fún ọ? Ká sòótọ́, ìpinnu ṣíṣe kò rọrùn. Èèyàn ní láti dàgbà dénú kéèyàn tó lè ṣèpinnu tó tọ́. Bí àpẹẹrẹ, àwọn òbí ní láti máa bá àwọn ọmọ wọn kéékèèké ṣèpinnu tó dára. Lóòótọ́, ó máa ń ṣòro láti ṣèpinnu tí ọ̀ràn bá díjú tó sì tún gba pé ká gbé ọ̀pọ̀ nǹkan yẹ̀ wò. Ṣùgbọ́n, ìpinnu ṣíṣe kì í ṣe ohun tó wá wúwo jù débi tí a ó fi kà á kún ara “àwọn ẹrù ìnira” tàbí àwọn ohun tó ń kó wàhálà báni táwọn tó “tóótun nípa tẹ̀mí” lè bá wa gbé. (Gálátíà 6:1, 2) Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ ara àwọn ohun tí “olúkúlùkù wa [yóò ti] ṣe ìjíhìn ara rẹ̀ fún Ọlọ́run.” (Róòmù 14:12) Bíbélì sọ pé: “Olúkúlùkù ni yóò ru ẹrù ti ara rẹ̀.” (Gálátíà 6:5) Ṣùgbọ́n báwo la ṣe lè máa ṣe àwọn ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, a ní láti mọ̀ dájú pé ó níbi tí òye ọmọ èèyàn mọ, ká sì tún mọ àwọn nǹkan tá a lè ṣe nípa ìyẹn.
Ohun Pàtàkì Tí A Ní Láti Mọ̀
4. Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo la rí kọ́ látinú àìgbọràn tọkọtaya àkọ́kọ́ nípa ìpinnu ṣíṣe?
4 Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìran èèyàn, tọkọtaya àkọ́kọ́ ṣe ìpinnu tó kó ìran èèyàn síyọnu. Wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ lọ jẹ èso igi ìmọ̀ rere àti búburú. (Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17) Kí ló sún wọn ṣe ìpinnu yẹn? Bíbélì sọ pé: “Obìnrin náà rí i pé igi náà dára fún oúnjẹ àti pé ohun kan tí ojú ń yánhànhàn fún ni, bẹ́ẹ̀ ni, igi náà fani lọ́kàn mọ́ra láti wò. Nítorí náà, ó mú nínú èso rẹ̀, ó sì jẹ ẹ́. Lẹ́yìn náà, ó fún ọkọ rẹ̀ ní díẹ̀ pẹ̀lú nígbà tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, òun náà sì jẹ ẹ́.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:6) Ìfẹ́ ìmọtara-ẹni-nìkan ló sún Éfà ṣe ìpinnu yẹn. Ohun tó sì ṣe ló mú kí Ádámù náà ṣàìgbọràn. Bí ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú ṣe “tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo èèyàn” nìyẹn. (Róòmù 5:12) Ó yẹ kí àìgbọràn Ádámù àti Éfà kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì kan nípa ibi tí òye ọmọ èèyàn mọ. Ẹ̀kọ́ yẹn ni pé: Tí àwa ọmọ èèyàn ò bá máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run nígbà gbogbo, ìpinnu tí kò tọ̀nà la óò máa ṣe.
5. Báwo ni Jèhófà ṣe ń tọ́ wa sọ́nà, kí la sì ní láti ṣe láti lè jàǹfààní rẹ̀?
5 A dúpẹ́ gan-an ni pé Jèhófà Ọlọ́run ń tọ́ wa sọ́nà! Ìwé Mímọ́ sọ fún wa pé: “Etí rẹ yóò sì gbọ́ ọ̀rọ̀ kan lẹ́yìn rẹ tí ń sọ pé: ‘Èyí ni ọ̀nà. Ẹ máa rìn nínú rẹ̀,’ bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ lọ sí apá ọ̀tún tàbí bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ lọ sí apá òsì.” (Aísáyà 30:21) Jèhófà máa ń tipa Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ bá wa sọ̀rọ̀. Nítorí náà, a ní láti kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́, ká ní ìmọ̀ tó péye nípa rẹ̀. A ní láti máa jẹ “oúnjẹ líle [tó] jẹ́ ti àwọn ènìyàn tí ó dàgbà dénú” ká lè máa ṣèpinnu tó tọ́. A tún ní láti máa “tipasẹ̀ lílò kọ́ agbára ìwòye [wa] láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.” (Hébérù 5:14) Ọ̀nà tá a lè gbà kọ́ agbára ìwòye wa ni pé ká máa fi àwọn ohun tá à ń kọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò.
