Ǹjẹ́ o Máa Ń ṣòótọ́ Nínú Gbogbo Nǹkan?
“Ẹni tí ó bá jẹ́ olùṣòtítọ́ nínú ohun tí ó kéré jù lọ jẹ́ olùṣòtítọ́ nínú ohun tí ó pọ̀ pẹ̀lú.”—LÚÙKÙ 16:10.
1. Kí ni ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tí Jèhófà gbà jẹ́ olùṣòtítọ́?
ǸJẸ́ o ti kíyè sí ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ sí òjìji igi bí ọjọ́ ṣe ń lọ? Ńṣe ni òjìji náà máa ń yí padà, kò sì ní dúró sójú kan. Bí òjìji ṣe máa ń yí padà bẹ́ẹ̀ gan-an ni ìlérí ọmọ aráyé àtohun tí wọ́n pinnu láti ṣe ń yí padà. Àmọ́ ṣá o, Jèhófà Ọlọ́run kì í yí padà nígbàkigbà. Nígbà tí Jákọ́bù ọmọ ẹ̀yìn Jésù pe Jèhófà ní “Baba àwọn ìmọ́lẹ̀ àtọ̀runwá,” ó sọ pé: “Kò . . . sí àyídà ìyípo òjìji lọ́dọ̀ rẹ̀.” (Jákọ́bù 1:17) Jèhófà kì í yí padà, ó sì ṣeé gbára lé, kódà nínú àwọn nǹkan tí ó kéré jù lọ pàápàá. “Ọlọ́run ìṣòtítọ́” ni Jèhófà.—Diutarónómì 32:4.
2. (a) Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣàyẹ̀wò ara wa láti mọ̀ bóyá olùṣòtítọ́ ni wá? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa gbé yẹ̀ wò nípa ìṣòtítọ́?
2 Ojú wo ni Ọlọ́run fi ń wo àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ tó jẹ́ olùṣòtítọ́? Ojú tí Dáfídì fi wò wọ́n náà ni Ọlọ́run fi ń wò wọ́n. Dáfídì sọ nípa wọn pé: “Ojú mi ń bẹ lára àwọn olùṣòtítọ́ ilẹ̀ ayé, kí wọ́n lè máa bá mi gbé. Ẹni tí ń rìn lọ́nà àìlálèébù, òun ni yóò máa ṣe ìránṣẹ́ fún mi.” (Sáàmù 101:6) Bẹ́ẹ̀ ni o, ńṣe ni inú Jèhófà máa ń dùn táwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ bá ń ṣòótọ́. Abájọ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi kọ̀wé pé: “Yàtọ̀ sí èyíinì, nínú ọ̀ràn yìí, ohun tí a ń retí nínú àwọn ìríjú ni pé kí a rí ènìyàn ní olùṣòtítọ́.” (1 Kọ́ríńtì 4:2) Kí ló túmọ̀ sí tá a bá sọ pé ẹnì kan jẹ́ olùṣòtítọ́? Inú àwọn nǹkan wo ló yẹ ká ti máa ṣòótọ́? Kí sì ni èrè téèyàn máa jẹ tó bá ń ‘rìn lọ́nà àìlálèébù’?
Ohun Tí Jíjẹ́ Olùṣòtítọ́ Túmọ̀ Sí
3. Kí ló máa fi hàn pé olùṣòtítọ́ ni wá?
3 Hébérù orí kẹta ẹsẹ ìkarùn-ún sọ pé: “Mósè gẹ́gẹ́ bí ẹmẹ̀wà . . . jẹ́ olùṣòtítọ́.” Kí ló mú kí Mósè wòlíì jẹ́ olùṣòtítọ́? Òun ni pé lákòókò tí wọ́n ń kọ́ àgọ́ ìjọsìn, “Mósè . . . ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún un. Ó ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́.” (Ẹ́kísódù 40:16) Àwa tá à ń jọ́sìn Jèhófà ń fi hàn pé a jẹ́ olùṣòtítọ́ nípa ṣíṣègbọràn sí Ọlọ́run bá a ṣe ń sìn ín. Èyí tún kan jíjẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà nígbà tá a bá dojú kọ ìdánwò tàbí ìṣòro tó lékenkà. Àmọ́ o, kì í ṣe ìgbà tá a bá yege àwọn ìdánwò ńlá nìkan ló máa hàn pé a jẹ́ olùṣòtítọ́. Jésù sọ pé: “Ẹni tí ó bá jẹ́ olùṣòtítọ́ nínú ohun tí ó kéré jù lọ jẹ́ olùṣòtítọ́ nínú ohun tí ó pọ̀ pẹ̀lú, ẹni tí ó bá sì jẹ́ aláìṣòdodo nínú ohun tí ó kéré jù lọ jẹ́ aláìṣòdodo nínú ohun tí ó pọ̀ pẹ̀lú.” (Lúùkù 16:10) Ó yẹ ká jẹ́ olùṣòtítọ́ kódà nínú àwọn nǹkan tó dà bíi pé kò tó nǹkan pàápàá.