6. Kí la ní láti ṣe kí ẹ̀rí ọkàn wa tó lè máa ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ?
6 Ẹ̀rí ọkàn tí Ọlọ́run dá mọ́ wa wà lára ohun pàtàkì tá à ń lò tá a bá fẹ́ ṣèpinnu. Ẹ̀rí ọkàn yìí lè ṣèdájọ́ wa, ó sì lè ‘fẹ̀sùn kàn wá tàbí kó gbè wá lẹ́yìn pàápàá.’ (Róòmù 2:14, 15) Àmọ́ a ní láti fi ìmọ̀ pípéye látinú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run la ẹ̀rí ọkàn wa lóye kó tó lè máa ṣiṣẹ́ dáadáa, a sì ní láti máa fi ìtọ́ni inú Bíbélì sílò kí ẹ̀rí ọkàn wa tó lè máa gún wa ní kẹ́ṣẹ́ bó ṣe yẹ. Tá ò bá fi Bíbélì tọ́ ẹ̀rí ọkàn wa sọ́nà, kíá ni àṣà ìbílẹ̀, ìwà àti ìṣe àwọn èèyàn tó wà láyìíká wa, àti èrò àwọn ẹlòmíràn tètè máa ń lágbára lórí rẹ̀. Irú ẹ̀rí ọkàn bẹ́ẹ̀ sì lè ṣì wá lọ́nà. Àmọ́ tí ẹ̀rí ọkàn bá ń gún wa ní kẹ́ṣẹ́ lemọ́lemọ́ tá ò kà á sí, tá a sì ń tẹ àwọn ìlànà Ọlọ́run lójú ńkọ́? Ó lè gíràn-án tó bá yá, kó wá kú tipiri bí ojú ibi tí wọ́n fi “irin ìsàmì” gbígbóná jó lára èèyàn, kó sì yigbì. (1 Tímótì 4:2) Ṣùgbọ́n ní ti ẹ̀rí ọkàn tá a bá fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run là lóye, ńṣe ló máa ń tọ́ni sọ́nà bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ.
7. Ohun pàtàkì wo la ní láti ṣe ká lè máa ṣèpinnu tó bọ́gbọ́n mu?
7 Nígbà náà, ohun pàtàkì tó máa jẹ́ ká lè máa fúnra wa ṣèpinnu tó bọ́gbọ́n mu ni pé ká mọ Ìwé Mímọ́ jinlẹ̀jinlẹ̀ ká sì mọ bá a ṣe lè fi ìmọ̀ yẹn sílò. Kò yẹ ká máa sáré ṣèpinnu láìronújinlẹ̀ nígbà tọ́ràn bá délẹ̀, dípò ìyẹn, ńṣe ló yẹ ká máa fara balẹ̀ yẹ àwọn ìlànà Bíbélì wò, ká ronú lé wọn lórí ká sì lò wọ́n. Kódà tó bá tiẹ̀ di pé a ní láti ṣèpinnu ojú ẹsẹ̀, gẹ́gẹ́ bíi ti Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò, kò ní bá wa lábo tí ohun tí Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ bá ti yé wa dáadáa, tá a sì ti fi Bíbélì kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa. Ẹ jẹ́ ká wá gbé apá méjì nínú ìgbésí ayé wa yẹ̀ wò, tó máa jẹ́ ká rí bí ìtẹ̀síwájú wa nípa tẹ̀mí ṣe lè jẹ́ ká túbọ̀ mọ bá a ṣe lè máa ṣèpinnu tó bọ́gbọ́n mu.
Àwọn Wo Ló Yẹ Ká Máa Bá Kẹ́gbẹ́?
8, 9. (a) Àwọn ìlànà wo ló fi hàn pé ó yẹ ká yẹra fún ẹgbẹ́ búburú? (b) Ṣé kìkì ìgbà tá a bá ń bá àwọn oníwàkiwà rìn nìkan là ń kẹ́gbẹ́ búburú? Ṣàlàyé.
8 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Kí a má ṣì yín lọ́nà. Ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́.” (1 Kọ́ríńtì 15:33) Jésù Kristi sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ kì í ṣe apá kan ayé.” (Jòhánù 15:19) Bí a bá ti mọ àwọn ìlànà yìí, kì í pẹ́ ká tó rí i pé kò yẹ ká máa bá àwọn àgbèrè, panṣágà, olè, ọ̀mùtípara àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ kẹ́gbẹ́. (1 Kọ́ríńtì 6:9, 10) Ṣùgbọ́n bí ìmọ̀ òtítọ́ tá a ní nínú Bíbélì ṣe ń jinlẹ̀ sí i, a óò tún rí i pé irú ewu kan náà la máa fi ara wa sí tá a bá ń jókòó ti irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ nípa wíwò wọ́n nínú sinimá, lórí tẹlifíṣọ̀n, lórí ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà tàbí ká máa kàwé tó sọ̀rọ̀ nípa wọn. Bákan náà ló ṣe léwu láti máa bá “àwọn tí ń fi ohun tí wọ́n jẹ́ pa mọ́” kẹ́gbẹ́ nípa bíbá wọn fọ̀rọ̀ jomi toro ọ̀rọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì.—Sáàmù 26:4.
9 Àwọn tí kì í ṣe oníwàkiwà àmọ́ tí wọn ò nígbàgbọ́ tó jinlẹ̀ nínú Ọlọ́run tòótọ́ ńkọ́, ǹjẹ́ ó yẹ ká máa rìn mọ́ wọn? Ìwé Mímọ́ sọ fún wa pé: “Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (1 Jòhánù 5:19) Ìyẹn jẹ́ ká rí i pé àwọn oníwà ìbàjẹ́ àtàwọn tó ń gba ìwà ìbàjẹ́ láyè nìkan kọ́ ló lè jẹ́ ẹgbẹ́ búburú. Nítorí náà, á dáa kó jẹ́ pé àwọn tó fẹ́ràn Jèhófà nìkan la yàn lọ́rẹ̀ẹ́ tímọ́tímọ́.
10. Kí ni yóò jẹ́ ká lè ṣe ìpinnu tó dára tó bá di ọ̀ràn níní àjọṣe pẹ̀lú àwọn èèyàn ayé?
10 Kò sí bá ò ṣe ní ní ìfarakanra rárá pẹ̀lú àwọn èèyàn ayé, Ọlọ́run pàápàá ò sọ pé ohunkóhun ò gbọ́dọ̀ dà wá pọ̀. (Jòhánù 17:15) Tá a bá lọ sóde ẹ̀rí, tàbí ilé ìwé, tàbí ibi iṣẹ́, kò sí bá ò ṣe ní lájọṣe kan tàbí òmíràn pẹ̀lú àwọn tí kì í ṣe ìránṣẹ́ Jèhófà. Kristẹni kan tí ọkọ tàbí aya rẹ̀ jẹ́ aláìgbàgbọ́ yóò máa ní ìfarakanra pẹ̀lú àwọn èèyàn ayé ju àwọn Kristẹni tí kò sí nírú ipò yẹn lọ. Ṣùgbọ́n tá a bá lo agbára ìwòye wa, àá rí i pé kéèyàn ní àjọṣe tó mọ níwọ̀n pẹ̀lú àwọn èèyàn ayé yàtọ̀ pátápátá sí pé ká kúkú máa bá wọn ṣe wọléwọ̀de. (Jákọ́bù 4:4) Tá a bá sì fi èyí sọ́kàn, a ó lè máa ṣèpinnu tó dára tó bá dọ̀rọ̀ kíkópa nínú àwọn ìgbòkègbodò kan lẹ́yìn iléèwé, irú bí eré ìdárayá àti ijó jíjó, tàbí lílọ síbi àpèjẹ táwọn ará ibi iṣẹ́ wa bá pè wá sí.