4, 5. Kí ni ohun tí jíjẹ́ tá a bá jẹ́ olùṣòtítọ́ “nínú ohun tí ó kéré jù lọ” yóò fi hàn?
4 Ìdí méjì ló fi ṣe pàtàkì pé ká máa ṣègbọràn nínú “ohun tí ó kéré jù lọ” lójoojúmọ́. Ìdí àkọ́kọ́ ni pé tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ó ń fi irú ojú tá a fi ń wo Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ hàn. Ẹ̀yin ẹ wo ohun tí Ọlọ́run fi dán Ádámù àti Éfà, àwọn ẹ̀dá èèyàn àkọ́kọ́ wò, láti mọ̀ bóyá ẹni ìdúróṣinṣin ni wọ́n. Òfin tí Ọlọ́run fún wọn kì í ṣe èyí tó nira rárá. Gbogbo onírúurú oúnjẹ tí ń bẹ nínú ọgbà Édẹ́nì ni Ọlọ́run sọ fún wọn pé wọ́n lè máa jẹ àyàfi èso igi kan ṣoṣo lára àwọn igi tó wà níbẹ̀, ìyẹn “igi ìmọ̀ rere àti búburú.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17) Ká ní pé wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́, tí wọ́n pa òfin kékeré yẹn mọ́ ni, ìyẹn ì bá fi hàn pé ìṣàkóso Jèhófà ni wọ́n fara mọ́. Tá a bá ń tẹ̀ lé ìtọ́ni Jèhófà nínú àwọn nǹkan tá à ń ṣe lójoojúmọ́, èyí á fi hàn pé Jèhófà la fara mọ́ pé ó jẹ́ ọba aláṣẹ.
5 Ìdí kejì ni pé nǹkan tá a bá ṣe “nínú ohun tí ó kéré jù lọ” yóò nípa lórí nǹkan tá a máa ṣe nígbà tí “ohun tí ó pọ̀” bá délẹ̀, ìyẹn nígbà tá a bá dojú kọ àwọn nǹkan ńlá nígbèésí ayé wa. Lórí ọ̀rọ̀ yìí, ẹ wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Dáníẹ́lì àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́ta táwọn náà jẹ́ Hébérù, ìyẹn Hananáyà, Míṣáẹ́lì àti Asaráyà. Àwọn ará Bábílónì mú wọn nígbèkùn ní ọdún 617 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Nígbà táwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ṣì wà lọ́dọ̀ọ́, bóyá kí wọ́n tó pé ọmọ ogún ọdún, wọ́n kó wọn lọ sí ààfin Nebukadinésárì Ọba. Níbẹ̀, ọba sọ pé káwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ “ṣètò ohun tí a yọ̀ǹda lójoojúmọ́ fún wọn láti inú àwọn oúnjẹ adùnyùngbà ọba àti láti inú wáìnì tí ó ń mu, àní láti fi bọ́ wọn fún ọdún mẹ́ta, kí wọ́n bàa lè dúró níwájú ọba ní òpin ọdún mẹ́ta náà.”—Dáníẹ́lì 1:3-5.
6. Ìdánwò wo ni Dáníẹ́lì àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́ta táwọn náà jẹ́ Hébérù dojú kọ ní ààfin ọba Bábílónì?