Bá A Bá Ń Wáṣẹ́
11. Kí la óò kọ́kọ́ ronú lé lórí tá a bá fẹ́ yan irú iṣẹ́ tí a ó ṣe?
11 Tá a bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì lọ́nà tó fi hàn pé a lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jinlẹ̀, èyí yóò ràn wá lọ́wọ́ nígbà tá a bá ń ṣèpinnu nípa bá a ó ṣe ṣe ojúṣe wa láti ‘pèsè fún àwọn tí í ṣe mẹ́ńbà agbo ilé wa.’ (1 Tímótì 5:8) Ohun tó yẹ ká kọ́kọ́ ronú lé lórí ni irú iṣẹ́ tí iṣẹ́ tá a fẹ́ ṣe jẹ́, ìyẹn ohun tí a óò máa ṣe níbẹ̀. Láìsí àní-àní, kò tọ̀nà ká lọ máa ṣe iṣẹ́ tó ń ṣètìlẹyìn fún ohun tí Bíbélì kà léèwọ̀. Ìdí nìyẹn tí Kristẹni tòótọ́ kì í fi í ṣe iṣẹ́ tó jẹ mọ́ ìbọ̀rìṣà, olè jíjà, gbígba ẹ̀jẹ̀ sára tàbí lílò ó lọ́nà míì tí kò bófin Ọlọ́run mu, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í ṣe àwọn iṣẹ́ míì tó jẹ mọ́ ìwà tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu. A ò ní jẹ́ purọ́ tàbí ká rẹ́ni jẹ, bí ọ̀gá ibi iṣẹ́ wa bá tiẹ̀ ní ká ṣe bẹ́ẹ̀.—Ìṣe 15:29; Ìṣípayá 21:8.
12, 13. Tá a bá fẹ́ ṣèpinnu nípa iṣẹ́ tá a fẹ́ ṣe, àwọn nǹkan wo la óò ronú lé lórí yàtọ̀ sí iṣẹ́ yẹn gan-an fúnra rẹ̀?
12 Bí iṣẹ́ yẹn kò bá rú òfin Ọlọ́run kankan ní tààràtà ńkọ́? Bí ìmọ̀ wa nínú òtítọ́ bá ṣe ń jinlẹ̀ tí agbára ìwòye wa sì túbọ̀ ń jí pépé, a óò rí i àwọn nǹkan pàtàkì míì tá a gbọ́dọ̀ gbé yẹ̀ wò. Bí iṣẹ́ yẹn yóò bá mú ká lọ́wọ́ nínú àwọn ohun tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu ńkọ́, irú bíi kéèyàn máa bá wọn dáhùn ẹ̀rọ tẹlifóònù níbi tí wọ́n ti ń ta tẹ́tẹ́? Bákan náà, ó yẹ ká tún ronú nípa àwọn tí yóò máa sanwó iṣẹ́ wa fún wa àti ibi tí iṣẹ́ tá a máa ṣe yẹn wà. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá jẹ́ ẹni tó ń fúnra rẹ̀ gba iṣẹ́ ṣe, ǹjẹ́ a óò gba iṣẹ́ kíkun ṣọ́ọ̀ṣì ká wá tipa bẹ́ẹ̀ máa ṣètìlẹyìn fún ìsìn èké?—2 Kọ́ríńtì 6:14-16.
13 Tó bá wá ṣẹlẹ̀ nígbà kan pé ọ̀gá ibi iṣẹ́ wa gba iṣẹ́ kíkun ṣọ́ọ̀ṣì tàbí ibi ìjọsìn èké kan ńkọ́? Nírú ipò yìí, ó yẹ ká ronú lórí bí a ṣe láṣẹ tó lórí iṣẹ́ tí wọ́n fẹ́ ṣe, àti ipa tá a máa kó nínú iṣẹ́ náà. Tó bá wá jẹ́ iṣẹ́ tí kò tẹ ìlànà Bíbélì lójú ńkọ́, irú bí iṣẹ́ pínpín lẹ́tà kiri nílùú, títí dé ibi tí èèyàn ti lè kọ́ ìwàkiwà? Ǹjẹ́ kò ní dára ká gbé ìlànà tó wà nínú Mátíù 5:45 yẹ̀ wò tá a bá ń ṣèpinnu wa? Bákan náà, ó ṣe pàtàkì pé ká ronú lórí ipa tí ṣíṣe iṣẹ́ náà lójoojúmọ́ lè ní lórí ẹ̀rí ọkàn wa. (Hébérù 13:18) Láti lè ṣe ojúṣe wa, ká ṣèpinnu tó máa fi hàn pé a dàgbà dénú nínú àwọn nǹkan bí irú iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tó yẹ ká ṣe, a gbọ́dọ̀ rí i pé agbára ìwòye wa jí pépé, ká sì fi ẹ̀kọ́ Bíbélì tọ́ ẹ̀rí ọkàn tí Ọlọ́run fún wa sọ́nà.
“Ṣàkíyèsí Rẹ̀ ní Gbogbo Ọ̀nà Rẹ”
14. Tá a bá fẹ́ ṣèpinnu, kí làwọn nǹkan tó yẹ ká máa ronú lé lórí nígbà gbogbo?
14 Tó bá wá kan àwọn ìpinnu tí a ó ṣe lórí àwọn ọ̀ràn míì ńkọ́, irú bíi bóyá ká lépa ẹ̀kọ́ ayé tàbí ká má lépa rẹ̀, ká gba irú ìtọ́jú kan tàbí ká kọ̀ ọ́? Tó bá ṣáà ti jẹ́ ọ̀rọ̀ ká ṣèpinnu, ńṣe ni ká wá àwọn ìlànà Bíbélì tó jẹ mọ́ ọ̀ràn tá a fẹ́ ṣèpinnu lé lórí, ka ronú lé wọn, ká sì tẹ̀ lé wọn. Sólómọ́nì, ọlọ́gbọ́n ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì, sọ pé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.”—Òwe 3:5, 6.
15. Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ lára àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní nípa ọ̀rọ̀ ìpinnu ṣíṣe?
15 Ohun tá a bá ṣe sábà máa ń nípa lórí àwọn ẹlòmíràn, nítorí náà ó yẹ ká máa ro ìyẹn náà mọ́ ohun tá a bá fẹ́ ṣe. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ nínú òfin má-jẹ-tibí má-jẹ-tọ̀hún tó wà nínú Òfin Mósè kò de àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní. Tí wọ́n bá fẹ́, wọ́n lè jẹ àwọn oúnjẹ kan tí Òfin Mósè kà sí àìmọ́, àyàfi tó bá jẹ́ èyí tí kò yẹ kí Kristẹni jẹ nítorí ìdí mìíràn. Ṣùgbọ́n àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí wọn nípa ẹran tó ṣeé ṣe kí wọ́n ti lò lára rẹ̀ nílé òrìṣà, ó ní: “Bí oúnjẹ bá mú arákùnrin mi kọsẹ̀, dájúdájú, èmi kì yóò tún jẹ ẹran láé, kí n má bàa mú arákùnrin mi kọsẹ̀.” (1 Kọ́ríńtì 8:11-13) Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní yìí níyànjú pé kí wọ́n máa gba ti ẹ̀rí ọkàn àwọn ẹlòmíì rò kí wọ́n má bàa mú wọn kọsẹ̀. Èyí fi hàn pé a kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìpinnu wa di “okùnfà ìkọ̀sẹ̀” fáwọn ẹlòmíì.—1 Kọ́ríńtì 10:29, 32.
Gbàdúrà Pé Kí Ọlọ́run Fún Ọ Lọ́gbọ́n
16. Ìrànlọ́wọ́ wo ni àdúrà ń ṣe fún wa tá a bá fẹ́ ṣèpinnu?
16 Ó ṣe pàtàkì ká máa gbàdúrà tá a bá fẹ́ ṣèpinnu, torí ó ń ranni lọ́wọ́ gan-an. Ọmọ ẹ̀yìn náà Jákọ́bù sọ pé: “Bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá ṣaláìní ọgbọ́n, kí ó máa bá a nìṣó ní bíbéèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, nítorí òun a máa fi fún gbogbo ènìyàn pẹ̀lú ìwà ọ̀làwọ́ àti láìsí gíganni; a ó sì fi í fún un.” (Jákọ́bù 1:5) A lè gbàdúrà sí Jèhófà láìṣiyèméjì, ká bẹ̀ ẹ́ pé kó fún wa lọ́gbọ́n ká lè ṣèpinnu tó tọ́. Nígbà tá a bá sọ àníyàn ọkàn wa fún Ọlọ́run tòótọ́, tá a sì bẹ̀ ẹ́ pé kó tọ́ wa sọ́nà, ẹ̀mí mímọ́ lè jẹ́ ká túbọ̀ lóye àwọn ẹsẹ Bíbélì tá a bá gbé yẹ̀ wò, kó sì mú wa rántí èyí tí ọkàn wa bá fò.