6 Àmọ́ ìṣòro ni oúnjẹ tí ọba Bábílónì pèsè jẹ́ fáwọn ọ̀dọ́ Hébérù mẹ́rin yìí. Ó ṣeé ṣe káwọn oúnjẹ tí Òfin Mósè kà léèwọ̀ wà lára oúnjẹ adùnyùngbà tí ọba pèsè. (Diutarónómì 14:3-20) Ó ṣeé ṣe kí wọ́n má dúńbú àwọn ẹran tí wọ́n fi soúnjẹ náà, ó sì lòdì sí Òfin Ọlọ́run láti jẹ irú oúnjẹ bẹ́ẹ̀. (Diutarónómì 12:23-25) Ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n ti kọ́kọ́ fi àwọn oúnjẹ náà rúbọ sí òrìṣà, gẹ́gẹ́ bí àṣà àwọn ará Bábílónì, kí wọ́n tó jọ jẹ oúnjẹ náà pa pọ̀.
7. Kí ni ìgbọràn Dáníẹ́lì àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́ta fi hàn?
7 Láìsí àní-àní, ọ̀rọ̀ pé a ka oúnjẹ kan léèwọ̀ kì í ṣe ìṣòro rárá lójú àwọn aráalé ọba Bábílónì. Àmọ́ ṣá o, Dáníẹ́lì àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ pinnu pé àwọn ò ní fi oúnjẹ tí Òfin Mósè kà léèwọ̀ sọ ara wọn di ẹlẹ́gbin. Èyí jẹ́ ọ̀ràn tó kan ìdúróṣinṣin wọn àti ìṣòtítọ́ wọn sí Ọlọ́run. Nítorí náà, àwọn ọ̀dọ́ mẹ́rin náà ní kí wọ́n máa fáwọn ní ewébẹ̀ àti omi, wọ́n sì gbà láti máa fún wọn. (Dáníẹ́lì 1:9-14) Ohun táwọn ọ̀dọ́kùnrin mẹ́rin yẹn ṣe lè má jẹ́ nǹkan kan lójú àwọn kan lónìí. Àmọ́, ìgbọràn wọn sí Ọlọ́run fi hàn pé wọ́n fara mọ́ Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ.
8. (a) Ìdánwò ńlá wo làwọn Hébérù mẹ́ta yẹn dojú kọ tó dán ìdúróṣinṣin wọn wò? (b) Kí ni ìdánwò náà yọrí sí, kí sì ni èyí fi hàn?
8 Jíjẹ́ tí àwọn ọ̀rẹ́ Dáníẹ́lì mẹ́ta jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun tí ó dà bíi pé kò tó nǹkan ló jẹ́ kí wọ́n lè yege ìdánwò ńlá tí wọ́n bá pàdé. Jọ̀wọ́ ṣí Bíbélì rẹ sí Dáníẹ́lì orí kẹta, kó o sì fúnra rẹ ka ìtàn nípa bí wọ́n ṣe fẹ́ fìyà ikú jẹ àwọn Hébérù mẹ́ta náà tìtorí pé wọ́n kọ̀ láti jọ́sìn ère wúrà tí Nebukadinésárì Ọba gbé kalẹ̀. Nígbà tí wọ́n mú àwọn ọ̀dọ́ náà déwájú ọba, wọ́n sọ ìpinnu wọn fún un tìgboyàtìgboyà pé: “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run wa, ẹni tí àwa ń sìn lè gbà wá sílẹ̀. Òun yóò gbà wá sílẹ̀ kúrò nínú ìléru oníná tí ń jó àti kúrò ní ọwọ́ rẹ, ọba. Ṣùgbọ́n bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kí ó di mímọ̀ fún ọ, ọba, pé àwọn ọlọ́run rẹ kì í ṣe èyí tí àwa ń sìn, àwa kì yóò sì jọ́sìn ère wúrà tí o gbé kalẹ̀.” (Dáníẹ́lì 3:17, 18) Ǹjẹ́ Jèhófà gbà wọ́n sílẹ̀? Ọwọ́ iná náà pa àwọn ẹ̀ṣọ́ tó gbé àwọn ọ̀dọ́kùnrin náà jù sínú iná ìléru, àmọ́ àwọn olóòótọ́ Hébérù mẹ́ta náà jáde wá láàyè, kódà iná ìléru náà ò tiẹ̀ jó irun kan lára wọn! Òótọ́ tí wọ́n ń ṣe bọ̀ látẹ̀yìnwá ràn wọ́n lọ́wọ́ láti jẹ́ olóòótọ́ ní àkókò ìdánwò ńlá yìí. Ǹjẹ́ èyí ò fi hàn pé ó yẹ káwa náà jẹ́ olóòótọ́ nínú àwọn ohun tó kéré jù?
Jíjẹ́ Olùṣòtítọ́ Nínú Bá A Ṣe Ń Lo “Ọrọ̀ Àìṣòdodo”
9. Ọ̀rọ̀ wo ni Jésù ń bá bọ̀ kó tó sọ ọ̀rọ̀ tó wà nínú Lúùkù 16:10?
9 Kí Jésù tó sọ ìlànà yẹn pé ẹni tó bá jẹ́ olùṣòtítọ́ nínú ohun tí ó kéré jù lọ yóò jẹ́ olùṣòtítọ́ nínú nǹkan ńlá, ó gba àwọn tó ń fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ nímọ̀ràn pé: “Ẹ yan àwọn ọ̀rẹ́ fún ara yín nípasẹ̀ ọrọ̀ àìṣòdodo, kí ó bàa lè jẹ́ pé, nígbà tí irúfẹ́ bẹ́ẹ̀ bá kùnà, wọn yóò lè gbà yín sínú àwọn ibi gbígbé àìnípẹ̀kun.” Lẹ́yìn náà ló wá sọ ọ̀rọ̀ nípa jíjẹ́ olùṣòtítọ́ nínú ohun tí ó kéré jù lọ. Lẹ́yìn ìyẹn, Jésù sọ pé: “Nítorí náà, bí ẹ kò bá tíì fi ara yín hàn ní olùṣòtítọ́ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ọrọ̀ àìṣòdodo, ta ni yóò fi ohun tí ó jẹ́ òtítọ́ sí ìkáwọ́ yín? . . . Kò sí ìránṣẹ́ ilé tí ó lè jẹ́ ẹrú fún ọ̀gá méjì; nítorí pé, yálà yóò kórìíra ọ̀kan, tí yóò sì nífẹ̀ẹ́ èkejì, tàbí yóò fà mọ́ ọ̀kan, tí yóò sì tẹ́ńbẹ́lú èkejì. Ẹ kò lè jẹ́ ẹrú fún Ọlọ́run àti fún Ọrọ̀.”—Lúùkù 16:9-13.
10. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a jẹ́ olùṣòtítọ́ nípa bá a ṣe ń lo “ọrọ̀ àìṣòdodo”?
10 Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣáájú àtèyí tó wà lẹ́yìn ẹsẹ yẹn ṣe fi hàn, ọ̀rọ̀ nípa lílo “ọrọ̀ àìṣòdodo,” ìyẹn àwọn nǹkan ìní wa, ni Jésù ń sọ nígbà tó sọ ohun tó wà nínú Lúùkù 16:10. Ìdí tí Bíbélì fi pè é ní ọrọ̀ àìṣòdodo ni pé ìkáwọ́ èèyàn aláìpé làwọn nǹkan ìní ti ara wà, àgàgà owó. Yàtọ̀ síyẹn, téèyàn bá nífẹ̀ẹ́ sí kíkó ọrọ̀ jọ, ó lè mú kí onítọ̀hún hu àwọn ìwà àìṣòdodo. A ó fi hàn pé a jẹ́ olùṣòtítọ́ tá a bá ń lo ọgbọ́n nínú bá a ṣe ń lo àwọn nǹkan ìní wa. Dípò tí a óò fi máa lò wọ́n láti fi gbọ́ tara wa nìkan, ó yẹ ká máa lò wọ́n láti fi mú kí iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run tẹ̀ síwájú àti láti fi ran àwọn aláìní lọ́wọ́. Tá a bá jẹ́ olùṣòtítọ́ lọ́nà yìí, a óò di ọ̀rẹ́ Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi, àwọn sì lẹni tó ní “àwọn ibi gbígbé àìnípẹ̀kun.” Wọ́n yóò gbà wá sínú àwọn ibi gbígbé yìí, tó túmọ̀ sí pé wọn yóò fún wa ní ìyè àìnípẹ̀kun yálà ní ọ̀run tàbí ní Párádísè lórí ilẹ̀ ayé.
11. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ṣàlàyé fáwọn tá à ń wàásù fún pé a mọrírì ọrẹ tí wọ́n bá ṣe láti fi ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe kárí ayé?
11 Ẹ tún wo àǹfààní tá à ń jẹ́ káwọn tá à ń fún ní Bíbélì tàbí àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì ní nígbà tá a bá lọ wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún wọn tá a sì ṣàlàyé fún wọn pé a mọrírì ọrẹ tí wọ́n bá ṣe láti fi ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe kárí ayé. Ǹjẹ́ kì í ṣe àǹfààní tí wọ́n fi lè lo àwọn nǹkan ìní wọn lọ́nà tó dára jù lọ là ń fún wọn yẹn? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè lo àwọn nǹkan ìní ti ara ni Lúùkù 16:10 ń sọ, síbẹ̀ a lè tẹ̀ lé ìlànà inú rẹ̀ láwọn ọ̀nà mìíràn nígbèésí ayé.
Òótọ́ Ṣe Pàtàkì
12, 13. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà fi hàn pé a jẹ́ aláìlábòsí?
12 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Àwa ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé a ní ẹ̀rí-ọkàn aláìlábòsí, gẹ́gẹ́ bí a ti dàníyàn láti máa hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.” (Hébérù 13:18) Dájúdájú, ọ̀rọ̀ náà “ohun gbogbo” kan gbogbo ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ owó. A máa ń tètè san gbèsè tá a bá jẹ àti owó orí wa láìṣàbòsí. Kí nìdí tá a fi ń ṣe bẹ́ẹ̀? Ìdí tá a fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ jẹ́ nítorí ẹ̀rí-ọkàn wa àti ní pàtàkì nítorí ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run àti nítorí pé a fẹ́ pa ìtọ́ni rẹ̀ mọ́. (Róòmù 13:5, 6) Kí la máa ń ṣe nígbà tá a bá rí ohun kan tó sọ nù tí kì í ṣe tiwa? A máa ń dá nǹkan ọ̀hún padà fún oníǹkan. Ẹ ò rí i pé ìjẹ́rìí tó dára ló máa yọrí sí nígbà tá a bá ṣàlàyé ohun tó mú ká dá nǹkan tí kì í ṣe tiwa padà fún oníǹkan!
13 Jíjẹ́ olóòótọ́ àti jíjẹ́ aláìlábòsí nínú gbogbo nǹkan tún kan ìwà wa níbi iṣẹ́. Tá a bá jẹ́ aláìlábòsí níbi iṣẹ́, èyí máa jẹ́ káwọn èèyàn fẹ́ mọ̀ nípa Ọlọ́run tá à ń sìn. A kì í ‘jí’ àkókò tó yẹ ká fi ṣiṣẹ́ nípa ṣíṣe ọ̀lẹ. Dípò ìyẹn, ńṣe la máa ń mú iṣẹ́ wa bí iṣẹ́, bí ẹni pé Jèhófà là ń ṣe é fún. (Éfésù 4:28; Kólósè 3:23) Ìwádìí kan fi hàn pé lórílẹ̀-èdè kan nílẹ̀ Yúróòpù, ìdá kan nínú mẹ́ta lára àwọn òṣìṣẹ́ tó sọ pé àwọn ò lè wá síbi iṣẹ́ nítorí pé ara wọn ò yá ló jẹ́ pé irọ́ ńlá ni wọ́n pa. Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kì í parọ́ tìtorí kí wọ́n má bàa wá síbi iṣẹ́. Nígbà míì, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ní ìgbéga níbi iṣẹ́ nítorí pé àwọn tó gbà wọ́n ṣíṣẹ́ rí i pé wọ́n jẹ́ aláìlábòsí àti òṣìṣẹ́kára.—Òwe 10:4.
Jíjẹ́ Olùṣòtítọ́ Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa
14, 15. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tá a lè gbà fi hàn pé a jẹ́ olùṣòtítọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù tí àwa Kristẹni ń ṣe?