17. Báwo làwọn ẹlòmíì ṣe lè ṣèrànwọ́ fún wa tá a bá fẹ́ ṣèpinnu?
17 Ǹjẹ́ àwọn ẹlòmíì lè ṣèrànlọ́wọ́ fún wa tá a bá fẹ́ ṣèpinnu? Bẹ́ẹ̀ ni o. Jèhófà ti ṣètò pé kí àwọn tó dàgbà dénú wà nínú ìjọ fún wa. (Éfésù 4:11, 12) A lè máa lọ gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ wọn, pàápàá tó bá jẹ́ pé ìpinnu pàtàkì kan la fẹ́ ṣe. Àwọn tí wọ́n ní òye tó jinlẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí wọ́n sì ti ní ìrírí lè rán wa létí àwọn ìlànà Bíbélì míì tó jẹ mọ́ ìpinnu tá a fẹ́ ṣe, wọ́n sì tún lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè “wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù.” (Fílípì 1:9, 10) Àmọ́ ṣá, ìkìlọ̀ kan rèé: A gbọ́dọ̀ kíyè sára, kó má di pé a wá jẹ́ káwọn ẹlòmíì gba ìpinnu ṣe fún wa. Ojúṣe wa ni.
Ṣé Gbogbo Ìpinnu Wa Ni Yóò Máa Yọrí sí Rere?
18. Kí ni ìpinnu dáadáa tá a bá ṣe lè yọrí sí?
18 Ǹjẹ́ gbogbo ìgbà ni ìpinnu tá a bá fara balẹ̀ ṣe, tó sì bá àwọn ìlànà Bíbélì mu á máa yọrí sí rere? Bẹ́ẹ̀ ni, nítorí pé gbogbo rẹ̀ ni yóò já sí rere nígbẹ̀yìn gbẹ́yín. Àmọ́ nígbà míì, ìyà lè kọ́kọ́ jẹ wá nítorí ìpinnu tá a ṣe. Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò mọ̀ pé wọ́n lè pa àwọn báwọn ṣe pinnu láti má ṣe júbà ère gìrìwò yẹn. (Dáníẹ́lì 3:16-19) Bákan náà, lẹ́yìn táwọn àpọ́sítélì sọ fún àjọ Sànhẹ́dírìn àwọn Júù pé àwọn gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò èèyàn, wọ́n kọ́kọ́ nà wọ́n ná kí wọ́n tó tú wọn sílẹ̀. (Ìṣe 5:27-29, 40) Yàtọ̀ síyẹn, “ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀” lè máà jẹ́ kí ìpinnu wa yọrí sí bá a ṣe fẹ́. (Oníwàásù 9:11) Bí a bá jìyà lọ́nà kan tàbí òmíràn lẹ́yìn tá a ti ṣèpinnu tó tọ̀nà, kí ó dá wa lójú pé Jèhófà yóò ṣèrànwọ́ fún wa ká lè fara dà á, yóò sì bù kún wa lọ́jọ́ iwájú.—2 Kọ́ríńtì 4:7.
19. Báwo la ṣe lè máa fìgboyà ṣe ojúṣe wa tó bá dọ̀rọ̀ ìpinnu ṣíṣe?
19 Nítorí náà tá a bá fẹ́ ṣèpinnu, ńṣe ló yẹ ká máa wá àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ tó jẹ mọ́ ìpinnu wa, ká ronú lé wọn lórí ká sì lò wọ́n. A mà dúpẹ́ gan-an o pé Jèhófà ń pèsè ìrànlọ́wọ́ fún wa nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ àtàwọn ará tó dàgbà dénú nínú ìjọ! Nígbà tá a sì ti nírú ìrànlọ́wọ́ àti ìtọ́sọ́nà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká nígboyà, ká máa fúnra wa ṣèpinnu tó bọ́gbọ́n mu, nítorí ojúṣe wa ni.
Ẹ̀kọ́ Wo Lo Kọ́?
• Kí lohun pàtàkì tá a ní láti ṣe tá a bá fẹ́ ṣèpinnu tó dára?
• Báwo ni ìtẹ̀síwájú wa nípa tẹ̀mí ṣe lè jẹ́ ká mọ irú àwọn tó yẹ ká bá kẹ́gbẹ́?
• Àwọn kókó pàtàkì wo ló yẹ ká ronú lé lórí nígbà tá a bá ń ṣèpinnu nípa iṣẹ́ tá a fẹ́ ṣe?
• Àwọn nǹkan wo ló lè ràn wá lọ́wọ́ tá a bá fẹ́ ṣèpinnu?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Àìgbọràn Ádámù àti Éfà kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Kó o tó ṣèpinnu pàtàkì, kọ́kọ́ wá àwọn ìlànà Bíbélì tó jẹ mọ́ ohun tó o fẹ́ ṣe ná