14 Báwo la ṣe lè fi hàn pé a jẹ́ olùṣòtítọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí Ọlọ́run fi síkàáwọ́ wa? Bíbélì sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí a máa rú ẹbọ ìyìn sí Ọlọ́run nígbà gbogbo, èyíinì ni, èso ètè tí ń ṣe ìpolongo ní gbangba sí orúkọ rẹ̀.” (Hébérù 13:15) Olórí ọ̀nà tá a lè gbà fi hàn pé a jẹ́ olùṣòtítọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù ni pé ká máa jáde òde ẹ̀rí déédéé. Ǹjẹ́ ó yẹ ká pa oṣù kan jẹ láìwàásù nípa Jèhófà àtàwọn nǹkan tó fẹ́ ṣe lọ́jọ́ iwájú? Síwájú sí i, tá a bá ń jáde òde ẹ̀rí nígbà gbogbo, a óò túbọ̀ mọ bá a ṣe lè gbọ́rọ̀ kalẹ̀, a óò sì túbọ̀ já fáfá nínú iṣẹ́ ìwàásù.
15 Ọ̀nà mìíràn tá a lè gbà fi hàn pé a jẹ́ olùṣòtítọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù ni pé ká máa tẹ̀ lé àwọn àbá tó máa ń wà nínú Ilé Ìṣọ́ àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Nígbà tá a bá múra sílẹ̀ tá a sì ń tẹ̀ lé àwọn àbá wọ̀nyí tàbí àwọn àbá mìíràn tó bá ìpínlẹ̀ wa mu, ǹjẹ́ iṣẹ́ ìwàásù wa kì í so èso rere? Nígbà tá a bá rí ẹnì kan tó nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run lóde ẹ̀rí, ǹjẹ́ a máa ń tètè padà lọ sọ́dọ̀ irú ẹni bẹ́ẹ̀ láti wá kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ síwájú sí i? Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá a bá bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ẹnì kan tó nífẹ̀ẹ́ sí ìhìn rere ńkọ́? Ǹjẹ́ a jẹ́ ẹni tó ń mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, tó sì ń ṣe àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ náà déédéé? Jíjẹ́ tá a bá jẹ́ olùṣòtítọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù lè yọrí sí ìyè àìnípẹ̀kun fún àwa àtàwọn tó bá fetí sílẹ̀ sí wa.—1 Tímótì 4:15, 16.
Bí A Ṣe Lè Ya Ara Wa Sọ́tọ̀ Nínú Ayé
16, 17. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà fi hàn pé a ya ara wa sọ́tọ̀ nínú ayé?
16 Nínú àdúrà tí Jésù gbà sí Ọlọ́run, ó sọ nípa àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Mo ti fi ọ̀rọ̀ rẹ fún wọn, ṣùgbọ́n ayé ti kórìíra wọn, nítorí pé wọn kì í ṣe apá kan ayé, gan-an gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe apá kan ayé. Èmi kò béèrè pé kí o mú wọn kúrò ní ayé, bí kò ṣe láti máa ṣọ́ wọn nítorí ẹni burúkú náà. Wọn kì í ṣe apá kan ayé, gan-an gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe apá kan ayé.” (Jòhánù 17:14-16) A lè pinnu látinú ọkàn wa wá pé a ò ní lọ́wọ́ nínú àwọn nǹkan ńlá táwọn èèyàn ayé ń ṣe, irú bí òṣèlú tàbí ogun, ayẹyẹ ìsìn, àwọn àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àti ìṣekúṣe. Àmọ́, tó bá dọ̀rọ̀ àwọn nǹkan kéékèèké ńkọ́? Ṣé kì í ṣe pé àwọn èèyàn ayé ti ń kéèràn ràn wá láwọn ọ̀nà kan táwa fúnra wa ò sì mọ̀? Bí àpẹẹrẹ tá ò bá ṣọ́ra, ká tó mọ̀ a lè bẹ̀rẹ̀ sí wọ aṣọ tí kò buyì kúnni tí kò sì bójú mu! Jíjẹ́ olùṣòtítọ́ béèrè pé ká jẹ́ ẹni tó ‘mẹ̀tọ́ mọ̀wà tó sì yè kooro ní èrò inú’ nínú ọ̀ràn aṣọ wíwọ̀ àti ọ̀nà tá a gbà ń múra. (1 Tímótì 2:9, 10) Bẹ́ẹ̀ ni o, “kò sí ọ̀nà kankan tí àwa gbà jẹ́ okùnfà èyíkéyìí fún ìkọ̀sẹ̀, kí a má bàa rí àléébù sí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa; ṣùgbọ́n lọ́nà gbogbo, a ń dámọ̀ràn ara wa fún ìtẹ́wọ́gbà gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Ọlọ́run.”—2 Kọ́ríńtì 6:3, 4.
17 Nítorí pé a fẹ́ láti fi ògo fún Jèhófà, à ń múra lọ́nà tó buyì kúnni nígbà tá a bá fẹ́ wá sáwọn ìpàdé ìjọ. Bá a ṣe ń ṣe náà nìyẹn nígbà tá a bá fẹ́ lọ sáwọn ìpàdé àyíká àti àgbègbè. Ó yẹ kí aṣọ tá a bá wọ̀ bá ohun tá a fẹ́ ṣe mu kó sì bójú mu. Ìjẹ́rìí lèyí jẹ́ fáwọn tó ń wò wá. Kódà àwọn áńgẹ́lì pàápàá ń rí ohun tá à ń ṣe bí wọ́n ṣe rí ohun tí Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni ń ṣe nígbà náà lọ́hùn ún. (1 Kọ́ríńtì 4:9) Nítorí náà, aṣọ tó bójú mu ló yẹ ká máa wọ̀ nígbà gbogbo. Àwọn kan lè máa fojú kékeré wo ọ̀rọ̀ irú aṣọ tó yẹ kéèyàn wọ̀, àmọ́ nǹkan ńlá ló jẹ́ lójú Ọlọ́run.
Ìbùkún Tá A Máa Rí Tá A Bá Jẹ́ Olùṣòtítọ́
18, 19. Àwọn ìbùkún wo lèèyàn máa gbádùn tó bá jẹ́ olùṣòtítọ́?
18 Bíbélì pe àwọn Kristẹni tòótọ́ ní “ìríjú àtàtà fún inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run tí a fi hàn ní onírúurú ọ̀nà.” Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n “gbára lé okun tí Ọlọ́run ń pèsè.” (1 Pétérù 4:10, 11) Yàtọ̀ síyẹn, pé a jẹ́ ìríjú túmọ̀ sí pé ohun tí Ọlọ́run fi sí wa níkàáwọ́ kì í ṣe tiwa, ìyẹn inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run, èyí tó kan iṣẹ́ ìwàásù. Bá a ṣe ń ṣe iṣẹ́ ìríjú wa bí iṣẹ́, a gbára lé agbára tí Ọlọ́run ń pèsè, ìyẹn “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá.” (2 Kọ́ríńtì 4:7) Ẹ ò rí i pé ẹ̀kọ́ tó dára gan-an lèyí jẹ́ láti ràn wá lọ́wọ́ láti kojú ìdánwò èyíkéyìí tá a lè bá pàdé lọ́jọ́ iwájú!
19 Onísáàmù náà kọ ọ́ lórin pé: “Ẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀. Jèhófà ń fi ìṣọ́ ṣọ́ àwọn olùṣòtítọ́.” (Sáàmù 31:23) Ẹ jẹ́ ká pinnu láti jẹ́ olùṣòtítọ́ nígbà gbogbo, ká mọ̀ dájú pé Jèhófà ni “Olùgbàlà gbogbo onírúurú ènìyàn, ní pàtàkì ti àwọn olùṣòtítọ́.”—1 Tímótì 4:10.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Kí nìdí tó fi yẹ ká jẹ́ “olùṣòtítọ́ nínú ohun tí ó kéré jù lọ”?
• Báwo la ṣe lè fi hàn pé a jẹ́ olùṣòtítọ́
nípa jíjẹ́ aláìlábòsí?
nínú iṣẹ́ ìwàásù?
nínú yíya ara wa sọ́tọ̀ nínú ayé?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Jẹ́ olùṣòtítọ́ nínú ohun tí ó kéré jù lọ kí o sì jẹ́ olùṣòtítọ́ nínú ohun tí ó pọ̀ pẹ̀lú
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
“Máa hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Ọ̀nà kan tá a lè gbà fi hàn pé a jẹ́ olùṣòtítọ́ ni pé ká máa múra sílẹ̀ dáadáa fún iṣẹ́ ìwàásù
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
Máa wọ aṣọ tó bójú mu kó o sì máa múra lọ́nà tó bójú mu